ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 7/1 ojú ìwé 29-31
  • “Èmi Ti Pa Ìgbàgbọ́ Mọ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Èmi Ti Pa Ìgbàgbọ́ Mọ́”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀rọ̀ tí Ó Fi Ẹnu Araarẹ̀ Sọ Wú Àwọn Dókítà Lórí
  • Àwọn Góńgó Tẹ̀mí
  • Ọjọ́-Ọ̀la Aláìléwu Kan
  • “Mi Ò Rí Irú Ìfẹ́ Báyìí Rí”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Bí Ìgbàgbọ́ Mi Ṣe Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Fara Da Ìṣòro
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Sọ fún Wọn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Wọn
    Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 7/1 ojú ìwé 29-31

“Èmi Ti Pa Ìgbàgbọ́ Mọ́”

GẸ́GẸ́ BÍ ÀWỌN Ọ̀RẸ́ BRUNELLA INCONDITI TI SỌ Ọ́

“ỌJỌ́ Saturday falẹ̀ ó sì dágùdẹ̀. Mó dánìkanwà nínú iyàrá, ní nínímọ̀lára àìnírètí. Ó ṣe mi bí ẹni pé mo ń rìn gba ọ̀dẹ̀dẹ̀ kọjá lọ. Kò sí láburú kankan, ṣùgbọ́n lójijì, ẹnìkan pa ilẹ̀kùn dé mọ́ mi gbàgà, kò sì sí ọ̀nà àbájáde, bí ó ti wù kí n gbìyànjú tó.”

Ìjákulẹ̀ lílégbákan wúwo rinrin lọ́kàn-àyà Brunella Inconditi tíí ṣe ọmọ ọdún 15. Ọjọ́ ṣíṣepàtàkì jùlọ nínú ìgbésí-ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọdé kan ti ń kọjá lọ. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yẹn ìfẹ́ rẹ̀ tí ń ga síi fún Jehofa àti Bibeli ti sún un láti ya ìgbésí-ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún un. Ní July 1990 ó yẹ kí ó ṣèrìbọmi ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Èdè Mímọ́gaara” ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Montreal, Canada. Kàkà bẹ́ẹ̀, Brunella máa tó dojúkọ ìdánwò ìgbàgbọ́ rẹ̀ tí yóò máa báa nìṣó títí jálẹ̀ ìgbésí-ayé rẹ̀.

Ó ku ọ̀tunla kí ó ṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ rẹ̀ nípasẹ̀ ìrìbọmi nínú omi, ni Brunella ti mọ̀ pé òun ti ní àrùn àpọ̀jù sẹ́ẹ̀lì funfun nínú ẹ̀jẹ̀. Àwọn dókítà ní ilé-ìwòsàn àwọn ọmọdé ládùúgbò fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìtọ́jú ìṣègùn lójú-ẹsẹ̀, nítorí náà Brunella kò fi ilé-ìwòsàn sílẹ̀.

Ọ̀rọ̀ tí Ó Fi Ẹnu Araarẹ̀ Sọ Wú Àwọn Dókítà Lórí

Brunella mọ̀ pé ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀ ni ẹ̀jẹ̀ jẹ́ fún Jehofa Ọlọrun. (Lefitiku 17:11) Àwọn òbí rẹ̀, Edmondo àti Nicoletta, ti sọ ní pàtó pé kí a máṣe lo ìfàjẹ̀sínilára kankan fún títọ́jú ọmọbìnrin wọn. Baba rẹ̀ rántí pé, “Brunella pẹ̀lú fẹ́ kí àwọn dókítà náà gbọ́ ọ lẹ́nu òun, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìtójúúbọ́ ni òun. Pẹ̀lú ìdúró gbọnyingbọnyin ni ó fi sọ fún wọn pé òun kò fẹ́ ìtọ́jú tí yóò tẹ àṣẹ Bibeli láti ‘fà sẹ́yìn . . . kúrò nínú ẹ̀jẹ̀’ lójú.”​—⁠Iṣe 15:⁠20.

Ní July 10, 1990, àwọn dókítà mẹ́ta àti oníṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan pàdépọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí Brunella àti àwọn òjíṣẹ́ méjì láti inú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó wà ládùúgbò. Àyẹ̀wò fihàn pé Brunella ní àrùn àpọ̀jù sẹ́ẹ̀lì funfun nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó légbákan láti inú sẹ́ẹ̀lì sẹ̀jẹ̀domi. Àwọn dókítà ṣàlàyé ìwéwèé wọn láti gbógunti àrùn náà. Wọ́n fọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ ṣàpèjúwe pé ó ṣòro gidigidi láti tọ́jú rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn alàgbà ìjọ náà rántí pé, “Ìwà àti ìpinnu Brunella láti ṣègbọràn sí Ọlọrun ti wọ àwọn dókítà àti oníṣẹ́ afẹ́nifẹ́re náà lọ́kàn. Ìfẹ́ àwọn òbí àti ìtìlẹ́yìn àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti inú ìjọ Kristian wú wọn lórí. Wọ́n tún mọrírì ọ̀nà tí a gbà lóye àti ọ̀nà tí a gbà bọ̀wọ̀ fún ipò wọn.”

Àwọn dókítà náà pètepèrò láti yẹra fún ìfàjẹ̀sínilára. Brunella yóò gba ìtọ́jú oníkẹ́míkà lójú méjéèjì, ṣùgbọ́n kò ní lekoko tó bí ó ti yẹ kí ó rí. Èyí yóò dín ìpalára tí ìtọ́jú náà lè ṣe fún sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kù. Nicoletta ṣàlàyé pé, “Dókítà náà gbé àwọn àìní Brunella nípa ti ara, ti ìmí-ẹ̀dùn, àti nípa tẹ̀mí yẹ̀wò. Nígbà tí a sọ fún wọn láti lọ bá ògbóǹtagí kan tí ó nírìírí nínú ìṣètọ́jú àrùn omi ara púpọ̀ ju ẹ̀jẹ̀ lọ ti àwọn ọmọdé láìlo ẹ̀jẹ̀, wọ́n fohùnṣọ̀kan.” Brunella àti àwọn agbo-òṣìṣẹ́ ilé-ìwòsàn náà mú ìdè ìrẹ́pọ̀ ọlọ́yàyà ti ìfẹ́ni dàgbà.

Àwọn Góńgó Tẹ̀mí

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtọ́jú àkọ́kọ́ mú àwọn ìyọrísí rere díẹ̀ wá, ìrírí adánniwò ti Brunella ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ̀rẹ̀ ni. Ní November 1990 àrùn rẹ̀ fún un ní ìtura, nítorí náà ó ṣèrìbọmi láìsí ìdádúró. Ní ríronú nípa ìwọ̀nba oṣù díẹ̀ sẹ́yìn, Brunella gbà pé: “Kò rọrùn rárá. O nílò ọ̀pọ̀lọpọ̀ okun, o sì níláti ronú bí ẹni ń fojúsọ́nà fún rere. . . . Ìgbàgbọ́ mi ni a fi sábẹ́ ìdánwò, ṣùgbọ́n mo dúró ṣinṣin síbẹ̀, mo ṣì ń wéwèé láti ní iṣẹ́ ìgbésí-ayé gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà [òjíṣẹ́ alákòókò kíkún] kan.”

Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1991, àìsàn Brunella tún padà sẹ́yìn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú nígbà tí ó ń gba ìtọ́jú oníkẹ́míkà, ṣùgbọ́n sí ìyàlẹ́nu àti ìdùnnú gbogbo ènìyàn, ara rẹ̀ yá. Nígbà tí ó fi máa di August ara rẹ̀ ti yá débi pé ó lè lo àkókò tí ó pọ̀ tó nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Àmódi rẹ̀ tún burú síi, nígbà tí ó sì fi máa di November 1991 àrùn jẹjẹrẹ ti wà ní àwọn ibi mélòókan lára rẹ̀. Ọ̀wọ́ àwọn dókítà alájọṣiṣẹ́ ní ilé-ìwòsàn mìíràn bẹ̀rẹ̀ síí fi ìtọ́jú onítànṣán tọ́jú rẹ̀.

Àní lábẹ́ àwọn àyíká ipò tí ó ṣòro bẹ́ẹ̀ pàápàá, Brunella di ìdúróṣinṣin rẹ̀ mú ó sì gbé àwọn góńgó tẹ̀mí kalẹ̀ fún araarẹ̀. Nígbà tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí mọ̀ nípa àrùn omi ara púpọ̀ ju ẹ̀jẹ̀ lọ náà, wọ́n sọ fún un pé ó lè má gbé kọjá oṣù mẹ́fà péré. Nísinsìnyí, tí ó ti tó ọdún kan àti ààbọ̀ lẹ́yìn náà, Brunella ṣì ń wéwèé fún ọjọ́-ọ̀la. Alàgbà ìjọ kan sọ̀rọ̀ àkíyèsí pé: “Kò fi àkókò kankan ṣòfò ní ṣíṣiṣẹ́ síhà àwọn góńgó rẹ̀. Ìgbàgbọ́ Brunella nínú Paradise tí Ọlọrun ṣèlérí ṣètìlẹ́yìn fún un jálẹ̀ gbogbo ìrírí adánniwò rẹ̀. Ó dàgbà di Kristian oníwà-àgbà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kéré ní ọjọ́-orí. Ìwà àti ìṣesí rẹ̀ nípalórí ìjọ náà ó sì jèrè ọkàn-àyà àwọn wọnnì tí wọ́n mọ̀ ọ́n, títíkan àwọn àwùjọ òṣìṣẹ́ ilé-ìwòsàn náà.” Ìyá rẹ̀ rántí pé: “Kò jẹ́ ṣàròyé. Nígbà tí ẹnìkan bá bi í pé báwo ni ara rẹ̀ ti ṣe, yóò dáhùn pé, ‘Ara ń yá’ tàbí, ‘Ó sàn, ìwọ náà ń kọ́?’”

Ọjọ́-Ọ̀la Aláìléwu Kan

Brunella wéwèé láti lọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀” ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní July 1992. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí àpéjọpọ̀ náà yóò fi tó a ti gba Brunella sílé ìwòsàn, ìfàsẹ́yìn sì ń bá ìwàláàyè rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọ́n gbé e sínú àga alágbàá-kẹ̀kẹ́ lọ sí àpéjọpọ̀ náà, bí ó ti fi dandan lé e pé òun yóò wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà Ṣiṣe Ohun tí Ó Tọ́ Ni Ojú Jehofa.

Ó padà sílé lọ́dọ̀ àwọn ìdílé rẹ̀ fún ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ṣẹ́kù nínú ìgbésí-ayé rẹ̀. Nicoletta sọ pé: “Títí dópin, ó túbọ̀ ní ìdàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn jú fún ara rẹ̀ lọ. Òun yóò fún wọn ní ìṣírí láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ní sísọ fún wọn pé, ‘Àwa yóò wà papọ̀ ní Paradise.’”

Brunella kú ní July 27, 1992, pẹ̀lú ìdúró gbọnyingbọnyin nínú ìrètí rẹ̀ fún ìwàláàyè nínú Paradise orí ilẹ̀-ayé. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí lépa àwọn góńgó rẹ̀ ni, ṣùgbọ́n ó wéwèé láti máa bá ipa-ọ̀nà rẹ̀ lọ lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀. Ní ìwọ̀nba ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀, Brunella kọ lẹ́tà tí ó tẹ̀lé e yìí, èyí tí a kà níbi ìsìn ìrántí rẹ̀.

“Ẹ̀yin Ọ̀rẹ́ Ọ̀wọ́n:

“Ẹ ṣeun fún wíwá tí ẹ wá. Wíwá yín túmọ̀sí ohun púpọ̀ fún ìdílé mi.

“Fún àwọn ènìyàn tí wọ́n súnmọ́ mi​—⁠a ti la ọ̀pọ̀ nǹkan kọjá. Ọ̀pọ̀ àwọn àkókò tí kò báradé ti wà, ṣùgbọ́n àwọn àkókò tí ń panilẹ́rìn-⁠ín ti wà pẹ̀lú. Ìjà nínira tí ó gba àkókò ni, ṣùgbọ́n n kò ronú pé ǹ bá ti kùnà. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ, ‘Èmi ti ja ìjà rere, èmi ti parí iré ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.’​—⁠2 Timoteu 4:⁠7.

“Mo tún ti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ó pọ̀, mo sì dàgbà dáadáa, àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn wọnnì tí wọ́n wà yí mi ká sì rí ìyípadà náà. Mo fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣètìlẹ́yìn fún mi.

“Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ nínú ètò ìgbékalẹ̀ titun àti nínú Jehofa mọ̀ pé àjíǹde yóò wà, gẹ́gẹ́ bí Johannu 5:​28, 29 ti sọ. Nítorí náà ẹ jẹ́ alágbára nínú òtítọ́, yóò sì ṣeéṣe fún wa láti tún fojúkanra lẹ́ẹ̀kansíi.

“Mo fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn wọnnì tí wọ́n mọ ohun tí mo ti là kọjá. Mo fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ní ìfọwọ́kónimọ́ra àti ìfẹnukonu pípẹ́títí. Mó nífẹ̀ẹ́ gbogbo yín.”

Brunella kò jẹ́ kí ìgbà èwe tàbí àmódi òun sún yíya ara òun sí mímọ́ fún Ọlọrun síwájú. Àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìpinnu rẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ lọ́mọdé lágbà ní ìṣírí láti pa ohunkóhun tí ó lè dí wọn lọ́wọ́ nínú sísúré ìje ìye tì sẹ́gbẹ̀ẹ́kan.​—⁠Heberu 12:⁠1.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́