Mímú Ìbẹ̀rù Oníwà-Bí-Ọlọ́run Dàgbà
“Bẹ̀rù Jehofa kí o sì yídà kúrò nínú búburú.”—OWE 3:7, NW.
1. Ta ni a tìtorí rẹ̀ kọ ìwé Owe?
ÌWÉ Owe nínú Bibeli ní ibú-ọrọ̀ ìmọ̀ràn tẹ̀mí nínú. Jehofa pèsè ìwé amọ̀nà yìí ní àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ láti fún àpẹẹrẹ-irú orílẹ̀-èdè rẹ̀ ti Israeli ní ìtọ́ni. Lónìí, ó pèsè àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n fún orílẹ̀-èdè Kristian mímọ́ rẹ̀, ‘àwọn ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé débá.’—1 Korinti 10:11; Owe 1:1-5; 1 Peteru 2:9.
2. Èéṣe tí ìkìlọ̀ Owe 3:7 fi bọ́sákòókò jùlọ lónìí?
2 Ní ṣíṣí i sí Owe 3:7 (NW), a kà pé: “Máṣe jẹ́ ọlọgbọ́n ní ojú ara rẹ. Bẹ̀rù Jehofa kí o sì yídà kúrò nínú búburú.” Láti ìgbà àwọn òbí wa àkọ́kọ́, nígbà tí Ejò ré Efa lọ pẹ̀lú ìlérí pé wọn yóò “mọ rere àti búburú,” ọgbọ́n ènìyàn lásán ti kùnà láti pèsè ìdáhùn sí àwọn àìní aráyé. (Genesisi 3:4, 5; 1 Korinti 3:19, 20) Kò tíì sí ìgbà kankan nínú ọ̀rọ̀-ìtàn tí èyí hàn kedere jú bi ó ti rí ní ọ̀rúndún ogún yìí—àwọn “ìkẹyìn ọjọ́” wọ̀nyí nígbà tí aráyé, ní kíkórè àwọn èsò ìrònú àìgbàgbọ́-nínú-wíwà-Ọlọ́run, ti ẹfolúṣọ̀n, di èyí tí a ń kó ìdààmú bá nípasẹ̀ èrò ìgbàgbọ́ ẹ̀yà-ìran tèmi lọ̀gá, ìwà-ipá, àti onírúurú ìwà-pálapàla gbogbo. (2 Timoteu 3:1-5, 13; 2 Peteru 3:3, 4) Ó jẹ́ ‘rúdurùdu ayé titun’ kan tí yálà àjọ UN tàbí àwọn ìsìn ayé tí ó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ kò lè wá ojútùú sí.
3. Àwọn ìdàgbàsókè wo ni a sọtẹ́lẹ̀ fún ọjọ́ wa?
3 Ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Ọlọrun fi tó wa létí pé àwọn agbo ọmọ-ogun ẹ̀mí-èṣù ti jáde lọ “sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀-ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọrun Olodumare . . . sí ibìkan tí a ń pè ní Har-mageddoni ní èdè Heberu.” (Ìfihàn 16:14, 16) Láìpẹ́ ìpáyà láti ọ̀dọ̀ Jehofa yóò bo àwọn ọba, tàbí àwọn olùṣàkóso wọnnì mọ́lẹ̀. Yóò rí bíi jìnnìjìnnì tí ó dàbo àwọn ará Kenaani nígbà tí Joṣua àti àwọn ọmọ Israeli wá láti mú ìdájọ́ ṣẹ sórí wọn. (Joṣua 2:9-11) Ṣùgbọ́n lónìí ó jẹ́ ẹni náà tí Joṣua ṣàpẹẹrẹ, Kristi Jesu—“ỌBA ÀWỌN ỌBA, ÀTI OLUWA ÀWỌN OLUWA”—tí yóò ‘ṣá àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn’ ní ìfihàn “ìrunú àti ìbínú Ọlọrun Olodumare.”—Ìfihàn 19:15, 16.
4, 5. Ta ni yóò rí ìgbàlà, èésìtiṣe?
4 Ta ni yóò rí ìgbàlà ní àkókò yẹn? Kìí ṣe àwọn wọnnì tí jìnnìjìnnì dàbò ni a óò gbàlà bíkòṣe olúkúlùkù ẹni tí ó bá ti mú ìbẹ̀rù tí ó kún fún ọ̀wọ̀ ńlá dàgbà fún Jehofa. Dípò kí wọ́n jẹ́ ọlọgbọ́n lójú araawọn, àwọn wọ̀nyí “yídà kúrò nínú búburú.” Ní ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn, wọ́n ń fi ohun tí ó dára bọ́ ọkàn wọn, tí ó fi jẹ́ pé búburú ní a lé jáde kúrò nínú ìrònú wọn. Wọ́n ṣìkẹ́ ọ̀wọ̀ gbígbámúṣé fún Jehofa Oluwa Ọba-Aláṣẹ, “Onídàájọ́ gbogbo ayé,” tí ó máa tó fìyà-ikú-jẹ olúkúlùkù ẹni tí ó bá rọ̀ mọ́ ìwà-búburú, gan-an bí ó ti pa àwọn ará Sodomu oníwà ìbàjẹ́ bàlùmọ̀ run ráúráú. (Genesisi 18:25) Nítòótọ́, fún àwọn ènìyàn Ọlọrun, “ìbẹ̀rù Oluwa ni orísun ìyè, láti kúrò nínú ìkẹkùn ikú.”—Owe 14:27.
5 Ní ọjọ́ ìdájọ́ àtọ̀runwá yìí, gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n bá fi ara wọn jìn pátápátá fún Jehofa nítorí ìbẹ̀rù láti máṣe mú un bínú láé yóò wá gbádùn ìmúṣẹ òtítọ́ tí a sọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nínú Owe 3:8: “[Ìbẹ̀rù Jehofa] yóò ṣe ìlera sí ìdodo rẹ: àti ìtura sí egungun rẹ.”
Bíbọlá fún Jehofa
6. Kí ni ó níláti sún wa láti kọbiara sí Owe 3:9?
6 Ìbẹ̀rù onímọrírì wa fún Jehofa, papọ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù jíjinlẹ̀ fún un, níláti sún wa láti kọbiara sí Owe 3:9: “Fi ohun-ìní rẹ bọ̀wọ̀ fún Oluwa, àti láti inú gbogbo àkọ́bí ìbísí-oko rẹ.” A kò fi ìkìmọ́lẹ̀ mú wa bọlá fún Jehofa pẹ̀lú àwọn ọrẹ-ẹbọ wa. Ìwọ̀nyí níláti jẹ́ àfínnú-fíndọ̀ ṣe, gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn ní nǹkan bíi ìgbà 12 láti inú Eksodu 35:29 sí Deuteronomi 23:23 ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹbọ ní Israeli ìgbàanì. Àwọn èso-àkọ́so fún Jehofa wọ̀nyí níláti jẹ́ ẹ̀bùn náà gan-an tí ó dára jùlọ tí a lè múwá bí ọrẹ-ẹbọ, ní àkànṣe àfiyèsí fún ìwàrere-ìṣeun àti ìṣeun-ìfẹ́ tí a ti gbádùn láti ọwọ́ rẹ̀ wá. (Orin Dafidi 23:6) Wọ́n níláti ṣàgbéyọ ìgbèròpinnu wa láti “máa báa nìṣó . . . ní wíwá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.” (Matteu 6:33, NW) Kí sì ni ó lè jẹ́ ìyọrísí bíbọlá fún Jehofa pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun iyebíye wa? “Bẹ́ẹ̀ni àká rẹ yóò kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, àti àgbá rẹ yóò sì kún fún ọtí-wáìnì titun.”—Owe 3:10.
7. Èso àkọ́so wo ni a níláti fifún Jehofa, kí ni yóò sì jẹ́ àbárèbábọ̀ rẹ̀?
7 Ọ̀nà àkọ́kọ́ tí Jehofa ń gbà bùkún wa jẹ́ tẹ̀mí. (Malaki 3:10) Fún ìdí yìí, èso-àkọ́so tí a ń fifún un lákọ̀ọ́kọ́ níláti jẹ́ tẹ̀mí. A níláti lo àkókò, agbára, àti gbogbo ipá wa ní ṣíṣe ìfẹ́-inú rẹ̀. Èyí ẹ̀wẹ̀ yóò gbé wa ró, ní ọ̀nà kan-náà tí irú àwọn ìgbòkègbodò náà gbà jẹ́ “oúnjẹ” afúnnilókun fún Jesu. (Johannu 4:34) Ilé ìkójọpamọ́ àwọn ìpèsè wa tẹ̀mí yóò kún bámúbámú, ayọ̀ wa, tí wáìní titun ṣàpẹẹrẹ, yóò sì kún àkúnwọ́sílẹ̀. Ní àfikún, bí a ti ń fìgbọkànlé gbàdúrà fún àpọ̀tó oúnjẹ ti ara fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, a lè máa fi ìwà-ọ̀làwọ́ ṣètọrẹ déédéé láti inú àlùmọ́ọ́nì wa ní ìtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà kárí-ayé. (Matteu 6:11) Gbogbo ohun tí a ní, títíkan àwọn ọrọ̀-ìní ti ara, wá sọ́dọ̀ wa láti ọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́. Òun yóò tú ìbùkún síwájú síi jáde, dé ìwọ̀n-ààyè náà tí a bá lo àwọn ohun ṣíṣeyebíye wọ̀nyí sí ìyìn rẹ̀.—Owe 11:4; 1 Korinti 4:7.
Àwọn Ìbáwí-Ìtọ́sọ́nà Onífẹ̀ẹ́
8, 9. Báwo ni a ṣe nílatí wo ìbáwí-ìtọ́sọ́nà àti ìbáwí?
8 Ní ẹsẹ 11 àti 12, Owe orí 3 tún sọ̀rọ̀ nípa ipò-ìbátan aláyọ̀ ti baba-tọmọ tí ń bẹ nínú àwọn ìdílé oníwà-bí-Ọlọ́run, àti pẹ̀lú láàárìn Jehofa àti àwọn àyànfẹ́ ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí lórí ilẹ̀-ayé. A kà pé: “Ọmọ mi, máṣe kọ ìbáwí Oluwa; bẹ́ẹ̀ni kí agara ìtọ́ni rẹ̀ kí ó máṣe dá ọ: nítorí pé ẹni tí Oluwa fẹ́ òun níí tọ́, gẹ́gẹ́ bí baba tií tọ́ ọmọ tí inú rẹ̀ dùn sí.” Àwọn ènìyàn ayé ṣe họ́ọ̀ sí ìbáwí-ìtọ́sọ́nà. Àwọn ènìyàn Jehofa níláti fi ayọ̀ tẹ́wọ́gbà á. Aposteli Paulu fa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yọ láti inú Owe, ní wíwí pé: “Ọmọ mi, má ṣe aláìnáání ìbáwí Oluwa, kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ bá ọ wí: nítorí pé ẹni tí Oluwa fẹ́, òun níí báwí . . . Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísinsìnyí, bíkòṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹyìn a só èso àlááfíà fún àwọn tí a ti tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.”—Heberu 12:5, 6, 11.
9 Bẹ́ẹ̀ni, ìbáwí-ìtọ́sọ́nà àti ìbáwí jẹ́ apá pípọndandan nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yálà a gbà á láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí, nípasẹ̀ ìjọ Kristian, tàbí bí a ti ń ṣàṣàrò lórí Ìwé Mímọ́ nígbà ìdákẹ́kọ̀ọ́ wa. Ó jẹ́ ọ̀ràn ìyè àti ikú fún wa láti kọbiara sí ìbáwí, gẹ́gẹ́ bí Owe 4:1, 13 pẹ̀lú ti sọ: “Ẹyin ọmọ, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ baba, kí ẹ sì fiyèsí àti mọ òye. Di ẹ̀kọ́ mú ṣinṣin, máṣe jẹ́ kí ó lọ; pa á mọ́, nítorí òun ni ẹ̀mí rẹ.”
Ayọ̀ Títóbi Jùlọ
10, 11. Kí ni díẹ̀ lára àwọn apá-ẹ̀ka ọ̀rọ̀ dídùn inú Owe 3:13-18?
10 Àwọn gbólóhùn-ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀lé e nísinsìnyí ti lẹ́wà tó, nítòótọ́ wọ́n jẹ́ ‘ọ̀rọ̀ dídùn àti ọ̀rọ̀ òtítọ́’! (Oniwasu 12:10) Àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí ti Solomoni wọ̀nyí ṣàpèjúwe ayọ̀ tòótọ́. Wọ́n jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí a níláti kọ sórí ọkàn-àyà wa. A kà pé:
11 “Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó wá ọgbọ́n rí, àti ọkùnrin náà tí ó gba òye. Nítorí tí owó rẹ̀ ju owó fàdákà lọ, èrè rẹ̀ sì ju ti wúrà dáradára lọ. Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ: àti ohun gbogbo tí ìwọ lè fẹ́, kò sí èyí tí a lè fi wé e. Ọjọ́ gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ọrọ̀ àti ọlá. Ọ̀nà rẹ̀, ọ̀nà dídùn ni, àti gbogbo ipa-ọ̀nà rẹ̀, àlááfíà. Igi ìyè níí ṣe fún gbogbo àwọn tí ó dì í mú: ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó dì í mú ṣinṣin.”—Owe 3:13-18.
12. Báwo ni ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ ṣe níláti ṣàǹfààní fún wa?
12 Ọgbọ́n—a ti mẹ́nukàn án níye-ìgbà tó nínú ìwé Owe, ìgbà 46 lápapọ̀! “Ìbẹ̀rù Oluwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n.” Èyí ni ọgbọ́n oníwà-bí-Ọlọ́run, gbígbéṣẹ́ tí a gbékarí ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ń mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ darí araawọn láìséwu la ẹ̀fúùfù-líle eléwu tí ń fẹ́ tagbára-tagbára nínú ayé Satani kọjá. (Owe 9:10) Ìfòyemọ̀, tí a tọ́kasí ní ìgbà 19 nínú ìwé Owe, ni olùrànlọ́wọ́ fún ọgbọ́n, tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbógunti àwọn ìhùmọ̀ Satani. Bí ó ti ń gbégbèésẹ̀ àrékérekè rẹ̀, Elénìní ńlá náà ti ní ìrírí ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n a ní ohun kan tí ó ṣeyebíye fíìfíì ju ìrírí lọ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́—ìfòyemọ̀ oníwà-bí-Ọlọrun, agbára-ìṣe náà láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ àti láti yan ọ̀nà tí ó yẹ láti gbà. Èyí ni ohun tí Jehofa ń kọ́ wa nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Owe 2:10-13; Efesu 6:11.
13. Kí ni ó lè dáàbòbò wá ní àwọn àkókò ìnira níti ètò-ọrọ̀-ajé, báwo sì ni?
13 Rúdurùdu ètò-ọrọ̀-ajé tí ó wà nínú ayé òde-ìwòyí jẹ́ olùṣèfilọ̀ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ inú Esekieli 7:19: “Wọn ó sọ fàdákà wọn sí ìgboro, wúrà wọn ni a ó sì mú kúrò; fàdákà wọn àti wúrà wọn kì yóò sì lè gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú Oluwa.” Gbogbo ọrọ̀ ohun ti ara lórí ilẹ̀-ayé kò tilẹ̀ ṣeé fiwéra rárá pẹ̀lú agbára ìgbàlà ti ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀. Ọlọgbọ́n Ọba Solomoni sọ ní àkókò-ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn pé: “Ààbò ni ọgbọ́n, àní bí owó ti jẹ́ ààbò: ṣùgbọ́n èrè ìmọ̀ ni pé, ọgbọ́n fi ìyè fún àwọn tí ó ní in.” (Oniwasu 7:12) Gbogbo àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà títunilára ti Jehofa lónìí tí wọ́n sì fi ọgbọ́n yan “ọjọ́ gígun,” ìyè àìnípẹ̀kun tí ó jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọrun fún olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jesu, jẹ́, aláyọ̀ nítòótọ́!—Owe 3:16; Johannu 3:16; 17:3.
Mímú Ọgbọ́n Tòótọ́ Dàgbà
14. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jehofa ti gba fi ọgbọ́n àwòfiṣàpẹẹrẹ hàn?
14 Ó bọ́síi gẹ́lẹ́ pé kí àwa ènìyàn, tí a dá ní àwòrán Ọlọrun, làkàkà láti mú ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ dàgbà, àwọn ànímọ́ tí Jehofa fúnraarẹ̀ fihàn nínú ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá yíyanilẹ́nu rẹ̀. “Ọgbọ́n ni Oluwa fi fi ìdí ayé sọlẹ̀, [ìfòyemọ̀, NW] ni ó sì fi pèsè àwọn ọ̀run.” (Owe 3:19, 20) Ó ń báa lọ láti ṣẹ̀dá àwọn ohun alààyè, kìí ṣe nípasẹ̀ ọ̀nà ìṣiṣẹ́ àdììtú ẹfolúṣọ̀n kan, tí kò ṣeé ṣàlàyé, bíkòṣe nípasẹ̀ àwọn ìṣe ìṣẹ̀dá ní tààràtà, ọ̀kọ̀ọ̀kan “ní irú tirẹ̀” àti fún ète tí ó lọ́gbọ́n nínú. (Genesisi 1:25) Nígbà tí a dá ènìyàn nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín pẹ̀lú òye àti agbára-ìṣe tí ó ga fíìfíì ju ti àwọn ẹranko, àtẹ́wọ́-ìyìn àwọn ọmọkùnrin Ọlọrun tí wọ́n jẹ́ angẹli ti gbọ́dọ̀ dún kí ó sì dún ládùn-ún-tún-dún la àwọn ọ̀run já. (Fiwé Jobu 38:1, 4, 7.) Ìrírantẹ́lẹ̀ onífòyemọ̀ ti Jehofa, ọgbọ́n rẹ̀, àti ìfẹ́ rẹ ni a rí ní kedere nínú gbogbo àwọn èso-iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé.—Orin Dafidi 104:24.
15. (a) Èéṣe tí kò fi tó láti wulẹ̀ mú ọgbọ́n dàgbà? (b) Ìgbọ́kànlé wo ní Owe 3:25, 26 níláti mú sọjí nínú wa?
15 Kìí ṣe kìkì pé a níláti mú àwọn ànímọ́ Jehofa ti ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ dàgbà nìkan ni ṣùgbọ́n a tún níláti dì wọ́n mú ṣinṣin, kí a máṣe dẹwọ́ dẹngbẹrẹ láé nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó fún wa ní ìṣílétí pé: “Ọmọ mi, máṣe jẹ́ kí wọn kí ó lọ kúrò ní ojú rẹ: pa ọgbọ́n tí ó yè, àti [ìfòyemọ̀, NW] mọ́: bẹ́ẹ̀ni wọn ó máa jẹ́ ìyè sí ọkàn rẹ, àti oore-ọ̀fẹ́ sí ọrùn rẹ.” (Owe 3:21, 22) Nípa báyìí a lè rìn láìléwu àti pẹ̀lú àlááfíà ọkàn, àní ní ọjọ́ “ìparun òjijì” náà tí ń bọ̀wá gẹ́gẹ́ bí olè èyí tí yóò dé sórí ayé Satani. (1 Tessalonika 5:2, 3) Nígbà ìpọ́njú ńlá náà fúnraarẹ̀, ìwọ kì yóò “fòyà ẹ̀rù òjijì, tàbí ìdahoro àwọn ènìyàn búburú, nígbà tí ó dé. Nítorí Oluwa ni yóò ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ, yóò sì pa ẹsẹ̀ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú àtimú.”—Owe 3:23-26.
Ìfẹ́ fún Oore Ṣíṣe
16. Ìgbésẹ̀ wo ní a béèrè pé kí àwọn Kristian gbé ní àfikún sí ìtara nínú iṣẹ́-òjísẹ́ náà?
16 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọjọ́ fún fífi ìtara hàn nínú wíwàásù ìhìnrere Ìjọba yìí láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìjẹ́rìí yìí ni a gbọ́dọ̀ fi àwọn ìgbòkègbodò Kristian mìíràn tì lẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ ní Owe 3:27, 28: “Máṣe fawọ́ ire sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí íṣe tirẹ̀, bí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é. Máṣe wí fún ẹnìkejì rẹ pé, Lọ, kí o sì padà wá, bí ó bá sì di ọ̀la, èmi ó fi fún ọ; nígbà tí ìwọ ní in ní ọwọ́ rẹ.” (Fiwé Jakọbu 2:14-17.) Bí ọ̀pọ̀ nínú aráyé ti di èyí tí òṣì àti ìyàn gbámú, àwọn ìkésíni kánjúkánjú ti wà fún wa láti ran àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa lọ́wọ́, ní pàtàkì àwọn ará wa nípa tẹ̀mí. Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti dáhùnpadà?
17-19. (a) Àìní kánjúkánjú wo ní a kúnjú rẹ̀ ní 1993, pẹ̀lú ìdáhùnpadà wo sì ni? (b) Kí ni ó fihàn pé àwọn ará wa tí a ń fòòró “ń di ajagunmólú pátápátá”?
17 Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀wò: Ní ọdún tí ó kọjá, ìkésíni kánjúkánjú kan fún ìrànlọ́wọ́ wá láti Yugoslavia àtijọ́. Ẹgbẹ́-àwọn-ará ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ nítòsí dáhùnpadà lọ́nà yíyanilẹ́nu. Ní àwọn oṣù tí otútù mú ní ìgbà-otútù tí ó kọjá, ó ṣeéṣe fún àwùjọ-òṣìṣẹ́ olùpèsè ìrànlọ́wọ́ láti wọ àwọn agbegbe tí ogun ti ń jà, ní fífọkọ̀ kó àwọn ìtẹ̀jáde tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, aṣọ ìgbotútù, oúnjẹ, àti àwọn egbòogi lọ sọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ṣaláìní. Ní àkókò-ìṣẹ̀lẹ̀ kan, àwọn ará béèrè fún ìyọ̀ǹda láti kó àwọn ìpèsè ìrànlọ́wọ́ tí ó wọn tọ́ọ̀nù 15, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ìyọ̀ǹda náà gbà, ó jẹ́ ti 30 tọ́ọ̀nù! Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Austria yára kó ọkọ̀ ẹrù mẹ́ta mìíràn ráńṣẹ́. Lápapọ̀, tọ́ọ̀nù 25 dé ibi tí a fẹ́ kí wọ́n dé sí. Ẹ wo bí inú àwọn ará wa ti dùn tó láti gba àwọn ìpèsè ti ara àti tẹ̀mí pípọ̀ kítikìti wọ̀nyí!
18 Báwo ni àwọn tí wọ́n gba ìpèsè wọ̀nyẹn ṣe dáhùnpadà? Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, alàgbà kan kọ̀wé pé: “Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ní Sarajevo wàláàyè ara wọn sì le, èyí tí ó sì ṣe pàtàkì jùlọ ni pé, a ṣì jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí láti farada ogun tí ó lòdìsọ́gbọ́n yìí. Ipò-ọ̀ràn náà ṣòro gidigidi níti oúnjẹ. Ǹjẹ́ kí Jehofa bùkún yín kí ó sì san èrè-ẹ̀san fún yín fún àwọn ìsapá tí ẹ ti ṣe fún wa. Àwọn aláṣẹ ní àkànṣe ọ̀wọ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nítorí ọ̀nà ìgbésí-ayé wọn tí ó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ àti nítorí ọ̀wọ̀ wọn fún àwọn aláṣẹ. Àwa pẹ̀lú ṣọpẹ́ fún oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹ kó wá fún wa.”—Fiwé Orin Dafidi 145:18.
19 Àwọn arákùnrin tí a wuléwu wọ̀nyí ti fi ìmọrírì hàn, pẹ̀lú, nípa iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá onítara wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn aládùúgbò tọ̀ wọ́n wá ní bíbéèrè fún àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú-ilé. Ní ìlú-ńlá Tuzla, níbi tí a kó tọ́ọ̀nù márùnún oúnjẹ ìrànlọ́wọ́ lọ, ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú 40 àwọn akéde ròyìn wákàtí 25 ní ìpíndọ́gba nínú iṣẹ́-ìsìn ní oṣù náà, ní ìtìlẹ́yìn dáradára fún àwọn akéde mẹ́sàn-án nínú ìjọ náà. Wọ́n ní iye pípẹtẹrí ti 243 tí wọ́n wá síbi Ìṣe-Ìrántí ikú Jesu. Nítòótọ́ àwọn arákùnrin ọ̀wọ́n wọ̀nyí “ń di ajagunmólú pátápátá nípasẹ̀ ẹni náà tí ó nífẹ̀ẹ́ wa.”—Romu 8:37, NW.
20. Irú “ìmúdọ́gba” wo ni ó ti wáyé ní Soviet Union àtijọ́?
20 Ìwà ọ̀làwọ́ tí a fihàn nípasẹ̀ àwọn ọkọ̀ akẹ́rù ńlá tí wọ́n kó oúnjẹ ìrànlọ́wọ́ àti aṣọ ìgbotútù tí a kó ráńṣẹ́ sí Soviet Union àtijọ́ ni ìtara àwọn ará tí ó wà níbẹ̀ ti bá dọ́gba pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, ní Moscow iye àwọn tí ó wá síbi Ìṣe-Ìrántí lọ́dún yìí jẹ́ 7,549, ní ìfiwéra pẹ̀lú 3,500 ní ọdún tí ó kọjá. Ní sáà-àkókò kan-náà, àwọn ìjọ ní ìlú-ńlá yẹn bísíi láti orí 12 sí 16. Ní gbogbo Soviet Union àtijọ́ (kí a mú Baltic States kúrò), ìbísí nínú àwọn ìjọ jẹ́ ìpín 14 nínú ọgọ́rùnún, nínú iye àwọn akéde Ìjọba ìpín 25 nínú ọgọ́rùnún, àti nínú àwọn àṣáájúọ̀nà ìpín 74 nínú ọgọ́rùn–ún. Èyí ti jẹ́ ẹ̀mí ìtara àti ìfara-ẹni-rúbọ tó! Ó ránnilétí ọ̀rúndún kìn-ìn-ní nígbà tí “ìmúdọ́gba” wà. Àwọn Kristian tí wọ́n ní àwọn ọrọ̀-ìní ohun ti ara àti tẹ̀mí ṣe àwọn ìtọrẹ ọlọ́làwọ́ fún àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní àwọn ibi tí nǹkan kò ti fi bẹ́ẹ̀ ṣẹnuure, nígbà tí ìtara àwọn tí a ń pọ́nlójú wọ̀nyí mú ayọ̀ àti ìṣírí wá fún àwọn olùṣètọrẹ náà.—2 Korinti 8:14, NW.
Kórìíra Ohun Búburú!
21. Báwo ni a ṣe fi ìyàtọ̀ hàn láàárín àwọn ọlọgbọ́n àti àwọn aṣiwèrè nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìparí ìwé Owe orí 3?
21 Orí kẹta ìwé Owe gbé ọ̀wọ́ àwọn ìfiwéra kalẹ̀ tẹ̀lé e, ó sì parí rẹ̀ pẹ̀lú ìṣílétí yìí: “Máṣe ìlara aninilára, má sì ṣe yan ọ̀kan nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Nítorí pé ìríra ni ẹlẹ́gan lójú Oluwa; ṣùgbọ́n àṣírí rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn olódodo. Ègún Oluwa ńbẹ ni ilé àwọn ènìyàn búburú: ṣùgbọ́n ó bùkún ibùjókòó àwọn olóòótọ́. Nítòótọ́ ó ṣe ẹ̀yà sí àwọn ẹlẹ́yà: ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀. Àwọn ọlọgbọ́n ni yóò jogún ògo: ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.”—Owe 3:29-35.
22. (a) Báwo ni a ṣe lè yẹra fún ìpín àwọn àṣiwèrè? (b) Kí ni àwọn ọlọgbọ́n kórìíra, kí ni wọ́n sì ń múdàgbà, pẹ̀lú èrè-ẹ̀san wo sì ni?
22 Báwo ní a ṣe lè yẹra fún dídi ẹni tí a kà mọ́ àwọn aṣiwèrè? A gbọ́dọ̀ kọ́ láti kórìíra búburú, bẹ́ẹ̀ni, kí a ṣe họ́ọ̀ sí àwọn ohun tí Jehofa ṣe họ́ọ̀ sí—gbogbo àwọn ọ̀nà békebèke ti ayé oníwà-ipá, ẹlẹ́bi-ẹ̀jẹ̀ yìí. (Tún wo Owe 6:16-19.) Ní ìyàtọ̀ sí èyí, a gbọ́dọ̀ mú ohun tí ó dára dàgbà—ìdúróṣinṣin, òdodo, àti inútútù—kí ó baà lè jẹ́ pé ní ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn àti ní ìbẹ̀rù Jehofa a ó lè jèrè “ọrọ̀, ọlá, àti ìyè.” (Owe 22:4) Èyí ni yóò jẹ́ èrè-ẹ̀san fún gbogbo àwa tí a bá fi ìdúróṣinṣin fi ìṣílétí náà sílò pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀lé Jehofa.”
Kí ni Àlàyé Rẹ?
◻ Báwo ni kókó-ọ̀rọ̀ ẹṣin-ọ̀rọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣe ní ìfisílò lónìí?
◻ Báwo ni a ṣe lè bọlá fún Jehofa?
◻ Èéṣe tí a kò fi níláti fojúkéré ìbáwí?
◻ Níbo ni a ti lè rí ayọ̀ títóbi jùlọ?
◻ Báwo ni a ṣe lè nífẹ̀ẹ́ oore kí a sì kórìíra ohun búburú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn wọnnì tí wọn fi ohun tí ó dára jùlọ tí wọ́n ní rúbọ sí Jehofa ní a ó bùkún fún lọ́pọ̀-yanturu