Ṣọọṣi Ijimiji Ha Kọni Pe Ọlọrun Jẹ Mẹtalọkan Bi?
Apa 4—Nigba Wo Ati Bawo ni Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Ṣe Gbèrú?
Awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ mẹta akọkọ ninu ọ̀wọ́ yii fihàn pe ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ni Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tabi awọn Òǹkọ̀wé Ṣọọṣi kò fi kọni. (Ilé-Ìṣọ́nà ti November 1, 1991; February 1, 1992; ati April 1, 1992) Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ti o kẹhin yii yoo jiroro bi ẹ̀kọ́ gbàbẹ́ẹ̀ laijanpata ti Mẹtalọkan ṣe gbèrú ati ipa ti Igbimọ Nicaea kó ni 325 C.E.
NI ỌDUN 325 C.E., olu-ọba Romu Constantine pe apejọ kan ti igbimọ awọn biṣọọbu ni ilu-nla ti Nicaea ni Asia Kekere. Ète rẹ̀ ni lati pari edekoyede ti isin ti ń baa lọ lori ipo ibatan Ọmọkunrin Ọlọrun pẹlu Ọlọrun Olodumare. Nipa awọn iyọrisi igbimọ yẹn, iwe Encyclopædia Britannica sọ pe:
“Constantine fúnraarẹ̀ ni o ṣalaga, ní fifi aapọn ṣamọna awọn ijiroro naa, ti oun fúnraarẹ̀ sì dábàá . . . ilana pataki tí ń ṣalaye ibatan Kristi pẹlu Ọlọrun ninu ìjẹ́wọ́ igbagbọ tí ajọ igbimọ naa tẹjade, ‘nipa jíjẹ́ ọ̀kan-náà [ho·mo·ouʹsi·os] pẹlu Baba.’ . . . Awọn biṣọọbu naa ti olu-ọba naa ti mú ní ìbẹ̀rù jinnijinni ti o kọja ààlà, fọwọsi ìjẹ́wọ́ igbagbọ naa àfi kìkì meji ninu wọn, eyi ti o pọju ninu wọn sì ṣe bẹẹ lodisi ìtẹ̀sí ọkan wọn.”1
Oluṣakoso alaigbagbọ yii ha dásí i nitori awọn idaniloju rẹ̀ nipa Bibeli bi? Bẹẹkọ. A Short History of Christian Doctrine sọ pe: “Niti tootọ Constantine kò lóye ohunkohun lara awọn ibeere ti a ń beere ninu ẹkọ-isin Griki.”2 Ohun ti o loye ni pe edekoyede ti isin halẹ̀mọ́ iṣọkan ilẹ-ọba rẹ̀, ó sì fẹ́ ki wọn di pipari.
Ó Ha Fidii Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Mulẹ Bi?
Igbimọ ti Nicaea ha fidii Mẹtalọkan mulẹ, tabi jẹrii sii, gẹgẹ bi ẹ̀kọ́ isin Kristẹndọm bi? Ọpọlọpọ tànmọ́-ọ̀n pe bẹẹ ni ọ̀ràn rí. Ṣugbọn awọn otitọ fi odikeji hàn.
Niti gidi ni ìjẹ́wọ́ igbagbọ tí igbimọ yẹn kede ní gbangba tẹnumọ awọn nǹkan kan nipa Ọmọkunrin Ọlọrun ti yoo yọnda fun oniruuru awọn awujọ alufaa ṣọọṣi lati wò ó gẹgẹ bi ọgba pẹlu Ọlọrun Baba ni ọ̀nà kan. Sibẹ, ó ń lani loye lati ri ohun ti Ìjẹ́wọ́ igbagbọ ti Nicaea kò sọ. Gẹgẹ bi a ti tẹ̀ ẹ́ jade ni ipilẹṣẹ, gbogbo ìjẹ́wọ́ igbagbọ naa sọ pe:
“A gbagbọ ninu Ọlọrun kan, Baba olodumare, ẹlẹdaa ohun gbogbo ti o ṣee fojuri ati eyi ti kò ṣee fojuri;
“Ati ninu Oluwa kan Jesu Kristi, Ọmọkunrin Ọlọrun, ti a bí lati ọdọ Baba, bíbí-kanṣoṣo, iyẹn ni, lati inu ara ti Baba wá, Ọlọrun lati ọdọ Ọlọrun, ìmọ́lẹ̀ lati inu ìmọ́lẹ̀, Ọlọrun otitọ lati inu Ọlọrun otitọ, ti a bí ti a kò ṣe, ti ó jẹ́ ọ̀kan-náà pẹlu Baba, nipasẹ Ẹni ti ohun gbogbo di wíwà, awọn ohun ti ń bẹ ni ọrun ati awọn ohun ti ń bẹ lori ilẹ̀-ayé, Ẹni ti o tori awa eniyan ati tori igbala wa sọkalẹ wa ti o sì di amárawọ̀, ni didi eniyan, ó jiya ó sì dide lẹẹkan sii ni ọjọ kẹta, ó goke re awọn ọ̀run, yoo sì wá ṣedajọ alààyè ati òkú;
“Ati ninu Ẹmi Mímọ́.”3
Ǹjẹ́ ìjẹ́wọ́ igbagbọ yii sọ pe Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́ jẹ́ ẹni mẹta ninu Ọlọrun kan bi? Ó ha sọ pe awọn mẹtẹẹta jẹ́ ọgba ni ayeraye, agbara, ipo, ati ọgbọ́n bi? Bẹẹkọ, kò sọ bẹẹ. Kò sí ilana mẹta-ninu-ọkan nihin-in bi o ti wu ki o mọ. Ìjẹ́wọ́ igbagbọ ti Nicaea ipilẹṣẹ kò fidii Mẹtalọkan mulẹ tabi jẹrii sii pe otitọ ni.
Ìjẹ́wọ́ igbagbọ yẹn, kò ṣe ju pe ó ka Ọmọkunrin si ọgba pẹlu Baba ni jíjẹ́ “ọ̀kan-náà.” Ṣugbọn kò sọ ohunkohun bi iyẹn nipa ẹmi mímọ́. Gbogbo ohun ti o sọ ni pe “a gbagbọ . . . ninu Ẹmi Mímọ́.” Iyẹn kọ́ ni ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ti Kristẹndọm.
Àní àpólà-ọ̀rọ̀ pataki naa “jẹ́ ọkan-náà” (ho·mo·ouʹsi·os) kò fi dandan tumọsi pe igbimọ naa gbagbọ ninu idọgba ti Baba ati Ọmọkunrin niti kíkà. Iwe New Catholic Encyclopedia sọ pe:
“Yala Igbimọ naa fẹ́ lati sọ pe otitọ ni ìdámọ̀ ìjọ́kan-náà Baba ati Ọmọkunrin niti kíkà kún fun iyemeji.”4
Bi o bá ti jẹ́ pe ohun ti igbimọ naa nílọ́kàn ni pe Ọmọkunrin ati Baba jẹ́ ọ̀kan niti kíkà ni, kì yoo jẹ́ Mẹtalọkan sibẹ. Kìkì pe yoo jẹ́ Ọlọrun meji-ninu-ọ̀kan, kì í ṣe mẹta-ninu-ọ̀kan gẹgẹ bi ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ti beere fun.
“Oju-iwoye Awọn Kéréje”
Ni Nicaea, ǹjẹ́ awọn biṣọọbu ni gbogbogboo ha gbagbọ pe Ọmọkunrin baradọgba pẹlu Ọlọrun bi? Bẹẹkọ, awọn kókó oju-iwoye ti ń fagagbaga wà. Fun apẹẹrẹ, ọ̀kan ni a ṣoju fun nipasẹ Arius, ẹni ti o kọni pe Ọmọkunrin ní ibẹrẹ ti o ṣe pàtó ni akoko ati nitori naa kò dọgba pẹlu Ọlọrun ṣugbọn ó jẹ́ ọmọ-abẹ ni gbogbo ọ̀nà. Athanasius, ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, gbagbọ pe Ọmọkunrin dọgba pẹlu Ọlọrun ni ọ̀nà kan. Awọn oju-iwoye miiran sì wà.
Nipa ipinnu igbimọ naa lati ka Ọmọkunrin si ọ̀kan-náà (ohun kan-naa) gẹgẹ bi Ọlọrun, Martin Marty sọ pe: “Nicaea niti gidi ṣoju fun oju-iwoye kéréje kan; ìyanjú naa kò rọrùn kò sì nitẹẹwọgba fun ọpọlọpọ ti wọn kì í ṣe oloju-iwoye Arius.”5 Bakan-naa, iwe naa A Select Library of Nicene and Post-Nicene Fathers of the Christian Church sọ pe “ipo ẹ̀kọ́ ti a lana lọna ti o ṣe kedere ni iyatọ ifiwera si ti ẹ̀kọ́ Arius ni kìkì awọn kéréje dimu, bi o tilẹ jẹ́ pe awọn kéréje yii ṣaṣeyọri ninu mimu èrò ọkàn wọn ṣẹ.”6 Iwe naa A Short History of Christian Doctrine sì sọ pe:
“Ohun ti ó jọ eyi ti o ṣee takò ní pataki fun ọpọlọpọ biṣọọbu ati awọn ẹlẹkọọ-isin Ila-oorun ni èrò ti a gbewọnu ìjẹ́wọ́ igbagbọ naa nipasẹ Constantine fúnraarẹ̀, ho·mo·ouʹsi·os [“ti jíjẹ́ ọ̀kan-náà”], eyi ti o di kókó ìyapa ninu rogbodiyan ti o jẹyọ tẹle e laaarin igbagbọ orthodox ati ti àdámọ̀.”7
Lẹhin igbimọ naa, edekoyede ń baa lọ fun ọpọ ẹwadun. Awọn wọnni ti wọn kín èrò naa lẹhin nipa mimu Ọmọkunrin dọgba pẹlu Ọlọrun Olodumare tilẹ di alaigbajumọ fun akoko kan. Fun apẹẹrẹ, Martin Marty sọ nipa Athanasius pe: “Òkìkí rẹ̀ kàn ó sì rọlẹ̀ a sì lé e lọ sí igbekun leralera tobẹẹ [ni awọn ọdun lẹhin igbimọ naa] debi pe o fẹrẹẹ di arinrin-ajo deedee kan.”8 Athanasius lo ọpọ ọdun ni igbekun nitori pe awọn ijoye oṣiṣẹ oṣelu ati ti ṣọọṣi lodisi oju-iwoye rẹ̀ ti o mú Ọmọkunrin baradọgba pẹlu Ọlọrun.
Nitori naa lati fi itẹnumọ kede pe Igbimọ ti Nicaea ni 325 C.E. fidii ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan mulẹ tabi sọ pe ó jẹrii sii kì í ṣe otitọ. Ohun ti o di ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan lẹhin naa kò sí ni akoko yẹn. Èrò naa pe Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mímọ́ jẹ́ Ọlọrun otitọ lọkọọkan ati ọgba ni ayeraye, agbara, ipo, ati ọgbọ́n, sibẹ ti wọn jẹ́ Ọlọrun kanṣoṣo—Ọlọrun mẹta-ninu-ọ̀kan—ni a kò mú gbèrú nipasẹ igbimọ yẹn tabi nipasẹ awọn Òǹkọ̀wé Ṣọọṣi ṣaaju ìgbà naa. Gẹgẹ bi iwe The Church of the First Three Centuries ṣe sọ:
“Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ti igbalode ti o jẹ́ olokiki . . . kò rí itilẹhin lati inu awọn èdè isọrọ Justin [Martyr]: akiyesi yii ni a sì lè nasẹ̀ rẹ̀ dé ọdọ gbogbo awọn Òǹkọ̀wé ṣaaju Igbimọ Nicaea; iyẹn ni pe, dé ọdọ gbogbo awọn òǹkọ̀wé Kristian fun ọrundun mẹta lẹhin ìbí Kristi. Otitọ ni pe, wọn sọrọ nipa Baba, Ọmọkunrin, ati Ẹmi alasọtẹlẹ tabi Ẹmi mímọ́, ṣugbọn kì í ṣe gẹgẹ bi alabaadọgba, kì í ṣe gẹgẹ bii pé ọ̀kan ti inú ekeji wa, kì í ṣe bii Mẹta ninu Ọ̀kan, ni èrò itumọ eyikeyii ti awọn Onigbagbọ Mẹtalọkan gbà nisinsinyi. Odikeji patapata ni otitọ naa. Ẹ̀kọ́ isin Mẹtalọkan, gẹgẹ bi awọn Òǹkọ̀wé wọnyi ti ṣalaye rẹ̀, yatọ niti gidi si ẹ̀kọ́ ode-oni. Eyi ni a sọ gẹgẹ bi otitọ ti a lè fi ẹ̀rí yẹwo gẹgẹ bi otitọ eyikeyii ninu ìtàn èrò eniyan.”
“A pe ẹnikẹni nija lati pese òǹkọ̀wé kanṣoṣo ti o toyeyẹ, ni akoko ọrundun mẹta akọkọ, ti ó gba ẹ̀kọ́ [Mẹtalọkan] yii gbọ́ ni èrò itumọ ti ode-oni.”9
Bi o ti wu ki o ri, Nicaea, ṣoju fun kókó iyipada nitootọ. O ṣí ọ̀nà silẹ fun itẹwọgba ti a faṣẹ si nipa Ọmọkunrin gẹgẹ bi ọgba pẹlu Baba, iyẹn sì la ọ̀nà silẹ fun èrò Mẹtalọkan ẹhin ìgbà naa. Iwe naa Second Century Orthodoxy, lati ọwọ́ J. A. Buckley, sọ pe:
“Titi di opin ọrundun keji ó keretan, Ṣọọṣi kari-aye wà ni iṣọkan ni èrò itumọ ipilẹ kan; gbogbo wọn gbagbọ ninu ipo-ajulọ ti Baba. Gbogbo wọn ka Ọlọrun Baba Olodumare si oun nikan ti o ni ipo-ajulọ, alaileyipada, atóbimáṣeéfẹnusọ ati alaini ibẹrẹ. . . .
“Pẹlu ikọjalọ awọn òǹkọ̀wé ọrundun keji ati awọn aṣaaju wọnni, Ṣọọsi naa rí araarẹ . . . ti ń yọ̀ tẹ̀rẹ́ diẹdiẹ ṣugbọn lọna ti ń baa lọ laidawọ duro siha kókó yẹn . . . nibi ti a ti dé opin gbogbo ìyìnrìn diẹdiẹ ti igbagbọ ipilẹsẹ yii ni Igbimọ Nicaea. Nibẹ ni iwọnba kéréje ti wọn lè dá rogbodiyan silẹ kan, ti fipa mu ọpọ eniyan agbàláìjanpata lati gba àdámọ̀ wọn, ati pẹlu awọn ọla-aṣẹ oṣelu ti o wà lẹhin rẹ̀, ó fi dandan mú, fi ẹ̀tàn mú, ti o sì dáyàfo awọn wọnni ti wọn lakaka lati pa ìmọ́gaara ipilẹsẹ igbagbọ wọn ti kò labawọn mọ́.”10
Igbimọ ti Constantinople
Ni 381 C.E., Igbimọ ti Constantinople jẹrii sii pe otitọ ni Ìjẹ́wọ́ igbagbọ ti Nicaea. Ó sì fi ohun miiran kan kun un. Ó pe ẹmi mimọ ni “Oluwa” ati “olùfúnni-ní-ìyè.” Ìjẹ́wọ́ igbagbọ ti a mú gbooro ti 381 C.E. (eyi ti o jẹ́ ohun ti a ń lò gidigidi ninu awọn ṣọọṣi lonii eyi ti a sì ń pe ni “Ìjẹ́wọ́ igbagbọ ti Nicaea”) fihàn pe Kristẹndọm wà ni bèbè lilana ẹ̀kọ́ gbàbẹ́ẹ̀-láìjanpata ti Mẹtalọkan ti o ti gbèrú gan-an. Sibẹ, kì í tilẹ ṣe igbimọ yii ni o pari ẹ̀kọ́ yẹn. Iwe New Catholic Encyclopedia gbà pe:
“Ó fanilọkan mọra pe 60 ọdun lẹhin Nicaea I Igbimọ ti Constantinople I [381 C.E.] yẹra fun homoousios [jíjẹ́ ọ̀kan-náà] ninu itumọ rẹ nipa jíjẹ́ Ọlọrun ti Ẹmi Mímọ́.”11
“Awọn ọmọwe ni a ti dà laamu nipasẹ ohun ti o farajọ ọ̀rọ̀ pẹlẹ ni ipa ti ìjẹ́wọ́ yii; ikuna rẹ̀, fun apẹẹrẹ, lati lo ọ̀rọ̀ naa homoousios [jíjẹ́ ọ̀kan-náà] ti Ẹmi Mímọ́ gẹgẹ bii alájọwà pẹlu Ọlọrun ati Ọmọkunrin.”12
Iwe gbédègbẹ́yọ̀ kan-naa yẹn gbà pe: “Homoousios [Jíjẹ́ ọ̀kan-náà] kò farahan ninu Iwe Mimọ.”13 Bẹẹkọ, Bibeli kò lo ọ̀rọ̀ naa yala fun ẹmi mimọ tabi fun Ọmọkunrin gẹgẹ bi ẹni ti o jẹ́ ọ̀kan-náà pẹlu Ọlọrun. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ti kò bá Bibeli mu ti o ṣeranwọ lati jalẹ si ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ti kò ba Bibeli mu, nitootọ, ti o jẹ́ òdì si Bibeli.
Àní lẹhin Constantinople paapaa, ó si gba ọpọ ọrundun ṣaaju ki ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan tó di eyi ti a tẹwọgba jakejado Kristẹndọm. Iwe New Catholic Encyclopedia sọ pe: “Ni Iwọ-oorun . . . idakẹjẹẹ gbogbogboo jọbii pe o ti bori niti Constantinople I ati ìjẹ́wọ́ igbagbọ rẹ̀.”14 Orisun yii fihàn pe ìjẹ́wọ́ igbagbọ igbimọ naa ni a kò mọ dunju lọna gbigbooro ni Iwọ-oorun titi fi di ọrundun keje tabi ikẹjọ.
Awọn ọmọwe tun gbà pe Ìjẹ́wọ́ igbagbọ Athanasius, ti a sábà maa ń ṣayọlo rẹ̀ gẹgẹ bi itumọ ọ̀pá idiwọn ati itilẹhin Mẹtalọkan, ni a kò kọ lati ọwọ Athanasius ṣugbọn lati ọwọ òǹkọ̀wé ti a kò mọ nigba ti o pẹ́ lẹhin naa. Iwe The New Encyclopædia Britannica ṣalaye pe:
“Ìjẹ́wọ́ igbagbọ naa ni a kò mọ̀ ni Ṣọọṣi Ila-oorun titi di ọrundun 12. Lati ọrundun 17, awọn ọmọwe akẹkọọjinlẹ ti fohunṣọkan pe Athanasius kọ́ ni ó kọ Ìjẹ́wọ́ igbagbọ Athanasius (o kú ni 373) ṣugbọn ó ṣeeṣe ki ó jẹ́ pe ìhà guusu France ni ọrundun 5. . . . Agbara idari ìjẹ́wọ́ igbagbọ naa dabi ẹni pe ó ti wà ni ìhà guusu France ní ipilẹṣẹ ati ni Spain ni ọrundun 6 ati 7. Wọn lò ó ninu ilana ijọsin ṣọọṣi ni Germany ni ọrundun 9 ati nigba kan lẹhin naa ni Romu.”15
Bi O Ṣe Gbèrú
Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan bẹrẹ idagbasoke diẹdiẹ rẹ̀ la sáà ọpọ ọrundun ja. Awọn èrò nipa mẹtalọkan ti awọn ẹlẹkọọ-isin Griki iru bii Plato, ẹni ti o gbé ni ọpọ ọrundun melookan ṣaaju Kristi, yọ́ wọnu awọn ẹ̀kọ́ ṣọọṣi ni kẹrẹkẹrẹ. Gẹgẹ bi The Church of the First Three Centuries ṣe sọ:
“A gbà pe ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan jẹ́ isọfunni ti o dé ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ti o sì jẹ́ ti aipẹ yii bi a ba fiwera; pe ipilẹṣẹ rẹ̀ wá lati inu orisun kan ti o ṣajoji patapata si ti Iwe Mimọ Kristian ati ti Ju; pe o dagba, a sì mú un wọnú isin Kristian, lati ọwọ́ awọn Òǹkọ̀wé Ẹlẹ́kọ̀ọ́ Plato; pe ni akoko Justin, ati tipẹtipẹ lẹhin naa, iyatọ niti ẹ̀dá ati rirẹlẹ tí Ọmọkunrin rẹlẹ ni a fi kọni nibi gbogbo; ati pe òjìji akọkọ ti ilapa-ero Mẹtalọkan ti ṣeefojuri nigba naa.”16
Ṣaaju Plato, mẹta-mẹta, tabi mẹtalọkan, wọ́pọ̀ ni Babiloni ati Egipti. Isapa awọn ọkunrin-ṣọọṣi lati fa awọn alaigbagbọ mọra ni orilẹ-ede Romu si ṣamọna si fifa diẹ lara awọn èrò wọnni wọnu isin Kristian ni kẹrẹkẹrẹ. Eyi nígbẹ̀hìn-gbẹ́hín jalẹ si titẹwọgba igbagbọ naa pe Ọmọkunrin ati ẹmi mimọ jẹ ọgba pẹlu Baba.a
Àní ọ̀rọ̀ naa “Mẹtalọkan” paapaa ni wọn wọn wulẹ tẹwọgba ni kẹrẹkẹrẹ. Ni apá ilaji keji ti ọrundun keji ni Theophilus, biṣọọbu Antioch ni Syria, kọwe ni èdè Griki ti o sì nasẹ ọ̀rọ̀ naa tri·asʹ, ti o tumọsi “mẹta-mẹta,” tabi “mẹtalọkan.” Lẹhin naa òǹkọ̀wé lédè Latin Tertullian ni Carthage, Ariwa Africa, nasẹ ọ̀rọ̀ naa trinitas, eyi ti o tumọsi “mẹtalọkan” wọnu awọn ikọwe rẹ̀.b Ṣugbọn ọ̀rọ̀ naa tri·asʹ ni a kò rí ninu Iwe Mimọ onimiisi Kristian lede Griki, ọ̀rọ̀ naa trinitas ni a kò sì rí ninu itumọ Latin ti Bibeli ti a ń pè ni Vulgate. Kò sí eyikeyii ninu ọ̀rọ̀ naa ti o bá Bibeli mu. Ṣugbọn ọ̀rọ̀ naa “Mẹtalọkan,” ti a gbekari èrò alaigbagbọ, yọ́ wọnu iwe ikẹkọọ awọn ṣọọṣi ati lẹhin ọrundun kẹrin ó di apakan ẹ̀kọ́ gbàbẹ́ẹ̀ laijanpata wọn.
Nipa bayii, kì í ṣe pe awọn ọmọwe ṣayẹwo Bibeli kúnnákúnná lati rí i bi a bá fi iru ẹ̀kọ́ bẹẹ kọni ninu rẹ̀. Kaka bẹẹ, awọn oṣelu ayé ati ti ṣọọṣi ni wọn pinnu ẹ̀kọ́ naa lọna ti o gbooro. Ninu iwe naa The Christian Tradition, onṣewe Jaroslav Pelikan pe afiyesi si “awọn kókó ti kò ba ẹ̀kọ́ isin mu ninu ariyanjiyan naa, ọpọ ninu eyi ti o dabi ẹni pe o ṣetan leralera lati pinnu abajade rẹ̀, kìkì lati di eyi ti a wọ́gi lé nipasẹ awọn ipá miiran ti o ṣe pataki bii wọn. Lọpọ ìgbà ẹ̀kọ́ isin ni o jọbi ẹni pe o maa ń jẹ́ ẹran ìjẹ fun—tabi jẹ́ imujade—oṣelu ṣọọṣi ati iforigbari animọ ìwà.”17 Ọjọgbọn E. Washburn Hopkins ti Yale sọ ọ́ ni ọ̀nà yii pe: “Itumọ mẹtalọkan tí ó kẹhin ti orthodox jẹ́ ọ̀ràn oṣelu ṣọọṣi lọna ti o gbooro.”18
Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan ti jẹ́ alaibọgbọnmu tó ni ifiwera pẹlu ẹ̀kọ́ ti kò díjú ti Bibeli pe Ọlọrun ni onipo-ajulọ ati pe kò ni ọgba! Gẹgẹ bi Ọlọrun ṣe sọ, “ta ni ẹyin o fi mi wé, ti yoo sì bá mi dọgba, ti ẹ o si fi mi jọ, ki awa lè jẹ́ ọgba?”—Isaiah 46:5.
Ohun ti Ó Duro Fun
Ki ni idagbasoke kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ti èrò Mẹtalọkan duro fun? Ó jẹ́ apakan iṣubu kuro ninu isin Kristian tootọ tí Jesu sọtẹlẹ. (Matteu 13:24-43) Aposteli Paulu ti sọtẹlẹ nipa ipẹhinda tí ń bọ̀wá naa pe:
“Ó daju pe akoko naa yoo wá nigba ti, jinna fíìfíì si nini itẹlọrun pẹlu ẹ̀kọ́ yiyekooro, awọn eniyan yoo jẹ́ onitara fun ohun ṣẹṣẹde ti wọn ó sì kó awọn olukọ jọ fun araawọn ni ibamu pẹlu ohun tí awọn funraawọn nifẹẹ sí; ati lẹhin naa, dipo fifetisilẹ si otitọ, wọn yoo yiju si ìtàn àlọ́.”—2 Timoteu 4:3, 4, Catholic Jerusalem Bible.
Ọ̀kan lara awọn ìtàn àlọ́ wọnni ni ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan. Awọn ìtàn àlọ́ diẹ miiran ti o ṣajeji si isin Kristian ti o tun gbèrú ni kẹrẹkẹrẹ ni: animọ adamọni ti aileku ọkàn eniyan, pọgatori, Limbo, ati idaloro ayeraye ninu iná ọ̀run àpáàdì.
Nitori naa, ki ni ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan? Niti gasikiya ó jẹ́ ẹ̀kọ́ abọriṣa ti ń fagọ̀ boju bi eyi ti o jẹ́ ti Kristian kan. Satani ni o ṣagbatẹru rẹ̀ lati tan awọn eniyan jẹ, lati sọ Ọlọrun di ẹni ti ń ṣe mọ̀dàrú ti o sì ṣoroo loye fun wọn. Eyi yọrisi didi ti wọn di ẹni ti o tubọ muratan lati gba awọn èrò isin èké ati awọn àṣà ti kò tọ̀nà miiran.
‘Nipa Eso Wọn’
Ni Matteu 7:15-19, Jesu sọ pe iwọ lè da isin èké mọ̀ yatọ si isin tootọ ni ọ̀nà yii:
“Ẹ maa kiyesi awọn èké wolii ti o ń tọ̀ yin wá ni àwọ̀ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikooko ni wọn ninu. Eso wọn ni ẹyin ó fi mọ̀ wọn. Eniyan a maa ká eso ajara lori ẹ̀gún ọ̀gàn, tabi eso ọpọtọ lara ẹwọn? Gẹgẹ bẹẹ gbogbo igi rere nii so eso rere; ṣugbọn igi buburu nii so eso buburu . . . Gbogbo igi ti kò bá so eso rere, a ké e lulẹ, a sì wọ́ ọ sọ sinu iná.”
Gbe apẹẹrẹ kan yẹwo. Jesu sọ ni Johannu 13:35 pe: “Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ pe, ọmọ-ẹhin mi ni ẹyin iṣe, nigba ti ẹyin bá ni ifẹ si ọmọnikeji yin.” Pẹlupẹlu, ni 1 Johannu 4:20 ati 21, Ọ̀rọ̀ onimiisi Ọlọrun polongo pe:
“Bi ẹnikẹni bá wi pe, emi fẹran Ọlọrun, ti o sì koriira arakunrin rẹ̀, èké ni: nitori ẹni ti kò fẹran arakunrin rẹ̀ ti o rí, bawo ni yoo ti ṣe lè fẹran Ọlọrun ti oun kò rí? Ofin yii ni awa sì rí gba lati ọwọ́ rẹ̀ wá, pe ẹni ti o bá fẹran Ọlọrun ki o fẹran arakunrin rẹ̀ pẹlu.”
Mu ilana ipilẹ naa pe awọn Kristian tootọ gbọdọ ní ifẹ laaarin araawọn bá ohun ti ó ṣẹlẹ ninu awọn ogun agbaye mejeeji ti ọrundun yii, ati awọn iforigbari miiran bakan-naa mu. Awọn eniyan isin kan-naa ninu Kristẹndọm pade lori pápá ìjà wọn sì pa araawọn ẹnikinni keji nitori awọn iyatọ niti orilẹ-ede. Ìhà kọọkan jẹwọ pe Kristian ni awọn, ìhà kọọkan sì ni awọn alufaa-ṣọọṣi rẹ̀, tí wọn fi idaniloju sọ pe Ọlọrun wà ni ìhà ọdọ wọn. Ìpalápalù “Kristian” lati ọwọ́ “Kristian” jẹ́ eso buburu. Ó jẹ́ itapa si ofin ifẹ ti Kristian, sísẹ́ awọn ofin Ọlọrun.—Tun wo 1 Johannu 3:10-12.
Ọjọ Iṣeṣiro
Nipa bayii, iṣubu kuro ninu isin Kristian ṣamọna si kì í ṣe kìkì awọn igbagbọ alaiwa-bi-Ọlọrun, bii ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan nikan ni, ṣugbọn sí awọn àṣà alaiwa-bi-Ọlọrun pẹlu. Sibẹ, ọjọ iṣeṣiro kan ń bọ̀, nitori pe Jesu sọ pe: “Gbogbo igi ti kò bá so eso rere, a ké e lulẹ, a sì wọ́ ọ sọ sinu iná.” Idi niyẹn ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fi rọni pe:
“Ẹ ti inu rẹ̀ [isin èké] jade, ẹyin eniyan mi, ki ẹ má baa ṣe alabaapin ninu ẹṣẹ rẹ̀, ki ẹ ma baa si ṣe gbà ninu ìyọnu rẹ̀. Nitori awọn ẹṣẹ rẹ̀ ga ani dé ọrun, Ọlọrun sì ti ranti aiṣedeedee rẹ̀.”—Ìfihàn 18:4, 5.
Laipẹ Ọlọrun yoo ‘fi í sinu ọkan-aya’ awọn alaṣẹ oṣelu lati yiju pada lodisi isin èké. Wọn yoo “sọ ọ́ di ahoro . . . wọn ó sì jẹ ẹran araarẹ̀, wọn o sì fi iná sun ún patapata.” (Ìfihàn 17:16, 17) Isin èké pẹlu awọn ẹ̀kọ́ isin rẹ̀ nipa Ọlọrun ni yoo di piparun raurau. Nitootọ, Ọlọrun yoo sọ fun awọn olùṣe isin èké gẹgẹ bi Jesu ti sọ ni ọjọ rẹ̀ pe: “A fi ile yin silẹ fun yin ni ahoro.”—Matteu 23:38.
Isin tootọ yoo la awọn idajọ Ọlọrun já, ki o baa lè jẹ́ pe, nikẹhin, gbogbo ọlá ati ogo yoo jẹ́ ti Ẹni naa ti Jesu sọ fun pe ‘iwọ nikan ni Ọlọrun otitọ.’ Oun ni Ẹni ti olorin naa ẹni ti o polongo pe: “Iwọ, orukọ ẹni-kanṣoṣo tii jẹ Jehofa, iwọ ni Ọga-ogo lori ayé gbogbo” dámọ̀.—Johannu 17:3; Orin Dafidi 83:18.
Awọn itọka:
1. Encyclopædia Britannica, 1971, Idipọ 6, oju-iwe 386.
2. A Short History of Christian Doctrine, lati ọwọ́ Bernhard Lohse, 1963, oju-iwe 51.
3. Ibid., oju-iwe 52 si 53.
4. New Catholic Encyclopedia, 1967, Idipọ VII, oju-iwe 115.
5. A Short History of Christianity, lati ọwọ́ Martin E. Marty, 1959, oju-iwe 91.
6. A Select Library of Nicene and Post-Nicene Fathers of the Christian Church, lati ọwọ́ Philip Schaff ati Henry Wace, 1892, Idipọ IV, oju-iwe xvii.
7. A Short History of Christian Doctrine, oju-iwe 53.
8. A Short History of Christianity, oju-iwe 91.
9. The Church of the First Three Centuries, lati ọwọ́ Alvan Lamson, 1869, oju-iwe 75 si 76, 341.
10. Second Century Orthodoxy, lati ọwọ́ J. A. Buckley, 1978, oju-iwe 114 si 115.
11. New Catholic Encyclopedia, 1967, Idipọ VII, oju-iwe 115.
12. Ibid., Idipọ IV, oju-iwe 436.
13. Ibid., oju-iwe 251.
14. Ibid., oju-iwe 436.
15. The New Encyclopædia Britannica, 1985, Itẹjade 15, Micropædia, Idipọ 1, oju-iwe 665.
16. The Church of the First Three Centuries, oju-iwe 52.
17. The Christian Tradition, lati ọwọ́ Jaroslav Pelikan, 1971, oju-iwe 173.
18. Origin and Evolution of Religion, lati ọwọ́ E. Washburn Hopkins, 1923, oju-iwe 339.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun isọfunni siwaju sii, wo iwe pẹlẹbẹ naa Should You Believe in the Trinity? ti a tẹjade lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
b Gẹgẹ bi a ti fihàn ninu awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ninu ọ̀wọ́ yii, bi o tilẹ jẹ pe Theophilus ati Tertullian lo awọn ọ̀rọ̀ wọnyi, wọn kò ni igbagbọ Mẹtalọkan ti Kristẹndọm ode-oni lọ́kàn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ọlọrun yoo mú ki awọn alaṣẹ oṣelu yiju pada lodisi isin èké
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Isin tootọ yoo la awọn idajọ Ọlọrun já