ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 11/15 ojú ìwé 7
  • Agbelebuu—Àmì Iṣapẹẹrẹ fun Isin Kristian Ha Ni Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Agbelebuu—Àmì Iṣapẹẹrẹ fun Isin Kristian Ha Ni Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Òótọ́ Ni Jésù Kú Lórí Àgbélébùú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì í Fi Lo Àgbélébùú Nínú Ìjọsìn?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ìdí Táwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Fi Í Lo Àgbélébùú Nínú Ìjọsìn
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì í Fi í Lo Àgbélébùú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 11/15 ojú ìwé 7

Agbelebuu—Àmì Iṣapẹẹrẹ fun Isin Kristian Ha Ni Bi?

FUN ọgọrọọrun ọdun ogunlọgọ ti gba agbelebuu gẹgẹ bi àmì iṣapẹẹrẹ kan fun isin Kristian. Ṣugbọn o ha jẹ bẹẹ nitootọ bi? Ọpọlọpọ ti wọn ti fi otitọ-inu gbagbọ bẹẹ ni o jẹ́ iyalẹnu fun gidigidi lati kẹkọọ pe agbelebuu kìí ṣe ti Kristẹndọm nikanṣoṣo rárá. Ni odikeji si eyi, awọn isin ti kìí ṣe ti Kristian jakejado ayé ti ń lò ó lọna gbigbooro.

Fun apẹẹrẹ, ni ibẹrẹ awọn ọdun 1500, bí Hernán Cortés ati awọn ọmọ-ogun “Kristian” rẹ̀ ti mura lati gbejako Ilẹ̀-ọba awọn Aztec‚ wọn gbe ọ̀pagùn ti ń polongo pe: “Jẹ ki a tẹle àmì Agbelebuu Mimọ ninu igbagbọ tootọ, nitori labẹ àmì yii ni awa yoo ṣẹgun.” O ti nilati jẹ iyalẹnu fun wọn lati ṣawari pe awọn ọ̀tá wọn abọriṣa ń júbà fun agbelebuu ti kò yatọ si tiwọn. Iwe naa Great Religions of the World sọ pe: “Cortés ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ fi ìtagìrì saṣẹhin fun ifeniyanrubọ ti awọn ara Aztec ati ohun ti o dabii lilo iwa bii ti Satani lati fi isin Kristian ṣẹlẹ́yà: . . . ni jíjúbà fun awọn àmì iṣapẹẹrẹ ti o dabi agbelebuu fun awọn ọlọrun ẹ̀fúùfù ati ti òjò.”

Ninu ọ̀rọ̀ olootu inu iwe irohin ti La Nación, onkọwe José Alberto Furque ṣalaye pe ni iha opin ọrundun Kejidinlogun, “ariyanjiyan gbigbona gidigidi ati arumọlara soke” bẹrẹ “laaarin awọn onimọ ijinlẹ nipa ẹda ati awọn awalẹ̀pìtàn lori ipilẹṣẹ ati itumọ awọn àmì alagbeelebuu” ti wọn ń rí la eyi ti o pọ̀ pupọ ninu ilẹ̀ Àárín Gbùngbùn ati Guusu America já. O dabi ẹni pe awọn kan ti háragàgà tobẹẹ gẹẹ lati daabo bo ipo ààyè agbelebuu gẹgẹ bi àmì iṣapẹẹrẹ kan fun kiki awọn “Kristian” nikan ti wọn fi ronu gbe àbá-èrò-orí naa jade pe lọna kan ṣáá a ti jihinrere fun awọn ara America ṣaaju ìrìn-àjò okun ti o jẹ ọgangan afiyesi ninu ìtàn ti Columbus! Èrò ti o jìnnà si otitọ yii di eyi ti a patì gẹgẹ bi alailẹsẹ nilẹ.

Bi akoko ti ń lọ, awọn awari siwaju sii lori kókó yii mu ki gbogbo iru awọn ariyanjiyan bẹẹ gbéjẹ́ẹ́. Furque kọwe pe: “Ninu iwe kan ti a tẹjade ni 1893 lati ọwọ́ Smithsonian Institution, a fidi rẹ̀ mulẹ pe agbelebuu ni a ti ń júbà fun . . . nigba pipẹ ṣaaju ki awọn ara Europe akọkọ to dé sí Ariwa America, eyi ti o jẹrii si àbá-èrò-orí naa . . . pe iru àmì iṣapẹẹrẹ bẹẹ farahan ninu gbogbo awujọ eniyan gẹgẹ bi apakan isin imulẹ ti ń jọsin fun awọn agbara ti wọn pilẹ̀ iwalaaye.”

Bibeli fihàn pe a kò pa Jesu lori agbelebuu àṣà atọwọdọwọ naa rárá ṣugbọn, kakabẹẹ, o jẹ lori opo-igi kan lasan, tabi stau·rosʹ. Ọ̀rọ̀ Griki yii, ti o farahan ni Matteu 27:40‚ niti gidi tumọsi ìtí-igi tabi òpó-igi kan lasan ti a nàró, bii iru eyi ti a ń lò fun awọn ipilẹ ile kíkọ́. Nitori naa, agbelebuu kò figbakanri ṣapẹẹrẹ isin Kristian tootọ. Jesu Kristi fi àmì iṣapẹẹrẹ gidi naa, tabi “àmì,” ti isin Kristian tootọ hàn nigba ti o sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ̀ pe, ọmọ-ẹhin mi ni ẹyin iṣe, nigba ti ẹyin bá ni ifẹ si ọmọnikeji yin.”—Johannu 13:35.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́