ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 2/15 ojú ìwé 12-17
  • “Ki Igbeyawo Ki o Ni̇́ Ọlá Laaarin Gbogbo Eniyan”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ki Igbeyawo Ki o Ni̇́ Ọlá Laaarin Gbogbo Eniyan”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipo-ayika Ti Ń Yipada
  • Ó Nipa Lori Ijọ Kristian
  • A Fà Wọn Lọ A Sì Tàn Wọn Jẹ
  • Kọkọrọ naa si Idena
  • Awọn Idẹwo ti O Wọ́pọ̀ fun Gbogbo Eniyan
  • Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Láyọ̀ Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Jẹ́ Kí Jèhófà Dáàbò Bo Ìgbéyàwó Rẹ Kó sì Fún Un Lókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • “Ẹ Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Ní Ọlá”
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Bí Ìgbéyàwó Bá Wà ní Bèbè Àtitúká
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 2/15 ojú ìwé 12-17

“Ki Igbeyawo Ki o Ni̇́ Ọlá Laaarin Gbogbo Eniyan”

“Ki igbeyawo ki o ní ọlá laaarin gbogbo eniyan, ki àkéte sì jẹ́ alaileeeri.”—HEBERU 13:4.

1. Ki ni ọpọ awọn eniyan kẹkọọ rẹ̀ nipa igbeyawo ti ó kẹsẹjari?

ARAADỌTA-ỌKẸ awọn eniyan, àní ninu sanmani ti ikọsilẹ rọrùn yii, ń gbadun igbeyawo ti ẹmi rẹ̀ gùn. Wọn ti rí ọ̀nà ìkẹ́sẹjárí, laika awọn iyatọ ninu iwa-animọ ati ipò àtilẹ̀wá ninu igbesi-aye si. Iru awọn igbeyawo bẹẹ ni a ń rí laaarin awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ninu ọ̀ràn ti ó pọ julọ awọn tọkọtaya wọnyi yoo gbà pe awọn ti niriiri apapọ akoko rere ati buburu, àní awọn okunfa fun ìráhùn diẹ lodisi ẹnikinni keji. Sibẹ, wọn ti kẹkọọ lati farada awọn iṣoro ti kò tó nǹkan ninu igbeyawo wọn sì pa ọkọ̀ igbeyawo wọn mọ́ soju ọ̀nà títọ́. Ki ni diẹ lara awọn kókó abajọ naa ti o ti jẹ́ ki wọn maa baa lọ?—Kolosse 3:13.

2. (a) Ki ni awọn kókó abajọ agbeniro diẹ ti ń mú ẹmi igbeyawo kan dè? (b) Ki ni awọn kókó abajọ diẹ ti ó lè fọ́ igbeyawo kan ká? (Wo apoti ni oju-iwe 14.)

2 Awọn ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí awọn kan tí igbeyawo Kristian wọn ti jẹ́ alayọ ti ó sì tọ́jọ́ ń ṣipaya ohun pupọ gan-an ni. Ọkọ kan ti o ti ṣegbeyawo fun ọdun 16 sọ pe: “Akoko yoowu ti iṣoro bá ti rúyọ, a ti ṣe isapa niti gidi lati fetisilẹ si oju-iwoye ẹnikinni keji.” Eyi ń tẹnumọ ọ̀kan lara awọn kókó amú-nǹkan-dúró gbọnyingbọnyin ninu ọpọlọpọ igbeyawo—ijumọsọrọpọ aláìfọ̀rọ̀ pamọ́, alaifọrọsabẹ-ahọn. Aya kan, ti a ti fẹ́ fun ọdun 31, sọ pe: “Dídi ọwọ́ araawa mú ati ṣiṣe awọn nǹkan apanilẹ́rìn-ín lati pa ìfẹ́ eléré-ìfẹ́ ti ó wà laaarin wa mọ́ ti sábà maa ń jẹ́ ohun àkọ́múṣe.” Iyẹn sì tun jẹ́ apa ìhà miiran kan ninu ijumọsọrọpọ. Tọkọtaya miiran, ti wọn ti gbeyawo fun ohun ti ó sunmọ 40 ọdun, tẹnumọ ijẹpataki bibaa lọ lati ni òye imọlara ìdẹ́rìn-ín-pani, ti jíjẹ́ ẹni ti ó lè fi araawọn ati ẹnikinni keji rẹ́rìn-ín. Wọn tun sọ pe ó ṣeranwọ lati lè rí ìwà ti ó dara julọ ati eyi ti o buru julọ ninu araawọn ẹnikinni keji ati sibẹ ki wọn lè fi ifẹ aduroṣinṣin hàn. Ọkọ naa mẹnukan imuratan lati gba aṣiṣe ati lẹhin naa ki a tọrọ aforiji. Nibi ti ẹmi ijuwọsilẹ bá ti wà, igbeyawo naa yoo ṣee tẹ̀síhìn-ín-sọ́hùn-ún dipo ki ó kán.—Filippi 2:1-4; 4:5, Kingdom Interlinear.

Ipo-ayika Ti Ń Yipada

3, 4. Iyipada ninu iṣarasihuwa wo ni ó ti wáyé nipa iṣotitọ ninu igbeyawo? Iwọ ha lè funni ni awọn apẹẹrẹ bi?

3 Jalẹ iwọnba ẹwadun ti ó kọja, ni gbogbo ayé, ìfòyemọ̀ ti yipada niti iṣotitọ ninu igbeyawo. Awọn lọ́kọláya kan gbagbọ pe kò sí ohun ti ó buru pẹlu jíjayé-orí araawọn, àdàpè-ọ̀rọ̀ ode-oni kan fun iwa-panṣaga, ni pataki bi ẹnikeji bá mọ̀ ti ó sì tẹwọgba a.

4 Kristian alaboojuto kan sọrọ nipa ipo naa pe: “Ayé ti fẹrẹẹ pa igbidanwo pataki eyikeyii lati gbé ni ibamu pẹlu akojọ-ofin iwarere tì. Ìwà mímọ́ ni a ti wá wò gẹgẹ bi ohun ayé-ijọ́hun.” Awọn ṣàràkí-ṣàràkí tí igba-ojú-mọ̀ ninu iṣelu, ere-idaraya, ati eré-ìnàjú ń tàpá si awọn ilana Bibeli nipa iwarere ni gbangba wálíà, iru awọn eniyan bẹẹ ni wọn sì ń baa lọ lati kókìkí. Ó fẹrẹẹ má sí ìtìjú kan ti a so mọ iwa aitọ eyikeyii tabi àyídáyiydà ti iwarere. Iwa mímọ́ ati iwatitọ ni a kìí sábà kà sí iyebiye laaarin awọn ti a fẹnulasan pe ni awọn eniyan onipo giga. Lẹhin naa, lori ipilẹ ilana ti ‘bi o ti wà lábàtà ni o wà ni gbànja,’ ogunlọgọ awọn eniyan tẹle apẹẹrẹ yẹn wọn sì fààyè gba ohun ti Ọlọrun dẹbi fun. Ńṣe ni ó rí bi Paulu ṣe sọ ọ́ pe: “Awọn ẹni ti ọkàn wọn le rekọja, ti wọn sì ti fi ara wọn fun wọbia, lati maa fi iwọra ṣiṣẹ iwa-eeri gbogbo.”—Efesu 4:19; Owe 17:15; Romu 1:24-28; 1 Korinti 5:11.

5. (a) Ki ni iduro Ọlọrun lori panṣaga? (b) Ki ni ìlò ti Bibeli lo ọ̀rọ̀ naa “agbere” ni ninu?

5 Awọn ọ̀pá idiwọn Ọlọrun kò tíì yipada. Iduro rẹ̀ ni pe gbígbé papọ laisi anfaani igbeyawo jẹ́ gbígbé ninu àgbèrè. Aiṣotitọ ninu igbeyawo ṣì jẹ́ panṣaga.a Aposteli Paulu sọ ni kedere pe: “Ẹyin kò mọ pe awọn alaiṣootọ kì yoo jogun ijọba Ọlọrun? Ki a má tàn yin jẹ; kìí ṣe awọn agbere, tabi awọn abọriṣa, tabi awọn panṣaga, tabi awọn alailera, tabi awọn ti ń fi ọkunrin ba ara wọn jẹ́ . . . ni yoo jogun ijọba Ọlọrun. Bẹẹ ni awọn ẹlomiran ninu yin sì ti jẹ́ rí: ṣugbọn a ti wẹ̀ yin nù, ṣugbọn a ti sọ yin di mímọ́, ṣugbọn a ti dá yin láre ni orukọ Jesu Kristi Oluwa, ati nipa ẹmi Ọlọrun wa.”—1 Korinti 6:9-11.

6. Iṣiri wo ni a lè rí ninu awọn ọ̀rọ̀ Paulu ni 1 Korinti 6:9-11?

6 Kókó kan ti ń funni niṣiiri ninu ẹsẹ-iwe mimọ yẹn ni gbolohun Paulu, “Bẹẹ ni awọn ẹlomiran ninu yin sì ti jẹ́ rí: ṣugbọn a ti wẹ̀ yin nù.” Bẹẹni, ọpọlọpọ ti wọn ti sáré ninu “aṣeju iwa wọbia” ni ìgbà ti o ti kọja ti pe orí araawọn wálé, wọn ti tẹwọgba Kristi ati ẹbọ rẹ̀, a sì ti wẹ̀ wọn nù. Wọn ti yàn lati wu Ọlọrun nipa gbígbé igbesi-aye oniwarere wọn sì tubọ layọ gẹgẹ bi iyọrisi eyi.—1 Peteru 4:3, 4.

7. Iforigbari wo ni o wà ninu liloye “iwapalapala,” ki sì ni oju-iwoye Bibeli?

7 Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, itumọ iwapalapala ti ayé ode-oni ni o ti di alailagbara tobẹẹ debi pe kò bá oju-iwoye Ọlọrun dọgba. Iwe atumọ ọ̀rọ̀ kan tumọ “iwapalapala” gẹgẹ bi “eyi ti o lodi si iwarere ti a ti fidii rẹ̀ mulẹ.” “Iwarere ti a ti fidii rẹ̀ mulẹ” lode-oni, eyi ti o fààyè gba ibalopọ takọtabo ṣaaju igbeyawo ati lẹhin ode igbeyawo ati bakan naa ibalopọ takọtabo laaarin ẹ̀yà kan-naa, ni ohun ti Bibeli kàléèwọ̀ gẹgẹ bi iwapalapala. Bẹẹni, bi a bá fi oju-iwoye ti Bibeli wò ó, iwapalapala jẹ́ iṣaigbọran si akojọ ofin iwarere ti Ọlọrun lọna wiwuwo rinlẹ.—Eksodu 20:14, 17; 1 Korinti 6:18.

Ó Nipa Lori Ijọ Kristian

8. Bawo ni iwapalapala ṣe lè nipa lori awọn wọnni ti wọn wà ninu ijọ Kristian?

8 Iwapalapala gbodekan tobẹẹ lonii debi pe ó tilẹ lè lo ikimọlẹ lori awọn wọnni ti wọn wà ninu ijọ Kristian. Ó lè nipa lori wọn nipasẹ itolẹsẹẹsẹ ori tẹlifiṣọn, fidio, ati akojọpọ iwe kíkà alaworan iṣekuṣe ti ń rẹninipowalẹ, eyi ti o wà kaakiri. Bi o tilẹ jẹ pe iwọnba kekere ninu awọn Kristian ni a nipa lé lori, a nilati gbà pe ọpọ julọ ninu awọn ọ̀ràn iyọnilẹgbẹ kuro ninu agbo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fun iwa aironupiwada ti kò yẹ Kristian ni ó tan mọ́ iru iwapalapala takọtabo kan. Ni ìhà ti ó dùn-ún gbọ́, ipin ti ó pọ̀ ninu awọn wọnni ti a yọlẹgbẹ ń mọ aṣiṣe wọn ní aṣiṣe lẹhin-ọ-rẹhin, ti wọn sì ń tún ọ̀nà igbesi-aye mímọ́ bẹrẹ, ati bi akoko ti ń lọ ti a ń gbà wọn pada sinu ijọ.—Fiwe Luku 15:11-32.

9. Bawo ni Satani ṣe ń fọgbọndari awọn alainiṣọọra?

9 Kò si tabi-tabi kankan pe Satani ń lọ kaakiri bii kinniun ti ń ké ramuramu kan, ti o ti wà ní sẹpẹ́ lati pa awọn ti kò ṣọra jẹ. Awọn ètekéte tabi “awọn ìṣe alárèékérekè” rẹ̀, ń dọdẹ mu awọn Kristian ti wọn kò ṣọra lọdọọdun. Ẹmi ayé rẹ̀ ti ó wà lọ́jọ́kọ́jọ́ jẹ́ onimọtara-ẹni-nikan, gbígbé-ayé-fún-afẹ́, ati oniwa-iṣekuṣe. O ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn ẹran-ara lọ́rùn. Ó kọ ikora-ẹni-nijaanu tì.—Efesu 2:1, 2; 6:11, 12, alaye ẹsẹ-iwe; 1 Peteru 5:8.

10. Awọn wo ni a lè ṣí silẹ si idẹwo, eesitiṣe?

10 Ta ni a lè ṣí silẹ ninu ijọ si awọn idẹwo iwapalapala? Ọpọ julọ awọn Kristian ni, yala wọn jẹ́ alagba ninu ijọ adugbo, alaboojuto arinrin-ajo, mẹmba idile Beteli, aṣaaju-ọna ti ń waasu fun ọpọlọpọ wakati loṣooṣu, awọn òbí ti ọwọ́ wọn dí fun gbigbe idile ró, tabi awọn ọ̀dọ́ eniyan ti ń dojukọ ikimọlẹ ojugba. Idẹwo ti ẹran-ara wọ́pọ̀ fun gbogbo eniyan. Òòfà ibalopọ takọtabo ni a lè tanna ràn nigba ti a kò reti rẹ̀ julọ. Nipa bayii Paulu lè kọwe pe: “Ẹni ti ó bá rò pe oun duro, ki o kiyesara, ki o má baà ṣubu. Kò sí idanwo kan ti o tii bá yin, bikoṣe iru eyi ti o mọniwọn fun eniyan [ọkunrin ati obinrin].” Ó dunni, ṣugbọn awọn Kristian kan ti wọn wà ninu ipo ẹ̀rú-iṣẹ́ ti juwọsilẹ fun ifanimọra iwapalapala yii.—1 Korinti 10:12, 13.

A Fà Wọn Lọ A Sì Tàn Wọn Jẹ

11-13. Awọn ipo wo ni o ti ṣamọna si iwapalapala?

11 Ki ni awọn idẹwo ati ipo ti ó ti ṣamọna awọn kan si ipa-ọna omugọ ti panṣaga ati agbere? Ọpọ ati olóríṣiríṣi apá ni wọn pín sí wọn sì lè yatọsira lati orilẹ-ede tabi iṣẹdalẹ kan si omiran. Bi o ti wu ki o ri, awọn ipo ipilẹ kan wà ti ń yọju ni ọpọlọpọ orilẹ-ede. Fun apẹẹrẹ, a rohin rẹ̀ pe awọn kan ti ṣeto awọn apejẹ nibi ti awọn ohun mimu líle ti wà larọọwọto fàlàlà. Awọn miiran ti nifẹẹ si orin ti ń fi èrò ibalopọ hàn ati ijó ti ayé ti ń runisoke. Ni awọn adugbo kan ni Africa, awọn ọkunrin ọlọ́rọ̀ wà—awọn alaigbagbọ—ti wọn ni awọn àlè; awọn obinrin kan ni a ti dẹwo lati wá aabo ti iṣunna-owo ninu iru ipo ti jíjẹ́ àlè àní bi o tilẹ ti jẹ́ pe ó wémọ́ iwapalapala. Ni awọn apa ibomiiran awọn Kristian ọkọ ti fi awọn idile wọn silẹ lati wá atijẹ ni ibi ìwakùsà tabi nibomiran. Nigba naa iduroṣinṣin ati iṣotitọ wọn ni a fi sinu idanwo dé iwọn kan tabi ni awọn ọ̀nà ti wọn kì bá tí niriiri rẹ̀ nile.

12 Ni awọn orilẹ-ede ti o ti goke àgbà awọn kan ti ṣubu sinu ikẹkun Satani nipa fifi ìgbà gbogbo wà pẹlu mẹmba ẹ̀yà odikeji laisi ẹnikẹta nibẹ—iru bii dídáwà papọ deedee ninu ọkọ̀ ayọkẹlẹ fun idanilẹkọọ lori ọkọ̀ wíwà.b Awọn alagba ti ń ṣe ikesini oluṣọ-agutan tún nilati lo iṣọra ki wọn má baa danikan wà pẹlu arabinrin kan nigba ti wọn bá ń gbà á nimọran. Awọn ijumọsọrọpọ lè di eyi ti ń ru ero-imọlara soke ki ó sì yọrisi ipo akotijubani fun tọtuntosi.—Fiwe Marku 6:7; Iṣe 15:40.

13 Awọn ipo ti a mẹnukan tán yii ti sún awọn Kristian kan lati dawọ wíwà lojufo duro ti wọn sì hu iwapalapala. Àní gẹgẹ bi o ti ṣẹlẹ ni ọrundun kìn-ín-ní, wọn ti fààyè gba araawọn lati di ẹni ti a dánwò ti ‘a sì fà lọ nipa ìfẹ́-ọkàn ẹran-ara tiwọn funraawọn,’ eyi ti ó ti ṣamọna si ẹṣẹ.—Jakọbu 1:14, 15; 1 Korinti 5:1; Galatia 5:19-21.

14. Eeṣe ti imọtara-ẹni-nikan fi jẹ́ kókó abajọ ti o wà nisalẹ awọn ọ̀ràn panṣaga?

14 Ayẹwo kínníkínní nipa awọn iyọnilẹgbẹ fihàn pe awọn iṣesi oniwapalapala ní awọn kókó abajọ wíwọ́pọ̀ kan bayii lábẹ́nú. Ninu iru awọn ọ̀ràn bẹẹ iru imọtara-ẹni-nikan kan wà. Eeṣe ti a fi sọ bẹẹ? Idi ni pe ninu awọn ọ̀ràn panṣaga, awọn alaimọwọmẹsẹ kan tabi ju bẹẹ lọ ni ọ̀ràn yoo baninujẹ. Ó lè jẹ́ alabaaṣegbeyawo-ẹni ti o bofinmu. Dajudaju yoo jẹ́ awọn ọmọ, bi eyikeyii bá wà, nitori bi panṣaga bá yọrisi ikọsilẹ, awọn ọmọ, ti wọn nifẹẹ si aabo idile ti ó sopọṣọkan, lè jiya ti ó pọ̀ julọ. Ẹni ti ó ṣe panṣaga naa ní ipo akọkọ ń ronu nipa igbadun ati anfaani tirẹ lọkunrin tabi lobinrin. Imọtara-ẹni-nikan niyẹn.—Filippi 2:1-4.

15. Ki ni ó ti lè jẹ́ diẹ ninu awọn okunfa ti ń ṣamọna si panṣanga?

15 Gẹgẹ bi o ti sábà maa ń rí panṣaga kìí ṣe iwa ailera ojiji. Ilọsilẹ diẹdiẹ, àní ti kò tilẹ ṣee fòyemọ̀ ninu igbeyawo naa funraarẹ ti wà. Boya ijumọsọrọpọ ti di alaijamọpataki tabi alaini abayọri ti o ṣe gunmọ. Ifunni niṣiiri tọtuntosi ti kò tó nǹkan ti lè wà. Ọkọọkan wọn ti lè foju tẹmbẹlu ẹnikeji. Tọkọtaya naa lè má ti maa tẹ́ araawọn lọ́rùn lọna ibalopọ takọtabo fun akoko kan. Dajudaju nigba ti panṣaga bá ṣẹlẹ, ipo-ibatan ti ń jo rẹhin pẹlu Ọlọrun ti wà. Jehofa ni a kò fòyemọ̀ ni kedere gẹgẹ bi Ọlọrun alààyè ti ó mọ gbogbo èrò ati iṣe mọ́. Ó tilẹ lè jẹ pe ni ọkàn panṣaga-ọkunrin naa, “Ọlọrun” ti di ọ̀rọ̀ lasan, olùwà kan ninu èrò lasan ti kìí ṣe apakan igbesi-aye ojoojumọ. Nigba naa ó di ohun ti ó tubọ rọrùn lati dẹṣẹ si Ọlọrun.—Orin Dafidi 51:3, 4; 1 Korinti 7:3-5; Heberu 4:13; 11:27.

Kọkọrọ naa si Idena

16. Bawo ni Kristian kan ṣe lè dena idẹwo lati jẹ́ alaiṣootọ?

16 Bi Kristian eyikeyii bá nilati rii ti a ń dẹ oun funraarẹ lọkunrin tabi lobinrin wo sinu oju-ọna aiṣotitọ, awọn kókó abajọ wo ni o nilati fi sọkan? Ṣaaju gbogbo rẹ̀, o nilati ronu lori itumọ ifẹ Kristian, ti a gbekari awọn ilana Bibeli lọna fifidimulẹ gbọnyingbọnyin. A kò nilati jẹ́ ki ifẹ ti ara-ìyára tabi eyi ti ń ru èrò ibalopọ takọtabo soke gbapo ki ó sì mú iṣubu sinu imọtara-ẹni-nikan yára kánkán, ní mimu ijiya wá fun awọn ẹlomiran. Kaka bẹẹ, ipo naa ni a nilati gbeyẹwo ni ọ̀nà ti Jehofa ń gbà wò ó. A nilati wò ó ninu ayika-ọrọ giga ju ti ijọ ati ẹgan ti iwa buburu yoo mú wa sori rẹ̀ ati sori orukọ Jehofa. (Orin Dafidi 101:3) Ìjábá ni a lè yẹra fun nipa níní èrò inu Kristi lori ọ̀ràn naa ati lẹhin naa ki a gbegbeesẹ bẹẹ gẹgẹ. Ranti, ifẹ alaimọtara-ẹni-nikan bii ti Kristi kò kuna rí lae.—Owe 6:32, 33; Matteu 22:37-40; 1 Korinti 13:5, 8.

17. Awọn apẹẹrẹ agbeniro ti iṣotitọ wo ni a ní?

17 Kọkọrọ kan si idena ni lati fun igbagbọ ati iriran ẹni nipa ireti ti ó wà niwaju lokun. Eyi tumọsi fifi awọn apẹẹrẹ ìpàwàtítọ́mọ́ titayọ tí awọn ọkunrin ati obinrin oluṣotitọ ìgbà laelae, ati Jesu funraarẹ, ti fi silẹ si apá oke julọ ninu ọkàn-àyà. Paulu kọwe pe: “Nitori naa, nigba naa, nitori a ní awọsanma ńlá bẹẹ ti awọn ẹlẹ́rìí yí wa ká, ẹ jẹ ki awa pẹlu mu gbogbo ẹrù-wíwúwo ati ẹṣẹ ti o lè fi tirọruntirọrun wépọ̀ mọ́ wa kuro, ẹ sì jẹ ki a fi ifarada sá ere-ije ti a gbé ka iwaju wa, gẹgẹ bi a ti ń tẹjumọ Olori Aṣoju ati Alaṣepe igbagbọ wa, Jesu. Nitori ayọ ti a gbé ka iwaju rẹ̀ ó farada igi oró, ó tẹmbẹlu itiju, ó sì ti jokoo ni ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun. Nitootọ, ẹ gbé e yẹwo finnifinni ẹni naa ti o ti farada iru ọ̀rọ̀ òdì bẹẹ lati ẹnu awọn ẹlẹṣẹ lodisi anfaani tiwọn funraawọn, ki ẹ má baa ṣaarẹ ki ẹ sì rẹwẹsi ninu ọkàn yin.” (Heberu 12:1-3, NW) Dipo fifi ọwọ́ ara-ẹni ri ọkọ̀ oju-omi ti igbeyawo, ọlọgbọn eniyan kan yoo ronu awọn ọ̀nà ti yoo gbà ṣatunṣe ibajẹ eyikeyii ki o baa lè gbà á pada, ni titipa bayii yẹra fun ọ̀fìn ti àdàkàdekè ati màgòmágó.—Jobu 24:15.

18. (a) Eeṣe ti àdàkàdekè kò fi jẹ́ ọ̀rọ̀ ti o lagbara jù kan lati ṣapejuwe panṣaga? (b) Oju wo ni Ọlọrun fi ń wo sísan ẹ̀jẹ́?

18 Ǹjẹ́ àdàkàdekè, eyi tíí ṣe aiṣododo si ilu ẹni, ha jẹ́ ọ̀rọ̀ kan ti ó lagbara jù nipa iwapalapala bi? Aiṣododo jẹ́ dída ìfọkàntánni tabi igbẹkẹleni. Dajudaju ẹ̀jẹ́ igbeyawo wémọ́ ìfọkàntánni ati ileri lati nifẹẹ ki a sì ṣìkẹ́, lójò-lẹ́ẹ̀rùn, la awọn akoko rere ati buburu já. Ó wémọ́ ohun kan ti awọn kan kà sí ohun ti kò bá ìgbà mu fun awọn akoko ti a ń gbé ninu rẹ̀—idaniloju ti a fifunni lati bọla funni ti a sọ ninu ẹ̀jẹ́ igbeyawo. Lati da ìfọkàntánni yẹn jẹ́ lati dá ẹṣẹ aiṣododo si ẹnikeji ẹni ninu igbeyawo. Oju ti Ọlọrun fi ń wo ẹ̀jẹ́ ni a sọ ni kedere ninu Bibeli: “Nigba ti iwọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fun Ọlọrun, maṣe duro pẹ́ lati san án: nitori kò ni inudidun si aṣiwere: san eyi ti iwọ jẹ́jẹ̀ẹ́.”—Oniwasu 5:4.

19. Ni iyatọ gédégédé si ki ni Satani ń yọ̀ nigba ti Ẹlẹ́rìí kan bá ṣubu?

19 Maṣe jẹ́ ki iyemeji kankan wà nipa rẹ̀. Gan-an gẹgẹ bi ayọ ńláǹlà ti wà ni ọrun lori igbala ẹlẹṣẹ kan, bẹẹ ni ayọ ńláǹlà wà lori ilẹ̀-ayé laaarin awọn agbo ẹgbàágbèje ti Satani, awọn ti ó ṣeefojuri ati awọn ti kò ṣeefojuri, nigba ti ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bá kùnà lati pa iwatitọ rẹ̀ mọ́ lọkunrin tabi lobinrin.—Luku 15:7; Ìfihàn 12:12.

Awọn Idẹwo ti O Wọ́pọ̀ fun Gbogbo Eniyan

20. Bawo ni a ṣe lè dena idẹwo? (2 Peteru 2:9, 10)

20 Iwapalapala ha jẹ́ ohun ti kò ṣeeyẹsilẹ ninu awọn ọ̀ràn kan bi? Ẹran-ara ati Satani ha lagbara tobẹẹ debii pe awọn Kristian kò lè dena ki wọn sì pa iwatitọ wọn mọ bi? Paulu funni ni iṣiri pẹlu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi: “Olododo ni Ọlọrun, ẹni ti kì yoo jẹ́ ki a dán yin wò ju bi ẹyin ti lè gbà; ṣugbọn ti yoo sì ṣe ọ̀nà àtiyọ pẹlu ninu idanwo naa, ki ẹyin ki o baa lè gbà á.” Ninu ayé ode-oni a kò lè yẹra fun idẹwo patapata, ṣugbọn nipa yiyiju si Ọlọrun ninu adura, dajudaju a lè farada a ki a sì ṣẹgun idẹwo eyikeyii.—1 Korinti 10:13.

21. Awọn ibeere wo ni a o dahun ninu ikẹkọọ wa ti yoo tẹle e?

21 Ki ni Ọlọrun fifun wa lati ràn wá lọwọ lati farada awọn idẹwo ki a sì kẹ́sẹjárí bi aṣẹgun? Ki ni a nilo lẹnikọọkan ki a baa lè daabobo igbeyawo wa, idile wa, ati ìfùsì orukọ Jehofa ati ti ijọ bakan naa? Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ wa ti o tẹle e yoo bojuto awọn ibeere wọnni.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “‘Àgbèrè’ ní ọ̀nà gbigbooro, ati gẹgẹ bi a ṣe lò ó ninu Matteu 5:32 ati 19:9, tọka dajudaju si ìlò gbigbooro ti ibalopọ takọtabo alaibofinmu tabi alaitẹlelana lẹhin ode igbeyawo. Porneia [ọ̀rọ̀ Griki naa ti a lò ninu awọn ẹsẹ-iwe mimọ wọnni] ní ninu ìlò (awọn) ẹ̀yà-ara ibimọ lọna aimọ ti o gadabú, ó kere tán ti eniyan kanṣoṣo (yala ni ọ̀nà ti ẹ̀dá tabi ni ọ̀nà òdì); pẹlupẹlu, ẹlomiran kan ti gbọdọ wà bi alajọpin iwa aimọ naa—eniyan kan yala ọkunrin tabi obinrin, tabi ẹranko kan.” (Ilé-Ìṣọ́nà, September 15, 1983, oju-iwe 30) Panṣaga: “Ibalopọ takọtabo ti a fínnú-fíndọ̀ ṣe laaarin ẹnikan ti ó ti gbeyawo ati ẹnikeji ti kìí ṣe ọkọ tabi aya ti ó bofinmu.”—The American Heritage Dictionary of the English Language.

b Ni kedere, awọn akoko ti o bojumu yoo wà nigba ti arakunrin kan yoo fi ọkọ̀ gbe arabinrin kan, iru awọn ipo bẹẹ ni a kò sì nilati ṣì lóye.

Iwọ Ha Ranti Bi?

◻ Ki ni awọn kókó abajọ diẹ ti ó ń ṣeranwọ lati fun igbeyawo lokun?

◻ Eeṣe ti a fi nilati sára fun oju-iwoye ayé nipa iwarere?

◻ Ki ni diẹ ninu awọn idẹwo ati ipo ti ó lè ṣamọna si iwapalapala?

◻ Ki ni kọkọrọ pataki julọ si didena ẹṣẹ?

◻ Bawo ni Ọlọrun ṣe ń ràn wá lọwọ ni awọn akoko idẹwo?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

AWỌN KÓKÓ ABAJỌ WIWỌPỌ NINU IGBEYAWO TI O TỌ́JỌ́

◻ Rírọ̀ timọtimọ mọ́ awọn ilana Bibeli

◻ Awọn alajọṣegbeyawo mejeeji ni ipo-ibatan lilagbara pẹlu Jehofa

◻ Ọkọ bọwọ fun aya rẹ̀, fun imọlara ati awọn èrò rẹ̀

◻ Ijumọsọrọpọ rere ti a ń ṣe lojoojumọ

◻ Wá ọ̀nà lati wu ẹnikinni keji

◻ Ero-imọlara ìdẹ́rìn-ín-pani; lílè fi ara-ẹni rẹ́rìn-ín

◻ Fi imuratan gba aṣiṣe; fi imuratan dariji

◻ Jẹ ki ifẹ elere-ifẹ maa baa lọ

◻ Ẹ wà ni iṣọkan ninu títọ́ awọn ọmọ ati bíbá wọn wí

◻ Didarapọ deedee ninu adura si Jehofa

AWỌN KÓKÓ ABAJỌ TI Ń SỌ IGBEYAWO DI ALAILAGBARA

◻ Imọtara-ẹni-nikan ati iṣorikunkun

◻ Kikuna lati ṣe awọn nǹkan papọ

◻ Ijumọsọrọpọ ti kò tó

◻ Aisi ifikunlukun ti ó tó laaarin awọn tọkọtaya

◻ Iṣabojuto ti kò dara tó nipa owó

◻ Iyatọsira ninu awọn ọpa-idiwọn idajọ ninu biba awọn ọmọ ati/tabi awọn ọmọ igbeyawo akọkọ lò

◻ Ki ọkọ maa pẹ́ nibi iṣẹ tabi ki o maa pa idile tì fun awọn ojuṣe miiran

◻ Ikuna lati bojuto awọn aini tẹmi idile

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Jijẹ ki igbeyawo ni ọlá ń mú ayọ pipẹtiti wa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́