ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 7/15 ojú ìwé 8-13
  • Kristi Koriira Iwa-Ailofin—Iwọ Ha Koriira Rẹ̀ Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kristi Koriira Iwa-Ailofin—Iwọ Ha Koriira Rẹ̀ Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Oriṣi Ikoriira Mẹta
  • Idi Ti A Fi Gbọdọ Koriira Iwa-Ailofin
  • Awọn Wọnni Tí Ń Koriira Iwa-Ailofin
  • Fifi Ikoriira Hàn Fun Iwa-Ailofin
  • Kikoriira Iwa-Aimọ Ibalopọ Takọtabo
  • Kikoriira Isin Èké ati Ipẹhinda
  • Ǹjẹ́ o Kórìíra Ìwà Àìlófin?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìwà Ọ̀daràn Ń Peléke Sí I Kárí Ayé—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Tí A Lè Gbà Mú Ìkórìíra Kúrò Pátápátá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • “Ìgbà Nínífẹ̀ẹ́ àti Ìgbà Kíkórìíra”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 7/15 ojú ìwé 8-13

Kristi Koriira Iwa-Ailofin—Iwọ Ha Koriira Rẹ̀ Bi?

“Iwọ fẹ́ ododo, iwọ sì koriira iwa-ailofin. Iyẹn ni idi ti Ọlọrun, Ọlọrun rẹ, fi fàmì ororo yàn ọ́ pẹlu ororo ayọ-aṣeyọri ju awọn ẹlẹgbẹ rẹ lọ.”—HEBERU 1:9, NW.

1. Yatọ si ninifẹẹ ododo, ohun miiran wo ni a tun beere fun lọwọ gbogbo awọn iranṣẹ Jehofa Ọlọrun tootọ?

AWỌN iranṣẹ tootọ fun Jehofa nifẹẹ rẹ̀     pẹlu gbogbo ọkan-aya, ọkàn, ero    inu, ati okun wọn. (Marku 12:30) Wọn fẹ́ lati mú inu Jehofa dun nipa pípa iwatitọ mọ́. (Owe 27:11) Lati ṣe iyẹn, kì í ṣe kìkì pe wọn gbọdọ nifẹẹ ododo nikan ni ṣugbọn wọn gbọdọ koriira iwa-ailofin pẹlu. Awofiṣapẹẹrẹ wọn, Jesu Kristi, ṣe bẹẹ dajudaju. Nipa rẹ̀ ni a sọ pe: “Iwọ fẹ́ ododo, iwọ sì koriira iwa-ailofin.”—Heberu 1:9, NW.

2. Ki ni iwa-ailofin ní ninu?

2 Ki ni iwa-ailofin? Ẹṣẹ ni, gẹgẹ bi aposteli Johannu ti fihàn nigba ti o kọwe pe: “Olukuluku ẹni ti ó sọ ẹṣẹ dàṣà ń sọ ailofin dàṣà pẹlu, ati nitori naa ẹṣẹ ni iwa-ailofin.” (1 Johannu 3:4, NW) Oniwa-ailofin kan ni “ofin kò kálọ́wọ́kò tabi ṣakoso.” (Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary) Iwa-ailofin ní gbogbo ohun ti o jẹ́ ibi, buburu, iwa-palapala, iwa-ibajẹ, ati àbòsí ninu. Yíyíju wo ayé fihàn wá pe iwa-ailofin pọ yamùrá lonii ju ti igbakigba ri lọ. Kò sí iyemeji pe a ń gbé ni “ìgbà ewu” ti aposteli Paulu sọ tẹlẹ ṣaaju ni 2 Timoteu 3:1-5. Ni oju-iwoye gbogbo iwa-ailofin yii, ó ti dara tó pe a paṣẹ fun wa lati koriira gbogbo ibi! Fun apẹẹrẹ, a sọ fun wa pe: “Ẹyin ti o fẹ́ Oluwa, ẹ koriira ibi.” (Orin Dafidi 97:10) Bakan naa, a kà pe: “Ẹ koriira ibi, ẹ sì fẹ́ ire.”—Amosi 5:15.

Oriṣi Ikoriira Mẹta

3-5. Ni awọn ọ̀nà mẹta wo ni a gbà lo ọ̀rọ̀ naa “koriira” ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun?

3 Ki ni o tumọsi lati koriira? Ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, “koriira” ni a lo ni ọ̀nà mẹta ọtọọtọ. Ikoriira tí àránkàn jẹ́ ète isunniṣe fun ti o si ń wá ọ̀nà lati pa kókó àfojúsọ rẹ̀ lara wà. Awọn Kristian gbọdọ yẹra fun iru ikoriira yii. Oun ni iru eyi ti o sún Kaini lati pa arakunrin rẹ̀ olododo Abeli. (1 Johannu 3:12) Eyi tún ni iru ikoriira tí awọn aṣaaju isin ní fun Jesu Kristi ninu.—Matteu 26:3, 4.

4 Siwaju sii, ọ̀rọ̀ naa “koriira” ni a lò ninu Iwe Mimọ ní èrò itumọ ti nínífẹ̀ẹ́ ti o dinku. Fun apẹẹrẹ, Jesu sọ pe: “Bi ẹnikan bá tọ̀ mi wá, ti kò sì koriira baba rẹ̀, ati ìyá, ati aya, ati ọmọ, ati arakunrin, ati arabinrin, ani ati ẹmi araarẹ pẹlu, kò lè ṣe ọmọ-ẹhin mi.” (Luku 14:26) Ni kedere, ohun ti Jesu wulẹ ní lọkan ni nínífẹ̀ẹ́ ti o dinku si eyi ti a ni fun oun fun awọn wọnyi. Jakọbu “koriira Lea,” ṣugbọn niti gidi ifẹ ti o ni fun un wulẹ dinku si eyi ti o ni fun Rakeli ni.—Genesisi 29:30, 31.

5 Lẹhin naa ni itumọ ọ̀rọ̀ naa “koriira” eyi ti o kàn wá gbọ̀ngbọ̀n nihin-in wà. Ó ní èrò níní iru imọlara mimuna ti ìríra fun tabi ainifẹẹ lilagbara si ẹnikan tabi ohun kan debi pe a o yẹra fun níní ohunkohun ṣe pẹlu iru ẹni tabi ohun kan bẹẹ. Ni Orin Dafidi 139 eyi ni a pe ni ‘ikoriira ni àkótán.’ Nibẹ ni Dafidi ti sọ pe: “Oluwa, ǹjẹ́ emi kò koriira awọn ti o koriira rẹ? Ǹjẹ́ inu mi kò ha sì bajẹ si awọn ti o dide si ọ? Emi koriira wọn ni àkótán: emi kà wọn si ọ̀tá mi.”—Orin Dafidi 139:21, 22.

Idi Ti A Fi Gbọdọ Koriira Iwa-Ailofin

6, 7. (a) Eeṣe, ni pataki, ti a fi gbọdọ koriira iwa-ailofin? (b) Ki ni idi alagbara keji lati koriira iwa-ailofin?

6 Eeṣe ti a fi gbọdọ koriira iwa-ailofin? Idi kan jẹ́ nitori ki a baa lè ní ọ̀wọ̀ ara-ẹni ati ẹ̀rí ọkàn rere. Kìkì ni ọ̀nà yii ni a lè gbà ní ipo ibatan rere pẹlu Baba wa olododo, Baba onífẹ̀ẹ́ ti ọ̀run, Jehofa. Dafidi fi apẹẹrẹ rere lélẹ̀ ninu ọ̀ràn yii, gẹgẹ bi a ti lè rí i nipa kíka Orin Dafidi 26. Fun apẹẹrẹ, ó sọ pe: “Emi ti koriira ijọ awọn oluṣe buburu; emi kì yoo si bá awọn eniyan buburu jokoo.” (Orin Dafidi 26:5) Ifẹ wa fun Ọlọrun ati ododo gbọdọ sún wa lati ní ìkannú ododo—bẹẹni, ikoriira—fun gbogbo ohun ti ó jẹ́ ailofin ni ọ̀nà ìgbàwo-nǹkan rẹ̀, ti o ni awọn iṣẹ ailofin awọn wọnni ti wọn ṣaigbọran ti wọn sì koriira Jehofa ninu. Siwaju sii pẹlu, a gbọdọ koriira iwa-ailofin nitori ẹ̀gàn ti ń mú wá sori orukọ Ọlọrun.

7 Idi miiran ti awọn eniyan Jehofa fi gbọdọ koriira iwa-ailofin ni pe ó léwu gan-an ó sì lè panilara. Fifunrugbin sí ipa ti ara, eyi ti o tumọsi fifunrugbin iwa-ailofin, yoo ni iyọrisi wo? Paulu kilọ pe: “Ki a maṣe tàn yin jẹ; a kò lè gan Ọlọrun: nitori ohunkohun ti eniyan bá funrugbin, oun ni yoo sì ká. Nitori ẹni ti o bá ń funrugbin sipa ti araarẹ̀, nipa ti ara ni yoo ká idibajẹ; ṣugbọn ẹni ti o bá ń funrugbin sipa ti ẹmi, nipa ti ẹmi ni yoo ká ìyè ainipẹkun.” (Galatia 6:7, 8) Nitori naa awa kò gbọdọ fẹ́ẹ́ ni ohunkohun lati ṣe pẹlu iwa-ailofin. Loootọ, a nilati koriira gbogbo iwa-ailofin fun wíwà lalaafia ati alaafia ọkàn tiwa funraawa.

Awọn Wọnni Tí Ń Koriira Iwa-Ailofin

8. Ta ni o ti fi apẹẹrẹ pataki lélẹ̀ ninu kikoriira iwa-ailofin, gẹgẹ bi iwe mimọ wo ti fihàn?

8 Ni kikoriira iwa-ailofin, Ọlọrun fi apẹẹrẹ pataki lélẹ̀ fun gbogbo awọn ẹ̀dá ọlọgbọnloye. Oun ní ìkannú lọna ododo si iwa-ailofin, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì sọ pe: “Ohun mẹfa ni Oluwa koriira: nitootọ, meje ni o ṣe irira fun ọkàn rẹ̀: oju igberaga, ètè èké, ati ọwọ́ ti ń ta ẹ̀jẹ̀ alaiṣẹ silẹ, àyà ti ń hùmọ̀ buburu, ẹsẹ ti o yara ni iré sísá si iwa-ika, ẹlẹ́rìí èké ti ń sọ èké jade, ati ẹni ti ń dá ìjà silẹ laaarin awọn arakunrin.” A tún kà pe: “Ibẹru Oluwa ni ikoriira ibi: irera, ati igberaga, ati ọ̀nà ibi, ati ẹnu arekereke, ni mo koriira.” (Owe 6:16-19; 8:13) Ju bẹẹ lọ, a sọ fun wa pe: “Nitori emi Oluwa fẹ́ idajọ, mo koriira ìjalè ninu aiṣododo.”—Isaiah 61:8.

9, 10. Bawo ni Jesu ṣe fihàn pe oun koriira iwa-ailofin?

9 Jesu Kristi ṣafarawe Baba rẹ̀ ninu kikoriira iwa-ailofin. Nipa bayii, a kà pe: “Iwọ fẹ́ ododo, iwọ sì koriira iwa-ailofin. Iyẹn ni idi ti Ọlọrun, Ọlọrun rẹ, fi fàmì ororo yàn ọ́ pẹlu ororo ayọ-aṣeyọri ju awọn ẹlẹgbẹ rẹ lọ.” (Heberu 1:9, NW) Jesu fi apẹẹrẹ lélẹ̀ fun wa ninu iru ikoriira yii. Ó fi ikoriira rẹ̀ nipa iwa-ailofin hàn nipa titudii awọn wọnni ti wọn ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é bi àṣà—awọn aṣaaju isin èké. Leralera, ó bu ẹnu àtẹ́ lù wọn gẹgẹ bi agabagebe. (Matteu, ori 23) Ni akoko miiran Jesu sọ fun wọn pe: “Ti eṣu baba yin ni ẹyin iṣe, ifẹkufẹẹ baba yin ni ẹ si ń fẹ ṣe.” (Johannu 8:44) Jesu fi ikoriira rẹ̀ fun iwa-ailofin hàn àní dé ìwọ̀n ti o fi lo ipa ti ara-ìyára, ni akoko iṣẹlẹ meji ni sisọ tẹmpili di mimọ tonitoni kuro lọwọ awọn oniwọra alagabagebe isin.—Matteu 21:12, 13; Johannu 2:13-17.

10 Jesu tún fi ikoriira rẹ̀ nipa iwa-ailofin ati ẹṣẹ hàn nipa pipa araarẹ mọ́ patapata kuro ninu wọn. Nitori naa, ó lè beere lọwọ awọn alatako rẹ̀ bakan naa pe: “Ta ni ninu yin ti o ti i dá mi ni ẹbi ẹṣẹ?” (Johannu 8:46) Jesu jẹ́ “mimọ, ailẹgan, aileeeri, ti a yà si ọtọ kuro ninu ẹlẹṣẹ.” (Heberu 7:26) Ní jijẹrii si eyi, Peteru kọwe pe Jesu “kò dẹṣẹ, bẹẹ ni a kò sì rí arekereke ni ẹnu rẹ̀.”—1 Peteru 2:22.

11. Awọn apẹẹrẹ ti o bá Iwe Mimọ mu wo ni a ní nipa awọn eniyan alaipe ti wọn koriira iwa-ailofin?

11 Bi o ti wu ki o ri, Jesu, jẹ́ ọkunrin pípé kan. Ǹjẹ́ a ni awọn apẹẹrẹ ti o bá Iwe Mimọ mu ti awọn eniyan alaipe ti wọn koriira iwa-ailofin nitootọ bi? Dajudaju a ní! Fun apẹẹrẹ, Mose ati awọn ọmọ Lefi ẹlẹgbẹ rẹ̀ fi ikoriira ńlá hàn fun ibọriṣa nipa pipa nǹkan bii 3,000 awọn abọriṣa pẹlu aṣẹ Jehofa. (Eksodu 32:27, 28) Finehasi fi ikoriira ńlá hàn fun iwa-ailofin nigba ti ó fi ẹ̀ṣín pa awọn alágbèrè meji.—Numeri 25:7, 8.

Fifi Ikoriira Hàn Fun Iwa-Ailofin

12. (a) Bawo ni a ṣe lè fi ikoriira wa hàn fun iwa-ailofin? (b) Ki ni awọn ọ̀nà gbigbeṣẹ diẹ ti a le gba lati yẹra fun awọn èrò ailofin?

12 Ni wíwá si akoko wa, bawo ni a ṣe lè fi ikoriira iwa-ailofin wa hàn? Nipa ṣiṣakoso awọn ironu, ọ̀rọ̀, ati iṣe wa. A nilati mu aṣa rironu nipa awọn ohun ti ń gbeniro dagba nigba ti iṣẹ pàtó kan ti a ń ṣe lọwọ kò bá gbà wá lọ́kàn. Bi ó ba ṣẹlẹ pe oorun dá loju wa ni òru, ìtẹ̀sí kan lè wà lati ní ironu òdì diẹ, bii rironu ṣáá nipa ohun ti ń binininu tabi lọwọ ninu awọn ìrònú-asán ti ibalopọ takọtabo. Maṣe fààyè gba iru awọn nǹkan bẹẹ lae, ṣugbọn ní aṣa lilọwọ ninu ironu tí o ṣanfaani. Fun apẹẹrẹ, gbiyanju lati ka awọn ẹsẹ-iwe mimọ sori, awọn ayọ mẹsan-an, ati eso ti ẹmi mẹsan-an. (Matteu 5:3-12; Galatia 5:22, 23) Iwọ ha lè darukọ awọn aposteli 12 bi? Iwọ ha mọ awọn Ofin Mẹwaa bi? Awọn ijọ meje wo ni a dari ọ̀rọ̀ sí ninu Ìfihàn? Kíkọ́ awọn orin Ijọba sori tún lè ṣeranwọ lati pa ọkàn wa mọ sori awọn nǹkan ti wọn jẹ́ otitọ, ni idaniyan pataki, jẹ ododo, mímọ́, yẹ ni fífẹ́, ti a sọrọ rẹ̀ daradara, ti o ni irohin rere, ti o sì lẹtọọsi iyin.—Filippi 4:8.

13. Kikoriira iwa-ailofin yoo mú wa lati koriira iru ọ̀rọ̀ wo?

13 Siwaju sii, a fihan pe a koriira iwa-ailofin nipa yiyẹra fun gbogbo ọ̀rọ̀ aimọ. Ọpọlọpọ awọn eniyan ayé gbadun lati maa sọ ati lati fetisilẹ si awọn awada ti kò mọ́, ṣugbọn awọn Kristian kò gbọdọ ní ìtẹ̀sí àní lati fetisilẹ si wọn. Kaka bẹẹ, a gbọdọ rìn kuro ki a sì yẹra fun kikopa ninu ijumọsọrọpọ eyikeyii ti o maa ń fi kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ di ọ̀rọ̀ ẹ̀fẹ̀. Bi kò bá ṣeeṣe lati rin kuro, a le fihan ó keretan nipa irisi oju wa pe a koriira iru ọ̀rọ̀ bẹẹ. A nilati kọbiara si imọran rere yii: “Ẹ maṣe jẹ ki ọrọ idibajẹ kan ti ẹnu yin jade, ṣugbọn iru eyi ti o dara fun ẹ̀kọ́, ki o lè maa fi oore-ọfẹ fun awọn ti ń gbọ.” (Efesu 4:29) A kò gbọdọ sọ araawa di alaimọ nipa sisọ ohun ti kò mọ́ tabi fifetisilẹ si i.

14. Idaabobo wo ni ikoriira iwa-ailofin yoo pese fun wa niti awọn aṣa iṣẹ-aje ati igbanisiṣẹ?

14 Ikoriira ti a ní fun iwa-ailofin ni a gbọdọ tún dari lodisi gbogbo awọn aṣa ti o kún fun ẹṣẹ. Kikoriira iwa-ailofin yoo ràn wa lọwọ lati yẹra fun idẹkun jijuwọsilẹ ninu ọ̀ràn yii. Awọn ojulowo Kristian ki i sọ ẹṣẹ di aṣa. (Fiwe 1 Johannu 5:18.) Fun apẹẹrẹ, a gbọdọ koriira gbogbo awọn aṣa iṣẹ-aje alábòsí. Lonii, ọpọlọpọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a ti fi sabẹ ikimọlẹ lati ṣe awọn ohun alábòsí fun awọn agbanisiṣẹ wọn ṣugbọn ti wọn ti kọ̀ lati ṣe bẹẹ. Awọn Kristian tilẹ ti ń muratan nigba miiran lati padanu iṣẹ wọn ju ki wọn ṣe ohun kan ti o pa ẹ̀rí ọkàn wọn ti wọn fi Bibeli kọ́ lara. Ju bẹẹ lọ, a tún fẹ́ lati fi ikoriira wa fun iwa-ailofin hàn nipa ṣiṣairú awọn ofin ìrìnnà ati nipa ṣiṣairẹnijẹ nigba ti a gbọdọ san awọn owo orí ati owó ibode.—Iṣe 23:1; Heberu 13:18.

Kikoriira Iwa-Aimọ Ibalopọ Takọtabo

15. Dídá eniyan pẹlu ìtẹ̀sí-ìwà-àdánidá lilagbara ti ibalopọ ṣiṣẹ fun awọn ète rere wo?

15 Gẹgẹ bi Kristian, a gbọdọ koriira gbogbo iwa-aimọ ti o wémọ́ ọ̀ràn ibalopọ takọtabo ni pataki. Nipa dídá araye pẹlu ìtẹ̀sí-ìwà-àdánidá lilagbara ti ibalopọ, Ọlọrun ṣiṣẹ fun ète rere meji. Ó rí i daju pe ẹ̀yà iran eniyan kò ní kú tán, ó sì tún ṣe ipese onífẹ̀ẹ́ julọ fun ayọ. Àní awọn eniyan ti wọn jẹ́ otoṣi, alaimọọkọ-mọọka, tabi awọn ti a fi anfaani dù ni awọn ọ̀nà miiran paapaa lè rí ayọ ńlá ninu ipo ibatan onigbeeyawo. Bi o ti wu ki o ri, Jehofa ti gbé awọn ààlà kalẹ laaarin eyi ti a lè gbadun ipo ibatan yii. Awọn ààlà atọrunwa ti a gbekalẹ wọnyi ni a gbọdọ bọwọ fun.—Genesisi 2:24; Heberu 13:4.

16. Ki ni o gbọdọ jẹ́ iṣarasihuwa wa siha eré inaju ati awọn aṣa oniwa-aimọ niti ibalopọ takọtabo?

16 Bi a bá koriira iwa-ailofin, awa yoo fi taapọntaaapọn yẹra fun gbogbo aṣa oniwa-aimọ niti ibalopọ takọtabo ati eré inaju oniwa palapala. Nitori naa awa yoo yẹra fun gbogbo awọn iwe, iwe irohin, ati awọn iwe agberohinjade ti a lè gbé ibeere dide si niti iwarere. Bakan naa, bi a bá koriira iwa-ailofin, awa ki yoo wo ìran awọn eré iwa-aimọ, yala lori tẹlifiṣọn, ninu awọn aworan ara ogiri, tabi lori ìtàgé. Bi a bá ri itolẹsẹẹsẹ kan pe o jẹ́ oniwa palapala, a gbọdọ sún wa lati pa apoti tẹlifiṣọn naa lọ́gán tabi ki a ni igboya lati fi ibi iṣere naa silẹ. Lọna ti o farajọra, kikoriira iwa-ailofin yoo mú wa ṣọra lodisi gbogbo orin ti ń ru ifẹkufẹẹ soke ninu awọn ọ̀rọ̀ orin tabi dídún rẹ̀. Awa kò ni wá ìmọ̀ awọn ọ̀ràn iwa palapala ṣugbọn awa yoo jẹ́ ‘ọmọ-ọwọ niti iwa ibi, sibẹ jẹ́ gende ni agbara iloye.’—1 Korinti 14:20.

17. Imọran wo ni Kolosse 3:5 fifunni ti o lè ràn wá lọwọ lati wà ni mimọ tonitoni niti iwarere?

17 Lọna ti ó yẹ rẹ́gí julọ, a gbà wá nimọran pe: “Nitori naa ẹ sọ awọn ẹ̀yà ara yin ti ń bẹ lori ilẹ̀-ayé dòkú niti iwa agbere, iwa-aimọ, ifẹ ọkàn ti ara fun ibalopọ.” (Kolosse 3:5, NW) Kò sí iyemeji pe awọn igbesẹ lilagbara ni a nilo ni iha ọdọ tiwa bi awa yoo bá pinnu lati wà ni mimọ tonitoni niti iwarere titilọ. Nipa ọrọ iṣe Griki ti a tumọ si ‘sọ dòkú’ ni Kolosse 3:5, The Expositor’s Bible Commentary sọ pe: “Ó damọran pe awa kì yoo wulẹ tẹ awọn iṣe ati ẹmi ironu buburu rì tabi ṣakoso rẹ̀. Awa nilati nù wọ́n nù kuro, ki a pa ọ̀nà igbesi-aye ogbologboo run patapata. ‘Lùpa yán-án-yán-yán’ lè fi ipá rẹ̀ hàn. . . . Ati itumọ ọ̀rọ̀ iṣe naa ati ipá itọka akoko rẹ̀ damọran ipinnu ara-ẹni ti a ṣe tagbaratagbara, lọna kan ti ń ronilara.” Nitori naa a gbọdọ yẹra fun aworan arufẹ iṣekuṣe soke bi ẹni pe ó jẹ́ aisan elewu, ti o lè ranni, ti ń ṣekupani, nitori iyẹn ni ohun ti o jẹ niti iwarere ati nipa tẹmi. Kristi sọ iru èrò kan-naa jade nigba ti o sọ pe ki a sọ apá, ẹsẹ, tabi oju kan paapaa nù bi ó bá ń mú wa kọsẹ.—Marku 9:43-48.

Kikoriira Isin Èké ati Ipẹhinda

18. Bawo ni a ṣe lè fi ikoriira wà fun iwa-ailofin isin hàn?

18 Lẹhin naa, pẹlu, gẹgẹ bi Jesu ti fi ikoriira rẹ̀ fun iwa-ailofin hàn nipa titudii awọn onisin agabagebe, bẹẹ ni Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii ń fi ikoriira wọn fun gbogbo iwa-ailofin isin agabagebe hàn. Bawo? Nipa pípín iwe ikẹkọọ Bibeli ti o sọ otitọ nipa ohun ti Babiloni Nla jẹ niti gidi di mímọ̀, aṣẹwo onisin. Bi a bá koriira agabagebe isin alailofin nitootọ, awa yoo jẹ alaifọrọ bọpobọyọ̀ ninu titudii Babiloni Nla, ilẹ-ọba isin èké agbaye. Awa yoo ṣe bẹẹ nititori awọn eniyan alailabosi ọkàn ti ó ti fọ́ loju ti ó sì ti dì ni igbekun tẹmi. Dé iwọn ti a ba koriira iwa-ailofin ti Babiloni Nla de nitootọ, dé iwọn yẹn ni a o jẹ́ onitara ninu ṣiṣajọpin ninu gbogbo apa ìhà iṣẹ-ojiṣẹ Ijọba naa.—Matteu 15:1-3, 7-9; Titu 2:13, 14; Ìfihàn 18:1-5.

19. Oju wo ni o yẹ ki a fi wo awọn apẹhinda, eesitiṣe?

19 Iṣẹ aigbọdọmaṣe naa lati koriira iwa-ailofin tún kan gbogbo igbokegbodo awọn apẹhinda. Iṣarasihuwa wa si awọn apẹhinda gbọdọ jẹ́ eyi ti Dafidi ni, ẹni ti o polongo pe: “Oluwa, ǹjẹ́ emi kò koriira awọn ti o koriira rẹ? Njẹ́ inu mi kò ha sì bajẹ sí awọn ti o dide si ọ? Emi koriira wọn ni àkótán: emi kà wọn sí ọ̀tá mi.” (Orin Dafidi 139:21, 22) Awọn apẹhinda ode-oni ti gbè sẹhin “ọkunrin iwa-ailofin,” awujọ alufaa Kristẹndọm. (2 Tessalonika 2:3, NW) Gẹgẹ bi Ẹlẹ́rìí aduroṣinṣin ti Jehofa, awa nitori naa kò ni ohunkohun papọ pẹlu wọn. Bi a ti jẹ alaipe, ọkan-aya wa lè fi tirọruntirọrun ni ìtẹ̀sí siha jíjẹ́ ẹni ti ń ṣariwisi nipa awọn arakunrin wa. Gẹgẹ bi ẹnikọọkan, awọn wọnni ti wọn jẹ́ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” jẹ́ eniyan alaipe. (Matteu 24:45-47) Ṣugbọn ẹgbẹ́ yii jẹ́ oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu. Awọn apẹhinda rinkinkin mọ́ awọn aṣiṣe tabi ohun ti o jọ aṣiṣe ti awọn arakunrin ti wọn ń mú ipo iwaju ṣe. Aabo wa sinmile yiyẹra fun igbekeeyide apẹhinda gẹgẹ bi ẹni pe o jẹ́ majele, eyi ti o jẹ́ nitootọ.—Romu 16:17, 18.

20, 21. Bawo ni a ṣe lè ṣakopọ awọn idi fun kikoriira iwa-ailofin?

20 A ti rí i pe ayé kún fun iwa-ailofin, eyi ti o ni itumọ ti o sunmọra pẹlu ẹṣẹ. Kò tó fun wa lati nifẹẹ ododo; a gbọdọ tún koriira iwa-ailofin. Diẹ lara awọn wọnni ti a ti yọlẹgbẹ kuro ninu ijọ Kristian lè ti ronu pe awọn nifẹẹ ododo, ṣugbọn wọn kò koriira iwa-ailofin tó. A tún ti rí idi ti a fi gbọdọ koriira iwa-ailofin. A kò lè ni ẹ̀rí ọkàn rere ati ọ̀wọ̀ ara-ẹni ayafi bi a bá ṣe bẹẹ. Siwaju sii pẹlu, iwa-ailofin tumọsi jíjẹ́ alaiduroṣinṣin pẹlu Jehofa Ọlọrun. Iwa-ailofin sì ń mú ki a karugbin eso kikoro gan-an—ibanujẹ, idibajẹ, ati ikú.

21 A tún ti ṣakiyesi bi a ṣe le fihàn pe a koriira iwa-ailofin. A ń ṣe bẹẹ nipa ṣiṣaini ohunkohun lati ṣe pẹlu iru iwa àbòsí, iwa palapala ibalopọ takọtabo, tabi ipẹhinda eyikeyii patapata. Niwọn bi a ti fẹ́ lati ṣajọpin ninu idalare Jehofa ti a sì lọkan ifẹ lati mú ọkan-aya rẹ̀ layọ, kì í ṣe pe a gbọdọ nifẹẹ ododo ki a sì mú ki ọwọ́ wa dí ninu iṣẹ-isin rẹ̀ nikan ni ṣugbọn a tún gbọdọ koriira iwa-ailofin, gẹgẹ bi Aṣaaju ati Alaṣẹ wa, Jesu Kristi ti ṣe.

Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?

◻ Bawo ni Iwe Mimọ ṣe lo ọ̀rọ̀ naa “koriira”?

◻ Ki ni awọn idi rere diẹ ti a fi nilati koriira iwa-ailofin?

◻ Awọn apẹẹrẹ rere wo ni a ní niti awọn wọnni ti wọn koriira iwa-ailofin?

◻ Bawo ni a ṣe lè fi ikoriira wa fun iwa-ailofin hàn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Jesu sọ inu tẹmpili di mimọ nitori pe ó koriira iwa-ailofin

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Bi a bá koriira iwa-ailofin, awa yoo yẹra fun eré inaju ibalopọtakọtabo oniwa palapala

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́