ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 3/15 ojú ìwé 8-9
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Bahamas

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Bahamas
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Pe Ìgbàgbọ́ Titun Níjà
  • Àwọn tí Wọ́n Ṣíwá Gbọ́ Orin Titun Náà
  • Ayọ̀ Mí Kún, Ẹnu Mi Ò Sì Gbọpẹ́, Láìka Àdánù Ńláǹlà Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 3/15 ojú ìwé 8-9

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Bahamas

ORÍLẸ̀-ÈDÈ Ọlọ́ba ti Bahamas​—⁠àgbájọ àwọn 3,000 erékùṣù àti erékùṣù kékeré​—⁠tò tẹ̀léra bí ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn oníyùn rékọjá òkun dúdú bí aró tí ó fẹ̀ ní 900 kìlómítà láàárín Florida àti Cuba. Lára àwọn 267,000 olùgbé ibẹ̀ ni ẹgbẹ́ àwọn olùpolongo Ìjọba tí ń pọ̀ síi wà. Orin ìyìn wọn pe ìwé Isaiah 42:​10-⁠12 wá sọ́kàn pé: “Ẹ kọ orin titun sí Oluwa, ìyìn rẹ̀ láti òpin ayé, ẹ̀yin tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀: erékùṣù, àti àwọn tí ń gbé inú wọn. . . . Jẹ́ kí àwọn tí ń gbé àpáta kọrin, jẹ́ kí wọ́n hó láti orí òkè-ńlá wá. Jẹ́ kí wọ́n fi ògo fún Oluwa, kí wọ́n sì wí ìyìn rẹ̀ nínú erékùṣù.”

A Pe Ìgbàgbọ́ Titun Níjà

Ní July ọdún 1992, aṣáájú-ọ̀nà déédéé kan (oníwàásù Ìjọba alákòókò kíkún) fi àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli náà Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye sóde lọ́dọ̀ ẹnìkan tí o mọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ajé. Lẹ́yìn tí ọkùnrin náà ti ka ìwé náà, ó sọ fún araarẹ̀ pé, ‘Ìsìn yìí jẹ́ ohun kan tí mo gbọ́dọ̀ wádìí rẹ̀ wò.’ Ní àwọn Sunday méjì tí ó tẹ̀lé e, ó lọ sí ìpàdé méjì ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Lẹ́yìn náà, a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan pẹ̀lú rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́fà péré tí ó ti bẹ̀rẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli rẹ̀, ìpèníjà kan dìde tí yóò dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ titun wò​—⁠ṣíṣayẹyẹ ọjọ́-ìbí.

Ìdílé ọkùnrin oníṣẹ́-ajé náà ń lọ́wọ́ nínú irú àwọn ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ìfẹ́ rẹ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ru ú sókè láti máa bá ẹ̀kọ́ Bibeli rẹ̀ nìṣó. Bí ìmọ̀ rẹ̀ nípa àwọn òtítọ́ Ìwé Mímọ́ ti ń pọ̀ síi, bẹ́ẹ̀ náà ni òye rẹ̀ nípa ọjọ́-ìbí àti àwọn họlidé ayé àti ojú tí Jehofa fi wò wọ́n ń pọ̀ síi.

Nígbà tí aya ọkùnrin yìí ṣètò ìpéjọpọ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà kan fún ayẹyẹ Ọjọ́ Baba, ó fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kọ̀ láti wà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n obìnrin náà ronú pé kò fẹ́ràn òun mọ́ àti pé ó ń fi ìsìn rẹ̀ ṣáájú òun àti ìdílé. Ọkùnrin náà fi inúrere ṣàlàyé pé ohun tí òun ń kọ́ láti inú Bibeli ń ṣèrànwọ́ láti yí òun padà di ọkọ àti baba tí ó sàn jù. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ́, ìmọrírì obìnrin náà fún ìfẹ́ tí ó ní fún àwọn òtítọ́ Ìwé Mímọ́ gbèrú síi. Nísinsìnyí ó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan pẹ̀lú ìdílé rẹ̀. Ẹ sì wo ayọ̀ tí ó ní ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” ní ọdún tí ó kọjá yìí! Aya àti ọmọbìnrin rẹ̀ wà níbẹ̀ wọ́n sì rí i tí ó ṣe ìrìbọmi.

Àwọn tí Wọ́n Ṣíwá Gbọ́ Orin Titun Náà

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí wọ́n ṣíwá láti Haiti ń darapọ̀ mọ́ àwùjọ Bahamas. Ó yẹ kí àwọn pẹ̀lú gbọ́ orin titun ti òtítọ́ Ìjọba náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń gbé ní Bahamas dúpẹ́ pé àwọn tọkọtaya ará Haiti-òun-America kan ti wọ̀lú. Àwọn ẹni wọ̀nyí ti ṣèrànwọ́ láti fokunfún àwọn àwùjọ Haiti titun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dásílẹ̀ ní erékùṣù Grand Bahama àti Abaco.

Gẹ́gẹ́ bí àrànṣe síwájú síi fún àwọn ará Haiti tí wọ́n lọ́kàn-ìfẹ́ nínú ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà, àpéjọpọ̀ àgbègbè Creole àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tí a ṣe ní Bahamas wáyé láti July 31 sí August 1, 1993. Iye àwọn tí ó wá jẹ́ 214, pẹ̀lú àwọn olùṣèyàsímímọ́ titun mẹ́ta tí a baptisi. Ọ̀pọ̀ àwọn ará Haiti tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní Bahamas tí padà sí erékùsù ibí tí wọ́n ti wá tàbí kí wọ́n ti ṣí lọ sí apá ibòmíràn láti da ohùn wọn pọ̀ mọ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò ní kíkọ orin ìyìn sí Jehofa.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ NÍPA ORÍLẸ̀-ÈDÈ

Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1993a

GÓŃGÓ IYE ÀWỌN TÍ Ń JẸ́RÌÍ: 1,294

ÌṢIRÒ-ÌFIWÉRA: Ẹlẹ́rìí 1 sí 197

ÀWỌN TÍ Ó PÉSẸ̀ SÍBI ÌṢE-ÌRÁNTÍ: 3,794

ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN AKÉDE TÍ WỌ́N JẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ: 186

ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BIBELI: 1,715

IYE TÍ Ó ṢÈRÌBỌMI: 79

IYE ÀWỌN ÌJỌ: 22

Ọ́FÍÌSÌ Ẹ̀KA: NASSAU

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fun àfikún ìsọfúnni, wo 1994 Calendar of Jehovah’s Witnesses.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Gbọ̀ngàn Ìjọba àkọ́kọ́, pẹ̀lú ọ́fíìsì ẹ̀ka àti ilé míṣọ́nnárì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn Ẹlẹ́rìí fi ìtara polongo ìhìnrere náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Milton G. Henschel àti Nathan H. Knorr pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì ní Nassau ní nǹkan bíi 45 ọdún sẹ́yìn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ọ́fíìsì ẹ̀ka titun, tí a yàsímímọ́ ní February 8, 1992

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́