Pípẹja Eniyan Ninu Omi Yika Ayé
“Nisinsinyi, bi mo bá ń kede ihinrere, kì í ṣe idi fun mi lati ṣogo, nitori aigbọdọmaṣe wà lori mi. Niti gidi, ègbé ni fun mi bi emi kò bá kede ihinrere!”—1 KORINTI 9:16, NW.
1, 2. (a) Awọn wo nitootọ ni wọn ti koju ipenija ti a nilọkan ni 1 Korinti 9:16, eesitiṣe ti o fi dahun bẹẹ? (b) Ẹru-iṣẹ wo ni Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti tẹwọgba?
AWỌN wo ní ọrundun lọna 20 yii ni wọn ti koju ipenija tí awọn ọrọ Paulu ti o wà loke yii gbekalẹ nitootọ? Awọn wo ni wọn ti lọ sinu ayé ni araadọta-ọkẹ lati pẹja awọn ọkunrin ati obinrin ti “aini wọn nipa tẹmi ń jẹ lọkan”? (Matteu 5:3, NW) Awọn wo ni wọn ti dagbale ewu ifisẹwọn ati iku, ti wọn sì ti jiya iru bẹẹ ni ọpọlọpọ ilẹ nitori mimu aṣẹ Kristi ni Matteu 24:14 ṣẹ?
2 Akọsilẹ dahun pe: Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni. Ni ọdun ti o kọja nikan iye Awọn Ẹlẹ́rìí ti o ju million mẹrin lọ ni wọn lọ lati ile de ile ‘ni pipolongo ihinrere’ ni 211 awọn orilẹ-ede ati ipinlẹ ati ni iye ti o ju 200 èdè lọ. Iwọnyi ki i wulẹ ṣe àṣàyàn awujọ ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ti a dalẹkọọ. Bẹẹkọ, gbogbo Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nimọlara ẹru-iṣẹ kan lati waasu ki wọn sì kọni lati ile de ile ati ni gbogbo akoko ti o bá yẹ. Eeṣe ti wọn fi nimọlara aini yẹn lati ṣajọpin igbagbọ wọn pẹlu awọn ẹlomiran? Nitori pe wọn mọ daju pe ìmọ̀ ń mú ẹru-iṣẹ wa.—Esekieli 33:8, 9; Romu 10:14, 15; 1 Korinti 9:16, 17.
Pípẹja Eniyan, Ipenija Yika Ayé
3. Bawo ni iṣẹ ẹja pípa naa ti gbọdọ gbooro tó?
3 Iṣẹ ẹja pípa titobi yii ni a kò fimọ, gẹgẹ bi a ti lè sọ pe o jẹ, si awọn odò kan tabi adágún tabi agbami òkun kan paapaa. Bẹẹkọ, gẹgẹ bi Jesu ti paṣẹ, a nilati ṣe é “ni gbogbo orilẹ-ede.” (Marku 13:10) Ṣaaju ki o tó goke lọ sọdọ Baba rẹ̀, Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Nitori naa ẹ lọ ki ẹ sì sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin, ki ẹ maa baptisi wọn ni orukọ Baba ati ti Ọmọkunrin ati ti ẹmi mimọ, ki ẹ maa kọ́ wọn lẹkọọ lati fiṣọra kiyesi ohun gbogbo ti mo ti paṣẹ fun yin. Ẹ sì wò ó! emi wà pẹlu yin ni gbogbo ọjọ titi de ipari eto igbekalẹ awọn nǹkan.”—Matteu 28:19, 20, NW.
4. (a) Ki ni o ti gbọdọ ya awọn Ju ọmọlẹhin Jesu ijimiji lẹnu? (b) Bawo ni Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe wo ìwọ̀n igbooro iṣẹ iwaasu wọn?
4 Fun awọn Ju ọmọlẹhin Jesu, iyẹn ti lè jẹ́ iṣẹ aṣẹ amunitagiri kan. Ó ń sọ fun awọn Ju ọmọ-ẹhin pe wọn yoo nilati jade lọ nisinsinyi sọdọ awọn Keferi “aláìmọ́” ti gbogbo awọn orilẹ-ede ki wọn sì kọ́ wọn lẹkọọ. Ó gba ìtúnṣebọ̀sípò diẹ fun wọn lati rí ara gba ipa tí iṣẹ ayanfunni naa ni sí ki wọn sì gbegbeesẹ lori rẹ̀. (Iṣe 10:9-35) Ṣugbọn àbùjá kò sí lọ́rùn ọpẹ; Jesu ti sọ fun wọn ninu owe àkàwé kan pe “oko ni ayé.” Nitori naa, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii wo gbogbo ayé gẹgẹ bi ibi ìran fun ẹ̀tọ́ ti wọn ní lati pẹja. Kò lè sí “ààlà omi ilu onibusọ 12” tabi “omi ipinlẹ” ti ń pààlà si iṣẹ aṣẹ wọn lati ọdọ Ọlọrun. Nigbamiran làákàyè ni a nilo nibi ti kò ti sí ominira isin. Sibẹ, wọn ń pẹja pẹlu èrò kanjukanju. Eeṣe ti iyẹn fi jẹ́ bẹẹ? Nitori pe awọn iṣẹlẹ ayé ati imuṣẹ asọtẹlẹ Bibeli fihan pe a wà ni apá ikẹhin iṣẹ ẹja pípa yika ayé naa.—Matteu 13:38; Luku 21:28-33.
Itẹsiwaju Ninu Iṣẹ Ẹja Pípa Yika Ayé
5. Iru awọn eniyan wo ni wọn ń dahunpada si iṣẹ ẹja pípa yika ayé?
5 Ọpọ julọ ninu awọn ẹni ami ororo ajogún Ijọba ni a “kó jade bi ẹja” ninu awọn orilẹ-ede ṣaaju 1935, nitori naa iye kíkún wọn ni ó ti pé ni pataki. Nitori naa, paapaa lati 1935, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń wá awọn eniyan onirẹlẹ wọnni ti a lè ṣapejuwe gẹgẹ bi “awọn ọlọkan tutu” ti wọn “yoo jogun ayé.” (Orin Dafidi 37:11, 29) Awọn wọnyi ni awọn eniyan ti wọn “ń kẹ́dùn, ti wọn sì ń kígbe nitori ohun irira ti wọn ń ṣe.” Wọn ń gbé ìgbésẹ̀ ni itilẹhin fun iṣakoso Ijọba Ọlọrun ṣaaju ki “ipọnju ńlá” to kọlu eto igbekalẹ awọn nǹkan ti Satani ti ó ti dómùkẹ̀ ti o sì ti bajẹ yii ati ki a tó yan awọn olujọsin rẹ̀ si “ìléru oníná” ti iparun ikẹhin.—Esekieli 9:4; Matteu 13:47-50; 24:21.
6, 7. (a) Awọn igbesẹ wo ni a gbé ni 1943 niti iṣẹ iwaasu? (b) Ki ni ó ti jẹ́ awọn iyọrisi rẹ̀?
6 Iṣẹ ẹja pípa yika ayé naa ha ti yọrisirere lati ìgbà yii wá bi? Ẹ jẹ ki awọn otitọ naa sọrọ funraawọn. Pada sẹhin ni 1943, Ogun Agbaye II ṣì ń lọ lọwọ, sibẹ awọn arakunrin oluṣotitọ ẹni ami ororo ni orile-iṣẹ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Brooklyn, New York, rí i ṣaaju pe iṣẹ ẹja pípa jantirẹrẹ yika ayé ni a o nilati ṣe. Nitori naa, awọn igbesẹ wo ni a gbé?a—Ifihan 12:16, 17.
7 Ni 1943 Watchtower Society dá ile-ẹkọ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun silẹ ti a ń pè ni Gilead (Heberu, “Okiti Ẹ̀rí”; Genesisi 31:47, 48) ti ó bẹrẹ sii dá ọgọrun-un kan awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun lẹkọọ ni gbogbo oṣu mẹfa mẹfa ki a baa lè rán wọn jade gẹgẹ bi apẹja iṣapẹẹrẹ kari ayé. Nigba naa lọ́hùn-ún, kìkì 126,329 Awọn Ẹlẹ́rìí ti wọn ń fi taapọntaapọn pẹja eniyan ni 54 ilẹ ni wọn wà. Laaarin ọdun mẹwaa iye wọnni ti fẹrẹẹ fò sókè dé 519,982 Awọn Ẹlẹ́rìí ni 143 ilẹ! Dajudaju, Ile-ẹkọ Gilead ń mú awọn akikanju ọkunrin ati obinrin apẹja jade, ti wọn muratan lati jade lọ sinu awujọ ẹgbẹ́ oun ọ̀gbà ti o ṣàjèjì ki wọn sì mú araawọn bá omi ipẹja titun mu. Gẹgẹ bi iyọrisi, ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan olotiitọ-ọkan dahunpada. Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun wọnni, ati Awọn Ẹlẹ́rìí adugbo ti wọn ń bá ṣiṣẹ, fi ipilẹ lélẹ̀ fun ibisi agbayanu ti ń ṣẹlẹ nisinsinyi.
8, 9. (a) Awọn apẹẹrẹ wo ni a lè tọka si nipa iṣẹ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun titayọ? (b) Bawo ni awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ṣe rí idagbasoke titayọ ninu awọn pápá wọn? (Tun wo 1992 Yearbook of Jehovah’s Witnesses.)
8 Ọpọlọpọ awọn oluṣotitọ apẹ́lẹ́nu-iṣẹ́ lati inu awọn kilaasi akọkọ ti Gilead wọnni ṣì ń ṣiṣẹsin ni ibi iṣẹ ayanfunni wọn ni ilẹ okeere, ani bi o tilẹ jẹ pe wọn jẹ́ ẹni ọjọ ori ti o ju 70 tabi 80 ọdun paapaa lọ nisinsinyi. Apẹẹrẹ kan ti o ṣapẹẹrẹ pupọ ninu iwọnyi ni ti Eric Britten ẹni ọdun 82 ati aya rẹ̀, Christina, ti wọn kẹkọọ jade ni kilaasi 15 Gilead ni 1950 ti wọn sì ń ṣiṣẹsin ni Brazil sibẹ. Nigba ti wọn lọ ṣiṣẹsin ni Brazil, Awọn Ẹlẹ́rìí ti wọn kere ju 3,000 ni wọn wà ni orilẹ-ede yẹn. Nisinsinyi iye ti o ju 300,000 ni wọn wà! Dajudaju, ‘ẹni kekere ti di alagbara orilẹ-ede’ ni Brazil nitori pe iṣẹ ẹja pípa naa ti jẹ́ amesojade.—Isaiah 60:22.
9 Ki sì ni a lè sọ nipa awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni Africa? Ọpọ julọ ninu wọn ti mú araawọn bá oriṣiriṣi awujọ ẹgbẹ́ oun ọ̀gbà mu wọn sì ti wá nifẹẹ awọn eniyan Africa. Apẹẹrẹ kan ni awọn arakunrin John ati Eric Cooke ati awọn aya wọn, Kathleen ati Myrtle, ti wọn ń ṣiṣẹsin ni South Africa ni lọwọlọwọ yii jẹ́. John ati Eric kẹkọọ jade ni kilaasi kẹjọ ni 1947. Awọn orilẹ-ede ti ọ̀kan tabi ekeji ninu awọn tẹgbọntaburo mejeeji wọnyi ti ṣiṣẹsin ni Angola, Zimbabwe, Mozambique, ati South Africa. Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun kan kú si Africa nitori àrùn, ati awọn miiran nitori ogun ati inunibini, iru bii Alan Battey ati Arthur Lawson, ti wọn kú lakooko ogun abẹle ẹnu aipẹ yii ni Liberia. Sibẹ, omi Africa ti jásí eyi ti ń mesojade gan-an. Iye ti o ju 400,000 Awọn Ẹlẹ́rìí lọ ń bẹ nisinsinyi jakejado apakan ilẹ̀-ayé gbigbooro yẹn.
Gbogbo Wọn Kó Ipa
10. Eeṣe ati ni ọ̀nà wo ni awọn aṣaaju-ọna ń gbà ṣe iṣẹ ti o yẹ fun oríyìn?
10 Bi o ti wu ki o ri, a nilati mọ daju pe nigba ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ àjèjì ti jẹ́ ẹgbẹẹgbẹrun diẹ ni iye, awọn akede adugbo ati awọn aṣaaju-ọnab ti di araadọta-ọkẹ. Wọn ń ṣe eyi ti o pọ̀ julọ ninu iṣẹ iwaasu naa kari ayé. Ni 1991 ipindọgba ti ó ju 550,000 awọn aṣaaju-ọna ati awọn ojiṣẹ arinrin-ajo ni wọn wà. Ẹ wo iru iye wiwọnilọkan ti iyẹn jẹ́ nigba ti a bá ronu nipa gbogbo Awọn Ẹlẹ́rìí oluṣotitọ wọnyi ti wọn ń ṣe isapa akanṣe lati lọwọ ninu iṣẹ ẹja pípa ńláǹlà naa, ti wọn ń ní ipindọgba ti o bẹrẹ lati ori nǹkan bii 60 si 140 wakati fun wiwaasu ni oṣu kọọkan. Ọpọlọpọ ń ṣe eyi pẹlu irubọ ati ìnáwó-nára ńláǹlà ti ara-ẹni. Ṣugbọn eeṣe? Nitori pe wọn nifẹẹ Jehofa Ọlọrun wọn pẹlu gbogbo ọkan-aya, ero-inu, ọkàn, ati okun wọn, wọn sì nifẹẹ aladuugbo wọn gẹgẹ bi araawọn.—Matteu 22:37-39.
11. Ẹ̀rí didaju wo ni ó wà nibẹ nipa ẹmi Jehofa lẹnu iṣẹ laaarin awọn eniyan rẹ̀?
11 Ki ni a lè sọ nipa iye Awọn Ẹlẹ́rìí miiran ti wọn ju million mẹta ati aabọ lọ ti wọn kò sí ninu iṣẹ-isin alakooko kikun ṣugbọn sibẹ ti wọn ń fi gbogbo ìtara sinu iṣẹ-isin Jehofa, ni ibamu pẹlu ipo ti o yi wọn ka? Awọn kan jẹ́ aya, ani ìyá ti ń bojuto awọn ọmọ keekeeke paapaa, sibẹ ti wọn ń lo diẹ ninu akoko ṣiṣeyebiye wọn ninu iṣẹ ẹja pípa yika ayé naa. Ọpọlọpọ jẹ ọkọ tabi baba ti wọn ni iṣẹ ounjẹ òòjọ́; sibẹ, wọn fi akoko silẹ ni awọn opin ọsẹ ati ni awọn irọlẹ lati kọ́ awọn àjèjì ni otitọ. Lẹhin naa ogunlọgọ awọn àpọ́n ọkunrin ati àpọ́n obinrin ati awọn ọ̀dọ́ ti wọn ń ṣajọpin ninu wiwaasu ti wọn sì ń mú otitọ fanimọra nipa ìwà wọn wà. Awujọ onisin miiran wo ni ó ní iye ti o ju million mẹrin awọn oluyọnda ara-ẹni ti a kìí sanwó fun ti wọn ń waasu ihinrere iṣakoso Ijọba Ọlọrun loṣooṣu? Dajudaju eyi fẹ̀rí ẹmi Jehofa lẹnu iṣẹ han!—Orin Dafidi 68:11; Iṣe 2:16-18; fiwe Sekariah 4:6.
Awọn Kókó-Abájọ Tí Ó Dákún Idagbasoke
12. Eeṣe ati ni awọn iye wo ni awọn eniyan ń dahunpada si otitọ?
12 Iṣẹ iwaasu gbigbooro yii ń mú iyọrisi ti ó pẹtẹrí wá lọdọọdun. Ni 1991 iye ti o ju 300,000 Awọn Ẹlẹ́rìí titun ni a baptisi nipasẹ iribọmi inu omi. Iyẹn jẹ́ ìbáṣe deedee iye awọn ijọ ti o ju 3,000 ti ọkọọkan ni 100 Awọn Ẹlẹ́rìí! Bawo ni a ṣe ṣaṣeyọri gbogbo eyi? Ẹ jẹ ki a ranti ohun ti Jesu sọ pe: “Kò sí ẹnikẹni ti o lè wá sọdọ mi, bikoṣe pe Baba ti o rán mi fà á: . . . A ṣá ti kọ ọ́ ninu awọn wolii pe, A o sì kọ́ gbogbo wọn lati ọdọ Ọlọrun [“Jehofa,” NW] wá. Nitori naa ẹnikẹni ti o bá ti gbọ, ti a sì ti ọdọ Baba kọ́, oun ni o ń tọ̀ mi wá.” Nitori naa, kì í wulẹ ṣe nipasẹ isapa eniyan ni ẹnikan fi ń dahunpada si ẹja pípa yika ayé. Jehofa mọ ipo ọkan-aya ó sì ń fa awọn ti o yẹ wọnni si ọdọ araarẹ̀.—Johannu 6:44, 45; Matteu 10:11-13; Iṣe 13:48.
13, 14. Ẹmi ironu rere wo ni ọpọ Awọn Ẹlẹ́rìí ti fihan?
13 Bi o ti wu ki o ri, awọn apẹja eniyan jẹ́ aṣoju, ti Jehofa ń lò lati fa awọn eniyan mọra. Nitori naa, iṣarasihuwa wọn siha awọn eniyan ati ipinlẹ nibi ti wọn ti ń pẹja ṣe pataki. Ó ti funni niṣiiri tó lati rí ọpọ jaburata awọn eniyan ti wọn ti fi awọn ọrọ Paulu si awọn ará Galatia sọkan pe: “Ẹ ma sì jẹ́ ki agara dá wa ni rere iṣe: nitori awa yoo ká nigba ti akoko bá dé, bi a kò bá ṣe àárẹ̀.”—Galatia 6:9.
14 Ọpọlọpọ Awọn Ẹlẹ́rìí oluṣotitọ ti ń waasu fun ọpọ ẹ̀wádún, nigba ti wọn ń kiyesi awọn idagbasoke ayé lọna timọtimọ. Wọn ti rí idide ati iṣubu eto ijọba Nazi ati ti Fascist, ati awọn eto igbekalẹ apàṣẹwàá miiran. Awọn kan ti ṣẹlẹrii ọpọlọpọ awọn ogun ti o ti ṣẹlẹ lati 1914. Wọn ti rí i ti awọn aṣaaju ayé fi ireti wọn kọ́ sára Imulẹ Awọn Orilẹ-ede ati lẹhin naa Iparapọ Awọn Orilẹ-ede. Wọn ti rí i ti a fi ofin de iṣẹ Jehofa ti a sì tún kàá sí lọna ofin ni ọpọlọpọ ilẹ. La gbogbo eyi já, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò tíì juwọsilẹ ninu ṣiṣe ohun ti o dara, eyi ti o ni ṣiṣiṣẹsin gẹgẹ bi apẹja eniyan ninu. Iru akọsilẹ titayọ ti iwatitọ wo ni eyi!—Matteu 24:13.
15. (a) Iranlọwọ wo ni a ti ní ninu mimu araawa bá awọn aini ipinlẹ wa kari ayé mu? (b) Bawo ni awọn itẹjade ṣe ṣeralọwọ ninu iṣẹ ayanfunni rẹ?
15 Awọn kókó abajọ miiran wà ti o ti dákún idagbasoke kari ayé yii. Ọ̀kan ni iṣarasihuwa ìṣeétẹ̀síhìn-ín tẹ̀sọ́hùn-ún ti awọn ọkunrin apẹja naa siha awọn aini ipinlẹ wọn. Pẹlu ìṣílọ kuro awọn awujọ ẹgbẹ́ oun ọ̀gbà, isin, ati èdè ọtọọtọ, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti mú òye wọn nipa awọn oju-iwoye oriṣiriṣi jantirẹrẹ wọnyi gbooro sii. Ijọ kari ayé ni a sì ti ràn lọwọ lọna pupọ jaburata nipasẹ pipese awọn Bibeli ati iwe ikẹkọọ Bibeli ni èdè ti ó ju 200 lọ. Bibeli New World Translation of the Holy Scriptures, lodiidi tabi lapakan, ni ó wà ni èdè 13 nisinsinyi, ti o ní èdè Czech ati Slovak ninu. Iwe pẹlẹbẹ naa Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! wà larọọwọto ni èdè 198 nisinsinyi, bẹrẹ lati Albanian dé ori Yoruba, pẹlu iye ẹ̀dà ti a tẹ̀ ti ó jẹ́ 72 million. Iwe naa Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí ni a ti tumọsi 69 èdè ni bayii. Mankind’s Search for God, ti a ti tẹjade ni 29 èdè, funni ni ijinlẹ òye sinu ipilẹṣẹ ati igbagbọ awọn eto igbekalẹ onisin titobi ninu ayé ó sì ń jásí aranṣe alailẹgbẹ ninu iṣẹ ẹja pípa yika ayé.
16. Bawo ni awọn kan ṣe dahunpada si awọn aini ni ilẹ miiran?
16 Kí tún ni ó ti mú iṣẹ ẹja pípa yika ayé naa tẹsiwaju? Ẹgbẹẹgbẹrun ni wọn ti muratan lati dahunpada si ‘ìpè ara Makedonia’ naa. Gan-an gẹgẹ bi Paulu ti muratan lati ṣí lọ si Asia Kekere lati Makedonia ni Europe, nipa ìpè Ọlọrun, ọpọlọpọ Awọn Ẹlẹ́rìí ti ṣí lọ si awọn ilẹ ati ipinlẹ nibi ti aini ti tobi ju fun awọn oniwaasu Ijọba, ati bakan naa fun awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ wà. Wọn ti dabi awọn ọkunrin apẹja gidi ti wọn rí i pe a ti pa awọn ẹja inu omi adugbo wọn daradara ti wọn sì ṣí lọ sinu awọn omi nibi ti awọn ọkọ̀ oju-omi kò ti pọ ti ẹja sì pọ lọpọlọpọ.—Iṣe 16:9-12; Luku 5:4-10.
17. Awọn apẹẹrẹ wo ni a ní nipa awọn wọnni ti wọn ti dahunpada si ‘ìpè Makedonia’?
17 Awọn kilaasi ẹnu aipẹ yii ti ile-ẹkọ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun Gilead ti ni awọn akẹkọọ lati oniruuru awọn orilẹ-ede Europe ninu ti wọn ti kọ́ èdè Gẹẹsi ti wọn sì ti yọnda araawọn fun iṣẹ-isin ni awọn ilẹ ati awujọ ẹgbẹ́ oun ọ̀gbà miiran. Bakan naa, nipasẹ Ile-Ẹkọ Ti Idanilẹkọọ Iṣẹ-Ojiṣẹ, ọpọlọpọ awọn arakunrin àpọ́n ni a fun ni idanilẹkọọ kára-kára oloṣu meji ti a sì rán wọn si awọn orilẹ-ede miiran lati fun awọn ijọ ati ayika lokun. Awọn odò ipẹja alailẹgbẹ miiran wà ni awọn ipinlẹ ti a ṣí silẹ nisinsinyi ni Ìhà Ila-oorun Europe ati awọn ilẹ Soviet alailọba tẹlẹri naa.—Fiwe Romu 15:20, 21.
18. (a) Eeṣe ti awọn aṣaaju-ọna fi sábà maa ń jẹ ọ̀jáfáfá ojiṣẹ? (b) Bawo ni wọn ṣe lè ran awọn miiran lọwọ ninu ijọ?
18 Afikun aranṣe kan ninu iṣẹ ẹja pípa kari ayé naa ni Ile-Ẹkọ Iṣẹ-Isin Aṣaaju-Ọna tí awọn aṣaaju-ọna deedee ń lọ. Jalẹ ọ̀sẹ̀ meji ti kíkárí itẹjade naa Shining as Illuminators in the World, ti a pese fun awọn aṣaaju-ọna nikan, loju mejeeji, wọn mú òye iṣẹ-ojiṣẹ wọn sunwọn sii gẹgẹ bi wọn ti gbe awọn kókó ẹkọ bii “Lilepa Ọ̀nà Ifẹ,” “Tẹle Jesu Gẹgẹ Bi Awokọṣe,” ati “Mimu Agbara Ikọnilẹkọọ Dagbasoke” yẹwo. Gbogbo ijọ ti gbọdọ kun fun imoore tó lati ni ọ̀wọ́ alajọṣiṣẹ ti awọn apẹja ile-de-ile titootun wọnyi ti wọn lè dá ọpọlọpọ lẹ́kọ̀ọ́ ninu iṣẹ ẹja pípa ńláǹlà yii!—Matteu 5:14-16; Filippi 2:15; 2 Timoteu 2:1, 2.
Ǹjẹ́ A Lè Sunwọn Sii Bi?
19. Bii aposteli Paulu, bawo ni a ṣe lè mu iṣẹ-ojiṣẹ wa sunwọn sii?
19 Bii Paulu, a fẹ́ lati ni iṣarasihuwa onifojusọna fun rere, tí ẹni ti ń wo ọ̀kánkán sàn-án. (Filippi 3:13, 14) Ó mú araarẹ̀ bá gbogbo iru awọn eniyan ati ipo ayika mu. Ó mọ bi a tií rí ipilẹ àjọfohùnṣọ̀kan ati bi a tií banironupọ lori ipilẹ iṣesi ní adugbo ati awujọ ẹgbẹ́ oun ọ̀gbà. A lè bẹrẹ awọn ikẹkọo Bibeli nipa wíwà lojufo ṣamuṣamu si ihuwapada onile si ihin-iṣẹ Ijọba ki a sì wá mú igbekalẹ ọrọ wa bá aini ẹni naa mu lẹhin naa. Pẹlu oniruuru awọn aranṣe ikẹkọọ Bibeli pupọ jaburata ti a ní, a lè fi eyi ti ó ṣe rẹ́gí pẹlu oju iwoye ẹnikọọkan funni. Ìṣeétẹ̀síhìn-ín tẹ̀sọ́hùn-ún ati iwalojufo ṣamuṣamu wa tun jẹ awọn kókó abajọ pataki ninu ẹja pípa amesojade.—Iṣe 17:1-4, 22-28, 34; 1 Korinti 9:19-23.
20. (a) Eeṣe ti iṣẹ ẹja pípa wa fi ṣe pataki tobẹẹ nisinsinyi? (b) Ki ni ẹru-isẹ ẹnikọọkan wa nisinsinyi?
20 Eeṣe ti iṣẹ ẹja pípa alailẹgbẹ yika ayé yii fi ṣe pataki tobẹẹ nisinsinyi? Nitori pe lati inu awọn asọtẹlẹ Bibeli ti o farahan ninu awọn iṣẹlẹ ti o ti ṣẹlẹ ti ó sì ń ṣẹlẹ, ó ṣe kedere pe eto igbekalẹ ayé Satani forile ogogoro opin oníjàábá. Nitori naa, ki ni awa, Ẹlẹ́rìí Jehofa, nilati maa ṣe? Awọn ọrọ-ẹkọ mẹtẹẹta ninu iwe irohin yii ti tẹnumọ ẹru-iṣẹ wa lati jẹ́ alakitiyan ati onitara ninu igbokegbodo ẹja pípa wa ninu apá ìpín tiwa ninu omi yika ayé. A ni idaniloju fifidi mulẹ naa lati inu Bibeli pe Jehofa ki yoo gbagbe igbokegbodo ẹja pípa alaapọn wa. Paulu sọ pe: “Ọlọrun kì í ṣe alaiṣododo ti yoo fi gbagbe iṣẹ yin ati ifẹ ti ẹyin fihan si orukọ rẹ̀, nipa iṣẹ iranṣẹ ti ẹ ti ṣe fun awọn eniyan mimọ, ti ẹ sì ń se. Awa sì fẹ́ ki olukuluku yin ki o maa fi iru aisinmi kan naa han, fun ẹ̀kún ireti titi de opin.”—Heberu 6:10-12.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tun wo iwe Revelation—Its Grand Climax At Hand!, oju-iwe 185 ati 186, ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
b “Akede aṣaaju-ọna . . . Oṣiṣẹ alakooko-kikun ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.”—Webster’s Third New International Dictionary.
Iwọ Ha Sọyeranti Bi?
◻ Eeṣe ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi wo gbogbo ayé gẹgẹ bi ibi ìran fun awọn igbokegbodo ẹja pípa wọn?
◻ Ibukun wo ni ile-ẹkọ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun Gilead ti jẹ́ fun iṣẹ ẹja pípa naa?
◻ Ki ni awọn kókó abajọ diẹ ti o ti pákún aṣeyọri Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?
◻ Bawo ni a ṣe lè sunwọn sii ninu iṣẹ-ojiṣẹ wa lẹnikọọkan?
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 24]
IYỌRISI ẸJA PÍPA JAKEJADO AWỌN ORILẸ-EDE
Ọdun Awọn Ilẹ Awọn Ẹlẹ́rìí
1939 61 71,509
1943 54 126,329
1953 143 519,982
1973 208 1,758,429
1983 205 2,652,323
1991 211 4,278,820
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Iṣẹ ìjẹ́rìí naa ni a ṣì ń ṣe laaarin awọn ọkunrin apẹja ará Galili