ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 4/1 ojú ìwé 25-28
  • Báwo Ni Ènìyàn Ṣe Lè Jẹ́ Ní Àwòrán Ọlọrun?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Ènìyàn Ṣe Lè Jẹ́ Ní Àwòrán Ọlọrun?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ànímọ́ Jehofa
  • Àwọn Ìsapá Láti Farawé Ọlọrun
  • Báwo Ni A Ṣe Lè Túbọ̀ Dàbí Ọlọrun Lónìí?
  • Wíwàásù Ìhìnrere Náà
  • Ẹ Gbé Jèhófà Ga Nítorí Òun Nìkan Ni Ọlọ́run Tòótọ́
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
  • Mọyì Àwọn Ìwà Dáadáa tí Ọlọ́run Ní
    Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
  • “Báyìí Ni Ọlọ́run Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Wa”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Fara Wé Jèhófà—Máa Ṣe Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 4/1 ojú ìwé 25-28

Báwo Ni Ènìyàn Ṣe Lè Jẹ́ Ní Àwòrán Ọlọrun?

“ỌLỌRUN dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, ní àwòrán Ọlọrun ni ó dá a; àti akọ àti abo ni ó dá wọn.” Báyìí ni àkọsílẹ̀ tí a mísí sọ, ṣùgbọ́n kí ni ó túmọ̀sí? Báwo ní a ṣe dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ ní àwòrán Ọlọrun?​—⁠Genesisi 1:⁠27.

Wọ́n ha dàbí Ọlọrun níti ara ìyára ni bí? Bẹ́ẹ̀kọ́, ìyẹn kò lè ṣeéṣe. Ènìyàn ni ọkùnrin náà, ẹlẹ́ran-ara, tí a dá láti gbé lórí ilẹ̀-ayé. Ẹ̀mí ni Ọlọrun, tí ń gbé nínú ògo ọ̀run aláìṣeéronúwòye tí ènìyàn kankan kò tilẹ̀ lè súnmọ́. (Eksodu 33:18-⁠20; 1 Korinti 15:50) Báwo nígbà náà ni a ṣe dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọrun? Ó jẹ́ níti pé a fún ènìyàn ní agbára láti lo àwọn ànímọ́ títayọ ti Ọlọrun​—⁠ìfẹ́, ìdájọ́-òdodo, ọgbọ́n, àti agbára​—⁠àti àwọn ànímọ́ mìíràn pẹ̀lú.

Àwọn Ànímọ́ Jehofa

Àwọn ànímọ́ Jehofa Ọlọrun farahàn nínú gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀, ṣùgbọ́n a gbé wọn yọ lọ́nà fífanimọ́ra nínú ìlòsí rẹ̀ pẹ̀lú tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́, Adamu àti Efa (Romu 1:20) Ìfẹ́ rẹ̀ ni a rí níti pé ó dá ilẹ̀-ayé lọ́nà tí ó yẹwẹ́kú fún ènìyàn láti gbé nínú rẹ̀. Jehofa dá obìnrin pípé fún ọkùnrin náà láti jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ àti ìyá àwọn ọmọ rẹ̀. Ó fi àwọn méjèèjì sínú ọgbà rírẹwà kan ó sì fún wọn ní ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ohun pípọndandan láti máa bá ìwàláàyè nìṣó àti láti láyọ̀. Èyí tí ó jẹ́ àgbàyanu jùlọ ni pé, Ọlọrun fún wọn ní àǹfààní láti wàláàyè títíláé.​—⁠Genesisi 2:​7-9, 15-⁠24.

Ọgbọ́n Ọlọrun ni a rí nínú dídán tí ó dán tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́ wò. Bí wọ́n bá níláti máa báa nìṣó ní jíjẹ́ mẹ́ḿbà àgbáńlá-ayé ti Jehofa láye lọ́run bí wọ́n bá sì níláti wàláàyè gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí ìran ènìyàn, wọ́n níláti jẹ́ àpẹẹrẹ nínú ìṣòtítọ́ àti ìjọsìn tòótọ́. Nítorí náà, Jehofa fún wọn ní àǹfààní láti fi ipò ọkàn wọn hàn lábẹ́ ìdánwò kan tí ó yẹ​—⁠wọn kò níláti jẹ nínú igi ìmọ̀ rere àti búburú. Ẹ wo bí ìyẹn ti fi ọgbọ́n hàn tó níhà ọ̀dọ̀ Jehofa láti yọ̀ǹda fún ènìyàn láti fi ẹ̀rí ìgbọ́ràn àti ìfẹ́ wọn fún un hàn ṣáájú fífún wọn ní àǹfààní àgbàyanu tí òun ní lọ́kàn!

Ìdájọ́-òdodo Ọlọrun ni a rí níti àìgbagbẹ̀rẹ́ rẹ̀ lórí àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n gíga lára àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ àti àìfi àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n wọnnì bánidọ́rẹ̀ẹ́. Èyí ni a rí nínú fífún Adamu àti Efa ní àǹfààní láti ṣe ohun tí ó tọ́. Nígbà tí wọ́n sì kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀, ìdájọ́-òdodo rẹ̀ ni a rí níti mímú kí wọ́n jẹ ìyà náà tí a làsílẹ̀ fún ìṣọ̀tẹ̀.

Agbára Jehofa ni a rí níti mímú tí ó mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ. Satani, ọlọ̀tẹ̀ ńlá náà, ti dọ́gbọ́n sọ pé òpúrọ́ ni Jehofa, Satani sì nawọ́ àwọn ohun ńláǹlà sí Efa bí ó bá lè ṣàìgbọ́ràn sí Ọlọrun. (Genesisi 3:​1-⁠7) Ṣùgbọ́n Satani kò lè mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Òun kò lè dá Jehofa dúró láti máṣe lé Adamu àti Efa jáde kúrò nínú ọgbà Edeni, kò sì ṣeéṣe fún un láti dènà ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Ọlọrun sí Adamu pé: “Erùpẹ̀ sá ni ìwọ, ìwọ ó sì padà di erùpẹ̀.” (Genesisi 3:19) Bí ó ti wù kí ó rí, Jehofa kò mú ìdájọ́ ikú ṣẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, nínú èyí pẹ̀lú òun fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn síwájú síi. Ó yọ̀ǹda àkókò fún Adamu àti Efa láti mú àwọn ọmọ jáde nípasẹ̀ èyí tí ète rẹ̀ àtètèkọ́ṣe fún ìran aráyé yóò fi di èyí tí a múṣẹ nígbẹ̀yìngbẹ́yín.​—⁠Genesisi 1:⁠28.

Níkẹyìn, ìdájọ́-òdodo, ìfẹ́, agbára, àti ọgbọ́n Jehofa Ọlọrun ni a fihàn nínú ìlérí rẹ̀ láti pèsè irú-ọmọ tí yóò pa àwọn iṣẹ́ Satani run kí ó sì mú gbogbo àwọn ìyọrísí bíbaninínújẹ́ tí ó wá láti inú ìṣọ̀tẹ̀ àkọ́kọ́ lòdìsí ọba-aláṣẹ àtọ̀runwá kúrò. (Genesisi 3:15) Ẹ wo àgbàyanu Ẹlẹ́dàá tí a ní!

Àwọn Ìsapá Láti Farawé Ọlọrun

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ́ aláìpé, àwọn ènìyàn ṣì lè fi àwọn ànímọ́ Ọlọrun hàn. Fún ìdí yìí, Paulu fún àwọn Kristian ọjọ́ rẹ̀ níṣìírí pé: “Ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọrun bí àwọn ọmọ ọ̀wọ́n.” (Efesu 5:⁠1) Bí ó ti wù kí ó rí, jálẹ̀ gbogbo ìtàn, àwọn tí ó pọ̀ jùlọ ti fi àìbọ̀wọ̀ bíburú jáì hàn fún àwọn ànímọ́ Ọlọrun. Nígbà tí ó fi máa di àkókò Noa, àwọn ènìyàn ti bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Jehofa fi pinnu láti pa aráyé run àyàfi Noa àti ìdílé rẹ̀. Noa jẹ́ “olódodo. Ó fi araarẹ̀ hàn ni aláìlábàwọ́n láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀,” ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ fún Ọlọrun hàn nípa mímú àṣẹ Ọlọrun ṣẹ. “Noa sì ṣe; gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó ṣe.” (Genesisi 6:​9, 22, NW) Noa fi ìfẹ́ fún ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti ìrọ̀tímọ́tímọ́ mọ́ ìdájọ́-òdodo hàn nípa jíjẹ́ “oníwàásù òdodo.” (2 Peteru 2:⁠5) Ó fi ọgbọ́n hàn ó sì lo agbára rẹ̀ níti gidi lọ́nà títọ́ nípa títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Ọlọrun láti kan áàkì títóbi kan, kó oúnjẹ pamọ́ sínú rẹ̀, kó àwọn ẹranko jọ, kí ó sì wọ inú áàkì náà nígbà tí Jehofa bá pàṣẹ. Ó tún fi ìfẹ́ rẹ̀ fún òdodo hàn nípa ṣíṣàì yọ̀ǹda kí àwọn aládùúgbò rẹ̀ burukú sọ òun dìbàjẹ́.

Bibeli sọ nípa ọ̀pọ̀ àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n fi àwọn ànímọ́ ti Ọlọrun hàn lọ́nà tí ó farajọra. Ẹni tí ó gba ìwájú jùlọ ni Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́ àwòrán Ọlọrun pátápátá láìkùsíbìkan òun nípa bẹ́ẹ̀ sì lè sọ pé: “Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba.” (Johannu 14:⁠9) Lára àwọn ànímọ́ tí Jesu fihàn, èyí tí ó tayọ jùlọ ni ìfẹ́. Ìfẹ́ fún Baba rẹ̀ àti aráyé sún un láti fi ilé rẹ̀ ní ọ̀run sílẹ̀ kí ó sì gbé lórí ilẹ̀-ayé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. Ó sún un láti ṣe Baba rẹ̀ lógo nípasẹ̀ ìwà òdodo rẹ̀ àti láti wàásù ìhìnrere ìgbàlà fún aráyé. (Matteu 4:23; Johannu 13:31) Lẹ́yìn náà, ìfẹ́ sún Jesu láti fi ìwàláàyè pípé rẹ̀ fúnni fún ìgbàlà aráyé àti, èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ, fún ìsọdimímọ́ orúkọ Ọlọrun. (Johannu 13:⁠1) Nínú ìlàkàkà láti ṣàfarawé Ọlọrun, àpẹẹrẹ tí ó dára ju ti Jesu Kristi ha wà láti tẹ̀lé bí?​—⁠1 Peteru 2:⁠21.

Báwo Ni A Ṣe Lè Túbọ̀ Dàbí Ọlọrun Lónìí?

Báwo ni àwa lónìí, ṣe lè fi ànímọ́ Ọlọrun hàn kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ hùwà ní àwòrán Ọlọrun? Ó dára, gbé ànímọ́ náà ìfẹ́ yẹ̀wò lákọ̀ọ́kọ́. Jesu sọ pé: “Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ̀, àti gbogbo inú rẹ̀, fẹ́ Ọlọrun Oluwa rẹ.” Báwo ni a ṣe lè fi ìfẹ́ hàn fún Ọlọrun? Aposteli Johannu dáhùn pé: “Èyí ni ìfẹ́ Ọlọrun, pé kí àwa kí ó pa òfin rẹ̀ mọ́: òfin rẹ̀ kò sì nira.”​—⁠Matteu 22:37; 1 Johannu 5:⁠3.

Ní tòótọ́, láti lè pa àwọn òfin Jehofa mọ́, a níláti mọ̀ wọ́n. Ìyẹn ní nínú kíkà, kíkẹ́kọ̀ọ́, àti ṣíṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Gẹ́gẹ́ bí onipsalmu náà, ó yẹ kí a lè sọ pé: “Èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó! ìṣàrò mi ni ní ọjọ́ gbogbo.” (Orin Dafidi 119:97) Bí a ti ń ní òye tí ó túbọ̀ jinlẹ̀ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ọ̀nà ti Ọlọrun gbà ń ronú yóò wọ̀ wá lára. A óò wá fẹ́ràn òdodo a óò sì kórìíra ìwà-àìlófin. (Orin Dafidi 45:⁠7) Ibi tí Adamu ti kùnà nìyẹn. Ó mọ òfin Jehofa, ṣùgbọ́n kò fẹ́ràn rẹ̀ tó láti rọ̀ mọ́ ọn. Nígbà tí a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, a níláti máa béèrè lọ́wọ́ araawa nígbà gbogbo pé, ‘Báwo ni èyí ṣe ba mi mu? Kí ni mo níláti ṣe láti mú ki ìwà mi túbọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ànímọ́ Ọlọrun?’

Jesu tún sọ pẹ̀lú pé: “Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí araàrẹ.” (Matteu 22:39) Gbogbo ènìyàn onílera ara fẹ́ràn araarẹ̀ tí ó sì ń wa èyí tí ó dára jùlọ fún araarẹ̀. Ìyẹn kò sì burú. Ṣùgbọ́n àwa ha ń fi irú ìfẹ́ kan náà hàn sí aládùúgbò wa bí? Àwa ha ń ṣègbọràn sí àṣẹ Bibeli náà: “Máṣe fawọ́ ire sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tíí ṣe tirẹ̀, bí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é”?​—⁠Owe 3:27; Galatia 6:⁠10.

Kí ni nípa ti ànímọ́ ọgbọ́n? Wíwá tí a ń wá ọ̀nà láti fí ànímọ́ yìí hàn ń sún wa láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nítorí pé ibẹ̀ ni ilé-ìṣúra ọgbọ́n àtọ̀runwá. Orin Dafidi 119:​98-⁠100 kà pé: “Nípa àṣẹ rẹ ìwọ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ: nítorí tí o wà pẹ̀lú mi láéláé. Èmi ní iyè nínú ju gbogbo àwọn olùkọ́ mi lọ, nítorí pé ẹ̀rí rẹ ni ìṣàrò mi. Òye yé mi ju àwọn àgbà lọ, nítorí tí mo pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́.” Ní Owe 3:18, ọgbọ́n ni a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “igi ìyè.” Bí a bá ní ìmọ̀ tí a sì lò ó, a ó jèrè ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun àti èrè ìyè àìnípẹ̀kun.​—⁠Oniwasu 7:⁠12.

Kí ni nípa ìdájọ́-òdodo? Nínú ayé búburú yìí, ìdájọ́-òdodo jẹ́ ànímọ́ pàtàkì fún àwọn wọnnì tí wọn yóò wu Ọlọrun. Jesu fẹ́ òdodo (ìdájọ́-òdodo) ó sì kórìíra ìwà-àìlófin. (Heberu 1:⁠9) Àwọn Kristian lónìí ń ṣe ohun kan náà. Ìdájọ́-òdodo ń mú kí wọ́n mọrírì àwọn ànímọ́ tí ó tọ́. Wọ́n yẹra fún àwọn ọ̀nà àìṣòdodo ayé yìí wọ́n sì sọ ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun di ohun pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí-ayé wọn.​—⁠1 Johannu 2:​15-⁠17.

Níti agbára, gbogbo wa ní in dé ìwọ̀n kan. Lọ́nà ti ẹ̀dá, a ní agbára ti ara ìyára àti ti ìmòye, bí a sì ti ń dàgbà gẹ́gẹ́ bí Kristian, a ń mú agbára dàgbà ní èrò tẹ̀mí. Jehofa ń fikún agbára wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ débi pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a dàbí aláìlera, a lè ṣàṣeparí ìfẹ́-inú Jehofa. Paulu sọ pé: “Èmi lè ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Filippi 4:13) Irú agbára kan náà wà fún wa lónìí bí a bá gbàdúrà fún ẹ̀mí Jehofa.

Wíwàásù Ìhìnrere Náà

Bí a ṣe lè fi àwọn ànímọ́ mẹ́rin pàtàkì ti Ọlọrun hàn ni a rí ní kedere nínú ìṣègbọràn wa sí àṣẹ náà: “Nítorí náà ẹ lọ, ẹ máa kọ́ orílẹ̀-èdè gbogbo, kí ẹ sì máa baptisi wọn ní orúkọ Baba, àti ní ti Ọmọ, àti ní ti Ẹ̀mí Mímọ́: Kí ẹ máa kọ́ wọn láti máa kíyèsí ohun gbogbo, ohunkóhun tí mo ti pa ní àṣẹ fún yín: ẹ sì kíyèsí i, èmi wà pẹ̀lú yín nígbà gbogbo, títí ó fi dé òpin ayé.” (Matteu 28:​19, 20) Irú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ń mú ìyè wá fún àwọn tí wọ́n dáhùnpadà. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìfihàn ìfẹ́ lọ́nà dídára tó fún àwọn tí ó jẹ́ pé, lọ́nà tí ó pọ̀ jùlọ, bí àjèjì ni wọ́n rí sí wa ní ìbẹ̀rẹ̀!

Síwájú síi, irú ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ipa-ọ̀nà ọgbọ́n. Ó ń mú èso tí ó wà pẹ̀ títí wá. Nípa irú iṣẹ́ mìíràn wo ni a lè sọ pé: “Ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba araàrẹ àti àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là”? (1 Timoteu 4:16) Kò sí àwọn olùpàdánù nínú ìṣẹ sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn. Àwọn tí wọ́n fetísílẹ̀ àti àwọn tí wọ́n ń kọ́ni ń rí ìbùkún tí kò nípẹ̀kun.

Níti ìdájọ́-òdodo, àwọn Kristian ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọn ní ìlànà òdodo. A ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sin Jehofa, ‘Ọlọrun ìdájọ́-òdodo.’ (Malaki 2:17) Àwọn wọnnì tí wọ́n ya ìgbésí-ayé wọn sí mímọ́ lónìí láti ṣiṣẹ́sin Jehofa tí wọ́n sì ń báa lọ ní ìṣòtítọ́ ní a polongo ní olódodo, tí ó ń ṣamọ̀nà sí pé kí wọn la Armageddoni já.​—⁠Romu 3:24; Jakọbu 2:​24-⁠26.

Ẹ wo bí wíwàásù àti kíkọ́ni ní ìhìnrere kárí ayé ti jẹ́ ìṣàfihàn agbára tó! (Matteu 24:14) Ó gba ìfaradà láti wáàsù léraléra ní àwọn ìpínlẹ̀ níbi tí àwọn tí ó pọ̀ jùlọ kò ti fẹ́ láti gbọ́. Ṣùgbọ́n Jehofa, nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, ń fúnni ní okun tí ó pọndandan láti faradà títí dé òpin.​—⁠Isaiah 40:​30, 31; Matteu 24:13; Luku 11:⁠13.

Nítòótọ́, gẹ́gẹ́ bí aláìpé ọmọ Adamu, a kò le ṣàmúlò àwọn ànímọ́ dídára wọ̀nyí ní pípé pérépéré. Síbẹ̀, rántí pé a dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọrun, bí a bá sì làkàkà láti túbọ̀ dàbí Ọlọrun, nígbà náà ní apá kan a mu ìdí fún wíwàláàyè wa ṣẹ. (Oniwasu 12:13) Bí a bá lo araawa dé góńgó láti ṣe gbogbo ohun ti a lè ṣe tí a sì béèrè fún ìdáríjì nígbà tí a ko ba dójú ìlà, nígbà náà a lè retí láti làájá sínú ayé titun òdodo Ọlọrun, níbi ti a óò ti dé ìjẹ́pípé nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Nígbà náà a óò wà nínú paradise ilẹ̀-ayé tí àwọn ènìyàn pípé kún fọ́fọ́, tí gbogbo wọn ń fi àwọn ànímọ́ Jehofa Ọlọrun hàn ní kíkún. Ayọ̀ náà mà ga o! Níkẹyìn, ní èrò ìtumọ̀ kíkún ọ̀rọ̀ náà, àwọn ènìyàn yóò jẹ́ ní àwòrán Ọlọrun.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Jesu fi bí a ṣe lè mú àwọn ànímọ́ àtọ̀runwá Jehofa dàgbà hàn wá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Níkẹyìn, ní èrò ìtumọ̀ kíkún àwọn ènìyan yóò jẹ́ ní àwòrán Ọlọrun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́