ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 8/1 ojú ìwé 26-27
  • Mo Rẹ Araami Silẹ Mo Sì Rí Ayọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Rẹ Araami Silẹ Mo Sì Rí Ayọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibẹrẹ Anfaani Kan
  • Iṣẹ-Ojiṣẹ Alakooko Kikun
  • Kò Rọrùn Láti Tọ́ Ọmọ Mẹ́jọ Ní Ọ̀nà Jèhófà, Àmọ́ Ó Máyọ̀ Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ìdílé Wa Ṣọ̀kan!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Jèhófà Máa Jẹ́ Kí Àwọn Ìpinnu Rẹ Yọrí Sí Rere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 8/1 ojú ìwé 26-27

Mo Rẹ Araami Silẹ Mo Sì Rí Ayọ

NI ỌDUN 1970, mo jẹ́ ẹni ọdun 23 ati olùlépa aṣeyọri. Nibi iṣẹ mi ní ibi iṣeto fun awọn ohun irinna ni Ivrea, Italy, a fi mi ṣe olori awọn akọwe. Mo pinnu lati jẹ ẹni pataki kan. Sibẹ mo ni isorikọ ati ainireti gan-an. Eeṣe?

Ọkọ mi ń lo eyi ti o pọ̀ julọ ninu akoko rẹ̀ ni ile ọtí ni títa kaadi pẹlu awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, o si fi mi silẹ lati gbé pupọ ninu awọn ẹrù idile. Ajọṣepọ wa bẹrẹ si buru sii. A ń ní gbolohun asọ̀ lori awọn nǹkan ti o kere julọ. Gẹgẹ bi abajade rẹ, ọkàn mi kun fun awọn ironu òdì.

‘Kò si ẹni ti o ni ọkan-ifẹ ninu rẹ niti gidi,’ ni emi yoo wi. ‘Wọn kan fẹ́ lati lo anfaani ipò rẹ ni.’ Emi yoo wi fun araami pe: ‘Ọlọrun kò le wà nitori tí ó ba wà ni, oun ki yoo gba ijiya ati iwa buburu ti o pọ̀ to bẹẹ laaye. Iwalaaye kò jamọ nǹkankan bikoṣe eré-ìje si iku.’ Emi kò lè loye idi ti eyi fi ri bẹẹ.

Ibẹrẹ Anfaani Kan

Ni ọjọ kan ni 1977, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa meji kan ilẹkun wa. Ọkọ mi, Giancarlo, kesi wọn wọlé, wọn si wọ inu pálọ̀ lati sọrọ. Ète rẹ̀ ni lati jẹ́ ki wọn di onigbagbọ ninu efoluṣọn bii tirẹ̀, ṣugbọn awọn ni wọn yí ironu rẹ̀ pada!

Laipẹ Giancarlo pẹlu bẹrẹ sii ṣe awọn iyipada ninu igbesi-aye rẹ̀. O di ẹni ti o tubọ mú suuru, ti o ń ya ọpọ akoko silẹ ti o sì ń fun emi ati ọmọdebinrin wa ní afiyesi pupọ sii. O gbiyanju lati sọ fun mi nipa ohun ti o ń kẹkọọ, ṣugbọn emi yoo fopin si ijiroro naa pẹlu ọ̀rọ̀ akọ kan.

Lẹhin naa ni ọjọ kan nigba ti Awọn Ẹlẹ́rìí naa ṣe ikesini, mo jokoo mo si tẹtisilẹ gidi. Wọn sọrọ nipa opin eto awọn nǹkan yii ati nipa Ijọba Ọlọrun, Paradise ilẹ̀-ayé, ati ajinde awọn oku. Ẹnu yà mi! N kò sùn fun oru ọjọ mẹta ti o tẹle e! Mo fẹ lati mọ pupọ sii, ṣugbọn igberaga ṣediwọ fun mi lati beere awọn ibeere lọwọ ọkọ mi. Lẹhin naa ni ọjọ kan, o fi oju lilekoko wi fun mi pe: “Lonii iwọ yoo tẹtisilẹ. Mo ni idahun si gbogbo awọn ibeere rẹ.” Nigba naa ni o wa tú awọn otitọ Bibeli jade fun mi.

Giancarlo wi fun mi pe Jehofa ni orukọ Ẹlẹdaa, pe olori awọn animọ Rẹ̀ ṣiṣekoko ni ifẹ, pe Oun rán Ọmọkunrin Rẹ̀ gẹgẹ bi irapada ki a baa le ni iye ainipẹkun, ati pe lẹhin iparun awọn eniyan buburu ni Armageddoni, Jesu Kristi yoo jí awọn oku dide nigba Ẹgbẹrun Ọdun Iṣakoso rẹ̀. O wi pe awọn ti a jí dide yoo dagba dé ijẹpipe niti ọpọlọ ati ara iyara ati pe wọn yoo ni anfaani lati gbe titilae ninu Paradise lori ilẹ̀-ayé.

Ni ọjọ ti o tẹle e, mo ba ọkọ mi lọ si Gbọngan Ijọba fun ìgbà akọkọ. Lẹhin naa mo wi fun un pe: “Awọn eniyan wọnyi nifẹẹ ara wọn ẹnikinni keji. Mo fẹ lati maa baa lọ ni wíwá sihin-in nitori pe wọn layọ niti gidi.” Mo bẹrẹ sii pesẹ si awọn ipade deedee, a si ń bámi ṣe ikẹkọọ Bibeli. Mo ronu pupọ nipa ohun ti mo ń kẹkọọ rẹ̀ ó sì tete dámilójú pe mo ti ri awọn eniyan tootọ ti Ọlọrun. Ni 1979 emi ati ọkọ mi fi ẹri iyasimimọ wa han si Jehofa nipa ṣiṣe iribọmi.

Iṣẹ-Ojiṣẹ Alakooko Kikun

Ni ipade ayika kan ni apa ipari ọdun yẹn, awiye kan ti ń fun igbokegbodo iwaasu alakooko kikun ni iṣiri ni a sọ. Mo nimọlara isunniṣe lati tẹwọgba iṣẹ-isin yẹn, mo si tọ Jehofa lọ ninu adura nipa ọ̀ràn naa. Ṣugbọn nigba naa ni mo loyun, ti awọn ìgbèrò mi si di eyi ti a jálù. La awọn ọdun mẹrin ti o tẹle e já, a ni awọn ọmọ mẹta. Meji ninu wọn ní awọn aleebu ara ti ń halẹ mọ iwalaaye, ni akoko ọtọọtọ. A dupẹ pe, ninu ọ̀ràn kọọkan, wọn jere ilera pada lẹkun-un-rẹrẹ.

Nisinsinyi mo nimọlara pe n kò le gbe ìgbèrò mi fun iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun tì sẹgbẹẹ mọ́. Mo fi iṣẹ ounjẹ oojọ mi silẹ lati le pọkanpọ daradara lori awọn ẹrù-iṣẹ́ mi gẹgẹ bii aya ati iya kan. Emi ati ọkọ mi ṣeto pe kí ẹnikan ṣoṣo maa ṣiṣẹ lati mowo wọle, eyi ti o tumọsi jíjá gbogbo ohun ti kò ṣe pataki silẹ. Sibẹ, Jehofa bukun fun wa jingbinni kò fi wa silẹ fun oṣi tabi aini.

Ni 1984 ọmọdebinrin mi, ti o jẹ́ ọmọ ọdun 15 nigba naa ti o si ṣẹṣẹ ṣe iribọmi, bẹrẹ iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun gẹgẹ bi aṣaaju-ọna. Ni akoko kan naa, ọkọ mi ni a yan si ipo alagba. Emi si ń kọ? Pẹlu nini imọlara pe ń kò le ṣe aṣaaju-ọna sibẹ, mo gbe gongo ilepa 30 wakati ninu iṣẹ iwaasu loṣooṣu kalẹ. Mo dori rẹ̀ mo si wi fun araami pe: ‘O ku iṣẹ! O ń ṣe pupọ.’

Bi o ti wu ki o ri, lẹẹkan sii igberaga di iṣoro mi. (Owe 16:18) Mo ń ronu nipa bi mo ti ń ṣe daradara si ati pe kò si aini fun mi lati ni itẹsiwaju eyikeyii sii nipa tẹmi. Ipo mi nipa ti ẹmi bẹrẹ sii jórẹ̀hìn, ti mo si tilẹ bẹrẹ sii padanu awọn animọ rere ti mo ti jere. Nigba naa mo ri ibawi ti mo nilo gbà.

Ni 1985 awọn alaboojuto arinrin-ajo meji ati awọn iyawo wọn ni a gba lalejo ni ile wa bi wọn ti ń ṣe ibẹwo onigbadegba wọn si ijọ wa. Ṣiṣakiyesi awọn Kristian oluyọnda ara-ẹni, onirẹlẹ wọnyi niti gidi mu mi lati ronu lori awọn ọ̀ràn. Mo ṣe iwadii lori koko ẹ̀kọ́ ti irẹlẹ, ni lilo awọn itẹjade Watch Tower Society. Mo ronu nipa irẹlẹ nla ti Jehofa fihàn ni biba awa ẹda eniyan ẹlẹṣẹ lò. (Orin Dafidi 18:35) Mo mọ pe mo nilati yí ironu mi pada.

Mo bẹ Jehofa lati ràn mi lọwọ lati mu irẹlẹ dagba ki n baa le sin in ni ọ̀nà ti oun ń fẹ́ ki ń gba sin oun ati lati ṣamọna mi ni lilo awọn ẹbun ti mo ni si ogo rẹ̀. Mo fọwọsi iwe fun iṣẹ isin oluranlọwọ aṣaaju-ọna, mo si bẹrẹ sii ṣiṣẹsin ninu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun ni March 1989.

Mo le wi nisinsinyi pe mo layọ nitootọ ati pe rirẹ araami silẹ ni ohun ti o ti dákún ayọ mi. Mo ti rí idi gidi fun wiwalaaye—ti ríran awọn talaka lọwọ lati wa mọ pe Jehofa, Ọlọrun otitọ naa, kò jinna si awọn ti ń wa a.—Bi Vera Brandolini ti sọ ọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́