Ẹtì Àwọn Ẹlẹ́kọ̀ọ́ Ìsìn
“ÈRÒ nípa àìlèkú ọkàn àti ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde àwọn òkú . . . jẹ àwọn ìpìlẹ̀-èrò méjì tí wọ́n yàtọ̀ síra gédégédé, nínú èyí tí ó ti yẹ kí a ṣe yíyàn kan.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí Philippe Menoud sọ ṣe àkópọ̀ ẹtì tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Protẹstanti àti Katoliki dojúkọ lórí ipò tí àwọn òkú wà. Bibeli sọ̀rọ̀ nípa ìrètí àjíǹde “ní ìkẹyìn ọjọ́.” (Johannu 6:39, 40, 44, 54, NW) Gisbert Greshake tí ó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn sọ pé, ṣùgbọ́n ìrètí ọ̀pọ̀ àwọn onígbàgbọ́ “sinmi lé orí àìlèkú ọkàn, èyí tí ń fi ara sílẹ̀ lẹ́yìn ikú tí ó sì ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọrun, nígbà tí ó sì jẹ́ pé ìrètí nínú àjíǹde ti pòórá dé ìwọ̀n àyè kan, bí kò bá tí ì pòórá pátápátá.”
Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìṣòro lílekoko kan jẹyọ, Bernard Sesboüé ṣàlàyé pé: “Ipò wo ni àwọn òkú wà láàárín ‘àkókò’ tí ó wà láàárín ikú wọn nípa ti ara àti àjíǹde ìkẹyìn?” Ó dàbí ẹni pé ìbéèrè yẹn ti wà ní àárín gbùngbùn àríyànjiyàn àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn. Kí ni ó ṣokùnfà rẹ̀? Èyí tí ó tún ṣe pàtàkì jùlọ ni pé, kí ni ìrètí tòótọ́ fún àwọn òkú?
Ìbẹ̀rẹ̀ àti Ìdàgbàsókè Ẹtì Kan
Àwọn Kristian àkọ́kọ́ ní òye tí ó ṣe kedere lórí ọ̀ràn náà. Wọ́n mọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́ pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun, nítorí pé Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu sọ pé: “Alààyè mọ̀ pé àwọn óò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan, . . . nítorí tí kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n, ní isà-òkú níbi tí ìwọ ń rè.” (Oniwasu 9:5, 10) Àwọn Kristian wọ̀nyẹn ń retí àjíǹde tí yóò wáyé nígbà “wíwàníhìn-ín Oluwa” ní ọjọ́-ọ̀la. (1 Tessalonika 4:13-17, NW) Wọn kò retí pé kí àwọn wà níbìkan tí àwọn ti lè mọ ohun tí ń lọ nígbà tí wọ́n ṣì ń dúró de àkókò yẹn. Joseph Ratzinger, tíí ṣe aṣíwájú lọ́wọ́lọ́wọ́ ti Ìjọ Vatican fún Ẹ̀kọ́-Ìsìn Ìgbàgbọ́, sọ pé: “Kò sí ẹ̀kọ́ ìsìn kankan tí ó fìdímúlẹ̀ lórí àìlèkú ọkàn nínú Ṣọ́ọ̀ṣì ìgbàanì.”
Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé àtúmọ̀ èdè Nuovo dizionario di teologia ṣàlàyé pé nígbà tí a bá ń ka ìwé tí àwọn Bàbá Ṣọ́ọ̀ṣì kọ, àwọn bíi Augustine tàbí Ambrose, “a ń mọ nípa ohun titun kan tí ó nííṣe pẹ̀lú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí a so mọ́ Bibeli—ìrúyọ ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀kọ́ àtubọ̀tán ọ̀rọ̀ ìtàn aráyé ti Griki, èyí tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ti èyí tí ó ní gbòǹgbò rẹ̀ nínú ìsìn Júù àti Kristian.” A gbé ẹ̀kọ́ titun yìí ka orí “àìlèkú ọkàn, ṣíṣe ìdájọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú èrè tàbí ìjìyà kété lẹ́yìn ikú.” Nípa bẹ́ẹ̀, a gbé ìbéèrè kan dìde nípa “ipò agbedeméjì”: Bí ọkàn bá la ikú ti ara já, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tí ó bá ń dúró de àjíǹde ní “ìkẹyìn ọjọ́”? Ẹtì kan tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ti jàdù láti yanjú ni èyí jẹ́.
Ní ọ̀rúndún kẹfà C.E., Póòpù Gregory I jiyàn pé kíámọ́sá nígbà ikú ọkàn yóò yára lọ sí ibi tí a ti kádàrá fún un. Póòpù John XXII ti ọ̀rúndún kẹrìnlá ni a yí lérò padà pé àwọn òkú yóò gba èrè wọn ìkẹyìn ní Ọjọ́ Ìdájọ́. Bí ò ti wù kí ó rí, Póòpù Benedict XII, kò gbà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti wà ṣáájú rẹ̀. Nínú lẹ́tà póòpù Benedictus Deus (1336), ó ṣòfin pé “ọkàn àwọn tí ó ti dolóògbé ń wọnú ipò ìdẹ̀ra [ní ọ̀run], ìjìyà [purgatory], tàbí ìdálẹ́bi [hẹ́ẹ̀lì] kété lẹ́yìn ikú, lẹ́yìn tí a óò wa so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú ara wọn tí a ti jí dìde ní òpin ayé.”
Láìka awuyewuye àti ìjiyàn sí, èyí ti jẹ́ ipò tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ti Kristẹndọm dìmú fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Protẹstanti àti Orthodox ní gbogbogbòò kò gbàgbọ́ nínú purgatory. Bí ó ti wù kí ó rí, láti ìgbà tí ọ̀rúndún tí ó kọjá ti parí, iye àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí ń pọ̀ síi ti tọ́ka síi pé ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àìlèkú ọkàn kò fẹsẹ̀múlẹ̀ nínú Bibeli, àti gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, “ẹ̀kọ́ ìsìn ti òde-òní sábà máa ń gbìyànjú láti wo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí odindi tí ń yòrò pátápátá nígbà ikú.” (The Encyclopedia of Religion) Nítorí náà, ó nira fún àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lórí Bibeli láti gbàgbọ́ pé “ipò agbedeméjì” ń bẹ. Bibeli ha sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bí, tàbí ó ha fúnni ni ìrètí tí ó yàtọ̀ bí?
Paulu Ha Gbàgbọ́ Nínú “Ipò Agbedeméjì” Bí?
Ìwé Catechism of the Catholic Church sọ pé: “Láti lè jíǹde pẹ̀lú Kristi, a gbọ́dọ̀ kú pẹ̀lú Kristi: a gbọ́dọ̀ ‘ti inú ara wa kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Oluwa’. [2 Korinti 5:8] Nígbà ‘lílọ’ yẹn tí ó jẹ́ ikú a ń ya ọkàn nípa kúrò lọ́dọ̀ ara. [Filippi 1:23] A óò so ò pọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú ara ní ọjọ́ àjíǹde àwọn òkú.” Ṣùgbọ́n nínú àwọn ẹsẹ tí a fàyọ níhìn-ín, aposteli Paulu ha sọ pé ọkàn ń la ikú ara já tí ó sì ń dúró de “Ìdájọ́ Ìkẹyìn” láti lè tún padà wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ara bí?
Ní 2 Korinti 5:1 (NW), Paulu ń tọ́ka sí ikú tirẹ̀ ó sì ń sọ̀rọ̀ nípa ‘ilé ti ilẹ̀-ayé’ tí a óò “túpalẹ̀.” Òun ha ń ronú pé ọkàn tí kò lè kú yóò fi ara sílẹ̀ bí? Rárá. Paulu gbàgbọ́ pé ènìyàn jẹ́ ọkàn kan, kì í ṣe pé ó ní ọkàn kan. (Genesisi 2:7; 1 Korinti 15:45) Kristian tí a fi àmì òróró yàn ní Paulu jẹ́ ẹni tí a fi ìrètí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, ‘pamọ́ dè é ní awọn ọ̀run.’ (Kolosse 1:5, NW; Romu 8:14-18) Nítorí náà, ‘ìfẹ́-ọkàn’ rẹ̀ ‘tí ó fi taratara ní’ jẹ́ láti jíǹde sí òkè-ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò lè kú ní àkókò tí Ọlọrun ti yàn kalẹ̀. (2 Korinti 5:2-4, NW) Ní sísọ̀rọ̀ nípa ìrètí yìí, ó kọ̀wé pé: “A óò yí gbogbo wa padà, . . . nígbà kàkàkí ìkẹyìn. Nitori kàkàkí naa yoo dún, a óò sì gbé awọn òkú dìde ní àìlèdíbàjẹ́, a óò sì yí wa padà.”—1 Korinti 15:51, 52, NW.
Ní 2 Korinti 5:8 (NW), Paulu sọ pé: “Awa jẹ́ onígboyà gidi gan-an ó sì dùnmọ́ wa nínú jọjọ lati kúkú máṣe wà ninu ara kí a sì fi ọ̀dọ̀ Oluwa ṣe ilé wa.” Àwọn kan gbàgbọ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ń tọ́ka sí ipò agbedeméjì ti dídúró. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ tún ń tọ́ka sí ìlérí Jesu fún àwọn olùṣòtítọ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé òun ń lọ láti lọ pèsè aye sílẹ̀ níbi tí òun yóò ti ‘gbà wọ́n sí ilé sọ́dọ̀ ara òun.’ Ṣùgbọ́n nígbà wo ni irú àwọn ìfojúsọ́nà bẹ́ẹ̀ yóò ní ìmúṣẹ? Kristi sọ pé yóò jẹ́ nígbà tí ‘òun bá padà wá’ nígbà wíwà níhìn-ín òun ní ọjọ́-ọ̀la. (Johannu 14:1-3, NW) Bákan náà, ní 2 Korinti 5:1-10, Paulu sọ pé ìrètí tí àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró jùmọ̀ní ni láti jogún ibùjókòó ti ọ̀run. Èyí yóò wáyé, kì í ṣe nípasẹ̀ àìlèkú ọkàn tí a méfò, bíkòṣe nípasẹ̀ àjíǹde nígbà wíwà níhìn-ín Kristi. (1 Korinti 15:23, 42-44) Charles Masson alálàyé ọ̀rọ̀ dé ìparí èrò pé 2 Korinti 5:1-10 “ni a lè lóye dáradára nígbà yẹn lọ́hùn-ún láì jẹ́ pé a ń yíjú sí èrò àìdánilójú ti ‘ipò agbedeméjì.’”
Ní Filippi 1:21, 23, (NW) Paulu sọ pé: “Ninu ọ̀ràn mi lati wà láàyè jẹ́ Kristi, ati lati kú, èrè. Mo wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ lọ́wọ́ awọn ohun méjì wọnyi; ṣugbọn ohun tí mo ní ìfẹ́-ọkàn sí ni ìtúsílẹ̀ ati wíwà pẹlu Kristi, nitori, láìsí àní-àní, èyí sàn púpọ̀púpọ̀ jù.” Paulu ha ń sọ̀rọ̀ nípa “ipò agbedeméjì” níhìn-ín bí? Àwọn kan rò bẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, Paulu sọ pé àwọn ohun méjì tí ó ṣeé ṣe kí ó fi òun sábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ ni—ìyè tàbí ikú. Ó fikún un, ní mímẹ́nuba ohun kẹta tí ó lè mú kí ó ṣeé ṣe, “Ṣugbọn ohun ti mo ni ìfẹ́-ọkàn sí ni ìtúsílẹ̀ ati wíwà pẹlu Kristi.” “Ìtúsílẹ̀” láti wà papọ̀ pẹ̀lú Kristi kété lẹ́yìn ikú ha ni bí? Ó dára, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i ṣáájú, Paulu gbàgbọ́ pé àwọn Kristian olùṣòtítọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni-àmì-òróró ni a óò jíǹde nígbà wíwà níhìn-ín Kristi. Nítorí náà, ó níláti ní àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àkókò yẹn lọ́kàn.
Èyí ni a lè rí nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a rí ní Filippi 3:20, 21 àti 1 Tessalonika 4:16. Irú “ìtúsílẹ̀” bẹ́ẹ̀ nígbà wíwà níhìn-ín Kristi Jesu yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún Paulu láti gba èrè náà tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀ fún un. Òtítọ́ náà pé èyí ni ìrètí rẹ̀ ni a rí nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ́mọkùnrin náà Timoteu pé: “Lati àkókò yii lọ a ti fi adé òdodo pamọ́ dè mí, èyí tí Oluwa, onídàájọ́ òdodo, yoo fún mi gẹ́gẹ́ bí èrè-ẹ̀san ní ọjọ́ yẹn, síbẹ̀ kì í ṣe fún emi nìkan, ṣugbọn fún gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n ti nífẹ̀ẹ́ ìfarahàn kedere rẹ̀ pẹlu.”—2 Timoteu 4:8, NW.
Àjíǹde—Òtítọ́ Títayọlọ́lá Ti Bibeli
Àwọn Kristian àkọ́kọ́ ka àjíǹde sí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí yóò bẹ̀rẹ̀ nígbà wíwà níhìn-ín Kristi, wọ́n sì rí okun àti ìtùnú gbà láti inú òtítọ́ títayọlọ́lá ti Bibeli yìí. (Matteu 24:3; Johannu 5:28, 29; 11:24, 25; 1 Korinti 15:19, 20; 1 Tessalonika 4:13) Wọ́n fi pẹ̀lú ìṣòtítọ́ dúró de ìdùnnú-ayọ̀ ọjọ́-ọ̀la yẹn, wọ́n kọ àwọn ẹ̀kọ́ apẹ̀yìndà ti àìlèkú ọkàn sílẹ̀.—Ìṣe 20:28-30; 2 Timoteu 4:3, 4; 2 Peteru 2:1-3.
Àmọ́ ṣáá o, a kò fi àjíǹde mọ sórí àwọn Kristian tí wọ́n ní ìrètí ti òkè ọ̀run. (1 Peteru 1:3-5) Àwọn babańlá àwọn Heberu àti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun nígbàanì lo ìgbàgbọ́ nínú agbára-ìṣe Jehofa láti mú àwọn òkú padà wá sí ìyè lórí ilẹ̀-ayé. (Jobu 14:14, 15; Danieli 12:2; Luku 20:37, 38; Heberu 11:19, 35) Àní àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọ̀nyẹn tí wọn kò tí ì mọ Ọlọrun láti àwọn ọ̀rúndún tí ó ti kọjá ní àǹfààní pípadà wá sí ìyè lórí paradise ilẹ̀-ayé, níwọ̀n bí ‘àjíǹde awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo yoo ti wà.’ (Ìṣe 24:15; Luku 23:42, 43) Èyí kì í ha ṣe ìfojúsọ́nà tí ń rù ìmọ̀lára sókè bí?
Dípò mímú kí a gbàgbọ́ pé ìjìyà àti ikú yóò máa bá a nìṣó títíláé, Jehofa tọ́ka sí àkókò náà nígbà tí a óò mú “ọ̀tá ìkẹyìn, ikú” kúrò títíláé tí aráyé olùṣòtítọ́ yóò sì lè wàláàyè títí ayérayé lórí Paradise ilẹ̀-ayé tí a mú padàbọ̀sípò. (1 Korinti 15:26, NW; Johannu 3:16; 2 Peteru 3:13) Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun àgbàyanu tó láti rí àwọn olólùfẹ́ wa tì ó ti kú tí wọ́n padà wàláàyè! Ẹ sì wo bí ìrètí yìí ti jẹ́ èyí tí ó dánilójú ju èrò àìdánilójú ti àìlèkú ọkàn ẹ̀dá ènìyàn lọ—ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ kan tí a gbéka orí ọgbọ́n-èrò-orí Griki, kì í ṣe lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun! Bí o bá gbé ìrètí rẹ karí ìlérí Ọlọrun tí ó dájú, ìwọ pẹ̀lú lè ní ìdánilójú pé láìpẹ́ “ikú kì yoo sì sí mọ́”!—Ìṣípayá 21:3-5, NW.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àjíǹde jẹ́ òtítọ́ títayọlọ́lá ti Bibeli