ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 4/1 ojú ìwé 21-25
  • Ìpinnu Mi Láti Tẹ̀síwájú Dé Ìdàgbàdénú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìpinnu Mi Láti Tẹ̀síwájú Dé Ìdàgbàdénú
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Ogun náà Yí Ìgbésí-Ayé Wa Padà
  • Ohun Ìdínà fún Ìtẹ̀síwájú Tẹ̀mí
  • Títẹ́wọ́gba Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà
  • Lílépa Iṣẹ́-Ìsìn Míṣọ́nnárì
  • Mímú Ara Mi Bá Pápá Ilẹ̀ Àjèjì Mu
  • Bíbẹ United States Wò
  • Bíbá A Nìṣó Láti Máa Tẹ̀síwájú Nípa Tẹ̀mí
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 4/1 ojú ìwé 21-25

Ìpinnu Mi Láti Tẹ̀síwájú Dé Ìdàgbàdénú

GẸ́GẸ́ BÍ CARL DOCHOW ṢE SỌ Ọ́

“Ìtẹ̀síwájú dé Ìdàgbàdénú Tàbí Ìfàsẹ́yìn Sínú Ẹ̀ṣẹ̀, Èwo Ni?” ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ inú Ilé-Ìṣọ́nà June 15, 1948 (lédè Gẹ̀ẹ́sì). Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà sún mi láti yípadà látorí ewu tẹ̀mí nínú ilẹ̀-oko United States sínú iṣẹ́-ìgbésí-ayé ti míṣọ́nnárì tí ó ti lé ní ọdún 43 ní South America.

ABÍ mi ní March 31, 1914, ìkẹta nínú ọmọkùnrin mẹ́rin, nínú ilé tí a fi igi kọ́ ní Vergas, Minnesota. Àwọn ọdún ìgbà èwe mi dùn púpọ̀. Mo rántí pípẹja pẹ̀lú Bàbá. Bí ó ti wù kí ó rí, Màmá sábà máa ń ṣàìsàn, mo sì níláti kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ ní ipele karùn-ún láti lè ràn án lọ́wọ́ nínú ilé. Nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 13, àyẹ̀wò àìsàn rẹ̀ fi hàn pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró.

Màmá mọ̀ pé òun kò lè pẹ́ láyé mọ́, nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí múra mí sílẹ̀ láti lè rọ́pò òun. Yóò jókòó sínú ilé ìdáná yóò sì máa fún mi ní ìtọ́sọ́nà nípa bí a ṣe ń gbọ́únjẹ àti bí a ṣe ń ṣe búrẹ́dì. Ní àfikún síi, ó kọ mi bí a ṣe ń fọṣọ, bí a ṣe ń bójútó ọgbà, àti bí a ṣe ń bójútó ọgọ́rùn-ún adìyẹ. Ó tún fún mi ní ìṣírí láti máa ka orí Bibeli kọ̀ọ̀kan lójoojúmọ́, mo sì ṣe bẹ́ẹ̀ láìka pé ń kò mọ̀wé kà tóbẹ́ẹ̀ sí. Lẹ́yìn dídá mi lẹ́kọ̀ọ́ fún oṣù mẹ́wàá, Màmá kú ní January 27, 1928.

Ogun náà Yí Ìgbésí-Ayé Wa Padà

Lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé II bẹ̀rẹ̀ ni September 1939, ọjọọjọ́ Sunday ni a máa ń gbàdúrà fún àwọn ọmọ ogun ní ṣọ́ọ̀ṣì Luther tí a ń lọ. Frank ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin pinnu láti máṣe pànìyàn, nítorí náà nígbà tí ó kọ̀ láti jà gẹ́gẹ́ bí apákan ológun, a fàṣẹ ọba mú un. Níbi ìjẹ́jọ́ rẹ̀ ó wí pé: “Kí n tó pa àwọn tí kò mọwọ́mẹsẹ̀, ẹ lè yìnbọn fún mi!” A rán an lẹ́wọ̀n ọdún kan nínú ọgbà-ẹ̀wọ̀n ní McNeil Island tí kò jìnnà sí etíkun Ìpínlẹ̀ Washington.

Frank rí iye tí ó lé ní 300 àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa níbẹ̀ tí a ti fi sẹ́wọ̀n nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìdásí-tọ̀tún-tòsì pátápátá lákòókò ogun náà. (Isaiah 2:4; Johannu 17:16) Kò pẹ́ kò jìnnà ó bẹ̀rẹ̀ sí darapọ̀ mọ́ wọn ó sì ṣe ìrìbọmi níbẹ̀ gan-an nínú ọgbà-ẹ̀wọ̀n. Nítorí ìwà ọmọlúwàbí rẹ̀, a dín àkókò tí ó yẹ kí ó lò kù sí oṣù mẹ́sàn-án. Ní November 1942 a gbọ́ ìròyìn pé wọ́n ti dá Frank sílẹ̀, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí ó fi sọ fún wa nípa ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun. Lẹ́yìn fífarabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìhìn-iṣẹ́ náà pẹ̀lú Bibeli, gbogbo wa lè rí i pé òtítọ́ ni ohun tí Frank fi ń kọ́ wa.

Ohun Ìdínà fún Ìtẹ̀síwájú Tẹ̀mí

Ní 1944, mo ṣí lọ sí agbègbè Malta, Montana, láti máa gbé pẹ̀lú àbúrò bàbá mi. Ohun kan wà tí ó rí bákan náà nínú ìgbésí-ayé àwa méjèèjì—àwọn ìyàwó tí wọ́n ti fi wá sílẹ̀ lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí a ṣègbéyàwó. Inú rẹ̀ dùn pé mo wá láti máa ran òun lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-oko àti gbígbọ́únjẹ, a sì ń pín èrè wa dọ́gba-dọ́gba. Àbúrò bàbá mi wí pé èmi ni yóò jogún 260 hectare ilẹ̀ oko rẹ̀ bí mo bá lè dúró ti òun. Ìgbà yẹn ni iṣẹ́ àgbẹ̀ ń mówó wọlé, mo mà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ o! Ọdọọdún ni ire oko wa ń jáde dáradára, a sì ń ta àlìkámà ní nǹkan bíi $3.16 òṣùnwọ̀n bushel kan.

Bí ó ti wù kí ó rí, inú àbúrò bàbá mi kò dùn pé mo ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ kékeré ti àwọn Ẹlẹ́rìí ní Malta. Ní June 7, 1947, láì jẹ́ kí àbúrò bàbá mi mọ̀, mo ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ àyíká ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Wolf Point. Níbẹ̀ ni Kristian arákùnrin kan tí késí mi láti di aṣáájú-ọ̀nà, tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti lo ìgbésí-ayé mi ní irú ọ̀nà yẹn jẹ́ ìfẹ́-ọkàn mi, mo ṣàlàyé pe àbúrò bàbá mi kò lè gbà mí láyè láé láti ya àkókò púpọ̀ bẹ́ẹ̀ sọ́tọ̀ fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, àbúrò bàbá mi já lẹ́tà tí ọ̀rẹ́ mí kan tí ó rọ̀ mí láti di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kọ sí mi ó sì kà á. Inú rẹ̀ ru, bàbá mi sì fún mi ní ìpinnu àfòtélé—jáwọ́ nínú wíwàásù tàbí kí o jáde. Ìpinnu àfòtélé náà jẹ́ ohun tí ó dára nítorí pé mo nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ àgbẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí n kò fi mọ̀ bóyá ǹ bá ti kúrò níbẹ̀ fúnra mi. Nítorí náà mo padà sọ́dọ̀ ìdílé mi ní Minnesota, gbogbo wọn ti ṣe ìrìbọmi báyìí wọ́n sì ti ń darapọ̀ mọ́ Ìjọ Detroit Lakes.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìdílé mi fún mi ní ìṣírí láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà, ṣùgbọ́n ní 1948 ìtara wọn nípa tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ sí dínkù. Ìgbà yẹn ní ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Ìtẹ̀síwájú dé Ìdàgbàdénú Tàbí Ìfàsẹ́yìn Sínú Ẹ̀ṣẹ̀, Èwo Ni?” pèsè ìṣírí tẹ̀mí tí mo nílò. Ó kìlọ̀ pé “ó dájú pé àwọn àbájáde bíbaninínújẹ́ ni yóò tẹ̀lé e bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ tí ń tẹ̀síwájú.” Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà sọ pé: “A kò lè dúró gbagidi kí a sì máa jórẹ̀yìn láìpa ara wa lára, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀síwájú nínú òdodo. Títẹ̀síwájú, láìdúró, ni ìgbéjàkò títóbi jù lòdì sí fífàsẹ́yìn.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé mi wá àwọn àwáwí mìíràn, mo gbàgbọ́ pé ìṣòro wọn gan-an ni ìfẹ́-ọkàn láti di ọlọ́rọ̀. Wọ́n ti rí àǹfààní ọrọ̀-ajé tí ó wà nínú lílo àkókò púpọ̀ nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ kí wọ́n sì lo díẹ̀ fún wíwàásù. Dípò kí n gbà kí ìfẹ́-ọkàn fún ọrọ̀ ré mi lọ, mo wéwèé láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Mo mọ̀ pé kò lè rọrùn, kódà mo tilẹ̀ ronú pé n kò ní lè ṣe é. Nítorí náà ní 1948, mo dán ara mi wò nípa mímọ̀ọ́mọ̀ pinnu láti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú-ọ̀nà nínú apá tí ó burú jùlọ nínú ọdún—December.

Títẹ́wọ́gba Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà

Jehofa bùkún ìsapá mi. Fún àpẹẹrẹ, ní ọjọ́ kan ipò ojú-ọjọ́ jẹ́ ìwọ̀n 27 sí ìsàlẹ̀ òdo lórí ìwọ̀n Celsius, láìka ìtutù ti afẹ́fẹ́ sí. Mo wà lẹ́nu iṣẹ́ ìjẹ́rìí òpópó-ọ̀nà mi gẹ́gẹ́ bí mo ti máa ń ṣe, mo ń pààrọ̀ ọwọ́ mi léraléra—mo ń ki èyí tí ó ti tutù bọnú àpò bí mo ti ń fi ọwọ́ kejì gbá ìwé ìròyìn mú tí ìyẹn yóò fi gan kí òun náà baà lè wọnú àpò. Ọkùnrin kan tọ̀ mí wá. Ó sì sọ̀rọ̀ pé òun ti ń ṣàkíyèsí ìgbòkègbodò mi fún ìgbà díẹ̀, ó béèrè pé: “Kí ni ó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyẹn tí ó ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀? Fún mi ní méjì yẹn kí n baà lè kà wọ́n.”

Láàárín àkókò náà, mo ń rí i pé kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ìdílé mi ń fi ipò tẹ̀mí mi sínú ewu, nítorí náà nítorí pé mo béèrè fún un lọ́dọ̀ Watch Tower Society, a fún mi ni iṣẹ́-àyànfúnni titun, ní Miles City, Montana. Mo ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ìjọ níbẹ̀, èyí tí a wá mọ̀ sí alábòójútó olùṣalága báyìí. Mo ń gbé nínú ilé alágbèérìn kan tí ó jẹ́ mítà méjì níbùú àti mẹ́ta lóròó, mo ń gbọ́ bùkátà ara mi ni ṣíṣe iṣẹ́ àgbàfọ̀ bí àbọ̀ṣẹ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan a máa ń pè mí fún ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí jùlọ—ìkórè.

Lákòókò yìí, mo ń gbọ́ nípa bí ipò ìdílé mi ṣe burú síi nípa tẹ̀mí. Níkẹyìn àwọn, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú nínú Ìjọ Detroit Lakes, kẹ̀yìn sí ètò-àjọ Jehofa. Lára àwọn akéde Ìjọba 17 tí ó wà ní ìjọ náà, kìkì 7 ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́. Ìdílé mi pinnu láti rí i pé mo jáde kúrò nínú ètò-àjọ Jehofa pẹ̀lú, nítorí náà mo rí i pé ojútùú kanṣoṣo ni ó wà, láti túbọ̀ tẹ̀síwájú síi. Ṣùgbọ́n báwo ni n óò ṣe ṣe é?

Lílépa Iṣẹ́-Ìsìn Míṣọ́nnárì

Nígbà àpéjọpọ̀ àgbáyé ní New York City ní 1950, mo fojú rí ìkẹ́kọ̀ọ́yege àwọn akẹ́kọ̀ọ́ míṣọ́nnárì láti kíláàsì kẹẹ̀ẹ́dógún ti Watchtower Bible School of Gilead. Mo ronú pé, ‘Óò, ká ní ó lè ṣeé ṣe fún èmi náà láti wà lára àwọn wọnnì tí ń ṣiṣẹ́sin Jehofa ní ilẹ̀ àjèjì.’

Mo fìwé ìwọlé-ẹ̀kọ́ ránṣẹ́ a sì tẹ́wọ́gbà mí gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ḿbà kíláàsì kẹtàdínlógún ti Gileadi, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní February 1951. Ọ̀gangan ibi tí a kọ ilé-ẹ̀kọ́ náà sí ní oko kan tí ó wà ní òkè New York má rẹwà o. Ẹ wo bí ó ṣe wù mí tó láti máa ṣiṣẹ́ ní oko náà lẹ́yìn tí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ bá ti parí, bóyá nínú gàá àwọn màlúù tàbí níta níbi tí àwọn irè-oko wà! Ṣùgbọ́n John Booth, alábòójútó Oko Ìjọba nígbà yẹn, ṣàlàyé pé èmi nìkanṣoṣo ni ó ní ìrírí nínú iṣẹ́ àgbàfọ̀ nígbà yẹn. Nítorí náà a yàn mí láti máa ṣe iṣẹ́ yẹn.

Gileadi kò rọrùn fún ẹnì kan tí ó ka kìkì ìpele ẹ̀kọ́ karùn-ún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé agogo 10:30 alẹ́ ni a máa ń paná, mo sábà máa ń kẹ́kọ̀ọ́ títí ti ọ̀gànjọ́ òru. Ní ọjọ́ kan ọ̀kan lára àwọn adánilẹ́kọ̀ọ́ pè mí lọ sínú ọ́fíìsì rẹ̀. Ó wí pé, “Carl, mo rí i pé àwọn máàkì rẹ̀ kò dára tó.”

Mo ronú nínú ara mi pé: ‘Págà, wọn óò ní kí n máa lọ sílé ni.’

Bí ó ti wù kí ó rí, adánilẹ́kọ̀ọ́ náà fi tìfẹ́tìfẹ́ fún mi ní ìmọ̀ràn lórí bí mo ṣe lè lo àkókò mi lọ́nà tí ó dára jùlọ láì jẹ́ pé mo ń kàwé títí di òru. Tẹ̀rùtẹ̀rù ni mo fi béèrè pé: “Mo ha tóótun tó láti máa bá a nìṣó ní Gileadi níhìn-ín bí?”

Ó fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ni. Ṣùgbọ́n n kò mọ̀ bóyá ìwọ yóò lè tóótun fún gbígba dípúlọ́mà.”

Ọ̀rọ̀ ààrẹ ilé-ẹ̀kọ́ náà, Nathan H. Knorr, tù mí nínú. Ó ti sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣáájú pé máàkì kò wú òun lórí bí “ànímọ́ arọ̀mọ́-nǹkan-típẹ́típẹ́” ti àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n bá dúró síbi iṣẹ́-àyànfúnni wọn.

Ẹ̀kọ́ tí ó nira fún mi jùlọ ni èdè Spanish, ṣùgbọ́n mo ń retí pé Alaska ni iṣẹ́-àyànfúnni mi yóò jẹ́, níbi tí òtútù rẹ̀ ti mọ́ mi lára nígbà tí mo ṣì wà nílé. Yàtọ̀ sí ìyẹn, n óò tún lè wàásù ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Nítorí náà ìwọ lè finúro bí ìyàlẹ́nu mi yóò ṣe tó nígbà tí a de ìdajì ìtòlẹ́ṣẹẹsẹ ẹ̀kọ́ náà, tí mo ri Ecuador, South America, gbà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́-àyànfúnni mi. Bẹ́ẹ̀ni, mo níláti máa sọ èdè Spanish, tí ó sì tún jẹ́ ibi tí ooru ti mú gan-an!

Ní ọjọ́ kan aṣojú ilé-iṣẹ́ òtẹlẹ̀múyẹ́ ti FBI kan bẹ̀ mí wò ní Ilé-Ẹ̀kọ́ Gileadi. Ó béèrè ọmọkùnrin ìránṣẹ́ ìjọ tí ó ti fi ètò-àjọ wa sílẹ̀ ní Detroit Lakes. Ogun Korea ń lọ lọ́wọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin yìí sì jẹ́wọ́ pé òun jẹ́ òjíṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa a sì tipa bẹ́ẹ̀ yọ̀ọ̀da rẹ̀ kúrò nínú iṣẹ́ ológun. Mo ṣàlàyé pé kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ́. Bí aṣojú náà ṣe ń dágbére fún mi, ó wí pé: “Kí Ọlọrun bùkún fún ọ nínú iṣẹ́ rẹ̀.”

Lẹ́yìn náà mo gbọ́ pé a pa ọ̀dọ́mọkùnrin náà nínú ìjà rẹ̀ àkọ́kọ́ ní Korea. Ẹ wo irú àbájáde búburú tí ó jẹ́ fún ẹnì kan tí ìbá ti tẹ̀síwájú dé ìdàgbàdénú nínú ètò-àjọ Ọlọrun!

Paríparí rẹ̀, ọjọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́yege wa alárinrin dé ní July 22, 1951. Àmọ́ ṣáá o, kò sí èyíkéyìí lára ìdílé mi tí ó wá, ṣùgbọ́n ìdùnnú-ayọ̀ mi pé pérépéré nígbà tí mo gbà ìwé-ẹ̀rí dípúlọ́mà nítorí ìlọsíwájú tí mo ti ní.

Mímú Ara Mi Bá Pápá Ilẹ̀ Àjèjì Mu

Nígbà kan mo wà lẹ́nu iṣẹ́-àyànfúnni mi, mo rí i pé ẹ̀kọ́ tí Màmá fún mi wúlò. Gbígbọ́únjẹ, fífọwọ́ fọṣọ, àti àìsí omi ẹ̀rọ kò jẹ́ ohun titun sí mi. Ṣùgbọ́n fífi èdè Spanish wàásù jẹ́ bẹ́ẹ̀! Mo lo ìwàásù tí a tẹ̀ lédè Spanish fún ìgbà díẹ̀. Ó gba ọdún mẹ́ta kí n tó lè sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn ní èdè Spanish ìyẹn sì jẹ́ pẹ̀lú lílo àkọsílẹ̀ rẹpẹtẹ.

Nígbà tí mo dé sí Ecuador ní 1951, iye tí ó dín sí 200 akéde Ìjọba ni ó wà níbẹ̀. Sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn dàbí èyí tí ó falẹ̀ fún ọdún 25 àkọ́kọ́ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli wa yàtọ̀ gédégédé sí ti àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti ìsìn Katoliki tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, ní pàtàkì bí a sì ṣe dìrọ̀ mọ́ ìtọ́ni Bibeli lórí ìṣòtítọ́ sí alábàáṣègbéyàwó kan jẹ́ ohun tí kò gbajúmọ̀.—Heberu 13:4.

Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wa láti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli sóde. Iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa ní Machala, tí ó wà ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ tí ó dára fún ṣíṣọ̀gbìn ọ̀gẹ̀dẹ̀, ṣèrànwọ́ láti ṣàlàyé èyí. Èmi àti Nicholas Wesley nìkan ní Ẹlẹ́rìí tí ó wà níbẹ̀ nígbà tí a débẹ̀ ní 1956. A óò jí ní òwúrọ̀ kùtù láti lè bá ọkọ̀ akóyọyọ tí a ń lò ní àwọn ọ̀nà márosẹ̀ tí a ń ṣe nígbà yẹn lọ́hùn-ún rìn. Lẹ́yìn tí a bá ti bá a rìn díẹ̀, a óò bọ́ sílẹ̀ tí a óò sì jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ lójú ọ̀nà padà sí ibi tí a ń gbé.

Ní ọjọ́ kan báyìí, èmi àti Nick ń ṣàkọsílẹ̀ láti lè mọ ẹni tí yóò fi ìwé ìròyìn síta jùlọ. Mo rántí pé tèmi ju ti Nick lọ ní ọjọ́kanrí, ṣùgbọ́n nígbà tí yóò fi di ìrọ̀lẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti fi 114 síta. A ń fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwé ìròyìn wa sílẹ̀ lóṣooṣù sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn wa. Ìgbà mẹ́fà ni mo fi ìwé ìròyìn tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan sóde láàárín oṣù kan. Ronú nípa iye àwọn tí yóò tipa àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyẹn kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bibeli!

Ní Machala a tún ní àǹfààní kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ ti ìjọ tí ń bẹ ní Ecuador. Ìyẹn jẹ́ ní ọdún 35 sẹ́yìn, ní 1960. Ní àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ wọ̀nyẹn, nǹkan bí ẹni 15 péré ni wọ́n ń wá sí àwọn ìpàdé wa. Lónìí Machala ní ìjọ 11 tí ń gbèrú!

Bíbẹ United States Wò

Ní apá ìparí àwọn ọdún 1970, mo padà lọ sí United States fún àkókò ìsinmi mo sì lo wákàtí díẹ̀ pẹ̀lú Frank ẹ̀gbọ̀n mi. Ó fi ọkọ̀ rẹ̀ gbé mi lọ sí orí òkè kékeré kan láti ibi tí a ti lè máa wo ọ̀nà tí ó gba Àfonífojì Odò Red kọjá. Àwọn ọkà tí ó ti ń pọ́n tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lẹlẹ, oko àlìkámà rẹpẹtẹ tí ó ti pọn tí ó soríkọ́, tí ó fi hàn pé ìkórè rẹpẹtẹ yóò wáyé, mú kí ó wuni. Lọ́ọ̀ọ́kán a lè rí Odò Sheyenne tí a gbin igi sí eteetí rẹ̀. Ìjíròrò ẹ̀gbọ́n mi bẹ́gidí ìgbádùn ẹwà títunilára náà.

“Ká ní o kì í ṣe òmùgọ̀ tí ń gbé ní South America ni, èyí náà ìbá ti jẹ́ tìrẹ!”

Kíá ni mo fèsì pé: “Frank, ó tó ọ gẹ́ẹ́.”

Kò sọ ọ̀rọ̀ mìíràn mọ́. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, àrùn rọpárọsẹ̀ pa á, ó sì fi oko ẹran pípinminrin mẹ́ta ní North Dakota sílẹ̀ lọ pẹ̀lú hectare ilẹ̀ tí ó lé ní 400, bákan náà sì ni 260 hectare oko tí ó jẹ́ ti ẹ̀gbọ́n mi ní Montana èyí tí òun ti jogún rẹ̀.

Wàyí o gbogbo ìdílé mi ti dolóògbé. Ṣùgbọ́n inú mi dùn pé ní Detroit Lakes, níbi tí gbogbo wa ti bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, mo ní ìdílé tẹ̀mí tí ó ju 90 àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin lọ.

Bíbá A Nìṣó Láti Máa Tẹ̀síwájú Nípa Tẹ̀mí

Àwọn ọdún 15 tí ó kẹ́yìn ti so èso rẹpẹtẹ nínú ìkórè tẹ̀mí níhìn-ín ní Ecuador. Láti orí akéde Ìjọba tí wọ́n jẹ́ 5,000 ní 1980, a ní iye tí ó lé ní 26,000 nísinsìnyí. Mo ti ká èso ìbùkún tí ń wá láti inú ríran iye tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún lára àwọn wọ̀nyí lọ́wọ́ láti ṣe ìrìbọmi.

Wàyí o, ní ẹni 80 ọdún, mo túbọ̀ ń ṣiṣẹ́ kára láti lè ní 30 wákàtí ní oṣù kan nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ ju bí mo ti ṣe lọ láti lè rí 150 wákàtí tí a ń béèrè lọ́wọ́ mi ní 1951. Láti 1989, tí mo ti gbọ́ pé mo ní àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀yà ara tí ń sun omi jáde lókè àpò-ìtọ̀, mo ti lo àǹfààní àkókò ìkọ́fẹpadà mi láti kàwé. Láti ọdún yẹn, mo ti ka Bibeli tán nígbà 19 àti ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom nígbà 6. Ọ̀nà yìí ni mo ń gbà tẹ̀síwájú síi nípa tẹ̀mí.

Bẹ́ẹ̀ni, mo ti ní àǹfààní láti ká àwọn èrè nípa ti ara ní ilẹ̀-oko ti United States. Ṣùgbọ́n àwọn èrè ọrọ̀ ti ara kò jámọ́ nǹkankan bí a bá fiwéra pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀ ti mo ti ní ìrírí rẹ̀ nínú ìkórè tẹ̀mí. Ẹ̀ká níhìn-ín ní Ecuador fi tó mi létí pé mo ti fi ìwé ìròyìn tí ó lé ní 147,000 sóde àti ìwé ńlá tí ó lé ní 18,000 nínú iṣẹ́-ìgbésí-ayé míṣọ́nnárì mi. Mo ka àwọn wọ̀nyí sí àwọn irúgbìn tẹ̀mí, èyí tí ọ̀pọ̀ nínú wọn ti hù; àwọn mìíràn ṣì lè hù nínú ọkàn-àyà àwọn ènìyàn bí wọ́n bá ṣe ń kà nípa àwọn òtítọ́ Ìjọba wọ̀nyí.

Èmi kò lè ronú lórí ohun mìíràn ju títẹ̀síwájú nìṣó títí wọnú ayé titun Ọlọrun pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ mi nípa tẹ̀mí àti àràádọ́ta àwọn mìíràn tí wọ́n ti yàn láti ṣiṣẹ́sin Ọlọrun wa, Jehofa. Owó kì yóò lè gbanilà jálẹ̀ òpin ayé búburú yìí. (Owe 11:4; Esekieli 7:19) Bí ó ti wù kí ó rí, èso iṣẹ́ wa nípa tẹ̀mí yóò máa bá a nìṣó—bí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá ń bá a nìṣó láti máa tẹ̀síwájú dé ìdàgbàdénú.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Mo ṣetán láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní Miles City, Montana, ní 1949

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Mo ń ra omi fún ilé míṣọ́nnárì wa, 1952

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Wíwàásù ní Machala, ní 1957

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Láti ìgbà tí mo ti dùbúlẹ̀ àìsàn ní 1989, mo ti ka Bibeli tán nígbà 19

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́