Kikẹsẹjari Ninu Ijakadi Pẹlu Ìmukúmu-Ọtí
“Lẹnu iṣẹ́, ní nǹkan bi agogo mẹwaa owurọ, emi yoo bẹrẹ sii ronu nipa ọtí líle. Ní agogo 12 ọ̀sán, emi yoo jade lọ lati mu ìgò kan tabi meji. Ní agogo mẹta ara mi yoo ti maa gbọ̀n. Mo ń wọna fun akoko ti oju mi yoo dá ki n baa lè mu ọtí miiran. Lọpọ ìgbà mo maa ń mu ìgò meji bi mo bá ń lọ sile. Ní nǹkan bi agogo meje, emi yoo tun ní ìfẹ́-ọkàn lilagbara naa. Emi yoo mu ọtí, ré lulẹ̀ lati ori aga laimọ, emi yoo tọ̀ si ṣokoto, ti n ó sì sùn sinu ìtọ̀ mi mọ́jú. Wo eyi ni ilọpo ọjọ 7 ti ń bẹ ninu ọsẹ; ilọpo ọsẹ 52 ninu ọdun; fun ọdun 29.”
ỌKUNRIN yii jẹ́ onìmukúmu-ọtí. Kìí ṣe oun nikan ni. Araadọta-ọkẹ jakejado ayé ń jijakadi pẹlu ipo aṣekupani yii debi pe, gẹgẹ bi Dokita Vernon E. Johnson ti sọ ọ, “ó níí ṣe pẹlu odindi eniyan kan: nipa ti ara, èrò-orí, ọgbọ́n ironu, ati nipa tẹmi.”a
Ọpọ awọn ogbogi wi pe a kò lè wo ìmukúmu-ọtí sàn ṣugbọn a lè dá a duro nipasẹ itolẹsẹẹsẹ yiyago fun un jalẹ akoko iwalaaye. Eyi kìí ṣe ohun abeere-fun ti kò mọgbọndani, nitori pe ọtí líle kò ṣekoko fun iwalaaye. Niti tootọ, àṣìlò ọtí líle ń mú airi ojurere Ọlọrun wá. (1 Korinti 6:9, 10) Ó sànjù lati wọ inu ayé titun Ọlọrun ní ẹni ti a fi ọtí dù ju lati juwọsilẹ fun iyanhanhan fun un ki a sì padanu iwalaaye ayeraye.—Matteu 5:29, 30.
Jíjàjàbọ́—ati wíwà lominira—kuro lọwọ ilokulo ọtí líle sábà maa ń jẹ́ ipenija ti ń janikulẹ. (Fiwe Romu 7:21-24.) Ki ni ohun ti o lè ṣeranlọwọ? Ẹ jẹ ki a pese awọn imọran taarata kan. Koda bi iwọ kìí bá mu ọtí líle rárá, imọran yii yoo pese isọfunni ó sì lè mú ki o ṣeeṣe fun ọ lati ran awọn ọ̀rẹ́ diẹ tabi ibatan kan ti ń jijakadi pẹlu ìmukúmu-ọtí lọwọ.
Wíwo Araarẹ Pẹlu Ailabosi
Ọ̀kan lara awọn ohun idiwọ titobi julọ lati bori ni sísẹ́ otitọ naa pe iwọ jẹ́ onímukúmu-ọtí. Sísẹ́ jẹ́ iru àbòsí kan. Ó jẹ́ aiṣootọ pẹlu ète kan: lati daabobo ominira rẹ lati mutí. ‘Iṣoro mi pẹlu ọtí líle kò buru tó iyẹn,’ ni iwọ lè ronu. ‘Idile mi ṣì wà pẹlu mi. Iṣẹ kò tíì bọ́ lọwọ mi.’ Ní pataki julọ, ọtí líle rẹ ṣì wà pẹlu rẹ.
Sísẹ́ lè mu ki o máṣe fetisilẹ si awọn ọ̀rẹ́ ti wọn fẹ́ lati ràn ọ́ lọwọ. Robert ṣakiyesi pe ọkọ ìyá iyawo oun ti mú ọ̀nà ìgbàmutí ti o méwu lọwọ dagba. “Lẹhin awọn ọjọ diẹ, mo kò ó loju,” ni Robert sọ, “ni bibeere lọwọ rẹ̀ bi ó bá nimọlara pe ọtí mimu rẹ̀ dakun iwa rẹ̀.” Abajade rẹ̀ ti jẹ́? “Ó sẹ́ kanlẹ, pẹlu awọn gbolohun-ọrọ bi, ‘Iwọ kò ni ẹ̀rí kankan’ ati, ‘Iwọ kò mọ bi imọlara mi ti ri.’”
Bi mẹmba idile tabi ọ̀rẹ́ kan ti ń ṣaniyan nipa ọtí mimu rẹ bá kò ọ́ loju, fi oju ailabosi, ti ń wadii ọ̀ràn wò wo araarẹ. (Owe 8:33) Iwọ ha lè gbé laisi ọtí líle fun odindi ọsẹ kan, odindi oṣu kan, tabi fun oṣu melookan bi? Bi kò bá ri bẹẹ, eeṣe ti kò fi ri bẹẹ? Maṣe dabi ọkunrin naa ti ń tan araarẹ jẹ pẹlu awọn èrò èké. Jakọbu wi pe: “Oun dabi ọkunrin ti o ń ṣakiyesi oju araarẹ̀ ninu awojiji: nitori o ṣakiyesi araarẹ̀, o sì bá tirẹ̀ lọ, loju kan-naa o sì gbagbe bi oun ti rí.”—Jakọbu 1:22-25.
Àní lẹhin ti imularada bá ti bẹrẹ, iwọ yoo ṣì nilati ṣọra fun sísẹ́. Iwe naa Willpower’s Not Enough ṣalaye pe: “Ẹni ti o ṣẹṣẹ bẹrẹ sii yẹra naa lè fi aṣiṣe gbagbọ pe nitori pe oun ti ṣiwọ mimu ọtí líle fun ìgbà diẹ kan—boya fun ìgbà akọkọ—a ti wo oun sàn nisinsinyi.” Ironu ikẹrabajẹ lilagbara gan-an ni eyi jẹ́, o sì jẹ́ igbesẹ akọkọ si itunpadasẹhin. Bi iwọ bá nilati dènà iru sísẹ́ bẹẹ, o nilo iranlọwọ awọn ẹlomiran.
Gba Iranlọwọ
Ní mímọ̀ pe oun kò lè dá ṣẹgun ìmukúmu-ọtí, ọkunrin kan ti a lè pè ní Leo wá iranlọwọ akọṣẹmọṣẹ. Lẹhin akoko igbatọju loju mejeeji, ó wà loju ọ̀nà si jijere iwosan. Leo nimọlara pe iniyelori iranlọwọ ogbogi ni a nilati fun ni akanṣe agbeyẹwo.b Bí iru iranlọwọ bẹẹ bá wà larọọwọto laduugbo, iwọ lè pinnu lati lo anfaani naa.
Bi o ti wu ki o ri, iwọ gbọdọ mọ̀ pe pupọ sii wà fun imularada ju kiki yiyẹra lọ. O ṣeeṣe ki awọn ọ̀ràn jijinlẹ ti iwọ ni lati koju wà nisalẹ ìmukúmu-ọtí. Didagunla si awọn nǹkan naa lè léwu. Dokita Charlotte Davis Kasl kọwe pe: “Mo ti fọrọ wá awọn eniyan ti wọn ti gba itọju fun lilo awọn eroja àfikẹ́ra ni ilokulo lẹnu wò fun ohun ti o tó ìgbà mẹrinla nitori pe ilokulo, ìdaradé, ati idagunla ti o jẹ pataki julọ ninu awọn iṣoro naa ni wọn kò ṣiṣẹ lé lori.”
Dennis rii pe eyi jẹ́ otitọ. “Mo jẹ́ ẹnikan ti o ti jawọ ninu ìmukúmu-ọtí ti mo sì ní ọpọlọpọ iṣoro sibẹ,” ni oun kọwe. “Kò tó lati dá ọtí mimu duro. Mo nilati bojuwẹhin wo awọn ìgbà ti mo ti lo kọja, mo ṣayẹwo awọn ẹkọ ìgbà ọmọde mi, mo loye bi wọn ṣe ń nipa lori mi, mo sì ṣe awọn iyipada diẹ ninu iwa mi.”
Bakan-naa, Leo ti nilati wo araarẹ̀ ni awojinlẹ ki o baa lè tẹsiwaju siha iwosan. “Mo jẹ́ ẹni ti ń jowu rekọja, ti mo sì jẹ́ oniwa-ipa,” ni oun wi. “Mo ń niriiri awọn akoko iyì ara-ẹni rirẹlẹ ati itanjẹ rironu pe mo jẹ́ ẹni ti o ṣe pataki ju bi mo ti jẹ́ niti gidi.” Leo fi imọran Bibeli naa ti o wà ni Efesu 4:22 si ilo: “Pe, niti iwa yin atijọ, ki ẹyin ki o bọ́ ogbologboo ọkunrin ni silẹ.” Bẹẹni, “iwa yin atijọ” ti lo idari alagbara kan lori animọ-iwa yin. Bí amọ̀ ti ń bá ohun kan ti a fi mọ mu, bẹẹ ni ipa-ọna rẹ atijọ ti mọ animọ-iwa rẹ lọna kan. Nigba ti o bá mu iwa buburu kuro, ki ni ohun ti o kù? Animọ-iwa kan ti a ti mọ boya la akoko awọn ọdun pupọ kọja. Nitori naa, iwosan gbọdọ ni ninu yíyí animọ-iwa ti o bá iwa rẹ atijọ mu pada.
Fidi Ipo-Ibatan kan Múlẹ̀ Pẹlu Ọlọrun
Iwosan Leo tun kan mimu ipo-ibatan ara-ẹni kan dagba pẹlu Ọlọrun. “Kíkọ́ lati gbarale Jehofa patapata yí iṣesi, iwa, ati oju-iwoye mi pada,” ni oun wi.
Bi o ti wu ki o ri, ó tọ́ lati lo iṣọra. Ipo ibatan eyikeyii—pẹlu awọn eniyan tabi pẹlu Ọlọrun—beere fun lílè sọrọ, ailabosi, ati igbẹkẹle. Iwọnyi ni awọn animọ naa gan-an ti ìmukúmu-ọtí ń bajẹ. A lè mú wọn dagba, ṣugbọn o ń gba akoko.
Gẹgẹ bi onímukúmu-ọtí kan, iwọ lè má mọ bi ipo-ibatan timọtimọ ṣe rí lara. Boya o kò tii niriiri ọ̀kan rí. Nitori naa ní suuru. Maṣe rọ́lu igbesẹ yii, ni rireti pe ki ipo-ibatan kan pẹlu Ọlọrun farahan gẹgẹ bi eso tí iyẹra fun ọtí maa ń mú jade funraarẹ. Ṣiṣẹ́ kara lati loye Ọlọrun ati awọn animọ rẹ̀. Maa ṣe aṣaro deedee, boya ki o maa fi tiṣọratiṣọra ka awọn orin Dafidi inu Bibeli ti ó fi imọlara jijinlẹ, imọriri nipa Jehofa ati awọn ọ̀nà rẹ̀ hàn.c
“Ọláńlá Agbara”
Ipo ibatan onigbẹkẹleni, ti o daju pẹlu Ọlọrun lè ni ipa alagbara lori rẹ. Jehofa yoo ti awọn isapa rẹ lati ri iwosan lẹhin. (Fiwe Orin Dafidi 51:10-12; 145:14.) Iwọ lè bá a sọrọ ninu adura atọkanwa ni akoko eyikeyii, pẹlu idaniloju pe oun yoo pese “ọláńlá agbara” fun ọ.—2 Korinti 4:7; Filippi 4:6, 7.
Ẹlẹdaa naa mọ iṣẹda rẹ dunju ju eniyan eyikeyii lọ. (Orin Dafidi 103:14) Awọn eniyan olugbaninimọran, ti wọn sinmilé ọgbọ́n eniyan, lè ṣeranlọwọ; ṣugbọn wo bi Ẹlẹdaa eniyan ṣe lè ràn ọ́ lọwọ pupọ pupọ sii tó ninu ijakadi yii! (Isaiah 41:10; 48:17, 18) Oun ti pese itilẹhin onifẹẹ ninu ijọ Kristian.
Eto Aṣetilẹhin Kan
Awọn alagba ti wọn dagba nipa tẹmi ninu ijọ Kristian lè jẹ́ orisun iranlọwọ nla kan. Diẹ ninu wọn yoo jẹwọ jijẹ olóye ninu papa ẹkọ iṣegun tabi ti ilera èrò-orí, ṣugbọn wọn mọ̀ wọn sì gbẹkẹle Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati awọn ilana rẹ̀. Wọn lè fi ẹ̀rí hàn lati jẹ́ “bi ibi ìlùmọ́ kuro loju ẹfuufu, ati aabo kuro lọwọ ìjì; bi odò-omi ni ibi gbigbẹ, bi òjìji apata nla ní ilẹ gbigbẹ.” (Isaiah 32:2) Lo anfaani iranlọwọ wọn lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́.d
Niti tootọ, iru awọn alagba Kristian bẹẹ, papọ pẹlu awọn mẹmba idile ati awọn ọ̀rẹ́ miiran, kì yoo ṣíji bò ọ́ kuro ninu iyọrisi awọn igbesẹ rẹ. Itẹjade naa Coming Off Drink ṣalaye pe: “Eroja ṣiṣekoko ninu itọju awọn onímukúmu-ọtí jẹ́ gbigbe awọn abajade ipalara tí ìmukúmu-ọtí ń mú wá kò wọn loju ati mimu ki wọn gba ẹru-iṣẹ fun iṣarasihuwa wọn.” Nitori naa wọn yoo jẹ́ oninuure ṣugbọn wọn yoo sọ otitọ taarata, ni fifun ọ niṣiiri lati koju otitọ gidi ki o sì rọ̀ mọ́ itọju eyikeyii ati ipa-ọna iwahihu ti o nilo lati bori ninu ogun rẹ lodisi ọtí líle.
Ẹru-Iṣẹ Rẹ Ni Iwosan Jẹ́
Bi o ti ń janfaani lati inu itilẹhin awọn ẹlomiran, iwọ ni lati mọ pe kò si eniyan tabi ẹmi eyikeyii ti o lè ṣe iwosan rẹ ní kànńpá. Ẹda olominira kan ni iwọ jẹ́. Iwosan rẹ jẹ́ ẹru-iṣẹ rẹ latokedelẹ. (Fiwe Genesisi 4:7; Deuteronomi 30:19, 20; Filippi 2:12.) Tẹwọgba ẹru-iṣẹ yẹn, Jehofa yoo sì bukun fun ọ. A mu un dá wa loju ni 1 Korinti 10:13 pe: “Kò si idanwo kan ti o tii bá yin, bikoṣe eyi ti o mọ niwọn fun eniyan: ṣugbọn olododo ni Ọlọrun, ẹni ti kì yoo jẹ́ ki a dán yin wò ju bi ẹyin ti le gbà; ṣugbọn ti yoo sì ṣe ọ̀nà atiyọ pẹlu ninu idanwo naa, ki ẹyin ki o baa le gbà á.” Nitori naa, fọkànbalẹ̀—iwọ lè kẹsẹjari ninu ijakadi pẹlu ìmukúmu-ọtí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bi o tilẹ jẹ pe a o tọka si onímukúmu-ọtí naa gẹgẹ bi ọkunrin, awọn ilana ti o wà nihin-in yii kan awọn obinrin onímukúmu-ọtí bakan-naa.
b Ọpọ ibudo ipese itọju, ile-iwosan, ati awọn itolẹsẹẹsẹ imularada ti wọn lè pese iranlọwọ ni o wà. Ilé-Ìṣọ́nà kò fọwọsi iru itọju kan ni pataki. Ẹnikan gbọdọ lo iṣọra ki ó ma baa di ẹni ti o lọwọ ninu awọn igbokegbodo ti yoo lodi si awọn ilana Iwe Mimọ. Bi o tilẹ ri bẹẹ, ní paripari rẹ̀, ẹnikọọkan yoo nilati pinnu fun araarẹ̀ iru itọju ti ó nilo.
c Awọn apẹẹrẹ diẹ ni Orin Dafidi 8, 9, 18, 19, 24, 51, 55, 63, 66, 73, 77, 84, 86, 90, 103, 130, 135, 139, 145.
d Awọn itọsọna ti wọn kun fun iranlọwọ fun awọn alagba ni a rí ninu Ilé-Ìṣọ́nà, November 1, 1983, oju-iwe 8 si 11.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
Boya iwọ ń jiya ìrẹ̀sílẹ̀ ati ìṣẹ́ tí ìmukúmu-ọtí ń muwa. Bi o bá ri bẹẹ, maṣe sọ ireti nù. Iranlọwọ wa larọọwọto.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
BI O BÁ NIRIIRI IFASẸHIN
“Wíwà ni imurasilẹ fun ifasẹhin dabi ṣiṣe idaraya iná pípa,” ni iwe naa Willpower’s Not Enough sọ. “Kò tumọsi pe o ń reti iná ṣugbọn pe o wà ni imurasilẹ lati gbé igbesẹ ìmẹrù-iṣẹ́-níṣẹ́ bí ọ̀kan bá ṣẹlẹ.” Bi o bá niriiri ifasẹhin:
□ Gbadura si Jehofa. Ni idaniloju pe oun lóye iṣoro rẹ ó sì ń fẹ́ lati ṣeranlọwọ.—Orin Dafidi 103:14; Isaiah 41:10.
□ Bá Kristian alagba kan sọrọ aṣiiri, lẹhin ti o ti pinnu ẹni ti iwọ yoo lọ bá bi aini naa bá dide. Jẹ alailabosi nipa ohun ti o ṣẹlẹ, ki o sì fetisilẹ yékéyéké si amọran rẹ̀ ti ó bá Iwe Mimọ mu.
□ Ṣọra fun ainireti. Kíkórìíra araarẹ yoo wulẹ sún ọ pada sinu ifasẹhin kikun ti o gogò ni, nitori naa fi aṣiṣe rẹ si igun oju-iwoye ti o yẹ. Pe o ti padanu ija-ogun kan kò tumọsi pe o ti padanu ogun naa. Nigba ti sárésáré ẹlẹmii-ẹṣin kan bá ṣubu, oun kìí pada si ibẹrẹ ìlà; a gbera nilẹ yoo maa bá eré-ìje naa lọ. Ṣe ohun kan-naa pẹlu ìkọ́fẹpadà rẹ. Oju-ọna ni o ṣì wà sibẹ. Awọn ọsẹ, oṣu, tabi ọdun ti o ti fi takété sí ọtí líle nigba ti o ti kọja ṣì wà sibẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Dènà sísẹ́ nipa fifi oju alailabosi, ti ń wadii ọ̀ràn wò wo araarẹ