Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
Ailabosi Fi Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa Hàn Lọna Rere
AILABOSI jẹ́ ohun pataki ti a beere fun lọwọ awọn Kristian. Aposteli Paulu kọwe ninu Heberu 13:18 pe: “Awa gbagbọ pe awa ni ẹ̀rí-ọkàn rere, a sì ń fẹ lati maa wà lódodo ninu ohun gbogbo.” Ṣiṣe ailabosi wa ń “ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọrun Olugbala wa ni ọ̀ṣọ́ ninu ohun gbogbo.” (Titu 2:10) Ailabosi naa papọ pẹlu iwaasu Ijọba, tí awọn Kristian meji ni ilẹ-ọba Guusu Pacific ti Tonga ń funni ni ẹ̀rí alagbara kan. Ọfiisi ẹka Watch Tower Society ni iha Iwọ-oorun Samoa rohin pe:
“Fun ọpọ ọdun tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan sọrọ nipa Ijọba Ọlọrun fun awọn eniyan ni abuleko mẹrin ti o wà ni erekuṣu wọn ṣugbọn laisi awọn abajade ṣiṣe gúnmọ́. Lẹhin naa, nigba ti ara ọkọ rẹ̀ kò yá, aya naa nilati bojuto oko wọn ki o gé àgbọn ti a ti yọ kuro ninu kókodu si wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ki o sì sá a gbẹ paali, eyi ti o jẹ́ orisun ti owó ń gbà wọle fun wọn kanṣoṣo. Nigba ti akoko tó fun awọn onraja lati yẹ àgbọn ti a sagbẹ naa wo, apo ẹlomiran ti dapọ mọ apo marun-un tirẹ̀. Awọn ara abule rọ̀ ọ́ lati tọju apo ti o lé silẹ naa ati lati wò ó gẹgẹ bi ibukun kan lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Arabinrin naa, bi o ti wu ki o ri, kọ̀ jalẹ, àní nigba ti a sanwo apo mẹfa fun un paapaa, ko jẹ́ gbà ju iye ti o tọ si i lọ. Iṣotitọ rẹ ni a ṣakiyesi.
“Lẹhin naa, nigba ti ọkọ naa nilati rin irin-ajo lọ si erekuṣu miiran, ontaja ile-itaja naa sọ fun un lati bá oun ra awọn ohun-eelo diẹ wá. Ẹlẹ́rìí naa ṣe gẹgẹ bi a ṣe sọ fun un ó sì dá owó ti ó kù pada fun ọkunrin naa. Ẹnu ya ọkunrin naa. Ó sọ pe iyẹn jẹ́ ìgbà akọkọ ti ẹnikẹni tíì dá owó ti ó kù pada. Awọn miiran ti o ti sọ fun lati bá oun ra nǹkan sábà maa ń pa owó ti o ṣẹ́kù mọ́ ìka. Ni akoko miiran, nigba ti Ẹlẹ́rìí naa nilo ohun kan ni ile-itaja ọkunrin yii, ọkunrin naa fun un ni kọkọrọ si ile-itaja, ni sisọ fun un lati mu ohun ti ó nilo ki o sì fi owó sinu ile-itaja naa. Awọn miiran ti wọn wà nibẹ beere idi ti ontaja ile-itaja naa yoo fi fun Ẹlẹ́rìí naa ni kọkọrọ ile-itaja ṣugbọn ti kì yoo fun awọn. Onile-itaja naa ṣalaye pe Ẹlẹ́rìí naa ni ẹnikanṣoṣo ni abule naa ti oun lè gbẹkẹle.
“Iwarere awọn tọkọtaya yii ni a ń jiroro laaarin awọn ara abule. Awọn Ẹlẹ́rìí naa ni a mọ̀ fun iṣotitọ wọn, ipo aidasi tọtuntosi wọn ninu ọ̀ràn, ati ijẹrii wọn nipa Ijọba Ọlọrun, eyi ti o fi iyatọ hàn laaarin igbagbọ awọn ará abule ati ikọnilẹkọọ Bibeli. Nisinsinyi nigba ti ibeere bá dide nipa Bibeli, awọn eniyan sábà maa ń tọ awọn Ẹlẹ́rìí naa lọ fun idahun. Eyi ọkọ tilẹ ti nilati dide kuro lori ibusun lalẹ, lọ si ipade abule kan, ti ó sì dahun awọn ibeere ti a ti gbé dide lori ọrọ-ẹkọ Bibeli. Nigba ti o bá ń lọ si ibi isinku ni abule naa, wọn ti sábà maa ń beere pe ki o sọ ohun ti Bibeli sọ nipa iku, awọn alaye rẹ̀ ni a si ti tẹwọgba.”
Nitori naa iṣotitọ tọkọtaya Ẹlẹ́rìí yii ati iwaasu Ijọba wọn ń funni ni ẹ̀rí rere kan ni erekuṣu Guusu Pacific lilẹwa yii. Wọn nireti pe awọn ẹlomiran yoo kẹkọọ Bibeli ti wọn yoo sì mú iduro wọn fun otitọ. Bi wọn bá ṣe bẹẹ, Jehofa Ọlọrun yoo bukun wọn dajudaju.—Johannu 8:32.