ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 8/1 ojú ìwé 8-12
  • ‘Jẹ Ki Ilọsiwaju Rẹ Di Mímọ̀’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Jẹ Ki Ilọsiwaju Rẹ Di Mímọ̀’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Akoko fun Ayẹwo Ara-ẹni
  • ‘Awọn Ìwà Èwe’
  • Bi Ilọsiwaju Ṣe Ń Farahàn
  • Ṣé O Ti Di “Géńdé” Kristẹni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Jẹ́ Kí Ìlọsíwájú Rẹ Fara Hàn Kedere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Máa Tẹ̀ Síwájú
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • ‘Fífi Ọwọ́ Títọ̀nà Mú Ọ̀rọ̀ Òtítọ́’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 8/1 ojú ìwé 8-12

‘Jẹ Ki Ilọsiwaju Rẹ Di Mímọ̀’

“Nigba ti mo di ọkunrin tán, mo fi ìwà èwe silẹ.”—1 KORINTI 13:11.

1. Bawo ni idagbasoke ṣe jẹ́ ẹ̀rí si iyanu iṣẹda?

LATI inu ẹyin ti o kere gan-an debi pe kìkì labẹ ẹ̀rọ amú-nǹkan tobi ni a ti lè rí i, ẹja àbùùbùtán kan lè dagba di iṣẹda kan ti o gun ju ọgọrun-un ẹsẹ bata lọ ki ó sì wọ̀n rekọja 80 tọọnu. Bakan naa, lati inu ọ̀kan lara awọn irugbin ti o kere julọ, igi sequoia giga fiofio lè dagba di giga rekọja 300 ẹsẹ bata. Loootọ, idagbasoke jẹ́ ọ̀kan lara awọn ohun iyanu ninu igbesi-aye. Gẹgẹ bi aposteli Paulu ti sọ ọ́, a lè gbìn ki a sì bomirin, ṣugbọn ‘Ọlọrun níí mú ibisi wa.’—1 Korinti 3:7.

2. Iru idagbasoke wo ni a sọ asọtẹlẹ rẹ̀ ninu Bibeli?

2 Bi o ti wu ki o ri, iru idagbasoke miiran kan ń bẹ ti o jẹ́ agbayanu bakan naa. Ó jẹ́ ọ̀kan ti a sọtẹlẹ lati ẹnu wolii Isaiah pe: “Ẹni-kekere kan ni yoo di ẹgbẹrun, ati kekere kan di alagbara orilẹ-ede: emi Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo ṣe e kánkán ni akoko rẹ̀.” (Isaiah 60:22) Asọtẹlẹ yii niiṣe pẹlu idagbasoke awọn eniyan Ọlọrun, ó sì ń ní imuṣẹ pataki ni ọjọ wa.

3. Bawo ni irohin ọdun iṣẹ-isin 1991 ṣe fihàn pe Jehofa ń mú iṣẹ awọn eniyan rẹ̀ yára kánkán?

3 Irohin ọdun iṣẹ-isin 1991 nipa igbokegbodo Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yika ayé fihàn pe iye awọn akede Ijọba dé gongo titun ti 4,278,820, aropọ 300,945 awọn eniyan ni a sì baptisi ni ọdun naa. Pẹlu ìrọ́wọlé awọn ẹni titun lọpọlọpọ tobẹẹ, 3,191 ijọ titun ni a dasilẹ, papọ pẹlu iye ayika ati agbegbe titun ti o ba eyi dọgba. Iyẹn ju ijọ titun mẹjọ ni ojumọ kan lọ, o fẹrẹẹ tó ayika titun kan ni ọjọ meji-meji. Ẹ wo agbayanu idagbasoke ti ó jẹ́! Ni kedere, Jehofa ń mú awọn nǹkan yára kánkán, ibukun rẹ̀ sì wà lori isapa awọn eniyan rẹ̀.—Orin Dafidi 127:1.

Akoko fun Ayẹwo Ara-ẹni

4. Awọn ibeere wo ni a gbọdọ gbeyẹwo bi a ti ń wo ọjọ-ọla?

4 Bi o tilẹ jẹ pe o munilọkanyọ lati rí, ibukun yii tun ń mú awọn ẹrù-iṣẹ́ kan wá pẹlu rẹ̀. Awọn ẹnikọọkan ti wọn dagbadenu ti wọn sì muratan lati bojuto aini tẹmi awọn ẹni titun wọnyi ha wà bi? Bi a ti ń wo iwaju fun ọjọ-ọla, ó ṣeni ni kayeefi lati ronu nipa iye awọn aṣaaju-ọna, iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ, alagba, ati awọn alaboojuto arinrin-ajo ti a o nilo lati bojuto idagbasoke ati imugbooro, ati bakan naa iye awọn oṣiṣẹ oluyọnda ara-ẹni ti a nilo ni awọn ọfiisi ẹ̀ka ati Ile Beteli yika ayé lati ṣetilẹhin fun iṣẹ naa. Nibo ni ọpọ jantirẹrẹ iye eniyan yii yoo ti wá? Kò si iyemeji pe ikore naa pọ̀ gidigidi. Ṣugbọn awọn wo lonii ni wọn wà ni ipo lati bojuto gbogbo awọn oṣiṣẹ ti a nilo lati ṣe ikore yẹn?—Matteu 9:37, 38.

5. Awọn ipo wo ni ó wà ni awọn agbegbe kan nitori idagbasoke yíyára kánkán?

5 A ti rohin rẹ̀, fun apẹẹrẹ, pe ni awọn apá ibikan ni ayé, awọn ijọ wà ti wọn ni awọn akede Ijọba ti iye wọn pọ̀ tó ọgọrun-un ti ẹyọ alagba kanṣoṣo ń ṣiṣẹsin papọ pẹlu iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ kan tabi meji. Nigba miiran alagba kan nilati ṣiṣẹsin ninu ijọ meji. Ni awọn ibomiran aini naa fun Kristian ojiṣẹ ti o tootun lati dari awọn ikẹkọọ Bibeli inu ile pọ̀ tobẹẹ gẹẹ debi pe awọn ẹni titun ni a nilati kọ orukọ wọn silẹ fun diduro de ẹnikan lati bá wọn ṣe ikẹkọọ. Ni agbegbe miiran sibẹ, awọn ijọ titun ni a ń da silẹ ni iru ìwọ̀n ti ó yara kánkán bẹẹ debi pe awọn ijọ mẹta, mẹrin, tabi marun-un paapaa nilati ṣajọpin Gbọngan Ijọba kan. Boya iwọ ti rí idagbasoke bi eyi ni agbegbe tirẹ.

6. Eeṣe ti ayẹwo ara-ẹni fi bá akoko mu ni ìhà ọdọ tiwa?

6 Ki ni ohun ti a ṣẹṣẹ mẹnukan loke yii sọ fun wa? Pe ni oju-iwoye awọn akoko, gbogbo wa nilati ṣayẹwo awọn ipo ayika wa lati rii bi a bá ń lo akoko ati ohun àmúṣọrọ̀ wa lọna ti o dara julọ ki a baa lè dahunpada si aini naa. (Efesu 5:15-17) Aposteli Paulu kọwe si awọn Kristian Heberu ti ọrundun kìn-ín-ní pe: “Nitori nigba ti akoko tó ti o yẹ ki ẹ jẹ́ olukọ, ẹ tun wà ni ẹni ti ẹnikan yoo maa kọ́ ni ibẹrẹ ipilẹ awọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun; ẹ sì di iru awọn ti kò lè ṣe aini wàrà, ti wọn kò sì fẹ́ ounjẹ lile.” (Heberu 5:12) Gẹgẹ bi awọn ọ̀rọ̀ wọnyẹn ti fihàn, aini wà fun awọn Kristian kọọkan lati dagbasoke. Ewu gidi kan sì wà pe ẹnikan lè wà pẹtiti ni ipò jíjẹ́ ọmọ-ọwọ tẹmi dipo titẹsiwaju si idagba di gende Kristian. Ni ibamu pẹlu eyi, Paulu rọ̀ wá pe: “Ẹ maa wadii araayin, bi ẹyin bá wà ninu igbagbọ; ẹ maa dán araayin wò.” (2 Korinti 13:5) Iwọ ha ti ṣayẹwo araàrẹ lati rí i bi o bá ti ń dagba nipa tẹmi lati ìgbà iribọmi rẹ bi? Tabi iwọ ha ṣì duro gbagidi ni? Bi o ti wu ki o ri, bawo, ni ẹnikan ṣe lè sọ?

‘Awọn Ìwà Èwe’

7. Fun ilọsiwaju tẹmi lati farahan, ki ni a gbọdọ ṣe?

7 “Nigba ti mo wà ni èwe, emi a maa sọrọ bi èwe, emi a maa moye bi èwe, emi a maa gbèrò bi èwe; ṣugbọn nigba ti mo di ọkunrin tán, mo fi ìwà èwe silẹ,” ni aposteli Paulu sọ. (1 Korinti 13:11) Ninu idagbasoke tẹmi, ni akoko kan gbogbo wa ni a dabi awọn ọmọde ninu ironu ati ìṣarasíhùwà wa. Bi o ti wu ki o ri, fun ilọsiwaju lati di eyi ti o farahan, a gbọdọ pa “ìwà èwe” tì, gẹgẹ bi Paulu ti sọ. Ki ni diẹ lara awọn ìwà èwe wọnyi?

8. Ni ibamu pẹlu awọn ọ̀rọ̀ Paulu ni Heberu 5:13, 14, ki ni ìwà èwe nipa tẹmi kan?

8 Lakọọkọ, ṣakiyesi awọn ọ̀rọ̀ Paulu ni Heberu 5:13, 14: “Olukuluku ẹni ti ń mu wàrà jẹ́ alailoye ọ̀rọ̀ ododo: nitori ọmọ ọwọ́ ni. Ṣugbọn ounjẹ lile ni fun awọn ti ó dagba, awọn ẹni nipa iriri, ti wọn ń lo ọgbọ́n wọn lati fi iyatọ saaarin rere ati buburu.” Iwọ ha ‘loye ọ̀rọ̀ ododo bi’? Iwọ ha mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, daradara tó lati tootun nipa lilo o lati “fi iyatọ saaarin rere ati buburu”? Paulu sọ pe awọn eniyan ti wọn dagbadenu lè ṣe bẹẹ nitori pe wọn ń jẹ “ounjẹ lile” deedee. Nipa bayii, ìfẹ́-ọkàn ẹnikan tabi òòfà rẹ̀ fun ounjẹ lile tẹmi jẹ́ àmì rere ti yala ẹnikan ti dagbasoke nipa tẹmi tabi ó ṣì wà ni èwe tẹmi.

9. Bawo ni òòfà ẹnikan fun ounjẹ tẹmi ṣe jẹ́ àmì itẹsiwaju ẹni naa nipa tẹmi?

9 Bawo, nigba naa, ni òòfà rẹ fun ounjẹ tẹmi ti ri? Oju wo ni o fi ń wo ọpọ yanturu ipese ounjẹ tẹmi ti Jehofa ń pese deedee nipasẹ awọn itẹjade ti a gbekari Bibeli ati awọn ipade Kristian ati apejọ? (Isaiah 65:13) Kò sí iyemeji pe iwọ maa ń layọ gidigidi bi a bá mu itẹjade titun kan jade ni awọn apejọpọ agbegbe ọdọọdun. Ṣugbọn ki ni o ń fi wọn ṣe gbàrà ti o bá ti dé ile? Ki ni o ń ṣe nigba ti itẹjade titun ti iwe irohin Ilé-Ìṣọ́nà tabi Ji! ba dé? Iwọ ha ń wá asiko lati ka awọn itẹjade wọnyi, tabi iwọ ha wulẹ ń ṣí wọn fàràfàrà lati wo awọn kókó itẹnumọ ki o sì fi wọn kún awọn yooku ninu pẹpẹ-ìwé rẹ ni bi? Iru awọn ibeere ti o jọ eyi ni a lè gbé dide nipa awọn ipade Kristian. Iwọ ha ń pesẹ si gbogbo awọn ipade bi? Iwọ ha ń murasilẹ ti o sì ń kópa ninu wọn bi? Lọna ti o hàn gbangba awọn kan ń ṣubu sinu àṣà aijẹun daradara tẹmi, ni kikawe gààràgà ati fifi ikanju kawe, gẹgẹ bi o ti rí. Ó ti yatọ si ti olorin naa tó, ẹni ti o sọ pe: “Emi ti fẹ́ ofin rẹ tó! Iṣaro mi ni ni ọjọ gbogbo.” Siwaju sii, Ọba Dafidi sọ pe: “Emi o ṣọpẹ́ fun ọ ninu ajọ ńlá: emi o maa yin ọ ni awujọ ọpọ eniyan.” (Orin Dafidi 35:18; 119:97) Ni kedere, ìwọ̀n ti a mọriri awọn ipese tẹmi dé jẹ́ àmì itọka kan nipa itẹsiwaju wa tẹmi.

10. Ìwà èwe tẹmi wo ni a fihàn ni Efesu 4:14?

10 Paulu ṣalaye ìwà miiran kan ti o jẹ ti èwe nipa tẹmi nigba ti o kilọ pe: “Ki awa ki o maṣe jẹ́ èwe mọ́, ti a ń fi gbogbo afẹfẹ ẹ̀kọ́ tì siwa tì sẹhin, ti a sì fi ń gbá kiri, nipa itanjẹ eniyan, nipa arekereke fun ọgbọnkọgbọn ati muni ṣina.” (Efesu 4:14) Gẹgẹ bi awọn òbí ti mọ̀ daradara, awọn ọmọde lẹmii itọpinpin nipa ohun gbogbo. Ni ọ̀nà kan eyi jẹ́ ìwà agbéniró kan nitori pe ó mu ki o ṣeeṣe fun wọn lati wá kiri ki wọn sì kẹkọọ ki wọn sì dagba di gende ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, ewu naa wà ninu dídi awọn ẹni ti a fi tirọruntirọrun pínníyà nipasẹ ohun kan lẹhin omiran. Ohun ti ó buru ju ni pe, nitori aini iriri, ìfẹ́ ìtọpinpin yii maa ń sìn wọn lọ sinu ijangbọn ńláǹlà niye ìgbà, ti wọn tilẹ ń wu araawọn ati awọn ẹlomiran lewu paapaa. Bi ọ̀ràn ti rí pẹlu nipa awọn èwe tẹmi niyii.

11. (a) Ki ni Paulu ni lọ́kàn ni lilo ede isọrọ naa “gbogbo afẹfẹ ẹ̀kọ́”? (b) ‘Afẹfẹ’ wo ni o dojukọ wá lonii?

11 Bi o ti wu ki o ri, ki ni Paulu ní lọkan nigba ti o sọ pe awọn èwe tẹmi ni a ń gbá kiri nipasẹ “gbogbo afẹfẹ ẹ̀kọ́”? Nihin-in, “afẹfẹ” ni a tumọ lati inu ọ̀rọ̀ Griki naa aʹne·mos, nipa eyi ti iwe International Critical Commentary ṣakiyesi pe ó hàn gbangba pe a “yàn án gẹgẹ bi eyi ti o ṣe wẹku fun èrò yiyipada.” Eyi ni a ṣakawe rẹ̀ daradara nipa awọn ọ̀rọ̀ Paulu ti o tẹle e, “nipa itanjẹ eniyan.” Ọ̀rọ̀ naa “itanjẹ” ni èdè ipilẹṣẹ tumọsi “ọmọ-ayò” tabi “títa ọmọ-ayò,” iyẹn ni pe, ayo kan ti a ń fi èèṣì jẹ́. Kókó naa ni pe a ń dojukọ wa lemọlemọ pẹlu awọn èrò ati ilepa titun ti o jọbi eyi ti kò lè panilara, ti ń fanimọra, ani ti o níláárí paapaa. Awọn ọ̀rọ̀ Paulu nii ṣe ní pataki julọ pẹlu awọn ọ̀ràn ti o tan mọ igbagbọ wa—awujọ idasilẹ ti ń gbé iṣọkan laaarin awọn ṣọọṣi ga siwaju, awọn ilana ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ati oṣelu, ati iru bẹẹ. (Fiwe 1 Johannu 4:1.) Ṣugbọn ilana naa tun jẹ́ otitọ sibẹ niti awọn àṣà ṣẹ̀ṣẹ̀dé ati àṣà ti ó lòde ti ayé—ọ̀nà ìgbàṣe àṣà ìgbàlódé, ere inaju, ounjẹ, ilera tabi eré idaraya, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Nitori aini iriri ati iṣediyele rere, èwe tẹmi ni iru awọn nǹkan bẹẹ lè pínníyà kọja àyè oun ni a sì lè dilọwọ kuro ninu nini ilọsiwaju tẹmi ati mimu awọn iṣẹ aigbọdọmaṣe Kristian rẹ̀ ti o tubọ ṣe pataki ṣẹ.—Matteu 6:22-25.

12. Bawo ni awọn ọmọde ṣe yatọ si awọn agbalagba nipa ẹrù-iṣẹ́?

12 Ìwà awọn ọdọmọde miiran ni iranlọwọ ati afiyesi tí wọn nilo lemọlemọ. Wọn kò mọ̀ tabi daniyan nipa awọn ẹrù-iṣẹ́ wọn; ìgbà ọmọde ni akoko igbesi-aye nigba ti ó fẹrẹẹ jẹ́ pe ohun gbogbo ni ṣereṣere ati idaraya. Gẹgẹ bi Paulu ṣe sọ ọ́, wọn ‘sọrọ bi èwe, moye bi èwe, gbèrò bi èwe.’ Wọn ṣàdéédé gbà pe awọn miiran yoo bojuto wọn. Ohun kan naa ni a lè sọ nipa èwe tẹmi. Nigba ti ẹni titun kan bá ń sọ ọ̀rọ̀ asọye Bibeli rẹ̀ akọkọ tabi kọkọ bẹrẹ ninu iṣẹ-ojiṣẹ pápá, obi tẹmi ni inu rẹ̀ dùn lati ṣe ohun gbogbo lati ṣeranlọwọ. Ki ni ń ṣẹlẹ bi ẹni titun naa bá ń baa lọ lati gbarale iru iranlọwọ bẹẹ ti kò sì fẹri itootun lati tẹwọgba ẹrù-iṣẹ́ ti bibojuto araarẹ̀ hàn? Ni kedere iyẹn yoo jẹ́ àmì aláìníkan-án-ṣe.

13. Eeṣe ti ẹnikọọkan fi gbọdọ kẹkọọ lati gbé ẹrù araarẹ?

13 Ni ọ̀nà yii ranti ọ̀rọ̀ iyanju aposteli Paulu pe bi o tilẹ jẹ pe a gbọdọ “maa ru ẹrù ọmọnikeji,” sibẹ “olukuluku ni yoo ru ẹrù ti araarẹ̀.” (Galatia 6:2, 5) Dajudaju, ó gba akoko ati isapa fun ẹnikan lati kẹkọọ lati lè gbé awọn ẹrù-iṣẹ́ Kristian ti o jẹ tirẹ, ó sì lè tumọsi ṣiṣe awọn irubọ ni awọn agbegbe kan. Bi o ti wu ki o ri, yoo jẹ́ aṣiṣe wiwuwo lati yọnda ara-ẹni lati di ẹni ti ó kowọnu igbadun ati eré igbesi-aye, wọn ìbáà jẹ́ eré inaju, irin-ajo igbafẹ, àfikún ohun ìní, tabi ilepa ti kò pọndandan fun ounjẹ oojọ paapaa, ti oluwarẹ yoo sì wulẹ wá dabi onworan kan lasan, ki a sọ ọ lọna bẹẹ, laisi ìfẹ́-ọkàn lati mú ipin ẹni ninu iṣẹ sisọni di ọmọ-ẹhin pọ sii tabi lati naga fun ilọsiwaju ati ẹrù-iṣẹ́ tẹmi. “Ki ẹ jẹ́ oluṣe ọ̀rọ̀ naa, ki o ma sì ṣe olugbọ nikan, ki ẹ maa tan araayin jẹ,” ni ọmọ-ẹhin Jakọbu rọni.—Jakọbu 1:22; 1 Korinti 16:13.

14. Eeṣe ti a kò fi nilati nitẹẹlọrun pẹlu fifi ìwà èwe tẹmi hàn?

14 Bẹẹni, ọpọlọpọ ìwà ti o rọrun lati foyemọ ti ń fi ọmọde kan hàn yatọ si agbalagba ni o wà. Bi o ti wu ki o ri, ohun pataki naa, gẹgẹ bi Paulu ti sọ ọ́, ni pe a ń fi awọn ìwà èwe silẹ ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ a sì ń dagbasoke. (1 Korinti 13:11; 14:20) Bi kìí bá ṣe bẹẹ, a lè di ẹni ti a dilọwọ ni èrò itumọ tẹmi. Ṣugbọn bawo ni ẹnikan ṣe ń ní itẹsiwaju? Ki ni ó wémọ́ mimu kí ìdagba di gende nipa tẹmi maa baa niṣo laidawọduro?

Bi Ilọsiwaju Ṣe Ń Farahàn

15. Ki ni awọn igbesẹ ipilẹ ninu ọ̀nà ìgbàdàgbàsókè?

15 Ó dara, bawo ni idagbasoke ṣe ń wáyé ninu ayé adanida? “Olukuluku ẹnikọọkan bẹrẹ igbesi-aye gẹgẹ bi ẹyọ sẹẹli kanṣoṣo,” ni The World Book Encyclopedia ṣalaye. “Sẹẹli naa gba awọn ohun eelo ó sì yi wọn pada si bulọọku ikọle ti o nilo lati dagba. Nipa bayii, ẹyọ sẹẹli kanṣoṣo naa ń dagba lati inu wá. Sẹẹli yii ni a lè sọ di pupọ ki a sì pín lati di iru sẹẹli miiran. Ìṣiṣẹ́ ikọle, isọdipupọ, ati pípín ni idagbasoke.” Kókó ti o yẹ fun akiyesi nihin-in ni pe idagbasoke ń wáyé lati inu wá. Nigba ti a bá gba ounjẹ aṣaraloore sinu, ti a sọ ọ́ di apakan ara, ti ara sì lò ó, o ń yọrisi idagbasoke. Eyi ni a ri kedere ninu ọ̀ràn ọmọ-ọwọ kan ti a ṣẹṣẹ bi. Gẹgẹ bi a ti mọ, ọmọ titun kan ti a ṣẹṣẹ bí ń gba ipese ti o ṣe deedee ti ounjẹ ti a ṣe lọna akanṣe, wàrà, eyi ti ó dọ́ṣọ̀ fun ọ̀rá ati eroja ounjẹ amunidagbasoke, awọn eroja ti a nilo fun idagbasoke. Ki ni iyọrisi rẹ̀? Iwọn idagbasoke niti lílómilára ati giga ti ọmọ kan ń gbadun ni ọdun akọkọ ni kò lẹgbẹ ni ọdun idagbasoke deedee eyikeyii miiran fun iyooku igbesi-aye rẹ̀.

16. Iru idagbasoke wo ni a rí ninu ọpọ julọ awọn akẹkọọ Bibeli titun, bawo sì ni a ṣe mu ki iyẹn ṣeeṣe?

16 Ohun pupọ wà ti a kẹkọọ rẹ̀ lati inu ọ̀nà ìgbàdàgbàsókè ti o bá iwa ẹ̀dá mu yii ti a lè mú bá itẹsiwaju wa tẹmi mu lati ipilẹ dé idagba di gende. Lakọọkọ ná, itolẹsẹẹsẹ ounjẹ jijẹ ti ń baa lọ pọndandan. Ronu pada sẹhin si ìgbà ti o ṣẹṣẹ bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli. Bi o bá dabi ọpọ julọ awọn miiran, boya iwọ kò mọ ohunkohun páàpáà nipa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ṣugbọn bi ọ̀sẹ̀ ti ń gori ọ̀sẹ̀ iwọ ń mura awọn ẹ̀kọ rẹ silẹ o sì ń ṣe ikẹkọọ Bibeli rẹ, ati ni akoko ti o kuru ni ifiwera, iwọ wá loye gbogbo awọn ẹ̀kọ́ ipilẹ nipa Iwe Mimọ. Iwọ gbọdọ gba pe, idagbasoke ti o jẹ́ àrà méríìyìírí ni iyẹn jẹ́, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ nitori jijẹun ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun deedee!

17. Eeṣe ti itolẹsẹẹsẹ ounjẹ jijẹ tẹmi fi jẹ́ kò-ṣeé-má-ṣe?

17 Bi o ti wu ki o ri, ki ni nipa ti isinsinyi? Iwọ ha ṣì ń tẹle itolẹsẹẹsẹ ounjẹ jíjẹ deedee bi? Ẹnikan kò gbọdọ ronu lae pe nitori pe oun ti ṣe iribọmi, kò sí idi eyikeyii mọ́ fun ikẹkọọ deedee ti a ṣe ni ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé lati gba ounjẹ aṣaraloore nipa tẹmi sinu. Ani bi o tilẹ jẹ pe Timoteu jẹ́ Kristian alaboojuto kan ti o dagbadenu, Paulu rọ̀ ọ́ pe: “Maa fiyesi nǹkan wọnyi; fi araarẹ fun wọn patapata; ki ilọsiwaju rẹ ki o lè hàn gbangba fun gbogbo eniyan.” (1 Timoteu 4:15) Meloomeloo ni ó wa yẹ ki ẹnikọọkan ninu wa ṣe bẹẹ tó! Bi o bá nifẹẹ ninu jijẹki ilọsiwaju tẹmi rẹ farahan, iru awọn isapa bẹẹ jẹ́ kò-ṣeé-má-ṣe.

18. Bawo ni ilọsiwaju tẹmi ẹnikan ṣe ń di eyi ti o farahan?

18 Jijẹki ilọsiwaju ẹni di eyi ti o farahan kò tumọsi ṣiṣe isapa akanṣe lati ṣe ṣekárími ohun ti ẹnikan mọ̀ tabi gbiyanju lati wú awọn ẹlomiran lori. Jesu sọ pe: “Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ilu ti a tẹ̀dó lori òkè kò lè farasin” ati pe, “ninu ọpọlọpọ ohun inu ni ẹnu isọ.” (Matteu 5:14; 12:34) Nigba ti ọkan-aya ati ero-inu wa bá kún fun awọn ohun rere ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, a ko lè pa á mọra bikoṣe pe ki a fi eyi hàn ninu ohun ti a ń ṣe tí a sì ń sọ.

19. Ki ni a gbọdọ pinnu lati ṣe nipa itẹsiwaju tẹmi wa, ni ifojusọna fun iyọrisi wo sì ni?

19 Fun idi yii, ibeere naa ni pe: Iwọ ha ń kẹkọọ Bibeli deedee ti o sì ń lọ si awọn ipade Kristian lati gba akojọpọ ọrọ aṣaraloore ti ó lè ru idagbasoke tẹmi rẹ ti inu lọhun-un soke bi? Maṣe ni itẹlọrun pẹlu jijẹ onworan alaibikita nigba ti o bá kan ọ̀ràn idagbasoke tẹmi. Gbé igbesẹ pàtó lati ri i daju pe iwọ ń lo ọpọ yanturu ounjẹ tẹmi tí Jehofa ń pese. Bi iwọ bá jẹ́ ẹnikan ti ‘inudidun rẹ̀ wà ninu ofin Jehofa, ati ninu ofin rẹ̀ ni o ń kà jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ lọsan-an ati loru,’ nigba naa a tún lè sọ nipa rẹ pe: “Yoo sì dabi igi ti a gbin si eti ipa odò, ti ń so eso rẹ̀ jade ni akoko rẹ̀; ewé rẹ̀ ki yoo sì rẹ̀; ati ohunkohun ti o ṣe ni yoo maa ṣe deedee.” (Orin Dafidi 1:2, 3) Bi o ti wu ki o ri, ki ni a lè ṣe lati ri i daju pe iwọ yoo maa baa lọ lati ní ilọsiwaju tẹmi? Eyi ni a o jiroro ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e.

Iwọ Ha Lè Dahun Bi?

◻ Eeṣe ti o fi bọ́ sí akoko fun wa lati kiyesi ilọsiwaju tẹmi wa?

◻ Bawo ni idagbasoke tẹmi ṣe tanmọ òòfà fun ounjẹ tẹmi?

◻ Ki ni “gbogbo afẹfẹ ẹ̀kọ́” tumọsi?

◻ Eeṣe ti olukuluku fi nilati gbé ẹrù araarẹ̀?

◻ Bawo ni ọwọ́ ṣe ń tẹ ilọsiwaju tẹmi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Iwọ ha ń wá akoko lati ka awọn itẹjade ti a gbekari Bibeli bi?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́