Ibojì Peteru—Ní Vatican Kẹ̀?
“ATI rí ibojì Aṣáájú àwọn Aposteli.” Rédíò Vatican ni ó gbé ìkéde ìjagunmólú ti Pope Pius XII sáfẹ́fẹ́. Ní òpin ọdún 1950 ni, wọ́n sì ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ọ̀wọ́ àwọn iṣẹ́ ìwakòtò dídíjú kan tí St. Peter’s Basilica darí rẹ̀ ni. Gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti sọ, àbájáde ìwádìí àwọn awalẹ̀pìtàn yìí jẹ́rìí síi pé Vatican gan-an ni a sin Peteru sí. Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo ènìyàn kọ́ ni ó gbà bẹ́ẹ̀.
Fún àwọn onísìn Katoliki, Ṣọ́ọ̀ṣì St. Peter ní Vatican ní ìjẹ́pàtàkì tí ó ṣàrà-ọ̀tọ̀. Ìwé amọ̀nà ti àwọn Katoliki wí pé: “Ète pàtàkì tí a ń tìtorí rẹ̀ rìnrìn-àjò mímọ́ lọ sí Romu ni láti lọ bá agbapò Peteru kí a sì rí ìbùkún rẹ̀ gbà, nítorí pé Peteru wá sí Romu a sì sin ín síbẹ̀.” Ṣùgbọ́n ṣe lóòótọ́ ni a sin Peteru sí Romu? Ibojì rẹ̀ ha wà ní Vatican bí? A ha ti rí àwọn egungun rẹ̀ bí?
Àdììtú Àwọn Awalẹ̀pìtàn
Àwọn iṣẹ́ ìwakòtò náà, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bíi 1940 tí ó sì gbà tó nǹkan bíi ọdún mẹ́wàá, ti jẹ́ kókó-ẹ̀kọ́ ọ̀pọ̀ àríyànjiyàn. Ki ni ohun tí àwọn awalẹ̀pìtàn tí popu yàn rí? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ibi ìsìnkú àwọn abọ̀rìṣà tí ó kún fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ibojì. Láàárín wọn, nísàlẹ̀ pẹpẹ popu ti òde-òní, ni wọ́n gbé rí ihò-àtọwọ́dá kan, ìyẹn ni, ihò-kótópó kan tí ó wà fún ohun ìrántí tí wọ́n ṣe láti gbé ère-ìrántí tàbí ère kan bọ inú rẹ̀, tí wọ́n gbé bọ inú ògiri tí a fi sìmẹ́ńtì pupa rẹ́ tí a sì fi ògiri méjì mọ odi sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ní paríparí rẹ̀, lọ́nà tí ó sì ṣòro gidigidi láti ṣàlàyé, wọ́n tún rí àwọn àkẹ̀kù òkú, èyí tí, wọ́n sọ pé, ó wá láti inú ọ̀kan lára àwọn ògiri méjì tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ náà.
Níhìn-ín ni ìtumọ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí mélòókan lára àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Katoliki ṣe sọ, àwárí náà jẹ́rìí sí ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ náà pé Peteru gbé Romu tí ó sì kú ikú ajẹ́rìíkú síbẹ̀ nígbà tí Nero ń ṣàkóso, bóyá nígbà inúnibíni ti 64 C.E. Wọ́n tilẹ̀ tún sọ pé àkẹ̀kù okú náà jẹ́ ohun ìrántí aposteli náà tí àkọlé kan sì lè fihàn pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn náà rí, gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ kan ṣe sọ, ó kà pé, “Peteru ń bẹ níhìn-ín.” Ó dàbí ẹni pé Pope Paul VI ń gbóríyìn fún ìméfò yìí nígbà tí ó kéde ní 1968 pé àwọn ti rí “àkẹ̀kù òkú Peteru Mímọ́, èyí tí ìfọkànsìn àti ìjúbà wa yẹ fún.”
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìjiyàn lórí ìjiyàn tún wa lòdìsí ìtumọ̀ yẹn. Onísìn Katoliki tí ó tún jẹ́ awalẹ̀pìtàn Antonio Ferrua, onísìn Jesuit tí ó kópa nínú iṣẹ́ ìwakòtò tí ó ṣẹlẹ̀ ní Vatican, ti jẹ́rìí síi lọ́pọ̀ ìgbà pé ‘wọn kò gba’ òun ‘láyè láti ṣe ìtẹ̀jáde’ gbogbo ohun tí òun mọ̀ lórí kókó-ẹ̀kọ́ náà, àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó hàn gbangba pé yóò tako ìjẹ́wọ́ náà pé a ti rí ohun ìrántí Peteru. Ní àfikún síi, ìwé amọ̀nà sí Romu, tí Kádínà Poupard ti Katoliki yẹ̀wò tí a sì tẹ̀jáde ní 1991, wí pé “àyẹ̀wò ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa àwọn egungun ènìyàn tí a rí lábẹ́ ìpìlẹ̀ Ògiri Pupa náà kò jọ ti aposteli Peteru rárá.” Lọ́nà tí ó yanilẹnu, nínú ìtẹ̀jáde tí ó tẹ̀lé e (lẹ́yìn náà ní 1991), gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà ti pòórá, àkòrí titun kan, tí a fún ní àkọlé náà “Ó Dánilójú: Peteru ń bẹ ni Sọ́ọ̀ṣì St. Peter,” ni wọ́n wá fikún un.
Títúmọ̀ Àwọn Àwárí Náà
Ó hàn gbangba pé àyè ṣì wà fún títúmọ̀ àwọn àwárí náà àti pé onírúurú ọ̀nà ní àwọn ènìyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lè túmọ̀ rẹ̀ sí. Nítòótọ́, òpìtàn Katoliki tí ó ní ọlá-àṣẹ jùlọ mọ̀ pé “ìṣòro ọ̀rọ̀-ìtàn náà pé Romu ni Peteru kú ikú ajẹ́rìíkú sí níti gidi, àti pé níbẹ̀ ni a sin ín sí, ni ó ṣe é jiyàn lé lórí.” Kí ni àwọn àwárí náà ṣípayá?
Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n tòròpinpin mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ Katoliki ti sọ, ohun ìrántí ihò-àtọwọ́dá jẹ́ “ohun ìrántí ìṣẹ́gun” tí Gaius kan báyìí, àlùfáà kan tí ó gbé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹta tọ́kasí. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Eusebius ti Kesaria, òpìtàn nípa ṣọ́ọ̀ṣì ní ọ̀rúndún kẹrin sọ, Gaius wí pé òun lè ‘fi ohun ìrántí ìṣẹ́gun Peteru hàn lórí Òkè Vatican.’ Àwọn alátìlẹyìn fún ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ jẹ́wọ́ pé níbẹ̀ ni a sin aposteli náà sí, nísàlẹ̀ ohun ìrántí náà tí a wá mọ̀ sí “ohun ìrántí ìṣẹ́gun Gaius.” Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn mìíràn túmọ̀ àbájáde àwọn iṣẹ́ ìwakòtò náà lọ́nà tí ó yàtọ̀ gédégédé, ní títọ́ka pé àwọn Kristian àkọ́kọ́ kò ka ìsìnkú àwọn òkú wọn sí tóbẹ́ẹ̀ àti pé kódà bí ó bá jẹ́ pé ibẹ̀ ni a ti pa Peteru, pípadà rí ara rẹ̀ yóò ti jẹ́ ohun tí kò rọrùn pé kí ó ṣẹlẹ̀. (Wo àpótí, ojú-ìwé 29.)
A rí àwọn wọnnì tí wọn kò gbà pé “ohun ìrántí ìṣẹ́gun Gaius” (bí ó bá jẹ́ ohun tí wọ́n rí nìyẹn) jẹ́ ibojì kan. Wọ́n gbà pé ó jẹ́ ohun ìrántí kan tí a kọ́ láti máa fi bọlá fún Peteru nígbà tí ọ̀rúndún kejì ń parí lọ àti pé nígbẹ̀yìn gbẹ́yín ó “wá di ohun tí a kà sí sàréè ohun ìrántí.” Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí Oscar Cullmann ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ti sọ, “àwọn iṣẹ́ ìwakòtò tí a ṣe ní Vatican kò fi ibojì Peteru hàn rárá.”
Kí ni ti àwọn egungun náà ṣe jẹ́? A ṣì lè sọ pé ibi tí àwọn egungun náà ti wá ṣì farasin. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, ibi ìsìnkú àwọn abọ̀rìṣà ni ó wà níbi tí a wá pè ní Òkè Vatican lónìí, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn òkú ènìyàn ni a sin sí agbègbè náà, tí a sì ti ṣàwárí ọ̀pọ̀lọpọ̀. Àkọlé tí a kò kọ tán náà (tí ó ṣeéṣe kí a ti kọ ní ọ̀rúndún kẹrin) tí àwọn kan sọ pé ó fi ibi tí wọ́n ti rí àwọn ohun ìrántí náà hàn gẹ́gẹ́ bí ibojì Peteru, ohun tí ó yẹ ẹ́ júlọ ni pé, èyí tí ń tọ́ka “sí ibi tí a rò pé àwọn egungun Peteru wà.” Ní àfikún síi, ọ̀pọ̀ lára àwọn onímọ̀ nípa àkọlé ní èrò náà pé àkọlé náà tilẹ̀ lè túmọ̀sí “Peteru kò sí níhìn-ín.”
‘Ẹ̀kọ́ Àtọwọ́dọ́wọ́ tí Kò Ṣeé Gbáralé’
Òpìtàn náà D. W. O’Connor sọ pé, “Àwọn orísun ìsọfúnni ìjímìjí tí wọ́n sì tún ṣeé gbáralé kò mẹ́nukan ibi tí Peteru kú ikú ajẹ́rìíkú sí, ṣùgbọ́n lára àwọn orísun ìsọfúnni tí ó dé kẹ́yìn tí wọn kò sì ṣeé gbáralé tóbẹ́ẹ̀ ìfohùnsọ̀kan gidi wà pé agbègbè Vatican ni.” Nítorí náà ìwákiri fún ibojì Peteru ní Vatican ni a gbékarí àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò ṣeé gbáralé. O’Connor tẹnumọ́ ọn pé: “Nígbà tí àwọn ohun ìrántí di ohun tí a fọwọ́ dan-in-dan-in mú, àwọn Kristian wá gbàgbọ́ nítòótọ́ pé [ohun ìrántí ìṣẹ́gun] Peteru níti gidi fi ibi tí sàréè rẹ̀ wà ní pàtó hàn.”
Àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ wọ̀nyí gbèrú ní sáà kan náà pẹ̀lú ìbọlá fún àwọn ohun ìrántí èyí tí kò bá ìwé mímọ́ mu. Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀rúndún kẹta sí ìkẹrin, onírúurú àwọn ibùdó ṣọ́ọ̀ṣì bẹ̀rẹ̀ síí lo àwọn ohun ìrántí, èyí tí ó jẹ́ òtítọ́ àti èyí tí ó jẹ́ èké—kìí sìí ṣe láìrí èrè kankan jẹ́ níti ọrọ̀-ajé—nínú ìjàkadì kí ọwọ́ lè tẹ wíwà ni ipò àjùlọ “nípa tẹ̀mí” àti láti lè gbé ọlá-àṣẹ tiwọn lárugẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn arìnrìn-àjò mímọ́ ń wọ́nà àtidé ibi tí wọ́n rò pé ó jẹ́ ibojì rẹ̀, bí a ti mú wọn gbàgbọ́ pé àkẹ̀kù okú Peteru ní agbára ìyanu. Ní òpin ọ̀rúndún kẹfà, àwọn onígbàgbọ́ máa ń ju ìrépé aṣọ tí a wọ̀n dáradára sórí “ibojì” náà. Àkọsílẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ kan wí pé, “Lọ́nà tí ó pẹtẹrí, bí ìgbàgbọ́ olùrawọ́-ẹ̀bẹ̀ náà ba fẹsẹ̀múlẹ̀, nígbà tí ó bá gba aṣọ rẹ̀ padà láti orí ibojì náà, yóò kún fún agbára àtọ̀runwá yóò sì tẹ̀wọ̀n ju bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀ lọ.” Èyí tọ́kasí bí ìgbàgbọ́ láìwádìí ṣe gbilẹ̀ tó nígbà yẹn.
Láti àwọn ọ̀rúndún yìí wá, àwọn ìtàn àròsọ bí irú èyí àti àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò ni ìpìlẹ̀ ti dákún ìdàgbàsókè iyì Vatican Basilica lọ́nà púpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn èrò tí ó yapa dìde. Ní ọ̀rúndún kejìlá àti kẹtàlá, àwọn onísìn Waldenses bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn àṣejù wọ̀nyí tí, wọ́n sì fi Bibeli, ṣàlàyé pé Peteru kò fẹsẹ̀ tẹ Romu rí. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, àwọn alágbàwí ìsìn Alátùn-únṣe Protẹstanti jiyàn lọ́nà kan náà. Ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, àwọn gbajú-gbajà ọlọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn ka ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ náà sí èyí tí kò lẹ́sẹ̀nílẹ̀, níti ọ̀rọ̀-ìtàn àti níti Ìwé Mímọ́. Ojú-ìwòye kan náà ni àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí wọ́n dáńgájíá ní, àwọn Katoliki àti àwọn mìíràn, títí di òní olónìí.
Peteru Ha Kú sí Romu Bí?
Ó dájú pé Peteru, ará Galili tí ó tún jẹ́ apẹja, kò fàyègba èrò èyíkéyìí nípa ipò olórí lórí àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristian ọ̀rúndún kìn-ín-ní. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pe araarẹ̀ ní “alàgbà ẹlẹgbẹ́ yín.” (1 Peteru 5:1-6, Revised Standard Version) Ẹ̀dá onírẹ̀lẹ̀ tí Peteru jẹ́ takora pẹ̀lú àwọn ohun-ọ̀ṣọ́ olówó gọbọi tí ó yí ibi tí wọ́n rò pé ó jẹ́ ibojì rẹ̀ ká, bí olùṣèbẹ̀wò èyíkéyìí tí ó bá bẹ Vatican Basilica wo ti lè rí i.
Láti lè gbé ìlọ́lájù rẹ̀ karí àwọn ètò ìsìn Kristian yòókù, Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki ti gbìyànjú láti fàṣẹ sí ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ‘tí ó dé kẹ́yìn tí kò sì ṣeé gbáralé’ tí ó sọ pé Peteru gbé Romu fún ìgbà díẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, lọ́nà tí ó yanilẹ́nu, àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ìgbàanì mìíràn kò jẹ́ gbà pé a sin ín sí Vatican, bíkòṣe ibòmíràn kan ní Romu. Síbẹ̀, èéṣe tí a kò fi rọ̀ mọ́ àwọn òtítọ́ tí a kọsílẹ̀ nínú Bibeli, orísun kanṣoṣo fún ìsọfúnni tààràtà nípa Peteru? Láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ó ṣe kedere pé, ní ìṣègbọràn sí àwọn ìtọ́sọ́nà tí ó rígbà láti ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti ìjọ Kristian ní Jerusalemu, Peteru ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ní apá ìlà-oòrùn ti ayé ìgbàanì, títíkan Babiloni.—Galatia 2:1-9; 1 Peteru 5:13; fiwé Iṣe 8:14.
Nígbà tí ó ń kọ̀wé sí àwọn Kristian ní Romu, ní nǹkan bíi 56 C.E., aposteli Paulu kí àwọn mẹ́ḿbà ìjọ náà tí wọ́n tó nǹkan bíi 30 láìdárúkọ Peteru rárá. (Romu 1:1, 7; 16:3-23) Lẹ́yìn náà, láàárín 60 sí 65 C.E., Paulu kọ lẹ́tà mẹ́fà láti Romu, ṣùgbọ́n kò dárúkọ Peteru—ẹ̀rí lílágbára tí ó yí ipò náà ká pé Peteru kò sí níbẹ̀.a (Fiwé 2 Timoteu 1:15-17; 4:11.) Ìgbòkègbodò Paulu ní Romu ni a ṣàpèjúwe ní ìparí ìwé Iṣe, ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kan síi, a kò tọ́kasí Peteru. (Iṣe 28:16, 30, 31) Ní àbárèbábọ̀, ìṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí inú Bibeli pẹ̀lú òtítọ́ inú, tí kò ní àwọn èrò tí ẹnìkan ti gbìn sínú tẹ́lẹ̀, yóò wulẹ̀ yọrísí ìparí èrò náà pé Peteru kò wàásù ní Romu.b
“Ipò olórí” tí popu wà ni a gbékarí àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò ṣeé gbáralé àti lílọ́ ìfisílò àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ lọ́rùn. Jesu ni ìpìlẹ̀ ìsìn Kristian, kìí ṣe Peteru. ‘Kristi ni orí ìjọ,’ ní Paulu wí. (Efesu 2:20-22; 5:23, NW) Jesu Kristi ni ẹni náà tí Jehofa rán láti bùkún àti láti gba gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ là.—Johannu 3:16; Iṣe 4:12; Romu 15:29; tún wo 1 Peteru 2:4-8.
Nígbà náà, gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n ń rìnrìn-àjò láti lọ wo ohun tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ ibojì Peteru láti lè pàdé ‘olùgbapò rẹ̀’ dojúkọ ìṣòro náà yálà láti gba ‘àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò ṣeé gbáralé’ tàbí láti gba Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ó ṣeé gbáralé gbọ́. Níwọ̀n bí àwọn Kristian ti ń fẹ́ kí Ọlọrun tẹ́wọ́gba ìjọsìn wọ́n, wọ́n ‘ń fi tọkàntara wo Aláṣepé ìgbàgbọ́ wọn, Jesu,’ àti àpẹẹrẹ pípé tí ó fi lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀lé.—Heberu 12:2, NW; 1 Peteru 2:21.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní nǹkan bíi ọdún 60 sí 61 C.E., Paulu kọ lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ara Efesu, Filippi, Kolosse, Filemoni, àti Heberu; nǹkan bíi 65 C.E., ni ó kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí Timoteu.
b Ìbéèrè náà “Peteru Ha Gbé Romu Rí Bí?” ni a gbéyẹ̀wò nínú Ilé-Ìsọ́nà, November 1, 1972, ojú-ìwé 669 sí 671 [Gẹ̀ẹ́sì].
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
“Iṣẹ́ ìwakòtò náà ti fihàn pé kò sí ẹ̀rí kankan tí ó dájú pé ibojì kan wà lábẹ́ Ihò-Àtowọ́dá náà; bẹ́ẹ̀ sì ni kò lè sí ìdánilójú kankan pé a rí ara Peteru Mímọ́ gbà padà lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ṣekú pa á kí ẹgbẹ́-àwùjọ àwọn Kristian baà lè sin ín. Bí a bá tọpasẹ̀ bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí gan-an, àti bí òfin ṣe gbé e kalẹ̀ ara ẹnìkan tí ó jẹ́ àjòjì (peregrinus), arúfin kan lásán-làsàn, ni a óò ti gbéjù sínú odò Tiber. . . . Jú bẹ́ẹ̀ lọ, kò lè sí ọkàn-ìfẹ́ kan náà tí wọ́n ní fún títọ́jú ara òkú fún ohun ìrántí ní ìgbà ìjímìjí yìí tó bí ó ṣe wà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, nígbà tí ìgbàgbọ́ nínú òpin ayé tí ń rọ̀dẹ̀dẹ̀ ti ń pòórá tí ẹgbẹ́ àwọn ajẹ́rìíkú sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí yọjú. Nítorí náà, ṣíṣeéṣe náà pé a kò rí ara Peteru Mímọ́ gbà padà níti tòótọ́ láti sìnkú rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ pọ́ńbélé.”—The Shrine of St. Peter and the Vatican Excavations, láti ọwọ́ Jocelyn Toynbee àti John Ward Perkins.