Ẹ Ṣe Iyebíye Lójú Ọlọrun!
“Èmi fi ìfẹ́ni ayérayé fẹ́ ọ, nítorí náà ni èmi ti ṣe pa oore-ọ̀fẹ́ mọ́ fún ọ.”—JEREMIAH 31:3.
1. Báwo ni ìhùwàsí Jesu sí àwọn ènìyàn gbáàtúù ti ọjọ́ rẹ̀ ṣe yàtọ̀ sí ti àwọn Farisi?
WỌ́N lè rí i ní ojú rẹ̀. Ọkùnrin yìí, Jesu, kò dàbí àwọn aṣáájú ìsìn wọn rárá; ó bìkítà. Àánú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe é nítorí pé “a bó wọn láwọ a sì fọ́n wọn ká bí awọn àgùtàn tí kò ní olùṣọ́ àgùtàn.” (Matteu 9:36) A retí pé kí àwọn aṣáájú ìsìn wọn jẹ́ àwọn olùṣọ́ àgùtàn onífẹ̀ẹ́, tí wọ́n ń ṣojú fún Ọlọrun onífẹ̀ẹ́, tí ó ní àánú. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọn fojú tẹ́ḿbẹ́lú àwọn gbáàtúù gẹ́gẹ́ bí aláìníláárí—àti ẹni ègún!a (Johannu 7:47-49; fiwé Esekieli 34:4.) Ní kedere, irú ojú-ìwòye tí ó lọ́, tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ojú-ìwòye Jehofa nípa àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó ti sọ fún Israeli, orílẹ̀-èdè rẹ̀ pé: “Èmi fi ìfẹ́ni ayérayé fẹ́ ọ.”—Jeremiah 31:3.
2. Báwo ni àwọn aláàbákẹ́gbẹ́pọ̀ Jobu mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe gbìyànjú láti mú kí ó gbàgbọ́ dájú pé òun kò jámọ́ nǹkankan lójú Ọlọrun?
2 Ṣùgbọ́n, ó dájú pé kì í ṣe àwọn Farisi ni ẹni àkọ́kọ́ tí wọ́n gbìyànjú láti mú àwọn àgùtàn olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún Jehofa gbàgbọ́ dájú pé àwọn jẹ́ aláìjámọ́ nǹkankan. Gbé ọ̀ràn ti Jobu yẹ̀wò. Lójú Jehofa òun jẹ́ olódodo àti aláìlẹ́bi, ṣùgbọ́n “àwọn olùtùnú” mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dọ́gbọ́n sọ pé Jobu jẹ́ oníwà pálapàla, apẹ̀yìndà burúkú tí yóò kú àkúrun. Wọ́n tẹnumọ́ ọn pé Ọlọrun kì yóò ka ìwà òdodo èyíkéyìí tí Jobu ti hù sí, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Ọlọrun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ pàápàá tí ó sì ń wo ọ̀run gan alára gẹ́gẹ́ bí ibi àìmọ́!—Jobu 1:8; 4:18; 15:15, 16; 18:17-19; 22:3.
3. Ọ̀nà wo ni Satani ń gbà lónìí láti gbìyànjú láti mú kí àwọn ènìyàn gbàgbọ́ dájú pé wọn kò níláárí tí wọn kò sí ṣeé nífẹ̀ẹ́?
3 Lónìí, Satani ṣì ń lo “ọgbọ́n àrékérekè” ti gbígbìyànjú láti mú àwọn ènìyàn gbàgbọ́ dájú pé a kò nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé wọ́n kò níláárí. (Efesu 6:11, àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References) Lóòótọ́, ó sábà máa ń ré àwọn ènìyàn lọ nípa ríru ìmọ̀lára ìwúfùkẹ̀ àti ìgbéraga wọn sókè. (2 Korinti 11:3) Ṣùgbọ́n ó tún máa ń ní inú dídùn sí bíba iyì ara-ẹni àwọn aláìlera jẹ́. Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” tí ó lekoko wọ̀nyí. Àwọn púpọ̀ lónìí dàgbà nínú àwọn ìdílé tí kò ti sí “ìfẹ́ni àdánidá”; àwọn púpọ̀ níláti bá àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ òǹrorò, onímọtara-ẹni-nìkan, àti olùwarùnkì lò lójoojúmọ́. (2 Timoteu 3:1-5) Àwọn ọdún ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìkórìíra, tàbí ìwà-ìkà ti lè mú kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ gbàgbọ́ dájú pé àwọn kò jámọ́ nǹkankan a kò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn. Ọkùnrin kan kọ̀wé pé: “Èmi kì í nímọ̀lára pé mo nífẹ̀ẹ́ ẹnikẹ́ni tàbí pé ẹnikẹ́ni nífẹ̀ẹ́ mi. Ó ṣòro fún mi láti gbàgbọ́ pé Ọlọrun bìkítà rárá nípa mi.”
4, 5. (a) Èéṣe tí èròǹgbà nípa kíka ara-ẹni sí aláìníláárí kò fi bá Ìwé Mímọ́ mu? (b) Àbájáde búburú wo ni gbígbàgbọ́ pé kò sí èyíkéyìí nínú ìsapá wa tí ó níláárí máa ń mú wá?
4 Èròǹgbà kíka ara-ẹni sí aláìníláárí jẹ́ fífi igi gún ojú òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ẹ̀kọ́ nípa ìràpadà. (Johannu 3:16) Bí Ọlọrun bá níláti san iye owó gíga bẹ́ẹ̀—ìwàláàyè Ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó ṣeyebíye—láti ra àǹfààní náà láti wàláàyè títíláé, dájúdájú Òun gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ wa; dájúdájú a gbọ́dọ̀ jámọ́ nǹkankan lójú Rẹ̀!
5 Síwájú síi, ẹ wo bí yóò ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni tó láti nímọ̀lára pé a ń ṣe ohun tí ń ba Ọlọrun nínú jẹ́, pé kò sí èyíkéyìí nínú ìsapá wa tí ó jámọ́ nǹkankan! (Fiwé Owe 24:10.) Pẹ̀lú ojú-ìwòye òdì yìí, ìṣírí tí ó wá láti inú ọkàn rere pàápàá, tí a pète láti ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun níbikíbi tí ó bá ti lè ṣeé ṣe, lè dún bí ìdálẹ́bi létí àwọn kan dípò bẹ́ẹ̀. Ó lè dàbí sísọ èrò-inú wa lọ́hùn-ún ní àsọtúnsọ pé ohunkóhun tí a ṣe kò tó.
6. Aporó dídára jùlọ wo ni ó wà fún níní èrò òdì nípa ara wa?
6 Bí o bá ṣàkíyèsí irú ìmọ̀lára òdì bẹ́ẹ̀ nínú ara rẹ, máṣe sọ̀rètínù. Púpọ̀ lára wa máa ń ṣe lámèyítọ́ ara wa lọ́nà tí kò lọ́gbọ́n nínú láti ìgbà dé ìgbà. Sì rántí pé, a pète Ọ̀rọ̀ Ọlọrun láti ‘mú awọn nǹkan tọ́’ kí ó sì lè ‘sojú awọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in-gbọn-in dé.’ (2 Timoteu 3:16; 2 Korinti 10:4) Aposteli Johannu kọ̀wé pé: “Nipa èyí ni awa yoo mọ̀ pé awa pilẹ̀ṣẹ̀ lati inú òtítọ́, awa yoo sì fún ọkàn-àyà wa ní ìdánilójú níwájú rẹ̀ níti ohun yòówù ninu èyí tí ọkàn-àyà wa ti lè dá wa lẹ́bi, nitori Ọlọrun tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Johannu 3:19, 20) Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà mẹ́ta tí Bibeli gbà ń kọ́ wa pé a ṣeyebíye fún Jehofa.
Jehofa Kà Ọ́ Sí
7. Báwo ni Jesu ṣe kọ́ gbogbo àwọn Kristian nípa ìníyelórí wọn lójú Ọlọrun?
7 Lákọ̀ọ́kọ́, Bibeli kọ́ wa ní tààràtà pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa jámọ́ nǹkan lójú Ọlọrun. Jesu wí pé: “Ológoṣẹ́ márùn-ún ni a ń tà ní ẹyọ-owó méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀síbẹ̀ kò sí ọ̀kan ninu wọn tí a gbàgbé níwájú Ọlọrun. Ṣugbọn awọn irun orí yín pàápàá ni a ti ka iye gbogbo wọn. Ẹ má bẹ̀rù; ẹ̀yin níyelórí ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn ológoṣẹ́.” (Luku 12:6, 7) Nígbà náà lọ́hùn-ún, nínú àwọn ẹyẹ jíjẹ, ológoṣẹ́ ni a ń tà ní owó pọ́ọ́kú jùlọ, síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá kò gbàgbé ìkankan nínú wọn. Nípa báyìí a ti fìdí ìpìlẹ̀ náà lélẹ̀ fún ìyàtọ̀ yíyanilẹ́nu: Bí ó bá di ọ̀ràn ti ẹ̀dá ènìyàn—tí wọ́n níyelórí púpọ̀, fíìfíì—Ọlọrun mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀. Níṣe ni ó dàbí ẹni pé a ka iye irun orí wa gan-an lẹ́nìkọ̀ọ̀kan!
8. Èéṣe tí ó fi jẹ́ òtítọ́ gidi láti ronú pé Jehofa lè ka iye irun orí wa?
8 A ha lè ka iye irun orí bí? Bí o bá gbà pé apá yìí nínú àkàwé Jesu kì í ṣe òtítọ́, rántí pé: Ọlọrun ń rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́ láìkùsíbìkan tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ó lè jí wọn dìde—kí ó tún wọn dá látòkèdélẹ̀, títíkan kẹ́míkà apilẹ̀ àbùdá wọn tí ó díjú àti gbogbo ọdún ìrántí àti ìrírí wọn. Kíka iye irun wa (nínú èyí tí orí ẹnì kan ti lè hu nǹkan bíi 100,000) yóò jẹ́ iṣẹ́ àrà tí ó rọrùn ní ìfiwéra!—Luku 20:37, 38.
Kí Ni Jehofa Rí Lára Wa?
9. (a) Kí ni àwọn ànímọ́ díẹ̀ tí Jehofa kà sí? (b) Èéṣe tí o fi ronú pé irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ ṣeyebíye lójú rẹ̀?
9 Èkejì, Bibeli ń kọ́ wa ní ohun tí Jehofa kà sí lára wa. Ní ṣókí, inú rẹ̀ máa ń dùn sí àwọn ànímọ́ wa tí ó dára àti nínú ìsapá wa. Ọba Dafidi sọ fún Solomoni ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Oluwa a máa wá gbogbo àyà, ó sì mọ gbogbo ète ìrònú.” (1 Kronika 28:9) Bí Ọlọrun ti ń wádìí ọkàn-àyà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀dá ènìyàn wò nínú ayé oníwà-ipá, tí ìkórìíra kún dẹ́nu yìí, ẹ wo bí inú rẹ̀ yóò ti dùn tó nígbà tí ó bá rí ọkàn-àyà kan tí ó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà, òtítọ́, àti òdodo! (Fiwé Johannu 1:47; 1 Peteru 3:4.) Kí ni ó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọrun bá rí ọkàn-àyà kan tí ìfẹ́ fún òun kún inú rẹ̀, tí ó ń fẹ́ láti kọ́ nípa òun kí ó sì ṣàjọpín irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? Ní Malaki 3:16, Jehofa sọ fún wa pé òun ń tẹ́tísílẹ̀ sí àwọn wọnnì tí wọ́n ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa òun àní òun tilẹ̀ ní “ìwé-ìrántí” fún gbogbo “àwọn tí ó bẹ̀rù Oluwa, tí wọ́n sì ń ṣe àṣàrò orúkọ rẹ̀.” Irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ ṣe iyebíye fún un!
10, 11. (a) Báwo ni àwọn kan ṣe lè ṣàìka ẹ̀rí náà sí pé Jehofa ka àwọn ànímọ́ rere wọn sí? (b) Báwo ni àpẹẹrẹ Abijah ṣe fi hàn pé Jehofa ń ka àwọn ànímọ́ rere sí ní gbogbo ọ̀nà?
10 Bí ó ti wù kí ó rí, ọkàn-àyà tí ń dára rẹ̀ lẹ́bi lè dènà irú ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ pé a jẹ́ ẹni tí ó níyelórí lójú Ọlọrun. Ó lè máa sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ láìdabọ̀ pé, ‘Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn ẹlòmíràn ń bẹ tí wọ́n jẹ́ ẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn ju èmi lọ. Ẹ wo bí a óò ṣe já Jehofa kulẹ̀ tó nígbà tí ó bá fi mí wé wọn!’ Jehofa kì í fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wéra, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ẹni tí kò ṣeé yípadà, elérò ọ̀pá-ìdiwọ̀n-tèmi-ò-gbọ́dọ̀-yingin. (Galatia 6:4) Pẹ̀lú òye-inú ńláǹlà ni ó fi ń mọ ọkàn-àyà, ó sì máa ń ka àwọn ànímọ́ dáradára sí ní gbogbo ọ̀nà.
11 Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Jehofa pàṣẹ pé kí a pa ìlà-ìdílé Ọba Jeroboamu apẹ̀yìndà run látòkèdélẹ̀, kí a gbá wọn sọnù bí “ìgbẹ́,” Ó pàṣẹ pé ọ̀kanṣoṣo péré lára àwọn ọmọkùnrin ọba, Abijah, ni kí a sin lọ́nà tí ó bójúmu. Èéṣe? “Lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a rí ohun rere díẹ̀ sípa Oluwa, Ọlọrun Israeli.” (1 Ọba 14:10, 13) Èyí ha túmọ̀ sí pé Abijah jẹ́ olùṣòtítọ́ olùjọ́sìn Jehofa bí? Ó lè má jẹ́ bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí ó ti kú, gẹ́gẹ́ bíi ti ìyókù agbo ilé rẹ̀ búburú. (Deuteronomi 24:16) Síbẹ̀, Jehofa ka “ohun rere” tí ó rí nínú ọkàn-àyà Abijah sí ó sì hùwà lọ́nà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Ìwé Matthew Henry’s Commentary on the Whole Bible sọ pé: “Níbi tí irú ohun rere kan bẹ́ẹ̀ bá wà, yóò di mímọ̀: Ọlọrun tí ń wá a, ń rí i, bí ó ti wù kí ó kéré mọ, inú rẹ̀ sì dùn sí i.” Má sì ṣe gbàgbé pé bí Ọlọrun bá rí kìkì ìwọ̀nba ànímọ́ dáradára kan lára rẹ, ó lè mú kí ó gbèrú níwọ̀n bí o bá ti ń sakun láti ṣiṣẹ́sìn ín pẹ̀lú ìṣòtítọ́.
12, 13. (a) Báwo ni Orin Dafidi 139:3 ṣe fi hàn pé Jehofa ń ka àwọn ìsapá wa sí? (b) Ní ọ̀nà wo ni a fi lè sọ pé Jehofa ń ku àwọn ìgbòkègbodò wa?
12 Lọ́nà kan náà Jehofa ń ka àwọn ìsapá wa sí. Ní Orin Dafidi 139:1-3 (NW), a kà pé: “Óò Jehofa, ìwọ ti yẹ̀ mí wò kínníkínní, ìwọ sì mọ̀ mí. Ìwọ fúnra rẹ ti wá mọ jíjókòó mi àti dídìde mi. Ó ti gbé èrò-inú mi yẹ̀wò láti ọ̀nà jínjìn réré. Ìrìnrìn-àjò mi àti ìdùbúlẹ̀ gbalaja mi ni ìwọ ti wọ̀n, ìwọ sì ti di ojúlùmọ̀ gbogbo àwọn ọ̀nà mi pàápàá.” Nítorí náà Jehofa mọ gbogbo ohun tí a ń ṣe. Ṣùgbọ́n ó tún rékọjá mímọ̀ lásán. Nínú èdè Heberu àpólà ọ̀rọ̀ náà “ìwọ sì ti di ojúlùmọ̀ gbogbo àwọn ọ̀nà mi pàápàá” tún lè túmọ̀ sí “gbogbo ọ̀nà mi ṣeyebíye fún ọ” tàbí “o ṣìkẹ́ gbogbo ọ̀nà mi.” (Fiwé Matteu 6:19, 20.) Ṣùgbọ́n, báwo ni Jehofa ṣe lè ṣìkẹ́ àwọn ọ̀nà wa nígbà tí a jẹ́ aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀ tóbẹ́ẹ̀?
13 Lọ́nà tí ó dùnmọ́ni, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti sọ, nígbà tí Dafidi kọ̀wé pé Jehofa ti “mọ” ìrìn-àjò àti àkókò ìsinmi òun, ọ̀rọ̀ Heberu náà ní olówuuru túmọ̀ sí láti “kù” tàbí “fẹ́.” Ìtọ́kasí kan ṣàkíyèsí pé: “Ó túmọ̀ sí . . . láti fẹ́ gbogbo ìyàngbò dànù, kí o sì ṣẹ́ku gbogbo ọkà sílẹ̀—láti tọ́jú gbogbo èyí tí ó níyelórí. Nítorí náà níhìn-ín, kí a sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó túmọ̀ sí pé Ọlọrun kù ú. . . . Ó ya gbogbo ìyàngbò sọ́tọ̀, tàbí gbogbo èyí tí kò níyelórí, ó sì rí ohun tí ó ṣẹ́kù tí ó jẹ́ ojúlówó tí ó sì ṣe pàtàkì.” Ní ìdàkejì, ọkàn-àyà tí ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi lè ku àwọn ìṣe wa dànù, ní dídá wa lẹ́bi gidigidi fún àwọn àṣìṣe àtẹ̀yìnwá kí ó sì ṣàìka àwọn àṣeyọrí wa sí nǹkankan. Ṣùgbọ́n Jehofa máa ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá bí a bá fi tọkàntọkàn ronúpìwàdà tí a sì làkàkà gan-an láti máṣe ṣe àwọn àṣìṣe wa mọ́. (Orin Dafidi 103:10-14; Ìṣe 3:19) Ó ń ku èyí tí kò wúlò dànù ó sì ń rántí àwọn iṣẹ́ rere wa. Ní tòótọ́, ó ń rántí wọn títí láé níwọ̀n ìgbà tí a bá ṣì dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ sí i. Òun yóò wò ó gẹ́gẹ́ bí àìṣòdodo láti gbàgbé àwọn wọ̀nyí, òun kì í sìí ṣe aláìṣòdodo!—Heberu 6:10.
14. Kí ni ó fi hàn pé Jehofa ka àwọn ìgbòkègbodò wa nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian sí?
14 Kí ni díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ rere tí Ọlọrun ń kà sí? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ohun tí a bá ṣe ní ṣíṣe àfarawé Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi. (1 Peteru 2:21) Nígbà náà, ó dájú pé iṣẹ́ kan tí ó ṣe pàtàkì gidigidi, ni títan ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun kálẹ̀. Ní Romu 10:15, a kà pé: “Ẹsẹ̀ awọn wọnnì tí ń polongo ìhìnrere awọn ohun rere ti dára rèǹtè-rente tó!” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè má ronú nípa ẹsẹ wa lásán-làsàn gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó “dára rèǹtè-rente,” ọ̀rọ̀ tí Paulu lò níhìn-ín ni ọ̀kan náà tí a lò nínú ìtumọ̀ Septuagint ti Griki láti ṣàpèjúwe Rebeka, Rakeli, àti Josefu—àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí a mọ̀ dáradára nítorí ẹwà wọn. (Genesisi 26:7; 29:17; 39:6) Nítorí náà lílọ́wọ́ tí a ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun wa, Jehofa, jẹ́ ohun tí ó rẹwà tí ó sì ṣeyebíye lójú rẹ̀.—Matteu 24:14; 28:19, 20.
15, 16. Èéṣe tí Jehofa fi ń ka ìfaradà wa sí, báwo sì ni àwọn ọ̀rọ̀ Ọba Dafidi ní Orin Dafidi 56:8 ṣe tẹnumọ́ òkodoro òtítọ́ yìí?
15 Ànímọ́ mìíràn tí Ọlọrun kà sí ni ìfaradà wa. (Matteu 24:13) Rántí pé, Satani ń fẹ́ kí o kẹ̀yìn sí Jehofa. Ojúmọ́ kọ̀ọ̀kan tí o fi ń dúró gẹ́gẹ́ bí adúróṣinṣin sí Jehofa jẹ́ ọjọ́ mìíràn tí o ti ṣèrànwọ́ láti pèsè ìdáhùn sí ẹ̀gàn Satani. (Owe 27:11) Nígbà mìíràn ìfaradà kì í ṣe ọ̀ràn tí ó rọrùn. Ìṣòro àìlera, ìṣòro ìṣúnná-owó, wàhálà èrò-ìmọ̀lára, àti àwọn ìdíwọ́ mìíràn lè mú kí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí ń kọjá lọ jẹ́ àdánwò. Ìfaradà lójú irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun tí ó ṣeyebíye gidigidi lójú Jehofa. Ìdí nìyẹn tí Ọba Dafidi fi sọ pé kí Jehofa fi omijé òun pamọ́ sínú “ìgò” ìṣàpẹẹrẹ, tí ó sì béèrè tìgboyà-tìgboyà pé, “Wọn kò ha sí nínú ìwé rẹ bí?” (Orin Dafidi 56:8) Bẹ́ẹ̀ni, Jehofa ka gbogbo omijé àti ìjìyà wa tí a ń faradà nígbà tí a ń di ìdúróṣinṣin wa mú sí ohun ṣíṣeyebíye ó sì ń rántí wọn. Àwọn pẹ̀lú jẹ́ ohun ṣíṣeyebíye lójú rẹ̀.
16 Lójú ìwòye àwọn ànímọ́ wa tí ó dára sí i àti àwọn ìsapá wa, ẹ wo bí ó ti ṣe kedere tó pé Jehofa ń rí ohun púpọ̀ láti kà sí nínú ẹnìkọ̀ọ̀kan wa! Láìka bí ayé Satani ti lè ṣe wá sí, Jehofa ń wò wá gẹ́gẹ́ bí ohun ṣíṣeyebíye àti apákan “àwọn ohun fífẹ́ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè.”—Haggai 2:7, NW.
Ohun Tí Jehofa Ti Ṣe Láti Fi Ìfẹ́ Rẹ̀ Hàn
17. Èéṣe tí ẹbọ ìràpadà Kristi fi níláti mú wa gbàgbọ́ dájú pé Jehofa àti Jesu nífẹ̀ẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan?
17 Ẹ̀kẹta, Jehofa ṣe ohun púpọ̀ láti lè fi ẹ̀rí ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún wa. Dájúdájú, ẹbọ ìràpadà Kristi ni ìdáhùn gbígbéṣẹ́ jùlọ sí irọ́ Satani pé a kò níláárí tàbí pé a kò ṣeé nífẹ̀ẹ́. Kí a máṣe gbàgbé láé pé ikú onírora tí Jesu jìyà rẹ̀ lórí òpó igi ìdálóró àti ìrora tí ó tilẹ̀ tún ju ìyẹn lọ tí Jehofa faradà ní wíwo ikú Ọmọkùnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ wọn fún wa. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìfẹ́ náà kàn wá lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Ojú tí aposteli Paulu fi wò ó nìyẹn, nítorí ó kọ̀wé pé: ‘Ọmọkùnrin Ọlọrun, nífẹ̀ẹ́ mi ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.’—Galatia 2:20.
18. Ní ọ̀nà wo ni Jehofa fi ń fà wá mọ́ Kristi?
18 Jehofa ti fi ẹ̀rí ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún wa nípa ríràn wá lọ́wọ́ lẹ́nìkọ̀ọ̀kan láti lo àǹfààní ẹbọ Kristi. Jesu sọ ní Johannu 6:44 pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù, tí ó dé ọ̀dọ̀ wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan, àti nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, èyí tí Jehofa ń lò láti ràn wá lọ́wọ́ láti lóye kí a sì fi àwọn òtítọ́ tẹ̀mí sílò láìka ibi ti agbára wa mọ àti àìpé wa sí, Jehofa fúnra rẹ̀ ń fà wá síhà ọ̀dọ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀ àti ìrètí ìyè ayérayé. Nítorí náà Jehofa lè sọ nípa wa gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ nípa Israeli pé: “Èmi fi ìfẹ́ni ayérayé fẹ́ ọ, nítorí náà ni èmi ti ṣe pa oore-ọ̀fẹ́ mọ́ fún ọ.”—Jeremiah 31:3.
19. Èéṣe tí àǹfààní àdúrà fi níláti mú wa gbàgbọ́ dájú nípa ìfẹ́ tí Jehofa fúnra rẹ̀ ní fún wa?
19 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé nípasẹ̀ àǹfààní àdúrà ni a fi ní ìrírí ìfẹ́ Jehofa ní ọ̀nà tí ó ṣe tímọ́tímọ́ jùlọ. Ó késí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti “máa gbàdúrà láìdabọ̀.” (1 Tessalonika 5:17) Ó ń tẹ́tísílẹ̀! A tilẹ̀ pè é ní “Olùgbọ́ àdúrà.” (Orin Dafidi 65:2, NW) Kò tí ì fi ẹrù-iṣẹ́ yìí lé ẹlòmíràn lọ́wọ́, kì í tilẹ̀ ṣe Ọmọkùnrin rẹ̀ fúnra rẹ̀ pàápàá. Rò ó wò ná: Ẹlẹ́dàá àgbáyé rọ̀ wá láti tọ òun wá nínú àdúrà, pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Ìrawọ́-ẹ̀bẹ̀ wa lè sún Jehofa pàápàá láti ṣe ohun mìíràn tí òun kì bá tí ṣe.—Heberu 4:16; Jakobu 5:16; wo Isaiah 38:1-16.
20. Èéṣe tí ìfẹ́ Ọlọrun fún wa kì í ṣe àwáwí fún ìjọra-ẹni-lójú tàbí ìgbéra-ẹni-lárugẹ níhà ọ̀dọ̀ wa?
20 Kò sí Kristian kan tí ó wàdéédéé tí yóò sọ ẹ̀rí irú ìfẹ́ àti iyì Ọlọrun bẹ́ẹ̀ di àwáwí fún wíwo ara rẹ̀ bíi pé òun ṣe pàtàkì ju bí òun ti jẹ́ níti gidi lọ. Paulu kọ̀wé pé: “Nípasẹ̀ inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi fún mi mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ lati máṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣugbọn lati ronú kí ó baà lè ní èrò-inú yíyèkooro, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti há ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún un.” (Romu 12:3) Nítorí náà bí a ṣe ń yọ̀ ṣìnkìn nínú ọ̀yàyà ìfẹ́ Bàbá wa ọ̀run, ẹ jẹ́ kí a yèkooro ní èrò-inú kí a sì rántí pé ìṣeun-ìfẹ́ Ọlọrun jẹ́ ohun tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí.—Fiwé Luku 17:10.
21. Irọ́ Satani wo ni a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti dènà, òtítọ́ àtọ̀runwá wo ni a sì níláti máa sinmẹ̀dọ̀ ronú lé lórí títíláé?
21 Ẹ jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe láti dènà gbogbo èròǹgbà tí Satani ń gbé lárugẹ nínú ayé ògbólógbòó tí ń kú lọ yìí. Ìyẹn ní nínú kíkọ ìrònú náà pé a kò jámọ́ nǹkankan tàbí pé a kò nífẹ̀ẹ́ wa sílẹ̀. Bí ìgbésí-ayé nínú ètò-ìgbékalẹ̀ yìí bá ti kọ́ ọ láti rí ara rẹ gẹ́gẹ́ bí ìdènà kan tí ó tilẹ̀ fo ìfẹ́ Ọlọrun pàápàá láyà púpọ̀ púpọ̀ jù láti borí, tàbí iṣẹ́ rere rẹ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó kéré jọjọ àní fún ojú rẹ̀ tí ń rí ohun gbogbo láti kíyèsí i, tàbí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ti pọ̀ jù tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ikú Ọmọkùnrin rẹ̀ ṣíṣeyebíye kò fi lè bò ó mọ́lẹ̀, a ti kọ́ ọ ní irọ́. Fi gbogbo ìríra tí ó bá yẹ fún un kọ irú irọ́ bẹ́ẹ̀! Ẹ jẹ́ kí a máa fi àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí tí aposteli Paulu kọ ní Romu 8:38, 39 sọ́kàn nígbà gbogbo pé: “Mo gbàgbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tabi ìyè tabi awọn áńgẹ́lì tabi awọn ìjọba-àkóso tabi awọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tabi awọn ohun tí ń bọ̀ tabi awọn agbára tabi ibi gíga tabi ibi jíjìn tabi ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yoo lè yà wá kúrò ninu ìfẹ́ Ọlọrun tí ó wà ninu Kristi Jesu Oluwa wa.”
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní tòótọ́, wọ́n dá ṣíọ̀ àwọn tálákà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ bíi “ʽam-ha·ʼaʹrets,” tàbí “àwọn ènìyàn ilẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ṣe sọ, àwọn Farisi kọ́ni pé ẹnì kan kò gbọdọ̀ fi ohun tí ó bá níyelórí síkàáwọ́ àwọn wọ̀nyí, kò sì gbọdọ̀ gba ìrírí wọn gbọ́, tàbí gbà wọ́n lálejò, tàbí jẹ́ àlejò wọn, tàbí kí ó tilẹ̀ ra nǹkan lọ́wọ́ wọn. Àwọn aṣáájú ìsìn wí pé bí ọmọbìnrin ẹnì kan bá lọ fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò dàbí yíyọ̀ǹda kí ẹnì kan kojú ẹranko ẹhànnà láìní ohun ìgbèjà.
Kí Ni Èrò Rẹ?
◻ Èéṣe tí Satani fi ń gbìyànjú láti mú wa gbàgbọ́ dájú pé a kò níláárí tí a kò sì nífẹ̀ẹ́ wa?
◻ Báwo ni Jesu ṣe kọ́ni pé Jehofa ka ẹnìkọ̀ọ̀kan wa sí?
◻ Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jehofa ka àwọn ànímọ́ wa sí ohun tí ó níyelórí?
◻ Báwo ni a ṣe lè mọ̀ dájú pé Jehofa ka ìsapá wa sí ohun ṣíṣeyebíye?
◻ Báwo ni Jehofa ṣe ń fi ẹ̀rí ìfẹ́ rẹ̀ fún wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan hàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Jehofa ń kíyèsí ó sì ń rántí gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n bá ń ronú lórí orúkọ rẹ̀