ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 1/15 ojú ìwé 3-4
  • A O Ha Gbà Ọ́ lọ Soke Ọrun Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A O Ha Gbà Ọ́ lọ Soke Ọrun Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Oniruuru Oju-iwoye Nipa Ìgbàlọsókè
  • ‘Gbà Lọ Soke Lati Pade oluwa’—Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Sọ Fún Wa, Ìgbà Wo Ni Nǹkan Wọ̀nyí Yóò Ṣẹlẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 1/15 ojú ìwé 3-4

A O Ha Gbà Ọ́ lọ Soke Ọrun Bi?

ỌPỌ eniyan gbagbọ pe wọn ó lọ si ọrun nigba ti wọn bá kú. Ṣugbọn awọn kan lero pe a o gbà wọn lọ soke ọrun ninu ohun ti a ń pe ni ìgbàlọsókè. Ifojusọna rẹ ha niyẹn bi?

Ìgbàlọsókè naa jẹ́ “ìpòórá aimọye araadọta-ọkẹ awọn eniyan lojiji laisi itọpasẹ eyikeyii nipa ibi ti wọn lọ!” Bẹẹ ni ajihinrere Protẹstanti kan sọ. Gẹgẹ bi Evangelical Dictionary of Theology ti wi, èdè-ìsọ̀rọ̀ naa “ìgbàlọsókè” tọkasi “siso awọn ṣọọṣi pọ ṣọkan pẹlu Kristi nigba wíwá rẹ̀ ẹlẹẹkeji.”

Awọn kan rii pe o ń dani lọ́kàn rú lati ronu nipa fifi awọn ọ̀rẹ́ ati mẹmba idile silẹ sẹhin lati pade Jesu Kristi. Sibẹ, ọpọlọpọ gbagbọ pe ìgbàlọsókè naa gbọdọ ṣẹlẹ. Yoo ha wáyé bi? Bi o ba ri bẹẹ, nigba wo?

Oniruuru Oju-iwoye Nipa Ìgbàlọsókè

Bibeli fihàn pe ṣaaju ibẹrẹ Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun tí Kristi ṣeleri naa, akoko kan yoo wà ti a ó pe ni “ipọnju nla.” Jesu sọ pe: “Nitori nigba naa ni ipọnju nla yoo wà, iru eyi ti kò sì lati ìgbà ibẹrẹ ọjọ ìwà di isinsinyi, bẹẹkọ, iru rẹ̀ kì yoo sì sí.” (Matteu 24:21; Ìfihàn 20:6) Awọn kan gbé ìgbàlọsókè naa ṣaaju ipọnju nla. Awọn miiran reti rẹ̀ ni akoko yẹn. Sibẹ awọn kan lero pe ìgbàlọsókè naa yoo de lẹhin idaamu alailẹgbẹ yẹn.

Oju-iwoye ìgbàlọsókè-lẹ́hìn-ìpọ́njú gbodekan titi di ibẹrẹ ọrundun kọkandinlogun. Lẹhin naa, ní England ni ajọ-igbokegbodo kan ti a dari lati ọwọ́ alufaa Ṣọọṣi ti Ireland tẹlẹri kan, John Nelson Darby ti gbèrú. Oun ati awọn ọmọ ṣọọṣi Anglican miiran ti wọn lọ́kàn kan-naa wá di ẹni ti a mọ gẹgẹ bi Ẹgbẹ́ Awọn Ará. Lati ibi ti o gbé ṣọọṣi rẹ̀ kalẹ si ni Plymouth, Darby rinrin-ajo lati waasu ni Switzerland ati ni awọn apá ibomiran ni Europe. O tẹnumọ ọn pe ipadabọ Kristi yoo ṣẹlẹ ni ipele meji. Yoo bẹrẹ pẹlu ìgbàlọsókè onibookẹlẹ kan, ninu eyi ti a o gba “awọn ẹni mímọ́” lọ soke ṣaaju ki akoko ipọnju ọlọdun meje tó sọ ilẹ̀-ayé dahoro. Nigba naa ni Kristi, tí “awọn ẹni mímọ́” wọnyi tẹle yoo farahan lọna ti o ṣee ri, wọn yoo si ṣakoso papọ lori ilẹ̀-ayé fun ẹgbẹrun ọdun kan.

Darby tẹnumọ aini naa lati jẹ ẹni ti a yasọtọ kuro ninu ayé, awọn wọnni ti wọn ṣajọpin oju-iwoye rẹ̀ ni asẹhinwa-asẹhinbọ sì wá di ẹni ti a mọ gẹgẹ bi Ẹgbẹ́ Awọn Ará ti a Yasọtọ Gédégbé. B. W. Newton dari apa ẹka yiyatọ kan ti o gbagbọ ninu ìgbàlọsókè ṣugbọn kìí ṣe ninu ọ̀kan ti o ṣaaju ipọnju. Agbẹnusọ ìgbàlọsókè-lẹ́hìn-ìpọ́njú Alexander Reese gbagbọ pe “awọn àbá-èrò-orí Ìgbàlọsókè Onibookẹlẹ jẹ́ ìyọnu fun ireti Wíwá Kristi.”

Awọn onigbagbọ ìgbàlọsókè-ṣáájú-ìpọ́njú gbagbọ pe iyatọ ninu oju-iwoye yii jẹ eyi ti o ṣe pataki tó lati nipa lori “iru ireti [wọn] ni ibatan pẹlu wíwá Kristi.” Awọn miiran fi igbẹkẹle sinu “àbá-èrò-orí ìgbàlọsókè ti kìí ṣe ti gbogbogboo,” ni gbigbagbọ pe awọn ti wọn jẹ aduroṣinṣin julọ si Kristi ni a o kọ́kọ́ gbalọsoke ti a o si mú awọn ti wọn tubọ jẹ́ ti ayé sii lẹhin naa.

Ọpọ awọn ẹgbẹ́ ajihinrere polongo ìgbàlọsókè awọn Kristian olododo ti kò jinna mọ́. Bi o ti wu ki o ri, loju-iwoye awọn èrò ti o yatọsira, iwe pẹlẹbẹ kan ti a tẹjade lati ọwọ́ Ṣọọṣi Pentikosti Elim ti Britain wi pe: “Nigba ti a gbagbọ ninu ìlapa-èrò ti o gbooro nipa awọn iṣẹlẹ ti o tanmọ ipadabọ Oluwa Jesu . . . , ominira ni a yọọda fun ninu itumọ asọtẹlẹ ni ibamu pẹlu igbagbọ ẹnikọọkan. Ọpọlọpọ tẹwọgba iduro ti kìí ṣe ti gbà-á-bẹ́ẹ̀ laijanpata, ni fifi suuru duro de awọn iṣẹlẹ naa funraawọn lati mú itolẹsẹẹsẹ alasọtẹlẹ naa ṣe kedere.”

Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti a misi, Bibeli, ni ọpa idiwọn nipasẹ eyi ti a gbọdọ diwọn ijotiitọ gbogbo igbagbọ. (2 Timoteu 1:13; 3:16, 17) Nitori naa, ki ni ohun ti ó sọ nipa ìgbàlọsókè?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́