ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 1/1 ojú ìwé 3-4
  • Pa Ìwàtítọ́ Mọ́ Kí O Sì Wàláàyè!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Pa Ìwàtítọ́ Mọ́ Kí O Sì Wàláàyè!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Hùwà Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Àwa Yóò Máa Rìn Nínú Ìwà Títọ́ wa!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Jóòbù Gbé Orúkọ Jèhófà Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Mi Ò Ní Fi Ìwà Títọ́ Mi Sílẹ̀!”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 1/1 ojú ìwé 3-4

Pa Ìwàtítọ́ Mọ́ Kí O Sì Wàláàyè!

“BÚ ỌLỌRUN, kí o sì kú”! Aya Jobu tí ó ju òkò àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lù ú, ni àwòrán rẹ̀ wà lára èpo ẹ̀yìn ìwé ìròyìn wa. Ìyẹn jẹ́ ní nǹkan bíi 3,600 ọdún sẹ́yìn. Síbẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a fi gbéjàko olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun yìí ń tẹnumọ́ ọ̀ràn àríyànjiyàn náà tí ń dojúkọ aráyé títí di òní olónìí. Jobu olùṣòtítọ́ ti jìyà ìpàdánù tí ó gadabú—àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ilé rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́wẹ̀wàá. Nísinsìnyí òkùnrùn búburú jáì kan ń dá a lóró, ó ń dán an wò títí dé ibi tí ìfaradà rẹ̀ pin sí. Kí ni ó fà á? Olórí ọ̀tá Ọlọrun àti ènìyàn, Satani Eṣu, ń ṣiṣẹ́ lórí ìpèníjà kan pé ènìyàn kò lè pa ìwàtítọ́ rẹ̀ sí Ọlọrun mọ́ lábẹ́ ìdánwò lílekoko.—Jobu 1:11, 12; 2:4, 5, 9, 10.

Lónìí, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọjọ́ Jobu, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa,” Satani Eṣu. (1 Johannu 5:19, NW) Nítòótọ́, ìyẹn túbọ̀ jẹ́ òtítọ́ lónìí, nítorí pé nísinsìnyí “ẹni tí a ń pè ní Èṣù ati Satani, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà,” ni a ti fi sọ̀kò láti ọ̀run sórí ilẹ̀-ayé yìí. (Ìṣípayá 12:9, NW) Èyí ṣàlàyé ìdí rẹ̀ tí ègbé ńláǹlà fi ń bá aráyé jà ní àkókò tiwa. Ogun àgbáyé kìn-ín-ní, tí ó bẹ́sílẹ̀ ní 1914, sàmì sí “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà” tí ó ti ń bá a lọ jìnnà wọnú ọ̀rúndún ogún yìí.—Matteu 24:7, 8, NW.

Nínú ayé oníkà, oníwà ìbàjẹ́ yìí, o ha ti ronú rí pé o ti dé ibi tí ìfaradà rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pin sí bí? O ha ti ṣe kàyéfì rí pé, ‘Ìgbésí-ayé ha ní ète kankan bí?’ Jobu ti lè ronú lọ́nà yẹn, ṣùgbọ́n kò fi ìgbà kan sọ ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun nù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe àwọn àṣìṣe. Ó sọ ìpinnu rẹ̀ jáde pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Títí èmi ó fi kú èmi kì yóò ṣí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi”! Ó ní ìgbọ́kànlé pé Ọlọrun yóò ‘mọ ìwàtítọ́ òun.’—Jobu 27:5; 31:6, NW.

Jesu Kristi, Ọmọkùnrin ti Ọlọrun, ní ìdí fún fífarada àdánwò nígbà tí ó wà níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé pẹ̀lú. Satani gbéjàko Jesu ní onírúurú ọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí níbi òkè-ńlá tí ó ti dán an wò, ó lo àwọn ohun tí Jesu ṣaláìní nípa ti ara ó sì dán bí Ó ti ní ìgbọ́kànlé nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tó wò. (Matteu 4:1-11) Ó gbéjàko Jesu léraléra nípa mímú kí àwọn akọ̀wé àti Farisi apẹ̀yìndà àti àwọn tí wọ́n tànjẹ ṣe inúnibíni sí i, kí wọ́n sì fi ẹ̀sùn sísọ̀rọ̀-òdì kàn án, kí wọ́n sì dìtẹ̀ láti pa á. (Luku 5:21; Johannu 5:16-18; 10:36-39; 11:57) Ohun tí wọ́n ṣe sí Jesu burú ju ohun tí àwọn olùtùnú èké mẹ́ta náà ṣe sí Jobu lọ.—Jobu 16:2; 19:1, 2.

Bí Jesu ti ń súnmọ́ òtéńté ìdánwò rẹ̀, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nínú ọgbà Getsemane pé: “Mo ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi àní títí dé ikú.” Lẹ́yìn náà, “ó da ojú rẹ̀ bolẹ̀, ó ń gbàdúrà ó sì ń wí pé: ‘Baba mi, bí ó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ife yii ré mi kọjá lọ. Síbẹ̀, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí emi ti fẹ́, bíkòṣe gẹ́gẹ́ bí iwọ ti fẹ́.’” Níkẹyìn, ní ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ inú Orin Dafidi 22:1, Jesu ké jáde lórí òpó igi oró pé: “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, èéṣe tí iwọ fi ṣá mi tì?” Ṣùgbọ́n lékè gbogbo rẹ̀ Ọlọrun kò kọ Jesu sílẹ̀ nítorí pé Jesu pa ìwàtítọ́ pípé pérépéré mọ́ sí I, ní fífi àwòkọ́ṣe lélẹ̀ fún gbogbo àwọn Kristian tòótọ́ láti tẹ̀lé. Jehofa san èrè fún ìpàwàtítọ́ mọ́ Jesu nípa jíjí i dìde àti gbígbé e ga sókè nínú àwọn ọ̀run gíga jùlọ. (Matteu 26:38, 39, NW; 27:46, NW; Iṣe 2:32-36; 5:30; 1 Peteru 2:21) Ọlọrun yóò san èrè fún gbogbo àwọn mìíràn tí wọ́n bá pa ìwàtítọ́ wọn sí i mọ́ ní irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀.

Kì í ṣe pé ìwàtítọ́ Jesu pèsè ìdáhùn pátápátá nípa ìpèníjà Satani nìkan ni ṣùgbọ́n ẹbọ ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ pèsè ìràpadà, lórí ìpìlẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n bá pa ìwàtítọ́ mọ́ ti lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. (Matteu 20:28) Lákọ̀ọ́kọ́, Jesu ṣe àkójọ àwọn “agbo kékeré” ẹni-àmì-òróró tí wọ́n di ajùmọ̀jogún pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba ọ̀run. (Luku 12:32, NW) Lẹ́yìn èyí, “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan” ni a kójọpọ̀ láti la “ìpọ́njú ńlá naa” já, kí wọ́n sì ti inú rẹ̀ jáde wá láti jogún ìyè ayérayé nínú ilẹ̀ àkóso ti Ìjọba Ọlọrun lórí ilẹ̀-ayé.—Ìṣípayá 7:9, 14-17, NW.

Jobu olùpa ìwàtítọ́ mọ́ yóò wà lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ òkú tí a óò jí dìde nígbà náà láti di apákan ẹgbẹ́-àwùjọ “ilẹ̀-ayé titun” alálàáfíà yẹn. (2 Peteru 3:13, NW; Johannu 5:28, 29) Gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn lára èpo ẹ̀yìn ìwé ìròyìn wa, ìwàtítọ́ ní èrè tirẹ̀ ní ọjọ́ Jobu nígbà tí Jehofa “bùkún ìgbẹ̀yìn Jobu ju ìṣáájú rẹ̀ lọ.” Ó ti jèrè okun tẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tí “kò fi ète rẹ̀ ṣẹ̀.” Ọlọrun mú kí ìwàláàyè rẹ̀ gùn síi ní fífi 140 ọdún kún un. Níti ohun-ìní ti ara, ó fún Jobu ní ìlọ́po méjì gbogbo ohun tí ó ti ní tẹ́lẹ̀rí, Jobu sì “ní ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta,” àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ni a sì kà sí àwọn tí ó lẹ́wà jùlọ ní gbogbo ilẹ̀ náà. (Jobu 2:10; 42:12-17) Ṣùgbọ́n ìtọ́wò lásán ni gbogbo aásìkí wọ̀nyí jẹ́ ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ìbùkún tí àwọn olùpa ìwàtítọ́ mọ́ yóò gbádùn nínú Paradise “ilẹ̀-ayé titun” náà. Ìwọ pẹ̀lú lè nípìn-ín nínú ìdùnnú yẹn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ojú-ewé tí ó tẹ̀lé e yóò ti ṣàlàyé!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Jesu fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùpa ìwàtítọ́ mọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́