ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 9/1 ojú ìwé 26-30
  • Jehofa Ti Bojuto Mi Daradara

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Ti Bojuto Mi Daradara
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Kutukutu Igbesi-aye
  • Jijẹrii fun Awọn Ibatan
  • Awọn Ibukun Laika Atako Si
  • Awọn Ẹri Siwaju sii Nipa Itọju Jehofa
  • Iṣẹ-ayanfunni kan ni Òkèèrè
  • Anfaani Iṣẹ-isin Siwaju sii—Ati Idanwo Kan
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 9/1 ojú ìwé 26-30

Jehofa Ti Bojuto Mi Daradara

MO BẸRẸ si ṣiṣẹsin Jehofa ni ọ̀nà ara-ọtọ kan, lati sọ ọ ni ranpẹ. Mo dagba ni eréko rirẹwa kan ní ariwa jijinna rere ni agbegbe New Zealand, ti o jẹ pe awọn eniyan Maori bii emi ni ń gbé ibẹ̀ ni pataki. Ni­gba ti mo ń rinrin-ajo lori ẹṣin lọjọ kan, molẹbi mi ti ń jẹ Ben pade mi loju ọna. Ó jẹ ìgbà ìwọ́wé (Ìlàjì-ayé ti iha guusu, igba ìrúwé ní Ìlàjì-ayé ti ìhà Ariwa), ni 1942. Mo jẹ ẹni ọdun 27 ni­gba naa ti mo si jẹ mẹmba ti ń ṣe deedee ni Ṣọọṣi ti England.

Fun ọpọlọpọ ọdun Ben ti ń ka awọn iwe Judge Rutherford, aarẹ Watch Tower Bible and Tract Society nigba yẹn, nisinsinyi oun ni lẹta kan lọwọ rẹ̀ ti oun ti rí gbà lati orile ọfiisi Watch Tower Society ti New Zealand ti o ń beere pe ki o kesi awọn eniyan adugbo si ibikan nibi ti wọn yoo ti lè ṣayẹyẹ Ounjẹ Alẹ Oluwa papọ. Siwaju sii, Ben nilati ṣeto fun ẹnikan lati dari isin naa. Ni wiwo mi lokeloke, Ben wi pe: “Iwọ ni ẹni naa.” Pẹlu igberaga fun jijẹ ẹni ti a kà si ẹni titootun—ati fun jijẹ ẹni ti o ti ń jẹ akara ati waini nigba gbígba ara Oluwa ninu ṣọọṣi—mo gbà.

Ni alẹ ti a ń wí yii, iye ti o to 40 eniyan pejọpọ ni ile Ben fun ṣiṣayẹyẹ iku Oluwa wa, ko si si ẹyọkan ninu wọn ti o jẹ Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nigba ti mo wọle ibatan mi fun mi ní ilapa-ero ọrọ-asọye naa. Mo yọ orin ti a tọka pe ki a fi bẹrẹ kuro ti mo si kesi ọkọ arabinrin Ben lati bẹrẹ pẹlu adura. Lẹhin naa mo bẹrẹ si ba akojọpọ ilapa-ero naa lọ, eyi ti o ni oniruuru awọn ibeere pẹlu awọn idahun ti a gbekari Iwe Mimọ ninu. Alufaa adugbo ti o wà nibẹ ń jálu ọ̀rọ̀ pẹlu atako, ṣugbọn iwọnyii ni a dahun nipa kika awọn Iwe Mimọ ti a tọkasi ninu ilapa-ero naa.

Mo sọyeranti pe ọ̀kan lara awọn ibeere ti ó wà ninu ilapa-ero naa niiṣe pẹlu akoko naa ninu ọdun ti o yẹ lati ṣayẹyẹ iṣẹlẹ yii. Bawo ni o ti tẹ́ gbogbo awọn ti o wá lọrun to nigba ti gbogbo wọn wo ìta lati oju ferese ti wọn si ri oṣupa gígúngbá rekete. Ni kedere, Nisan 14 ni ọjọ naa jẹ́.

Alẹ ọjọ yẹn mà ga o! Ayẹyẹ wa gba wakati mẹrin! Ọpọlọpọ awọn ibeere ni a gbe dide ti a si dahun rẹ̀ lati inu Iwe Mimọ ti o wà ninu ilapa-ero Society. Ni wiwẹhin pada, mo mọ̀ pe ń ba má ti la iriri yẹn já bi ko ba si abojuto onifẹẹ ti Jehofa—ani bi o tilẹ jẹ pe ni akoko yẹn emi kì í ṣe ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ti o ti ṣe iyasimimọ. Bi o tilẹ ri bẹẹ, ni alẹ Iṣe-Iranti yẹn ni 1942, mo ṣawari ète mi ninu igbesi-aye.

Kutukutu Igbesi-aye

A bi mi ni 1914. Baba mi ti kú ni nǹkan bii oṣu mẹrin ṣaaju ibi mi, mo si ranti jijẹ ọdọmọkunrin ti ń jowu awọn ọmọ ti wọn ni baba ti o fẹran wọn. Mo padanu iyẹn gidigidi. Fun mama mi igbesi-aye laisi ọkọ jẹ ijakadi lilekoko kan, ti a tubọ mu ki o ṣoro gan-an nipasẹ ipa ti Ogun Agbaye I ní.

Gẹgẹ bi èwe kan, mo gbé omidan kan ti ń jẹ Agnes Cope niyawo, o si ti jẹ ẹnikeji mi ninu igbesi-aye fun ohun ti o ju ọdun 58 lọ. Ni ibẹrẹ a jijakadi lapapọ lati lè ṣaṣeyọri ninu igbesi-aye. Mo kuna gẹgẹ agbẹ nitori ọgbẹlẹ lilekenka. Mo ri ọna àbùjá ninu eré idaraya, ṣugbọn titi di ìgbà iriri Iṣe-Iranti 1942 yẹn, emi ko ni ète gidi kan ninu igbe­si-aye.

Jijẹrii fun Awọn Ibatan

Lẹhin Iṣe-Iranti yẹn, mo kẹkọọ Bibeli pẹlu iharagaga, mo si ń jiroro awọn iwe lori Bibeli ti a tẹjade lati ọwọ́ Watch Tower Society pẹlu diẹ lara awọn mọlẹbi mi. Ni Sep­tember 1943 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan lati agbegbe miiran wa ṣabẹwo si awujọ tiwa ti o jẹ adado. A ní ijiroro gbigbona janjan kan, ti o gba wakati mẹrin. Lẹhin naa, ni mimọ pe wọn nilati gbera ni òwúrọ̀ ọjọ keji, mo beere pe: “Ki ni ń damiduro fun didi ẹni ti a ribọmi nisinsinyi?” Meji lara awọn mọlẹbi mi ati emi ni a ribọmi ni deedee agogo kan aabọ oru.

Lẹhin naa, mo rinrin-ajo pupọ kaakiri lati jẹrii fun awọn mọlẹbi mi. Awọn kan jẹ olugbọ rere, fun idi yii mo gbe ijiroro mi ka Matteu ori 24. Awọn miiran kò tẹ́tísílẹ̀, ni iru awọn ọran bẹẹ mo lo awọn ọrọ Jesu si awọn Farisi ti a ṣakọsilẹ ninu Matteu ori 23. Bi akoko ti ń lọ ṣá o, mo kẹkọọ lati jẹ ọlọgbọn ẹwẹ sii, ni afarawe Baba wa ọrun alaanu ati onifẹẹ.—Matteu 5:43-45.

Lakọọkọ aya mi tako ifẹ-ọkan mi lati ṣiṣẹsin Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, laipẹ oun darapọ mọ mi, ati ni December 1943 oun di ẹnikeji wiwulo ti o ṣeyasimimọ, ti a baptisi. Awọn marun-un miiran lati abule wa ní Waima darapọ pẹlu rẹ̀ ni ṣiṣe iribọmi ni ọjọ manigbagbe yẹn, ni mimu aropọ iye awọn akede Ijọba naa ni agbegbe yẹn di mẹsan-an.

Awọn Ibukun Laika Atako Si

Ni 1944 awọn arakunrin lati agbegbe mii­ran ṣebẹwo sọdọ wa, lọ́tẹ̀ yii wọn pese idalẹkọọ ti a nilo ninu iṣẹ ojiṣẹ ile-de-ile lọna bi aṣa. Bi wíwà nibẹ wa laaarin awujọ ti ń ṣe kedere sii, atako lati ọdọ awọn aṣoju Kristẹndọm bẹrẹ pelemọ. (Johannu 15:20) A ni ikoniloju leralera pẹlu awọn alufaa adugbo, ni yiyọrisi awọn ijiroro gígùn lori ẹkọ-igbagbọ. Ṣugbọn Jehofa fun wa ni iṣẹgun, awọn mẹmba miiran ni awujọ naa, ti o ní arabinrin mi ninu, wá sabẹ abojuto onifẹẹ Jehofa.

Ijọ kan ni a dasilẹ ni Waima ni June 1944. Inunibini ati ẹtanu isin dagba soke. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a ko fun laaye lati sinku sibi isinku adugbo. Nigba miiran atako naa yoo di ti oniwa-ipa. Ihalẹmọni ojukoju wà. Ọkọ ayọkẹlẹ ati ibi igbọkọsi mi ni a jó kanlẹ. Bi o tilẹ ri bẹẹ, pẹlu ibukun Jehofa, ni ohun ti o dín si oṣu mẹta, o ṣeeṣe fun wa lati ra ọkọ akẹru kan. Ti mo si lo kẹkẹ ẹru aláfẹṣinfà lati kó idile mi ti ń pọ̀ sii lọ si awọn ipade.

Ibisi ninu iye awọn alabaakẹgbẹpọ tumọsi pe a ní aini kanjukanju kan fun ibi ipejọpọ ti o tubọ tobi sii, nitori naa a pinnu lati kọ́ Gbọngan Ijọba kan ní Waima. Eyi ni Gbọngan Ijọba akọkọ ti a kọ ní New Zealand. Oṣu mẹrin lẹhin ti a gé awọn igi akọkọ lulẹ ni December 1, 1949, apejọ papọ mọ́ iyasimimọ ni a ṣe ninu gbọngan titun ti o gba 260 ijokoo. Ni ọjọ wọnni iyẹn jẹ aṣepari titayọ kan, ti a muṣe nipasẹ iranlọwọ Jehofa.

Awọn Ẹri Siwaju sii Nipa Itọju Jehofa

Niwọn bi iye awọn olupokiki Ijọba ni ariwa jijinna rere ni New Zealand ti ń baa lọ lati maa pọ̀ sii, awọn alaboojuto arinrin-ajo ń funni nisiiri lati ṣiṣẹsin nibi ti aini ti pọju. Ni idahunpada, ní 1956, mo ṣí idile mi lọ si Pukekohe, ni guusu Auckland. A ṣiṣẹsin nibẹ fun ọdun 13.—Fiwe Iṣe 16:9.

Awọn apẹẹrẹ meji ti itọju Jehofa ni akoko yii si wà ninu iranti mi. Nigba ti a gbà mi siṣẹ lati ọwọ́ ijọba ibilẹ naa gẹgẹ bi awakọ akẹru ati mimu ẹrọ ṣiṣẹ, a kesi mi lati wá si idanilẹkọọ Ile-ẹ̀kọ́ Iṣẹ-ojiṣẹ Ijọba ọlọsẹ mẹrin ni ẹka ile-iṣẹ Watch Tower Society ti o wà ní Auck­land. Mo beere fun iyọọda ọsẹ mẹrin kuro lẹnu iṣẹ fun ète yii, ọga onimọ iṣẹ-ẹrọ naa si sọ pe: “Ni gbogbo ọna. Mo daniyan pe ki ọpọlọpọ awọn eniyan dabii tirẹ. Nigba ti o ba pada de, ki o wa ri mi ni ọfiisi mi.” Nigba ti mo bẹ ọfiisi rẹ̀ wò nikẹhin, mo gba owo fun ọ̀sẹ̀ mẹrin ti n kò fi si lẹnu iṣẹ. Nipa bẹẹ, awọn aini idile mi nipa ti ara ni a pese fun.—Matteu 6:33.

Iyẹn ni apẹẹrẹ akọkọ. Ekeji ṣẹlẹ lẹhin ti aya mi ati emi ti tẹwọgba iṣẹ-isin aṣaaju-ọna deedee ní 1968. Lẹẹkan sii, a gbẹkẹle Jehofa fun itilẹhin, oun si san ere-ẹsan fun wa. Ni òwúrọ̀ ọjọ kan lẹhin ounjẹ òwúrọ̀, aya mi ṣi ẹ̀rọ amounjẹ-tutu ti ko si ri ohunkohun nibẹ ju kiki idaji butter. “Sarn,” ni o wi, “a ko ni ohunkohun ti o ṣẹku sibẹ lati jẹ. Ṣe a si ń jade lọ fun iṣẹ-isin papa lonii sibẹ?” Idahunpada mi? “Bẹẹni!”

Ni ẹnu ilẹkun akọkọ, onile naa tẹwọgba iwe ikẹkọọ ti a fi lọ̀ ọ́ ti o si fi pẹlu inurere fun wa ni dọsini ẹyin melookan gẹgẹ bi ọrẹ. Ẹnikeji ti a bẹwo fun wa ni ẹbun awọn ẹfọ—kumara (ọdunkun didun), cauliflower, ati karọti. Lara awọn ohun eelo ounjẹ ti a mu wa sile ni ọjọ yẹn ni ẹran ati butter. Bawo ni awọn ọ̀rọ̀ Jesu ti jasi otitọ to ninu ọran tiwa: “Ẹ sa wo ẹyẹ oju ọrun; wọn kii furugbin, bẹẹni wọn kii kore, wọn kii si kojọ sinu abà, ṣugbọn Baba yin ti ń bẹ ni ọrun ń bọ wọn. Ẹyin kò ha sàn ju wọn lọ?”—Matteu 6:26.

Iṣẹ-ayanfunni kan ni Òkèèrè

Rarotonga ní Erekuṣu Cook! Eyi ni ibi iṣẹ-ayanfunni aṣaaju-ọna akanṣe wa ni 1970. Oun ni o má jẹ ile wa fun ọdun mẹrin ti o tẹle e. Ipenija akọkọ nihin-in ni lati kọ́ ede titun kan. Bi o ti wu ki o ri, nitori ijọra ti o wa laaarin ede Maori ti New Zealand ati Maori ti Erekuṣu Cook, o ṣeeṣe fun mi lati sọ ọrọ awiye mi akọkọ lẹhin ọsẹ marun-un ti a dé.

Ni Erekuṣu Cook, iwọnba awọn akede Ijọba ni o wà, a ko si ni ibi kankan lati pejọpọ. Lẹẹkan sii, ni idahun si adura, Jehofa pese fun awọn aini wa. Ifọrọwerọ alaijẹ-bi-aṣa kan pẹlu oniṣọọbu kan yọrisi fifi ilẹ bibojumu kan háyà fun wa, laaarin ọdun kan pere a ti ni ibugbe kekere kan ati Gbọngan Ijọba kan ti o gba 140 eniyan. Lati igba naa lọ a ti gba ibukun kan tẹle omiran, si iyin Jehofa.

Ohun ti a mọriri ni pataki ni ifẹ alejo ti erekuṣu naa nawọ rẹ̀ si wa. Ni ọpọ igba, nigba ti a ba wà ninu iṣẹ ojiṣẹ, a ń fun wa ni awọn ohun mimu atunilara—eyi ti a fẹran daradara ní agbegbe oju ọjọ olooru. Ni ọpọ igba awa yoo de sile lati ba ọgẹdẹ, ibẹpẹ, mangoro, ati ọsan ti a fi silẹ si ẹnu ọna wa laini orukọ ẹni ti o gbe e wá.

Ni 1971 emi ati aya mi, papọ pẹlu awọn akede mẹta miiran lati Rarotonga, rinrin-ajo lọ si erekuṣu Aitutaki, ti a mọ daradara fun adagun odo rẹ̀ rirẹwa. A ri awọn olufẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun laaarin awọn olugbe ibẹ ẹlẹmi alejo ti a si bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli mẹrin, eyi ti awa ń ba lọ nipasẹ ikọwe ranṣẹ lẹhin ti a ti pada si Rarotonga. Nigba ti o ṣe awọn akẹkọọ wọnni ní Aitutaki ni a baptisi, ti a si dá ijọ kan silẹ. Ni 1978 Gbọngan Ijọba keji ni Erekuṣu Cook ni a kọ́ sibẹ. Jehofa ń mu ki awọn nǹkan dagba ni idahunpada si fifurugbin ati bibomirin ti a ṣe.—1 Korinti 3:6, 7.

Mo ni anfaani lati ṣebẹwo si awọn erekuṣu mẹwaa ni Erekuṣu Cook, lọpọ igba labẹ awọn ayika ipo ti ń danniwo. Irin-ajo ninu ọkọ oju omi kan lẹẹkanṣoṣo si Atiu, 114 ibusọ ni jijinna, maa ń gba ohun ti o ju ọjọ mẹfa lọ nitori iji lile ati irugudu òkun. (Fiwe 2 Ko­rinti 11:26.) Ani bi o tilẹ jẹ pe ipese ounjẹ mọniwọn ti ọpọlọpọ ti o yi mi ka si ń ṣaisan nitori pipẹ loju okun, mo layọ nitori itọju Jehofa, ti o si yọrisi gigunlẹ si ibi ti mo ń lọ laisewu.

Ní 1974 a ko fun wa laaye lati duro ni Erekusu Cook nitori naa a nilati pada si New Zealand. Nigba yẹn ijọ mẹta ni o wà lori awọn erekuṣu naa.

Anfaani Iṣẹ-isin Siwaju sii—Ati Idanwo Kan

Ni pipada si New Zealand, ilẹkun anfaani titun ṣi silẹ. (1 Korinti 16:9) Society nilo ẹnikan ti yoo le tumọ Ilé-ìṣọ́nà ati iwe ikẹkọọ Bibeli miiran si ede Maori ti Erekusu Cook. A fun mi ni anfaani naa, o si jẹ temi titi di ọjọ oni. Nigba naa mo ni anfaani lati ṣebẹwo deedee si awọn arakunrin mi ni Erekuṣu Cook, lakọọkọ gẹgẹ bi alaboojuto ayika kan, lẹhin naa gẹgẹ bi adele alaboojuto agbegbe.

Nigba ọ̀kan lara awọn ibẹwo wọnni, Arakunrin Alex Napa, aṣaaju-ọna akanṣe kan lati Rarotonga, lọ pẹlu mi ninu irin-ajo lori agbami-okun fun ọjọ 23 ti o mu wa dé Manahiki, Rakahanga, ati Penrhyn—awọn erekuṣu ni ariwa Cook. Ni erekuṣu kọọkan, Jehofa sun ọkan-aya awọn eniyan adugbo ẹlẹmi alejo lati pese ibugbe fun wa ati lati tẹwọgba ọpọ awọn iwe ikẹkọọ Bibeli. (Fiwe Iṣe 16:15.) Ni awọn erekuṣu wọnyi, ìsàn perli pọ̀ rẹpẹtẹ, ni ọpọ igba awọn eniyan fun wa ni perli gẹgẹ bi itilẹhin siha iṣẹ iwaasu jakejado aye. Nitori naa, bi a ti fun wọn ni perli tẹmi, a gba perli gidi.—Fiwe Matteu 13: 45, 46.

Bawo ni agbegbe adado yẹn ni apa ayé ti lẹwa to! Finuwoye awọn ẹja ekura ti wọn ń fi alaafia luwẹẹ pẹlu awọn ọmọde ninu adagun odo! Iru irisi ologo wo ni oju ọrun gbeyọ ni alẹ! Bawo ni awọn ọrọ olorin naa ti jẹ otitọ to: “Ọjọ de ọjọ ń fọhun, ati oru de oru ń fi imọ hàn.”—Orin Dafidi 19:2.

Lẹhin naa, ni ọdun mẹsan-an sẹhin, ni idanwo gidi ti iwatitọ de. Aya mi ni a gba si ile-iwosan nitori ṣíṣàn ẹ̀jẹ̀ sinu ọpọlọ. Iṣẹ́-abẹ ni a nilo, ṣugbọn dokita ki yoo gbà lati ṣe e laisi lilo ẹ̀jẹ̀. Emi ati aya mi ko le fi pẹlu ẹri-ọkan gbà pẹlu igbaṣe nǹkan ti yoo ru ofin Ọlọrun. Ṣugbọn ẹri-ọkan dokita naa paṣẹ pe gbogbo ọ̀nà ti o bá ṣeeṣe, ti ó ní ẹ̀jẹ̀ ninu, ni ki a lò lati pa iwalaaye mọ.

Ilera aya mi jorẹhin, a si fi si ẹka itọju loju mejeeji, ti a si fayegba kiki ibẹwo ti o mọniwọn. Oun padanu ìgbọ́ràn rẹ̀ nitori ikimọlẹ lori ọmọleti. Ó di ipo oniyanpọnyanrin kan. Lẹhin ibẹwo kan dokita kan tẹle mi de inu ọkọ ayọkẹlẹ mi, ni titẹnu mọ pe kiki anfaani kanṣoṣo ti aya mi ní ni iṣẹ́-abẹ pẹlu ẹ̀jẹ̀ ti o si ń rọ̀ mi lati fọwọsi i. Sibẹ, emi ati aya mi gbẹkẹle Jehofa—ani bi ṣiṣegbọnran si ofin rẹ̀ ba tilẹ yọrisi pipadanu awọn ọdun melookan ninu igbesi-aye isinsinyi.

Lojiji, ipo ilera aya mi sàn diẹ sii. Mo dé ni ọjọ kan mo si ba a ni ijokoo lori bẹẹdi ti o ń kawe. Ni awọn ọjọ ti o tẹ̀lé e oun bẹrẹ sii jẹrii fun awọn alaisan agbatọju ati awọn oṣiṣẹ nọọsi. Lẹhin naa a késí mi wọnu ofiisi oníṣẹ́-abẹ naa. “Ọgbẹni Wharerau,” ni oun wí, “ọkunrin olurinnakore gidi kan ni iwọ jẹ́! A gbagbọ pe iṣoro iyawo rẹ ti sàn.” Lairo tẹ́lẹ̀, iwọn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà ni iwọn deedee. Lapapọ, emi ati aya mi dupẹ lọwọ Jehofa ti a si tubọ sọ ipinnu wa dọtun lati ṣe gbogbo ohun ti a lè ṣe ninu iṣẹ-isin rẹ̀.

Nisinsinyi a ti ran mi pada si Erekuṣu Cook lẹẹkan sii mo sì ń ṣiṣẹsin ní Rarotonga. Iru anfaani onibukun wo ni o jẹ! Ni wiwẹhin pada emi ati aya mi kun fun ọpẹ́ gidigidi fun itọju Jehofa fun ohun ti o ju ẹwadun marun-un lọ ninu iṣẹ-isin rẹ̀. Nipa ti ara, awa ko ṣe alaini awọn koṣeemani igbesi-aye. Niti ero tẹmi, awọn ibukun naa pọ̀ jigbinni ju ohun ti a lè kà. Ọkan ti o gba afiyesi ni iye awọn mọlẹbi mi nipa ti ara ti wọn ti tẹwọgba otitọ. Mo lè ka iye ti o ju 200 lọ nisinsinyi ti wọn ti jẹ Awọn Ẹlẹ́rìí ti a ti baptisi fun Jehofa, papọ pẹlu 65 awọn atọ- mọdọmọ taarata. Ọmọ-ọmọ kan jẹ́ mẹmba idile Beteli ti New Zealand, nigba ti ọmọbinrin kan pẹlu ọkọ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ meji ń ṣe iṣẹ ìkọ́lé ni awọn ẹ̀ka.—3 Johannu 4.

Ni wiwo iwaju, mo fọkansikẹ ifojusọna fun wiwalaaye ninu paradise nibi ti, jakejado ilẹ̀-ayé, ẹwa yoo tayọ ju ti pẹtẹlẹ eweko rirẹwa ti a ti bi mi. Iru anfaani wo ni yoo jẹ lati ki mama ati baba mi kaabọ nigba ajinde ati lati sọ fun wọn nipa ẹbọ irapada naa, Ijọba naa, ati awọn ẹri miiran nipa itọju Jehofa.

Ipinnu mi, ti a gbéró nipasẹ imọ naa pe Ọlọrun ń tọju mi, rí gẹgẹ bi olorin naa ti ṣakọsilẹ ni Orin Dafidi 104:33: “Emi o maa kọrin si Oluwa [“Jehofa,” NW] nigba ti mo wà laaye: emi o maa kọrin si Ọlọrun mi ni gba ayé mi.”—Gẹgẹ bi Sarn Wharerau ti sọ ọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Gbọngan Ijoba akọkọ ti a kọ́ ní New Zealand, ni 1950

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́