ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 11/15 ojú ìwé 3
  • Awọn Wo Ni A Túnbí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Wo Ni A Túnbí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ero-imọlara ati Ero-inu
  • Ṣé Dandan Ni Kéèyàn Di Àtúnbí Kó Tó Lè Nígbàlà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Jésù Kọ́ Nikodémù Lẹ́kọ̀ọ́ ní Òru
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Di Àtúnbí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kíkọ́ Nikodemu Lẹkọọ
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 11/15 ojú ìwé 3

Awọn Wo Ni A Túnbí?

GBOGBO ẹni rere ni ó ha ń lọ si ọrun bi? Ọpọlọpọ rò bẹẹ, ṣugbọn Jesu Kristi kò gbà bẹẹ. Ní bíbá Nikodemu oluṣakoso Ju naa sọrọ, ẹni ti o yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ wá sọdọ rẹ̀ ni òru, Jesu wi pe: “Ko sì sí ẹni ti o gòkè re ọrun.”—Johannu 3:13.

Sibẹ, Jesu fihàn Nikodemu pe akoko naa ń bọ̀wá nigba ti awọn eniyan kan yoo ni anfaani lati wọnu Ijọba ọrun. Jesu sọ nipa awọn wọnyi pe: “Bikoṣepe a fi omi ati ẹmi bí eniyan, oun kò lè wọ ijọba Ọlọrun. Eyi ti a bí nipa ti ara, ara ni; eyi ti a si bí nipa ti ẹmi, ẹmi ni. Ki ẹnu ki o máṣe yà ọ, nitori mo wi fun ọ pe, A kò le ṣe alaitun yin bí.” Ṣugbọn Nikodemu ṣekayeefi nipa bi a ṣe lè tun ẹnikẹni bí.—Johannu 3:1-9.

Boya iwọ pẹlu ṣekayeefi nipa ohun ti Jesu ni lọkan. Awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ha le ní nǹkan ṣe pẹlu awọn iriri iyinilọkanpada lojiji tí awọn kan tí wọn ro pe wọn ti kun fun ẹmi Ọlọrun sọ pe wọn ni bi?

Awọn Ero-imọlara ati Ero-inu

Awọn kan sọ pe ni pipinnu boya ẹnikan ti di atunbi, ohun ti o ṣe pataki ni nini imọlara agbara ẹmi. Sibẹ, ọkan-aya wa ati ero-inu wa le sì wá lọna, paapaa ti ero-imọlara alagbara bá nipa lori wa.—Jeremiah 17:9.

William Sargant, oluwadii kan nipa ipa ti ero-imọlara ń ní lori ero-inu, tọka si aini naa “lati ṣọra lodisi awọn ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ ti a tẹwọgba labẹ ipo ti ero-imọlara ti ru soke nigba ti ọpọlọ wa lè maa tàn wá jẹ.” Gẹgẹ bi Sargant ti wi, apẹẹrẹ kan ni ti abajade iwaasu awọn olùṣèsọjí ati ijẹniniya ninu iná ọ̀run àpáàdì ti wọn fi ń halẹmọni. Ta ni ki yoo fẹ ki a tún oun bí lati lè lọ si ọrun bi o ba jẹ pe kiki yíyàn ti o ṣẹ́kù ni ìdálóró anipẹkun? Sargant sọ pe labẹ iru pakanleke ti ero-imọlara bẹẹ, “ironu ni a ń patì, ètò agbara iṣiṣẹ ọpọlọ yoo daṣẹduro fun ìgbà diẹ ná, ti awọn ero ati ero-igbagbọ titun yoo si di eyi ti a tẹwọgba laijanpata.”—The Mind Possessed.

Wàyi o, nigba naa, bawo ni ẹnikan ṣe lè mọ̀ daju bi ero-igbagbọ kan lori didi àtúnbí ba jẹ eyi ti a ti “tẹwọgba laijanpata”? Ọ̀nà ọlọgbọn tootọ ni lati jẹ ki gbogbo ohun ti ẹmi mimọ Ọlọrun mu ki awọn onkọwe Bibeli ṣakọsilẹ rẹ̀ samọna ẹni. Awọn Kristian ni a fun ní iṣiri lati jọsin Ọlọrun ‘pẹlu agbara ironu wọn’ wọn si nilati wadii daju pe ohun ti wọn gbagbọ jẹ otitọ.—Romu 12:1, 2, NW; 1 Tessalonika 5:21.

Didi ẹni ti a túnbí ṣí ọ̀nà ọ̀kan lara awọn anfaani ṣiṣe pataki julọ ti a tíì nawọ rẹ̀ si awọn eniyan rí silẹ. A so ó pọ̀ mọ́ idagbasoke ṣiṣekoko kan ninu iṣiṣẹyọri ète Ọlọrun. Niwọn bi gbogbo iwọnyi ti jẹ otitọ, awọn ibeere bii iru iwọnyi ń jẹyọ: Awọn wo ni a túnbí? Bawo ni eyi ṣe ń ṣẹlẹ? Awọn ifojusọna wo ni a gbeka iwaju iru awọn ẹnikọọkan bẹẹ? Awọn nikan ni a o ha sì gbàlà bi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Nikodemu ṣekayeefi nipa bi a ṣe le tún ẹnikẹni bí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́