ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 7/1 ojú ìwé 8-13
  • Jehofa, Aláìṣègbè “Onidaajọ Gbogbo Ayé”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa, Aláìṣègbè “Onidaajọ Gbogbo Ayé”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀nà Tí Jehofa Ń Gbà Ṣe Idajọ
  • Awọn Eniyan Onidaajọ ni Akoko Awọn Babanla
  • Eto Igbekalẹ Idajọ Israeli
  • Awọn Onidaajọ ni Israeli
  • Fifi Idajọ Ododo Sí Ìlò
  • Ẹyin Alagba, Ẹ Fi Ododo Ṣe Idajọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ǹjẹ́ Òfin Tí Ọlọ́run Fún Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Bá Ẹ̀tọ́ Mu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ta Ni Ìyàwó Kéènì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Mọ Àwọn Ọ̀nà Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 7/1 ojú ìwé 8-13

Jehofa, Aláìṣègbè “Onidaajọ Gbogbo Ayé”

“Baba . . . ń ṣedajọ láìṣègbè ni ibamu pẹlu iṣẹ olukuluku.”—1 PETERU 1:17, NW.

1, 2. (a) Eeṣe ti a fi gbọdọ kún fun ibẹru ki a sì tún kún fun itunu nipa ironu naa pe Jehofa ni Onidaajọ titobi naa? (b) Ninu ọ̀ràn ofin Jehofa lodisi awọn orilẹ-ede, ipa wo ni awọn iranṣẹ rẹ̀ ori ilẹ̀-ayé kó?

JEHOFA ni “Onidaajọ” ńlá ti “gbogbo ayé.” (Genesisi 18:25) Gẹgẹ bi Onipo-Ajulọ Ọlọrun agbaye, ó ni ẹ̀tọ́ patapata lati ṣe idajọ awọn ẹ̀dá rẹ̀. Eyi lakooko kan-naa jẹ́ ironu amúnikúnfún-ẹ̀rù ọlọ́wọ̀ ati atunininu. Mose lọna ti ó wúni lori sọ ohun ti o jọbi ẹnà yii, ni wiwi pe: “Nitori OLUWA [“Jehofa,” NW] Ọlọrun yin, Ọlọrun awọn ọlọrun ni, ati Oluwa awọn oluwa, Ọlọrun titobi, alagbara, ati ẹlẹ́rù [“amúnikúnfún-ẹ̀rù,” NW], ti kì í ṣe ojuṣaaju, bẹẹ ni kì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Oun níí máa ṣe idajọ alainibaba ati opó, o sì fẹ́ alejo [“àtìpó olùgbé,” NW], lati fun un ni ounjẹ ati aṣọ.”—Deuteronomi 10:17, 18.

2 Iru ìwàdéédéé apàfiyèsí wo ni eyi jẹ́! Ọlọrun titobi, alagbara, amúnikúnfún ẹ̀rù, sibẹ ti ó jẹ́ aláìṣègbè ti ó sì ń fi tifẹtifẹ gbèjà ire awọn aláìníbaba, opó, ati awọn àtìpó olùgbé. Ta ni o lè daniyan fun Onidaajọ kan ti o tubọ jẹ́ onifẹẹ yatọ sí Jehofa? Ni fifi araarẹ̀ han gẹgẹ bi ẹni ti o ní ọ̀ràn ofin kan lodisi awọn orilẹ-ede ti ń bẹ ninu ayé Satani, Jehofa pe awọn iranṣẹ rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé lati jẹ́ Awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀. (Isaiah 34:8; 43:9-12) Oun kò gbarale ẹ̀rí wọn lati fi ipo jíjẹ́ Ọlọrun ati ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀ ti o bá ofin mu hàn. Ṣugbọn ó fi anfaani ara-ọtọ naa lati jẹ́rìí niwaju gbogbo araye pe wọn mọ ipo-ajulọ rẹ̀ dunju jíǹkí awọn ẹlẹ́rìí rẹ̀. Awọn ẹlẹ́rìí rẹ̀ tẹriba fun ipo ọba-alaṣẹ ododo rẹ̀ funraawọn, ati nipasẹ iṣẹ-ojiṣẹ itagbangba wọn, wọn ń sún awọn ẹlomiran lati fi araawọn sabẹ ọla-aṣẹ Onidaajọ Onipo-Ajulọ naa.

Ọ̀nà Tí Jehofa Ń Gbà Ṣe Idajọ

3. Bawo ni a ṣe lè ṣàkópọ̀ ọ̀nà ìgbàdájọ́ Jehofa, bawo sì ni a ṣe ṣàkàwé eyi ninu ọ̀ràn ti Adamu ati Efa?

3 Ni akoko ìtàn ijimiji araye, Jehofa funraarẹ ṣedajọ awọn olùṣeláìfí kan bayii. Awọn apẹẹrẹ ọ̀nà ti ó ń gbà bojuto awọn ọ̀ràn idajọ fi apẹẹrẹ lélẹ̀ fun awọn wọnni lara awọn iranṣẹ rẹ̀ ti wọn yoo ni ẹrù-iṣẹ́ lẹhin naa lati dari awọn ìgbẹ́jọ́ idajọ laaarin awọn eniyan rẹ̀. (Orin Dafidi 77:11, 12) Ọ̀nà ti ó ń gbà ṣe idajọ ni a lè ṣàkópọ̀ rẹ̀ bayii: idurogbọnyingbọnyin nibi ti o bá ti pọndandan, aanu nibi ti o bá ti ṣeeṣe. Ninu ọ̀ràn ti Adamu ati Efa, awọn ẹda eniyan pipe ti wọn ti mọ̀ọ́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀, aanu kò yẹ fun wọn. Fun idi yii, Jehofa paṣẹ ijiya iku fun wọn. Ṣugbọn aanu rẹ̀ ṣiṣẹ siha awọn atọmọdọmọ wọn. Jehofa fi imuṣẹ aṣẹ ikú naa falẹ̀, ní titipa bayii yọọda fun Adamu ati Efa lati ni awọn ọmọ. Ó fi tifẹtifẹ pese ireti idande kuro ninu oko-ẹrú si ẹṣẹ ati ikú fun awọn iran àtẹ̀lé wọn.—Genesisi 3:15; Romu 8:20, 21.

4. Bawo ni Jehofa ṣe bá Kaini lò, eesitiṣe ti ọ̀ràn yii fi jẹ́ ohun ti a lọ́kàn-ìfẹ́ si ni pataki?

4 Ọ̀nà ti Jehofa gbà bá Kaini lò jẹ́ ohun ti a lọ́kàn-ìfẹ́ sí ní pataki nitori pe ó jẹ́ ọ̀ràn akọkọ ti a kọsilẹ ti ó wémọ́ ọ̀kan lara awọn iran àtẹ̀lé alaipe ti Adamu ati Efa, “ti a ti tà sábẹ́ ẹṣẹ.” (Romu 7:14) Jehofa ha ka eyi sí ki o sì bá Kaini lò lọna ti o yatọ si bi Ó ti bá awọn òbí rẹ̀ lò bi? Ọ̀ràn yii ha sì lè pese ẹ̀kọ́ kan fun awọn Kristian alaboojuto lonii bi? Ẹ jẹ ki a wò ó ná. Ni fifoye mọ ìhùwàpadà òdì ti Kaini nigba ti a kò fojurere tẹwọgba ẹbọ rẹ̀, Jehofa fi tifẹtifẹ kilọ fun un nipa ewu ti ó wà ninu rẹ̀. Owe atijọ kan sọ pe: ‘Iṣedena àrùn sàn ju iwosan àrùn lọ.’ Jehofa lọ debi ti o lè lọ jinna dé nipa kikilọ fun Kaini nipa yiyọnda fun itẹsi rẹ̀ ti o kún fun ẹṣẹ lati ṣakoso lori rẹ̀. Ó saakun lati ràn án lọwọ lati “ṣe rere.” (Genesisi 4:5-7) Eyi ni ìgbà akọkọ ti Ọlọrun késí eniyan ẹlẹṣẹ kan lati ronupiwada. Lẹhin ti Kaini fi iṣarasihuwa alaironupiwada hàn ti ó sì dẹṣẹ ńlá rẹ̀, Jehofa paṣẹ ijiya ìlélọ kuro ní ilu fun un, ni mímú eyi fúyẹ́ pẹlu aṣẹ ti ó ka awọn eniyan miiran léèwọ̀ lati maṣe pa á.—Genesisi 4:8-15.

5, 6. (a) Bawo ni Jehofa ṣe tẹsiwaju pẹlu ìran ti o wà ṣaaju Ikun-omi? (b) Ki ni Jehofa ṣe ṣaaju ki o tó mú idajọ ṣẹ lodisi awọn olùgbé Sodomu ati Gomorra?

5 Ṣaaju Ikun-omi, nigba ti ‘Jehofa rí i pe buburu eniyan pọ̀ yanturu ni ilẹ̀-ayé, ó nimọlara ibanujẹ ninu ọkan-aya rẹ̀.’ (Genesisi 6:5, 6) Ó “nimọlara àbámọ̀” niwọn bi ó ti kábàámọ̀ pe ọpọ julọ ninu iran naa ti o wà ṣaaju Ikun-omi ti ṣi ominira ifẹ-inu wọn lò ati pe oun gbọdọ mú idajọ ṣẹ lori wọn. Sibẹ, ó fun wọn ni ikilọ ti ó yẹ, ni lilo Noa fun ọpọlọpọ ọdun gẹgẹ bi “oniwaasu ododo.” Lẹhin igba naa, Jehofa kò ni idi lati ‘fà sẹhin kuro ninu fifi ìyà jẹ ayé awọn eniyan alaiwa-bi-Ọlọrun yẹn.’—2 Peteru 2:5.

6 Jehofa ni a sọ ọ́ di dandan fun bakan naa lati bojuto ọ̀ràn ofin kan lodisi awọn olùgbé Sodomu ati Gomorra oniwa ibajẹ. Ṣugbọn ṣakiyesi bi o ti bẹrẹ. Ó ti gbọ́ ‘igbe ẹ̀sùn’ nipa ìwà adániníjì ti awọn eniyan wọnyi, bi ó bá tilẹ jẹ́ kìkì nipasẹ awọn adura Loti olododo. (Genesisi 18:20; 2 Peteru 2:7, 8) Ṣugbọn ṣaaju ki o tó gbegbeesẹ, ó “sọkalẹ lọ” lati rí awọn otitọ daju nipasẹ awọn angẹli rẹ̀. (Genesisi 18:21, 22; 19:1) Ó tún lo akoko lati tún mú un dá Abrahamu loju pe oun kì yoo hùwà lọna ti kò bá idajọ ododo mu.—Genesisi 18:23-32.

7. Ẹ̀kọ́ wo ni awọn alagba ti wọn ń ṣiṣẹsin ninu igbimọ idajọ lè kọ́ lati inu awọn apẹẹrẹ ọ̀nà ìgbàṣèdájọ́ Jehofa?

7 Ki ni awọn alagba lonii lè kẹkọọ lati inu awọn apẹẹrẹ wọnyi? Ninu ọ̀ràn ti Adamu ati Efa, awọn wọnni ti wọn kò yẹ fun idalẹbii ninu ọ̀ràn naa, bi o tilẹ jẹ́ pe wọn bá awọn ẹlẹbi tan, ni Jehofa fi ifẹ ati igbatẹniro hàn fun. Ó fi aanu hàn si awọn iran àtẹ̀lé Adamu ati Efa. Ninu ọ̀ràn ti Kaini, Jehofa rí ewu tí Kaini wà ninu rẹ̀ ṣaaju ó sì fi inurere bá a ronu papọ, ni gbigbiyanju lati ṣediwọ fun dídá ẹṣẹ. Ani lẹhin lile e lọ kuro nílùú paapaa, Jehofa lo igbatẹniro nipa Kaini. Siwaju sii, Jehofa mu idajọ ṣẹ lori iran ti o wà ṣaaju Ikun-omi naa kìkì lẹhin fifi ọpọ julọ suuru onifarada hàn. Ni oju ìwà buburu alágídí, Jehofa “nimọlara ibanujẹ ninu ọkan-aya rẹ̀.” Ó kábàámọ̀ pe awọn eniyan ṣọ̀tẹ̀ lodisi iṣakoso ododo rẹ̀ ati pe oun ni a sọ ọ́ di dandan fun lati dá wọn lẹ́jọ́ lọna ailojurere. (Genesisi 6:6, NW; fiwe Esekieli 18:31; 2 Peteru 3:9.) Ninu ọ̀ràn ti Sodomu ati Gomorra, Jehofa gbegbeesẹ kìkì lẹhin ti o ti rí awọn otitọ daju. Iru awọn apẹẹrẹ titayọlọla wo ni eyi jẹ́ fun awọn wọnni ti wọn nilati bojuto awọn ọ̀ràn ofin lonii!

Awọn Eniyan Onidaajọ ni Akoko Awọn Babanla

8. Awọn ofin ipilẹ ti Jehofa wo ni a mọ̀ ni akoko awọn babanla?

8 Bi o tilẹ jẹ́ pe ó hàn kedere pe kò sí akojọ ofin ti a kọ silẹ ni akoko naa, awujọ awọn babanla ni wọn mọ awọn ofin ipilẹ ti Jehofa dunju, awọn iranṣẹ rẹ̀ sì wà labẹ aigbọdọmaṣe lati pa wọn mọ́. (Fiwe Genesisi 26:5.) Awokẹkọọ naa ti ó wáyé ni Edeni ti fi aini naa fun igbọran ati itẹriba fun ipo ọba-alaṣẹ Jehofa hàn. Ọ̀ràn Kaini ti fi ainitẹẹwọgba Jehofa fun iṣikapaniyan hàn. Lọ́gán lẹhin Ikun-omi, Ọlọrun fun araye ni awọn ofin nipa ìjẹ́mímọ́ iwalaaye, iṣikapaniyan, ijiya iku, ati jíjẹ ẹ̀jẹ̀. (Genesisi 9:3-6) Jehofa fi tagbara tagbara dẹbi fun panṣaga ni akoko iṣẹlẹ ti ó wémọ́ Abrahamu, Sara, ati Abimeleki, ọba Gerari, lẹbaa Gasa.—Genesisi 20:1-7.

9, 10. Awọn apẹẹrẹ wo ni wọn fihan pe eto igbekalẹ idajọ wà ninu ẹgbẹ awujọ ti awọn babanla?

9 Ni awọn ọjọ wọnni awọn olori idile ń hùwà gẹgẹ bi awọn onidaajọ wọn sì ń bojuto awọn ọ̀ràn iṣoro. Jehofa sọ nipa Abrahamu pe: “Nitori ti mo mọ̀ ọ́n pe, oun yoo fi aṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀ ati fun awọn ará ile rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ki wọn ki o maa pa ọ̀nà OLUWA [“Jehofa,” NW] mọ́ lati ṣe ododo ati ẹ̀tọ́.” (Genesisi 18:19) Abrahamu fi aimọtara-ẹni-nikan ati òye hàn ninu yiyanju aáwọ̀ kan laaarin awọn darandaran tirẹ ati awọn ti Loti. (Genesisi 13:7-11) Ni ṣiṣe bii baba olori idile ati onidaajọ, Judah dẹbi fun Tamari aya ọmọkunrin rẹ̀ lati di ẹni ti a sọ ni okuta pa ki a sì sun ún, ni gbigbagbọ pe ó jẹ́ panṣaga obinrin kan. (Genesisi 38:11, 24; fiwe Joṣua 7:25.) Bi o ti wu ki o ri, nigba ti o mọ gbogbo otitọ naa, ó pè é ni olododo ju oun fúnraarẹ̀ lọ. (Genesisi 38:25, 26) Ó ti ṣe pataki tó lati mọ gbogbo otitọ ṣaaju ṣiṣe ipinnu idajọ!

10 Iwe Jobu pàṣamọ̀ mọ́ eto igbekalẹ idajọ ó sì fi ìfanilọ́kànmọ́ra idajọ aláìṣègbè hàn. (Jobu 13:8, 10; 31:11; 32:21) Jobu fúnraarẹ̀ ronu pada nipa akoko ti oun jẹ́ onidaajọ ti a gbeniyi ẹni ti o jokoo ni ẹnu ibode ilu-nla tí ń ṣabojuto idajọ ododo ti ó sì ń gbeja ipa-ọna opó ati awọn ọmọdekunrin alainibaba. (Jobu 29:7-16) Nipa bayii, ẹ̀rí wà pe laaarin awujọ awọn babanla, “awọn agbaagba ọkunrin” ń ṣiṣẹ gẹgẹ bi awọn onidaajọ laaarin awọn iran àtẹ̀lé Abrahamu ani ṣaaju Ijadelọ ati ilana iṣakoso ti a gbekalẹ lọna ofin tí Ọlọrun fifun orilẹ-ede Israeli. (Eksodu 3:16, 18) Nitootọ, ìṣàdéhùn majẹmu Ofin ni Mose gbekalẹ fun “awọn agbaagba ọkunrin,” tabi awọn alagba, ní Israeli, ti wọn ṣoju fun awọn eniyan naa.—Eksodu 19:3-7.

Eto Igbekalẹ Idajọ Israeli

11, 12. Gẹgẹ bi awọn ọmọwe Bibeli meji ti wi, ki ni o fi iyatọ gedegbe saaarin eto igbekalẹ idajọ Israeli ati ti awọn orilẹ-ede miiran?

11 Ifisilo idajọ ododo ni Israeli yatọ patapata gbáà si ọ̀nà ìgbàṣe nǹkan lọna ofin tí awọn orilẹ-ede tí wọn wà yíká ń tẹle. Kò si iyatọ ti a fi saaarin ofin ilu ati ofin ìwà ọdaran. Mejeeji ni o wépọ̀ mọra pẹlu awọn ofin iwarere ati ti isin. Láìfí kan lodisi aladuugbo ẹni jẹ́ láìfí kan lodisi Jehofa. Ninu iwe rẹ̀ The People and the Faith of the Bible, onṣewe André Chouraqui kọwe pe: “Ofin atọwọdọwọ ti awọn onidaajọ Heberu yatọ si ti awọn aladuugbo rẹ̀, kì í ṣe kìkì ninu ìrélànàkọjá ati ìjìyà-ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nikan ṣugbọn ninu itumọ awọn ofin naa gan-an. . . . [Ofin] Torah kò yatọ gedegbe si igbesi-aye ojoojumọ; ó ń dari irú ati ohun ti igbesi-aye ojoojumọ ní ninu nipa fifunni ni ibukun tabi ègún. . . . Ni Israeli . . . ó fẹrẹẹ lè má ṣeeṣe lati fi iyatọ kedere han ninu awọn igbokegbodo ti awọn onidaajọ ati ti ilu-nla. A fi wọn pamọ sinu igbesi-aye oniṣọkan ti a ṣeto patapata siha imuṣẹ ifẹ-inu Ọlọrun alaaye.”

12 Ipo alailẹgbẹ yii fi iṣabojuto idajọ ododo ni Israeli sori ìwọ̀n kan ti o tubọ ga ju ti awọn orilẹ-ede ti wọn jọ wà ni akoko kan naa lọ. Ọmọwe Bibeli Roland de Vaux kọwe pe: “Ofin Israeli, laika ijọra ninu irú ati ọrọ inu rẹ̀ sí, pilẹ yatọ si awọn awẹ́ gbolohun ‘awọn adehun ifohunṣọkan’ ti Gabasi ati ẹka akọsilẹ gbolohun ‘awọn akojọ ofin’ wọn. Ofin isin ni. . . . Kò sí akojọ ofin Gabasi ti a lè fiwe ofin Israeli, eyi ti a ka gbogbo rẹ̀ si ti Ọlọrun gẹgẹ bi oluṣegbekalẹ rẹ̀. Bi ó bá ní ninu, ti o sì ń pa awọn ilana ofin iwarere ati ti ààtò pọ nigba pupọ, eyi jẹ́ nitori pe o kari gbogbo pápá Majẹmu atọrunwa, ati nitori pe Majẹmu yii ṣakoso ibatan awọn eniyan pẹlu araawọn ati ibatan wọn pẹlu Ọlọrun bakan naa.” Kò yanilẹnu pe Mose beere pe: “Orilẹ-ede ńlá wo ni o sì wà, ti o ni ilana ati idajọ ti i ṣe ododo tó bi gbogbo ofin yii, ti mo fi siwaju yin ni oni?”—Deuteronomi 4:8.

Awọn Onidaajọ ni Israeli

13. Ni awọn ọ̀nà wo ni Mose gbà jẹ́ apẹẹrẹ rere fun awọn alagba lonii?

13 Pẹlu eto igbekalẹ igbimọ aṣofin kan ti a gbéga bẹẹ, iru ọkunrin wo ni a nilo lati ṣiṣẹ gẹgẹ bi onidaajọ? Nipa onidaajọ akọkọ ti a yàn sípò gan-an ni Israeli, Bibeli wi pe: “Ọkunrin naa Mose, o ṣe ọlọkan tutu ju gbogbo eniyan lọ ti ń bẹ lori ilẹ.” (Numeri 12:3) Kò dá araarẹ̀ lójú jù. (Eksodu 4:10) Bi o tilẹ jẹ pe a beere lọwọ rẹ̀ lati ṣe idajọ awọn eniyan, nigba miiran ó di alágbàwí wọn niwaju Jehofa, ni bíbẹ̀bẹ̀ lọdọ rẹ̀ lati dariji wọn ti o tilẹ ń yàn lati fi araarẹ̀ rubọ nititori wọn. (Eksodu 32:11, 30-32) Ó sọ lọna ewì pe: “Ohùn mi yoo maa sẹ̀ bi ìrì, bi òjò winniwinni sara eweko titun, ati bi ọ̀wàrà òjò sara ewébẹ̀.” (Deuteronomi 32:2) Jinna patapata sí ṣiṣedajọ awọn eniyan naa nipa títẹ̀ sí ọgbọn tirẹ fúnraarẹ̀, ó polongo pe: “Nigba ti wọn bá ni ẹjọ́, wọn a tọ̀ mí wá; emi a sì ṣe idajọ laaarin ẹnikinni ati ẹnikeji, emi a sì maa mú wọn mọ ilana Ọlọrun, ati ofin rẹ̀.” (Eksodu 18:16) Nigba ti kò bá dá a lójú, a fi ọ̀ràn naa lé Jehofa lọwọ. (Numeri 9:6-8; 15:32-36; 27:1-11) Mose jẹ́ apẹẹrẹ rere fun awọn alagba ti wọn ‘ń bojuto agbo Ọlọrun’ lonii ti wọn sì ń ṣe awọn ipinnu idajọ. (Iṣe 20:28) Ǹjẹ́ ki ipo ibatan wọn pẹlu awọn arakunrin wọn bakan naa jásí “òjò winniwinni sara eweko titun.”

14. Ki ni awọn ẹ̀rí itootun tẹmi ti awọn ọkunrin ti Mose yàn sípò gẹgẹ bi onidaajọ ni Israeli?

14 Nigba ti o yá Mose kò lè danikan gbé ẹrù bibojuto awọn ọ̀ràn idajọ fun awọn eniyan naa mọ. (Eksodu 18:13, 18) Ó gba amọran àna rẹ̀ lati wá iranlọwọ. Lẹẹkan sii, iru awọn ọkunrin wo ni ó yàn? A kà pe: “Iwọ ó sì ṣà ninu gbogbo awọn eniyan yii awọn ọkunrin ti o tó [“tóótun,” NW], ti o bẹru Ọlọrun, awọn ọkunrin oloootọ, ti o koriira ojukokoro; . . . Mose sì yan awọn eniyan ti o tó [“tóótun,” NW] ninu gbogbo Israeli, o sì fi wọn ṣe olori awọn eniyan, olori ẹgbẹẹgbẹrun, olori ọ̀rọ̀ọ̀rún, olori araadọta, olori mẹwaa mẹwaa. Wọn si ń ṣe idajọ awọn eniyan nigbakugba: ọ̀ràn ti o ṣoro, wọn a mútọ Mose wá, ṣugbọn awọn tikalaawọn ṣe idajọ gbogbo ọ̀ràn keekeeke.”—Eksodu 18:21-26.

15. Ki ni ẹ̀rí itootun awọn wọnni ti wọn ṣiṣẹsin gẹgẹ bi onidaajọ ni Israeli?

15 A lè rí i pe ọjọ-ori kì í ṣe kókó ipilẹ pataki fun yíyan awọn ọkunrin lati ṣe onidaajọ. Mose wi pe: “Ẹ mú awọn ọkunrin ọlọgbọn wa, ati amoye [“oniriiri,” NW], ati ẹni ti a mọ̀ ninu awọn ẹ̀yà yin, emi yoo sì fi wọn jẹ olori yin.” (Deuteronomi 1:13) Ni àmọ̀dunjú ni Mose mọ ohun ti Elihu ọ̀dọ́ ti sọ ni ọpọlọpọ ọdun ṣaaju: “Eniyan nlanla kì í ṣe ọlọgbọ́n, bẹẹ ni awọn àgbà ni òye ẹ̀tọ́ kò yé.” (Jobu 32:9) Dajudaju, awọn wọnni ti a yàn sípò nilati jẹ́ ‘awọn ọkunrin oniriiri.’ Ṣugbọn lékè gbogbo rẹ̀ wọn nilati jẹ awọn ọkunrin ti o tóótun, olùbẹ̀rù Ọlọrun, aṣeéfọkàntán, ti wọn koriira èrè ti kò bá idajọ ododo mu ti wọn sì jẹ́ ẹni ti o moye ati ọlọgbọ́n-inu. Nitori naa, o jọbi ohun ti ó hàn kedere, pe “awọn olori” ati “awọn onidaajọ” ti a mẹnukan ni Joṣua 23:2 ati 24:1 kò yatọ si ‘awọn àgbà ọkunrin’ ti a mẹnukan ninu awọn ẹsẹ kan naa wọnyẹn ṣugbọn a yàn wọn lati aarin wọn wá.—Wo Insight on the Scriptures, Idipọ 2, oju-iwe 549.

Fifi Idajọ Ododo Sí Ìlò

16. Ki ni a gbọdọ kiyesi lonii nipa awọn itọni ti Mose fi fun awọn onidaajọ ti a ṣẹṣẹ yàn sípò?

16 Niti awọn itọni ti a fifun awọn onidaajọ ti a yàn sípò wọnyi, Mose sọ pe: “Mo sì fi aṣẹ lélẹ̀ fun awọn onidaajọ yin nigba naa pe, ẹ maa gbọ ẹjọ́ laaarin awọn arakunrin yin, ki ẹ sì maa ṣe idajọ ododo laaarin olukuluku ati arakunrin rẹ̀, ati àlejò ti ń bẹ lọdọ rẹ̀. Ẹ kò gbọdọ ṣe ojuṣaaju ni idajọ; ẹ gbọ ti ẹni kekere gẹgẹ bii ti ẹni nla; ẹ kò gbọdọ bẹ̀rù oju eniyan; nitori pe ti Ọlọrun ni idajọ: ọ̀ràn ti o bá sì ṣoro fun yin, ẹ mú un tọ̀ mi [Mose] wá, emi yoo sì gbọ́ ọ.”—Deuteronomi 1:16, 17.

17. Awọn wo ni a yàn sípò gẹgẹ bi onidaajọ, ikilọ wo sì ni Ọba Jehoṣafati fifun wọn?

17 Nitootọ, ọ̀ràn kan ni a lè mú wá fun Mose kìkì ni akoko igbesi-aye rẹ̀. Nitori naa awọn iṣeto siwaju sii ni a ṣe fun awọn ọ̀ràn lilekoko ti a nilati gbé lọ sọdọ awọn alufaa, awọn ọmọ Lefi, ati awọn onidaajọ ti a yàn lákànṣe. (Deuteronomi 17:8-12; 1 Kronika 23:1-4; 2 Kronika 19:5, 8) Si awọn onidaajọ ti o yàn sípò ninu awọn ilu-nla Judah, Ọba Jehoṣafati sọ pe: “Ẹ kiyesi ohun ti ẹyin ń ṣe! Nitori ẹyin kò dajọ fun eniyan bikoṣe fun Oluwa, . . . bayii ni ki ẹyin ki o maa ṣe, ní ìbẹ̀rù Oluwa, ni otitọ, ati pẹlu ọkàn pípé. Ẹjọ́ ki ẹjọ́ ti o bá si dé ọdọ yin lati ọdọ awọn arakunrin yin ti ń gbé ilu wọn, . . . ki ẹyin ki o kilọ fun wọn, ki wọn ki o maṣe dẹṣẹ si Oluwa, ibinu a sì wá sori yin, ati sori awọn arakunrin yin: ẹ ṣe bẹẹ gẹgẹ ẹyin ki yoo sì jẹ̀bi.”—2 Kronika 19:6-10.

18. (a) Ki ni diẹ lara awọn ilana ti awọn onidaajọ ni Israeli gbọdọ fisilo? (b) Ki ni awọn onidaajọ nilati ranti, iwe mimọ wo ni o sì fi abajade bi wọn bá gbàgbé eyi hàn?

18 Lara awọn ilana tí awọn onidaajọ ni Israeli nilati fisilo ni awọn ti o tẹle e yii: idajọ ododo ọgbọọgba fun olowo ati otoṣi (Eksodu 23:3, 6; Lefitiku 19:15); aiṣojuṣaaju pọ́nńbélé (Deuteronomi 1:17); kò sí gbigba owó-ẹ̀hìn. (Deuteronomi 16:18-20) Awọn onidaajọ nilati ranti lemọlemọ pe awọn wọnni ti wọn ń dá lẹ́jọ́ jẹ́ awọn agutan Jehofa. (Orin Dafidi 100:3) Nitootọ, ọ̀kan lara awọn idi ti Jehofa fi ṣá Israeli ti ara tì ni pe awọn alufaa ati oluṣọ agutan wọn kùnà lati fi ododo ṣe idajọ wọn sì fi ìrorò bá awọn eniyan naa lò.—Jeremiah 22:3, 5, 25; 23:1, 2; Esekieli 34:1-4; Malaki 2:8, 9.

19. Iniyelori wo ni iṣayẹwo awọn ọ̀pá idiwọn ododo Jehofa nipa idajọ ododo ṣaaju Sanmani Tiwa ní fun wa, ki ni a o sì gbeyẹwo ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e?

19 Jehofa kò yipada. (Malaki 3:6) Atunyẹwo ṣókí yii nipa ọ̀nà ti a gbọdọ gbà ṣe idajọ ni Israeli ati oju ti Jehofa fi wo ṣíṣe idajọ ododo lọna eyikeyii gbọdọ mú ki awọn alagba ti wọn ni ẹrù-iṣẹ́ fun ṣiṣe awọn ipinnu idajọ lonii duro ki wọn sì ronu. Apẹẹrẹ Jehofa gẹgẹ bi Onidaajọ, ati eto igbekalẹ idajọ ti o dasilẹ ni Israeli, fi idi awọn ilana mulẹ ti o fi apẹẹrẹ lélẹ̀ fun iṣaboojuto idajọ ododo laaarin ijọ Kristian. Eyi ni a o ri ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e.

Awọn Ibeere Atunyẹwo

◻ Bawo ni a ṣe lè ṣàkópọ̀ ọ̀nà ìgbàṣèdájọ́ Jehofa?

◻ Bawo ni a ṣe ṣapẹẹrẹ ọ̀nà Jehofa ninu awọn ibalo rẹ̀ pẹlu Kaini ati ìran ti o wà ṣaaju Ikun-omi?

◻ Awọn wo ni wọn ṣiṣẹ gẹgẹ bi onidaajọ ni akoko awọn babanla, bawo sì ni?

◻ Ki ni o fi iyatọ gedegbe saaarin eto igbekalẹ idajọ Israeli ati awọn orilẹ-ede miiran?

◻ Iru awọn ọkunrin wo ni a yàn sípò gẹgẹ bi onidaajọ ni Israeli, awọn ilana wo sì ni wọn ti nilati tẹle?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ni akoko awọn babanla ati ni Israeli, awọn àgbààgbà ọkunrin ti a yàn sípò fi idajọ ododo funni ni ẹnu bodè ilu-nla

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́