Irapada Kan ní Paṣipaarọ fun Ọpọlọpọ
NI MARCH 31, 1970, ọkọ ofuurufu kan ni a fipá jágbà nitosi Mount Fuji ni Japan. Mẹsan an lara mẹmba awọn awujọ kan ti a mọ̀ si Japanese Red Army Faction mu eyi ti o ju 120 èrò ati awọn mẹmba alaboojuto ọkọ ofuurufu naa ní àmúdá ti wọn si beere fun irin ajo kan ti kò léwu de North Korea.
Nigba ti ọkọ ofuurufu naa gunlẹ ni Seoul, Republic of Korea, igbakeji minista eto irinna ti ilẹ Japan Shinjiro Yamamura fínnúfíndọ̀ yọọda lati fi ẹmi araarẹ wewu nitori awọn ti a mu ní àmúdá naa. Ni gbigba lati tẹwọgba a gẹgẹ bi iduro fun aabo wọn, awọn afipájá nǹkan gbà naa tú gbogbo awọn ti wọn mú ní àmúdá silẹ ayafi awọn oṣiṣẹ ọkọ ofuurufu naa. Nigba naa ni wọn wa fò lọ si Pyongyang, nibi ti wọn ti túúbá fun awọn alaṣẹ ilẹ North Korea. Lẹhin naa Ọgbẹni Yamamura ati awakọ ofuurufu naa pada si Japan laini ipalara.
Ninu ọran yii, ẹnikan ṣiṣẹ gẹgẹ bii paṣipaarọ fun iwalaaye eyi ti o ju 120 eniyan ti a mu ní àmúdá. Eyi lè ṣeranwọ fun wa lati rí bi ọkunrin kan ṣe le fi ẹmi rẹ̀ lelẹ gẹgẹ bi irapada ni paṣipaarọ fun ọpọlọpọ. Ṣugbọn Flati loye ẹ̀kọ́ igbagbọ Bibeli nipa irapada, a gbọdọ ṣayẹwo kókó ẹ̀kọ́ yii lọna ti o tubọ ṣe kinnikinni.
un ohun kan, a gbọdọ tọpasẹ ipilẹṣẹ ẹ̀ṣẹ̀. “Nitori gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ̀ ti ti ipa ọdọ eniyan kan wọ aye, ati ikú nipa ẹ̀ṣẹ̀; bẹẹ ni ikú si kọja sori eniyan gbogbo, lati ọdọ ẹni ti gbogbo eniyan ti dẹ́ṣẹ̀,” ni Bibeli ṣalaye. (Romu 5:12) Bawo ni iyẹn ṣe ṣẹlẹ? Ọkunrin naa ti a mẹnukan nibẹ ni Adamu, eniyan ti a kọkọ dá. Iwọ lè ka akọsilẹ ọlọ́rọ̀ itan nipa iṣẹda rẹ̀ ati ohun ti o ṣamọna si ìmọ̀ọ́mọ̀yapa rẹ̀ kuro ninu ọ̀pá idiwọn Ọlọrun. Eyi ni a lalẹsẹẹsẹ ninu awọn ori mẹta akọkọ iwe inu Bibeli naa Genesisi.
Akọsilẹ yẹn fihan pe ọ̀dádá kan wà lẹhin awọn iṣẹlẹ naa nigba ti Adamu kọkọ dẹ́ṣẹ̀. Lati le tẹ́ ifẹkufẹẹ tirẹ lọrun, ọ̀dádá yẹn pete lati ṣakoso Adamu ati iru ọmọ eyikeyii ti oun lè ní. Ọdádá naa ni Satani Eṣu. A tun ń pe e ni “ejò laelae nì” nitori pe o lo ejò kan lati sin Adamu bọ́ sinu ẹ̀ṣẹ̀. (Ifihan 12:9) Bi o tilẹ jẹ pe Ẹlẹdaa naa ti o nifẹẹ iran eniyan ti sọ fun Adamu lati bọwọ fun ẹ̀tọ́ Rẹ̀ lati pinnu ohun ti o dara ati ohun ti kò dara, ejò naa fẹ̀tàn fa aya Adamu, Efa, sinu ṣiṣaigbọran si Ọlọrun. Oun lẹhin naa rọ ọkọ rẹ̀ lati ṣaigbọran. Lọna yẹn, Adamu fi idadurolominira kuro lọdọ Ọlọrun hàn ni gbangba, ni fífínnúfíndọ̀ yọọda lati di ẹlẹ́ṣẹ̀, ti o sì jẹ pe kìkì iru igbesi-aye bẹẹ ni oun lè fi ṣọwọ si awọn ọmọ rẹ̀.
A ṣì ń jiya awọn abajade naa. Bawo ni o ṣe ri bẹẹ? O dara, Ẹlẹdaa naa ti ṣofin lọna ẹ̀tọ́ pe bi Adamu ati Efa ba mọ̀ọ́mọ̀ yan aigbọran, ikú ni yoo jẹ iyọrisi rẹ̀. Nitori naa, nipa dídẹ́ṣẹ̀, Adamu ta gbogbo iran-eniyan sinu oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ati ikú.—Genesisi 2:17; 3:1-7.
Bawo ni a ṣe lè tun iran-eniyan rapada kuro ninu ipo ẹ̀ṣẹ̀ yẹn? Jesu Kristi wa si aye “lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe irapada ọpọlọpọ eniyan,” eyi si ṣí ọna naa silẹ lati tun iran-eniyan rapada.—Matteu 20:28.
Bíbò ati Títúsílẹ̀
Bibeli fihan pe ọna ìgbà tún iran-eniyan rapada ní igbesẹ meji ninu: (1) rírà pada ati (2) titusilẹ. Nipa ọrọ Griki naa (lyʹtron) ti a tumọ si “irapada,” ọmọwe Bibeli naa Albert Barnes kọwe pe: “Ọrọ naa irapada lóréfèé tumọsi iye kan ti a san fun itunrapada awọn ìgbèkùn. Nigba ogun, tí ọ̀tá kan ba kó awọn ẹlẹwọn, owó ti a ń beere fun ìtúsílẹ̀ wọn ni a ń pè ni irapada; iyẹn ni pe, ó jẹ ohun ti a tipa rẹ̀ dá wọn silẹ lominira. Nitori naa ohunkohun ti o bá tú ẹnikẹni silẹ kuro ninu ipo ijiya kan, tabi ìjoró, tabi ẹ̀ṣẹ̀, ni a ń pe ni irapada.”
Bẹẹni “ohunkohun ti o ba tú ẹnikẹni sílẹ̀” ni a le tọkasi gẹgẹ bii lyʹtron. Nitori naa ọrọ Griki yii tẹnumọ iṣe tabi ọna ìgbà túnisílẹ̀.a
Aposteli Paulu lo ọrọ ti o tanmọ ọn naa an·tiʹly·tron lati tẹnumọ iniyelori iye-owo ti a san gẹgẹ bi irapada naa. Ni 1 Timoteu 2:6 (New World Translation), oun kọwe pe “[Jesu] fi araarẹ funni” gẹgẹ bi “irapada kan ti o ṣe rẹ́gí fun gbogbo eniyan.” Nigba ti o ń sọrọ lori eyi, iwe Greek and English Lexicon to the New Testament ti Parkhurst wi pe: “O ṣapẹẹrẹ iye-owo kan nipasẹ eyi ti a fi tun awọn igbekun rapada kuro lọwọ awọn ọ̀tá; iru paṣipaarọ yẹn ninu eyi ti a gbà tun iwalaaye ẹnikan ra pada nipasẹ iwalaaye ẹlomiran.” Nihin-in, itẹnumọ wà lori irú ìṣerẹ́gí tabi agbara ipese iyọrisi ti a reti ti iye-owo irapada naa ti a san lati mu ki awọn òṣùwọ̀n idajọ ododo wà deedee. Bawo ni a ṣe lè lo ẹbọ irapada Jesu bi “irapada kan ti o ṣe rẹ́gí”?
Irapada Kan Ti O Ṣe Rẹ́gí
Adamu ta gbogbo iran-eniyan, titi kan awa, sinu ẹ̀ṣẹ̀ ati ikú. Iye-owo, tabi ìjìyà, ti oun san ni iwalaaye eniyan pípé rẹ̀, pẹlu agbara lati lè walaaye titilae. Lati kájú eyi, iwalaaye eniyan pipe miiran ni a nilo—irapada kan ti o ṣe rẹ́gí—ni a nilati san. Bi o ti wu ki o ri, kò si ẹnikẹni ti eniyan alaipe bí ti o lè pese iwalaaye eniyan pipe ti a nilo. (Jobu 14:4; Orin Dafidi 51:5) Bi o ti wu ki o ri, ninu ọgbọ́n rẹ̀, Ọlọrun ṣí ọ̀nà kan silẹ kuro ninu awọn ìhámọ́ wọnyi. Ó ta àtaré iwalaaye pipe Ọmọ bibi rẹ̀ kanṣoṣo lati ọrun sinu wundia kan, ni jijẹ ki a bi i gẹgẹ bi eniyan pipe kan. (Luku 1:30-38; Johannu 3:16-18) Ẹkọ yii nipa ìbí Jesu lati ọdọ wundia kan kì í ṣe itan kan ti a dọgbọn hùmọ̀ lati gbé oludasilẹ isin kan ga. Kaka bẹẹ, ó ṣalaye igbesẹ ti o bá ọgbọ́n mu kan ninu ipese irapada ti Ọlọrun.
Ki o baa lè ṣaṣepari itunrapada naa, Jesu nilati pa akọsilẹ mimọ tonitoni kan mọ́ ni gbogbo igba ti o wà lori ilẹ-ayé. Oun ṣe eyi. Lẹhin naa ni o kú ikú irubọ kan. Ni ọna yii, Jesu san iye-owo iwalaaye eniyan pipe rẹ̀ gẹgẹ bi irapada naa lati gba iran-eniyan silẹ. (1 Peteru 1:19) Nitori naa a lè sọ lọna ti o ṣe deede pe ‘ẹnikan kú fun gbogbo eniyan.’ (2 Korinti 5:14) Bẹẹni, “bi gbogbo eniyan ti kú ninu Adamu, bẹẹ ni a ó si sọ gbogbo eniyan di alaaye ninu Kristi.”—1 Korinti 15:22.
Ọkunrin Kan ni Paṣipaarọ fun Ọpọlọpọ
Ninu ọran ti fifipa já ọkọ̀ gbà ti a mẹnukan ni iṣaaju, awọn àmúdá naa kò ni ọ̀nà kankan lati gbà dá ara wọn silẹ, koda bi wọn ba tilẹ jẹ́ ọlọ́rọ̀. Iranlọwọ ode ni a nilo, ọkunrin naa ti o si pese araarẹ gẹgẹ bii paṣipaarọ nilati kúnjú awọn ipo pataki kan. Ohun kan naa ni o jẹ otitọ ni ọna kan ti o tubọ jinlẹ ni isopọ pẹlu itunrapada ti a nilo lati ra araye pada. Olorin kan kọwe pe: “Awọn wọnni . . . ti wọn . . . ń fọ́nnu nipa ọpọ yanturu ọrọ̀ wọn, ọkankan ninu wọn lọnakọna kò lè tun arakunrin kan rapada paapaa, tabi fun Ọlọrun ni irapada fun un; (iye-owo itunrapada ọkàn wọn sì ṣeyebiye gan-an debi pe o ti dáwọ́ duro fun akoko titilọ gbére).” (Orin Dafidi 49:6-8, NW) Niti gidi, aini kan wà fun iranlọwọ òde fun iran-eniyan. Iwalaaye ọkunrin kan yoo tó lati ṣe itunrapada gbogbo araye bi o ba ṣe pe o kúnjú awọn ipo pataki ti a beere fun lati mu oṣunwọn idajọ ododo Ọlọrun wà deedee. Jesu Kristi ni o ti jẹ́ ẹda eniyan pipe kanṣoṣo naa ti o doju ìlà awọn ohun ti a beere fun naa.
Jehofa Ọlọrun ti pese fun idasilẹ iran-eniyan nipa fifi Jesu Kristi san irapada. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe eyi ti o jù bẹẹ lọ. Oun ti dá ẹbi ikú fun Satani Eṣu, ẹni naa ti o sin iran-eniyan sinu ẹ̀ṣẹ̀. (Ifihan 12:7-9) Laipẹ Jehofa yoo há ẹlẹbi ẹṣẹ naa mọ́ yoo si mú idajọ ṣẹ nipa ‘gbígbé e sọ sinu adagun iná ati imí-ọjọ,’ eyi ti ń ṣapẹẹrẹ iparun ayeraye. (Ifihan 20:1-3, 7-10, 14) Pẹlu imukuro ẹda-ẹmi buburu yii ati nipasẹ ifisilo irapada naa, iran-eniyan yoo gbadun idasilẹ kii ṣe kiki kuro ninu ìgbánimú ẹ̀ṣẹ̀ ati ikú nikan ni ṣugbọn kuro ninu ipa idari Satani pẹlu. Bi wọn ti dominira nipa bayii ati nipa anfaani ẹbọ irapada Kristi ti a ti fisilo ni kikun, iran-eniyan onigbọran yoo tẹsiwaju de ijẹpipe ti ẹda eniyan.
Iṣeto Irapada naa ati Iwọ
Lẹhin kíkọ́ nipa ẹbọ irapada Jesu Kristi, ọpọlọpọ ni Gabasi ti mọriri ohun ti Ọlọrun ti ṣe fun wọn. Kazuo jẹ apẹẹrẹ kan. Igbesi-aye rẹ̀ sinmi lori fífà thinner ọ̀dà (eroja ti a fi ń po ọ̀dà ṣàn) si agbárí ki ó sì gbà á pé. Nigba ti o ba ń wakọ labẹ agbara idari rẹ̀, leralera ni o maa ń ba awọn ọkọ rẹ̀ jẹ́. Mẹta ninu awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fi ọwọ araawọn pa araawọn lẹhin ti wọn ti ba ilera wọn jẹ́. Kazuo pẹlu gbiyanju lati fọwọ araarẹ̀ pa araarẹ̀. Lẹhin naa, o bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli. Bi a ti sun un nipa otitọ ti o kẹkọọ rẹ̀, o pinnu lati fọ igbesi-aye rẹ̀ mọ́. O jijakadi pẹlu aṣa lilo araarẹ ni ilokulo pẹlu thinner ọ̀dà, ọpọ awọn iyọrisi buburu ni o si wà. O ni iriri iṣoro nitori ifẹkufẹẹ ara rẹ̀ ati ìyánhànhàn lati ṣe ohun ti o tọ́. Ayọ rẹ̀ ti pọ tó lati le gbadura si Ọlọrun fun idariji nipasẹ ìtóye ẹbọ irapada Jesu Kristi! Nipasẹ adura ati pẹlu iranlọwọ lati ọdọ awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti wọn jẹ́ Kristian, Kazuo bori iwa buburu rẹ̀ oun nisinsinyi si ń sin Jehofa gẹgẹ bi ojiṣẹ alayọ kan pẹlu ẹri-ọkan mimọ tonitoni.
Iwọ ha ranti Chisako, ti a mẹnukan ni ibẹrẹ ọrọ-ẹkọ ti o ṣaaju eyi bi? Nipasẹ ikẹkọọ Bibeli, oun pẹlu wá loye iṣeto onifẹẹ ti irapada naa. Imọlara rẹ̀ ni a rusoke lọna jijinlẹ nigba ti o kẹkọọ pe Ọlọrun fi Ọmọkunrin rẹ̀ funni lati tú iran-eniyan silẹ kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀. Chisako ya igbesi-aye rẹ̀ si mímọ́ fun Jehofa. Ani nisinsinyi paapaa, ni ẹni ọdun 77, oun ń lo nǹkan ti o tó 90 wakati ni oṣooṣu ni sisọ fun awọn ẹlomiran nipa ifẹ titobi Jehofa ati inurere ailẹtọọsi ti oun ń fihan.
Irapada naa gbọdọ ṣe pataki fun ọ pẹlu. Nipasẹ rẹ̀, Ọlọrun yoo ṣí ọ̀nà silẹ si ominira tootọ fun araye—ominira kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀ ati ikú. Ọjọ ọla titayọlọla ti iwalaaye ayeraye ninu paradise ori ilẹ-aye kan wà ni iwaju fun awọn wọnni ti wọn bá tẹwọgba ẹbọ irapada Jesu Kristi. Jọwọ wá Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kàn ki o si ṣayẹwo funraarẹ bi o ṣe le gbadun ominira kuro lọwọ ẹ̀ṣẹ̀ ati ikú nipasẹ iṣeto onifẹẹ ti irapada naa.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ninu Iwe Mimọ lede Heberu, pa·dhahʹ ati awọn ọrọ ti o tanmọ ọn ni a tumọ si “tunrapada” tabi “iye-owo itunrapada,” eyi ti o ń ṣakopọ ìtúsílẹ̀ ti o ni ninu.—Deuteronomi 9:26.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Nipasẹ ifọwọsowọpọ ọlọlawọ ti Mainichi Shimbun