Àwọn Ìwé Ìtàn Fífanimọ́ra ti Josephus
TIPẸ́TIPẸ́ ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀-ìtàn ti ń sinmẹ̀dọ̀ ronú lórí àwọn ìwé fífanimọ́ra tí Josephus kọ. A bí i ní ọdún mẹ́rin péré lẹ́yìn ikú Kristi, ó jẹ́ olùfojúrí àwọn ìmúṣẹ adótùútù-pani ti àsọtẹ́lẹ̀ Jesu nípa orílẹ̀-èdè àwọn Ju ti ọ̀rúndún kìn-ín-ín. Josephus jẹ́ ọ̀gá ológun, aṣojú orílẹ̀-èdè, Farisi, àti ọ̀mọ̀wèé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀.
Àwọn ìwé tí Josephus kọ kún fún àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ń gbanilọ́kàn. Wọ́n tànmọ́lẹ̀ sí àwọn ìwé inú Bibeli nígbà tí wọ́n sì pèsè ìtọ́sọ́nà alákọsílẹ̀ fún ìrísí àyíká àti ìrísí ojú-ilẹ̀ Palestine. Abájọ tí ọ̀pọ̀ fi ka àwọn ìwé rẹ̀ sí àfikún ṣíṣeyebíye fún ibi àkójọ-ìwé-kíkà wọn!
Ìgbésí-Ayé Rẹ̀ ní Ìbẹ̀rẹ̀
A bí Joseph ben Matthias, tàbí Josephus, ní 37 C.E., ọdún kìn-ín-ní ìṣàkóso Caligula olú-ọba Romu. Baba Josephus wá láti ìdílé àlùfáà. Ó sì sọ pé ìyá òun jẹ́ ọmọ-ìran Jonathan àlùfáà àgbà ti Hasmonaea.
Nígbà tí kò tíì pé ogún ọdún, Josephus jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ onítara-ọkàn nínú Òfin Mose. Ó fìṣọ́ra wádìí kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ẹ̀ya ìsìn Ju mẹ́ta—àwọn Farisi, Sadusi, àti àwọn Essene. Ní fífaramọ́ èyí tí a mẹ́nukàn gbẹ̀yìn, ó pinnu láti gbé pẹ̀lú anìkàndágbé ní aṣálẹ̀ kan tí ń jẹ́ Bannus fún ọdún mẹ́ta, ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ Essene kan. Ní pípa èyí tì ní ẹni ọdún 19, Josephus padà sí Jerusalemu ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn Farisi.
Lílọ sí Romu àti Pípadàbọ̀
Josephus rìnrìn-àjò lọ sí Romu ní 64 C.E. láti bẹ̀bẹ̀ fún àwọn àlùfáà Ju tí Felix gómìnà ìpínlẹ̀ Judea ti rán lọ sọ́dọ̀ Olú-Ọba Nero fún ìjẹ́jọ́. Bí ọkọ̀ rẹ ti rì lójú ọ̀nà, díẹ̀ ló kù kí Josephus kú. Kìkì 80 péré nínú àwọn 600 èrò ọkọ̀ ojú-omi náà ni a yọ nínú ewu.
Nígbà ìbẹ̀wò Josephus sí Romu, òṣèré Ju kan júwe rẹ̀ fún aya Nero, olú-ọbabìnrin Poppaea. Obìnrin náà kó ipa pàtàkì nínú àṣeyọrí ohun tí ó bá wá. Ìgbórínlọ́lá ìlú-ńlá náà tẹ èrò wíwàpẹ́títí mọ́ Josephus lọ́kàn.
Nígbà tí Josephus padà sí Judea, ìṣọ̀tẹ̀ lòdìsí Romu ti fìdímúlẹ̀ ṣinṣin nínú ọkàn àwọn Ju. Pé ó jẹ́ òtúbáńtẹ́ láti jagun pẹ̀lú àwọn ará Romu ni ó gbìyànjú láti tẹ̀ mọ́ àwọn ará orílẹ̀-èdè rẹ̀ lọ́kàn. Láìlè dá wọn dúró àti bóyá nítorí ìbẹ̀rù pé wọn yóò ka òun sí ọ̀dàlẹ̀, ó tẹ́wọ́gba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Ju ní Galili. Josephus gbá àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jọ ó fún wọn ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ ó sì wá àwọn ìpèsè fún lílò àti jíjẹ sílẹ̀ ní ìmúrasílẹ̀ fún ogun lòdìsí àwọn ọmọ-ogun Romu—ṣùgbọ́n òtúbáńtẹ́ ni ó jásí. Galili ṣubú sọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun Vespasian. Lẹ́yìn ìsàgatì ọlọ́jọ́-47, wọ́n borí odi-agbára Josephus ní Jotapata.
Nígbà tí Josephus túúbá tán, ó fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ sàsọtẹ́lẹ̀ pé Vespasian yóò di olú-ọba láìpẹ́. Wọ́n tì í mọ́lé ṣùgbọ́n wọn kò fìyà jẹ ẹ́ nítorí ìsọtẹ́lẹ̀ yìí. Wọ́n dá Josephus sílẹ̀ lómìnira nígbà tí ó jásí òtítọ́. Àkókò ìyípadà kan ni ìyẹn jẹ́ nínú ìgbésí-ayé rẹ̀. Títí gbogbo àkókò tí ó kù kí ogun náà fi parí, ó ṣiṣẹ́sin àwọn ará Romu gẹ́gẹ́ bí ògbufọ̀ àti olùlàjà. Ní ṣíṣàgbéyọ inúrere tí Vespasian àti àwọn ọmọkùnrin Titus àti Domitian fihàn sí i, Josephus fi orúkọ ìdílé náà Flavius kún tirẹ̀.
Àwọn Ìwé tí Flavius Josephus Kọ
Èyí tí ó lọ́jọ́lórí jùlọ nínú àwọn ìwé tí Josephus kọ ni a pe àkọlé rẹ̀ ní The Jewish War. A gbàgbọ́ pé ó pèsè àkọsílẹ̀ onídìpọ̀ méje yìí láti fi àwòrán agbára gíga tí Romu ní hàn àwọn Ju ní kedere àti láti pèsè ìdálọ́wọ́kọ́ fún wọn ní ìlòdìsí àwọn ìdìtẹ̀ ọjọ́-iwájú. Àwọn ìwé wọ̀nyí ṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀-ìtàn àwọn Ju láti ìgbà ìkólẹ́rú Jerusalemu láti ọwọ́ Antiochus Epiphanes (ní ọ̀rúndún kejì B.C.E.) títí di ìgbà gbọ́nmisi-omi-òtó onírúdurùdu ti 67 C.E. Gẹ́gẹ́ bí olùfojúrí kan, nígbà náà ni Josephus jíròrò ogun tí ó dé òtéńté rẹ̀ ní 73 C.E.
Òmíràn nínú àwọn ìwé Josephus ni The Jewish Antiquities, ọ̀rọ̀-ìtàn àwọn Ju tí ó ní 20 ìdìpọ̀. Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Genesisi àti ìṣẹ̀dá, ó ń bá a lọ títí di ìgbà tí ogun bẹ́ sílẹ̀ pẹ̀lú Romu. Josephus tẹ̀lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìròyìn Bibeli tímọ́tímọ́, ní fífi àwọn ìtumọ̀ àtọwọ́dọ́wọ́ àti àwọn àkíyèsí láti òkèèrè wá kún un.
Josephus kọ ìròyìn ti ara-ẹni kan tí ó fún ní àkọlé tí ó rọrùn náà Life. Ó gbìyànjú nínú rẹ̀ láti dáre fún ìdúró rẹ̀ nígbà ogun ó sì gbìdánwò láti mú àwọn ẹ̀sùn tí Justu ti Tiberias fi kàn án kúrò. Ìwé kẹrin—ìgbèjà-ìdúró onídìpọ̀ méjì tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Against Apion—gbèjà àwọn Ju lòdìsí ìfinihàn lọ́nà òdì.
Ìjìnlẹ̀-Òye Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun
Kò sí iyèméjì pé ọ̀pọ̀ nínú ọ̀rọ̀-ìtàn Josephus péye. Nínú ìwé rẹ̀ tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Against Apion, ó fihàn pé àwọn Ju kò fìgbà kan rí ka àwọn ìwé Apocrypha kún apákan Ìwé Mímọ́ tí a mísí. Ó pèsè ẹ̀rí nípa ìpéye àti ìṣọ̀kan inú àwọn ìwé Ọlọrun. Josephus sọ pé: “Àwa kò ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àìlóǹkà àwọn ìwé láàárín wá, tí ọ̀rọ̀ wọn kò dọ́gba tí wọ́n sì tako araawọn, . . . àyàfi ìwé méjìlélógún péré [èyí tí ó dọ́gba pẹ̀lú pípín àwọn Ìwé Mímọ́ òde-òní sí ìwé 39], nínú èyí tí àwọn àkọsílẹ̀ gbogbo ìgbà tí ó ti kọjá wá; èyí tí a gbàgbọ́ nítòótọ́ pé ó jẹ́ ti Ọlọrun.”
Nínú ìwé The Jewish Antiquities, Josephus fi àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó gbàfiyèsí kún ìròyìn Bibeli. Ó sọ pé “Isaaki jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n” nígbà tí Abrahamu dì í tọwọ́tẹsẹ̀ fún ìrúbọ. Gẹ́gẹ́ bí Josephus ti sọ, lẹ́yìn ṣíṣèrànwọ́ ní kíkọ́ pẹpẹ náà, Isaaki sọ pé “‘lákọ̀ọ́kọ́ òun kò yẹ ní ẹni tí à bá bí, bí òun bá níláti kọ ìpinnu Ọlọrun àti ti baba òun . . . Nítorí náà ó bọ́ sórí pẹpẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kí a lè fi í rúbọ.”
Josephus fi àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyí kún ìròyìn Ìwé Mímọ́ nípa ìlọkúrò àwọn ọmọ Israeli ní Egipti ìgbàanì: “Iye àwọn tí ó lépa wọn jẹ́ ẹgbẹ̀ta kẹ̀kẹ́-ẹṣin, pẹ̀lú ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ẹlẹ́ṣin, àti ọ̀kẹ́ mẹ́wàá àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́sẹ̀, tí gbogbo wọn dira ogun.” Josephus tún sọ pé “nígbà tí Samueli di ẹni ọdún méjìlá, ó bẹ̀rẹ̀ síí sọtẹ́lẹ̀: àti pé nígbà kan tí ó wà lójú oorun, Ọlọrun fi orúkọ tí ó ń jẹ́ pè é.”—Fiwé 1 Samuel 3:2-21.
Àwọn ìwé mìíràn tí Josephus kọ pèsè ìjìnlẹ̀-òye nípa àwọn owó-orí, òfin, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀. Salome ni ó pe orúkọ obìnrin náà tí ó jó níbi àsè Herodu tí ó sì béèrè fún orí Johannu Arinibọmi. (Marku 6:17-26) Ọ̀pọ̀ ohun tí a mọ̀ nípa Herodu ní Josephus ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Ó tilẹ̀ sọ pé “kí ó baà lè fi ọjọ́-orí gígùn rẹ̀ bò, [Herodu] kun irun rẹ̀ ní àwọ̀ dúdú.”
Ìdìtẹ̀ Ńlá Lòdìsí Romu
Ní kìkì ọdún 33 lẹ́yìn tí Jesu fúnni ní àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa Jerusalemu àti tẹ́ḿpìlì rẹ̀, ìmúṣẹ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí farahàn. Àwọn ẹ̀yà-ẹgbẹ́ Ju abẹnugan ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní Jerusalemu fi dandan lé bíbọ́ àjàgà Romu kúrò. Ní 66 C.E., ìròyìn nípa èyí ni ó fa ìkójọ àti rírán àwọn legioni Romu jáde lábẹ́ Cestius Gallus, gómìnà Syria. Iṣẹ́ wọn ni láti paná ọ̀tẹ̀ náà kí wọ́n sì fìyàjẹ àwọn olùṣeláìfí. Lẹ́yìn mímú ìparun wá sórí àwọn àrọ́ko Jerusalemu, àwọn ọmọ-ogun Cestius pàgọ́ wọn yíká ìlú tí a mọ ògiri yíká náà. Ní lílo ọ̀nà-ìgbàṣe kan tí a ń pè ní testudo, àwọn ọmọ-ogun Romu ṣàṣeyọrí ní pípa àwọn apata wọn pọ̀ bí igbá-ẹ̀yìn ìjàpá fún ìdáàbòbò kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá. Ní fífẹ̀rí àṣeyọrí ọ̀nà-ìgbàṣe yìí hàn, Josephus sọ pé: “ọ̀kọ̀ tí a jù lù wọ́n jábọ́, wọ́n sì yọ̀ dànù láìṣe wọ́n ní ìpalára kankan; nítorí náà àwọn ọmọ-ogun náà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ sọ ògiri náà di aláìlágbára, láìpa àwọn fúnraawọn lára, wọ́n sì múra gbogbo àwọn nǹkan sílẹ̀ fún dídánásun géètì tẹ́ḿpìlì.”
Josephus wí pé: “Nígbà náà ni ó ṣẹlẹ̀ pé Cestius . . . pé àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ kúrò níbẹ̀ . . . Ó fi ìlú-ńlá náà sílẹ̀, láìsí ìdí kankan rárá.” Ó hàn gbangba pé láìgbèrò láti gbé Ọmọkùnrin Ọlọrun ga, Josephus ṣàkọsílẹ̀ ìṣe náà gan-an tí àwọn Kristian ní Jerusalemu ti dúró dè. Òun ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jesu Kristi! Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú, Ọmọkùnrin Ọlọrun ti kìlọ̀ pé: “Nígbà tí ẹ̀yin ba sì rí i tí a fi ogun yí Jerusalemu ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Judea kí ó sálọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàárín rẹ̀ kí wọ́n jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bẹ ní ìgbèríko kí ó máṣe wọ inú rẹ̀ lọ. Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọnnì, kí a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ.” (Luku 21:20-22) Gẹ́gẹ́ bí ìtọ́ni tí Jesu fúnni, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olùṣòtítọ́ yára sá kúrò nínú ìlú-ńlá náà, wọ́n takété, a sì dá wọn sí kúrò lọ́wọ́ ìrora ẹ̀dùn tí ó débá a lẹ́yìn náà.
Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Romu padà wá ní 70 C.E., àtubọ̀tán náà ni Josephus ṣàkọsílẹ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ lọ́nà síṣe kedere. Àkọ́bí ọmọkùnrin Vespasian, Ọ̀gágun Titus, wá láti ṣẹ́gun Jerusalemu, pẹ̀lú tẹ́ḿpìlì rẹ̀ títóbilọ́lá. Láàárín ìlú-ńlá náà, àwọn ẹ̀yà-ẹgbẹ́ tí ń bárajagun gbìyànjú láti gba àkóso. Wọ́n ṣe àwọn nǹkan tí ó rékọjá àlà, a sì ta ẹ̀jẹ̀ púpọ̀ sílẹ̀. Josephus sọ pé “àwọn kan ni àjálù abẹ́lé wọn kó ìkìmọ́lẹ̀ bá tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí wọ́n fi dàníyàn pé kí àwọn ọmọ-ogun Romu wọlé gbógun tì wọ́n,” ní ìrètí “ìdásílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ìṣẹ́ abẹ́lé.” Ó pe àwọn ọlọ̀tẹ̀ tí ń bẹ láàárín ìlú-ńlá náà ní “àwọn ọlọ́ṣà” tí wọ́n lọ́wọ́ nínú bíba ohun-ìní àwọn ọlọ́rọ̀ jẹ́ àti pípa àwọn sàràkí ènìyàn ní ìpakúpa—àwọn wọnnì tí wọ́n kẹ́fín pé wọ́n múratán láti juwọ́sílẹ̀ fún àwọn ọmọ-ogun Romu.
Láàárín ogun abẹ́lé, ipò ìgbésí-ayé ní Jerusalemu jọ́rẹ̀yìn dé ìwọ̀n tí ó ṣòro láti finúrò, a sì fi àwọn òkú sílẹ̀ láìsin. Àwọn aṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba tìkáraawọn “bá araawọn jà, bí wọ́n ti ń tẹ àwọn òkú mọ́lẹ̀ níbi tí wọ́n wà pelemọ lórí araawọn.” Wọ́n piyẹ́ àwọn ènìyàn ìlú fún oúnjẹ àti ọrọ̀. Igbe-ẹkún àwọn tí a pọ́nlójú ń báa nìṣó.
Titus gba àwọn Ju níyànjú láti yọ̀ọ̀da ìlú náà kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ gba ara wọn là. Ó “rán Josephus láti bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè wọn; nítorí pé ó tànmọ́ọ̀ pé wọ́n lè juwọ́sílẹ̀ fún ìyíléròpadà ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè tiwọn.” Ṣùgbọ́n wọ́n kẹ́gàn Josephus. Lẹ́yìn náà ni Titus kọ́ ògiri onígi ṣónṣó yí ìlú-ńlá náà ká pátá. (Luku 19:43, NW) Nígbà tí gbogbo ìrètí fún sísá àsálà di èyí tí a ké kúrò tí a sì ṣèdíwọ́ fún ìṣípòpadà kúrò lójú kan, ìyàn “pa gbogbo agboolé àti ìdílé àwọn ènìyàn náà run pátápátá.” Ìjà tí ń báa lọ náà fikún iye àwọn tí ó kú. Láìmọ̀ pé òun ń mú asọtẹ́lẹ̀ Bibeli ṣẹ, Titus ṣẹ́gun Jerusalemu. Lẹ́yìn náà, ní kíkíyèsí àwọn ògiri ràbàtà àti àwọn ilé-ìṣọ́ rẹ̀ tí a mọ odi agbára sí, ó polongo pé: “Kìí ṣe ẹlòmíràn ni ó ta àwọn Ju dànù kúrò nínú àwọn odi-agbára wọ̀nyí bíkòṣe Ọlọrun.” Iye tí ó rékọjá àádọ́ta-ọ̀kẹ́ kan àwọn Ju ni wọ́n ṣègbé.—Luku 21:5, 6, 23, 24.
Lẹ́yìn Ogun Náà
Lẹ́yìn ogun náà Josephus lọ sí Romu. Ní gbígbádùn ìtìlẹ́yìn ìdílé Flavius, ó gbé gẹ́gẹ́ bí ọlọ̀tọ̀ Romu nínú ilé-ńlá tí Vespasian ń gbé tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Titus. Nígbà náà ni Josephus lépa ìwé kíkọ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìgbésí-ayé.
Ó dùnmọ́ni láti kíyèsi pé Josephus gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ti fihàn ni ó hùmọ̀ ọ̀rọ̀ náà “Ìṣàkóso Ọlọrun.” Nípa orílẹ̀-èdè Ju, ó kọ̀wé pé: Ìjọba wa . . . ni a lè pè ní Ìṣàkóso Ọlọrun kan, nípa kíka ọlá-àṣẹ àti agbára sí ti Ọlọrun.”
Josephus kò fìgbàkan rí pe araarẹ̀ ní Kristian. Kò kọ̀wé lábẹ́ ìmísí Ọlọrun. Síbẹ̀, àwọn ìwé ìtàn fífanimọ́ra ti Josephus ní àwọn ohun-iyebíye ọ̀rọ̀-ìtàn tí ń lanilóye.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Josephus níbi àwọn ògiri Jerusalemu