ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 4/15 ojú ìwé 6-9
  • Ọrun-apaadi—Idaloro Ayeraye Tabi Sàréè Lápapọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọrun-apaadi—Idaloro Ayeraye Tabi Sàréè Lápapọ̀?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹkọ Àríkọ́gbọ́n Inú Èdè
  • Ṣiṣetumọ Apejuwe Iná Ọrun-Apaadi
  • Yíya Èjìrẹ́ Ẹkọ-Isin Nípa
  • Kí Ni Ọ̀run Àpáàdì Jẹ́ Gan-an?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ṣé Ọ̀run Àpáàdì Wà Lóòótọ́? Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọ̀run Àpáàdì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kí Ni Jésù Fi Kọ́ni Nípa Ọ̀run Àpáàdì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Kí Ló Ti Ṣẹlẹ̀ sí Iná Ọ̀run Àpáàdì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 4/15 ojú ìwé 6-9

Ọrun-apaadi—Idaloro Ayeraye Tabi Sàréè Lápapọ̀?

AHA ti sọ fun ọ pe awọn Baba Ṣọọṣi ijimiji, awọn ẹlẹkọọ-isin ọrundun agbedemeji, ati awọn Alatun-un-ṣe jiyan pe awọn idaloro ti a ń niriiri ninu ọrun-apaadi jẹ́ ainipẹkun bi? Bi o bá rí bẹẹ, ó lè yà ọ́ lẹnu lati mọ̀ pe awọn ọmọwe Bibeli kan ti a kà sí gidigidi ti ń gbé ipenija dide si oju-iwoye yẹn nisinsinyi. Ni Britain, ọ̀kan ninu wọn, John R. W. Stott, kọwe pe, “Iwe Mimọ tọka siha iparun-raurau, ati pe ‘idaloro ti a mọlara titi ayeraye’ jẹ́ igbagbọ-atọwọdọwọ ti ó nilati fààyè silẹ fun ọla-aṣẹ onipo-ajulọ ti Iwe Mimọ.”—Essentials—A Liberal-Evangelical Dialogue.

Ki ni o sun un lati pari ero pe idaloro ainipẹkun ni a kò gbekari Bibeli?

Ẹkọ Àríkọ́gbọ́n Inú Èdè

Alaye rẹ̀ akọkọ wemọ èdè. Ó ṣalaye pe nigba ti Bibeli bá tọka si ipo idalẹbi ikẹhin (“Gehenna”; wo apoti, oju-iwe 8), ó sábà maa ń lo awọn ọ̀rọ̀ “iparun,” “ọ̀rọ̀-ìṣe” Griki naa “apollumi (lati parun) ati ọ̀rọ̀-orukọ naa apòleia (iparun).” Ǹjẹ́ awọn ọ̀rọ̀ wọnyi ha tọka si idaloro bi? Stott ṣalaye pe nigba ti ọ̀rọ̀-ìṣe naa bá jẹ́ taarata ti o sì nilo ọ̀rọ̀ olùfaragbà, “apollumi” tumọsi “pa.” (Matteu 2:13; 12:14; 21:41) Nipa bayii, ni Matteu 10:28, nibi ti itumọ ti King James Version ti mẹnukan pípa ti Ọlọrun pa “ara ati ọkàn run ni ọrun-apaadi,” èrò ti ó wà nibẹ niti gidi ni piparun ninu ikú, kìí ṣe ninu ijiya ayeraye. Ni Matteu 7:13, 14, Jesu ṣe iyatọ ifiwera ‘oju-ọna tóóró, ti ó lọ si ibi ìyè’ pẹlu ‘oju-ọna gbòòrò . . . ti o lọ si ibi iparun.’ Stott ṣalaye pe: “Yoo ṣajeji, nigba naa, bi a kò bá pa awọn eniyan ti a sọ pe wọn jiya iparun run nitootọ.” Pẹlu idi rere ó dé ipari-ero naa pe: “Bi pípa bá jẹ́ lati fi iwalaaye du ara, o hàn gbangba pe ọrun-apaadi yoo jẹ́ ìfìwàláàyè ti ara-ìyára ati tẹmi duni, iyẹn ni pe, iparẹ-raurau ẹ̀dá.”—Essentials, oju-iwe 315 si 316.

Ṣiṣetumọ Apejuwe Iná Ọrun-Apaadi

Sibẹ, ọpọ awọn onisin yoo fohunṣọkan pẹlu ààrẹ Eto-ajọ Ijọ-onitẹbọmi ti iha Guusu Morris H. Chapman, ẹni ti o sọ pe: “Mo waasu ọrun-apaadi gidi kan.” Ó fikun un pe: “Bibeli pè é ni ‘adagun ina,’ emi kò sì ronu pe a lè tun itumọ rẹ̀ sọ dara ju iyẹn lọ.”

Ki a gbà bẹẹ, apẹẹrẹ iná ti a lò ninu Bibeli lè ru aworan idaloro niti ero-ori yọ. Bi o ti wu ki o ri, iwe naa Essentials sọ ọ́ di mimọ pe: “Kò si iyemeji pe ó jẹ́ nitori pe gbogbo wa ti ní iriri irora lilegbakan ti ki nǹkan joni, pe iná ni isopọ pẹlu ‘idaloro ti a mọ̀lára ninu ero-inu wa.’ Ṣugbọn lajori ìlò iná kìí ṣe lati ṣokunfa irora, ṣugbọn lati mú iparun wá, gẹgẹ bi gbogbo awọn ilé ti a ti ń sun ohun deérú lagbaaye ti jẹrii si i.” (Oju-iwe 316) Fifi iyatọ gédégédé yẹn sọkan yoo ràn ọ́ lọwọ lati yẹra fun wíwá itumọ kan ti kò si nibẹ niti gidi fun Iwe Mimọ. Awọn apẹẹrẹ diẹ:

Nipa awọn wọnni ti a gbé sọ sinu Gehenna, Jesu sọ pe “kokoro wọn kìí kú, . . . iná naa kìí sìí kú.” (Marku 9:47, 48) Bi awọn ọ̀rọ̀ ti o wà ninu iwe Judith inu awọn iwe kíkọ ti kìí ṣe ojulowo-otitọ, (“Oun yoo rán iná ati ìdin sinu ẹran-ara wọn wọn yoo sì sunkun fun irora titi laelae.”—Judith 16:17, The Jerusalem Bible) ti nipa lori wọn, awọn àlàyé Bibeli kan jiyan pe awọn ọ̀rọ̀ Jesu dọgbọn tumọsi idaloro ayeraye. Sibẹ, iwe Judith inu awọn iwe kíkọ ti kìí ṣe ojulowo-otitọ, ti kò ni ìmísí Ọlọrun, ni ó ṣoro lati jẹ́ ọpa-idiwọn fun pipinnu itumọ awọn ikọwe Marku. Isaiah 66:24, iwe mimọ ti Jesu sọrọ bá lọna ti o ṣe kedere, sọ pe iná ati ìdin naa ń jẹ ara òkú (“awọn ẹ̀kùrẹ̀,” ni Isaiah sọ) awọn ọ̀tá Ọlọrun run. Kò sí isọfunni nipa idaloro ainipẹkun ti a mọlara ninu yala awọn ọ̀rọ̀ Isaiah tabi ti Jesu wọnni. Apejuwe iná ṣapẹẹrẹ iparun patapata.

Ìfihàn 14:9-11 sọrọ nipa awọn kan ti a “fi iná ati sulfuru dá . . . lóró . . . Èéfín oró wọn sì ń lọ soke titi laelae.”a Eyi ha fi idaloro ayeraye ti a mọlara ninu iná orun-apaadi hàn bi? Niti gasikiya, gbogbo ohun ti ayọka yii sọ ni pe awọn ẹni buburu ni a daloro, kìí ṣe pe a dá wọn lóró titi lae. Ọ̀rọ̀ ẹsẹ-iwe naa sọ pe èéfín wọn—ẹ̀rí pe iná naa ti ṣe iṣẹ iparun rẹ̀—ni o ń baa lọ laelae, kìí ṣe idaloro oníná naa.

Ìfihàn 20:10-15 sọ pe ninu “adagun iná ati sulfuru, a o . . . maa dá wọn lóró tọ̀sántòru lae ati laelae.” Nigba ti a bá kọkọ kà á, eyi lè dún bi ẹ̀rí nipa idaloro ayeraye ti a mọ̀lára nipasẹ iná, ṣugbọn kìí ṣe bẹẹ ni pàtó. Eeṣe? Lara awọn idi miiran ti o wa, “ẹranko ati wolii èké” ati “iku ati ipo-oku” yoo wá sopin ninu ohun ti a pè ni “adagun iná” nihin-in. Gẹgẹ bi o ti lè fi tirọruntirọrun pari-ero, ẹranko, wolii èké, iku, ati ipo-oku kìí ṣe eniyan gidi; nitori naa, wọn kò lè niriiri idaloro ti a mọ̀lára. Kaka bẹẹ, ni G. B. Caird kọwe ninu A Commentary on the Revelation of St. John the Divine, “adagun iná” tumọsi “iparẹ-raurau ati igbagbe patapata.” Òye yii ni o nilati rọrun fun wa lati ni, nitori pe Bibeli funraarẹ sọ nipa adagun iná yii pe: “Adagun iná. Eyi ni iku keji.”—Ìfihàn 20:14.

Yíya Èjìrẹ́ Ẹkọ-Isin Nípa

Laika awọn alaye wọnyi si, ọpọ awọn onigbagbọ tẹpẹlẹ mọ ọn pe “iparun” kò tumọ si ohun ti ọ̀rọ̀ naa sọ ṣugbọn ó tumọ si idaloro ayeraye. Eeṣe? Ironu wọn ni èjìrẹ́ iná ọrun-apaadi ti isin—ẹkọ aileku ọkàn ẹda eniyan nipa le lori. Ati niwọn bi o ti lè jẹ pe ṣọọṣi wọn ti mú awọn èjìrẹ́ wọnyi dagba fun ọpọ ọrundun, wọn le nimọlara pe awọn ọrọ ẹsẹ-iwe ti o sọ nipa iparun niti gasikiya tumọ si idaloro ayeraye. Ó ṣetan, ọkàn ẹ̀dá eniyan ti kò lè kú kò lè ṣíwọ́ lati maa walaaye—tabi bẹẹ kọ ni ni ọpọlọpọ ti ronu.

Ṣugbọn ṣakiyesi koko ti alufaa-ṣọọṣi Anglican Philip E. Hughes sọ: “Lati jiyan pe kìkì ọkàn ẹ̀dá eniyan ni a bí pẹlu aileku jẹ́ lati di ipo kan ti a kò tẹwọgba nibikankan ninu ẹkọ Iwe Mimọ mú, nitori pe ninu ìfàwòránhàn ti Bibeli irisi ẹ̀dá eniyan ni a sábà maa ń rí gẹgẹ bi apapọ apa ti tẹmi ati ti ara. . . . Ikilọ Ọlọrun ni ibẹrẹ, nipa igi ti a kaleewọ naa, ‘Ni ọjọ ti iwọ bá jẹ ninu rẹ̀ kiku ni iwọ o kú,’ ni a sọ ni taarata si eniyan gẹgẹ bi iṣẹda ara-oun-ẹmi kan—bi oun bá nilati jẹ ninu rẹ̀, bẹẹ gan-an ni ó rí pe oun yoo kú lọna ti ara-oun-ẹmi. Kò si idamọran pe apa kan rẹ̀ jẹ́ alaileku ati nitori naa pe kiku rẹ̀ yoo jẹ́ ni kìkì apakan.”—The True Image—The Origin and Destiny of Man in Christ.

Bakan naa, ẹlẹkọọ-isin Clark Pinnock sọ pe: “Èrò yii [pe ọkàn ẹ̀dá eniyan jẹ́ alaileku] ti nipa lori ẹkọ-isin tipẹ, tipẹ sẹhin ṣugbọn kò bá Bibeli mu. Bibeli kò fi aileku adanida ti ọkàn kọni.” Esekieli 18:4, 20 ati Matteu 10:28 jẹrii si eyi. Ju bẹẹ lọ, Jesu funraarẹ sọrọ nipa ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lasaru ti o kú gẹgẹ bii pe ó ‘lọ sinmi,’ tabi sun. Jesu sọ pe oun ń lọ “jí i dide ninu oorun.” (Johannu 11:11-14) Nitori naa, ẹ̀dá eniyan, tabi ọkàn eniyan, Lasaru ti kú, ṣugbọn lẹhin ìgbà ti akoko diẹ ti kọja paapaa, oun ni a lè jí dide, mú pada wá si ìyè lẹẹkan sii. Awọn otitọ fi iyẹn hàn. Jesu jí Lasaru dide kuro ninu oku.—Johannu 11:17-44.

Bawo ni awọn koko wọnyi ṣe nipa lori ẹkọ idaloro ayeraye? Lẹhin lọhun-un ni ọrundun kẹtadinlogun, aláròkọ William Temple ṣakiyesi pe: “[Awọn iwe mimọ] ti o sọrọ nipa didi ẹni ti a gbé sọ sinu iná ti ń jó àjóòkú wà. Ṣugbọn bi a kò bá koju iwọnyi pẹlu ìtànmọ́ ọ̀n ṣaaju naa pe ohun ti a tipa bayii gbé sọ sinu rẹ̀ jẹ́ alaileeparun, a o ní aworan ero-inu naa, kìí ṣe pe yoo jó titi lae, ṣugbọn pe a o pa a run.” Alaye titọna yẹn ṣì jẹ́ otitọ sibẹ, nitori pe ó jẹ́ ohun ti Bibeli fi kọni niti gasikiya.

Lọna ti kò ṣeésẹ́, iwọ ni awọn idi amunilapapandodo lati gbé ibeere dide si èrò nipa idaloro ayeraye ti a mọ̀lára ninu ọrun-apaadi. Tabi boya iwọ fẹ lati lọ rekọja wiwulẹ gbe ibeere dide ki o sì tẹle amọran ọjọgbọn ẹkọ-isin Pinnock, ẹni ti o sọ pe: “Gbogbo àgbájọ igbagbọ ti o rọ̀gbà yi ọrun-apaadi ká, ti o ní idaloro ailopin ninu, . . . ni a nilati jájùsílẹ̀ lori ipilẹ ẹkọ ti o yèkooro.” Bẹẹni, ọna-iwahihu, idajọ-ododo, ati—eyi ti o ṣe pataki julọ—Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, sọ fun ọ lati ṣe iyẹn gan-an.

Bi iwọ bá ṣe bẹẹ, iwọ yoo rí i pe irisi tootọ nipa ọrun-apaadi jẹ́ ohun ti o ṣeégbàgbọ́ nitootọ. Iwọ lè rí isọfunni ti ń ranni lọwọ lori akori yii ninu iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.b Jọwọ beere fun un nigba ti o bá bá awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pade. Ka awọn akori naa “Kinni Nṣẹlẹ Nigba Iku?” “Iru Ibo Ni Hell Jẹ?” ati “Ajinde—Fun Tani, ati Nibo?” Iwọ yoo lóye pe irisi tootọ nipa ọrun-apaadi kìí ṣe ohun ti o ṣeégbàgbọ́ nikan ṣugbọn ó jẹ́ afunni nireti pẹlu.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ninu ayọka Bibeli yii, ‘fi iná daloro’ ni ipilẹ tọka si idaloro tẹmi, sibẹ ti o ni ipẹkun. Fun awọn kulẹkulẹ siwaju sii, wo iwe Revelation—Its Grand Climax At Hand! ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

b A tẹ̀ ẹ́ jade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

ṢIṢETUMỌ AWỌN EDE-ISỌRỌ NAA

Ninu ọrọ-ẹkọ yii awọn ede-isọrọ naa “ọrun-apaadi” ati “iná ọrun-apaadi” gẹgẹ bi awọn ẹlẹkọọ-isin ninu Kristẹndọm ti lò ó tọka si ọ̀rọ̀ Griki naa geʹen·na, eyi ti o farahan ni ìgbà 12 ninu “Majẹmu Titun.” (Matteu 5:22, 29, 30; 10:28; 18:9; 23:15, 33; Marku 9:43, 45, 47; Luku 12:5; Jakọbu 3:6) Bi o tilẹ jẹ pe oniruuru itumọ Bibeli tumọ ọ̀rọ̀ Griki yii si “ọrun-apaadi,” awọn itumọ miiran lo ìtumọ̀-àyálòpalẹ́tàdà rẹ̀ “Gehenna.” Ó baradọgba pẹlu ‘ikú keji, adagun ina,’ apẹẹrẹ iparun ainipẹkun ti a rí ninu iwe ti o kẹhin Bibeli.—Ìfihàn 20:14.

Nipa awọn ọ̀rọ̀ meji yooku ti a maa ń tumọ nigba miiran si “ọrun-apaadi,” A Dictionary of the Bible (1914), ti a tẹ̀ lati ọwọ William Smith, ṣakiyesi pe: “Ọrun-apaadi . . . ni ọ̀rọ̀ ti a maa ń lò ni gbogbogboo ti o sì dunni pe awọn olutumọ wa lò lati tumọ èdè Heberu naa Sheol. Boya ìbá ti sàn jù lati jẹ ki ó wà ni ọ̀rọ̀ Heberu naa Sheol, bi bẹẹ sì kọ́ ki a tú u si ‘sàréè’ tabi ‘ihò’ nigba gbogbo. . . . Ninu M[ajẹmu] T[itun], ọ̀rọ̀ naa Hades, bii Sheol, nigba miiran wulẹ tumọsi ‘sàréè’ . . . Ni ero-itumọ yii ni awọn ijẹwọ-igbagbọ fi sọ nipa Oluwa wa pe ‘Ó lọ si isalẹ sinu ọrun-apaadi,’ ti o tumọ si ipo awọn oku ni gbogbogboo.”

Laidabi Gehenna, eyi ti o famiṣapẹẹrẹ iparun ikẹhin, Sheol ati Hades tọka si iku ninu sàréè gbogbo araye, pẹlu ireti didi ẹni ti a ji dide si ìyè lẹẹkan sii.—Ìfihàn 20:13.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Jesu jí Lasaru dide kuro ninu oorun iku

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́