ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 6/1 ojú ìwé 28-31
  • Mo Kún fun Ìmoore fun Itilẹhin Jehofa tí Kìí Kùnà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Kún fun Ìmoore fun Itilẹhin Jehofa tí Kìí Kùnà
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Oṣu Mẹfa ti Ń Danilaamu
  • Ọjọ Alayọ Julọ Ninu Igbesi-Aye Mi
  • Ayọ Ninu Iṣẹ-Ojiṣẹ Naa
  • Funraami
  • Mo Kun fun Imoore fun Itilẹhin Ọlọrun
  • Ohun Tó Jẹ́ Kí N máa Láyọ̀ Láìka Àìlera Mi Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Mo Ti Wá Dẹni Iyì
    Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Kò Rọrùn Láti Tọ́ Ọmọ Mẹ́jọ Ní Ọ̀nà Jèhófà, Àmọ́ Ó Máyọ̀ Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Bí Mo Tiẹ̀ Jẹ́ Aláìlera, Okun Inú Ń Gbé Mi Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 6/1 ojú ìwé 28-31

Mo Kún fun Ìmoore fun Itilẹhin Jehofa tí Kìí Kùnà

GẸGẸ BI SHARON GASKINS ṢE SỌ Ọ́

PARADISE lori ilẹ̀-ayé! Mo ri araami ti mo ń fò kiri pẹlu ariwo yika awọn papa oko tútù, ti mo ń lé awọn labalábá kiri, ti mo ń bá awọn ọmọ kinniun ṣere. Ó mà dara o! Ṣugbọn awọn iyemeji wà. Ireti mi ti ń fi ìgbà gbogbo pari si ainireti tó!

Fun bi o ti pẹ́ tó ti mo lè ranti pada mọ, àga alágbàá kẹ̀kẹ́ ni o ti jẹ́ alabaakẹgbẹ mi atigbadegba. Lati ìgbà ìbí, ni àrùn rọpá-rọsẹ̀ ti já awọn ayọ ìgbà ọmọde gbà mọ́ mi lọwọ. Awọn ọmọde miiran ń jẹgbadun lori yìnyín ati kẹ̀kẹ́, ṣugbọn mo dá jokoo, laitilẹ lè rìn. Nitori naa nigba ti Mama bá mú mi lọ lati ọ̀dọ̀ onigbagbọ wòósàn kan si omiran, a ń fi tọkantọkan wọna fun iṣẹ́ iyanu kan. Lati ìgbà de ìgbà, bi o ti wu ki o ri, awa yoo fi ibẹ̀ silẹ lẹhin ti a kò bá ṣe imularada kankan. Ó jẹ ijakulẹ fun mi ṣugbọn ó ti jẹ́ irora-ọkan fun mama mi tó!

Ni yíyánhànhàn fun ireti tootọ, mama mi bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ibẹrẹ 1964. Ọjọ-ori mi jẹ nǹkan bii ọdun mẹfa ati aabọ nigba naa.

O jẹ ohun agbayanu lati kẹkọọ pe paradise ẹlẹwa kan ti wà rí lori ilẹ̀-ayé yii. Lọna ti o banininujẹ, ọkunrin akọkọ naa, Adamu, ti padanu gbogbo rẹ̀, ṣugbọn mo lọkàn-ìfẹ́ sí isunmọra pẹkipẹki pẹlu Ọlọrun ti oun ti gbadun nigba kan ri. Ki ni ìbá ti ri lati gbadun ipo-ibatan kan pẹlu Ọlọrun? Tabi lati walaaye nigba ti Ọmọkunrin tirẹ̀ funraarẹ rin lori ilẹ̀-ayé? Awọn àròjinlẹ̀ mi tun gbé mi lọ si awọn ọjọ iwaju. Àní ni ọjọ ori ìgbà ọmọde yẹn paapaa, o hàn gbangba si mi pe a ti ri otitọ.

Mama bẹrẹ sii kó idile lọ si Gbọngan Ijọba awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Awọn ipade wọn yatọ gan-an si awọn ohun ti a ti rí ni awọn ṣọọṣi! Awọn eniyan ati ayika naa ru ero-imọlara mi soke lọna jijinlẹ.

Kíkó wa dé Gbọngan Ijọba jẹ idanwo lile gidi kan fun mama mi. Yatọ si emi, awọn ọmọ keekeeke mẹta wà, a kò sì ni ọkọ̀ ayọkẹlẹ. A ń wọ takisi nigba ti oun bá lagbara rẹ̀. Mo sì lè ranti bi ó ti jà fitafita tó ni ọjọ Sunday kan. Kò si takisi kankan ni àrọ́wọ́tó. Nigba naa, lojiji ati lairotẹlẹ, ọkunrin kan dé pẹlu ọkọ̀ akẹ́rù rẹ̀ ó sì gbé wa. A pẹ lẹhin fun ipade naa, ṣugbọn a dé ibẹ̀. Awa ti kun fun ọpẹ́ tó si Jehofa!

Laipẹ awọn arakunrin ati arabinrin wa ọ̀wọ́n nipa tẹmi ti wọn ní ọkọ̀ ayọkẹlẹ ń fi tifẹtifẹ gba ọwọ́ fun araawọn lati gbé wa lọ. Iyanju Mama lati maṣe pa ipade jẹ ayafi bi a bá ń ṣaisan niti gidi tẹ ijẹpataki kiko araawa jọpọ mọ́ mi lọkan bi mo ti kere tóo ni. (Heberu 10:24, 25) Bi ohun ti o ti kọ́ ti wú u lori, mama mi ya igbesi-aye rẹ̀ si mimọ si Jehofa a sì ṣe iribọmi fun un ni 1965.

Ni akoko naa mo ti dagba tó lati mọriri awọn ipade lẹkun-un-rẹrẹ sii. Ni Ijọ Cypress Hills ni Brooklyn, New York, awọn oyinbo, adúláwọ̀, awọn ara Spain, ati awọn miiran wà ti wọn ń jọsin ni ifẹgbẹkẹgbẹ. Ó dabi ohun tí ó tọna gan-an pe awọn olubẹru Ọlọrun gbọdọ maa gbé ninu iru ẹgbẹ́-ará tootọ.—Orin Dafidi 133:1.

Mama mi kọ́ mi bi mo ṣe lè murasilẹ fun awọn ipade. Eyi kìí ṣe iṣoro niti ero-ori, ṣugbọn ipo-ọran ti ara-ìyára ni. Àrùn rọpá-rọsẹ̀ ń yíi awọn iṣẹ rirọrun si awọn iṣẹ idawọle ti o lekoko. Kò tíì ṣeeṣe rí, kò sì tíì ṣeeṣe sibẹ, fun mi lati fa ìlà títọ́ kan lati lè sàmì si awọn idahun ninu awọn iwe ikẹkọọ Bibeli wa. Pẹlu idanrawo, bi o ti wu ki o ri, ìṣọwọ́ fàlà mi gúnrégé sii.

Ero-inu mi a maa kún fun awọn ohun pupọ lati sọ. Ṣugbọn bi wọn bá ti ń fẹ jade kuro ni ẹnu mi, awọn ọ̀rọ̀ naa a dojúrúmọ́ra. Isinmẹdọ ṣe pataki ki awọn iṣan ara mi má baa di líle. Mo tun nilati pọkanpọ sori pipe ọ̀rọ̀ kọọkan ni kedere bi o bá ti lè ṣeeṣe tó. Mo ń ni ijakulẹ bi ọrọ-ilohunsi kò bá dún bi o ti yẹ ki o rí tabi nigba ti mo bá mọ̀ pe awọn eniyan kò loye awọn ọ̀rọ̀ mi. Niwọn bi wọn ti mọ̀ mi, bi o ti wu ki o ri, awọn arakunrin ati arabinrin ninu ijọ ni o ṣeeṣe fun jù lati loye ọ̀rọ̀ mi. Bi o ti wu ki o ri, mo ṣì ni awọn ọjọ didara ati ọjọ lilekoko pẹlu iṣoro yii.

Oṣu Mẹfa ti Ń Danilaamu

Ni ọmọ ọdun mẹjọ, mo ni iriri oṣu mẹfa ti o ti ni ipa lori mi titi di oni yii. Laika gbogbo aájò ti ara, ti iṣẹ, ati ọ̀rọ̀ ti a fun mi si, awọn dokita gbé mi lọ si ile-iwosan ti ń munipadabọsipo ni West Haverstraw, New York. Emi ati mama mi ní idaamu ọkàn. Ni ọdun diẹ ṣaaju, nigba ti awọn dokita ṣe aṣiṣe ni sisọ pe mo ni ifasẹhin ọpọlọ, o wi fun wọn pe oun kò ni fi mi si ile-iwosan àrùn ọpọlọ lae. Nitori naa ipinya fun ìgbà diẹ paapaa ṣoro fun un. Bi o ti wu ki o ri, ó rii pe gbigbe igbesi aye ti ń mu ibisi wa laisi oun ati baba mi tumọsi wiwa ni ipo itẹlọrun niti ara bi o bá ti lè ṣeeṣe tó.

Ilé-lílò naa dara, ṣugbọn mo nimọlara ìpatì. Akoko igbokegbodo tí ó gba agbara gidigidi ati ibinu fi imọlara mi nipa ibẹ hàn gbangba. Lẹẹkọọkan ni awọn òbí mi ń rí ààyè lati rinrin-ajo oniwakati mẹta ninu bọọsi lati ṣebẹwo sọdọ mi, paapaa niwọn ìgbà ti Mama ti loyun ọmọ rẹ̀ ikarun-un sinu. Nigba ti wọn bá nilati lọ, o maa ń bí mi ninu gan-an debi ti dokita fi sọ pe awọn ibẹwo naa gbọdọ dinku. A gba mi laaye lati lọ si ile kìkì lẹẹmeji.

Awọn oniṣegun egungun kọ́ mi bi a ṣe ń rin pẹlu iranlọwọ awọn àgbékọ́ amáraró ati awọn ohun àfirìn ti a fi òjé wiwuwo ṣe. Ó dabi ẹni pe wọn wuwo gan-an ni. Bi o ti wu ki o ri, iwọn iwuwo naa ṣeranwọ fun mi lati lè máraró ti kìí sìí jẹ́ ki n tàkìtì. Eyi ni igbesẹ akọkọ siha ririn funraami laisi àgbékọ́ amáraró.

Bibu ounjẹ, díde bọ́tìnnì—iṣẹ eyikeyii ti o bá gba lilo awọn ìka-ọwọ́—ti maa ń ṣoro bi kò bá tilẹ ṣaiṣeeṣe fun mi. Ṣugbọn de iwọn aaye kan mo kọ́ bi mo ṣe lè jẹun ki ń sì wọ ẹwu funraami. Eyi ṣeranwọ nikẹhin ninu iṣẹ-isin mi si Ọlọrun.

Idanilẹkọọ mi pari, o tun di ile lẹẹkan sii. Mama ń jẹ ki n rìn ni lilo awọn òye mi titun. Ṣiṣe bẹẹ jẹ gidigbo niti ero-imọlara, nitori pe bi o tilẹ jẹ pe mo fẹ́ lati ṣe awọn nǹkan funraami, ṣiṣaṣeyọri wọn jẹ́ eyi ti ń janikulẹ, ti ń gba akoko, ti o si ń muni ṣaarẹ. Họwu, mimura fun awọn ipade ni emi nikan jẹ́ iṣẹ idawọle oniwakati meji!

Nigba ti a rìn de odikeji opopona lati Gbọngan Ijọba, mo rìn irin naa funraami gan-an. Aṣeyọri nla gbá à ni!

Ọjọ Alayọ Julọ Ninu Igbesi-Aye Mi

Mama mi rii daju pe idile ń ni eto ounjẹ tẹmi ti o wà deedee. O ń kẹkọọ pẹlu mi ti ó sì reti pe ki ń ka gbogbo itẹjade awọn iwe agberohinjade wa, Ilé-Ìṣọ́nà ati Ji! Awọn ipade wà lati murasilẹ fun ki a sì pesẹ sibẹ. Bi o tilẹ jẹ pe ero-inu ati ọkan-aya mi ń fi iharagaga gba ẹkọ yii, awọn ironu jijinlẹ nipa yiya igbesi-aye mi si mimọ fun Jehofa ki n sì fi ẹri eyi hàn nipa iribọmi ninu omi wà ni inu lọhun un. Mama mi ràn mi lọwọ lati ri pe laika ipo ahẹrẹpẹ mi si, emi ni mo ni ẹrù-iṣẹ́ didahun fun ipo tẹmi mi niwaju Ọlọrun. Emi kò lè reti lati wọ inú ayé titun lori awọn ẹ̀tọ́ tirẹ̀, lati laaja wọnú rẹ̀ ni gbigbarale mama mi patapata.

Mo nifẹẹ Ọlọrun, ṣugbọn ipo mi yà mi sọtọ gẹgẹ bi ẹni ti o yatọ si awọn miiran—ohun àmọ̀dájú rironilara kan fun ọdọlangba kan. O ṣoro lati tẹwọgba awọn ààlà mi. Inu mi sábà maa ń rusoke fun ibinu, eyi ni mo si nilati ṣakoso ṣaaju iribọmi. (Galatia 5:19, 20) Ki sì ni bi emi kò bá lè gbe ni ibamu pẹlu iyasimimọ mi si Jehofa?

Gẹgẹ bi mama mi ti beere, alagba ijọ kan bá mi sọrọ. Ó tọka si ibeere wolii Elija si awọn ọmọ Israeli pe: “Yoo ti pẹ́ tó ti ẹyin o maa ṣiyemeji?” (1 Awọn Ọba 18:21) Ni kedere, inu Jehofa kò dun si àìnípinnu mi.

Mo jí sáyé nipa tẹmi mo sì gbadura tọkantọkan fun iranlọwọ Jehofa ati fun ipinnu naa lati ya igbesi-aye mi si mimọ fun un. Arabinrin kan ninu ijọ bá mi kẹkọọ. Ó kere si mi, ìyá rẹ̀ sì ti ku nigba ti oun wà ni ọmọde. Bi o tilẹ ri bẹẹ, oun ti ṣe iyasimimọ si Ọlọrun nigba ti oun ṣi kere gan-an.

Ni ẹni ọdun 17, mo ṣe ọkàn mi gírí. Mo fẹ lati ṣiṣẹsin Jehofa de ibi ti agbara mi bá lè de. Ni August 9, 1974—nigba ti mo ṣe iribọmi—ni ọjọ alayọ julọ ninu igbesi-aye mi.

Ayọ Ninu Iṣẹ-Ojiṣẹ Naa

Ikopa ninu iṣẹ-ojiṣẹ gbé awọn idiwọ giga bi oke nla kalẹ. Ipenija ti o ga julọ ni lati mu ki a lóye mi. Emi yoo sọrọ ketekete bi o bá ti lè ṣeeṣe tó. Lẹhin naa, nibikibi ti o bá ti pọndandan, ẹnikeji mi ninu iṣẹ-ojiṣẹ papa yoo tun awọn ọ̀rọ̀ mi sọ fun onile. Awọn miiran huwapada lọna òdì, ni wiwo mi bii ojiya ipalara lọwọ ìloni ni ilokulo fun anfaani awọn Ẹlẹ́rìí. Ṣugbọn wiwaasu jẹ ẹ̀tọ́ mi ati ìfẹ́-ọkàn atinuwa mi.

Ririn lati ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà fun ipinlẹ kan paapaa lè jẹ eyi ti ń muni ṣaarẹ patapata. Ọpọ ile ní agbegbe iṣiṣẹ iwaasu wa ní àtẹ̀gùn, eyi ti o mú ki wọn jẹ́ ibi ti emi kò lè dé. Ni ìgbà otutu, awọn opopona ti o kun fun yinyin mu ki iṣẹ ile-de-ile fẹrẹẹ jẹ eyi ti kò ṣeeṣe fun mi rara. (Iṣe 20:20) Bi o ti wu ki o ri, awọn arakunrin nipa tẹmi ṣeranwọ lọna titobi, Jehofa sì ti bukun mi nisinsinyi pẹlu aga alágbàá kẹ̀kẹ́ eyi ti o ni ẹrọ àfiṣiṣẹ́, ti o mu ki iṣẹ-ojiṣẹ tubọ rọrun sii.

Bi akoko ti ń lọ, mo bẹrẹ sii jẹrii nipasẹ ikọwe ranṣẹ. Fifi ọwọ́ kọ lẹta kò níí tó nitori ọwọ́-ìkọ̀wé mi kò ṣeékà fun ọpọ julọ awọn eniyan. Nitori naa ẹrọ-itẹwe onina di onkọwe mi. Titẹwe mi kò yá nitori àìṣiṣẹ́báramu awọn ọwọ mi. Ni nǹkan bi ilaji akoko, emi yoo ni ẹyọ lẹta kan lọkan ti emi yoo sì tẹ omiran. Ó lè gbà tó wakati kan tabi ju bẹẹ lọ lati tẹ oju-iwe kanṣoṣo.

Laika aini kìmí sí, lati ìgbà dé ìgbà, mo ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna oluranlọwọ, ni lilo 60 wakati tabi ju bẹẹ lọ ninu iṣẹ-ojiṣẹ naa ni oṣu kan. Eyi beere fun itolẹsẹẹsẹ ti o jíire, afikun isapa, ati itilẹhin awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ mi. Ẹmi aṣaaju-ọna wọn fun mi niṣiiri. Mama mi tun ti jẹ́ apẹẹrẹ rere nipa ṣiṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna deedee tabi oluranlọwọ nigba ti ó ń dojukọ inira, ilera ti kò sunwọn, ati ipenija títọ́ ọmọ meje ninu agbo-ile ti o pin si meji niti isin.

Funraami

Ni ẹni ọdun 24, mo pinnu lati jade lọ funraami. Ṣíṣí lọ mi si ìhà Bensonhurst ni Brooklyn jasi ibukun. Ijọ Marlboro dabi idile kan ti o hunpọ̀ pẹkipẹki. Ó ti fun igbagbọ lokun tó lati wà pẹlu wọn! Àní pẹlu kìkì ọkọ̀ ayọkẹlẹ meji tabi mẹta ti ó wà ni ijọ naa, awọn arakunrin nipa tẹmi ń gbé mi lọ si gbogbo ipade. Sibẹ emi kò gbé ibẹ fun ìgbà pipẹ.

Pẹlu imọlara bi ẹni pe mo jẹ́ ajánikulẹ̀, mo pada sọdọ idile mi ti mo sì kowọnu ikarisọ jijinlẹ ọlọdun mẹta. Irugudu ibinu tun pada farahan. Nigba naa ni awọn èrò ifọwọ ara-ẹni pa ara-ẹni dé ati awọn igbidanwo melookan lati mú wọn ṣẹ. Iku rọdẹdẹ bi awọsanma ṣíṣúdùdù. Ṣugbọn mo gbarale Ọlọrun gidigidi ti mo sì ṣeleri lati fi imọriri hàn fun ẹbun iwalaaye rẹ̀. Itunu ati imọran ti ọ̀dọ̀ awọn alagba wa. Eyi, papọ pẹlu adura, idakẹkọọ, suuru ni iha ọ̀dọ̀ idile mi, ati awọn iranlọwọ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ diẹ, tún ironu mi ṣe.

Nipasẹ Ilé-Ìṣọ́nà, Jehofa fi jẹlẹnkẹ pese ijinlẹ-oye lori ikarisọ mimuna. Bẹẹni, oun bikita fun awọn eniyan rẹ̀ ó sì lóye awọn imọlara wa. (1 Peteru 5:6, 7) Bi akoko ti ń lọ ikarisọ jijinlẹ ká kuro. Ni ọdun mẹwaa lẹhin naa, Jehofa ṣì ń ràn mi lọwọ lati koju ijakulẹ ati ikarisọ. Nigba miiran imọlara aijamọ nǹkan fẹrẹẹ gbé mi mì tán. Laika eyiini si, adura, ikẹkọọ Bibeli, ati idile mi tẹmi jẹ́ agbayanu aranṣe lilaaja.

Lẹhin iwakiri fun ile miiran ti o jasi otubantẹ, mo ti fi ìlọ́ra pinnu lati gbé pẹlu idile mi fun iyooku igbesi-aye mi. Lẹhin naa Jehofa dahun awọn adura mi. Ààyè kan ṣí silẹ ni ìhà Bedford-Stuyvesant ti Brooklyn. Ni opin ìgbà ìwọ́wé 1984, mo ṣí lọ sibẹ, mo sì ti wà nibẹ lati ìgbà yẹn wá.

Awọn mẹmba Ijọ Lafayatte ti wọn fifẹẹ hàn gan-an ń fi inurere gbé mi lọ si awọn ipade. Eyi ti o ṣì ṣe ketekete ninu ọkàn mi ni Ikẹkọọ Iwe Ijọ ti mo kọkọ lọ. A ṣe é ni àjà kẹrin—kò sì sí ẹ̀rọ agbéniròkè! Kìkì pẹlu iranlọwọ Jehofa ni mo fi lọ soke sodo awọn àtẹ̀gùn wọnni. Bi akoko ti ń lọ ọgangan ààyè kan ti o tubọ rọrun lati dé ni a pese. Ati nisinsinyi Jehofa ti bukun mi pẹlu anfaani níní Ikẹkọọ Iwe Ijọ kan ninu ile mi.

Ẹmi aṣaaju-ọna ti o tayọ gbèèràn ninu ijọ yii. Nigba ti mo dé, nǹkan bi 30 aṣaaju-ọna ni wọn wà, awọn kan sì fun mi ni itọju ati afiyesi akanṣe. Ayika onitara naa sún mi lati jẹ́ aṣaaju-ọna oluranlọwọ lóòrèkóòrè sii.

Ni April 1989 Ijọ Lafayette ati Pratt kọ́ Gbọngan Ijọba titun kan si opopona kan-naa ti ile mi wà. Wẹ́kú gan-an ni ó ṣe, nitori pe fun ijorẹhin ara-ìyára siwaju sii, rírìn ti wá di iṣoro lẹẹkan sii. Pẹlu kẹ̀kẹ́ mi ti ó ní ẹ̀rọ ati awọn arakunrin ati arabinrin tẹmi ni ẹ̀gbẹ́ mi, bi o ti wu ki o ri, irin-ajo lọ si ipade ati padabọ kun fun igbadun. Mo ti mọriri iru itilẹhin onifẹẹ bẹẹ jinlẹjinlẹ tó!

Mo Kun fun Imoore fun Itilẹhin Ọlọrun

Bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹsẹ mi kò duro deedee, ọkan-aya mi duroṣanṣan. Ẹkọ-iwe daradara mú ki igbesi-aye tubọ rọrùn diẹ si, sibẹ Ọlọrun ti tì mi lẹhin. Nigba miiran emi kò mọ ibi ti ounjẹ ti yoo tẹlee yoo ti wá, ṣugbọn Jehofa ti tì mi lẹhin ó sì ti jẹ́ oluṣotitọ Olupese. Eyi ti ó ṣọwọn fun mi, nitootọ, ni awọn ọ̀rọ̀ Dafidi pe: “Emi ti wà ni èwe, emi sì dagba; emi kò tii rí ki a kọ olódodo silẹ, tabi ki iru-ọmọ rẹ̀ ki o maa ṣagbe ounjẹ.”—Orin Dafidi 37:23-25.

Ni ọpọ ìgbà Jehofa mú ki o ṣeeṣe fun mi lati pa iduro ti ó bá Iwe Mimọ mu mọ́ nipa ríràn mi lọwọ lati kọ̀ lati gba ẹ̀jẹ̀ lakooko iṣẹ-abẹ. (Iṣe 15:28, 29) Lẹnu aipẹ yii, baba mi kú. Pipadanu ẹnikan ti o sunmọni pẹkipẹki jẹ́ ọ̀ràn ibanujẹ gan-an. Kìkì okun lati ọ̀dọ̀ Jehofa ni o ti tì mi lẹhin la iṣoro yii ati awọn miiran já.

Ilera mi lè maa baa lọ lati kùnà, ṣugbọn igbẹkẹle mi ninu Ọlọrun ati ipo-ibatan mi pẹlu rẹ̀ ni o ń gbé iwalaaye mi ró. Mo ti layọ tó lati wà laaarin awọn eniyan Jehofa ati lati ní itilẹhin rẹ̀ ti kìí kùnà!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́