Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Puerto Rico
NÍ ÀÁRÍN Òkun Caribbean àti Agbami Òkun Atlantic ni Puerto Rico, erékùṣù títunilára ti ilẹ̀ olóoru náà wà. Christopher Columbus sọ ní ọdún 1493 pé àwọn ará Spania ni wọ́n ni ín, ó sì sọ ibẹ̀ ní San Juan Bautista ní ìrántí Johannu Oníbatisí. Láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni a ti ń pe ìlú tí ó tóbi jùlọ níbẹ̀ ní Puerto Rico, tàbí “Èbúté Ọrọ̀.” Bí àkókò ti ń lọ, orúkọ yìí wá di èyí tí a ń lò fún gbogbo erékùṣù náà, a sì ń pe ìlú-ńlá náà ní San Juan.
Puerto Rico ti jásí èbúté ọrọ̀ ní onírúurú ọ̀nà. Wúrà rẹpẹtẹ ni wọ́n fi ọkọ̀ kó lọ láti ibí yìí ní àwọn ọdún tí ilẹ̀ Spania ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso. Ní báyìí, erékùṣù náà ń kó ìrèké, kọfí, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà, àti àwọn èso ọsàn ní ọlọ́kan-ò-jọ̀kan ráńṣẹ́ sí ilẹ̀ òkèèrè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ilé-iṣẹ́ tí ń lo ẹ̀rọ àti àwọn tí ń ṣiṣẹ́sin àwọn ará ìlú ni wọ́n gbé ètò-ọrọ̀-ajé rẹ̀ ró. Bí ó ti wù kí ó rí, Puerto Rico ti jásí èbúté ọrọ̀ ní ọ̀nà kan tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì jù.
A bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìnrere nípa Ìjọba Ọlọrun ní ibí yìí ní àwọn ọdún 1930. Lónìí, àwọn akéde ìhìnrere tí wọ́n ju 25,000 lọ ni wọ́n wà ní Puerto Rico. Ní 1993 àwùjọ òṣìṣẹ́ tí ó wà ní ẹ̀ka Watch Tower Society yìí ti bísíi láti 23 sí iye tí ó ju 100 lọ. Ìbísí yìí pọndandan kí ẹ̀ka náà baà lè bójútó títúmọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli sí èdè Spanish, kí wọ́n sì mú kí irúfẹ́ àwọn ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún nǹkan bí 350,000,000 ènìyàn tí ń sọ èdè Spanish lágbàáyé.
Pápá Titun
Ọ́fíìsì ẹ̀ka náà tún ròyìn pé: “Pápá titun ti ṣí sílẹ̀ ní Puerto Rico nítorí pé a ti ń sapá láti mú ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà tọ àwọn adití lọ. Arábìnrin kan sọ ìrírí tí ó tẹ̀lé e yìí: ‘Mo ń ṣiṣẹ́ láàárín àwọn adití mo sì ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ obìnrin kan tí àwọn ọmọ kékeré méjì wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí ó mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí ni mí, ó kọ̀ mí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nítorí pé ọkọ rẹ̀, tí òun pẹ̀lú jẹ́ adití, kò fẹ́ràn àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
“‘Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà obìnrin kan náà yìí bẹ ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tí ó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí wò. Ó darapọ̀ mọ́ wọn láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ó sì gbádùn rẹ̀ gidigidi. Mo padà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ obìnrin náà, ó sì tún un sọ pé ọkọ òun kò fẹ́ràn àwọn Ẹlẹ́rìí. Bí ó ti wù kí ó rí, ó fẹ́ láti lóye Bibeli, ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ sì ti sú u nítorí pé kò sí ohun tí wọ́n ń kọ́ wọn. A bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́, a sì ń lo ìwé-àṣàrò-kúkúrú. Ní ọjọ́ kan ó sọ pé kí n padà wá ní ọjọ́ Saturday nítorí pé ọkọ òun yóò wà níbẹ̀. Mo bi í pé: “Ṣùgbọ́n kò fẹ́ràn wa, àbí?” Ó fèsì pé: “Ó fẹ́ láti mọ ohun tí gbogbo èyí dá lé lórí.”
“‘Ní ọjọ́ kejì àwọn méjèèjì ń kan ìlẹ̀kùn mi! Níwọ̀n bí ọkọ rẹ̀ ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè, mo késí wọn lọ sí ìpàdé fún àwọn adití. Ọkùnrin náà ti débẹ̀ ṣáájú mi kò sì tí ì pa ìpàdé kan jẹ láti ìgbà náà wá. Ó ń wàásù fún àwọn adití mìíràn, ó ti lọ sí àpéjọ kan, ó sì ń fojúsọ́nà fún ṣíṣe ìrìbọmi.’”
Ìròyìn ẹ̀ka náà ń bá a lọ pé: “Ní àpéjọpọ̀ agbègbè wa ní ọdún yìí, gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní a lo èdè ìfaraṣàpèjúwe fún, ọ̀pọ̀ àwọn adití pésẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú ìdílé wọn. Ìṣẹ́jú tí ń ru ìmọ̀lára sókè dé nígbà ọ̀rọ̀-àsọyé tí ó kẹ́yìn nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ náà mẹ́nukan iṣẹ́ tí a ti ṣe láàárín àwọn adití tí ó sì sọ pé nǹkan bíi 70 ni ó wá. Àtẹ́wọ́ ńlá ró, ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí olùbánisọ̀rọ̀ náà ti ṣàkíyèsí, àwọn adití náà kò gbọ́. Nítorí náà nígbà tí ó sọ fún àwọn adití láti wo àwùjọ, olùbánisọ̀rọ̀ náà tún ìbéèrè náà béèrè pé, ‘Ẹ ha láyọ̀ pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin yín tí wọ́n jẹ́ adití wà pẹ̀lú yín níhìn-ín bí?’ ó sì sọ fún àwùjọ láti pàtẹ́wọ́ nípa jíju ọwọ́ wọ́n méjèèjì. Ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu láti rí 11,000 àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n ń pàtẹ́wọ́ nípa jíju ọwọ́ wọn. Ayọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí wọ́n jẹ́ adití kún àkúnwọ́sílẹ̀ wọ́n sì nímọ̀lára pé àwọn jẹ́ apákan ẹgbẹ́-àwọn-ará ńlá kárí-ayé. Omijé ayọ̀ dà pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ lójú ọ̀pọ̀ ènìyàn.”
Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń kópa nínú iṣẹ́ ìkórè náà ní Puerto Rico, kò sí iyèméjì pé yóò máa báa nìṣó láti jẹ́ èbúté ọrọ̀. Àwọn “àgùtàn” Ọlọrun, tí ó pè ní “àwọn ohun fífanilọ́kànmọ́ra láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,” yóò máa báa nìṣó láti wọlé wá kí á baà lè fi ògo kún ilé Jehofa.—Johannu 10:16, NW; Haggai 2:7, NW.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ NÍPA ORÍLẸ̀-ÈDÈ
Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1994
GÓŃGÓ IYE ÀWỌN TÍ Ń JẸ́RÌÍ: 25,428
ÌṢIRÒ-ÌFIWÉRA: Ẹlẹ́rìí 1 sí 139
ÀWỌN TÍ Ó PÉSẸ̀ SÍBI ÌṢE-ÌRÁNTÍ: 60,252
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN AKÉDE TÍ WỌ́N JẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ: 2,329
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BIBELI: 19,012
IYE TÍ Ó ṢÈRÌBỌMI: 919
IYE ÀWỌN ÌJỌ: 312
Ọ́FÍÌSÌ Ẹ̀KA: GUAYNABO