Ìlò ati Aṣilo Awọn Aworan Isin
IBI iran naa ni St. Petersburg, Russia. Ọjọ naa ni August 2, 1914. Awọn eniyan ti a ti ru imọlara wọn soke ti wọn ń ju aworan isin yẹbẹyẹbẹ ti padepọ ní aafin olu-ọba. Pẹpẹ kan ni a ti kọ́ saaarin gbungbun gbọngan titobi kan. Aworan obinrin ti o gbé ọmọ kan dani duro lori pẹpẹ naa. Aworan isin yii ni a ń pè ní “Vladimir Iya Ọlọrun.” Awọn awujọ naa wò ó gẹgẹ bi ìṣúra mimọ julọ ní Russia.
Niti tootọ, aworan isin naa ni a gbagbọ pe o ń ṣiṣẹ iyanu. Ní 1812, nigba ti awọn ọmọ ogun ilẹ̀ Russia gbógunti Napoléon, Ọgagun Kutuzov gbadura niwaju rẹ̀. Nisinsinyi, lẹhin pipaṣẹ fun orilẹ-ede rẹ̀ lati jagun, Czar Nicholas II duro niwaju rẹ̀. Pẹlu ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti o gbe soke, o ṣe ibura kan pe: “Mo fi tọkantọkan bura pe emi ki yoo jẹ ki alaafia ki o wà lae niwọn bi ọ̀tá kanṣoṣo bá ṣì ṣẹ́kù sori ilẹ̀ Russia.”
Ni ọ̀sẹ̀ meji lẹhin naa olu-ọba naa rinrin-ajo lọ si ibujọsin ni Moscow lati wá ibukun Ọlọrun sori ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ. Ni Cathedral ti Igbalọsoke-ọrun, o kunlẹ o si gbadura niwaju ògiri alaworan isin oniwura titobi naa—ògiri kan ti o ní awọn aworan Jesu, Maria, angẹli, ati ti “awọn ẹni mimọ” lara.
Awọn iṣarasihuwa ti isin wọnyi kùnà lati mú ìjábá kuro. Ni eyi ti o din si ọdun mẹrin, awọn ọmọ-ogun Russia jiya ohun ti o ju ikú million mẹfa ti wọn sì padanu ipinlẹ pupọ. Siwaju sii, olu-ọba naa, aya rẹ̀, ati awọn ọmọ wọn marun-un ni a ṣekupa lọna ika-onroro. Dipo iṣakoso ọlọba ti o ti pẹ́ tó ọpọ ọrundun naa, orilẹ-ede naa ni ijọba olufẹ iyipada ti o tako isin bẹrẹ sii ṣakoso. Igbẹkẹle Czar Nicholas ninu awọn aworan isin jásí asán.
Sibẹ, titi di oni yii ní Russia ati ni awọn ilẹ̀ miiran, araadọta-ọkẹ ṣì ń baa lọ lati maa bọ̀wọ̀ nla fun awọn aworan isin. Eyi gbé awọn ibeere pataki dide. Bawo ni Ọlọrun ṣe wo awọn iṣe ifọkansin ti a ṣe niwaju iru awọn aworan bẹẹ? Ki sì ni nipa àṣà siso wọn kọ́ sara ògiri ninu ilé?
Ki Ni Ohun ti Bibeli Sọ?
Nigba ti Jesu wà lori ilẹ̀-ayé, o ṣegbọran si Ofin Ọlọrun ti a fifunni nipasẹ Mose. Eyi ní ninu ekeji ohun ti a pè ní Ofin Mẹwaa, eyi ti o sọ pe: “Iwọ kò gbọdọ yá ère fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti ń bẹ loke ọrun, tabi ti ohun kan ti ń bẹ ni isalẹ ilẹ, tabi ti ohun kan ti ń bẹ ninu omi ni isalẹ ilẹ. Iwọ kò gbọdọ tẹ ori ara rẹ ba fun wọn, bẹẹ ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn: nitori emi ni OLUWA Ọlọrun rẹ̀, Ọlọrun owú ni mi.”—Eksodu 20:4, 5.
Ni ibamu pẹlu eyi, Jesu kò jọsin Ọlọrun pẹlu aranṣe awọn aworan tabi ère ti a fi ọwọ́ eniyan ṣe. Kaka bẹẹ, ijọsin rẹ̀ wà ní ibamu pẹlu ipolongo Baba rẹ̀ pe: “Emi ni Oluwa: eyi ni orukọ mi: ògo mi ni emi kì yoo fi fun ẹlomiran, bẹẹ ni emi kì yoo fi ìyìn mi fun ère gbígbẹ́.”—Isaiah 42:8.
Siwaju sii, Jesu ṣalaye idi rẹ̀ ti a fi nilati jọsin Ọlọrun laisi aranṣe awọn ohun ti a fọwọ ṣe. “Ṣugbọn wakati ń bọ̀,” ni ó sọ “ó sì dé tán nisinsinyi, nigba ti awọn olusin tootọ yoo maa sin Baba ni ẹmi ati ni otitọ: nitori iru wọn ni Baba ń wá ki o maa sin oun. Ẹmi ni Ọlọrun: awọn ẹni ti ń sin in kò lè ṣe alaisin in ni ẹmi ati ní otitọ.”—Johannu 4:23, 24.
Bii ti Jesu, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tootọ kọ́ awọn miiran ni ọ̀nà títọ́ lati jọsin. Fun apẹẹrẹ, aposteli Paulu nigbakan rí bá awujọ awọn ọmọran Griki ti wọn ń lo ère lati jọsin awọn ọlọrun wọn ti kò ṣeefojuri sọrọ. O sọ fun wọn nipa Ẹlẹ́dàá eniyan o si sọ pe: “Kò yẹ fun wa ki a rò pe, Iwa-Ọlọrun dabi wura, tabi fadaka, tabi okuta, ti a fi ọgbọ́n ati ihumọ eniyan ṣe ni ọnà.” Lẹhin naa, aposteli kan-naa ṣalaye pe awọn Kristian ‘ń rin nipa igbagbọ, kìí ṣe nipa riri’ ati pe awọn Kristian nilati “sá fun ibọriṣa.”—Iṣe 17:16-31; 2 Korinti 5:7; 1 Korinti 10:14.
Iriri kan ninu igbesi-aye aposteli Peteru fihàn pe oun yára lati ṣatunṣe ihuwa eyikeyii ti o lè ṣamọna si ibọriṣa. Nigba ti ọ̀gá ologun Romu naa Korneliu wólẹ̀ ni ẹsẹ̀ rẹ̀, Peteru kọ̀. O gbé Korneliu soke, ni sisọ pe: “Dide; eniyan ni emi tikaraami pẹlu.”—Iṣe 10:26.
Nipa ti aposteli Johannu, awọn iran atọrunwa mu un kun fun ibẹru tobẹẹ gẹẹ ti oun fi wólẹ̀ ni ẹsẹ̀ angẹli kan. “Wò ó,” ni angẹli naa fun un ni imọran. “Maṣe bẹẹ: iranṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ ni emi, ati ti awọn arakunrin rẹ wolii, ati ti awọn ti ń pa ọ̀rọ̀ inu iwe yii mọ́: foribalẹ fun Ọlọrun.” (Ìfihàn 22:8, 9) Aposteli naa mọriri imọran yii. Pẹlu ifẹ, o ṣakọsilẹ iṣẹlẹ naa fun anfaani wa.
Ṣugbọn bawo ni awọn iriri òkè wọnyi ṣe tanmọ ìlò awọn aworan ijọsin? O dara, bi kò bá tọ́ fun Korneliu lati tẹriba fun ọ̀kan ninu awọn aposteli Kristi, ki ni nipa bibọwọ nla fun aworan alailẹmii ti “awọn ẹni mimọ”? Bi kò bá sì tọ́ fun ọ̀kan ninu awọn aposteli Kristi lati foribalẹ niwaju angẹli kan ti o walaaye, nigba naa ki ni nipa bibọwọ nla fun aworan alailẹmii ti awọn angẹli? Dajudaju, iru ihuwa bẹẹ lodisi ikilọ Johannu pe: “Ẹyin ọmọ mi, ẹ pa ara yin mọ́ kuro ninu oriṣa.”—1 Johannu 5:21.
Gẹgẹ bi Aranṣe Ikọnilẹkọọ Ti A Lè Fi Ṣẹ̀ṣọ́
Eyi kò tumọsi pe wiwulẹ ni aworan ibi iṣẹlẹ Bibeli kan jẹ́ ibọriṣa. Iwe-irohin yii ń lo aworan awọn iṣẹlẹ inu Bibeli daradara gẹgẹ bi aranṣe ikọnilẹkọọ. Bakan naa, aworan awọn ibi iṣẹlẹ inu Bibeli ni a lè lò lati fi ṣe awọn ògiri ibugbe ati ilé lọ́ṣọ̀ọ́. Sibẹ, Kristian tootọ kan kì yoo fẹ́ lati ṣaṣefihan aworan kan ti oun mọ̀ pe awọn miiran ń bọ̀wọ̀ nla fun, bẹẹ ni oun kì yoo gbe aworan ti o ṣi Bibeli loye kọ́ sara ògiri rẹ̀.—Romu 14:13.
Ọpọ julọ ninu awọn aworan isin Kristẹndọm fi òbìrí ìmọ́lẹ̀ hàn yika ori Jesu, Maria, angẹli, ati “awọn ẹni mimọ.” Eyi ni a ń pè ní ìmọ́lẹ̀-ògo. Nibo ni ìmọ́lẹ̀-ògo ti pilẹṣẹ? “Ipilẹṣẹ rẹ̀ kìí ṣe ti Kristian,” ni iwe gbédègbẹ́yọ̀ The Catholic Encyclopedia (itẹjade 1987) jẹwọ, “nitori pe awọn oníṣẹ́-ọnà ati awọn agbẹ́gilére abọriṣa lò ó lati fi ami-apẹẹrẹ ṣoju fun iyì-ọlá ati agbara nla awọn oniruuru ọlọrun ajọsinfun.” Siwaju sii, iwe naa The Christians, lati ọwọ́ Bamber Gascoigne, ní aworan kan ninu ti a mu lati inu Ibi-àkójọ-ohun-ìṣẹ̀ǹbáyé Capitoline ní Romu nipa ọlọ́run-oòrùn kan ti o ní ìmọ́lẹ̀-ògo. Awọn abọriṣa Romu ni wọn ń jọsin ọlọrun yii. Lẹhin naa, Gascoigne ṣalaye pe, “ìmọ́lẹ̀-ògo oòrùn” ni “isin Kristian yálò.” Bẹẹni, ìmọ́lẹ̀-ògo naa ni isopọ pẹlu ijọsin oòrùn nipasẹ awọn abọriṣa.
Ǹjẹ́ awọn aworan ti o da awọn iṣẹlẹ inu Bibeli pọ̀ mọ́ ami-apẹẹrẹ ijọsin ère oloriṣa ha yẹ lati di eyi ti a gbékọ́ sara ògiri ilé Kristian kan bi? Rara. Bibeli gbaninimọran pe: “Irẹpọ ki ni tẹmpili Ọlọrun sì ni pẹlu oriṣa? . . . Nitori naa ẹ jade kuro laaarin wọn, ki ẹ sì ya ara yin si ọ̀tọ̀, ni Oluwa wi, ki ẹ maṣe fi ọwọ́ kan ohun aimọ; emi o sì gbà yin.”—2 Korinti 6:16, 17.
Bi akoko ti ń lọ, awọn Kristian alafẹnujẹ bẹrẹ sii gbojufo iru imọran bẹẹ dá. Ipẹhinda dide, bi Jesu ati awọn aposteli rẹ̀ ti sọtẹlẹ. (Matteu 24:24; Iṣe 20:29, 30; 2 Peteru 2:1) Ni kutukutu ọrundun kẹrin C.E., olu-ọba Romu Constantine sọ isin Kristian apẹhinda di isin Orilẹ-ede. Nisinsinyi ọpọ yanturu awọn abọriṣa polongo araawọn ní “Kristian.” Aṣa kan ti o wọpọ laaarin wọn jẹ ijọsin awọn aworan olu-ọba. Wọn tún maa ń gbe aworan awọn baba-nla wọn ati ti awọn eniyan olokiki miiran kọ́ sara ògiri pẹlu. “Ni iṣọkan pẹlu isin-awo olu-ọba,” ni John Taylor ṣalaye ninu iwe rẹ̀ Icon Painting, “awọn eniyan ń jọsin aworan rẹ̀ ti a yà sara aṣọ gbigbopọn ati igi, iwọnba sì ni alafo ti o wà laaarin ijọsin olu-ọba ati ijọsin awọn aworan isin.” Nipa bayii, ijọsin oloriṣa ti awọn aworan ni a fi kikunlẹbọ awọn aworan Jesu, Maria, angẹli ati “awọn ẹni mimọ” rọ́pò rẹ̀.
Bawo Ni Awọn Aṣaaju Isin Ṣe Dá Eyi Lare?
Gẹgẹ bi iwe gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion ṣe sọ, awọn aṣaaju isin lo ìjiyàn atijọ kan-naa gẹgẹ bi awọn ọmọran oloriṣa ti ṣe. Awọn ọkunrin bii Plutarch, Dio Chrysostom, Maxim ará Tire, Celsus, Porphyry, ati Julian gbà pe awọn ère jẹ alailẹmii. Ṣugbọn awọn abọriṣa wọnyi da ìlò ère lare nipa jijiyan pe iwọnyi jẹ aranṣe fun jijọsin awọn ọlọrun wọn alaiṣeefojuri. Oluṣe aworan isin ọmọ ilẹ̀ Russia naa Leonid Ouspensky gbà ninu iwe naa The Meaning of Icons pe: “Awọn Baba Ṣọọṣi lo irinṣẹ́ imọ-ọran Griki, ni titẹwọgba òye ati èdè rẹ̀ wọnu ẹ̀kọ́-ìsìn Kristian.”—Fiwe Kolose 2:8.
Ọpọ eniyan ri idalare ikunlẹbọ awọn aworan lọna ti ẹ̀kọ́-ìsìn gẹgẹ bi eyi ti o ṣoro lati loye. “Iyatọ laaarin jijọsin aworan isin kan nitori ohun ti o lè duro fun, tabi jijọsin rẹ̀ funraarẹ . . . ti kereju lati fihàn lati ọwọ́ ẹnikẹni ayafi awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìwé giga,” ni John Taylor sọ ninu iwe Icon Painting.
Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, ohun ti Bibeli sọ nipa awọn aworan isin rọrun lati loye. Ronu nipa Emilia, ti ń gbe ní Johannesburg, South Africa. Oun jẹ Katoliki olufọkansin kan ti o maa ń kunlẹ ti o sì ń gbadura niwaju awọn aworan. Lẹhin naa, ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ilẹ̀kùn rẹ̀. O layọ gidigidi lati rii ninu Bibeli Lédè Potogi pe Ọlọrun ní orukọ, Jehofa. (Orin Dafidi 83:18, Almeida) Ninu ikẹkọọ Bibeli rẹ̀, o beere pe: “Ki ni ohun ti mo nilati ṣe lati yẹra fun ṣiṣaimu inu Jehofa dùn?” Ẹlẹ́rìí naa tọkasi awọn aworan ti o gbékọ́ sara ògiri rẹ̀ o sì sọ pe ki o ka Orin Dafidi 115:4-8. Ni alẹ́ yẹn nigba ti ọkọ Emilia wá sile, o sọ fun un pe oun fẹ́ lati mu awọn aworan isin rẹ̀ kuro. O fohunṣọkan. Ni ọjọ keji, o mu ki awọn ọmọkunrin rẹ̀ meji, Tony ati Manuel, fọ́ awọn aworan naa si wẹ́wẹ́ ki wọn si jó wọn. Lonii, ni nǹkan bi ọdun 25 lẹhin naa, Emilia ha ni àbámọ̀ eyikeyii nipa eyi bi? Rara. Niti tootọ, papọ pẹlu idile rẹ̀, oun ti ran ọpọ ninu awọn aladuugbo rẹ̀ lọwọ lati di olujọsin Jehofa alayọ.
Iru awọn iriri ti o jọ eyi ni a ti tunsọ lọpọ ìgbà. Gẹgẹ bi abajade iṣẹ sisọni di ọmọ-ẹhin kari-aye ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, araadọtaọkẹ ń kẹkọọ lati jọsin Ọlọrun “ni ẹmi ati ni otitọ.” Iwọ pẹlu lè niriiri awọn ibukun lati inu ọ̀nà ijọsin titayọ yii nitori pe, gẹgẹ bi Jesu ti sọ, “iru wọn ni Baba ń wá ki o ma sin oun.”—Johannu 4:23, 24.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Czar Nicholas II ń fi aworan isin súre fun awọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ̀
[Credit Line]
Fọ́tò lati ọwọ́ C.N.