Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Ìlú Aláààrẹ Ti Philippines
ÀWỌN erékùṣù págunpàgun 7,083 ti ilẹ̀ olóoru tí wọ́n parapọ̀ di àwọn Ìlú Aláààrẹ ti Philippines jẹ́ apá òkè àwọn òkè-ńlá pípọwọ́léra tí omi bò lápákan.a Àwọn 62,000,000 olùgbé Philippines sì fẹ́ láti máa sọ̀rọ̀ lórí èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ kókó-ọ̀rọ̀ èyíkéyìí. Ẹ̀mí jíjẹ́ ẹni tí ó dùn-ún bá sọ̀rọ̀ yìí yọrísí pápá eléso kan fún ìjẹ́rìí Ìjọba.
Jíjẹ́rìí ní Ilé-Ẹ̀kọ́
Ní erékùṣù Masbate, ó ṣeéṣe fún ọ̀dọ́ ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ gíga kan láti jẹ́rìí fún olùkọ́ àti kíláàsì rẹ̀ nígbà ìbéèrè àfidánrawò òtítọ́-tàbí-èké kan. Ó ròyìn pé:
“Gbólóhùn náà ni pé, ‘Bí Ọlọrun bá nífẹ̀ẹ́ mi, òun kì yóò fún mi ní ìṣòro tàbí kí ó jẹ́ kí n jìyà.’ Nígbà tí olùkọ́ mi yẹ ìwé ìdánwò wa wò, ó rí i pé gbogbo wọn dáhùn pé òtítọ́ àyàfi èmi. Olùkọ́ mi yọ̀ǹda fún mi láti ṣàlàyé ìdí tí mó fi dáhùn pé bẹ́ẹ̀kọ́ fún kíláàsì. Mo sọ pé kìí ṣe Ọlọrun ni ó ń fún wa ní ìṣòro, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gba ìjìyà láàyè tí ó sì yọ̀ǹda kí a dán wa wò. Ní lílo Bibeli mi, tí mo máa ń mú lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ nígbà gbogbo, mo bá kíláàsì mi ronúpọ̀ lórí àwọn ọ̀rọ̀ inú 1 Johannu 4:8, ‘Ìfẹ́ ni Ọlọrun.’ Lẹ́yìn àlàyé mi, òye ọ̀rọ̀ náà yé olùkọ́ mi, ó gbá tábìlì alápòótí rẹ̀ pẹ́pẹ́, ó sì wí pé: ‘Marilou tọ̀nà.’ Èmi nìkanṣoṣo ní mo gba ìdáhùn tí ó tọ̀nà sí ìbéèrè yìí tí mo sì gba máàkì tí ó ga jùlọ.”
Ìhìn-Iṣẹ́ Ìjọba náà Wà Níbi Gbogbo
Nígbà tí ó ń nípìn-ín nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé ní apá ibòmíràn ní Philippines, aṣáájú-ọ̀nà déédéé kan (olùpòkìkí ìhìnrere alákòókò kíkún) bá ìyá àwọn ọmọ kékeré mẹ́ta kan pàdé. Obìnrin náà fi ọkàn-ìfẹ́ onítara hàn nínú ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà, èyí sì mú kí ó rọrùn fún un láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn pé ó ń kọ́ ẹ̀kọ́ Bibeli, pàápàá láti ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ń báa nìṣó.
Ọkùnrin náà ṣí lọ sí ìlú-ńlá mìíràn pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, ní ríronú pé èyí yóò fi òpin sí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ aya rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí. Bí ó ti wù kí ó rí, kò pẹ́ tí wọ́n fi rí ibi tí obìnrin yìí ń gbé ó sì padà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀. Bí a ti lè retí, inú bí ọkọ rẹ̀ gidigidi. Ó gbé ìbínú rẹ̀ lọ sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀, níbi tí ó ti sọ ìmọ̀lára rẹ̀ fún oníbàárà kan tí ó ń bá tún ọkọ̀ ṣe. Ọkùnrin náà kò mọ̀ pé oníbàárà yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
Ẹlẹ́rìí náà ṣàlàyé pé yóò ṣàǹfààní gidigidi fún ìdílé náà lódidi bí ìyàwò rẹ̀ bá ń bá ẹ̀kọ́ Bibeli rẹ̀ nìṣó. Yóò lè bẹ̀rẹ̀ síí fi àwọn ìlànà Bibeli sílò nínú ilé náà gan-an. Ó tún dámọ̀ràn pé ọkọ náà fúnraarẹ̀ lè jàǹfààní nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọrun.
Kí ni ìjíròrò yìí yọrísí? Aya ọkùnrin náà ní òmìnira púpọ̀ síi láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ọkùnrin náà sì pinnu láti tún dá ìdílé rẹ̀ padà sí ilé tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀. Obìnrin náà tẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí níbẹ̀ débi tí ó fi di akéde Ìjọba tí kò tíì ṣèrìbọmi. Ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú tẹ́wọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, gbogbo ìdílé náà sì bẹ̀rẹ̀ síí lọ sí àwọn ìpàdé Kristian.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àfikún ìsọfúnni, wo 1994 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ NÍPA ORÍLẸ̀-ÈDÈ
Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1993
GÓŃGÓ IYE ÀWỌN TÍ Ń JẸ́RÌÍ: 116,576
ÌṢIRÒ-ÌFIWÉRA: Ẹlẹ́rìí 1 sí 549
ÀWỌN TÍ Ó PÉSẸ̀ SÍBI ÌṢE-ÌRÁNTÍ: 357,388
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN AKÉDE TÍ WỌ́N JẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ: 22,705
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BIBELI: 94,370
IYE TÍ Ó ṢÈRÌBỌMI: 7,559
IYE ÀWỌN ÌJỌ: 3,332
Ẹ̀KA Ọ́FÍÌSÌ: MANILA
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Jíjẹ́rìí ní ibi-ọjà ń mú àwọn ìyọrísí rere wá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ẹ̀ka ọ́fíìsì Watchtower Society ní Manila