ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 9/1 ojú ìwé 19-21
  • Ṣọ́ra fún Fífọ́nnu

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣọ́ra fún Fífọ́nnu
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipa tí Ó Ń Ní Lórí Ipò-Ìbátan
  • Fífọ́nnu Ń Jẹyọ Lati Inú Àìlera
  • “Ṣugbọn Òtítọ́ Ni!”
  • A Ha Nílò Rẹ̀ fún Kíkẹ́sẹjárí Bí?
  • Àǹfààní Jíjẹ́ Oníwọ̀ntúnwọ̀nsì
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Ànímọ́ Rere Rẹ Di Àbùkù Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • O Lè Jẹ́ Amẹ̀tọ́mọ̀wà Bí Kò Bá Tiẹ̀ Rọrùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • “Ọgbọ́n Wà Pẹ̀lú Àwọn Amẹ̀tọ́mọ̀wà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà—Ànímọ́ Tó Ń gbé Àlàáfíà Lárugẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 9/1 ojú ìwé 19-21

Ṣọ́ra fún Fífọ́nnu

LÓNÌÍ ọ̀pọ̀ ènìyàn ń fojú wo fífọ́nnu gẹ́gẹ́ bí ìwàrere. Fífi ọrọ̀ àjogúnbá, òye-iṣẹ́, ati àṣeyọrí ẹni yangàn ti di àṣà tó gbòde. Awọn kan gbàgbọ́ pé fífọ́nnu pọndandan lati lè ṣàṣeyọrí. Awọn mìíràn nímọ̀lára pé ó ń fikún iyì-ara-ẹni. Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò jíjẹ́ oníwọ̀ntunwọ̀nsì kò tíì parẹ́ pátápátá, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di àṣà tí kò bódemu mọ́.” Òǹkọ̀wé Jody Gaylin kọ̀wé pé: “Lọ́nà tí kò dùnmọ́ni, fífọ́nnu láìtijú . . . ni àṣà tó gbòde bayii. Ìjíròrò pẹlu ọ̀rẹ́ tabi ojúlùmọ̀ kan ti ní àṣekún titun: fífọn fèrè àṣeyọrí ẹni.”

Awọn ẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ láwùjọ ti fi ọ̀pá-ìdiwọ̀n lelẹ̀. O ṣeéṣe kí o ti gbọ́ awọn ọ̀rọ̀ olùgbégbá orókè akànṣẹ́ tẹ́lẹ̀rí kan pé: “Kìí ṣe èèṣì rárá pé emi ni ọkùnrin títóbilọ́lá jùlọ lágbàáyé ní àkókò yii ninu ọ̀rọ̀-ìtàn.” A tún mọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ mẹ́ḿbà kan lára ẹgbẹ́ akọrin Beatles bí-ẹni-mowó pẹlu pé: “A lókìkí ju Jesu Kristi lọ bayii.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé awọn kan fojú wo irú awọn gbólóhùn bẹ́ẹ̀ bí èyí tí kò lẹ́ṣẹ̀ ninu, awọn mìíràn gba awọn tí ń sọ wọn gẹ́gẹ́ bí àwòfiṣàpẹẹrẹ láwùjọ fún ìgbéra-ẹni-lárugẹ tí wọ́n sì níláti tẹ̀lé.

Fífọ́nnu tí ń gbèèràn gbé ìbéèrè naa dìde pé: Ó ha bójúmu lati máa fi ọrọ̀-ìní tabi agbára ẹni yangàn bí? Ó bá ìwà ẹ̀dá mu, lati máa yọ̀ṣìnkìn nitori àṣeyọrí ẹni ati lati sọ fún awọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ati ẹbí nipa rẹ̀ pẹlu. Ṣugbọn awọn tí wọn ń gbé ní ìbámu pẹlu àṣàyàn ọ̀rọ̀ naa ńkọ́: “Bí ọwọ́ rẹ̀ bá ti tẹ̀ ẹ́, lò ó kí gbogbo ayé gbọ́”? Síwájú síi, awọn wọnnì tí wọn kìí fónnu ní gbangba ńkọ́, ṣugbọn tí wọn máa ń lo ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ lati ríi dájú pé awọn mìíràn mọ̀ nipa okun ati àṣeyọrí wọn? Irú ìpolówó ara-ẹni bẹ́ẹ̀ ha dára, ó ha sì pọndandan, gẹ́gẹ́ bí awọn kan ṣe jẹ́wọ́ bí?

Ipa tí Ó Ń Ní Lórí Ipò-Ìbátan

Ronú nipa ipa tí ìfọ́nnu awọn ẹlòmíràn máa ń ní lórí rẹ. Fún àpẹẹrẹ, kí ni yoo jẹ́ ìhùwàpadà rẹ sí awọn gbólóhùn tí wọn tẹ̀lé e wọnyi?

“Awọn ìwé tí n kò tíì kọ dára ju awọn ìwé tí awọn ẹlòmíràn ti kọ lọ.”​—⁠Gbajú-gbajà òǹṣèwé kan.

“Kání pé mo wà níbẹ̀ nígbà ìṣẹ̀dá ni, emi ìbá ti pèsè awọn àbá wíwúlò fún ṣíṣètò àgbáyé lọ́nà dídára síi.”​—⁠Ọba Sànmánnì Agbedeméjì.

“Kò dájú pé Ọlọrun kan wà, bí ọ̀kan bá sì wà, n kò lè gbàgbọ́ pé kìí ṣe emi ní Onítọ̀hún.”​—⁠Ọlọ́gbọ́n-ìmọ̀-ọ̀ràn ọ̀rúndún kọkàndínlógún.

Ọ̀rọ̀ awọn ènìyàn wọnyi ha fà ọ́ mọ́ra bí? Iwọ ha rò pé iwọ yoo gbádùn wíwà papọ̀ pẹlu wọn bí? Kò dájú rárá. Ní gbogbogbòò, fífọ́nnu​—⁠níti gidi tabi lọ́nà àwàdà pàápàá⁠—​kìí fi awọn ẹlòmíràn lára balẹ̀, ó ń bí wọn ninu, boya kí ó tilẹ̀ mú wọn ṣe ìlara. Èyí ni ipa tí ó ní lórí Asafu onipsalmu naa, tí ó jẹ́wọ́ pé: “Mo ṣe ìlara nitori awọn (tí ń fọ́nnu).” (Orin Dafidi 73:3) Dájúdájú, kò sí ẹnikẹ́ni ninu wa tí ó fẹ́ jẹ́ okùnfà ìmọ̀lára búburú fún awọn ọ̀rẹ́ ati alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ wa! Korinti kìn-⁠ín-ní 13:4 sọ pé: “Ìfẹ́ . . . kìí fẹ̀.” Ìfẹ́ Ọlọrun ati jíjẹ́ ẹni tí ó tètè ń kíyèsí ìmọ̀lára awọn ẹlòmíràn yoo sún wa lati yàgò fún fífi awọn òye⁠-⁠iṣẹ́ ati ọrọ̀-ìní tí a rò pé a ní ṣàṣehàn.

Nígbà tí ẹnìkan bá kó araarẹ̀ níjàánu tí ó sì sọ̀rọ̀ níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó ń fi awọn tí ń bẹ láyìíká rẹ̀ lára balẹ̀ kí wọn sì nímọ̀lára dídara nipa araawọn. Agbára kan tí kò ṣeé díyelé ni èyí jẹ́. Bóyá èyí ni aṣáájú-òṣèlú ọmọ ilẹ̀ Britain naa Lord Chesterfield ní lọ́kàn nígbà tí ó ń gba ọmọkùnrin rẹ̀ ní ìmọ̀ràn pé: “Jẹ́ ọlọgbọ́n ju awọn ẹlòmíràn lọ bí ó bá ṣeéṣe fún ọ; ṣugbọn má ṣe sọ fún wọn.”

Awọn ènìyàn kò ní ẹ̀bùn kan-naa. Ohun tí ó rọrùn fún ẹnìkan lè nira fún ẹlòmíràn. Ìfẹ́ yoo sún ẹnìkan lati bá awọn wọnnì tí wọn kò ní ẹ̀bùn ní apá ibi tí oun ní tirẹ̀ sí kẹ́dùn. Ó ṣeéṣe pé, ẹnìkejì yẹn ní ẹ̀bùn ní awọn apá ibòmíràn. Aposteli Paulu sọ fún wa pé: “Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà ninu yin, nipa oore ọ̀fẹ́ tí a fifún mi, kí ó máṣe ró ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣugbọn kí ó lè rò níwọ̀ntúnwọ̀nsì, bí Ọlọrun ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olúkúlùkù.”​—⁠Romu 12:⁠3.

Fífọ́nnu Ń Jẹyọ Lati Inú Àìlera

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé awọn kan lè yẹra fún awọn adámálèṣe, kí wọn nímọ̀lára jíjẹ́ ẹni rírẹlẹ̀ bí wọn bá wà níwájú wọn, awọn mìíràn ń hùwàpadà lọ́nà yíyàtọ̀. Wọn parí èrò sí pé awọn tí ń fọ́nnu kò dá araawọn lójú. Òǹkọ̀wé Frank Trippett ṣàlàyé ìdí tí ó fi jẹ́ pé lójú awọn ẹlòmíràn, bí eré bí àwàdà, ẹnìkan tí ń ṣe fọ́ńté lè máa rẹ iyì araarẹ̀ sílẹ̀: “Gbogbo ènìyàn mọ̀ lọ́kàn araawọn pé fífọ́nnu máa ń fi awọn àmì àìlera fífarasin tí ó sì ń baninínújẹ́ hàn.” Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti mọ̀ nipa ẹ̀tàn tí ń bẹ ninu fífọ́nnu naa, kò ha bọ́gbọ́nmu lati yàgò fún yíyin ara-ẹni lọ́nà tí kò níláárí bí?

“Ṣugbọn Òtítọ́ Ni!”

Bí awọn kan ṣe máa ń dá ìgbéra-ẹni-lárugẹ láre nìyí. Wọn nímọ̀lára pé níwọ̀n bí wọn ti ní ẹ̀bùn ní awọn ọ̀nà kan nítòótọ́, lati díbọ́n lọ́nà mìíràn yoo túmọ̀sí jíjẹ́ alágàbàgebè.

Ṣugbọn ìfọ́nnu wọn ha jẹ́ òtítọ́ bí? Ìdíwọ̀n ara-ẹni máa ń jẹ́ èyí tí a gbékarí èrò ati ìmọ̀lára ara-ẹni. Ohun tí a wòye pé ó jẹ́ okun títayọ ninu araawa lè má jọ awọn mìíràn lójú. Òtítọ́ naa pé ẹnìkan nímọ̀lára àpàpàǹdodo lati fi agbara rẹ̀ ṣe ṣekárími tilẹ̀ lè fihàn pé oun kò lágbára rárá​—⁠kò lágbára tó lati dádúró láìsí ìpolówó. Bibeli mọ ìjótìítọ́ ìtẹ̀sí ènìyàn síhà títan ara-ẹni jẹ nígbà tí ó gbani níyànjú pé: “Ẹni tí ó bá rò pé oun dúró, kí ó kíyèsára, kí ó má ba ṣubú.”​—⁠1 Korinti 10:⁠12.

Àní bí ẹnìkan bá tilẹ̀ ní ẹ̀bùn lọ́nà títayọ ní awọn apá ibìkan pàtó, èyí ha dá fífọ́nnu láre bí? Rárá, nitori pé fífọ́nnu ń fi ògo fún ènìyàn, nígbà tí ó sì jẹ́ pé ẹ̀bùn èyíkéyìí tí a ní wá lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Oun ni ó níláti gba ògo naa. Èéṣe tí a fi níláti gba ìyìn fún ohun kan tí a bí mọ́ wa? (1 Korinti 4:⁠7) Yàtọ̀ sí ìyẹn, bí a ti ní okun naa ni a tún ní àìlera. Jíjẹ́ aláìlábòsí ha béèrè pé kí a pe àfiyèsí sí awọn àṣìṣe ati àbùkù wa bí? Ó dàbí ẹni pé díẹ̀ lára awọn tí ń fọ́nnu ronú bẹ́ẹ̀. Nítòótọ́, ó lè jẹ́ pé Ọba Herodu Agrippa I jẹ́ ẹlẹ́bùn ọ̀rọ̀-sísọ. Síbẹ̀ àìjẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì rẹ̀ jálẹ̀ sí ikú ẹlẹ́gbin gidigidi. Ìṣẹ̀lẹ̀ rírínilára yẹn fi bí jíjẹ́ ẹni tí ó gbọ́n lójú ara-ẹni ṣe kó Ọlọrun nírìíra tó, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí lójú ọ̀pọ̀ awọn ènìyàn mìíràn.​—⁠Iṣe 12:​21-⁠23.

Ní gbogbogbòò, awọn tálẹ́ǹtì ati okun máa ń di mímọ̀ láìsí ìpolówó ara-ẹni láìnídìí. Nígbà tí awọn ẹlòmíràn bá mọ awọn ànímọ́ tabi àṣeyọrí ẹnìkan tí wọn sì gbóríyìn fún un, ó túbọ̀ máa ń buyì kún ẹni tí a fifún. Owe 27:2 sọ pẹlu ọgbọ́n pé: “Jẹ́ kí ẹlòmíràn kí ó yìn ọ́, kí ó máṣe ẹnu araàrẹ; àlejò, kí ó má sì ṣe ètè araàrẹ.”

A Ha Nílò Rẹ̀ fún Kíkẹ́sẹjárí Bí?

Awọn kan lérò pé ìpolówó ara-ẹni pẹlu ìdánilójú pọndandan lati lè ṣàṣeyọrí ninu ẹgbẹ́ àwùjọ abáradíje tí òde ìwòyí. Wọn ń ṣàníyàn pé bí wọn kò bá lahùn kí wọn sì polówó okun wọn, ojú á fò wọ́n dá, a kò sì ní mọrírì wọn. Àlàyé inú ìwé ìròyìn Vogue yii jẹ́ àpẹẹrẹ irú àníyàn tí wọ́n máa ń fihàn: “Níbi tí a ti kọ́ wa nígbà kan rí pé ìwọ̀ntúnwọ̀nsì jẹ́ ìwàrere, ní bayii a ń kẹ́kọ̀ọ́ pé pípa ẹnu mọ́ lè jẹ́ àbùkù ara.”

Lójú awọn wọnnì tí wọn fẹ́ lati gbé ìtẹ̀síwájú wọn karí ọ̀pá ìdiwọ̀n ayé yii, àníyàn naa lè jẹ́ ọ̀kan tí ó fìdímúlẹ̀. Ṣugbọn ipò-ìdúró ti Kristian yàtọ̀. Oun mọ̀ pé awọn onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ni Ọlọrun bìkítà fún tí ó sì yàn lati lo agbára wọn, kìí ṣe awọn onírera. Nitori naa, kò sí ìdí kankan fún Kristian lati yíjú sí ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ìgbéra-ẹni-lárugẹ. Lóòótọ́, ẹnìkan tí ó dá araarẹ̀ lójú jù lè gbayì fún ìgbà díẹ̀ nipa jíjẹ́ afipámúni tabi adọ́gbọ́ndarí ẹni. Síbẹ̀ láìpẹ́ a óò tú u fó yoo sì di ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀, tí a tilẹ̀ tẹ́ lógo pàápàá. Ó rí gẹ́gẹ́ bí Jesu Kristi ti wí pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé araarẹ̀ ga, ni a óò rẹ̀ sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ araarẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.”​—⁠Matteu 23:12; Owe 8:13; Luku 9:⁠48.

Àǹfààní Jíjẹ́ Oníwọ̀ntúnwọ̀nsì

Ralph Waldo Emerson kọ̀wé pé: “Ẹnikẹ́ni tí mo ba ṣáà ti bá pàdé ni ọ̀gá mi ní awọn ọ̀nà kan. Níti pé mo ń kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀.” Àlàyé rẹ̀ wà ní ìbámu pẹlu ìgbaniníyànjú onímìísí àtọ̀runwá ti aposteli Paulu pé kí awọn Kristian máṣe ‘ṣe ohunkóhun lati inú ẹ̀mí asọ̀ tabi lati inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣugbọn pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú kí wọn máa kà á sí pé awọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wọn lọ.’ (Filippi 2:⁠3, NW) Ojú-ìwòye oníwọ̀ntúnwọ̀nsì yii fi ẹnìkan sí àyè tí ó ti lè kẹ́kọ̀ọ́ lára awọn ẹlòmíràn.

Nitori naa kíyèsára kí agbára rẹ má baà di àìlera rẹ. Máṣe dín agbára ati ìkẹ́sẹjárí rẹ kù nipa fífọ́nnu. Fi ànímọ́ ẹ̀mí-ìrẹ̀lẹ̀ kún ìwàfunfun rẹ. Èyí ni ó ń gbé iyì-ẹni ga lójú awọn ẹlòmíràn. Ó ṣèrànwọ́ fún ẹnìkan lati gbádùn ipò-ìbátan tí ó sunwọ̀n síi pẹlu ènìyàn ẹlẹgbẹ rẹ̀ ó sì ń mú ìtẹ́wọ́gbà Jehofa Ọlọrun wá.​—⁠Mika 6:⁠8; 2 Korinti 10:⁠18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́