Ìpàdé Ọdọọdún
OCTOBER 1, 1994
ÌPÀDÉ ỌDỌỌDÚN ti mẹ́ḿbà Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ni a ó ṣe ní October 1, 1994, ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ní 2932 Kennedy Boulevard, Jersey City, New Jersey. A ó ṣe ìpàdé àṣeṣáájú ti kìkì àwọn mẹ́ḿbà ní agogo 9:30 òwúrọ̀, tí ìpàdé ọdọọdún ti gbogbogbòò yóò sì tẹ̀lé e ní agogo 10:00 òwúrọ̀.
Àwọn mẹ́ḿbà Àjọ-Ẹgbẹ́ níláti fi ìyípadà èyíkéyìí nínú àwọn àdírẹ́sì ìfìwéránṣẹ́ wọn nínú ọdún tí ó kọjá tó Ọ́fíìsì Akọ̀wé létí nísinsìnyí kí àwọn lẹ́tà ìfitónilétí tí a ń lò déédéé àti ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni baà lè dé ọ̀dọ̀ wọn ní July.
Àwọn ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni náà, tí a ó fi ránṣẹ́ sí àwọn mẹ́ḿbà pẹ̀lú ìfitónilétí nípa ìpàdé ọdọọdún náà, ni a níláti dá padà kí ó baà lè dé Ọ́fíìsì Akọ̀wé Society láìpẹ́ ju August 1 lọ. Mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan níláti kọ ọ̀rọ̀ kún ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni tirẹ̀ ní kíámọ́sá kí ó sì dá a padà, ní sísọ yálà òun fúnra-òun yóò wà ní ibi ìpàdé náà tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. Ìsọfúnni tí a fifúnni lórí ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ṣe pàtó lórí kókó yìí, níwọ̀n bí a ó ti gbáralé e fún pípinnu àwọn wo ni yóò wà níbẹ̀ fúnraawọn.
A retí pé gbogbo àkókò ìjókòó náà, títíkan ìpàdé iṣẹ́-àmójútó tí a ń ṣe déédéé àti àwọn ìròyìn, yóò ti parí nígbà tí ó bá fi máa di agogo 1:00 ọ̀sán tàbí ní kété lẹ́yìn náà. Kì yóò sí àkókò ìjókòó ti ọ̀sán. Nítorí àyè tí ó mọníwọ̀n, ìgbàwọlé yóò jẹ́ nípasẹ̀ tíkẹ́ẹ̀tì nìkanṣoṣo. Kì yóò sí ìṣètò kankan fún síso ìpàdé ọdọọdún náà pọ̀ mọ́ wáyà tẹlifóònù lọ sí àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ mìíràn.