ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 11/15 ojú ìwé 4-6
  • Idi ti A Fi Tún Awọn Kan Bí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Idi ti A Fi Tún Awọn Kan Bí
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ète Ọlọrun fun Araye
  • Ki Ni Ń Ṣẹlẹ Si Ọkàn Nigba Iku?
  • A Tún Wọn Bí Lati Ṣakoso Gẹgẹ Bi Ọba
  • Ki Ni Nipa Ti Ilẹ̀-ayé?
  • Ta ni Yoo Janfaani?
  • Ó Bọ́gbọ́n Mu Láti Gbà Gbọ́ Pé Ilẹ̀ Ayé Yóò Di Párádísè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Báwo Ni Ìgbàgbọ́ Rẹ Nínú Àjíǹde Ti Lágbára Tó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Olólùfẹ́ Wa Tí Wọ́n Ti Kú?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 11/15 ojú ìwé 4-6

Idi ti A Fi Tún Awọn Kan Bí

“BIKOṢEPE a tún eniyan bí, oun kò le rí ijọba Ọlọrun.” (Johannu 3:3) Awọn ọ̀rọ̀ wọnni ti mu ìwúrí ati iruniloju lapapọ bá ọpọ eniyan lati igba ti Jesu Kristi ti sọ ọ lati eyi ti o ju 1,900 ọdun lọ sẹhin.

Fun oye yekeyeke nipa awọn gbolohun ọ̀rọ̀ Jesu nipa didi àtúnbí, a nilati kọkọ dahun awọn ibeere wọnyi: Ki ni ete Ọlọrun fun iran eniyan? Ki ni ń ṣẹlẹ si ọkàn nigba iku? Ki ni a pete pe ki Ijọba Ọlọrun ṣe?

Ète Ọlọrun fun Araye

Ọkunrin akọkọ, Adamu, ni a dá ní ẹda eniyan pipe ọmọ Ọlọrun. (Luku 3:38) Jehofa Ọlọrun kò pete lae pe ki Adamu kú. Adamu ati aya rẹ̀, Efa, ni ifojusọna fun mimu idile eniyan alailẹṣẹ ti yoo walaye titi lae ti yoo si kun paradise ori ilẹ̀-ayé kan jade. (Genesisi 1:28) Iku kìí ṣe apakan ète Ọlọrun fun ọkunrin ati obinrin ni atetekọṣe. O jáwọ àárín agbo eniyan kiki nitori abajade ìṣọ̀tẹ̀ lodisi ofin atọrunwa.—Genesisi 2:15-17; 3:17-19.

Ìṣọ̀tẹ̀ yii gbé ariyanjiyan ńláǹlà nipa ìlànà-ẹ̀tọ́ dide, iru bii ti ẹ̀tọ́ ipo ọba-alasẹ Ọlọrun ati iṣeeṣe naa fun awọn eniyan lati duro ni oluṣotitọ si awọn ofin rẹ̀. Yoo beere fun akoko lati le yanju awọn ariyanjiyan wọnyi. Ṣugbọn ète Jehofa Ọlọrun fun araye kò yipada, oun kò si le kùnà ninu ohun ti ó pinnu lati ṣe. Oun ń fẹ niti gidi gan an lati fi idile eniyan pípé kan ti yoo gbadun iwalaaye titi lae ninu Paradise kún ilẹ̀-ayé. (Orin Dafidi 37:29; 104:5; Isaiah 45:18; Luku 23:43) A nilati ni otitọ ipilẹ yii lọkan nigba ti a bá ń gbe ọ̀rọ̀ Jesu nipa didi àtúnbí yẹwo.

Ki Ni Ń Ṣẹlẹ Si Ọkàn Nigba Iku?

Laimọ ohun ti ẹmi mimọ Ọlọrun ti ṣipaya fun awọn onkọwe Bibeli, awọn ọmọran ara Griki ń jijakadi lati wá itumọ ninu igbesi-aye. Wọn kò le gbagbọ pe eniyan ni a dá lati gbé kiki fun ọdun melookan, lọpọ ìgbà labẹ awọn ipo òṣì ati àre, ati lẹhin naa ki o kàn ṣáà ṣíwọ́ lati maa walaaye. Ninu eyi wọn tọna. Ṣugbọn ninu awọn ipari èrò wọn nipa ireti tí eniyan ní lẹhin iku, wọn kuna. Wọn pari èrò pe iwalaaye eniyan ń baa lọ ninu iru ọ̀nà miiran kan lẹhin iku, pe ọkàn àìleèkú kan wà ninu ẹnikọọkan.

Awọn Ju ati awọn Kristian alafẹnujẹ ni iru awọn oju-iwoye bẹẹ nipa lé lori. Iwe naa Heaven—A History sọ pe: “Nibikibi ti awọn Ju ti wọn jẹ àtìpó bá ti bá awọn ọjọgbọn Griki pade, èròǹgbà naa nipa àìleèkú ọkàn yoo jẹyọ.” Iwe naa fikun un pe: “Ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ awọn Griki nipa ọkàn ní abajade pipẹ titi lori awọn ero-igbagbọ ti Ju ati lẹhin-ọ-rẹhin ti Kristian. . . . Nipa dídá àjólùpọ̀ ẹkọ-ero-ori ti Plato ati àṣà atọwọdọwọ ti Bibeli ti a kò tíì rí iru rẹ̀ rí silẹ, Philo [ọmọran Ju ti Alexandria kan ni ọrundun kìn-ín-ní] la ọ̀nà silẹ fun awọn Kristian onironu ti ẹhin ìgbà naa.”

Ki ni Philo gbagbọ? Iwe kan-naa ń baa lọ pe: “Ni tirẹ̀, iku ń dá ọkàn pada si ipo rẹ̀ ipilẹṣẹ, ṣaaju ìbí. Niwọn bi ọkàn ti jẹ ti ayé ẹmi, iwalaaye ninu ara kò wá jẹ́ ohunkohun miiran mọ́ bikoṣe abala iṣẹlẹ onigba kukuru, ti o sábà maa ń mú ibanujẹ wá.” Bi o ti wu ki o ri, “ipo” Adamu “ṣaaju ìbí” rẹ̀ jẹ ti aláìwà nibikibi. Gẹgẹ bi akọsilẹ Bibeli ti sọ ọ, Ọlọrun kò pete iṣipopada ojú-ẹsẹ̀ sinu ilẹ-ọba miiran nigba iku, bi ẹni pe ayé wulẹ jẹ ibi ipadepọ kan fun imurasilẹ fun iyipada bọ sinu igbesi-aye giga ju tabi eyi ti o rẹlẹ ju.

Ero-igbagbọ naa pe ọkàn eniyan jẹ alaileeku ni a kò fi kọni ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti ó ní imisi, Bibeli. Kò tilẹ lo èdè naa “ọkàn àìleèkú” lẹẹkanṣoṣo paapaa. O ṣalaye pe a dá Adamu ní ọkàn kan, kìí ṣe pẹlu ọkàn kan. Genesisi 2:7 sọ pe: “OLUWA Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ̀ mọ eniyan; o si mí ẹmi iye si iho imu rẹ̀; eniyan si di alaaye ọkàn.” A kò figbakankan gbé ifojusọna fun yálà iwalaaye ni ọrun tabi ti idaloro ayeraye ninu iná ọ̀run-àpáàdì kalẹ fun araye rí. Bibeli fihàn pe ọkàn naa, tabi ẹnikan, ti o bá ku kò mọ ohunkohun nipa iwalaaye. (Orin Dafidi 146:3, 4; Oniwasu 9:5, 10; Esekieli 18:4) Gẹgẹ bi abajade rẹ̀, oju-iwoye tí awọn ọ̀mọ̀ràn ti ní nipa ọkàn jẹ́ eyi ti kò bá iwe mimọ mu. A nilati ṣọra fun awọn èròǹgbà ti ń ṣinilọna eyi ti o lè mú ki òye wa nipa ọ̀rọ̀ Jesu nipa didi àtúnbí ṣókùnkùn.

A Tún Wọn Bí Lati Ṣakoso Gẹgẹ Bi Ọba

Jesu sọ fun Nikodemu pe awọn wọnni ti ‘a túnbí wọ ijọba Ọlọrun.’ (Johannu 3:3-5) Ki ni Ijọba yẹn? Ni ede iṣapẹẹrẹ, ní ipilẹṣẹ ìtàn eniyan, Jehofa Ọlọrun funni ni isọfunni ṣaaju nipa ète rẹ̀ lati lo “iru-ọmọ” akanṣe kan—alakooso kan ti ń bọ̀—lati fọ́ ori Ejo laelae ni, Satani Esu. (Genesisi 3:15; Ìfihàn 12:9) Gẹgẹ bi a ti ṣi i paya ni ṣisẹ-n-tẹle ninu Iwe Mimọ, “iru-ọmọ” yii ni a fihàn gẹgẹ bii Jesu Kristi, ẹni ti ń ṣakoso pẹlu awọn alajumọṣakoso ni ọ̀nà ìgbà fi ipo ọba-alaṣẹ Ọlọrun hàn lọna ara-ọtọ, Ijọba ti Messia. (Orin Dafidi 2:8, 9; Isaiah 9:6, 7; Danieli 2:44; 7:13, 14) Eyi ni Ijọba ọrun naa, akoso kan ninu awọn ọrun ti yoo dá ipo ọba-alaṣẹ Jehofa lare ti yoo si yọ araye kuro ninu ìdè si ẹ̀ṣẹ̀ ati iku.—Matteu 6:9, 10.

Awọn 144,000 ti a rà lati inu iran eniyan wá ni wọn papọ pẹlu Jesu gẹgẹ bi alajumọṣakoso. (Ìfihàn 5:9, 10; 14:1-4) Ọlọrun ti yan diẹ lara idile alaipe ti Adamu lati di awọn “eniyan mímọ́ ti Ọga-ogo,” ti wọn ń ṣakoso pẹlu Kristi ninu Ijọba ti Messia naa. (Danieli 7:27; 1 Korinti 6:2; Ìfihàn 3:21; 20:6) Awọn ọkunrin ati obinrin wọnyi gba Jesu Kristi gbọ, ẹni ti o wi pe a o “tún” wọn “bí.” (Johannu 3:5-7) Bawo ni ati eeṣe ti bíbí yii fi ṣẹlẹ?

Awọn ẹnikọọkan wọnyi ni a ti baptisi ninu omi gẹgẹ bi ọmọlẹhin Kristi. Ọlọrun ti dari ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọn lori ipilẹ ẹbọ irapada Jesu, o ti polongo wọn ni olododo, o si ti gbà wọn ṣọmọ gẹgẹ bi ọmọkunrin tẹmi. (Romu 3:23-26; 5:12-21; Kolose 1:13, 14) Si iru awọn ẹni bẹẹ ni aposteli Paulu sọ pe: “Ẹyin ti gba ẹmi isọdọmọ, nipa eyi ti awa fi ń ké pe, Abba, Baba. Ẹmi tìkaraarẹ̀ ni o ń ba ẹmi wa jẹrii pe, ọmọ Ọlọrun ni awa iṣe: bi awa ba si jẹ ọmọ, ǹjẹ́ ajogun ni awa, ajogun Ọlọrun, ati ajumọjogun pẹlu Kristi; bi o ba ṣe pe awa baa jiya, ki a si le ṣe wa logo pẹlu rẹ̀.”—Romu 8:15-17.

Gẹgẹ bi ọmọlẹhin Kristi, awọn wọnyi ti ní ìbí titun, tabi ní ibẹrẹ titun, ninu igbesi-aye. O ti yọrisi idaniloju naa pe wọn yoo ṣajọpin ninu ogún Jesu ti ọrun. (Luku 12:32; 22:28-30; 1 Peteru 1:23) Aposteli Peteru ṣapejuwe ìtúnbí naa bayii pe: “Ẹni [Ọlọrun] ti o tún wa bí, gẹgẹ bi ọpọlọpọ aanu rẹ̀, sinu ireti aaye nipa ajinde Jesu Kristi kuro ninu òkú, sinu ogún aidibajẹ, ati ailabawọn, ati eyi ti kìí ṣá, ti a ti fi pamọ ni ọrun dè yin.” (1 Peteru 1:3, 4) Iwalaaye titun yii ní ọrun di eyi ti o ṣeeṣe fun iru awọn ẹnikọọkan bẹẹ nitori pe Ọlọrun jí wọn dide bi o ti ṣe jí Jesu dide.—1 Korinti 15:42-49.

Ki Ni Nipa Ti Ilẹ̀-ayé?

Eyi kò tumọsi pe gbogbo araye onigbọran ni yoo di ẹni ti a túnbí nikẹhin lati le ti ayé lọ si ọrun. Iru èròǹgbà alaṣiṣe bẹẹ ni awọn ọmọran bii Philo, ẹni ti o rò pe “iwalaaye ninu ara kò [jẹ́] ohunkohun miiran mọ́ bikoṣe abala iṣẹlẹ, onigba kukuru, ti o sábà maa ń mú ibanujẹ wá” ní. Ṣugbọn kò si ohun ti o buru pẹlu awọn ẹ̀dá ori ilẹ̀-ayé ti Jehofa Ọlọrun dá ni ipilẹṣẹ.—Genesisi 1:31; Deuteronomi 32:4.

Iwalaaye eniyan ni a kò figba kan pète rẹ̀ pe ki o kuru ki o si kun fun irora. Jesu Kristi ati awọn wọnni ti a túnbí lati sìn gẹgẹ bi ọba ati alufaa pẹlu rẹ̀ ni ọrun yoo mu gbogbo abajade aṣepalara ti ìṣọ̀tẹ̀ Satani kuro. (Efesu 1:8-10) Nipasẹ wọn gẹgẹ bi “iru-ọmọ Abrahamu” ti a ṣeleri, “ni a o bukun fun gbogbo orilẹ-ede ayé.” (Galatia 3:29; Genesisi 22:18) Fun araye onigbọran eyi yoo tumọsi iwalaaye lori paradise ilẹ̀-ayé, ti o yatọ patapata si iwalaaye onigba kukuru, ti o sì kun fun irora lode-oni.—Orin Dafidi 37:11, 29; Ìfihàn 21:1-4.

Ta ni Yoo Janfaani?

Lara awọn ti yoo janfaani lati inu ipese Ọlọrun fun bibukun araye ni awọn òkú ti a jí dìde ti wọn lo igbagbọ ninu ẹbọ irapada Jesu yoo wà. (Johannu 5:28, 29; Iṣe 24:15) Ọpọjulọ ninu wọn ni kò tíì kọ́ nipa Ọlọrun ati Kristi rí ati nitori naa wọn kò lè fi igbagbọ hàn ninu Jesu. Awọn ti a jí dìde yoo ní ninu bakan naa awọn aduroṣinṣin eniyan bii Johannu Arinibọmi, ti o ku ṣaaju ki iku Jesu to ṣí ọ̀nà silẹ fun iwalaaye ti ọrun. (Matteu 11:11) Yatọ si awọn wọnyi, ‘ogunlọgọ nla lati inu orilẹ-ede gbogbo ti fọ awọn aṣọ wọn ti wọn si ti sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọdọ-agutan naa,’ Jesu Kristi. Wọn dahun pada lọna ti o dara si iṣẹ iwaasu Ijọba naa eyi ti awọn “arakunrin” Jesu ti a ti túnbí ń ṣe òléwájú rẹ̀ ti wọn yoo si la ogun Ọlọrun ti Armageddoni ja sinu ayé kan ti a fọ̀ mọ́. (Ìfihàn 7:9-14; 16:14-16; Matteu 24:14; 25:31-46) Ninu iṣeto Ọlọrun, nitori naa, araadọta-ọkẹ ni a o gbàlà, bi o tilẹ jẹ pe a kò tún wọn bí lati ṣakoso pẹlu Kristi ninu awọn ọrun.—1 Johannu 2:1, 2.

Iwọ yoo ha wà lara awọn ti yoo jogun iwalaaye ninu paradise ilẹ̀-ayé bi? Iwọ lè wà lara wọn bi o bá lo igbagbọ ninu ẹbọ irapada Jesu Kristi ti o sì fi akitiyan darapọ pẹlu ijọ Kristian tootọ naa. Awọn ẹkọ-ero-ori kò tíì sọ ọ́ dibajẹ ṣugbọn o ti wà ni “ọwọ̀n ati ipilẹ otitọ.” (1 Timoteu 3:15; fiwe Johannu 4:24; 8:31, 32.) Nigba naa iwọ le wọna fun ọjọ iwaju yiyanilẹnu nigba ti awọn ọmọ Ọlọrun ti a túnbí yoo maa ṣakoso ni ọrun ti a o sì mú gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun lori ilẹ̀-ayé padabọsipo si ijẹpipe lori paradise ilẹ̀-ayé ti o jẹ́ agbayanu. Nitori naa yára gbá anfaani tirẹ lati walaaye ninu ayé titun onibukun ayeraye yẹn mú.—Romu 8:19-21; 2 Peteru 3:13.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

A kò fìgbàkanrí fun Adamu ni yíyàn meji niti yala iwalaaye ní ọrun tabi idaloro ayeraye ninu iná ọ̀run-àpáàdì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́