Pọọlu Ní Ilodisi Plato Lori Ọ̀rọ̀ Ajinde
APỌSITELI Pọọlu kọwe nipa ajinde ni 1 Kọrinti 15:35-58 ati 2 Kọrinti 5:1-10. Ni ṣiṣe bẹẹ, oun ha tẹ̀lé ero-ọkan ti aileeku ọkan ti Plato ati ti awọn ọmọran Giriiki, tabi oun ha wà ní iṣọkan pẹlu ẹkọ Jesu ati ti iyooku Iwe Mimọ bi?
Iwe pẹlẹbẹ naa Immortality of the Soul or Resurrection of the Individual: St. Paul’s View with Special Reference to Plato, ti a kọ ní 1974 ti a si fọwọ si nipasẹ biṣọọbu àgbà ti Ṣọọṣi Greek Orthodox ti North ati South America, funni ni idahun oníṣìípayá. Lẹhin jijiroro bi ajinde ti rí ninu awọn iwe mimọ ti a mẹnukan loke yii ati agbara idari awọn Giriiki ti akoko naa, onkọwe naa de ori ipari ero ti o tẹ̀lé e yii:
“Plato fi kọni pe ọkàn ń baa lọ ninu iwalaaye titilae ati alailopin, kuro ninu ara. Fun Plato ọkàn naa jẹ alaileeku lọna adanida ati lọna ajogunba . . . St. Paul kò kọni ni yala iru oju iwoye bẹẹ tabi ṣe ijẹwọ eyikeyii lati ṣe bẹẹ . . .
“Apọsiteli Pọọlu kò ṣaniyan nipa aileeku irisi ara tabi ti ẹmi gẹgẹ bi awọn apa ti o yatọ ti o si duro sọtọ ṣugbọn nipa ajinde gbogbo apapọ ẹmi-ọkan ara eniyan gẹgẹ bi abajade ajinde Jesu. Erongba Pọọlu nipa iru ara ti eniyan yoo ní ní ajinde kò ní ohunkohun iṣe pẹlu mimu awọn ara ti o ti ku pada si iye lati inu ipo oku.
“Erongba rẹ̀ nipa ajinde ara ni a le ṣalaye lọna ti o sanju gẹgẹ bi itunpada mubọsipo kan, atunda, ati ipadatunṣe, nipasẹ agbara Ọlọrun, ti gbogbo iṣọkan eniyan, ti ẹnikan naa, ti animọ iwa kan-naa, ti ọpọlọ-oun-ara kan-naa, ati animọ ọpọlọ ati ara ẹnikọọkan kan-naa. Ajinde wa ọjọ-ọla yoo ṣẹlẹ kii ṣe gẹgẹ bi ohun-ini adanida tiwa funraawa, ṣugbọn gẹgẹ bi ẹbun ologo ẹwà ti Ọlọrun.”
Bẹẹni, aileeku ọkan kii ṣe ohun-ini adanida eniyan eyikeyii. Dipo bẹẹ, o jẹ́ ẹbun oniyebiye ati oloore-ọfẹ lati ọwọ́ Jehofa nipasẹ Oluwa wa Jesu Kristi fun awọn wọnni ti wọn parapọ jẹ́ ijọ Kristẹni ti a fàmì òróró yàn.—1 Kọrinti 15:20, 57; Filipi 3:14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọmọran Giriiki naa Plato
[Credit Line]
Foto Vatican Museum