Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Wíwàásù ní Àsìkò Tí Ó Kún fún Ìdààmú
APOSTELI Paulu sọtẹ́lẹ̀ pé “ní awọn ọjọ́ ìkẹyìn awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò yoo wà níhìn-ín.” (2 Timoteu 3:1) Ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti jẹ́ òtítọ́ tó! Àwọn ènìyàn El Salvador ní Central America ti ní ìrírí òtítọ́ kíkorò yìí fún ọjọ́ pípẹ́. Fún èyí tí ó ju ẹ̀wádún lọ, orílẹ̀-èdè yìí ni ogun abẹ́lé ti bòmọ́lẹ̀ tí ó sì ti mú ìṣẹ́ àti ikú wá sórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Ogun náà ti parí báyìí, ṣùgbọ́n ìṣẹ́ ṣì kù. Ìwà-ọ̀daràn ti gbilẹ̀ lọ́nà tí ó lágbára lẹ́yìn ogun náà. Alálàyé kan ní ilé-iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n àdúgbò sọ láìpẹ́ yìí pé: “Ìwà-ipá àti olè-jíjà ti di ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ báyìí.”
Ìgbì ìwà-ọ̀daràn yìí kò yọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sílẹ̀. Àwọn fọ́léfọ́lé ti fọ́ ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọ́n sì ti jí ohun-èlò ìkọrin. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà àjọ-ìpàǹpá àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n dìhámọ́ra ogun ti fipá rọ́wọ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba nígbà tí ìpàdé Kristian ń lọ lọ́wọ́, tí wọ́n sì jí owó, aago, àti ọ̀pọ̀ àwọn ohun mìíràn tí ó ṣeyebíye láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbẹ̀. Nínú ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ wọn, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Ẹlẹ́rìí ni àwọn adigunjalè ti pa.
Láìka gbogbo àwọn ohun-ìdènà wọ̀nyí sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní El Salvador ń bá a lọ láti máa wàásù ìhìnrere náà. Wọ́n ń ṣe èyí ní ìgbọràn sí àṣẹ Ìwé Mímọ́ pé: “A níláti kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere naa ní gbogbo awọn orílẹ̀-èdè.” (Marku 13:10) Ọ̀pọ̀ ṣì wà ní ilẹ̀ yìí tí ń yánhànhàn fún ìrètí Ìjọba tí Bibeli ní, àwọn Ẹlẹ́rìí sì ń sakun láti dé ọ̀dọ̀ gbogbo wọn. Ìjẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà ń já sí ọ̀nà ìwàásù tí ó gbéṣẹ́.
Nígbà tí ó ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn, Ẹlẹ́rìí kan lo gbogbo àǹfààní tí ó ní láti bá àwọn aláìsàn yòókù sọ̀rọ̀ nípa ìlérí Ọlọrun fún ọjọ́ iwájú, bí a ti rí i nínú Bibeli. Aláìsàn kan tí àárẹ̀ tirẹ̀ pọ̀ gan-an kédàárò pé: “Láìpẹ́ èmi yóò kú!” Ṣùgbọ́n ojú aláìsàn náà tí ó dágùdẹ̀ kò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá Ẹlẹ́rìí náà láti máṣe ṣàjọpín ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ka ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tẹ̀jáde fún ọkùnrin náà. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Ẹlẹ́rìí náà fi ilé ìwòsàn sílẹ̀, ní ríronú pẹ̀lú ìbànújẹ́ pé ọkùnrin náà yóò kú láìpẹ́.
Ní ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà Ẹlẹ́rìí náà níláti lọ láti gba ìwòsàn ní ilé ìwòsàn mìíràn. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, aláìsàn kan wá bá a ó sì sọ pé: “O ha rántí mi bí?” Ọkùnrin tí ó ti bá pàdé ní ọdún mẹ́rin ṣáájú ni, ọkùnrin tí ó ti retí pé yóò kú! Ẹ wo irú ìdùnnú-ayọ̀ tí ó jẹ́ nígbà tí ọkùnrin náà rọ̀ mọ́ ọn tí ó sì fikún un pé: “Ní báyìí èmi náà ti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa!” Ọkùnrin náà ti tẹ́wọ́gba ìrètí Bibeli fún ọjọ́-ọ̀la, ó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó sì ti ya ìgbésí-ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa. Kì í ṣe kìkì pé ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún ti ń nípìn-ín nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé fún nǹkan bí ọdún méjì.
Ní ọ̀nà yìí, èso òtítọ́ tí a ti gbìn ní ọ̀nà àìjẹ́-bí-àṣà bọ́ sórí ọkàn-àyà rere. Àǹfààní yìí ti ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́ ti sún àwọn Kristian tòótọ́ láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù láìka “awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò” wọ̀nyí sí.