ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 8/1 ojú ìwé 3
  • “Kò Wulẹ Dabi Ẹni Pe a Lè Jumọsọrọpọ!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Kò Wulẹ Dabi Ẹni Pe a Lè Jumọsọrọpọ!”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nígbà kan Rí àti Nísinsìnyí—Àwọn Ìlànà Bíbélì Ràn Án Lọ́wọ́ Láti Yí Padà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ta Ni Máíkẹ́lì, Olú-Áńgẹ́lì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ta Ni Máíkẹ́lì Olú-Áńgẹ́lì?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ṣé Jésù Ni Máíkẹ́lì Olú Áńgẹ́lì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 8/1 ojú ìwé 3

“Kò Wulẹ Dabi Ẹni Pe a Lè Jumọsọrọpọ!”

MICHAEL, ti o jẹ́ agbẹjọro kan, nilati jẹ́ olubanisọrọpọ gbigbeṣẹ kan. Iṣẹ rẹ̀ beere fun un. Ṣugbọn lẹhin ọdun 16 ninu igbeyawo, a fi ipá mú Michael lati mọ̀ pe nigba ti ó bá dé ile wá bá aya rẹ̀, Adrian, awọn òye-iṣẹ́ ibanisọrọpọ rẹ̀ a dabi eyi ti o ti poora. “Iyàn jíjà, ṣiṣariwisi, ifẹsunkanni,” ni Michael ranti, “emi ati Adrian saba maa ń bá araawa jà, mo sì ronu pe yoo wulẹ mú agara dá wa ni. Mo ṣe kayeefi bi a bá lè pe iyẹn ni igbeyawo, òpòòrò aini itẹlọrun ati imunibinu ti ń baa lọ. Bi ó bá nilati jẹ́ ipa tiwa niyẹn fun gbogbo iyooku igbesi-aye wa papọ, mo fẹ́ lati bọ́ lọwọ igbeyawo naa—emi kò ṣeré. Emi kò wulẹ lè koju 20, 30, 40 ọdun ti iru imunibinu ati pakanleke ti kò yipada bẹẹ.”

Awọn ironu bi eyi kò mọ sọdọ Michael ati Adrian nikan. Wọn jẹ́ otitọ gidi fun ọpọ tọkọtaya ti ija ati idawọ asọ̀ duro ń tẹlera ninu ipo-ibatan wọn. Ijumọsọrọpọ ti o rọrùn julọ ń yọrisi ogun àfẹnujà. Wọn “ń gbọ́” awọn ohun ti a kò sọ. Wọn ń sọ ohun ti wọn kò ni lọkan. Wọn ń gbejakora wọn sì ń fẹsunkanra, lẹhin naa wọn yoo pada sinu idakẹjẹẹ afibinuhan. Wọn kò pinya, ṣugbọn bẹẹ ni wọn kìí ṣe “ara kan” nitootọ. (Genesisi 2:24) Ijakulẹ patapata ni ipo-ibatan naa jẹ́. Fifasẹhin yoo tumọsi pipinya; titẹsiwaju yoo tumọsi kikoju awọn àìdọ́gba naa bi o bá ti ń yọju. Lati yẹra fun irora eyikeyii ninu yiyan mejeeji, awọn tọkọtaya wọnyi muratan lati gbà lati jìnnà sira niti ero-imọlara lọna kan ti kò lewu.

Iru awọn tọkọtaya bẹẹ ni aini wà fun lati ‘gba itọsọna olóye-iṣẹ́’ ninu igbeyawo wọn. (Owe 1:5) Itọsọna yii wà ninu Bibeli, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Lẹta ekeji ti Paulu kọ si Timoteu tẹnumọ ọn pe Bibeli ní “èrè fun ẹkọ, fun ibaniwi, fun itọni.” (2 Timoteu 3:16) Bayii ni ọ̀ràn naa ti ri ninu wiwo ijakulẹ ijumọsọrọpọ inu igbeyawo sàn, gẹgẹ bi a o ti rii.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́