Ọlọrun Kò Gbagbe “Ifẹ ti Ẹyin Fihàn si Orukọ Rẹ̀”
“ỌLỌRUN kìí ṣe alaiṣododo ti yoo fi gbagbe iṣẹ́ yin ati ifẹ ti ẹyin fihàn si orukọ rẹ̀, nipa iṣẹ́ iranṣẹ ti ẹ ti ṣe fun awọn eniyan mimọ, ti ẹ sì ń ṣe.” (Heberu 6:10) Awọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu wọnyi jẹ otitọ fun awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Ila-oorun Europe. Wọn ń fi otitọ ṣiṣẹsin fun ire orukọ Ọlọrun, fun ọpọ ẹwadun wọn ti ṣiṣẹ aṣelaagun kárakára labẹ ikanilọwọko ti a gbé kà wọn lori lati ọwọ́ awọn ijọba àná ti Soviet ń ṣakoso. Jehofa ranti awọn iṣe rere ti wọn ti ṣe ó sì rọ̀jò awọn ibukun Ijọba naa lé wọn lori. Fun apẹẹrẹ, ẹ jẹ ki a wo irohin ọdun iṣẹ-isin ti o kọja kiki lati ibi mẹta ninu awọn agbegbe wọnyẹn.
Awọn Ipinlẹ Soviet Union Tẹlẹri
Awọn ipinlẹ Soviet Union tẹlẹri rohin pe laaarin ọdun iṣẹ-isin 1992, gongo iye awọn akede Ijọba naa fi ipin 35 ninu ọgọrun-un lọ soke—lati 49,171 si 66,211! Ṣugbọn iyẹn kò mọ sibẹ, niwọn bi awọn akede wọnyẹn ti jẹ alaapọn gidigidi, gẹgẹ bi a ṣe rii ninu awọn ibisi didara ninu ifisode awọn iwe ikẹkọọ Bibeli, titikan awọn iwe-irohin. Wọn ti lo awọn iwe-pẹlẹbẹ ati iwe ilewọ pẹlu lọna rere, ni fifi 1,654,559 sode. Iyẹn pọ ju ilọpo meji 477,235 iye ti ọdun ti o kọja lọ! Ki ni o ti jẹ ihuwapada si gbogbo awọn ifisode wọnyi? Ilọpo meji iye awọn ikẹkọọ Bibeli. Nisinsinyi a ń ṣe ikẹkọọ Bibeli 38,484.
Bakan naa, ikopa ninu iṣẹ-isin aṣaaju-ọna oluranlọwọ fi ipin 94 ninu ọgọrun-un lọ soke. Eyi lọna ti o ṣe kedere fikun akọsilẹ jijọju ninu iye awọn ọmọlẹhin 26,986, ti a ṣẹṣẹ baptisi, ni ifiwera pẹlu 6,570 fun ọdun ti o kọja, ibisi yiyanilẹnu ti ipin 311 lori ọgọrun-un!
Bawo ni diẹ ninu awọn ẹni ti a ṣẹṣẹ baptisi naa ṣe di ẹni ti o nifẹẹ ninu ihinrere naa lakọọkọ? Nigba miiran aniyan jijinlẹ ti Ẹlẹ́rìí naa tí ń ṣe ikẹkọọ jẹ́ kókó abajọ kan. Alaboojuto oluṣalaga kan lati Moldova sọ pe:
“Emi ati aya mi ṣebẹwo sọdọ obinrin kan ti o ti figbakan ri fifẹhan ninu otitọ Bibeli. Ikẹkọọ Bibeli kan ni a bẹrẹ pẹlu rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, ọkọ rẹ̀ kò fi ifẹ kankan hàn rara. Lọjọ kan nigba ti a wà loju ọ̀nà lati bẹ̀ ẹ́ wò ki a baà lè maa bá ikẹkọọ naa lọ, ipo oju ọjọ di eyi ti ń munigbọn pẹ̀pẹ̀ ti o si ń fún yìnyín. Ekukaka ni a fi ri ẹnikẹni ni oju popo, ṣugbọn o ṣeeṣe lati de ile rẹ̀ gan-an ni akoko ti a dá. Obinrin naa sọ fun ọkọ rẹ̀ pe: ‘Ṣe o ri bi awọn eniyan wọnyi ṣe bikita pupọ nipa wa tó? Wọn de lasiko bi yìnyín tilẹ ń fún.’ Iṣẹlẹ yii mu ki ọkọ rẹ̀ bẹrẹ sii ronu. O pa ero rẹ̀ dà o sì darapọ mọ́ ikẹkọọ naa, oun ati iyawo rẹ̀ sì ti di Ẹlẹ́rìí ti a baptisi nisinsinyi.”
Nigba miiran iwa ọmọluwabi awọn Ẹlẹ́rìí naa lè ru ìfẹ́-ọkàn soke ninu ihinrere naa. Alagba kan, ti oun naa wá lati Moldova, ni iriri yii:
“Ọkunrin kan ti mo ṣebẹwo sọdọ rẹ ninu ipinlẹ ti mo ti ń waasu kò ni ìfẹ́-ọkàn ninu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. O sọ pe oun jẹ onisin Orthodox, bii ti baba ati baba rẹ̀ agba. Nitori naa o sọ pe ki ń fi sakaani naa silẹ. Bi o ti wu ki o ri, ṣaaju ki ń to fi ibẹ silẹ, o fun mi ni anfaani naa lati sọ idi ti mo fi ṣebẹwo fun oun. Mo tọkasi Matteu 28:19, ti o sọ pe: ‘Ẹ lọ ẹ maa sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọlẹhin, ẹ maa baptisi wọn ni orukọ Baba, ati niti Ọmọ, ati niti ẹmi mimọ.’ Mo wa fun ni adirẹsi ibi ipade wa mo sì fi ibẹ silẹ. Si iyalẹnu mi, ọkunrin yii wá si ipade wa ni ọsẹ kan lẹhin naa! O duro titi tí itolẹsẹẹsẹ naa fi pari. O ṣalaye pe jalẹ gbogbo ọsẹ naa, oun ti kabaamọ hihuwa bi onroro bẹẹ si mi. Ikẹkọọ Bibeli kan ni a bẹrẹ loju ẹsẹ, o sì ti di ọ̀kan lara awọn arakunrin wa nisinsinyi.”
Apa titayọ miiran ninu ọdun iṣẹ-isin naa ni ti idahunpada jaburata si aini awọn arakunrin wa ni agbegbe yẹn. Ni sáà otutu ti ọdun 1991 si 1992, nǹkan bi 400 tọọnu ounjẹ ati aṣọ rẹpẹtẹ fun awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọde ni a fi ranṣẹ si awọn ti wọn ṣalaini. Awọn ipese wọnyi ni a pinkiri si eyi ti o fẹrẹẹ jẹ gbogbo apa ipinlẹ Soviet Union tẹlẹri, koda titi de Irkutsk ni Siberia ati Khabarovsk, nitosi Japan. Ami wiwunilori kan ni o jẹ nitootọ pe Jehofa kò ti i gbagbe ifẹ ti awọn arakunrin wa ti fihàn si orukọ rẹ̀! Ẹ̀rí ifẹ arakunrin yii ti ẹmi Jehofa ru soke tun ti ni iyọrisi siso wọn pọ̀ ṣọkan pẹlu idile wọn yika ayé. Fun apẹẹrẹ, arabinrin kan ni Ukraine kọwe si ẹka ile-iṣẹ pe:
“Iranlọwọ ti ẹ fifun wa ti nipa lori imọlara wa gidigidi. Awa ni a sún lati sunkun a sì dupẹ lọwọ Jehofa Ọlọrun fun ṣiṣaigbagbe wa. Loootọ, a ni inira niti ohun ti ara ni lọwọlọwọ bayii, ṣugbọn a dupẹ fun iranwọ ti o wá lati ọdọ awọn arakunrin wa ni Iwọ-oorun, awọn nǹkan tun ti rọ̀ṣọ̀mù fun wa nipa ohun ti ara. Nitori iranlọwọ yin, idile wa yoo lè ya akoko pupọ sii sọtọ fun iṣẹ-isin Jehofa nisinsinyi. Bi Jehofa bá fẹ́, emi ati ọmọbinrin mi yoo ṣe aṣaaju-ọna oluranlọwọ ni awọn oṣu akoko ẹ̀ẹ̀rùn.”
Ni afikun, isapa ipese awọn iranwọ ti jẹrii fun awọn ará ìta nitori ti awọn onworan lè ri pe awọn Ẹlẹ́rìí fi ifẹ hàn nipasẹ iṣe wọn. Idile kan lati ijọ miiran kọwe pe: “A gba awọn iranwọ ohun ti ara ti o ni ninu ounjẹ ati aṣọ. O pọ pupọ! Itilẹhin ati iṣiri yin jẹ ẹkọ arikọgbọn fun wa pe awa pẹlu nilati maa ṣe daadaa si awọn ẹlomiran. Iṣe ifẹ yii ni awọn alaigbagbọ kò ṣaikiyesi, titikan awọn olufifẹhan ati awọn idile wọn; o ti jẹ ijẹrii nla kan nipa ẹgbẹ́ ará tootọ naa.”
Awọn apejọpọ agbegbe marun-un ati apejọpọ agbaye kan ti a ṣe ni June ati July ti o kọja yii, pẹlu ẹṣin-ọrọ naa “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀,” jẹ ẹ̀rí ibukun Jehofa miiran lori iṣẹ́ aṣekara awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ati ifẹ ti wọn ti fihàn fun sisọ orukọ rẹ̀ di mímọ̀. Awọn apejọpọ wọnyi ni 91,673 eniyan pesẹ si, ti a si baptisi 8,562. St. Petersburg ni iye ti o pọ̀ julọ wá, ibi ti a ti ṣe apejọpọ agbaye naa, nibi ti 46,214—titikan awọn ayanṣaṣoju lati nǹkan bi 30 orilẹ-ede yika ayé—ti korajọpọ ni Papa Iṣere nla ti Kirov.
Ni Siberia ọkunrin ẹni nǹkan bi 60 ọdun wá si ilẹ apejọpọ ni Irkutsk lati wulẹ foju gán-ánní rẹ̀. O sọ pe: “Gbogbo awọn ti o wá ni wọn mura daadaa, pẹlu oju ti ń rẹrin-in musẹ, wọn si jẹ oninuure sì ẹnikinni-keji. Awọn eniyan wọnyi dabi idile kanṣoṣo ti o sopọṣọkan. Ẹnikan lè nimọlara pe wọn jẹ ọ̀rẹ́ kìí ṣe kìkì ni papa iṣere naa ṣugbọn bakan naa ninu ọ̀nà ìgbà gbé igbesi-aye pẹlu. Mo gba iwe ikẹkọọ Bibeli gbigbamuṣe mo sì kẹkọọ daradara sii nipa iru eto-ajọ ti eyi jẹ́. Mo fẹ lati kàn si awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ati lati kẹkọọ Bibeli pẹlu wọn.”
Ni apejọpọ kan-naa ni Irkutsk, nibi ti 5,051 ti pesẹ, obinrin olufifẹhan kan lati Yakut Republic, Siberia, ṣalaye pe: “Mo wo awọn eniyan naa, mo sì fẹ́rẹ̀ sọkun ayọ. Mo dupẹ lọwọ Jehofa gan-an pe o ran mi lọwọ lati mọ iru awọn eniyan bẹẹ. Nihin-in ni apejọpọ yii, mo ti gba iwe ikẹkọọ, mo sì fẹ́ bá awọn ẹlomiran sọrọ nipa rẹ̀. Mo fẹ gidigidi lati jẹ olujọsin Jehofa kan.”
Oludari Papa Iṣere nla Central ni Alma Ata, Kazakhstan, nibi ti 6,605 ti wa si apejọpọ naa, sọ ohun ti o tẹle yii: “Iṣesi yin mu mi lori ya. A ti mu mi pa iyemeji mi rẹ pe gbogbo yin, ni tèwe-tàgbà, jẹ awọn eniyan ti ń bọwọ funni. Emi kò lè sọ pe mo gbagbọ ninu Ọlọrun, ṣugbọn mo gbagbọ ninu awọn ohun mímọ́ ọlọwọ ti ẹgbẹ́ ará yin sọ di mímọ̀, ninu iṣesi yin si awọn iniyelori tẹmi ati tara.”
Ọ̀gá ọlọpaa kan ni apejọpọ Alma Ata sọ pe: “Mo ti ni ifarakanra lẹẹmeji pẹlu ẹyin eniyan yii, ìgbà kọọkan si jẹ ni apejọpọ kan. O jẹ ohun ti o gbadunmọni lọna kikọyọyọ lati ṣiṣẹ pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.”
Romania
Bakan naa, Jehofa kò tii gbagbe ifẹ ti awọn ara ni Romania ti fihàn si orukọ rẹ̀. Ọdun iṣẹ-isin ti o kọja yii ri ọpọ iṣẹlẹ alayọ fun awọn Ẹlẹ́rìí. Lakọọkọ, ẹka ile-iṣẹ ni a tun dasilẹ lẹẹkansi ni Bucharest. Igbokegbodo ti a fayegba kẹhin labẹ ofin dopin ni 1949. Ọfiisi naa ni nǹkan bi 20 arakunrin ati arabinrin ti wọn ń ṣiṣẹ ninu ile lilo titun naa. Ẹka ile-iṣẹ naa ń ṣiṣẹsin 24,752 akede—gongo ti o ga ju ti igbakigba ri lọ ti ó fi ibisi ipin 21 ninu ọgọrun-un rekọja ipindọgba ti ọdun ti o kọja.
Lẹhin wiwaasu fun ọpọ ọdun labẹlẹ, awọn akede naa ń ṣatunṣebọsipo daradara ninu iṣẹ́ ijẹrii itagbangba ti ẹnu-ọna-de-ẹnu-ọna. Iriri kan lati Ijọba Ibilẹ Mureş fihàn bi awọn Ẹlẹ́rìí melookan ṣe lo anfaani eyikeyii ti wọn ni lọna rere lati waasu fun awọn ẹlomiran, koda nigba ti wọn ba ń rinrin ajo. Ẹka ile-iṣẹ kọwe pe:
“Akede kan pinnu lati waasu lati inu iyara ọkọ oju-irin kan si omiran. Ihuwapada awọn eniyan naa lapapọ jẹ eyi ti o dara, ṣugbọn ninu iyara ti o kẹhin, awọn iṣoro melookan jẹyọ. Kò si eyikeyii ninu awọn arinrin-ajo naa ti o fẹ́ lati gba ẹ̀dà kan ninu awọn iwe-irohin wa. Nikẹhin, ọkunrin kan, ti ọkàn rẹ̀ ti ru, dide duro ó sì kigbe pe: ‘Emi yoo gba oju ferese da gbogbo iwe-irohin rẹ sita! Eeṣe ti o fi ń yọ wa lẹnu pupọ tobẹẹ pẹlu isin rẹ?’ Akede naa fi inurere dahun pe koda bi o bá tilẹ da awọn iwe-irohin naa sita, ẹlomiran lè janfaani lati inu iwa rẹ̀—iyẹn ni awọn wọnni ti wọn yoo he awọn iwe-irohin naa. Ni ṣiṣakiyesi iparọrọ akede naa, ọkunrin naa ni a mú ori rẹ̀ wu pupọ debi ti o fi gba awọn iwe-irohin naa ti oun funraarẹ si bẹrẹ sii há wọn fun awọn arinrin-ajo yooku ninu iyara naa. Lọna yiyanilẹnu, gbogbo wọn gba iwe-irohin kan. Lẹhin pipin wọn, ọkunrin naa kò ni ẹ̀dà kankan fun araarẹ̀. Nitori naa, akede naa beere lọwọ rẹ̀: ‘Ọ̀gá, iwọ kò ha fẹ ẹ̀dà eyikeyii fun araarẹ ni bi?’ Nigba yii ni ọkunrin naa já ọkan ninu awọn iwe-irohin naa gbà lọwọ arinrin-ajo kan ti o ni ẹ̀dà meji o si sọ pe: ‘Ẹ̀dà kan ti tẹ̀ mi lọwọ nisinsinyi!’”
Ni ọpọ orilẹ-ede iṣẹ́ iwaasu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti fi awọn igba kan ru atako awọn alufaa Kristẹndọm soke. Ni Romania, awọn alufaa Ṣọọṣi Orthodox sábà maa ń binu yánnayànna si awọn Ẹlẹ́rìí. Ṣugbọn eyi kò lè dá Jehofa duro ni bibukun awọn eniyan rẹ̀ fun ifẹ ti wọn ti fihàn si orukọ rẹ̀. Alaboojuto ayika kan kọwe pe:
“Papọ pẹlu awọn ijọ adugbo, a jade lọ fun iṣẹ-isin ni awọn igberiko. Ọgọrun-un awọn arakunrin ni o wa. A háyà bọọsi kan ti o gbe wa rin nǹkan bii 50 kilomita lọ si igberiko, si ilu kekere kan. A pe ọpọlọpọ wá sibi ọrọ-asọye fun gbogbo eniyan eyi ti yoo wáyé ni inu Gbọngan Ibilẹ. Gẹ́rẹ́ ti ipade naa bẹrẹ, alufaa Orthodox dé lati dabarú ipade wa. Awọn ọ̀gá ọlọpaa gbiyanju lati da awọn alufaa naa duro. Sibẹsibẹ, o kọ̀ lati ṣe wọ̀ọ̀. O ṣaṣeyọri ni dida ipade naa duro nigba ti o fọ́ gilaasi ẹnu-ọna abawọle nla naa. Bi o ti wu ki o ri, ọpọ ninu awọn olugbe adugbo naa kò fohunṣọkan paapaa pẹlu ìwà alufaa naa. Ijẹrii kíkúná ni a lè fifun gbogbo awọn ti o wá sibẹ nigna naa, ti a si pín ọpọ rẹpẹtẹ awọn iwe ikẹkọọ.”
Lọna bibanininujẹ, ni awọn apa ibikan ni orilẹ-ede naa, iwọnba awọn Ẹlẹ́rìí diẹ ni o wà. Nigba ti aṣaaju-ọna alakooko kikun kan kọkọ de si ijọba ibilẹ Olt, o ri kiki awọn arakunrin mẹsan-an pere ni gbogbo ijọba ibilẹ naa ati ipinlẹ titobi kan lati waasu. Lẹhin ọdun kan iye awọn Ẹlẹ́rìí lọ soke si 27, ninu awọn ẹni ti marun-un jẹ akede ti a mu sọji. Aṣaaju-ọna naa fidi ibugbe rẹ̀ kalẹ si Corabia, nibi ti kò ti si awọn Ẹlẹ́rìí kankan rara. Lẹhin ti awọn Ẹlẹ́rìí naa ti wà nibẹ fun kiki ọjọ 45, oludari pariiṣi adugbo naa ṣatako lori redio Craiova lodisi iṣẹ́ wọn. O sọ pe wọn ti fi ẹkọ wọn “ba” ilu-nla Corabia “jẹ́,” ni gbigbiyanju lati mu ki awọn eniyan yí isin wọn pada. Atako naa ń baa niṣo, pẹlu ero-ọkan lati dá iṣẹ́ naa duro ki o si ba orukọ rere awọn Ẹlẹ́rìí naa jẹ́ ni adugbo yẹn. Gbogbo rẹ̀ de ogogoro nigba ti awọn ara wà ni Bucharest fun apejọpọ agbegbe. Oludari isin Orthodox fun Corabia ṣe ikede alagbara kan lẹhin isin ṣọọṣi rẹ̀: “Gbogbo wa nilati ṣe iwọde ojupopo kan ki a ba lè ru awọn ọlọpaa soke lati gbe igbesẹ lodisi awọn Ẹlẹ́rìí, ti wọn ti fi awọn itẹjade wọn kun gbogbo adugbo yii ti wọn sì ti fun awọn eniyan ni majele jẹ.” Ṣugbọn ni alẹ́ ti o ṣaaju ọjọ ti o yẹ ki ipade naa waye, ohun aramanda kan ṣẹlẹ. Awujọ awọn fọlefọle kan ba katidira naa ati Gbọngan Ibilẹ Ilu-nla naa jẹ́. Nitori naa, ipade iṣatako naa ni kò figbakan waye mọ!
Awọn Ipinlẹ Yugoslavia Tẹlẹri
Ọdun iṣẹ-isin 1992 ti jẹ ọdun ti o lekoko julọ fun awọn ará ni agbegbe Yugoslavia. Bi o ti wu ki o ri, ni akoko kan naa, wọn ti ni awọn iriri onidunnu melookan. Ki a dupẹ, Jehofa kò gbagbe iṣẹ́ wọn ati ifẹ ti wọn fihàn si orukọ rẹ̀.
Ogun kọkọ bẹrẹ ni Slovenia, lẹhin naa ni Croatia, ati lẹhin naa ni Bosnia ati Herzegovina. Laaarin ọdun kan, lati inu orilẹ-ede alailọba kanṣoṣo, awọn Orilẹ-ede marun-un ni wọn ń sakun lati fidi awọn aala-ilẹ, ofin, ati owó wọn mulẹ. Ọgọrọọrun awọn Ẹlẹ́rìí nilati sá fi ile wọn silẹ ki wọn si sádi awọn arakunrin wọn nibomiran. Lọna ti o jọra pẹlu ti awọn orilẹ-ede miiran ni iha Ila-oorun Europe, awọn igbimọ ti ń bojuto ọ̀ràn pajawiri ni a yàn ni awọn ilu-nla, ti wọn ń bojuto ibugbe, ounjẹ, ati fun awọn ará ti wọn ṣalaini. Laaarin ọdun iṣẹ-isin naa, nǹkan bi tọọnu ounjẹ 55 ni a pin fun awọn ará ni awọn ijọ laaarin awọn agbegbe ti wahala bá naa. Ọpọ lẹ́tà imọriri ni a ti ri gbà.
Awọn ará ni Dubrovnik sọ bi wọn ti kun fun ọpẹ́ tó fun iranwọ ti a fun wọn. Bi arabinrin kan ti pada sile pẹlu ẹrù ounjẹ rẹ̀, aladuugbo kan beere ibi ti o ti ra awọn ẹyin naa. Arabinrin naa sọ fun un pe awọn arakunrin rẹ̀ nipa tẹmi ni agbegbe miiran ni wọn fi i ranṣẹ. O ya aladuugbo naa lẹnu pupọ. Ninu ọ̀ràn miiran ọkunrin kan ti a kò mọ̀ ri lati Slovenia pe alagba kan o si sọ pe: “Mo ti gbọ pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń pin awọn ounjẹ ti wọn gbà lati ọ̀dọ̀ awọn arakunrin wọn lọna ti o tọ́. Mo ti fi awọn melookan ranṣẹ si awọn eniyan; bi o ti wu ki o ri, wọn kò de ibi ti wọn ń lọ. Emi ha lè fi iru awọn ẹrù iranwọ bẹẹ ranṣẹ si yin, ki ẹyin si pin wọn bi?” Bakan naa, awọn iwe-irohin ati redio ti rohin daradara nipa iṣẹ́ iranwọ wa.
Arakunrin kan ti a baptisi ni apejọpọ agbaye ti Zagreb ni 1991 ni o mọ̀ nipa awọn iṣoro ti ń dide bọ̀ ti o si ra odindi ile itaja ounjẹ kan. O kó ounjẹ naa lọ si ile rẹ̀ nitosi agbegbe ti ogun ti ń jà. Bi ọ̀wọ́n ounjẹ naa ti ń múná sii, ipese yii wa di ibukun gidi kan fun awọn ara.
O ṣeeṣe lati rí iyọọda gba fun lilo ọkọ̀ akẹru nla kan lati fi kó awọn ounjẹ wiwọpọ lọ fun awọn ará ti a kogunti ni Sarajevo. A layọ lati sọ pe jíjá awọn ounjẹ naa funni ni a ṣe laṣeyọrisirere.
Ìjà naa ti ṣọṣẹ́ fun awọn ara-ilu. Lọna ti o banininujẹ, ni opin ọdun iṣẹ-isin naa, mẹfa ninu awọn arakunrin ati arabinrin wa ati awọn olufifẹhan meji ni wọn padanu ẹmi wọn, ti awọn diẹ sì farapa.
Bi o ti wu ki o ri, ọpọ iriri fihàn pe ni pataki, o jẹ aabo lati jẹ ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ninu ọ̀ràn kan awọn ará ń rinrin-ajo lọ si apejọpọ agbegbe kan ni Belgrade nigba ti awọn ṣọja da bọọsi naa duro, ti wọn sì beere boya awọn mẹmba isin pato kan wà lara wọn. Awọn ará naa dahun pe kò si eyikeyii ninu wọn nibẹ. Wọn nilati fi awọn kaadi idanimọ wọn hàn, ti awọn kan ninu wọn si ni orukọ ti o lè fihàn pe wọn jẹ ti isin yẹn. Awọn ṣọja naa fẹsun irọ pipa kan wọn, ṣugbọn awọn ara naa ní iwe imara-ẹni kuro ni ṣọọṣi naa pẹlu wọn; bi o tilẹ jẹ pe a bi wọn sinu isin yẹn, wọn sọ pe, wọn ti di Ẹlẹ́rìí Jehofa nisinsinyi, ti wọn ń rinrin-ajo lọ si apejọpọ wọn. Pẹlu eyi awọn ṣọja naa gba wọn laaye lati maa bá irin-ajo wọn niṣo.
Awọn aṣaaju-ọna ń baa niṣo ninu iṣẹ-isin wọn pẹlu itara ti kò jórẹ̀hìn, ti eyi sì ti jẹ isunniṣiṣẹ tootọ fun iṣẹ́ naa. Ilé-Ìṣọ́nà, pẹlu awọn akori ẹhin iwe rẹ̀ alawọ oriṣiriṣi ti ń munilaraya gaga, ni a ń tumọ lẹsẹkan naa ni gbogbo awọn ede pataki ti ẹkùn naa. O ń pese “ìwọ̀n ounjẹ wọn” nipa tẹmi deedee “ni akoko” fun awọn olufẹ otitọ ati ododo. (Luku 12:42) Laaarin ọdun iṣẹ-isin 1992, awọn arakunrin ati arabinrin titun 674 ni a baptisi.
Pẹlu idaniloju, Ọlọrun kò tii gbagbe iṣẹ́ awọn ara ni iha Ila-oorun Europe ati ifẹ ti wọn ti fihàn si orukọ rẹ̀. Siwaju sii, o ń fẹ ki gbogbo awọn olujọsin rẹ̀, laika ibi ti wọn lè maa gbé sí, maa tẹle imọran rere ti Paulu funni tẹle e, ni Heberu 6:11, eyi ti o sọ pe: “Awa si fẹ ki olukuluku yin ki o maa fi iru aisinmi kan naa hàn, fun ẹ̀kún ireti titi de opin.”