Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Gíga Jùlọ ti Àwọn Ìsìn Àgbáyé Yóò Ha Kẹ́sẹjári̇́ Bi̇́?
ỌGỌ́RỌ̀Ọ̀RÚN àwọn aṣáájú ìsìn kórajọpọ̀ níbi Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Gíga Jùlọ ti Àwọn Ìsìn Àgbáyé ẹlẹ́ẹ̀kejì tí wọ́n ṣe ní Chicago, Illinois, U.S.A., ní ìgbà ẹ̀rùn ọdún 1993. Àwọn aṣojú ìsìn Búdà, Kristẹndọm, Hindu, Ju, àti Musulumi pésẹ̀. Àwọn àjẹ́ àti àwọn olùjọ́sìn abo-ọlọ́run pésẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú. Wọ́n jíròrò ipa-iṣẹ́ wọn láti mú òpin débá ogun. Alága ìgbìmọ̀ aṣòfin gíga jùlọ náà gbà pé “ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ìforígbárí tí ó léwu jọjọ nínú ayé lónìí ní ọwọ́ ìsìn nínú.”
Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn
Ìgbìmọ̀ aṣòfin gíga jùlọ náà ha ṣàṣeyọrí bí? Ṣàkíyèsí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbi Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Gíga Jùlọ ti Àwọn Ìsìn Àgbáyé alákọ̀ọ́kọ́ ní ọ̀gọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Ìyẹn pẹ̀lú wáyé ní Chicago, ní ìgbà ẹ̀rùn ọdún 1893, iye tí ó rékọjá 40 àwọn ìsìn ni a sì ṣojú fún. Àjọìgbìmọ̀ fún Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Gíga Jùlọ ti Àwọn Ìsìn Àgbáyé náà gbà pé àwọn wọnnì tí wọ́n wá síbẹ̀ ní 1893 “gbàgbọ́ pé yóò jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ọ̀wọ́ àwọn ìkórajọpọ̀ àmúlùmálà ìgbàgbọ́ àgbáyé tí yóò pakún òye, àlàáfíà àti ìtẹ̀síwájú. Kò rí bẹ́ẹ̀. Àìrí ara gba nǹkan sí ìsìn àti ìwà-ipá ti jẹ́ apákan àwọn ogun ní 100 ọdún tí ó ti kọjá, ó sì ń báa lọ bẹ́ẹ̀ títí di òní.” Kí ni ìdí fún ìkùnà náà? Nítorí pé àpapọ̀ ìpìlẹ̀-èrò àmúlùmálà ìgbàgbọ́ ni Ọlọrun kò tẹ́wọ́gbà. Bibeli sọ pé: “Ẹ máṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.”—2 Korinti 6:14-17.
Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, ìtẹ̀jáde Zion’s Watch Tower ti September 1893 tẹnumọ́ àìsí ìtìlẹ́yìn Ìwé Mímọ́ fún Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Gíga Jùlọ tí Àwọn Ìsìn Àgbáyé nígbà tí ó sọ, ní ṣàkó pé: “Wọ́n ti hú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn láyípo alámọ̀ sísun tí wọ́n jẹ́ àgbàyanu jáde láti inú àwókù Babiloni àti àwọn ìlú-ńlá ìgbàanì mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn kan wà tí wọn kò tíì rí síbẹ̀. . . . Wọn kò tíì rí èyíkéyìí tí ó sọ nípa bí Mose àti Joṣua ti pe ‘Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Gíga Jùlọ ti Ìsìn’ ti àwọn ọmọ Moabu àti ti Ammoni, àti Edomu jọ . . . Wọn kò tíì rí èyíkéyìí tí ó sọ̀ nípa bí Samueli arúgbó tí ìlera rẹ̀ jípépé ṣe ránṣẹ́ lọ sí Gati àti Ekroni láti késí àwùjọ agbẹnusọ fún àwọn àlùfáà Dagoni láti wá sí Ṣilo kí wọ́n sì jọ pé àpérò pẹ̀lú àwọn àlùfáà Jehofa . . . Wọn kò tíì rí èyíkéyìí tí ó sọ nípa bí Elija arúgbó tí ó di àmùrè awọ ṣe dábàá ‘ìpéjọ’ pẹ̀lú àwọn àlùfáà Baali àti Moloku fún ìjíròrò ọlọ́sẹ̀ kan lórí àwọn èrò-ìgbàgbọ́ ìsìn ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, pẹ̀lú ojú-ìwòye náà láti gbé ọ̀wọ̀ tọ̀tún-tòsì ga fún ìsìn ẹnìkínní kejì.”
Ìjọba Ọlọrun—Ìrètí Kanṣoṣo Náà
Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Gíga Jùlọ ti Àwọn Ìsìn Àgbáyé kì yóò kẹ́sẹjárí. Àwọn ìwé-ìròyìn àti àwọn àyànṣaṣojú lo àwọn èdè-ìsọ̀rọ̀ bíi “rúdurùdu,” “ìrusókè-ariwo,” àti “ìdàrúdàpọ̀ aláriwo” ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ aṣòfin gíga jùlọ náà. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tì sọ, àní àwọn ọlọ́pàá dásí i láti pẹ̀tù sí àwọn ìṣèdíwọ́ méjì tí ìyapa níti ìṣèlú dásílẹ̀. Nínú ìwé-àkọsílẹ̀ kan ní 1952, ìgbìmọ̀ aṣòfin gíga jùlọ náà ṣe àkọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ète rẹ̀ pé: “Láti fìdí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Gíga Jùlọ ti Àwọn Ìsìn wíwà títílọ múlẹ̀ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ fún jíjèrè àlàáfíà àgbáyé àti òye láàárín gbogbo ènìyàn.” Ní ìyàtọ̀ ìfiwéra, Jesu sọ pé Ìjọba òun kìí ṣe apákan ayé. Bibeli tọ́ka sí Ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ojútùú kanṣoṣo náà sí àwọn ìṣòro aráyé.—Danieli 2:44; Johannu 18:36.