ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 5/1 ojú ìwé 14-20
  • Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Jẹ́ Aláápọn Ní Gbogbo Ilẹ̀-Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Jẹ́ Aláápọn Ní Gbogbo Ilẹ̀-Ayé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ní Ìfojúsọ́nà fún Òpin Àkókò Àwọn Kèfèrí
  • Fífi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ti A Ti Fìdìí Rẹ̀ Múlẹ̀ Náà
  • Dídé Gbogbo Ilẹ̀-Ayé tí A Ń Gbé
  • Mímú Ìhìnrere náà Dé Ọ̀dọ̀ Gbogbo Ẹni tí A Bá Lè Mú Un Dé
  • Àwọn Oníwàásù—Àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́run Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • A Bí Ìjọba Ọlọ́run ní Ọ̀run
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 5/1 ojú ìwé 14-20

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Jẹ́ Aláápọn Ní Gbogbo Ilẹ̀-Ayé

“Ẹ ó sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé òpin ilẹ̀-ayé.”—⁠IṢE 1:⁠8.

1. Ìhìn-iṣẹ́ wo ni Jesu sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun yóò pòkìkí ní ọjọ́ wa?

NÍGBÀ tí ó ń ṣàpèjúwe iṣẹ́ tí Jehofa rán Ọmọkùnrin rẹ̀ wá sórí ilẹ̀-ayé láti ṣe, Jesu wí pé: “Èmi kò lè ṣàìmá wàásù ìjọba Ọlọrun.” (Luku 4:43) Lọ́nà kan náà, nígbà tí ó ń sọ nípa iṣẹ́ tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yóò ṣe lórí ilẹ̀-ayé nígbà tí ó bá padà wá pẹ̀lú ọlá-àṣẹ ti ọba, Jesu wí pé: “A ó sì wàásù ìhìnrere ìjọba yìí ní gbogbo ayé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”​—⁠Matteu 24:⁠14.

2. (a) Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀ pé kí a fún ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà ní ìpolongo gbígbòòrò? (b) Ìbéèrè wo ni gbogbo wa níláti bí araawa léèrè?

2 Èéṣe tí ìròyìn nípa Ìjọba Ọlọrun fi ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀? Èéṣe tí Ìjọba náà fi béèrè fún irúfẹ́ ìpolongo gbígbòòrò bẹ́ẹ̀? Ó jẹ́ nítorí pé Ìjọba Messia náà ni yóò dá ipò ọba aláṣẹ àgbáyé Jehofa láre. (1 Korinti 15:​24-⁠28) Nípasẹ̀ rẹ̀, Jehofa yóò mú ìdájọ́ ṣẹ lòdìsí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti Satani, yóò sì mú ìlérí rẹ̀ láti bùkún gbogbo ìdílé orí ilẹ̀-ayé ṣẹ. (Genesisi 22:​17, 18; Danieli 2:44) Nípa mímú kí a jẹ́rìí nípa Ìjọba náà, Jehofa ti ṣàwárí àwọn wọnnì tí òun ti fòróróyàn lẹ́yìn náà láti jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Ọmọkùnrin rẹ̀. Nípasẹ̀ ìpolongo Ìjọba, iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ kan ni a ń ṣàṣeparí rẹ̀ lónìí pẹ̀lú. (Matteu 25:​31-⁠33) Jehofa fẹ́ kí gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè mọ̀ nípa ète rẹ̀. Ó fẹ́ kí wọ́n ní àǹfààní láti yan ìyè gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ-abẹ́ Ìjọba rẹ̀. (Johannu 3:16; Iṣe 13:47) Ìwọ ha ń nípìn-⁠ín kíkún nínú pípòkìkí Ìjọba yìí bí?

Ní Ìfojúsọ́nà fún Òpin Àkókò Àwọn Kèfèrí

3. (a) Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, kí ni kókó-ẹ̀kọ́ náà tí C. T. Russell gbé jáde lákànṣe nígbà ọ̀kan lára ìrìn-àjò tí ó kọ́kọ́ ṣe láti ṣètò àwọn àwùjọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli? (b) Kí ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìjímìjí wọnnì lóye rẹ̀ níti ipò tí wọ́n níláti fi Ìjọba Ọlọrun sí nínú ìgbésí-ayé wọn?

3 Lẹ́yìn lọ́hùn-⁠ún ní ọdún 1880, Charles Taze Russell, olóòòtú àkọ́kọ́ fún ìwé ìròyìn Ile-Iṣọ Na, rin ìrìn-àjò la ìhà àríwá ìlà-oòrùn United States já láti fi ìṣírí fún ìdásílẹ̀ àwọn àwùjọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, kókó-ẹ̀kọ́ tí ó sọ̀rọ̀ lé lórí ní “Àwọn Ohun tí ó Tanmọ́ Ìjọba Ọlọrun.” Gẹ́gẹ́ bí ó ti farahàn nínú àwọn ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ti Ile-Iṣọ Na, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli (gẹ́gẹ́ bí a ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sí nígbà náà) lóye pé bí àwọn bá níláti fi ẹ̀rí jíjẹ́ ẹni yíyẹ láti nípìn-⁠ín nínú Ìjọba Ọlọrun hàn, wọ́n gbọ́dọ̀ fi Ìjọba náà ṣe ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n lọ́kàn-ìfẹ́ sí, ní fífi ayọ̀ lo ìgbésí-ayé wọn, agbára wọn, àti àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn nínú iṣẹ́-ìsìn rẹ̀. Gbogbo ohun yòókù nínú ìgbésí-ayé níláti wà ní ipò kejì. (Matteu 13:​44-⁠46) Ẹrù-iṣẹ́ wọn ní nínú pípòkìkí ìhìnrere nípa Ìjọba Ọlọrun fún àwọn ẹlòmíràn. (Isaiah 61:​1, 2) Ìwọ̀n àyè wo ni wọ́n ṣe ìyẹn dé ṣáájú òpin Àkókò Àwọn Kèfèrí ní 1914?

4. Dé ìwọ̀n àyè wo ni ẹgbẹ́ àwọn Àkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kéréje náà ṣe ìpínkiri àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ṣáájú 1914?

4 Láti àwọn ọdún 1870 títí dé 1914, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kéréníye ní ìfiwéra. Ní 1914, kìkì 5,100 ni wọ́n ń fi taápọn taápọn nípìn-⁠ín nínú jíjẹ́rìí fún gbogbo ènìyàn. Ẹ sì wo irú ìjẹ́rìí àrà-ọ̀tọ̀ tí ó jẹ́! Ní 1881, ọdún méjì péré lẹ́yìn tí a kọ́kọ́ tẹ Ile-Iṣọ Na jáde, wọ́n dáwọ́lé ìpínkiri ìtẹ̀jáde olójú-ewé 162 náà Food for Thinking Christians. Láàárín ìwọ̀nba oṣù díẹ̀, wọ́n ṣe ìpínkiri ẹ̀dà 1,200,000. Ní ìwọ̀nba ọdún díẹ̀, àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ mẹ́wàá mẹ́wàá àwọn ìwé-àṣàrò-kúkúrú ní a ń pínkiri lọ́dọọdún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè.

5. Àwọn wo ni àwọn olùpín-ìwé-ìsìn kiri, irú ẹ̀mí wo sì ni wọ́n fihàn?

5 Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1881 pẹ̀lú, àwọn kan fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda araawọn fún iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere olùpín-ìwé-ìsìn kiri. Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n jẹ́ aṣíwájú fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà òde-òní (àwọn ajíhìnrere alákòókò-kíkún). Àwọn kan lára àwọn olùpín-ìwé-ìsìn kiri náà, tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ rìn tàbí gun kẹ̀kẹ́ ológeere, ni àwọn fúnraawọn jẹ́rìí ní èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo apá orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé. Àwọn mìíràn lọ sí àwọn pápá ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n sì jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti mú ìhìnrere náà lọ sí àwọn ilẹ̀ bíi Finland, Barbados, àti Burma (tí ń jẹ́ Myanmar nísinsìnyí). Wọ́n fi ìtara ìjíhìn iṣẹ́ Ọlọrun hàn bíi ti Jesu Kristi àti àwọn aposteli rẹ̀.​—⁠Luku 4:43; Romu 15:​23-⁠25.

6. (a) Báwo ní ìrìn-àjò Arákùnrin Russell láti tan òtítọ́ Bibeli kálẹ̀ ti gbòòrò tó? (b) Ohun mìíràn wo ni a ṣe láti mú ìwàásù ìhìnrere tẹ̀síwájú síi ní àwọn pápá ilẹ̀ òkèèrè ṣáájú òpin Àkókò Àwọn Kèfèrí?

6 Arákùnrin Russell fúnraarẹ̀ rìnrìn-àjò lọ́nà gbígbòòrò láti tan òtítọ́ kálẹ̀. Ó lọ sí Canada léraléra; ó sọ̀rọ̀ ní Panama, Jamaica, àti Cuba; ó rin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrìn-àjò lọ sí Europe; ó sì yí ayé po nínú ìrìn-àjò ìjíhìnrere. Ó tún rán àwọn ọkùnrin mìíràn jáde láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wíwàásù ìhìnrere ní àwọn pápá ilẹ̀ òkèèrè kí wọ́n sì mú ipò iwájú. Adolf Weber ni a rán lọ sí Europe ní àárín àwọn ọdún 1890, iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ sì nasẹ̀ láti Switzerland dé France, Italy, Germany, àti Belgium. E. J. Coward ni a rán lọ sí agbègbè Caribbean. Robert Hollister ni a rán lọ sí àwọn ilẹ̀ Gábàsì ní 1912. Níbẹ̀, àwọn àkànṣe ìwé-àṣàrò-kúkúrú ni a pèsè ní èdè mẹ́wàá, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀dà lára ìwọ̀nyí ni àwọn olùṣèpínkiri tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ náà sì pínkiri jákèjádò ilẹ̀ India, China, Japan, àti Korea. Bí ìwọ bá wàláàyè nígbà náà, ọkàn-àyà rẹ yóò ha ti sún ọ láti fi gbogbo ara sapá láti mú ìhìnrere náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n wà nínú àti lẹ́yìn-òde ìpínlẹ̀ rẹ bí?

7. (a) Báwo ni a ṣe lo àwọn ìwé ìròyìn láti ṣe iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà kíkankíkan síi? (b) Kí ni sinimá “Photo-Drama of Creation” jẹ́, àwọn ènìyàn mélòó ni wọ́n sì wò ó ní ọdún kanṣoṣo péré?

7 Bí Àkókò Àwọn Kèfèrí tí ń súnmọ́ òpin wọn, a lo àwọn ìwé ìròyìn láti tẹ àwọn ìwàásù Bibeli tí Arákunrin Russell sọ jáde. Ìtẹnumọ́ wọn tí ó ṣe pàtàkì jùlọ kò sí lórí ọdún 1914, bíkòṣe, lórí ète Ọlọrun àti ìdánilójú ìmúṣẹ rẹ̀. Àwọn ìwé ìròyìn tí wọ́n pọ̀ tó 2,000 nígbà kan náà, tí wọ́n ń dé ọ̀dọ̀ 15,000,000 òǹkàwé, ń gbé àwọn ìwàásù wọn jáde déédéé. Lẹ́yìn náà, bí ọ̀yẹ̀ ọdún 1914 ti bẹ̀rẹ̀ síí là, Society bẹ̀rẹ̀ síí fi sinimá “Photo-Drama of Creation” rẹ̀ hàn fún gbogbo ènìyàn. Nínú ìfàwòránhàn mẹ́rin oníwákàtí méjì, ó gbé àwọn òtítọ́ Bibeli kalẹ̀ láti ìgbà ìṣẹ̀dá títí lọ dé àkókò Ẹgbẹ̀rúndún. Láàárín ọdún kanṣoṣo péré, àwùjọ òǹwòran tí àpapọ̀ iye wọn rékọjá àádọ́ta ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-⁠án ní North America, Europe, Australia, àti New Zealand, ti wò ó.

8. Ní 1914, ilẹ̀ mélòó ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ti mú ìhìnrere náà dé?

8 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìsọfúnni tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ti fihàn, ní apá ìparí ọdún 1914, ẹgbẹ́ àwọn ajíhìnrere onítara yìí ti tan ìpòkìkí wọn nípa Ìjọba Ọlọrun kálẹ̀ dé ilẹ̀ 68.a Ṣùgbọ́n kìkì ìbẹ̀rẹ̀ ni ìyẹn jẹ́!

Fífi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ti A Ti Fìdìí Rẹ̀ Múlẹ̀ Náà

9. Ní àwọn àpéjọpọ̀ Cedar Point, báwo ni a ṣe fi àkànṣe ìsúnniṣe fún iṣẹ́ ìjẹ́rìí Ìjọba náà?

9 Nígbà tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli péjọpọ̀ ní Cedar Point, Ohio, ní 1919, J. F. Rutherford, tí ó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, polongo pé: “Ìpè iṣẹ́ wa ti jẹ́ tí ó sì jẹ́ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ láti kéde ìjọba Messia ológo tí ń bọ̀ wá.” Ní àpéjọpọ̀ Cedar Point kejì, ní 1922, Arákùnrin Rutherford tẹnumọ́ òtítọ́ náà pé ní ìparí Àkókò Àwọn Kèfèrí, ní 1914, ‘Ọba ògo náà ti gba agbára ńlá fún araarẹ̀ ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí jọba.’ Tẹ̀lé ìyẹn, ó mú ọ̀ràn náà wá síwájú àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ní tààràtà, ní wíwí pé: “Ẹ ha gbàgbọ́ pé Ọba ògo náà ti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀ bí? Nígbà náà ẹ padà sí pápá, Óò ẹ̀yin ọmọkùnrin Ọlọrun ẹni gíga jùlọ! . . . Ẹ kéde ìhìn-iṣẹ́ náà jìnnà réré. Ayé gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Jehofa ni Ọlọrun àti pé Jesu Kristi ni Ọba àwọn ọba àti Oluwa àwọn oluwa. Ọjọ́ gbogbo àwọn ọjọ́ ni èyí. Ẹ kíyèsi, Ọba náà ti ń jọba! Ẹ̀yin ni aṣojú olùpolongo rẹ̀.”

10, 11. Báwo ni a ṣe lo rédíò, àwọn ọkọ̀ àyọ́kẹ́lẹ́ tí ń gbóhùnsáfẹ́fẹ́, àti àwọn ìwé ìsọfúnni lọ́nà gbígbéṣẹ́ láti mú òtítọ́ Ìjọba dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn?

10 Iye tí ó ju 70 ọdún ti kọjá lẹ́yìn àwọn àpéjọpọ̀ Cedar Point wọ̀nyẹn​—⁠nǹkan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 80 ọdún láti ìgbà tí Jehofa ti bẹ̀rẹ̀ síí lo ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìṣàkóso Messia ti Ọmọkùnrin rẹ̀. Dé ìwọ̀n àyè wo níti gidi ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ṣàṣeparí iṣẹ́ náà tí a làlẹ́sẹẹsẹ fún wọn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun? Ìpín wo ni ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ń ní nínú rẹ̀?

11 Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1920, rédíò di ohun tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó gẹ́gẹ́ bí ohun-èlò kan ti a lè lò láti pòkìkí ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà lọ́nà gbígbòòrò. Ní àwọn ọdún 1930, àwọn ọ̀rọ̀-àwíyé àpéjọpọ̀ tí ń gbé Ìjọba náà jáde lákànṣe gẹ́gẹ́ bí ìrètí aráyé ni àwọn ilé-iṣẹ́ rédíò alásokọ́ra tàbí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ alátagbà àti àwọn ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù tí ó yí ayé po gbé jáde. Àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí a so àwọn ẹ̀rọ gbohùngbohùn mọ́ ni a lò pẹ̀lú láti lu àwo àwọn ọ̀rọ̀-àwíyé Bibeli tí a gbà ohun rẹ̀ sílẹ̀ ní ìtagbangba. Lẹ́yìn náà, ní 1936, ní Glasgow, Scotland, àwọn arákùnrin wa bẹ̀rẹ̀ síí gbé ìsọfúnni àgbékiri kọ́rùn bí wọ́n ti ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ gba àwọn agbègbè ìṣòwò kọjá láti polówó àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé ìtagbangba. Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tí a ń gbà jẹ́rìí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní àkókò yẹn nígbà tí iye wa kéré.

12. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti fihàn, kí ni ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ jùlọ fún wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan láti fúnni ní ìjẹ́rìí?

12 Dájúdájú, Ìwé Mímọ́ mú kí ó ṣe kedere pé gẹ́gẹ́ bíi Kristian, àwa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ní ẹrù-iṣẹ́ láti jẹ́rìí. A kò wulẹ̀ lè jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ inú ìwé ìròyìn tàbí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ orí rédíò ṣe iṣẹ́ náà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristian adúróṣinṣin​—⁠àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọ̀dọ́​—⁠ti tẹ́wọ́gba ẹrù-iṣẹ́ yẹn. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ìwàásù láti ilé-dé-ilé ti di àmì kan tí a fi ń dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ̀ yàtọ̀.​—⁠Iṣe 5:42; 20:⁠20.

Dídé Gbogbo Ilẹ̀-Ayé tí A Ń Gbé

13, 14. (a) Èéṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí kan fi ń ṣí lọ sí àwọn ìlú mìíràn, àní sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pẹ̀lú, láti máa bá iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn lọ? (b) Báwo ni ìdàníyàn onífẹ̀ẹ́ fún àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ ìbí ẹni ṣe ṣèrànwọ́ láti tan ìhìnrere náà kálẹ̀?

13 Ní mímọ̀ pé ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà ni a níláti wàásù rẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé, díẹ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti fi ìrònújinlẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí wọ́n lè ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan láti dé àwọn agbègbè lẹ́yìn-òde ìpínlẹ̀ ìlú tiwọn.

14 Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ṣí lọ kúrò ní ilẹ̀ ìbí wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti lè ṣílọ nítorí àwọn àǹfààní ohun ti ara, wọ́n ti rí ohun ṣíṣeyebíye jù kan, àwọn kan ni a sì ti sún láti padà sí ilẹ̀ tàbí sí àwùjọ ibi tí a bí wọn sí láti ṣàjọpín òtítọ́ náà. Nípa báyìí, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, ìwàásù ìhìnrere náà ti gbòòrò síi ní Scandinavia, Greece, Italy, àwọn orílẹ̀-èdè Ìlà-Oòrùn Europe, àti ọ̀pọ̀ àwọn agbègbè mìíràn. Nísinsìnyí pàápàá, ní àwọn ọdún 1990, ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà ń tànkálẹ̀ ní ọ̀nà kan náà.

15. Ní àwọn ọdún 1920 àti 1930, kí ni àwọn kan tí ìṣarasíhùwà wọn dàbí èyí tí Isaiah 6:8 sọjáde ṣàṣeparí rẹ̀?

15 Ní fífi ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílò nínú ìgbésí-ayé wọn, ó ti ṣeéṣe fún àwọn kan láti mú araawọn wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún iṣẹ́-ìsìn ní àwọn ibi tí wọn kò gbé rí tẹ́lẹ̀. W. R. Brown (tí a sábà máa ń pè ní “Bible Brown”) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí. Ní 1923, ó ṣí kúrò ní Trinidad lọ sí Ìwọ̀-Oòrùn Africa, láti mú iṣẹ́ ìjíhìnrere náà tẹ̀síwájú síi. Ní àwọn ọdún 1930, Frank àti Gray Smith, Robert Nisbet, àti David Norman wà lára àwọn wọnnì tí wọ́n mú ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà lọ sí bèbè-etíkun ìlà-oòrùn Africa. Àwọn mìíràn ṣèrànwọ́ láti ro oko pápá South America. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1920, George Young, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Canada, kópa nínú iṣẹ́ náà ní Argentina, Brazil, Bolivia, Chile, àti Peru. Juan Muñiz tí ó ti sìn ní Spain, ń báa lọ ní Argentina, Chile, Paraguay, àti Uruguay. Gbogbo àwọn wọ̀nyí fi ẹ̀mí kan tí ó dàbí èyí tí Isaiah 6:8 sọjáde hàn: “Èmi nìyí; rán mi.”

16. Níbo yàtọ̀ sí àwọn ibùdó pàtàkì fún àwọn olùgbé ìlú ni a ti ń jẹ́rìí ní àwọn ọdún tí ó ṣáájú ogun?

16 Wíwàásù ìhìnrere náà ń dé àwọn agbègbè àdádó pàápàá. Àwọn ọkọ̀ ojú-omi kékeré tí àwọn Ẹlẹ́rìí ń bójútó ń ṣèbẹ̀wò sí gbogbo abúlé àwọn apẹja ní Newfoundland, bèbè etíkun Norway títí lọ dé Arctic, àwọn erékùṣù Pacific, àti àwọn èbúté ọkọ̀ Gúúsù Ìlà-Oòrùn Asia.

17. (a) Ní 1935, ilẹ̀ mélòó ni àwọn Ẹlẹ́rìí ti dé? (b) Èéṣe tí a kò fi parí iṣẹ́ náà síbẹ̀?

17 Lọ́nà tí ó yanilẹ́nu, nígbà tí ó fi máa di ọdún 1935, ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dí fún wíwàásù ní ilẹ̀ 115, wọ́n sì ti dé àwọn ilẹ̀ 34 mìíràn yálà nínú ìrìn-àjò ìwàásù tàbí nípasẹ̀ àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a fi ṣọwọ́ nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́. Síbẹ̀, iṣẹ́ náà kò tíì parí. Ní ọdún yẹn Jehofa ṣí ojú wọn payá sí ète rẹ̀ láti kó “ogunlọ́gọ̀ ńlá” kan jọ tí wọn yóò làájá tààràtà wọnú ayé titun rẹ̀. (Ìfihàn 7:​9, 10, 14, NW) Iṣẹ́ ìwàásù púpọ̀ síi ṣì wà láti ṣe!

18. Nínú iṣẹ́ ìpòkìkí Ìjọba, ipa wo ni Ilé-Ẹ̀kọ́ Gileadi àti Ilé-Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ ti gbéṣe?

18 Àní nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bo ilẹ̀-ayé mọ́lẹ̀ tí a sì fòfinde àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ilẹ̀, ilé-ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti fi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn tí wọ́n fojúsọ́nà fún dídi míṣọ́nnárì láti ṣàṣeparí iṣẹ́ tí ó tún tóbi jù kan ti ìpòkìkí Ìjọba jákèjádò gbogbo orílẹ̀-èdè. Títí di òní, àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege ní Gileadi ti ṣiṣẹ́sìn ní àwọn ilẹ̀ tí ó ju 200 lọ. Wọ́n ti ṣe ju wíwulẹ̀ fi àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde kí wọ́n sì kọjá lọ sí ibòmíràn. Wọ́n ti darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ṣètò àwọn ìjọ, wọ́n sì ti fún àwọn ènìyàn ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti tẹ́wọ́gba ẹrù-iṣẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn alàgbà àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́yege ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ ti ṣèrànwọ́ pẹ̀lú láti kúnjú àwọn àìní ṣíṣekókó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ yìí ní àwọn kọ́ńtínẹ́ǹtì mẹ́fà. A ti fi ìpìlẹ̀ lílágbára kan lélẹ̀ fún ìdàgbà síwájú síi.​—⁠Fiwé 2 Timoteu 2:⁠2.

19. Dé ìwọ̀n àyè wo ní àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ti dáhùnpadà sí ìkésíni náà láti ṣiṣẹ́sìn ní àwọn agbègbè tí àìní gbé pọ̀ jù?

19 Àwọn ẹlòmíràn ha lè ṣèrànwọ́ láti bójútó díẹ̀ lára àwọn àgbègbè ìpínlẹ̀ tí a kò tíì ṣe bí? Ní 1957, ní àwọn àpéjọpọ̀ kárí-ayé, àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ìdílé​—⁠àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí wọ́n dàgbàdénú​—⁠ni a fún ní ìṣírí láti ṣàgbéyẹ̀wò lílọ sí àwọn agbègbè tí àìní gbé pọ̀ jù láti máa gbé níbẹ̀ kí wọ́n sì máa bá iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn lọ níbẹ̀. Ìkésíni náà jọ ọ̀kan tí Ọlọrun nawọ́ rẹ̀ sí aposteli Paulu lọ́pọ̀lọpọ̀, ẹni tí ó rí ọkùnrin kan tí ń bẹ̀ ẹ́ nínú ìran pé: “Rékọjá wá sí Makedonia, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” (Iṣe 16:​9, 10) Àwọn kan ṣílọ ní àwọn ọdún 1950, àti àwọn mìíràn lẹ́yìn náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún kan ṣí lọ sí Ireland àti Colombia; ọgọ́rọ̀ọ̀rún ṣí lọ sí ọ̀pọ̀ àwọn ibòmíràn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá mẹ́wàá ṣílọ sí àwọn agbègbè tí àìní gbé pọ̀ jù láàárín orílẹ̀-èdè tiwọn.​—⁠Orin Dafidi 110:⁠3.

20. (a) Láti 1935, kí ni a ti ṣàṣeparí rẹ̀ ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ní Matteu 24:14? (b) Ní àwọn ọdún mélòókan tí ó ti kọjá, báwo ni a ṣe mú iṣẹ́ náà yárakánkán?

20 Pẹ̀lú ìbùkún Jehofa lórí àwọn ènìyàn rẹ̀, iṣẹ́ ìpolongo Ìjọba ń báa nìṣó láti máa tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìṣísẹ̀ kan tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀. Láti ọdún 1935 iye àwọn akéde ti ga síi ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po ọgọ́rin, ìwọn ìbísí nínú òtú àwọn aṣáájú-ọ̀nà sì ti jẹ́ ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-⁠ún rékọjá ìwọ̀n ìbísí nínú iye àwọn akéde. Ìṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé ni a bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ọdún 1930. Ìpíndọ́gba tí ó ju àádọ́ta-ọ̀kẹ́ mẹ́rin àti ààbọ̀ lọ ni a ń darí lóṣooṣù nísinsìnyí. Láti 1935 wá iye tí ó rékọjá billion 15 wákàtí ni a ti yàsọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìpòkìkí Ìjọba náà. Ìhìnrere náà ni a ń wàásù rẹ̀ déédéé ní ilẹ̀ 231 nísinsìnyí. Bí àwọn àgbègbè ìpínlẹ̀ ní Ìlà-Oòrùn Europe àti Africa tí ń ṣí sílẹ̀ fún ìwàásù ìhìnrere náà ní fàlàlà síi, àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé ni a ti lò lọ́nà gbígbéṣẹ́ láti fi ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà hàn ketekete níwájú gbogbo ènìyàn. Gẹ́gẹ́ bí Jehofa ti ṣèlérí ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, ní Isaiah 60:22, dájúdájú ó ‘ń mú iṣẹ́ náà yárakánkán ní àkókò rẹ̀.’ Ẹ wo bí ó ti jẹ́ àǹfààní títóbilọ́lá fún wa tó láti kópa nínú rẹ̀!

Mímú Ìhìnrere náà Dé Ọ̀dọ̀ Gbogbo Ẹni tí A Bá Lè Mú Un Dé

21, 22. Kí ni a lè ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́ níbikíbi tí a bá ti ń ṣiṣẹ́sìn?

21 Oluwa kò tíì sọ pé iṣẹ́ náà ti parí. Ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ṣì ń tẹ́wọ́gba ìjọsìn tòótọ́. Nítorí náà ìbéèrè náà dìde pé, Àwa ha ń ṣe gbogbo ohun tí ó bá ṣeéṣe láti lo àkókò náà tí sùúrù Jehofa ti yọ̀ọ̀da fún iṣẹ́ yìí lọ́nà rere bí?​—⁠2 Peteru 3:⁠15.

22 Kìí ṣe gbogbo ènìyàn ni ó lè ṣílọ sí àgbègbè ìpínlẹ̀ tí a ń ṣe lẹ́ẹ̀kan lọ́gbọ̀n. Ṣùgbọ́n o ha ń lo àwọn àǹfààní tí ó ṣí sílẹ̀ fún ọ lẹ́kùn-⁠ún-rẹ́rẹ́ bí? Ìwọ ha ń wàásù fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ? fún àwọn olùkọ́ àti àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ bí? Ìwọ ha ti mú araàrẹ bá àwọn ipò tí ń yípadà ní àgbègbè ìpínlẹ̀ rẹ mu bí? Bí ó bá jẹ́ pé nítorí àwọn ìṣètò iṣẹ́ tí ń yípadà, ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀ ni ó máa ń wà nílé ní ọ̀sán, ìwọ ha ti ṣe àwọn ìyípadà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ kí o baà lè késí wọn ní ìrọ̀lẹ́ bí? Bí kò bá ṣeéṣe fún àwọn àlejò tí a kò késí láti dé inú àwọn ilé, ìwọ ha ń ṣe ìjẹ́rìí nípasẹ̀ tẹlifóònù tàbí ìjẹ́rìí nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́ bí? Ìwọ ha ń padà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn-ìfẹ́ tí a fihàn tí o sì ń yọ̀ǹda láti darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé bí? Ìwọ ha ń ṣàṣeparí iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ ní àṣejálẹ̀ bí?​—⁠Fiwé Iṣe 20:21; 2 Timoteu 4:⁠5.

23. Bí Jehofa ti ń kíyèsí ohun tí a ń ṣe nínú iṣẹ́-ìsìn rẹ̀, kí ni ó gbọ́dọ̀ dájú nínú ọ̀ràn tiwa?

23 Ǹjẹ́ kí gbogbo wa lè ṣe iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa ní ọ̀nà kan tí ń fihàn kedere fún Jehofa pé nítòótọ́ ni a mọrírì àǹfààní títóbilọ́lá ti jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ní àwọn àkókò ṣíṣe pàtàkì wọ̀nyí. Ǹjẹ́ kí ó lè jẹ́ àǹfààní wa láti jẹ́ ẹlẹ́rìí tí ọ̀ràn ṣojú rẹ̀ bí Jehofa ti ń mú ìdájọ́ ṣẹ sórí ètò-ìgbékalẹ̀ ògbólógbòó náà tí ó ti díbàjẹ́ tí ó sì ń mú Ẹgbẹ̀rúndún Ìṣàkóso ológo ti Jesu Kristi wọlé wá!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A kà á ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí a gbà pín ilẹ̀-ayé ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990.

Ní Ṣíṣàtúnyẹ̀wò

◻ Èéṣe tí wíwàásù ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà fi ṣe pàtàkì?

◻ Dé ìwọ̀n àyè wo ni a wàásù ìhìnrere náà títí di 1914?

◻ Báwo ni ìjẹ́rìí tí a ti fúnni láti ìgbà ìfìdímúlẹ̀ Ìjọba náà ti jẹ́ kíkankíkan tó?

◻ Kí ni ó lè mú kí ìpín tiwa nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà túbọ̀ mésojáde?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA​—⁠Olùpòkìkí Ìjọba Ọlọrun

Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn àpéjọpọ̀ yíká ayé ní ọdún 1993 sí 1994, a ṣe ìfilọ̀ nípa ìmújáde ìwé titun kan tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Jehovah’s Witnesses​—⁠Proclaimers of God’s Kingdom. Èyí ni ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó ní ìsọfúnni jùlọ, tí ó sì kúnrẹ́rẹ́. Ó jẹ́ ìwé olójú-ewé 752, tí a yàwòrán sí lọ́nà rírẹwà, pẹ̀lú èyí tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún àwòrán tí a kójọpọ̀ láti ilẹ̀ 96 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ṣáájú kí ọdún 1993 tó parí, a ti tẹ̀ ẹ́ jáde ní èdè 25 a sì ń túmọ̀ rẹ̀ sí èdè púpọ̀ síi ní lọ́wọ́lọ́wọ́.

Kí ni ó mú kí irú ìwé bẹ́ẹ̀ bá ìgbà mu? Ní àwọn ọdún ẹnu àìpẹ́ yìí àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn kárí-ayé ti di Ẹlẹ́rìí Jehofa. Gbogbo wọn gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa ìtàn ètò-àjọ náà tí wọ́n ń darapọ̀ mọ́ dáradára. Síwájú síi, ìwàásù wọn àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jọ́sìn ti dé ọ̀dọ̀ àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà-ìran kárí-ayé, àwọn ènìyàn tàgbà-tèwe láti onírúurú ipò ìṣúnná-owó àti ti ẹ̀kọ́-ìwé gbogbo sì ti tẹ́wọ́gbà á. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n kíyèsí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa àwọn Ẹlẹ́rìí​—⁠kìí wulẹ̀ ṣe nípa ohun tí wọ́n gbàgbọ́ nìkan bíkòṣe nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀, ìtàn, ètò-àjọ, àti àwọn góńgó wọn pẹ̀lú. Àwọn mìíràn ti kọ̀wé nípa wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí fìgbà gbogbo jẹ́ láìṣàbòsí. Bí ó ti wù kí ó rí, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó mọ ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lóde-òní ju bí àwọn Ẹlẹ́rìí náà fúnraawọn ti mọ̀ ọ́n lọ. Àwọn olóòtú ìwé yìí ti sakun láti gbé ìtàn yẹn kalẹ̀ láìfi ẹ̀tanú gbè sápákan àti lọ́nà àìṣẹ̀tàn. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n tún ti ṣàkọsílẹ̀ ìmúṣẹ àwọn apá-ìhà ṣíṣepàtàkì gan-⁠an nínú àmì wíwàníhìn-⁠ín Kristi tí a kọsílẹ̀ nínú Matteu 24:14 títí di òní, wọ́n sì ti ṣe é pẹ̀lú kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó jẹ́ pé kìkì àwọn wọnnì tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà tí a sọtẹ́lẹ̀ níbẹ̀ lójú méjèèjì ni wọ́n lè pèsè rẹ̀.

A pín ìwé náà sí lájorí ẹ̀ka-ìpín méje:

Ẹ̀ka-Ìpín 1: Apá yìí ṣàgbéyẹ̀wò ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ó ní àkópọ̀ ṣókí, tí ó kún fún ìsọfúnni nípa ìtan wọn ti òde-òní láti 1870 títí dé 1992 nínú.

Ẹ̀ka-Ìpín 2: Níhìn-⁠ín ni àtúnyẹ̀wò oníṣìípayá wà nípa ìdàgbàsókè àwọn èrò ìgbàgbọ́ tí o fìyàtọ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti àwọn àwùjọ ìsìn yòókù ní ṣísẹ̀-⁠n-tẹ̀lé.

Ẹ̀ka-Ìpín 3: Apá yìí nínú ìwé náà ṣàyẹ̀wò ìdàgbàsókè ìgbékalẹ̀ ètò-àjọ wọn. Ó ròyìn àwọn òtítọ́ gbígbádùnmọ́ni nípa àwọn ìpàdé ìjọ àti àpéjọpọ̀ wọn, àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ ńlá, àti àwọn ilé lílò fún títẹ àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ó ṣe ìgbéjade ìtara tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ń pòkìkí Ìjọba Ọlọrun àti ìfẹ́ tí ó farahàn bí wọ́n ti ń bójútó araawọn lẹ́nìkínní kejì ní àwọn àkókò oníyánpọnyánrin.

Ẹ̀ka-Ìpín 4: Níhìn-⁠ín ni ìwọ yóò ti rí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ fífanimọ́ra nípa bí ìpòkìkí Ìjọba Ọlọrun ti rìn jìnnà lọ dé àwọn orílẹ̀-èdè ńláńlá àti àwọn erékùṣù jíjìnnà réré káàkiri ayé. Wulẹ̀ rò ó wò ná​—⁠wíwàásù ní ilẹ̀ 43 ní ọdún 1914, ṣùgbọ́n ní ilẹ̀ 229 ní ọdún 1992! Ìrírí àwọn wọnnì tí wọ́n ti kópa nínú ìmúgbòòrò yíká àgbáyé yìí ń mọ́kànyọ̀ nítòótọ́.

Ẹ̀ka-Ìpín 5: Ṣíṣàṣeparí gbogbo iṣẹ́ ìpòkìkí Ìjọba yìí ti béèrè fún ìmúgbèrú àwọn ilé lílò fún ṣíṣe ìtẹ̀jáde àwọn Bibeli àti àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ni èdè tí ó ju igba lọ jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè. Níhìn-⁠ín ni ìwọ yóò ti kọ́ nípa apá-ẹ̀ka iṣẹ́ wọn yẹn.

Ẹ̀ka-Ìpín 6: Àwọn Ẹlẹ́rìí náà tún ti dojúkọ àdánwò​—⁠àwọn kan nítorí àìpé ẹ̀dá, àwọn mìíràn nítorí àwọn èké arákùnrin, àti èyí tí ó túbọ̀ pọ̀ síi nítorí inúnibíni ní tààràtà. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kìlọ̀ pé èyí yóò rí bẹ́ẹ̀. (Luku 17:1; 2 Timoteu 3:12; 1 Peteru 4:12; 2 Peteru 2:​1, 2) Ẹ̀ka-ìpín yìí nínú ìwé náà fi ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ níti gidi hàn ketekete àti bí ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti mú kí ó ṣeéṣe fún wọn láti jagunmólú.

Ẹ̀ka-Ìpín 7: Ní àkótán, ìwé náà ṣàgbéyẹ̀wò ìdí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ní ìdánilójú fífìdímúlẹ̀gbọnyin pé ètò-àjọ náà tí wọ́n jẹ́ apákan rẹ̀ ní a ń ti ọwọ́ Ọlọrun darí nítòótọ́. Ó tún jíròrò ìdí tí wọ́n fi nímọ̀lára àìgbọ́dọ̀máṣe, gẹ́gẹ́ bí ètò-àjọ àti lẹ́nìkọ̀ọ̀kan, láti máa báa lọ ní ṣíṣọ́nà.

Ní àfikún sí ti òkè yìí, ìwé tí a ṣe lọ́nà fífanimọ́ra yìí ní ẹ̀ka-ìpín rírẹwà àti èyí tí ó kún fún ìsọfúnni gidigidi olójú-ewé 50 tí ó ní àwọn àwòrán aláwọ̀ mèremère, tí ń fi orílé-iṣẹ́ àgbáyé àti àwọn ilé-lílò ẹ̀ka tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń lò kárí ayé hàn.

Bí o kò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ìwọ yóò jàǹfààní nípa gbígbà àti kíka ẹ̀dà kan nínú ìtẹ̀jáde fífanimọ́ra yìí.

Àlàyé Ọ̀rọ̀ Láti Ẹnu Àwọn Díẹ̀ tí Wọ́n Ti Kà Á

Kí ni ìdáhùnpadà àwọn wọnnì tí wọ́n ti ka ìwé yìí? Ìwọ̀nba díẹ̀ nìyí:

“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí kíka àkọsílẹ̀ fífanimọ́ra, tí ó jótìítọ́ gidi náà Jehovah’s Witnesses​—⁠Proclaimers of God’s Kingdom tán ni. Kìkì ètò-àjọ kan tí ó fi ìdúróṣinṣin àti ìrẹ̀lẹ̀ farajìn fún òtítọ́ ni ó lè kọ̀wé láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n, tìgboyàtìgboyà, àti lọ́nà ẹlẹgẹ́ bẹ́ẹ̀.”

“Ó dàbí ìwé Iṣe, pẹ̀lú àìlábòsí àti àìfọ̀rọ̀bọpobọyọ̀ rẹ̀.”

“Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìtẹ̀jáde tí ń ru ìfẹ́ ìtọpinpin sókè tó! . . . Ó jẹ́ àgbà-iṣẹ́ nínú ọ̀rọ̀ ìtàn.”

Lẹ́yìn kíka nǹkan bí ìdajì nínú ìwé náà, ọkùnrin kan kọ̀wé pé: “Jìnnìjìnnì dàbò mí, kẹ́kẹ́ pa mọ́ mi lẹ́nu, omi sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máa jábọ́ lójú mi. . . . Ní gbogbo ọdún ìgbésí-ayé mi, kò sí ìtẹ̀jáde mìíràn tí ó tíì ru èrò ìmọ̀lára mi sókè tóbẹ́ẹ̀.”

“Ayọ̀ ń kún inú mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá ronú lórí bí ìwé yìí yóò ṣe fún ìgbàgbọ́ àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn ẹni titun tí wọ́n ń wá sínú ètò-àjọ náà lónìí lókun tó.”

“Kò sí ìgbà kan rí tí èmi kò mọrírì òtítọ́, ṣùgbọ́n kíka ìwé yìí ti là mí lójú ó sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti lóye ju ti ìgbàkígbà rí lọ pé ẹ̀mí mímọ́ Jehofa ni ó wà lẹ́yìn gbogbo rẹ̀.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

A mú ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn àní nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí náà kéré níye pàápàá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́