Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Sweden
SWEDEN wà ní apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Scandinavia tí omi yíká ó sì tàn kálẹ̀ kọjá Arctic Circle. Ó lókìkí kárí ayé nítorí igbó rẹ̀ títutùyọ̀yọ̀ tí ó dí kìjikìji bákan náà sì ni àwọn adágún, àti àwọn òkè-ńlá rẹ̀, Sweden jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè Europe tí àwọn olùgbé rẹ̀ kò tó nǹkan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń wá àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ rí níbẹ̀ pẹ̀lú àṣeyọrí bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ọdún tí ó kẹ́yìn 1800. Gbé àpẹẹrẹ àìpẹ́ yìí kan yẹ̀wò.
Obìnrin kan kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí, ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ kò nífẹ̀ẹ́ sí èyí. Ó sọ fún ìyàwó rẹ̀ láti dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ọkùnrin yìí ń ṣiṣẹ́ ní ilé tí a ń kó ohun tí wọ́n fi ń pọn ọtí sí. Ní ọjọ́ kan awakọ̀ ọkọ̀ akẹ́rù kan wá sí ilé ìkẹ́rùsí náà pẹ̀lú ọmọ-ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ọlọ́dún mẹ́wàá. Bàbá àgbà náà ní kí ọkùnrin náà máa bá òun wo ọmọkùnrin náà nígbà tí òun ń kó ẹrù sínú ọkọ̀. Kí ó wulẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀, ọkùnrin náà béèrè lọ́wọ́ ọmọkùnrin náà pé ẹ̀bùn wo ni ó rí gbà fún ọjọ́-ìbí rẹ̀ àìpẹ́. Sí ìyàlẹ́nu ọkùnrin náà, ọmọkùnrin náà sọ fún un pé òun àti ìdílé òun kì í ṣe ayẹyẹ ọjọ́-ìbí nítorí àwọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ọmọkùnrin náà tún sọ fún un pé òun máa ń gba ẹ̀bùn ní àwọn ìgbà mìíràn nínú ọdún òun kò sì pàdánù ohunkóhun, níwọ̀n bí òun ti ní ìdílé tí ó lọ́yàyà tí ó sì nífẹ̀ẹ́. Ó fikún un pé, kò sí ẹ̀bùn tí ó níyelórí tí ó tó èyí.
Ọmọkùnrin náà padà lọ pẹ̀lú bàbá rẹ̀ àgbà ní ìgbà mélòókan. Ní gbogbo ìgbà, ọkùnrin náà yóò béèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè lọ́wọ́ ọmọkùnrin náà, ọ̀nà tí ọmọkùnrin náà ń gbà fún un ní ìdáhùn tí ó jẹ́ aláìlábòsí, tí ó ṣe tààràtà láìlọ́tìkọ̀ wú u lórí púpọ̀. Ìmọrírì ọmọkùnrin náà fún ìníyelórí òtítọ́ ru ìmọ̀lára rẹ̀ sókè. Ní alẹ́ ọjọ́ kan lẹ́yìn tí ọkùnrin náà ti wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n kan tí ń fi ipò tí ń bani nínú jẹ́ nínú ayé hàn, ó rí i pé òun níláti ṣe ìwádìí àwọn ohun ti ẹ̀mí ní ọ̀nà tí ó ṣe pàtàkì síi. Ó tẹ Ẹlẹ́rìí tí ó ti bá aya rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀ láago ó sì ní kí ó padà wá. Láìpẹ́, Ẹlẹ́rìí kan ń bá ọkùnrin náà ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ó sì tẹ̀síwájú lọ́nà tí ó yá kánkán. Ó ṣe ìrìbọmi ní April 10, 1994. Ìyàwó rẹ̀ ti ṣe ìrìbọmi nísinsìnyí pẹ̀lú.
Ìdàgbàsókè Ń Béèrè Ìkọ́lé
Sweden jẹ́ ilé fún ọ̀pọ̀ àwọn olùwá-ibi-ìsádi láti àwọn ilẹ̀ mìíràn, àwọn Ẹlẹ́rìí ní Sweden sì rí ìyọrísí rere láti inú wíwàásù fún wọn. Ní gbogbogbòò iṣẹ́ náà ti ní irú àṣeyọrí báyìí débi pé àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba titun ni a nílò síi láti lè pèsè àyè fún ìgbòòrò náà. Láti 1986 si 1993, Gbọ̀ngàn Ìjọba 37 ni a kọ́ nípa ọ̀nà ìgbàkọ́lé kíákíá, nígbà tí a mú gbọ̀ngàn 8 mìíràn gbòòrò síi tí a sì ṣàtúnṣe wọn. Ní 1994 nìkan, Gbọ̀ngàn Ìjọba méje ni a kọ́ ní àfikún, a sì tún àwọn mẹ́ta ṣe.
Ní báyìí, ìjọ 65 ni ó ń retí ìrànlọ́wọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba titun tàbí láti mú èyí tí wọ́n ń lò nísinsìnyí gbòòrò síi tàbí láti ṣàtúnṣe rẹ̀. Àwọn 2,500 olùyọ̀ọ̀da ara-ẹni ni ó ń ṣèrànlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé bẹ́ẹ̀, àwọn ìjọ sì mọrírì ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ wọn gidigidi.
Nígbà mìíràn àríwá Sweden, tí ó tàn kálẹ̀ kọjá Arctic Circle, ni a máa ń pè ní ilẹ̀ oòrùn òrugànjọ́. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé láàárín apákan ìgbà ẹ̀rùn oòrùn kì í wọ̀ rárá níbẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, jákèjádò Sweden, ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ síi. Pẹ̀lú ìbùkún Jehofa, ìmọ́lẹ̀ ti ẹ̀mí yẹn kì yóò ṣe bàìbàì ṣùgbọ́n yóò máa báa lọ láti máa tàn yòò síwájú àti síwájú síi.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ NÍPA ORÍLẸ̀-ÈDÈ
Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1994
GONGO IYE ÀWỌN TÍ Ń JẸ́RÌÍ: 24,246
ÌṢIRÒ-ÌFIWÉRA: Ẹlẹ́rìí 1 sí 362
ÀWỌN TÍ Ó PÉSẸ̀ SÍBI ÌṢE-ÌRÁNTÍ: 40,372
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN TÍ WỌ́N JẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ: 2,509
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BIBELI: 11,306
IYE TÍ A BATISÍ: 850
IYE ÀWỌN ÌJỌ: 358
Ọ́FÍÌSÌ Ẹ̀KA: ARBOGA
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọ́fíìsì ẹ̀ka àti Ilé Beteli ní Arboga
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Ẹlẹ́rìí àkọ́kọ́ ní Hjo lo bọ́ọ̀sì kékeré yìí láti kárí àgbègbè ìpínlẹ̀ iṣẹ́ tí ó tó 5,000 kìlómítà níbùú-lóòró