ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 6/1 ojú ìwé 9
  • Awọn Ọmọ Ile-ẹkọ Nigeria Ni a Bukun Fun Iṣotitọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Ọmọ Ile-ẹkọ Nigeria Ni a Bukun Fun Iṣotitọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí Àárín Èmi àti Olùkọ́ Mi Lè Gún?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kó Má Bàa Sí Wàhálà Láàárín Èmi àti Olùkọ́ Mi?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Kò Retí Pé Òun Á Ṣàṣeyọrí Tó Tóyẹn
    Jí!—2003
  • Àwọn Olùkọ́—Èé Ṣe Tá A Fi Nílò Wọn?
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 6/1 ojú ìwé 9

Awọn Olupokiki Ijọba Rohin

Awọn Ọmọ Ile-ẹkọ Nigeria Ni a Bukun Fun Iṣotitọ

APOSTELI Paulu kọwe pe: “Bi o lè ṣe, bi o ti wà ní ipa tiyin, ẹ maa wà ní alaafia pẹlu gbogbo eniyan.” (Romu 12:18) Awọn ọmọ ile-ẹkọ ti wọn jẹ awọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Nigeria fi imọran yii silo, ani nigba ti a tilẹ ṣe inunibini si wọn paapaa. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, Jehofa bukun fun wọn.

◻ Olukọ kan kò fẹran Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa rárá. Lakooko apejọ títò sori ìlà ni owurọ ọjọ kan, o pe gbogbo Awọn Ẹlẹ́rìí naa wá sí iwaju o si paṣẹ fun wọn lati kọ orin orilẹ-ede. Wọn kọ̀, ni sisọ pe awọn fẹ lati fi ifọkansin ti a yasọtọ gédégédé fun Ọlọrun. Olukọ naa lẹhin eyi kó gbogbo wọn lọ si ìta o si sọ fun wọn lati gé koriko. Ni akoko yii, awọn akẹkọọ yooku ń bá ẹkọ wọn lọ ninu kilaasi.

Agbalagba Ẹlẹ́rìí kan mú iwe pẹlẹbẹ naa School and Jehovah’s Witnesses lọ fun olukọ naa, ní ṣiṣalaye iduro aidasi-tọtuntosi Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, olukọ naa kọ̀ lati jiroro ọran naa tabi lati gba iwe pẹlẹbẹ naa. Niti tootọ, oun lẹsẹkẹsẹ mu ijiya awọn ọmọ naa gbóná-janjan sii.

Awọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa naa ń baa lọ lati foriti ijiya yii wọn si ń baa lọ lati gé koriko naa ani nigba ti olukọ naa kò si nibẹ paapaa. Ní ọjọ kan olukọ naa farapamọ o sì ń wò wọn láìmọ̀ bi wọn ṣe ń baa lọ ní ṣiṣiṣẹ ti wọn si n kọrin Ijọba. Oun ni a wu lori tobẹẹ debi pe o dá wọn pada si kilaasi, ni fifi iyalẹnu han fun iṣarasihuwa wọn. Ki ni iyọrisi rẹ̀? Olukọ naa nisinsinyi ń ṣe ikẹkọọ Bibeli pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa!

Dajudaju awọn ọmọ ile-ẹkọ wọnyi ni a bukun fun nitori iṣotitọ wọn si Jehofa ati awọn ilana rẹ̀.—Owe 10:22.

◻ Ruth ati awọn ọrẹ rẹ̀ pẹlu ni a bukun fun nitori iṣotitọ wọn si awọn ohun ti Jehofa beere fun lati maṣe ‘jẹ́ apakan aye.’ (Johannu 17:16) Ruth, ẹni ti o jẹ́ ọmọ ọdun 18, bẹrẹ aṣaaju-ọna nigba ti o wà ní ọmọ ọdun 12. Oun ati Awọn Ẹlẹ́rìí miiran ni a ṣatako si lati ọ̀dọ̀ awọn mẹmba oṣiṣẹ ile-ẹkọ fun kíkọ̀ lati kọ orin orilẹ-ede. Olukọ kan sọ pe oun fẹ́ lati ri awọn obi ọmọbinrin naa. Lẹhin ti wọn ṣalaye, ni lilo iwe pẹlẹbẹ naa School, olukọ naa ní itẹlọrun kò si yọ awọn akẹkọọ naa lẹnu mọ́.

Bi o ti wu ki o ri, ní ọjọ kan, olukọ kan lati India fiwọsi lọ ọ̀kan ninu awọn ọmọbinrin naa o sì fiya jẹ ẹ́ niwaju kilaasi nigba ti kò kọ orin orilẹ-ede. Ọmọbinrin naa fi igboya gbeja ìgbàgbọ́ rẹ̀ olukọ naa si mu un lọ lati rí olukọ àgbà. Nigba ti wọn dé ibẹ̀, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí naa ri i pe igbakeji olukọ àgbà wà nibẹ pẹlu. Si iyalẹnu rẹ̀, olukọ àgba ati igbakeji olukọ àgbà bẹrẹ sii rẹrin-in. Ní yiyiju si olukọ naa, olukọ àgbà wi pe: “Màdáàmù, maṣe dààmú araarẹ nipa awọn ọmọbinrin wọnyi. Ani bi o bá tilẹ pa wọn paapaa, wọn yoo yan lati kú jù lati ka orin orilẹ-ede lọ. Ṣe iwọ ko tii gbọ́ nipa wọn ni?” Oun ati igbakeji rẹ̀ lẹhin naa sọrọ nipa ìgbàgbọ́ ati igboya Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ní bíbá ọmọbinrin naa sọrọ, olukọ àgbà naa wi pe oun káàánú fun ikotijubani ti o ti jiya rẹ̀. Lẹhin naa o fikun un pe: “Maa baa lọ ninu awọn iṣẹ ìgbàgbọ́ rẹ. Mo gba ti isin rẹ̀ ati ti iduro onigboya rẹ lẹhin-ode ati nihin-in ní ile-ẹkọ.” Lẹhin naa, olukọ naa ti o ti ṣàtakò tọrọ aforiji lọwọ Ẹlẹ́rìí naa, ni sisọ pe oun nisinsinyi loye iduro alaidasi tọtuntosi tí Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dìmú.

Awọn ọmọde wọnyi tẹ̀lé apẹẹrẹ awọn Heberu mẹta ti wọn ki yoo ba iwatitọ wọn si Ọlọrun jẹ́ nipa titẹriba fun ère kan, ati ti Daniẹli pẹlu, ti o kọ̀ lati dawọ gbigbadura si Jehofa duro. Awọn ọkunrin wọnyi ni Jehofa bukun fun nitori pe wọn jẹ́ oluṣotitọ si awọn ofin ododo ti Ọlọrun.—Daniẹli, ori 3 ati 6.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́