Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa—Báwo Ni A Ṣe Níláti Ṣe É Lemọ́lemọ́ Tó?
KÉRÉSÌMESÌ, Easter, ọjọ́ àwọn “ẹni mímọ́.” Ọ̀pọ̀ họlidé àti àwọn ayẹyẹ ìsìn ni àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm ń ṣe. Ṣùgbọ́n ìwọ ha mọ iye ayẹyẹ tí Jesu Kristi pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa ṣe bí? Ọ̀kanṣoṣo péré, ní ìdáhùn náà! Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ayẹyẹ ìsìn yòókù tí Olùdásílẹ̀ Ìsìn-Kristian fàṣẹ sí.
Ní kedere, bí Jesu bá dá kìkì ayẹyẹ kan sílẹ̀, ó ṣe pàtàkì gidigidi. Àwọn Kristian níláti ṣe é gan-an gẹ́gẹ́ bí Jesu ti pàṣẹ. Kí ni ayẹyẹ tí kò lẹ́gbẹ́ yìí?
Ayẹyẹ Kanṣoṣo Náà
Ayẹyẹ yìí ni Jesu fi lélẹ̀ ní ọjọ́ náà tí ó kú. Ó ti ṣèrántí àsè Ìrékọjá ti àwọn Ju pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Lẹ́yìn náà ó fi díẹ̀ nínú àkàrà aláìwú ti Ìrékọjá náà fún wọn, ní wíwí pé: “Èyí ni ara mi tí a fifún yín.” Tẹ̀lé ìyẹn, Jesu fi ago wáìní kan fún wọn, ní wíwí pé: “Ago yìí ni májẹ̀mú titun [nínú] ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín.” Ó tún sọ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Luku 22:19, 20; 1 Korinti 11:24-26) Ayẹyẹ yìí ni a pè ní Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa, tàbí Ìṣe-Ìrántí. Òun ni ayẹyẹ kanṣoṣo tí Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣe é.
Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì púpọ̀ sọ pé àwọn ń pa ayẹyẹ yìí mọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ayẹyẹ-ìsìn wọn yòókù, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jùlọ ń ṣayẹyẹ rẹ̀ lọ́nà tí ó yàtọ̀ sí bí Jesu ti pa á láṣẹ. Bóyá ìyàtọ̀ tí ó gbàfiyèsí jùlọ ni ìṣelemọ́lemọ́ ayẹyẹ náà. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan ń ṣe é lóṣooṣù, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àní lójoojúmọ́ pàápàá. Èyí ha ni ohun tí Jesu ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ́ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi” bí? The New English Bible sọ pé: “Ẹ ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ìrántí mi.” (1 Korinti 11:24, 25) Báwo ni a ti ń ṣe ìrántí tàbí àyájọ́ kan lemọ́lemọ́ tó? Ó sábà máa ń jẹ́ ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo lọ́dún.
Rántí, pẹ̀lú, pé Jesu bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ yìí ó sì kú lẹ́yìn náà ní oṣù Nisan 14 lórí kàlẹ́ndà àwọn Ju.a Ìyẹn jẹ́ ọjọ́ Ìrékọjá, àjọyọ̀ kan tí ń rán àwọn Ju létí ìdáǹdè títóbilọ́lá tí wọ́n ní ìrírí rẹ̀ ní Egipti ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún B.C.E. Ní àkókò náà ẹbọ ọ̀dọ́-àgùtàn kan yọrísí ìgbàlà fún àkọ́bí àwọn Ju, nígbà tí ó jẹ́ pé angẹli Jehofa pa gbogbo àkọ́bí àwọn ará Egipti.—Eksodu 12:21, 24-27.
Báwo ni èyí ṣe ṣèrànwọ́ fún òye wa? Ó dára, Kristian aposteli Paulu kọ̀wé pé: “A ti fi ìrékọjá wa, àní Kristi, rúbọ fún wa.” (1 Korinti 5:7) Ikú Jesu jẹ́ ẹbọ Ìrékọjá títóbi jù, ní fífún aráyé ní àǹfààní fún ìgbàlà kan tí ó tóbilọ́lá púpọ̀. Nítorí náà, fún àwọn Kristian, Ìṣe-Ìrántí ikú Kristi ti rọ́pò Ìrékọjá àwọn Ju.—Johannu 3:16.
Ìrékọjá jẹ́ ayẹyẹ ẹlẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Nígbà náà, lọ́nà tí ó bá ọgbọ́n ìrònú mu, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní Ìṣe-Ìrántí jẹ́. Ìrékọjá—ní ọjọ́ náà tí Jesu kú—sábà máa ń bọ́ sí ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nisan ti àwọn Ju. Fún ìdí yìí, ikú Kristi ni a níláti ṣèrántí rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ni ọjọ́ tí ó dọ́gba pẹ̀lú Nisan 14 lórí kàlẹ́ńdà. Ní 1994 ọjọ́ yẹn jẹ́ Saturday, March 26, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, èéṣe tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm kò fi tíì sọ èyí di ọjọ́ ayẹyẹ àkànṣe kan? Wíwo ọ̀rọ̀-ìtàn ní ṣókí yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.
Àṣà Àwọn Aposteli Wà Nínú Ewu
Kò sí iyèméjì kankan pé ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E., àwọn wọnnì tí àwọn aposteli Jesu tọ́sọ́nà ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọ̀rúndún kejì, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ síí yí àkókò ayẹyẹ ìrántí rẹ̀ padà. Wọ́n ṣe Ìṣe-Ìrántí náà ní ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú ọ̀sẹ̀ (tí a ń pè ní Sunday nísinsìnyí), kìí ṣe ní ọjọ́ náà tí ó bá Nisan 14 dọ́gba. Èéṣe tí wọ́n fi ṣe ìyẹn?
Fún àwọn Ju, ọjọ́ kan máa ń bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bíi agogo mẹ́fà ní ìrọ̀lẹ́ títí lọ dé àkókò kan-náà ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lé e. Jesu kú ní Nisan 14, 33 C.E., èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ láti ìrọ̀lẹ́ Thursday títí dé ìrọ̀lẹ́ Friday. A jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, ní kùtùkùtù òwúrọ̀ Sunday. Àwọn kan fẹ́ kí a máa ṣe ayẹyẹ ìrántí ikú Jesu ní ọjọ́ kan tí a yàn nínú ọ̀sẹ̀ náà lọ́dọọdún, dípò kí ó jẹ́ ní ọjọ́ tí Nisan 14 bá bọ́ sí. Wọ́n tún wo ọjọ́ àjíǹde Jesu gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ṣe pàtàkì ju ọjọ́ ikú rẹ̀ lọ. Fún ìdí yìí, wọ́n fàbọ̀ sórí Sunday.
Jesu pàṣẹ pé kí a ṣèrántí ikú òun, kìí ṣe àjíǹde òun. Níwọ̀n bí Ìrékọjá àwọn Ju sì ti máa ń bọ́ sí ọjọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́dọọdún, ní ìbámu pẹ̀lú kàlẹ́ndà Gregory tí àwa ń lò nísinsìnyí, ó wulẹ̀ bá ìwà-ẹ̀dá mu pé kí ohun kan náà jẹ́ òtítọ́ nípa Ìṣe-Ìrántí. Nítorí náà ọ̀pọ̀lọpọ̀ yàn láti faramọ́ ìṣètò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà kí wọ́n sì ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa ní Nisan 14 lọ́dọọdún. Nígbà tí ó yá a bẹ̀rẹ̀ síí pè wọ́n ní àwọn Quartodeciman, tí ó túmọ̀sí “Àwọn Ọlọ́jọ́ Kẹrìnlá.”
Àwọn ọ̀mọ̀wèé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan mọ̀ dájú pé “Àwọn Ọlọ́jọ́ Kẹrìnlá” wọ̀nyí ń tẹ̀lé àwòkọ́ṣe àwọn aposteli ìpilẹ̀ṣẹ̀. Òpìtàn kan sọ pé: “Níti ọjọ́ ṣíṣayẹyẹ Pascha [Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa], lílo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Quartodeciman ti Asia ń báa nìṣó pẹ̀lú ti ṣọ́ọ̀ṣì Jerusalemu. Ní ọ̀rúndún kejì àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyí níbi Pascha wọn ní Nisan ọjọ́ kẹrìnlá ṣèrántí ìràpadà tí ikú Kristi ṣe.”—Studia Patristica, Ìdìpọ̀ Karùn ún, 1962, ojú-ìwé 8.
Àríyànjiyàn kan Gbèrú
Nígbà tí ọ̀pọ̀ ní Asia Kékeré tẹ̀lé àṣà àwọn aposteli, wọ́n ya Sunday sọ́tọ̀ fún ṣíṣayẹyẹ ní Romu. Ní nǹkan bí ọdún 155 C.E., Polycarp ti Smyrna, aṣojú ìjọ Asia, ṣèbẹ̀wò sí Romu láti jíròrò èyí àti àwọn ìṣòro mìíràn. Lọ́nà tí ó baninínújẹ́, kò sí ìfohùnṣọ̀kan èyíkéyìí lórí kókó-ọ̀ràn yìí.
Irenaeus ti Lyons kọ̀wé nínú lẹ́tà kan pé: “Kò ṣeéṣe fún Anicetus [ti Romu] láti yí Polycarp lérò padà láti máṣe ṣe ohun tí ó ti ń fìgbà gbogbo ṣayẹyẹ rẹ̀ pẹ̀lú Johannu ọmọlẹ́yìn Oluwa wa àti àwọn aposteli yòókù tí òun bá kẹ́gbẹ́pọ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni Polycarp pẹ̀lú kò tíì yí Anicetus lọ́kàn padà láti ṣe é, nítorí tí ó sọ pé ó yẹ kí òun rọ̀ mọ́ àṣà àwọn àgbà tí wọ́n wà ṣáájú òun.” (Eusebius, Ìwé 5, orí 24) Ṣàkíyèsí pé a ròyìn rẹ̀ pé Polycarp gbé ìdúró rẹ̀ karí ọlá-àṣẹ àwọn aposteli, nígbà tí Anicetus dúró lé àṣà àwọn àgbà tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ ní Romu.
Àríyànjiyàn yìí gbónájanjan síi ní apá ìparí ọ̀rúndún kejì C.E. Ní nǹkan bíi 190 C.E., Victor ni a yànsípò ní pàtó gẹ́gẹ́ bíi biṣọọbu Romu. Ó gbàgbọ́ pé Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa ni a níláti ṣe ní ọjọ́ Sunday, ó sì wá ìtìlẹ́yìn àwọn aṣáájú púpọ̀ mìíràn síi bí ó ti lè ṣe tó. Victor fipá mú àwọn ìjọ Asia láti yípadà sí ìṣètò ọjọ́ Sunday náà.
Ní fífèsìpadà lórúkọ Asia Kékeré, Polycrates ti Efesu kọ̀ láti juwọ́sílẹ̀ fún ìkìmọ́lẹ̀ yìí. Ó wí pé: “Àwa pa ọjọ́ náà mọ́ láìyí i padà, bẹ́ẹ̀ ni a kò fikún un, a kò sì yọ kúrò.” Lẹ́yìn náà ni ó wá ṣàkọsílẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn aláṣẹ, títíkan aposteli Johannu. Ó rinkinkin mọ́ ọn pé: “Gbogbo àwọn wọ̀nyí pátá pa ọjọ́ kẹrìnlá mọ́ fún Pascha gẹ́gẹ́ bí Ìhìnrere ti sọ, láìyapa kúrò nínú rẹ̀ lọ́nà èyíkéyìí.” Polycrates fikún un pé: “Ní tèmi o, ẹ̀yin ará, . . . ìhalẹ̀mọ́ni kò lè kópayà bá mi. Nítorí pé àwọn tí wọ́n sàn jù mí lọ ti sọ pé, Àwa kò gbọ́dọ̀ má gbọ́ ti Ọlọrun ju ti ènìyàn lọ.”—Eusebius, Ìwé 5, orí 24.
Èsì yìí kò dùn mọ́ Victor nínú. Ìwé ìtàn kan sọ pé ó “yọ gbogbo Ṣọ́ọ̀ṣì Asia kúrò lẹ́gbẹ́, ó sì fi ìwé-ìsọfúnni rẹ̀ tí ń lọ yíká ránṣẹ́ sí gbogbo Ṣọ́ọ̀ṣì tí ó tẹ́wọ́gba èrò rẹ̀, pé wọ́n kò níláti ní ìdàpọ̀ kankan mọ́ pẹ̀lú wọn.” Bí ó ti wù kí ó rí, “ìgbésẹ̀ oníwàǹwára àti ọ̀yájú tí ó gbé yìí ni gbogbo àwọn ènìyàn ọlọgbọ́n àti oníwọ̀ntunwọ̀nsì tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ rẹ̀ kò fi ọkàn rere gbà, tí mélòókan nínú wọn sì kọ̀wé síi ní ṣàkó, ní gbígbà á nímọ̀ràn láti . . . pa ìfẹ́, ìṣọ̀kan, àti àlàáfíà mọ́.”—Antiquities of the Christian Church ti Bingham, Ìwé 20, orí 5.
A Gbé Ìpẹ̀yìndà Kalẹ̀
Láìka irú àwọn ìṣàtakò bẹ́ẹ̀ sí, àwọn Kristian ní Asia Kékeré di àwọn tí a ń kọ̀tì lọ́nà tí ń ga síi lórí ọ̀ràn ìgbà tí ó yẹ láti ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa. Àwọn ìyàtọ̀síra ti yọ́ wọlé ní àwọn ibòmíràn. Àwọn kan ń ṣayẹyẹ gbogbo sáà náà lódidi láti Nisan 14 títí jálẹ̀ Sunday tí o tẹ̀lé e. Àwọn mìíràn túbọ̀ ń ṣayẹyẹ àkókò-ìṣẹ̀lẹ̀ náà lemọ́lemọ́—lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní ọjọ́ Sunday.
Ní 314 C.E. Ìgbìmọ̀ Arles (France) gbìyànjú láti fipá sọ ìṣètò ti Romu di dandan kí wọ́n sì tẹ àfidípò èyíkéyìí mọ́lẹ̀. Àwọn Quartodeciman yòókù kò gbà pẹ̀lú wọn. Kí wọ́n baà lè yanjú èyí àti àwọn ọ̀ràn mìíràn tí ń ya àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ jíjẹ́ Kristian nínú ilẹ̀-ọba rẹ̀ nípá, olù-ọba abọ̀rìṣà náà Constantine pe ìpàdé ìjíròrò ìlànà ìsìn ti ìkópọ̀ṣọ̀kan àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àgbáyé, Ìgbìmọ̀ Nicaea ní 325 C.E. Ó gbé àṣẹ-òfin kan jáde tí ó pàṣẹ fún gbogbo àwọn tí ń bẹ ní Asia Kékeré láti faramọ́ ọ̀nà tí Romu ń gbà ṣe é.
Ó jẹ́ ohun tí ó dùnmọ́ni láti kíyèsí ọ̀kan nínú àwọn àlàyé pàtàkì tí a gbé dìde fún pípa ayẹyẹ Ìṣe-Ìrántí ikú Kristi tì ní ìbámu pẹ̀lú ọjọ́ tí a gbékarí kàlẹ́ndà àwọn Ju. Ìwé náà A History of the Christian Councils, láti ọwọ́ K. J. Hefele, ṣàlàyé pé: “A polongo rẹ̀ ní pàtàkì pé kò yẹ fún èyí, tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ nínú gbogbo àjọyọ̀, láti tẹ̀lé àṣà (ìṣirò) àwọn Ju, tí wọ́n ti fi ìwà-ọ̀daràn bíbanilẹ́rù jùlọ sọ ọwọ́ araawọn di eléèérí, tí a sì ti sọ ọkàn wọn di afọ́jú.” (Ìdìpọ̀ 1, ojú-ìwé 322) Láti wà nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ ni a wò gẹ́gẹ́ bí “‘ìtẹríba tí ń tẹ́nilógo’ fún Sinagọgu èyí tí ó bí Ṣọ́ọ̀ṣì nínú,” ni J. Juster tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú Studia Patristica, Ìdìpọ̀ Kẹrin, 1961, ojú-ìwé 412 sọ.
Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ ìkórìíra àwùjọ àwọn Ju tó! Àwọn tí wọ́n ṣayẹyẹ Ìṣe-Ìrántí ikú Jesu ní ọjọ́ náà gan-an tí ó kú ni a wò gẹ́gẹ́ bí olùtẹ̀lé àṣà àwọn Ju. Wọ́n gbàgbé pé Jesu fúnraarẹ̀ jẹ́ Ju àti pé ó ti fún ọjọ́ náà ní ìtumọ̀ nípa fífi ìwàláàyè rẹ̀ rúbọ nígbà náà nítorí aráyé. Láti ìgbà náà lọ, àwọn Quartodeciman ni a dẹ́bi fún gẹ́gẹ́ bí àwọn aládàámọ̀ àti olùyapa a sì ṣenúnibíni sí wọn. Ìgbìmọ̀ Antioku ní 341 C.E. pàṣẹ-òfin pé a níláti yọ wọ́n lẹ́gbẹ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú wọn ṣì wàláàyè ní 400 C.E., iye kéréje wọn sì ń báa lọ fún ìgbà pípẹ́ lẹ́yìn náà.
Láti àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn wá, Kristẹndọm ti kùnà láti padà sí ìṣètò ti Jesu ní ìpilẹ̀sẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n William Bright gbà pé: “Nígbà tí ọjọ́ àkànṣe kan, Friday Rere, di èyí tí wọ́n fi jin ìṣèrántí Ìjìyà-Títí-Dójú-Ikú lọ́nà yẹn, ó ti pẹ́ jù láti fi àwọn ohun tí ó níí ṣe pẹ̀lú ‘pashca’ èyí tí Paul Mímọ́ ti sopọ̀ mọ́ ikú ìrúbọ náà mọ síbẹ̀: wọ́n ti fi òmìnira kà á mọ́ àjọyọ̀ Àjíǹde náà fúnraarẹ̀, tí ìdàrúdàpọ̀ àwọn èrò sì fìdí araarẹ̀ múlẹ̀ nínú èdè ààtò àwọn Kristẹndọm elédè Griki àti Latin.”—The Age of the Fathers, Ìdìpọ̀ 1, ojú-ìwé 102.
Lónìí Ńkọ́?
‘Lẹ́yìn gbogbo ọdún wọ̀nyí,’ ní ìwọ lè béèrè, ‘ìgbà tí a ṣe Ìṣe-Ìrántí ha ṣe pàtàkì níti gidi bí?’ Bẹ́ẹ̀ni, ó ṣe pàtàkì. Àwọn ìyípadà ni a ṣe nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin ọlọ́kàn-líle tí wọ́n ń làkàkà fún agbára. Àwọn ènìyàn tẹ̀lé àwọn èrò-ọkàn ti araawọn dípò ṣíṣègbọràn sí Jesu Kristi. Ní kedere ni ìkìlọ̀ aposteli Paulu ní ìmúṣẹ pé: “Èmi mọ̀ pé, lẹ́yìn lílọ mi, ìkookò búburú yóò wọ àárín yín [àwọn Kristian], ní àìdá agbo sí, àti láàárín ẹ̀yin tìkáraayín ni àwọn ènìyàn yóò dìde, tí wọn óò máa sọ̀rọ̀ òdì, láti fa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sẹ́yìn wọn.”—Iṣe 20:29, 30.
Ọ̀ràn tí a ń gbéyẹ̀wò ni ti ṣíṣègbọràn. Ayẹyẹ kanṣoṣo péré ni Jesu gbékalẹ̀ fún àwọn Kristian láti ṣe. Bibeli ṣàlàyé ìgbà àti bí a ṣe níláti ṣayẹyẹ rẹ̀ ní kedere. Nígbà náà, ta ni ó ní ẹ̀tọ́ láti yí ìyẹn padà? Àwọn Quartodeciman ìjímìjí jìyà inúnibíni àti ìyọlẹ́gbẹ́ dípò kí wọ́n juwọ́sílẹ̀ lórí kókó-ọ̀ràn yìí.
Ìwọ lè lọ́kàn-ìfẹ́ láti mọ̀ pé àwọn Kristian ṣì wà lórí ilẹ̀-ayé tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún àwọn ohun tí Jesu fẹ́ tí wọ́n sì ń ṣayẹyẹ Ìṣe-Ìrántí ikú rẹ̀ ní ọjọ́ náà tí ó fi lélẹ̀. Ní ọdún yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yóò pàdé pọ̀ nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn káàkiri ilẹ̀-ayé lẹ́yìn agogo mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ní Saturday, March 26—nígbà tí ọjọ́ kẹrìnlá Nisan bẹ̀rẹ̀. Nígbà náà ni wọn yóò ṣe ohun náà gan-an tí Jesu sọ pé kí wọ́n ṣe ní àkókò tí ó nítumọ̀ jùlọ yìí. Èéṣe tí ìwọ kò fi ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa pẹ̀lú wọn? Nípa pípésẹ̀ síbẹ̀, ìwọ pẹ̀lú lè fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Jesu Kristi.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nisan, oṣù àkọ́kọ́ nínú ọdún àwọn Ju, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfarahàn òṣùpá titun. Nípa báyìí, Nisan 14 máa ń sábàá jẹ́ nígbà òṣùpá àrànmọ́jú.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
“ÌRÀPADÀ ṢÍṢEYEBÍYE YẸN”
Ẹbọ ìràpadà Jesu Kristi fi púpọ̀ púpọ̀ ju ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ kan lọ. Jesu sọ nípa araarẹ̀ pé: “Ọmọ-Ènìyàn tìkalárarẹ̀ kò ti wá kí a baà máa ṣe ìránṣẹ́ fún un, bíkòṣe láti máa ṣe ìránṣẹ́ fúnni, àti láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Marku 10:45) Ó tún ṣàlàyé pé: “Ọlọrun fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ̀ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Johannu 3:16) Fún àwọn òkú, ìràpadà náà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àjíǹde àti ìfojúsọ́nà fún ìyè ayérayé.—Johannu 5:28, 29.
Ikú Jesu Kristi tí ó ṣe pàtàkì lọ́nà ṣíṣekókó ní a ń ṣèrántí rẹ̀ níbi àwọn ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa. Ìrúbọ rẹ̀ ṣàṣeparí ohun púpọ̀ gan-an! Obìnrin kan tí àwọn òbí oníwà-bí-Ọlọrun kọ́ tí ó sì ti rìn nínú òtítọ́ Ọlọrun fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún sọ ọ̀rọ̀ ìmọrírì rẹ̀ jáde pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:
“Àwa ń fojúsọ́nà fún Ìṣe-Ìrántí. Ó túbọ̀ ń jẹ́ àkànṣe síi lọ́dọọdún. Mo rántí bí mo ṣe dúró nínú ilé kan tí a ti ń di òkú ní 20 ọdún sẹ́yìn, ní wíwo òkú baba mi ọ̀wọ́n àti bí mo ṣe wá ní ìmọrírì àtọkànwá tòótọ́ fún ìràpadà. Ó ti jẹ́ ìmọ̀ orí lásán ṣáájú ìgbà náà. Óò, mo mọ gbogbo Ìwé Mímọ́ náà àti bí mo ṣe lè ṣàlàyé wọn! Ṣùgbọ́n kìkì nígbà ti mo nímọ̀lára ìṣẹ̀lẹ̀ aláìṣínilórí ti ikú ni ọkàn-àyà mi tó sọ kúlúkúlú fún ayọ̀ lórí ohun tí a óò ṣàṣeparí rẹ̀ fún wa nípasẹ̀ ìràpadà ṣíṣeyebíye yẹn.”