ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 1/15 ojú ìwé 21-23
  • O Ha Ti Fún Ẹnikẹ́ni Ní Ìṣírí Láìpẹ́ Yìí bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Ha Ti Fún Ẹnikẹ́ni Ní Ìṣírí Láìpẹ́ Yìí bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ó Wémọ́ Ìṣírí?
  • Wọ́n Fúnni Ní Ìṣírí
  • Lo Àǹfààní Láti Fúnni Ní Ìṣírí
  • Ta Ni Ó Nílò Ìṣírí?
  • Jẹ́ Ẹni Tí Ń Fúnni Ní Ìṣírí
  • ‘Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú Lẹ́nì Kìíní-Kejì Lójoojúmọ́’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Máa Fúnni Níṣìírí Bíi Ti Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ìsinsìnyí Ló Yẹ Ká Máa Fún Ara Wa Níṣìírí Ju ti Ìgbàkigbà Rí Lọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ìtùnú àti Ìṣírí—Àwọn Ohun Iyebíye Alápá Púpọ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 1/15 ojú ìwé 21-23

O Ha Ti Fún Ẹnikẹ́ni Ní Ìṣírí Láìpẹ́ Yìí bí?

ẸNI ọdún 17 péré ni Elena nígbà tí àwọn dókítà rí i pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀yà ara tí ń pèsè ẹyin-ọmọ. Ìyá rẹ̀, Mari, níláti kojú làásìgbò ti rírí Elena nínú ìrora gógó.

Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, a gbé Elena lọ sí ilé-ìwòsàn kan ní Madrid, Spania, 1,900 kìlómítà sí ilé rẹ̀ ní Erékùṣù Canary. Ní Madrid àwùjọ àwọn dókítà múratán láti ṣe iṣẹ́-abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀. (Iṣe 15:28, 29) Ṣùgbọ́n ní kété lẹ́yìn ti iṣẹ́-abẹ náà bẹ̀rẹ̀, ó hàn gbangba pé ipò Elena yóò yọrí sí ikú. Àrùn jẹjẹrẹ náà ti tàn ká gbogbo ara rẹ̀, àwọn oníṣẹ́-abẹ náà kò sì lè yanjú ìṣòro náà. Elena kú lẹ́yìn ọjọ́ kẹjọ tí ó dé sí Madrid.

Mari kò níláti dánìkan dojúkọ ìrírí agbonijìgì tí ń banilẹ́rù yẹn. Àwọn Kristian alàgbà méjì tí wọ́n san owó ìrìn-àjò wọn fúnra wọn, bá òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà lọ sí Madrid wọ́n sì wà níbẹ̀ títí tí Elena fi kú. Mari ṣàlàyé pé: “Wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti kojú ìmọ̀lára òfò tí mo ní nínú lọ́hùn-ún. Èmi kò lè gbàgbé ìṣírí tí wọ́n fún mi láé. Ìtìlẹyìn nípa tẹ̀mí àti ìrànwọ́ gbígbéṣẹ́ tí wọ́n fún mi kò ṣeé díyelé. Wọ́n jẹ́ ‘ibi ìlùmọ́’ tòótọ́ ‘kúrò lójú ẹ̀fúùfù.’”—Isaiah 32:1, 2.

Ó ń mú inú Jehofa dùn pé àwọn olùṣọ́ àgùtàn onífẹ̀ẹ́ bí irú àwọn wọ̀nyí ń bójútó àwọn àgùtàn rẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. (Owe 19:17; 1 Peteru 5:2-4) Bí ó ti wù kí ó rí, fífúnni ní ìṣírí kì í ṣe àǹfààní àwọn alàgbà nìkan. Gbogbo Kristian ń pàdé pọ̀ láti gba ìtọ́ni tẹ̀mí àti láti ‘fún ara wọn ní ìṣírí lẹ́nìkínní kejì.’ (Heberu 10:24, 25, NW) Ìṣírí jẹ́ apákan tí a pilẹ̀ dámọ́ ètò-ẹgbẹ́ Kristian.

Kí Ni Ó Wémọ́ Ìṣírí?

Gan-an gẹ́gẹ́ bí òdòdó kan tí ó rẹwà ṣe ń rọ nígbà tí a bá fi omi dù ú, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnìkọ̀ọ̀kan—nínú ìdílé àti nínú ìjọ—ṣe lè soríkọ́ nítorí àìrí ìṣírí gbà. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ìṣírí tí ó bọ́ sákòókò lè fún àwọn wọnnì tí wọ́n bá dojúkọ ìdánwò lókun, ó lè mú kí àwọn tí wọ́n soríkọ́ tújúká, kí ó sì fún àwọn wọnnì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́sin Ọlọrun pẹ̀lú ìṣòtítọ́ ní agbára.

Ọrọ Griki náà tí a túmọ̀ sí “ìṣírí” ní nínú èrò nípa ìrẹ̀lẹ́kún, ọ̀rọ̀ ìyànjú, àti ọ̀rọ̀ ìtùnú. Nítorí náà, ìṣírí kò pin sórí sísọ fún ẹnì kan pé ó ń ṣe dáradára. Ó tún lé wémọ́ pípèsè ìtìlẹyìn àti ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí.

Níti gidi, lọ́nà olówuuru ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀ sí “ìṣírí” túmọ̀ sí “kíkésí ẹnì kan wá síwájú ẹni.” Rírìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí ń mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti fún ọ̀kan lára wọn ní ìtìlẹyìn ojú-ẹsẹ̀ bí ó bá fẹ́ káàárẹ̀ tàbí kọsẹ̀. (Oniwasu 4:9, 10) Ó dùnmọ́ni pé, àwọn ènìyàn Jehofa “ń ṣiṣẹ́sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” (Sefaniah 3:9, NW) Aposteli Paulu sì pe Kristian kan ní “ojúlówó alájọru àjàgà.” (Filippi 4:3, NW) Ṣíṣiṣẹ́ papọ̀ lábẹ́ àjàgà kan náà nípa ṣíṣiṣẹ́sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ń mú ẹrù náà fúyẹ́, ní pàtàkì fún àwọn wọnnì tí wọn kò lágbára nípa tẹ̀mí.—Fiwé Matteu 11:29.

Wọ́n Fúnni Ní Ìṣírí

Níwọ̀n bí ìṣírí ti ṣe pàtàkì gidigidi, ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn Ìwé Mímọ́ díẹ̀ yẹ̀wò nípa rẹ̀. Nígbà tí Mose wòlíì Ọlọrun ń súnmọ́ òpin ìwàláàyè rẹ̀, Jehofa yan Joṣua sípò láti jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Israeli. Èyí kì í ṣe iṣẹ́ àyànfúnni kan tí ó rọrùn, gẹ́gẹ́ bí Mose fúnra rẹ̀ ti mọ̀ dáradára. (Numeri 11:14, 15) Fún ìdí èyí, Jehofa sọ fún Mose láti “fi àṣẹ fún Joṣua, kí ó sì gbà á níyànjú, kí ó sì mú un ní ọkàn le.”—Deuteronomi 3:28.

Lákòókò àwọn onídàájọ́ ní Israeli, ọmọbìnrin Jefta fi tìfẹ́-inú tìfẹ́-inú tẹ̀lé ẹ̀jẹ́ tí bàbá rẹ̀ jẹ́ nípa pípa ṣíṣeéṣe náà láti ní ìdílé kan tì kí ó baà lè ṣiṣẹ́sìn ní ibùjọsìn Jehofa. A ha gbójúfo ìrúbọ rẹ̀ dá bí? Rárá, nítorí Onidajọ 11:40 sọ pé: “Kí àwọn ọmọbìnrin Israeli máa lọ ní ọdọọdún láti pohùnréré ọmọbìnrin Jefta ará Gileadi ní ọjọ́ mẹ́rin ní ọdún.” Irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀ ti gbọ́dọ̀ máa fún ọmọbìnrin Jefta olùfi-ara-ẹni-rúbọ ní ìṣírí.

Fífúnni ní ìṣírí ń béèrè ìgboyà nígbà mìíràn. Nígbà ìrìn-àjò míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ ti aposteli Paulu, ó bá àtakò rírorò pàdé ní àwọn ìlú-ńlá mélòókan ní Asia Kékeré. Wọ́n lé e kúrò ní Antioku, díẹ̀ ni ó kù kí wọ́n pa á ní Ikoniomu, wọ́n sọ ọ́ ní òkúta wọ́n sì fi í sílẹ̀ pẹ̀lú èrò pé ó ti kú ní Listra. Ṣùgbọ́n, ní kété lẹ́yìn náà, Paulu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ padà sí àwọn ìlú-ńlá wọ̀nyí, “wọ́n ń fún ọkàn awọn ọmọ-ẹ̀yìn lókun, wọ́n ń fún wọn ní ìṣírí lati dúró ninu ìgbàgbọ́ wọ́n sì ń wí pé: ‘A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọrun.’” (Iṣe 14:21, 22, NW) Paulu ṣetán láti fi ìwàláàyè rẹ̀ wewu láti fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn titun wọ̀nyí ní ìṣírí.

Síbẹ̀, kì í ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn titun nìkan ní àwọn Kristian tí wọ́n nílò ìṣírí. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà Paulu ní ìrírí ìrìn-àjò oníṣòro lójú ọ̀nà sí Romu, níbi tí yóò ti jẹ́jọ́. Bí ó ṣe ń súnmọ́ ibi tí ó ń lọ, ó ṣeé ṣe kí ó ti ní ìrẹ̀wẹ̀sì lọ́nà kan ṣáá. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé ibi kan tí ó jẹ́ kìlómítà 74 sí ìhà gúúsù ìlà-oòrùn Romu, a mú un lọ́kàn le. Èéṣe? Nítorí pé àwọn arákùnrin láti Romu ti wá láti pàdé rẹ̀ ní Ibi Ọjà Apiọsi àti Ilé-Èrò Mẹ́ta. “Bí Paulu sì ti tajúkán rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun ó sì mọ́kànle.” (Iṣe 28:15, NW) Ní àwọn àkókò mìíràn bí èyí irú, wíwà níbẹ̀ wa nìkan lè fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ní ìṣírí gidigidi.

Lo Àǹfààní Láti Fúnni Ní Ìṣírí

Níti gidi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní ni ó wà láti fúnni ní ìṣírí. Ọ̀rọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ tí ó dára tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan gbé kalẹ̀ ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun ha ru ọkàn-àyà rẹ sókè bí? Ó ha dùn mọ́ ọ pé àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí wà nínú ìjọ bí? Ìfaradà àwọn àgbàlagbà ha ń mú orí rẹ wú bí? Ìwọ ha kansáárá sí ọ̀nà tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà gbà lo Bibeli nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé bí? Nígbà náà gbóríyìn fún wọn, kí o sì sọ ohun kan tí ó lè fún wọn ní ìṣírí.

Ìṣírí ń kó ipa tí ó ṣekókó nínú ìdílé àti bákan náà nínú ìjọ. Ó lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “ninu ìbáwí ati ìlànà èrò-orí Jehofa.” (Efesu 6:4, NW) Sísọ fún ọmọdé kan pé ó káre, àti ṣíṣàlàyé ìdí rẹ̀ fún un, lè fún un ní ìṣírí gidigidi! Lákòókò àwọn ọdún ọ̀dọ́langba, nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ bá dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò àti ìkìmọ́lẹ̀, ìṣírí lóòrèkóòrè ṣekókó.

Àírí ìṣírí gba lákòókò ọmọdé lè léwu gidigidi. Lónìí Michael, Kristian alàgbà kan, jẹ ẹni tí ó yámọ́ni, ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Bàbá mi kò sọ pé mo káre rí. Nítorí náà mo dàgbà di ẹni tí ó pàdánù iyì-ara-ẹni. . . . Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo jẹ́ ẹni 50 ọdún nísinsìnyí, mo ṣì mọrírì ìdánilójú tí àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fún mi pé mo ń ṣe iṣẹ́ rere gẹ́gẹ́ bí alàgbà kan. . . . Ìrírí tèmi fúnra mi ti kọ́ mi bí ó ti ṣepàtàkì tó láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ìṣírí, mo sì máa ń lo ara mi dé góńgó láti fi í fúnni.”

Ta Ni Ó Nílò Ìṣírí?

Àwọn Kristian alàgbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ àṣekára yẹ ní fífún ní ìṣírí. Paulu kọ̀wé pé: “Awa fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin ará, pé kí ẹ ní ẹ̀mí ìkanisí fún awọn wọnnì tí ń ṣiṣẹ́ kára láàárín yín tí wọ́n sì ń ṣe àbójútó lórí yín ninu Oluwa tí wọ́n sì ń ṣí yín létí; kí ẹ sì máa fún wọn ní ìkàsí tí ó ju àrà-ọ̀tọ̀ lọ ninu ìfẹ́ nitori iṣẹ́ wọn.” (1 Tessalonika 5:12, 13, NW) Ó rọrùn láti ṣàìka iṣẹ́ àṣekára tí àwọn alàgbà ń ṣe sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ ìmọrírì àtọkànwá àti ìṣírí lè mú kí ẹrù náà dàbí èyí tí ó fúyẹ́.

Àwọn wọnnì tí wọ́n ń bẹ láàárín wa tí wọ́n ń farada àwọn àyíká ipò tí ó nira nílò ìṣírí pẹ̀lú. Bibeli gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ́kún fún awọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún awọn aláìlera.” (1 Tessalonika 5:14, NW) Àwọn òbí anìkàntọ́mọ, àwọn opó, àwọn ọ̀dọ́langba, àwọn àgbàlagbà, àti àwọn aláàbọ̀ ara wà lára àwọn wọnnì tí wọ́n lè nímọ̀lára ìsoríkọ́ tàbí kí wọ́n ní àìlera tẹ̀mí láti ìgbà-dé-ìgbà.

María jẹ́ obìnrin Kristian kan tí ó ṣàdédé rí i pé ọkọ òun ti já òun jù sílẹ̀. Ó wí pé: “Bíi ti Jobu, mo fẹ́ láti kú ní àwọn ìgbà mìíràn. [Jobu 14:13] Síbẹ̀ n kò juwọ́ sílẹ̀, ọpẹ́lọpẹ́ ìṣírí tí mo rí gbà. Àwọn alàgbà méjì, tí mo mọ̀ dáradára, lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí ní ríràn mí lọ́wọ́ láti rí ìníyelórí bíbá a nìṣó nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún. Àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ olóye sì tún tù mí nínú, ní fífi sùúrù tẹ́tísílẹ̀ bí mo ṣe ń tú ọkàn-àyà mi jáde. Nípa lílo Bibeli, wọ́n mú kí ó ṣeé ṣe fún mi láti rí àwọn nǹkan ní ọ̀nà tí Jehofa gbà ń rí wọn. Èmi kò mọ iye ìgbà tí a ka Orin Dafidi 55:22, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé nípa fífi ìwé mímọ́ yìí sílò, mo jèrè ìwàdéédéé tẹ̀mí àti ti èrò-ìmọ̀lára mi padà. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ ní ọdún 12 sẹ́yìn, inú mi sì dùn láti sọ pé mo ti ń bá iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún nìṣó títí di ìsinsìnyí. Ìgbésí-ayé mi jẹ́ elérè-ẹ̀san àti aláyọ̀ láìka ìrora ti èrò-ìmọ̀lára lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan sí. Ó dá mi lójú pé rírí ìṣírí gbà ní àkókò kan bí èyí lè mú ìyàtọ̀ ńláǹlà wá nínú ìgbésí-ayé ẹnì kan.”

Àwọn kan nílò ìṣírí nítorí pé wọ́n ti ṣe àṣìṣe wọ́n sì ń tiraka nísinsìnyí láti ṣe àtúnṣe wọn. Bóyá a ti fún wọn ní ìbáwí onífẹ̀ẹ́. (Owe 27:6) Àwọn alàgbà tí wọ́n ti pèsè ìbáwí náà lè wà lójúfò láti gbóríyìn fúnni nígbà tí wọ́n bá rí i pé ìmọ̀ràn tí a gbékarí Ìwé Mímọ́ náà ni a ń fi sílò. Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí wọn yóò ṣàǹfààní lọ́nà méjì—ó ń jẹ́rìí sí ìfẹ́ wọn fún ẹni tí ó hùwà láìfí náà kí ó má baà ‘banújẹ́ púpọ̀ jù’ ó sì ń rán an létí àwọn àǹfààní tí ó wà nínú fífi ìmọ̀ràn náà sílò.—2 Korinti 2:7, 8, NW.

Alàgbà kan ṣe àṣìṣe ńlá kan ó sì pàdánù àǹfààní jíjẹ́ alábòójútó nínú ìjọ. Ó sọ pé: “Nígbà tí wọ́n ṣe ìfilọ̀ nípa ìmúkúrò mí gẹ́gẹ́ bí alàgbà, mo rò pé kò ní rọrùn fún àwọn ara láti bá mi kẹ́gbẹ́pọ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà pa ìdí ọ̀ràn náà mọ́ mẹ́rẹ́n-mẹ́rẹ́n wọ́n sì ń bá a nìṣó láti fún mi ní ìṣírí. Àwọn yòókù nínú ìjọ pẹ̀lú nawọ́ ìfẹ́ àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ sí mi, èyí tí ó dájú pé ó fikún ìkọ́fẹpadà mi nípa tẹ̀mí.”

Jẹ́ Ẹni Tí Ń Fúnni Ní Ìṣírí

Nínú ìgbésí-ayé wa tí ọwọ́ ti ń dí fọ́fọ́, ó rọrùn láti gbójúfo ìṣírí dá. Ṣùgbọ́n ẹ wo bí ó ṣe lè ṣàǹfààní tó! Láti lè fúnni ní ìṣírí tí ó gbéṣẹ́, o gbọ́dọ̀ fí ohun méjì sọ́kàn. Àkọ́kọ́ ni pé, ronú nípa ohun tí ó yẹ láti sọ, kí ìṣírí rẹ baà lè ṣe pàtó. Èkejì, wá àǹfààní láti bá ẹnì kan tí ó yẹ fún ìgbóríyìn tàbí tí ó nílò ìgbéró sọ̀rọ̀.

Bí o bá ṣe ń ṣe èyí lemọ́lemọ́ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ayọ̀ rẹ yóò ṣe pọ̀ tó. Ó ṣetán, Jesu mú un dá wa lójú pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà ninu fífúnni ju èyí tí ó wà ninu rírígbà lọ.” (Iṣe 20:35, NW) Nípa fífún àwọn ẹlòmíràn ní ìṣírí, ìwọ yóò fún ara rẹ ní ìṣírí. Èéṣe tí o kò fi í ṣe góńgó rẹ láti fún ẹnì kan ní ìṣírí ní ojoojúmọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́