Ṣiṣẹ́ Kára Fún Ìgbàlà Agbo-Ilé Rẹ
“Ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Oluwa.”—EFESU 6:4.
1, 2. Àwọn ìpèníjà wo ni ó dojúkọ àwọn òbí lónìí?
ÌWÉ ìròyìn gbígbajúmọ̀ kan pè é ní ìyípìlẹ̀dà. Èyí jẹ́ nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan tí ó ṣàpèjúwe àwọn ìyípadà tí ń múni tagìrì tí ó ti wáyé nínú ìdílé ní àwọn ọdún ẹnu àìpẹ́ yìí. Ìwọ̀nyí ni a sọ pé ó jẹ́ “ìyọrísí àrànkálẹ̀ àrùn ìkọ̀sílẹ̀, ìtúngbeyàwóṣe, ìtún-ìkọ̀sílẹ̀-ṣe, àìtọ́sófin, àti àwọn pákáǹleke titun nínú àwọn ìdílé wíwà papọ̀.” Irúfẹ́ àwọn másùnmáwo àti pákáǹleke bẹ́ẹ̀ kò yanilẹ́nu, nítorí tí Bibeli sọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ènìyàn yóò dojúkọ “awọn àkókò lílekoko” ní àkókò “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí.—2 Timoteu 3:1-5, NW.
2 Nítorí náà, àwọn òbí lónìí dojúkọ àwọn ìpèníjà tí àwọn ìran tí wọ́n ti wà ṣáájú kò mọ̀ rí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí díẹ̀ láàárín wa ti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà ní àwọn ọ̀nà ìfọkànsìn Ọlọrun láti “ìgbà ọmọdé,” ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí ‘rìn nínú òtítọ́’ ni. (2 Timoteu 3:15; 3 Johannu 4) Àwọn ọmọ wọn ti lè tóójúbọ́ nígbà tí àwọn òbí bẹ̀rẹ̀ síí kọ́ wọn ní àwọn ọ̀nà Ọlọrun. Síwájú síi, iye àwọn ìdílé anìkàntọ́mọ kan tí ó túbọ̀ ń pọ̀ síi àti àwọn ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe ni a rí láàárín wa. Ohun yòówù kí àwọn àyíká-ipò rẹ jẹ́, ìṣílétí aposteli Paulu ṣeé fisílò: “Ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Oluwa.”—Efesu 6:4.
Àwọn Kristian Òbí àti Ipa-Iṣẹ́ Wọn
3, 4. (a) Àwọn okùnfà wo ni ó ti mú kí ìfàsẹ́yìn débá ipa tí àwọn baba ń kó? (b) Èéṣe tí àwọn baba tí wọ́n jẹ́ Kristian fi gbọ́dọ̀ ṣe ju jíjẹ́ olùpèsè jíjẹ-mímu lásán lọ?
3 Ṣàkíyèsí pé Paulu darí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní Efesu 6:4 sí àwọn “baba” ní pàtàkì. Òǹkọ̀wé kan ṣàlàyé pé ní àwọn ìran tí ó ti wà ṣáájú “ẹrù-iṣẹ́ àwọn baba ni láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà lọ́nà ti ìwàhíhù àti tẹ̀mí; ẹrù-iṣẹ́ àwọn baba ni láti mú kí àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀kọ́-ìwé. . . . Ṣùgbọ́n Ìyípìlẹ̀dà Ilé-Iṣẹ́ Àfẹ̀rọṣe mú ìbátan tímọ́tímọ́ yìí kúrò; àwọn baba fi oko àti àwọn ilé-ìtajà wọn sílẹ̀, wọ́n fi ilé wọn sílẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ní àwọn ilé-iṣẹ́ ẹ̀rọ àti lẹ́yìn náà ní àwọn ọ́fíìsì. Àwọn ìyá tẹ́rígba ọ̀pọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ tí àwọn baba ti ń fìgbà kan rí bójútó. Lọ́nà tí ó túbọ̀ ń ga síi, ipò jíjẹ́ baba di èyí tí a ń gbékarí gẹ́gẹ́ bí orúkọ lásán.”
4 Ẹ̀yin Kristian ọkùnrin: Ẹ máṣe jẹ́ kí jíjẹ́ olùpèsè jíjẹ-mímu lásán tẹ́ yín lọ́rùn, ní fífi gbogbo ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ìtọ́dàgbà àwọn ọmọ yín sílẹ̀ fún àwọn aya yín. Owe 24:27 rọ àwọn baba ní àwọn àkókò ìgbàanì pé: “Múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ lóde, kí o sì fi ìtara túlẹ̀ ní oko rẹ; níkẹyìn èyí, kí o sì kọ́ ilé rẹ.” Bákan náà lónìí, gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́kùnrin kan, ìwọ lè níláti ṣiṣẹ́ kára àti fún àkókò gígùn láti gbọ́ bùkátà ìdílé. (1 Timoteu 5:8) Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìnwá ìgbà náà, jọ̀wọ́ wá àkókò láti “kọ́ ilé rẹ”—nípa ti èrò-ìmọ̀lára àti nípa tẹ̀mí.
5. Báwo ni àwọn Kristian aya ṣe lè ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà agbo-ilé wọn?
5 Ẹ̀yin Kristian aya: Ẹ̀yin pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára fún ìgbàlà agbo-ilé yín. Owe 14:1 sọ pé: “Ọlọgbọ́n obìnrin ní kọ́ ilé rẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí alájọṣègbéyàwó, ìwọ àti ọkọ rẹ jọ ni ẹrù-iṣẹ́ fífún àwọn ọmọ yín ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ ni. (Owe 22:6; Malaki 2:14) Èyí lè ní nínú fífún àwọn ọmọ rẹ ní ìbáwí, mímúra wọn sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé Kristian àti iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá, tàbí dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé pàápàá nígbà tí kò bá ṣeéṣe fún ọkọ rẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. O tún lè ṣe púpọ̀ láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ ní àwọn iṣẹ́ ilé, ìwà ọmọlúwàbí, ìmọ́tótó ara, àti ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan mìíràn tí ó lè ṣèrànlọ́wọ́. (Titu 2:5) Nígbà tí àwọn ọkọ àti àwọn aya bá ṣiṣẹ́ papọ̀ ní ọ̀nà yìí, wọ́n lè kúnjú àìní àwọn ọmọ wọn lọ́nà tí ó sàn jù. Kí tilẹ̀ ni díẹ̀ lára àwọn àìní wọ̀nyí?
Bíbójútó Àwọn Àìní Wọn Níti Èrò-Ìmọ̀lára
6. Ipa wo ni àwọn ìyá àti baba ń kó nínú ìdàgbàsókè àwọn ọmọ wọ́n níti èrò-ìmọ̀lára?
6 ‘Nígbà tí abiyamọ bá ń tọ́jú àwọn ọmọ òun tìkáraarẹ̀,’ wọ́n máa ń nímọ̀lára wíwà ní ààbò, láìléwu, pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. (1 Tessalonika 2:7; Orin Dafidi 22:9) Díẹ̀ ni àwọn ìyá tí wọ́n lè dènà ìsúnniṣe náà láti darí gbogbo àfiyèsí wọn sórí àwọn ọmọ wọn jòjòló. Wòlíì Isaiah béèrè pé: “Obìnrin ha lè gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ bí, tí kì yóò fi ṣe ìyọ́nú sí ọmọ inú rẹ̀?” (Isaiah 49:15) Nípa báyìí, àwọn ìyá ń kó ipa pàtàkì nínú ìdàgbàsókè àwọn ọmọ níti èrò-ìmọ̀lára. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn baba pẹ̀lú ń kó ipa pàtàkì nínú ọ̀ràn yìí. Onímọ̀-ẹ̀kọ́ nípa ìdílé Paul Lewis sọ pé: “N kò tíì rí òṣìṣẹ́ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà kanṣoṣo rí tí ó tíì gbọ́ kí ọmọdé kan [tí ó ti yapòkíì] ròyìn pé òun ní ipò-ìbátan dídára pẹ̀lú baba wọn rí. Kìí tilẹ̀ ṣe ọ̀kan nínú ọgọ́rùn-ún.”
7, 8. (a) Ẹ̀rí wo ni a ní níti ìdè lílágbára tí ó wà láàárín Jehofa Ọlọrun àti Ọmọkùnrin rẹ̀? (b) Báwo ni àwọn baba ṣe lè mú ìdè ìfẹ́ dàgbà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn?
7 Nítorí náà ó ṣekókó pé kí àwọn baba tí wọ́n jẹ́ Kristian fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ mú ìdè ìfẹ́ dàgbà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi. Nígbà ìrìbọmi Jesu, Jehofa polongo pé: “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.” (Luku 3:22) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni a sọ pẹ̀lú ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ díẹ̀ yẹn! Jehofa (1) jẹ́wọ́ mímọ Ọmọkùnrin rẹ̀, (2) ó sọ ìfẹ́ tí ó ní fún Jesu jáde ní gbangba, ó sì (3) fi títẹ́wọ́ tí ó tẹ́wọ́gba Jesu hàn. Síbẹ̀, èyí kọ́ ni ìgbà kanṣoṣo náà tí Jehofa sọ ìfẹ́ tí ó ní fún Ọmọkùnrin rẹ̀ jáde. Jesu sọ fún Baba rẹ̀ lẹ́yìn náà pé: “Ìwọ ṣá fẹ́ràn mi ṣíwájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.” (Johannu 17:24) Ṣùgbọ́n, níti tòótọ́, kìí ha ṣe gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin onígbọràn ni ó yẹ kí àwọn baba wọn jẹ́wọ́ pé àwọn mọ̀, pé àwọn nífẹ̀ẹ́, tí àwọn sì tẹ́wọ́gbà bí?
8 Bí ìwọ bá jẹ́ baba, ó ṣeéṣe kí ìwọ lè ṣe púpọ̀ láti mú ìdè ìfẹ́ dàgbà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ nípa sísọ àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ni tí ó yẹ jáde déédéé nípa ìṣesí ti ara-ìyára àti ọ̀rọ̀-ẹnu. A gbà pé, ó ṣòro fún àwọn ọkùnrin kan láti fi ìfẹ́ni wọn hàn, pàápàá jùlọ bí wọn kò bá tíì rí ìfẹ́ni tí ó farahàn gbangba gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn baba tí ó bí wọn. Síbẹ̀ náà ìgbìdánwò tí kò jágaara láti fi ìfẹ́ hàn fún àwọn ọmọ rẹ lè ní ipa lílágbára lórí wọn. Ó ṣetán, “ìfẹ́ ní gbéniró.” (1 Korinti 8:1) Bí àwọn ọmọ rẹ bá nímọ̀lára ààbò nítorí ìfẹ́ bíi ti baba tí o fihàn, wọn yóò nítẹ̀sí púpọ̀ síi láti jẹ́ ‘ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin gidi’ wọn yóò sì ní òmìnira fàlàlà láti finú hàn ọ́.—Owe 4:3, NW.
Bíbójútó Àwọn Àìní Wọn Tẹ̀mí
9. (a) Báwo ní àwọn ọmọ Israeli olùbẹ̀rù Ọlọrun tí wọ́n jẹ́ òbí ṣe bójútó àìní tẹ̀mí àwọn ọmọ wọn? (b) Àwọn àǹfààní wo ni àwọn Kristian ní láti kọ́ àwọn ọmọ wọn láìjẹ́-bí-àṣà?
9 Àwọn ọmọ pẹ̀lú ní àwọn àìní tẹ̀mí. (Matteu 5:3) Mose gba àwọn ọmọ Israeli tí wọ́n jẹ́ òbí níyànjú pé: “Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí mo paláṣẹ fún ọ ní òní, kí ó máa wà [ní] àyà rẹ: kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi, kí ìwọ kí ó sí máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ ísọ nígbà tí ìwọ bá jókòó nínú ilé rẹ, àti nígbà tí ìwọ bá ń rìn ní ọ̀nà, àti nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, àti nígbà tí ìwọ bá dìde.” (Deuteronomi 6:6, 7) Bí ìwọ bá jẹ́ Kristian òbí, ìwọ lè ṣe púpọ̀ nínú fífúnni ní ìtọ́ni rẹ lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà, bí ìgbà tí “ìwọ bá ń rìn ní ọ̀nà.” Àkókò tí ẹ fi wà papọ̀ nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ìdílé, tí ẹ fi ń nájà, tàbí tí ẹ fi ń rìn papọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ yín láti ẹnu-ọ̀nà dé ẹnu-ọ̀nà nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian ń pèsè àwọn àǹfààní gbígbámúṣé láti fúnni ní ìtọ́ni lábẹ́ àyíká ipò kan tí ó dẹrùn. Àwọn àkókò oúnjẹ jẹ́ àkókò dídára ní pàtàkì fún àwọn ìdílé láti jùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀. Òbí kan ṣàlàyé pé, “A ń lo àkókò oúnjẹ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí ó bá ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà.”
10. Èéṣe tí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé fi máa ń jẹ́ ìpèníjà ní àwọn ìgbà mìíràn, ìpinnu wo sì ni àwọn òbí gbọ́dọ̀ ní?
10 Bí ó ti wù kí ó rí, ìtọ́ni gẹ́gẹ́ bí àṣà nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ tún ṣekókó. A gbà pé, “Ní àyà ọmọdé ni wèrè dì sí.” (Owe 22:15) Àwọn òbí kan sọ pé lọ́nà tí ó rọrùn àwọn ọmọ wọn lè mọ̀ọ́mọ̀ dínà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. Báwo? Nípa ṣíṣe wọ́nran-wọ̀nran àti fífi ìdálágara hàn, nípa dídá ìpínyà ọkàn sílẹ̀ lọ́nà tí ń bíni nínú (bíi bíbá àwọn àbúrò jà), tàbí nípa dídíbọ́n pé wọn kò mọ kókó ìpìlẹ̀ àwọn òtítọ́ Bibeli. Bí èyí bá ń báa lọ títí dé orí dídi ìjà ìfẹ́-inú-taló-lágbára jù, ìfẹ́-inú ti òbí kan ni ó gbọ́dọ̀ lágbára jùlọ. Àwọn Kristian òbí kò gbọ́dọ̀ juwọ́sílẹ̀ láti jẹ́ kí àwọn ọmọ jọba lé agbo ilé náà lórí.—Fiwé Galatia 6:9.
11. Báwo ni a ṣe lè mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé gbádùnmọ́ni?
11 Bí àwọn ọmọ rẹ kìí bá gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, bóyá o lè ṣe àwọn ìyípadà díẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, o ha lo ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gẹ́gẹ́ bí àwáwí fún ṣíṣàtúnyẹ̀wò àwọn ohun tí ó kù-díẹ̀-ká-à-tó tí àwọn ọmọ rẹ ṣe lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí bí? Bóyá yóò dára jùlọ láti jíròrò irúfẹ́ àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ ní ìdákọ́ńkọ́. Ẹ ha ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ yín déédéé bí? Bí ẹ bá wọ́gilé e nítorí eré orí tẹlifíṣọ̀n tàbí ìgbòkègbodò eré ìdárayá kan tí ẹ yànláàyò, ó ṣeéṣe kí àwọn ọmọ yín má fi ọwọ́ tí ó ṣe pàtàkì mú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ìwọ ha ní ìgbónára àti ìtara-ọkàn nínú ọ̀nà tí o gbà ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ bí? (Romu 12:8) Bẹ́ẹ̀ni, ìkẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ gbádùnmọ́ni. Gbìyànjú láti mú kí gbogbo àwọn ọmọ lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Máṣe kámikàmìkámi, jẹ́ olùgbéniró, fọ̀yàyà gbóríyìn fún àwọn ọmọ rẹ fún ìkópa wọn. Àmọ́ ṣáá o, má wulẹ̀ kárí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n gbìyànjú láti dé inú ọkàn-àyà.—Owe 23:15.
Bíbániwí Nínú Òdodo
12. Èéṣe tí ìbáwí kìí fìgbà gbogbo ní nínanilẹ́gba nínú?
12 Àwọn ọmọ pẹ̀lú ní àìní lílágbára fún ìbáwí. Gẹ́gẹ́ bí òbí, ẹ níláti gbé àwọn ààlà kalẹ̀ fún wọn. Owe 13:24 sọ pé: “Ẹni tí ó bá fa ọwọ́ pàṣán sẹ́yìn, ó kórìíra ọmọ rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ ẹ a máa tètè nà án.” Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli kò ní in lọ́kàn pé nígbà gbogbo ìbáwí ni a gbọ́dọ̀ máa fifúnni pẹ̀lú ẹgba. Owe 8:33 sọ pé: “Gbọ́ ẹ̀kọ́,” a sì sọ fún wa pé “ìbáwí wọ inú ọlọgbọ́n ju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ nínú aṣiwèrè.”—Owe 17:10.
13. Ọ̀nà wo ni ó yẹ kí a gbà fún ọmọ ní ìbáwí?
13 Ní àwọn ìgbà mìíràn, ìbáwí ẹlẹ́gba lè jẹ́ ohun yíyẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, bí a bá fi í fúnni pẹ̀lú ìbínú, ó ṣeéṣe kí ó di àṣerégèé kí ó má sì gbéṣẹ́. Bibeli kìlọ̀ pé: “Ẹ̀yin baba, ẹ máṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọ́n má baà rẹ̀wẹ̀sì.” (Kolosse 3:21) Nítòótọ́, “ìnilára mú ọlọgbọ́n ènìyàn sínwín.” (Oniwasu 7:7) Ọ̀dọ́ kan tí a mú ọkàn rẹ̀ korò lè ṣọ̀tẹ̀ lòdìsí àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n òdodo pàápàá. Nípa báyìí, àwọn òbí níláti lo Ìwé Mímọ́ láti bá àwọn ọmọ wọn wí nínú òdodo ní ọ̀nà fífìdímúlẹ̀gbọnyin tí ó sì wàdéédéé. (2 Timoteu 3:16) Ìbáwí Ọlọrun ni a ń fifúnni pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìwàtútù.—Fiwé 2 Timoteu 2:24, 25.a
14. Kí ni àwọn òbí níláti ṣe bí wọ́n bá ní ìtẹ̀sí láti bínú?
14 Àmọ́ ṣáá o, “nínú ohun púpọ̀ ni gbogbo wa ń ṣì í ṣe.” (Jakọbu 3:2) Àní òbí kan tí ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ lọ́nà yíyẹ pàápàá lè jọ̀gọ̀nù fún ìkìmọ́lẹ̀ ojú-ẹsẹ̀ kí ó sì sọ ohun kan tí kò fi inúrere hàn tàbí kí ó faraya. (Kolosse 3:8) Bí ìyẹn bá níláti wáyé, máṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ọmọ rẹ nínú ìsoríkọ́ ńlá tàbí pẹ̀lú ìwọ fúnraàrẹ nínú ipò ìmúbínú. (Efesu 4:26, 27) Yanjú ọ̀ràn náà pẹ̀lú ọmọ rẹ, ní bíbẹ̀ ẹ́ bí ìyẹn bá jẹ́ ohun yíyẹ. (Fiwé Matteu 5:23, 24.) Fífi irú ìrẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ hàn lè túbọ̀ fa ìwọ àti ọmọ rẹ súnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí. Bí o bá nímọ̀lára pé o kò lè ṣàkóso ẹ̀mí rẹ tí ìwọ yóò sì fi ìbínú hàn, wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà tí a yànsípò nínú ìjọ.
Àwọn Agbo-Ilé Anìkàntọ́mọ àti Àwọn Ìdílé Onígbeyàwó Àtúnṣe
15. Báwo ni a ṣe lè ran àwọn ọmọdé nínú ìdílé òbí anìkàntọ́mọ lọ́wọ́?
15 Ṣùgbọ́n, kìí ṣe gbogbo àwọn ọmọ ni wọ́n ní ìtìlẹ́yìn àwọn òbí méjì. Ní United States, ọmọ 1 nínú 4 ni òbí anìkàntọ́mọ ń tọ́ dàgbà. ‘Àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba’ wọ́pọ̀ ní àwọn àkókò tí a kọ Bibeli, ìdàníyàn fún wọn ni a sì mẹ́nukan lemọ́lemọ́ nínú Ìwé Mímọ́. (Eksodu 22:22) Lónìí, àwọn agbo-ilé Kristian anìkàntọ́mọ bákan náà ń dojúkọ àwọn ìkìmọ́lẹ̀ àti ìṣòro, ṣùgbọ́n wọ́n ń rí ìtùnú nínú mímọ̀ pé Jehofa ni “baba àwọn aláìníbaba àti onídàájọ́ àwọn opó.” (Orin Dafidi 68:5) Àwọn Kristian ni a rọ̀ láti “máa bójútó àwọn aláìníbaba àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn.” (Jakọbu 1:27) Àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lè ṣe púpọ̀ láti ran àwọn ìdílé anìkàntọ́mọ lọ́wọ́.b
16. (a) Kí ni àwọn òbí anìkàntọ́mọ níláti ṣe nítorí agbo-ilé tiwọn? (b) Èéṣe tí ìbáwí fi lè ṣòro, ṣùgbọ́n èéṣe tí a gbọ́dọ̀ fi í fúnni?
16 Bí ìwọ bá jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ, kí ni ìwọ fúnraàrẹ lè ṣe láti ṣe agbo-ilé rẹ láǹfààní? O níláti jẹ́ aláápọn nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìdílé, lílọ sí ìpàdé, àti iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá. Ṣùgbọ́n, ìbáwí ní pàtàkì lè jẹ́ ìpèníjà tí ó ṣòro. Bóyá o ṣì ń kẹ́dùn ìpàdánù ẹnìkejì rẹ tí ó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n. Tàbí o ń jìjàkadì pẹ̀lú ìmọ̀lára ẹ̀bi tàbí ìbínú nítorí ìtúká ìgbéyàwó. Bí ìwọ àti ẹnìkejì rẹ tẹ́lẹ̀rí bá jọ ní ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ lábẹ́ òfin, ẹ̀rù tilẹ̀ lè bà ọ́ pé ọmọ rẹ lè yàn láti wà pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀ tí ó pínyà tàbí tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ náà. Irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ lè mú kí ó ṣòro fún ọ níti èrò-ìmọ̀lára láti fúnni ní ìbáwí wíwà déédéé. Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli sọ fún wa pé “ọmọ tí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ fún araarẹ̀, á dójúti ìyá rẹ̀.” (Owe 29:15) Nítorí náà máṣe juwọ́sílẹ̀ nítorí ẹ̀bi-ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀dùn-ẹ̀ṣẹ̀, tàbí ìkìmọ́lẹ̀ èrò-ìmọ̀lára tí alábàáṣègbéyàwó rẹ tẹ́lẹ̀rí mú wá. Gbé àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n lílọ́gbọ́n nínú tí ó sì ṣedéédéé kalẹ̀. Máṣe fi àwọn ìlànà Bibeli bánidọ́rẹ̀ẹ́.—Owe 13:24.
17. Báwo ní ipa tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ń kó ṣe lè di èyí tí kò ṣe kedere nínú agbo-ilé òbí anìkàntọ́mọ, kí sì ni a lè ṣe láti dènà èyí?
17 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìṣòro lè dìde bí ìyá anìkàntọ́mọ bá bá ọmọkùnrin rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí ọkọ àyàndípò—baálé ilé—tàbí ọmọbìnrin rẹ gẹ́gẹ́ bí alábàárò, ní dídi ẹrù àwọn ìṣòro ara-ẹni rù ú. Kìí ṣe ohun yíyẹ ni láti ṣe bẹ́ẹ̀ ó sì máa ń da ọmọ láàmú. Nígbà tí ipa òbí àti ọmọ bá di èyí tí kò ṣe kedere mọ́, ìbáwí lè wólulẹ̀. Jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé òbí ni ìwọ jẹ́. Bí ìwọ bá jẹ́ ìyá tí ó nílò ìmọ̀ràn tí a gbékarí Bibeli, wá a sọ́dọ̀ àwọn alàgbà tàbí bóyá arábìnrin àgbàlagbà kan tí ó dàgbàdénú.—Fiwé Titu 2:3-5.
18, 19. (a) Kí ni àwọn ìpèníjà díẹ̀ tí àwọn ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe ń dojúkọ? (b) Báwo ni àwọn òbí àti àwọn ọmọ nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe ṣe lè fi ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ hàn?
18 Àwọn ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe ń dojúkọ àwọn ìpèníjà. Ní lemọ́lemọ́, àwọn òbí onígbeyàwó àtúnṣe ń rí i pé “ìfẹ́ ojú-ẹsẹ̀” ṣọ̀wọ́n. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ ìgbéyàwó ìṣáájú le tètè mọ̀ ọ́ lára bí a bá fi ohun tí ó dàbí ìṣègbè èyíkéyìí hàn sí àwọn ọmọ ìgbéyàwó àtúnṣe. (Fiwé Genesisi 37:3, 4.) Ní tòótọ́, àwọn ọmọ ìgbéyàwó ìṣáájú lè máa jìjàkadì pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn fún òbí tí ó ti di olóògbé náà kí wọ́n sì bẹ̀rù pé nínífẹ̀ẹ́ òbí ìgbéyàwó àtúnṣe yóò jẹ́ àìfi ìdúróṣinṣin hàn sí baba tàbí ìyá tiwọn fúnraawọn. Ìgbìdánwò láti fúnni ní àwọn ìbáwí tí a nílò ni a lè kò lójú pẹ̀lú ìránnilétí rírorò náà pàdé pé, ‘Ìwọ kọ́ ni òbí mi gan-an!’
19 Owe 24:3 sọ pé: “Ọgbọ́n ni a fií kọ́ ilé; òye ni a sì fií fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ni, ó gba ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ láti ọ̀dọ̀ olúkúlùkù kí ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe kan tó lè kẹ́sẹjárí. Bí àkókò tí ń lọ, àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́gba òtítọ́ tí ó sábà máa ń ronilára náà pé àwọn nǹkan ti yípadà. Àwọn òbí inú ìgbéyàwó àtúnṣe bákan náà lè fẹ́ láti kọ́ láti jẹ́ onísùúrù àti olùgbatẹnirò, kí wọ́n má tètè máa bínú nígbà tí wọ́n bá dojúkọ ohun tí ó dàbí ṣíṣánitì. (Owe 19:11; Oniwasu 7:9) Ṣáájú títẹ́wọ́gba ipa-iṣẹ́ ti fífúnni ní ìbáwí, ṣiṣẹ́ láti kọ́kọ́ fìdí ipò ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ múlẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ìgbéyàwó àkọ́kọ́ náà. Títí di ìgbà tí irú ìdè bẹ́ẹ̀ bá di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀, àwọn kan lè kà á sí ohun tí ó sàn jù láti jẹ́ kí ẹni tí ó jẹ́ òbí gan-an fúnni ní ìbáwí. Nígbà tí pákáǹleke bá dìde, ẹ gbọ́dọ̀ sapá láti jùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀. “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùnlukùn,” ni Owe 13:10 (NW) sọ.c
Máa Báa Nìṣó ní Ṣíṣiṣẹ́ fún Ìgbàlà Agbo-Ilé Rẹ!
20. Kí ni àwọn olórí ìdílé tí wọ́n jẹ́ Kristian níláti máa báa lọ láti ṣe?
20 Àwọn ìdílé Kristian lílágbára kìí ṣe ọ̀ràn èèṣì. Ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olórí ìdílé gbọ́dọ̀ máa báa lọ láti ṣiṣẹ́ kára fún ìgbàlà agbo-ilé yín. Ẹ wà lójúfò, ní kíkíyèsí àwọn ànímọ́ tí kò dára tàbí ìtẹ̀sí ti ayé. Ẹ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ, ìwà, ìfẹ́, ìgbàgbọ́, àti ìwà mímọ́. (1 Timoteu 4:12) Ẹ fi ìṣùpọ̀-èso ẹ̀mí Ọlọrun hàn. (Galatia 5:22, 23) Sùúrù, ìgbatẹnirò, ìdáríjì, àti ìwà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ yóò sọ ìsapá yín láti kọ́ àwọn ọmọ yín ní àwọn ọ̀nà Ọlọrun di alágbára.—Kolosse 3:12-14.
21. Báwo ni a ṣe lè mú kí àyíká ọlọ́yàyà, àti aláyọ̀ máa wà nìṣó nínú ilé ẹni?
21 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun, gbìyànjú láti di ẹ̀mí ayọ̀, ọlọ́yàyà mú nínú ilé rẹ. Ẹ lo àkókò papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, ní lílàkàkà láti jùmọ̀ jẹ oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan lójoojúmọ́ ó kérétán. Àwọn ìpàdé Kristian, iṣẹ́-ìsìn pápá, àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ṣekókó. Síbẹ̀, “ìgbà láti rẹ́rìn-ín . . . àti ìgbà láti tọ pọ́n-ún pọ́n-ún káàkiri” tún wà. (Oniwasu 3:1, 4, NW) Bẹ́ẹ̀ni, ẹ wéwèé àwọn àkókò fún eré-ìtura tí ń gbéniró. Ìbẹ̀wò sí àwọn ibi-àkójọ ohun ìṣẹ̀m̀báyé, ọgbà ẹranko, àti àwọn ibòmíràn bẹ́ẹ̀ yóò gbádùn mọ́ gbogbo ìdílé. Tàbí ẹ lè pa tẹlifíṣọ̀n kí ẹ sì lo àkókò fún kíkọrin, fífetísílẹ̀ sí ohùn orin, títayò, àti sísọ̀rọ̀. Èyí lè ran ìdílé lọ́wọ́ láti túbọ̀ súnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí.
22. Èéṣe tí o fi níláti ṣiṣẹ́ kára fún ìgbàlà agbo-ilé rẹ?
22 Ǹjẹ́ kí gbogbo ẹ̀yin Kristian òbí máa báa lọ láti ṣiṣẹ́ kí ẹ baà lè mú inú Jehofa dùn ní kíkún “bí ẹ ti ń bá a lọ ní síso èso ninu iṣẹ́ rere gbogbo tí ẹ sì ń pọ̀ sí i ninu ìmọ̀ pípéye nipa Ọlọrun.” (Kolosse 1:10, NW) Kọ́ agbo-ilé rẹ sórí ìpìlẹ̀ lílágbára ti ìṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. (Matteu 7:24-27) Sì ní ìdánilójú pé ìsapá rẹ láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ dàgbà “nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Oluwa” yóò ní ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀.—Efesu 6:4.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Ojú-Ìwòye Bibeli: ‘Pàṣán Ìtọ́ni’—O Ha Ti Di Alaibagbamu Bi?” nínú Jí! ti September 8, 1992.
b Wo Ilé-Ìṣọ́nà ti March 15, 1981, ojú-iwé 12 sí 23.
c Wo Ilé-Ìṣọ́nà ti May 1, 1985, ojú-ìwé 21 sí 25.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Báwo ni ọkọ àti aya ṣe lè fọwọ́sowọ́pọ̀ nínú gbígbé agbo-ilé wọn ró?
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn àìní ti èrò-ìmọ̀lára tí àwọn ọmọdé ní, báwo sì ni a ṣe lè kúnjú ìwọ̀nyí?
◻ Báwo ni àwọn olórí ìdílé ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn gẹ́gẹ́ bí àṣà àti lọ́nà tí àìjẹ́-bí-àṣà?
◻ Báwo ni àwọn òbí ṣe lè bániwí nínú òdodo?
◻ Kí ni a lè ṣe fún àǹfààní àwọn ìdílé anìkàntọ́mọ àti àwọn òbí onígbeyàwó àtúnṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìfẹ́ àti ìtẹ́wọ́gbà baba ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè ọmọ kan níti èrò-ìmọ̀lára