Ìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Fi Ń Báa Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà
“Ẹ máa báa nìṣó ní ṣíṣọ́nà nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tí Oluwa yín ń bọ̀.”—MATTEU 24:42, NW.
1. Ta ni ìṣílétí náà “ẹ máa báa nìṣó ní ṣíṣọ́nà” kàn?
GBOGBO àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun—yálà èwé tàbí àgbà, yálà ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèyàsímímọ́ tàbí tí ó ti lo ọdún gbọọrọ nínú iṣẹ́-ìsìn—ni ìṣílétí Bibeli náà kàn pé: “Ẹ máa báa nìṣó ní ṣíṣọ́nà”! (Matteu 24:42, NW) Èéṣe tí èyí fi ṣe pàtàkì?
2, 3. (a) Àmì wo ni Jesu ṣàlàyé ní kedere, kí sì ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ti fihàn? (b) Àwọn àyíká ipò wo tí a tọ́kasí nínú Matteu 24:42 ni ó ń dán ìjójúlówó ìgbàgbọ́ wa wò, báwo sì ni?
2 Ní apá ìparí iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé, Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ tí kò ṣeé fojúrí nínú agbára Ìjọba. (Matteu, orí 24 àti 25) Ó ṣàpèjúwe àkókò wíwàníhìn-ín rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba yẹn ní kedere—àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ sì fihàn pé a gbé e gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba nínú àwọn ọ̀run ní 1914. Ó tún ṣàlàyé àyíká ipò kan tí yóò dán ìjójúlówó ìgbàgbọ́ wa wò nígbà náà. Èyí jẹ́ ní ìtọ́kasí àkókò náà nígbà tí òun yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Amúdàájọ́ṣẹ láti pa ètò-ìgbékalẹ̀ búburú ìsinsìnyí run nígbà ìpọ́njú ńlá tí Jesu sọ nípa rẹ̀ pé: “Níti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnìkan tí ó mọ̀, kìí ṣe àwọn angẹli àwọn ọ̀run tàbí Ọmọkùnrin, bíkòṣe Baba nìkan.” Ìyẹn ni òun ní lọ́kàn nígbà tí ó fi sọ pé: “Nítorí náà ẹ máa báa nìṣó ní ṣíṣọ́nà nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tí Oluwa yín ń bọ̀.”—Matteu 24:36, 42, NW.
3 Mímọ̀ tí a kò mọ ọjọ́ àti wákàtí náà tí ìpọ́njú ńlá yóò bẹ̀rẹ̀ béèrè pé a níláti máa gbé ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bíi Kristian tòótọ́ lójoojúmọ́, bí a bá jẹ́wọ́ jíjẹ́ Kristian. Ọ̀nà tí o gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ yóò ha jásí ìtẹ́wọ́gbà fún Oluwa nígbà tí ìpọ́njú ńlá náà bá dé bí? Tàbí bí ó bá ṣe pé ikú ni ó kọ́kọ́ dé, òun yóò ha rántí rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí ó fi ìdúróṣinṣin ṣiṣẹ́sin Jehofa títí dé òpin ìwàláàyè rẹ ìsinsìnyí bí?—Matteu 24:13; Ìfihàn 2:10.
Àwọn Ọmọ-Ẹ̀yìn Ìjímìjí Sakun Láti Máa Ṣọ́nà
4. Kí ni a lè kọ́ láti inú àpẹẹrẹ Jesu níti ìṣọ́nà nípa tẹ̀mí?
4 Jesu Kristi fúnraarẹ̀ fi àpẹẹrẹ dídára jùlọ lélẹ̀ nípa ìṣọ́nà nípa tẹ̀mí. Ó gbàdúrà lemọ́lemọ́ àti pẹ̀lú ìgbóná-ọkàn sí Baba rẹ̀. (Luku 6:12; 22:42-44) Nígbà tí àdánwò dojúkọ ọ́, ó gbáralé ìtọ́sọ́nà inú Ìwé Mímọ́ pátápátá. (Matteu 4:3-10; 26:52-54) Kò yọ̀ọ̀da kí a pín ọkàn òun níyà kúrò nínú iṣẹ́ tí Jehofa ti yàn fún òun. (Luku 4:40-44; Johannu 6:15) Àwọn wọnnì tí wọ́n ń fojú wo araawọn gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Jesu yóò ha máa ṣọ́nà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí?
5. (a) Èéṣe tí àwọn aposteli Jesu fi ní ìṣòro láti pa ìwàdéédéé tẹ̀mí mọ́? (b) Ìrànlọ́wọ́ wo ni Jesu fún àwọn aposteli rẹ̀ lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀?
5 Ní ìgbà mìíràn, àwọn aposteli Jesu pàápàá mikàn. Nítorí híháragàgà jù àti àwọn èrò òdì, wọ́n bá ìjákulẹ̀ pàdé. (Luku 19:11; Iṣe 1:6) Ṣáájú kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ láti gbáralé Jehofa ní kíkún, àwọn àdánwò òjijì kan dà wọ́n ríborìbo. Nípa báyìí, nígbà ti a fàṣẹ ọba mú Jesu, àwọn aposteli rẹ̀ sá. Lẹ́yìn náà ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, ìbẹ̀rù mú kí Peteru sẹ́ léraléra pé òun kò tilẹ̀ mọ Kristi. Àwọn aposteli kò tíì fi ìmọ̀ràn Jesu náà sọ́kàn pé: “Ẹ máa báa nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo.” (Matteu 26:41, 55, 56, 69-75, NW) Jesu lo Ìwé Mímọ́ láti fún ìgbàgbọ́ wọn lókun lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀. (Luku 24:44-48) Nígbà tí ó sì dàbí ẹni pé àwọn kan lára wọn lè fi iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà tí a ti fi sí ìkáwọ́ wọn sí ipò kejì, Jesu fún ìsúnniṣe wọn láti pọkànpọ̀ sórí iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ náà lókun.—Johannu 21:15-17.
6. Àwọn ìdẹkùn méjì wo ni Jesu ti kìlọ̀ ṣáájú fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣọ́ra fún?
6 Ṣáájú, Jesu ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ́ apákan ayé. (Johannu 15:19) Ó tún ti gbà wọ́n nímọ̀ràn láti máṣe lo agbára lórí araawọn bíkòṣepé kí wọ́n ṣiṣẹ́sìn papọ̀ gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. (Matteu 20:25-27; 23:8-12) Wọ́n ha kọbiara sí ìmọ̀ràn rẹ̀ bí? Wọ́n ha fi iṣẹ́ tí ó fifún wọn sí ipò ìwájú bí?
7, 8. (a) Báwo ni àpẹẹrẹ dídára jùlọ ti àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ín-ní ṣe fihàn pé wọ́n fi ìṣílétí Jesu sọ́kàn? (b) Èéṣe tí ìṣọ́nà nípa tẹ̀mí tí ń báa lọ fi ṣe pàtàkì?
7 Níwọ̀n ìgbà tí àwọn aposteli ṣì wàláàyè, wọ́n dáàbòbo ìjọ. Ìtàn jẹ́rìí síi pé àwọn Kristian ìjímìjí kò lọ́wọ́ nínú àwọn àlámọ̀rí ìṣèlú ti Ilẹ̀-Ọba Romu àti pé wọn kò sì ní ẹgbẹ́ àwọn àwùjọ àlùfáà tí a gbé ga. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, wọ́n jẹ́ olùfìtara pòkìkí Ìjọba Ọlọrun. Ní òpin ọ̀rúndún kìn-ín-ní, wọ́n ti wàásù jákèjádò Ilẹ̀-Ọba Romu, ní sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn ní Asia, Europe, àti Àríwá Africa.—Kolosse 1:23.
8 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn àṣeparí wọ̀nyẹn nínú wíwàásù kò túmọ̀sí pé kò sí ìdí kankan mọ́ láti máa báa nìṣó ní ṣíṣọ́nà nípa tẹ̀mí. Wíwá Jesu tí a sọtẹ́lẹ̀ ṣì jìnnà. Bí ìjọ sì ti wọnú ọ̀rúndún kejì C.E., àwọn ipò ọ̀ràn dìde tí ó fi ipò tẹ̀mí àwọn Kristian sínú ewu. Báwo ni ó ṣe rí bẹ́ẹ̀?
Àwọn tí Wọ́n Ṣíwọ́ Láti Máa Ṣọ́nà
9, 10. (a) Lẹ́yìn ikú àwọn aposteli, àwọn ìdàgbàsókè wo ni ó fihàn pé ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ jíjẹ́ Kristian kò ṣọ́nà? (b) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo tí a tọ́kasí nínú ìpínrọ̀ yìí ni ìbá ti ran àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ jíjẹ́ Kristian lọ́wọ́ láti máa jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí nìṣó?
9 Àwọn kan tí wọ́n wá sínú ìjọ bẹ̀rẹ̀ síí fi ọgbọ́n-ìmọ̀-ọ̀ràn Griki ṣàlàyé ìgbàgbọ́ wọn, kí wọ́n baà lè mú kí ohun tí wọ́n ń wàásù túbọ̀ ní ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn ayé. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ olórìṣà, bíi Mẹ́talọ́kan àti àìlèkú-ọkàn àjogúnbá, di apákan irú ìsìn Kristian kan tí a kó àbàwọ́n bá. Èyí jálẹ̀ sí pípa ìrètí ẹgbẹ̀rúndùn tì. Èéṣe? Àwọn wọnnì tí wọ́n tẹ́wọ́gba ìgbàgbọ́ àìlèkú-ọkàn parí rẹ̀ sí pé nínú ilẹ̀-àkóso ẹ̀mí ni ọkàn kan tí yóò wàláàyè lẹ́yìn ikú ara ìyára yóò ti gba gbogbo ìbùkún ìṣàkóso Kristi. Nítorí náà wọn kò rí ìdí kankan fún ṣíṣọ́nà fún wíwàníhìn-ín Kristi nínú agbára Ìjọba.—Fiwé Galatia 5:7-9; Kolosse 2:8; 1 Tessalonika 5:21.
10 Àwọn ìdàgbàsókè mìíràn mú kí ipò-ọ̀ràn yìí ga síi. Àwọn kan tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristian alábòójútó bẹ̀rẹ̀ síí lo àwọn ìjọ tí wọ́n wà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dé ipò sàràkí. Wọ́n fi ọgbọ́n àyínìke ka àwọn èrò àti ẹ̀kọ́ wọn sí èyí tí ó ní ìníyelórí kan náà bíí ti Ìwé Mímọ́ tàbí tí ó tilẹ̀ lọ́lá ju ìwọ̀nyí lọ. Nígbà tí àǹfààní náà ṣí sílẹ̀, ṣọ́ọ̀sì apẹ̀yìndà yìí tilẹ̀ mú araarẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣiṣẹ́sìn fún ire ti ọ̀ràn ìṣèlú.—Iṣe 20:30; 2 Peteru 2:1, 3.
Àwọn Ìyọrísí Ìṣọ́nà tí A Mú Pọ̀ Síi
11, 12. Èéṣe tí Ìṣàtúnṣe Ìsìn Protẹstanti kò fi ṣàmìsí pípadà sí ìjọsìn tòótọ́?
11 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ìwàkíwà tí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Katoliki hù, àwọn Alátùn-ún-ṣe Ìsìn kan ké gbàjarè ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún. Ṣùgbọ́n èyí kò sàmìsí pípadà sí ìjọsìn tòótọ́. Èéṣe tí kò fi rí bẹ́ẹ̀?
12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú àwọn àwùjọ ìsìn Protẹstanti já araawọn gbà kúrò lábẹ́ agbára Romu, wọn kò já ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti àṣà ìpẹ̀yìndà jù sílẹ̀—èròngbà nípa ẹgbẹ́ àlùfáà-òun-ọmọ-ìjọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́ nínú Mẹ́talọ́kan, àìlèkú-ọkàn, àti ìdálóró ayérayé lẹ́yìn ikú. Àti, gẹ́gẹ́ bíi ti Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Katoliki, wọ́n ń báa lọ láti máa jẹ́ apákan ayé, níwọ̀n bí wọ́n ti ní àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwùjọ àwọn olóṣèlú. Nítorí náà wọ́n ní ìtẹ̀sí láti fọwọ́ rọ́ ìfojúsọ́nà èyíkéyìí nípa wíwá Kristi gẹ́gẹ́ bí Ọba tì sẹ́yìn.
13. (a) Kí ni ó fihàn pé àwọn ènìyàn kan ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sí iyebíye níti tòótọ́? (b) Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni àwọn díẹ̀ tí wọ́n jẹ́wọ́ jíjẹ́ Kristian wá lọ́kàn-ìfẹ́ sí ní pàtàkì? (d) Èéṣe tí àwọn púpọ̀ fi nírìírí ìjákulẹ̀?
13 Síbẹ̀, Jesu ti sọtẹ́lẹ̀ pé lẹ́yìn ikú àwọn aposteli, àwọn ojúlówó ajogún Ìjọba (tí ó fiwé àlìkámà) yóò máa dàgbà nìṣó ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ayédèrú Kristian (tàbí, èpò) títí di ìgbà ìkórè. (Matteu 13:29, 30) A kò lè fi pẹ̀lú ìdánilójú èyíkéyìí ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo àwọn wọnnì tí Ọ̀gá náà ń wò bí àlìkámà lẹ́sẹẹsẹ. Ṣùgbọ́n ó yẹ fún àfiyèsí pé ní àwọn ọ̀rúndún kẹrìnlá, ìkẹẹ̀ẹ́dógún, àti ìkẹrìndínlógún, a rí àwọn ọkùnrin tí wọ́n fi ìwàláàyè àti òmìnira wọn wewu láti lè mú kí Bibeli wà ní èdè tí gbogbo ènìyàn lóye. Kìí ṣe pé àwọn mìíràn wulẹ̀ gba Bibeli gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nìkan ni ṣùgbọ́n wọ́n tún kọ Mẹ́talọ́kan gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Àwọn kan kọ ìgbàgbọ́ nínú àìlèkú-ọkàn àti ìdálóró nínú iná ọ̀run àpáàdì gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò sí ní ìṣọ̀kan rárá pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, nítorí ìkẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ síi nínú Bibeli, àwọn àwùjọ ní United States, Germany, England, àti Russia bẹ̀rẹ̀ síí sọ ìdánilójú ìgbàgbọ́ wọn jáde pé ipadàbọ̀ Kristi ti súnmọ́lé. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn ìfojúsọ́nà wọn yọrísí ìjákulẹ̀. Èéṣe? Dé ìwọn àyè tí ó pọ̀, ó jẹ́ nítorí pé wọ́n gbáralé ènìyàn jù tí wọn kò sì gbáralé Ìwé Mímọ́ tó.
Bí Àwọn Wọ̀nyí Ṣe Fi Ẹ̀rí Ṣíṣọ́nà Hàn
14. Ṣàpèjúwe ọ̀nà tí C. T. Russell àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ rẹ̀ gbà kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
14 Lẹ́yìn náà, ní 1870, Charles Taze Russell àti díẹ̀ lára àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ dá àwùjọ kan sílẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní Allegheny, Pennsylvania. Àwọn kọ ni ẹni àkọ́kọ́ láti fi òye mọ ọ̀pọ̀ lára àwọn òtítọ́ Bibeli tí wọ́n tẹ́wọ́gbà, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sọ ọ́ di àṣà láti máa farabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò gbogbo ìwé mímọ́ lórí ìbéèrè pàtó kan.a Góńgó wọn kìí ṣe láti wá ẹsẹ ìwé mímọ́ tí ó jẹ́rìí sí èrò kan tí wọ́n ti gbìn sọ́kàn tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ó jẹ́ láti ríi dájú pé wọ́n dé ìparí èrò tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ohun gbogbo tí Bibeli sọ lórí ọ̀ràn náà.
15. (a) Kí ni àwọn mìíràn yàtọ̀ sí Arákùnrin Russell wá lóye rẹ̀? (b) Kí ni ó mú kí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí?
15 Àwọn díẹ̀ kan ṣáájú wọn ti lóye pé Kristi yóò padà láìṣeéfojúrí gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí. Àwọn kan ti ríi pé ète ìpadàbọ̀ Kristi kìí ṣe láti jó ilẹ̀-ayé ráúráú kí ó sì pa gbogbo ẹ̀dá ènìyàn rẹ́ kúrò, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ láti bùkún fún gbogbo ìdílé orí ilẹ̀-ayé. Àwọn díẹ̀ tilẹ̀ wà pàápàá tí wọ́n ti mọ̀ pé ọdún 1914 yóò sàmìsí òpin Àkókò Àwọn Kèfèrí. Ṣùgbọ́n lójú àwọn Àkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí wọ́n ń darapọ̀ mọ́ Arákùnrin Russell, ìwọ̀nyí rékọjá àwọn kókó fún ìjíròrò ẹ̀kọ́-ìsìn lásán. Wọ́n kọ́ ìgbésí-ayé wọn yíká àwọn òtítọ́ wọ̀nyí wọ́n sì pòkìkí wọn jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè ní ìwọ̀n kan ti kò tíì sí irú rẹ̀ rí nínú sànmánì yẹn.
16. Ní ọdún 1914, èéṣe tí Arákùnrin Russell fi kọ̀wé pé: “A wà ní ìgbà àdánwò”?
16 Síbẹ̀, wọ́n níláti máa báa nìṣó ní ṣíṣọ́nà. Èéṣe? Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli ti sàmìsí ọdún 1914, wọn kò mọ ohun náà gan-an tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọdún yẹn dájú. Èyí gbé ìdánwò kan ka iwájú wọn. Nínú Ile-Iṣọ Na ti November 1, 1914, Arákùnrin Russell kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí a rántí pé a wà ní ìgbà ìdánwò. . . . Bí ìdí èyíkéyìí bá wà tí yóò sún ẹnìkan láti jáwọ́ kúrò nínú ìgbàgbọ́ nínú Oluwa àti Òtítọ́ Rẹ̀ kí ó sì dẹ́kun rírúbọ fún Ète ti Oluwa, nígbà náà kìí wulẹ̀ ṣe ìfẹ́ fún Ọlọrun nínú ọkàn-àyà ni ó ti fa níní ìfẹ́-ọkàn nínú Oluwa, bíkòṣe nǹkan mìíràn; bóyá ìrètí pé àkókò kúrú; ìyàsímímọ́ wà fún kìkì àkókò kan pàtó.”
17. Báwo ni A. H. Macmillan, àti àwọn ẹlòmíràn bíi tirẹ̀, ṣe pa ìwàdéédéé nípa tẹ̀mí mọ́?
17 Àwọn kan pa iṣẹ́-ìsìn Jehofa tì nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ṣùgbọ́n A. H. Macmillan jẹ́ ẹnìkan tí kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ó fi tòótọ́tòótọ́ jẹ́wọ́ pé: “Nígbà mìíràn, àwọn ìfojúsọ́nà wa fún ọjọ́ kan pàtó pọ̀ ju ohun tí Ìwé Mímọ́ yọ̀ọ̀da fún.” Ki ni ó ràn án lọ́wọ́ láti di ìwàdéédéé rẹ̀ nípa tẹ̀mí mú? Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, ó lóye pé, “nígbà tí àwọn ìfojúsọ́nà wọnnì kò bá ní ìmúṣẹ, ìyẹn kò yí àwọn ète Ọlọrun padà.” Ó fikún un pé: “Mó kẹ́kọ̀ọ́ pé a gbọ́dọ̀ gba àwọn àṣìṣe wa kí a sì máa báa lọ ní wíwá inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún ìlàlóye síi.”b Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìjímìjí wọnnì jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣe àtúnṣebọ̀sípò ojú-ìwòye wọn.—2 Timoteu 3:16, 17.
18. Báwo ni ìṣọ́nà àwọn Kristian ṣe mú àwọn àǹfààní tí ń tẹ̀síwájú wá nínú ọ̀ràn ti ṣíṣàì jẹ́ apákan ayé?
18 Ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀lé e, àìní tí ó wà fún wọn láti máa báa lọ ní ṣíṣọ́nà kò dínkù. Dájúdájú, wọ́n mọ̀ pé àwọn Kristian kò níláti jẹ́ apákan ayé. (Johannu 17:14; Jakọbu 4:4) Ní ìbámu pẹ̀lú ìyẹn, wọn kò darapọ̀ mọ́ Kristẹndọm láti fọwọ́sí Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gẹ́gẹ́ bí ìfarahàn Ìjọba Ọlọrun lọ́nà òṣèlú. Ṣùgbọ́n ní ọdún 1939 gan-an ni wọ́n tó rí ọ̀ràn àìdásítọ̀tún-tòsì Kristian ní kedere.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, November 1, 1939 (Gẹ̀ẹ́sì).
19. Àwọn àǹfààní wo nínú ìṣàbójútó ìjọ ni ó ti jáde wá nítorí pé ètò-àjọ náà ń báa lọ láti máa ṣọ́nà?
19 Wọn kò ní ẹgbẹ́ àlùfáà rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà kan tí a dìbòyàn ronú pé wíwàásù nínú ìjọ ni gbogbo ohun tí a níláti retí láti ọ̀dọ̀ wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn mímúhánhán láti ṣe ohun tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, ètò-àjọ náà tún ipa-iṣẹ́ àwọn alàgbà gbéyẹ̀wò lójú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ léraléra ní ojú-ìwé Ilé-Ìṣọ́nà. Àwọn ìyípadà nínú ọ̀nà ìṣètòjọ ni a ṣe ní ìbáramu pẹ̀lú ohun tí Ìwé Mímọ́ fihàn.
20-22. Báwo ni a ti ṣe ń múra gbogbo ètò-àjọ náà sílẹ̀ lọ́nà tí ń tẹ̀síwájú láti ṣàṣeparí iṣẹ́ ìpòkìkí Ìjọba yíka ayé tí a sọtẹ́lẹ̀ náà?
20 Ètò-àjọ náà lódidi ni a bẹ̀rẹ̀ síí múra rẹ̀ sílẹ̀ ní pẹrẹwu láti ṣe àṣeparí iṣẹ́ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti làsílẹ̀ fún ọjọ́ wa ní kíkún. (Isaiah 61:1, 2) Dé ìwọ̀n àyè wo ni a fi níláti pòkìkí ìhìnrere náà ní ọjọ́ wa? Jesu wí pé: “A kò lè ṣàìmá kọ́ wàásù ìhìnrere ní gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Marku 13:10) Lójú ìwòye ènìyàn, iṣẹ́ yẹn ti sábà máa ń farahàn bí èyí tí kò ṣeéṣe.
21 Síbẹ̀, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé nínú Kristi gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ, ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà ti tẹ̀síwájú. (Matteu 24:45, NW) Wọ́n ti fi pẹ̀lú ìṣòtítọ́ àti ìfìdímúlẹ̀gbọnyin ṣàlàyé iṣẹ́ tí ó yẹ láti ṣe fún àwọn ènìyàn Jehofa. Láti 1919 síwájú, ìtẹnumọ́ púpọ̀ síi ni a fifún iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, kò rọrùn láti lọ láti ilé dé ilé kí wọ́n sì bá àwọn àjèjì sọ̀rọ̀. (Iṣe 20:20) Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ bíi “Alábùkúnfún Ni Àwọn Aláìṣojo” (ní 1919) àti “Ẹ Jẹ́ Onígboyà Gidi Gan-an” (ní 1921) ran àwọn díẹ̀ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa.
22 Ìkésíni náà, ní 1922, pé “ẹ fọnrere, ẹ fọnrere, ẹ fọnrere, Ọba náà àti ìjọba rẹ̀” pèsè ìsúnniṣe tí a nílò láti mú kí iṣẹ́ yìí ní ìjẹ́pàtàkì tí ó tọ́ síi. Láti 1927 lọ, àwọn alàgbà tí wọn kò tẹ́wọ́gba ẹrù-iṣẹ́ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu yẹn ni a mú kúrò. Ní nǹkan bí àkókò yẹn, àwọn arìnrìn-àjò tí ń ṣojú fún Society, àwọn arìnrìn-àjò ìsìn, ni a yàn láti di olùdarí iṣẹ́-ìsìn ní ẹkùn-ìpínlẹ̀, ní fífún àwọn akéde kọ̀ọ̀kan ní ìtọ́ni nínú iṣẹ́-ìsìn pápá. Kìí ṣe gbogbo ènìyàn ni ó lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ṣùgbọ́n ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀ ọ̀pọ̀ ń yọ̀ọ̀da odidi ọjọ́ gbáko fún iṣẹ́-ìsìn náà, ní bíbẹ̀rẹ̀ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, wọ́n a wulẹ̀ dúró díẹ̀ láti jẹ búrẹ́dì tí a fi ẹ̀ran sí nínú, àti lẹ́yìn náà wọ́n a sì máa báa lọ nínú iṣẹ́-ìsìn títí di ìrọ̀lẹ́. Ìwọ̀nyẹn jẹ́ àwọn àkókò pàtàkì fún ìdàgbàsókè ìṣàkóso Ọlọrun, a sì jàǹfààní ńláǹlà nípa ṣíṣàtúnyẹ̀wò ọ̀nà tí Jehofa ń gbà darí àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó ń báa lọ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Pẹ̀lú ìbùkún rẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù ìhìnrere Ìjọba náà ti a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ni a óò mú wá sí ìparí aláṣeyọrísírere.
Ìwọ Ha Ń Báa Lọ Ní Ṣíṣọ́nà Bí?
23. Níti ìfẹ́ Kristian àti ìyàsọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, báwo ni àwa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ṣe lè fihàn pé a ń báa nìṣó ní ṣíṣọ́nà?
23 Ní dídáhùnpadà sí ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ Jehofa, ètò-àjọ rẹ̀ ń báa lọ láti máa mú wa wà lójúfò sí àwọn àṣà àti ìṣarasíhùwà tí yóò fi wa hàn gẹ́gẹ́ bí apákan ayé, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ sínú ewu kíkọjá lọ pẹ̀lú rẹ̀. (1 Johannu 2:17) Lẹ́yìn náà, àwa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ní ìdí láti máa báa lọ ní ṣíṣọ́nà nípa dídáhùnpadà sí ìdarísọ́nà Jehofa. Jehofa tún ń fún wa ní ìtọ́ni nípa gbígbé àti ṣíṣiṣẹ́ papọ̀. Ètò-àjọ rẹ̀ ti ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọrírì tí ó pọ̀ síi fún ohun tí ìfẹ́ Kristian túmọ̀sí níti gidi. (1 Peteru 4:7, 8) Bíbá a lọ wa láti máa ṣọ́nà béèrè pé kí a fi taratara sakun láti fi ìmọ̀ràn yìí sílò, láìka àwọn àìpé ti ẹ̀dá sí.
24, 25. Ní àwọn ọ̀nà síṣekókó wo ni a níláti máa báa nìṣó ní ṣíṣọ́nà, pẹ̀lú ìfojúsọ́nà wo sì ni?
24 Lọ́nà tí ó ṣe déédéé, olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà ti rán wa létí pé: “Fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀lé Oluwa; má sì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ araàrẹ.” (Owe 3:5) “Ẹ máa gbàdúrà ní àìsinmi.” (1 Tessalonika 5:17) A ti gbà wá nímọ̀ràn láti kọ́ láti gbé àwọn ìpinnu wa karí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ‘fìtílà fún ẹsẹ̀ wa, àti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà wa.’ (Orin Dafidi 119:105) A ti fi tìfẹ́tìfẹ́ fún wa ní ìṣírí láti fi wíwàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun sí ipò iwájú nínú ìgbésí-ayé wa, iṣẹ́ náà tí Jesu sọtẹ́lẹ̀ fún ọjọ́ wa.—Matteu 24:14.
25 Bẹ́ẹ̀ni, olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà ń ṣọ́nà nítòótọ́. Lẹ́nìkọ̀ọ̀kan àwa pẹ̀lú níláti máa ṣọ́nà. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kí a lè wà lára àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìdúró rere níwájú Ọmọkùnrin ènìyàn nígbà tí ó bá wá láti mú ìdájọ́ ṣẹ.—Matteu 24:30; Luku 21:34-36.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Faith on the March, láti ọwọ́ A. H. Macmillan, Prentice-Hall, Inc., 1957, ojú-ìwé 19 sí 22.
b Wo Ilé-Ìṣọ́nà, August 15, 1966, ojú-ìwé 504 sí 510 (Gẹ̀ẹ́sì).
Ní Ṣíṣàtúnyẹ̀wò
◻ Gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn ní Matteu 24:42, èéṣe tí a fi níláti máa báa nìṣó ní ṣíṣọ́nà?
◻ Báwo ni Jesu àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ọ̀rúndún kìn-ín-ní ṣe pa ṣíṣọ́nà nípa tẹ̀mí mọ́?
◻ Láti 1870, àwọn ìdàgbàsókè wo ni ó ti wà nítorí pé àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ń báa nìṣó ní ṣíṣọ́nà?
◻ Kí ni yóò fúnni ní ẹ̀rí pé àwa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ń báa lọ ní ṣíṣọ́nà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọwọ́ Jesu dí lẹ́nu iṣẹ́ tí Baba rẹ̀ yàn fún un. Ó tún gbàdúrà pẹ̀lú ìgbóná-ọkàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Charles Taze Russell nígbà tí ọjọ́ ogbó ń dé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba tí ó rékọjá 4,700,000 ni wọ́n jẹ́ aláápọn ní gbogbo ilẹ̀-ayé