ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 6/1 ojú ìwé 6-10
  • Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé A Ń kẹ́dùn, A Kò Wà Láìní Ìrètí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé A Ń kẹ́dùn, A Kò Wà Láìní Ìrètí
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ikú Di Apákan Ìdílé Ẹ̀dá Ènìyàn
  • Àwọn Olùṣòtítọ́ Tí Wọ́n Kẹ́dùn
  • Ẹ̀dùn-Ọkàn Nígbà Ayé Jesu
  • Ìrètí Wo Ni Ó Wà fún Àwọn Òkú?
  • Ìrànlọ́wọ́ Tí Ó Gbéṣẹ́ fún Àwọn Tí Ń Kẹ́dùn
  • Ojúlówó Ìrètí Fáwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Olólùfẹ́ Wa Tí Wọ́n Ti Kú?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Ìrètí Tí Ó Dájú fún Àwọn Òkú
    Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
  • Ǹjẹ́ Ó Burú Kéèyàn Máa Ṣọ̀fọ̀?
    Jí!—2001
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 6/1 ojú ìwé 6-10

Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé A Ń kẹ́dùn, A Kò Wà Láìní Ìrètí

“Awa kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nipa awọn wọnnì tí wọ́n ń sùn ninu ikú; kí ẹ má baà kárísọ gan-an gẹ́gẹ́ bí awọn yòókù tí kò ní ìrètí ti ń ṣe pẹlu.”—1 TESSALONIKA 4:13.

1. Kí ni ẹ̀dá ènìyàn ń ní ìrírí rẹ̀ láti ìgbà dé ìgbà?

O HA ti pàdánù ẹnì kan tí o fẹ́ràn nínú ikú bí? Láìka ọjọ́ orí sí, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú wa ni ìpàdánù ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ kan ti bà nínú jẹ́. Bóyá òbí wa àgbà, òbí wa, ẹnìkejì wa nínú ìgbéyàwó, tàbí ọmọ. Ọjọ́ ogbó, àìsàn, àti jàm̀bá máa ń fa ikú nígbà gbogbo. Ìwà ọ̀daràn, ìwà-ipá, àti ogun máa ń dákún ìṣẹ́ àti ẹ̀dùn-ọkàn náà. Lọ́dọọdún yíká ayé, ìpíndọ́gba iye tí ó lé ní 50 million ènìyàn ní ń kú. Ìpíndọ́gba ojoojúmọ́ ní 1993 jẹ́ 140,250. Ẹ̀dùn-ọkàn tí ikú ń fà ń nípa lórí àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé, ìmọ̀lára òfò sì máa ń ga gan-an.

2. Kí ni ohun tí kò bá ìwà-ẹ̀dá mu nípa ikú àwọn ọmọdé?

2 Kò ha yẹ kí a bá àwọn òbí kan ní California, U.S.A., dárò, àwọn tí wọ́n pàdánù ọmọbìnrin wọn aboyún nínú ìṣẹ̀lẹ̀ bíbaninínújẹ́ jàm̀bá òjijì ti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan? Lẹ́ẹ̀kan náà, wọ́n pàdánù ọmọbìnrin wọn kanṣoṣo àti ìkókó tí ìbá jẹ́ ọmọ-ọmọ wọn àkọ́kọ́. Ọkọ obìnrin tí ó kàgbákò náà pàdánù ìyàwó àti ọmọ tí ìbá jẹ́ àkọ́bí rẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin. Kì í ṣe ohun tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu pé kí àwọn òbí pàdánù ọmọ, bóyá ó ṣì kéré tàbí ó ti dàgbà. Kò bá ìwà ẹ̀dá mu pé kí àwọn ọmọ kú ṣáájú àwọn òbí wọn. Gbogbo wa nífẹ̀ẹ́ ìwàláàyè. Nítorí náà, dájúdájú ikú jẹ́ ọ̀tá.—1 Korinti 15:26.

Ikú Di Apákan Ìdílé Ẹ̀dá Ènìyàn

3. Báwo ni ikú Abeli ṣe lè ti nípa lórí Adamu àti Efa?

3 Ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ti ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba fún nǹkan bí ẹgbàata ọdún ti ọ̀rọ̀-ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìṣọ̀tẹ̀ àwọn òbí ẹ̀dá ènìyàn wa àkọ́kọ́, Adamu àti Efa. (Romu 5:14; 6:12, 23) Bibeli kò sọ fún wa bí wọ́n ṣe hùwàpadà sí ìṣìkàpa ọmọkùnrin wọn Abeli láti ọwọ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Kaini. Fún ìdí tí ó ju ẹyọ kan lọ, ó ti níláti jẹ́ ìrírí tí ó mú wọn banújẹ́. Níhìn-ín yìí, fún ìgbà àkọ́kọ́, wọ́n dojúkọ ìjótìítọ́ ikú ẹ̀dá ènìyàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, èyí tí ó hàn lójú ọmọkùnrin àwọn fúnra wọn. Wọ́n rí èso ìṣọ̀tẹ̀ wọn àti ti bíbá a lọ tí wọ́n ń bá a lọ láti máa ṣi òmìnira ìfẹ́-inú lò. Láìka ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sí, Kaini yàn láti jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó ṣekúpa arákùnrin rẹ̀. A mọ̀ pé ikú Abeli ti níláti mú ìmọ̀lára ìbànújẹ́ wá fún Efa gan-an nítorí pé nígbà tí ó bí Seti, ó wí pé: “Ọlọrun yan irú-ọmọ mìíràn fún mi ní ipò Abeli tí Kaini pa.”—Genesisi 4:3-8, 25.

4. Èéṣe tí àròsọ àtọwọ́dọ́wọ́ ti àìleèkú ọkàn kò fi lè jẹ́ ìtùnú lẹ́yìn ikú Abeli?

4 Àwọn òbí wa ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ bákan náà rí ìjótìítọ́ ìdájọ́ ìjìyà tí Ọlọrun fún wọn—pé bí wọ́n bá ṣọ̀tẹ̀ tí wọ́n sì ṣàìgbọràn, wọn “óò kú.” Láìka irọ́ Satani sí, dájúdájú àròsọ àtọwọ́dọ́wọ́ ti àìleèkú ọkàn kò tíì jẹ jáde síbẹ̀, nítorí náà wọn kò lè rí ìtùnú èké kankan láti inú ìyẹn. Ọlọrun ti sọ fún Adamu pé: “Ìwọ óò . . . padà sí ilẹ̀; nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá, erùpẹ̀ sá ni ìwọ, ìwọ óò sì padà di erùpẹ̀.” Òun kò mẹ́nu kan ìwàláàyè ọjọ́-ọ̀la kan gẹ́gẹ́ bí àìleèkú ọkàn ní ọ̀run, hẹ́ẹ̀lì, Líḿbò, pọ́gátórì, tàbí níbikíbi mìíràn. (Genesisi 2:17; 3:4, 5, 19) Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkàn tí ó wàláàyè tí ó sì ti ṣẹ̀, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ Adamu àti Efa yóò kú wọn kì yóò sì máa bá a lọ láti wàláàyè. A mí sí Ọba Solomoni láti kọ̀wé pé: “Alààyè mọ̀ pé àwọn óò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan, bẹ́ẹ̀ni wọn kì í ní èrè mọ́; nítorí ìrántí wọn ti di ìgbàgbé. Ìfẹ́ wọn pẹ̀lú, àti ìríra wọn, àti ìlara wọn, ó parun nísinsìnyí; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì ní ìpín mọ́ láéláé nínú ohun gbogbo tí a ń ṣe lábẹ́ oòrùn.”—Oniwasu 9:5, 6.

5. Kí ni ìrètí tòótọ́ fún àwọn òkú?

5 Ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ti jẹ́ òtítọ́ tó! Nítòótọ́, ta ni rántí àwọn babańlá ti igba ọdún tàbí ọ̀ọ́dúnrún ọdún sẹ́yìn mọ́? Ní ọ̀pọ̀ ìgbà àwọn ibojì wọn pàápàá ni a kò mọ̀ tàbí tí a ti patì tipẹ́tipẹ́. Èyí ha túmọ̀ sí pé kò sí ìrètí kankan fún àwọn tí a fẹ́ràn tí wọ́n ti kú bí? Rárá, kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Marta wí fún Jesu nípa ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Lasaru, tí ó kú pé: “Mo mọ̀ pé yoo dìde ninu àjíǹde ní ìkẹyìn ọjọ́.” (Johannu 11:24) Àwọn Heberu gbàgbọ́ pé Ọlọrun yóò jí àwọn òkú dìde ní àkókò kan ní ọjọ́ iwájú. Síbẹ̀, ìyẹn kò dí wọn lọ́wọ́ kíkẹ́dùn nítorí pípàdánù ẹnì kan tí wọ́n fẹ́ràn.—Jobu 14:13.

Àwọn Olùṣòtítọ́ Tí Wọ́n Kẹ́dùn

6, 7. Báwo ni Abrahamu àti Jakobu ṣe hùwàpadà sí ikú?

6 Ní nǹkan bí ẹgbàajì ọdún sẹ́yìn, nígbà tí Sara aya Abrahamu kú, “Abrahamu . . . wá láti ṣọ̀fọ̀ Sara àti láti sọkún rẹ̀.” Olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun náà fi ìmọ̀lára rẹ̀ tí ó jinlẹ̀ hàn nítorí pípàdánù aya rẹ̀ ọ̀wọ́n àti adúróṣinṣin. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ akọni alákíkanjú ọkùnrin, òun kò tijú láti fi ẹ̀dùn-ọkàn rẹ̀ hàn nípasẹ̀ omijé.—Genesisi 14:11-16; 23:1, 2.

7 Ipò ti Jakobu farajọ èyí. Nígbà tí a tàn án jẹ láti gbàgbọ́ pé ọmọkùnrin rẹ̀ Josefu ni ẹranko búburú ti pa, báwo ni ó ṣe hùwàpadà? A kà ní Genesisi 37:34, 35 pé: “Jakobu sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sí ara rẹ̀, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ púpọ̀. Àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin dìde láti ṣìpẹ̀ fún un; ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbìpẹ̀; ó sì wí pé, Nínú ọ̀fọ̀ ni èmi óò sá sọ̀kalẹ̀ tọ ọmọ mi lọ sí isà-òkú. Báyìí ni bàbá rẹ̀ sọkún rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ni, ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá ènìyàn ó sì bá ìwà ẹ̀dá mu láti fi ẹ̀dùn-ọkàn hàn nígbà tí ẹni ti a fẹ́ràn bá kú.

8. Báwo ni àwọn Heberu ṣe sábà máa ń fi ẹ̀dùn-ọkàn wọn hàn?

8 Àwọn kan lè ronú pé nípasẹ̀ ọ̀pá ìdiwọ̀n ti ìgbàlódé àti ti àdúgbò, ìhùwàpadà Jakobu ni a ṣe láṣejù tí ó sì jẹ́ onígbòónára tí ó pọ̀ jù. Ṣùgbọ́n a tọ́ ọ dàgbà ní àkókò tí ó yàtọ̀ àti lábẹ́ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí ó yàtọ̀. Bí o ṣe fi ẹ̀dùn-ọkàn rẹ̀ hàn—ní wíwọ aṣọ ọ̀fọ̀—ni àkọ́kọ́ irú àṣà yìí tí a mẹ́nu kàn nínú Bibeli. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, ṣíṣọ̀fọ̀ ni a tún fi hàn nípa ohùnréré ẹkún, nípa kíkọrin arò, àti nípa jíjókòó sínú eérú. Lórí ìpìlẹ̀ àwọn ẹ̀rí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, àwọn Heberu kì í ṣe àwọn tí kò lè fi ojúlówó ìmọ̀lára wọn hàn nígbà tí wọ́n bá ń fi ẹ̀dùn-ọkàn hàn.a—Esekieli 27:30-32; Amosi 8:10.

Ẹ̀dùn-Ọkàn Nígbà Ayé Jesu

9, 10. (a) Báwo ni Jesu ṣe hùwàpadà sí ikú Lasaru? (b) Kí ni ìṣarasíhùwà Jesu fi hàn wá nípa rẹ̀?

9 Kí ni a lè sọ nípa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu àkọ́kọ́? Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Lasaru kú, àwọn arábìnrin rẹ̀ Marta àti Maria ṣọ̀fọ̀ ikú rẹ̀ pẹ̀lú igbe àti ẹkún. Báwo ni ọkùnrin pípé náà Jesu ṣe hùwàpadà nígbà tí ó dé ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà? Àkọsílẹ̀ Johannu sọ pé: “Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà tí ó sì tajúkán rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé: ‘Oluwa, kání o ti wà níhìn-ín ni, arákùnrin mi kì bá tí kú.’ Nitori naa, Jesu, nígbà tí ó rí i tí ó ń sunkún ati awọn Júù tí wọ́n bá a wá tí wọ́n ń sunkún, ó kérora ninu ẹ̀mí ó sì dààmú; ó sì wí pé: ‘Níbo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?’ Wọ́n wí fún un pé: ‘Oluwa, wá wò ó.’ Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í da omijé.”—Johannu 11:32-35.

10 “Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í da omijé.” Àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ wọ̀nyí sọ igba nípa irú ẹ̀dá ènìyàn tí Jesu jẹ́, ìyọ́nú rẹ̀, àti ìmọ̀lára rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ nípa ìrètí àjíǹde lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, “Jesu sọkún.” (Johannu 11:35, King James Version) Àkọsílẹ̀ náà tẹ̀síwájú nípa sísọ pé àwọn òǹwòran sọ̀rọ̀ àkíyèsí pé: “Ẹ wò ó, ìfẹ́ni tí ó ti ní fún [Lasaru] ti pọ̀ tó!” Dájúdájú, bí ọkùnrin pípé náà Jesu bá sọkún nítorí tí ó pàdánù ọ̀rẹ́ rẹ̀, kì í ṣe ohun ìtìjú bí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣọ̀fọ̀ tí ó sì sọkún lónìí.—Johannu 11:36.

Ìrètí Wo Ni Ó Wà fún Àwọn Òkú?

11. (a) Kí ni a lè kọ́ láti inú àwọn àpẹẹrẹ inú Bibeli nípa ṣíṣọ̀fọ̀? (b) Èéṣe tí a kò kẹ́dùn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí kò ní ìrètí?

11 Kí ni a lè kọ́ láti inú àwọn àpẹẹrẹ inú Bibeli wọ̀nyí? Pé ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá ó sì bá ìwà ẹ̀dá mu láti kẹ́dùn a kò sì níláti tijú láti fi ẹ̀dùn-ọkàn wa hàn. Àní nígbà tí ìrètí àjíǹde bá tilẹ̀ pẹ̀tù sí wa lọ́kàn, ikú ẹnì kan tí a fẹ́ràn ṣì jẹ́ òfò tí ń daniláàmú, tí a ń mọ̀lára gan-an. Ọ̀pọ̀ ọdún, tàbí ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, ti àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ àti ti àjọpín ni ó wá sópin lójijì pẹ̀lú ìbànújẹ́. Nítòótọ́, a kò kẹ́dùn bí àwọn tí kò ní ìrètí tàbí bíi ti àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìrètí èké. (1 Tessalonika 4:13) Bákan náà, a kò ṣì wá lọ́nà nípa àròsọ àtọwọ́dọ́wọ́ kankan ti pé ènìyàn ní àìleèkú ọkàn tàbí pé ó ń ba a lọ láti máa wàláàyè nípa àtúnwáyé. A mọ̀ dájú pé Jehofa ti ṣèlérí ‘àwọn ọ̀run titun ati ilẹ̀-ayé titun kan ninu èyí tí òdodo yoo máa gbé.’ (2 Peteru 3:13) Ọlọrun “yoo . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [wa], ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.

12. Báwo ni Paulu ṣe sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ nípa àjíǹde jáde?

12 Ìrètí wo ni ó wà fún àwọn tí wọ́n ti kú?b Kristian òǹkọ̀wé náà Paulu ni a mí sí láti fún wa ní ìtùnú àti ìrètí nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a óò sọ di asán.” (1 Korinti 15:26) Ìwé The New English Bible sọ pé: “Ọ̀tá ìkẹyìn tí a óò parun ni ikú.” Èéṣe tí ìyẹn fi dá Paulu lójú tóbẹ́ẹ̀? Nítorí pé Jesu Kristi, ẹni tí a jí dìde kúrò nínú òkú, ni ó yí i lọ́kàn padà tí ó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. (Ìṣe 9:3-19) Ìdí nìyẹn bákan náà tí Paulu fi lè sọ pé: “Níwọ̀n bí ikú ti wá nípasẹ̀ ènìyàn kan [Adamu], àjíǹde òkú pẹlu wá nípasẹ̀ ènìyàn kan [Jesu]. Nitori gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú ninu Adamu, bẹ́ẹ̀ pẹlu ni a óò sọ gbogbo ènìyàn di ààyè ninu Kristi.”—1 Korinti 15:21, 22.

13. Báwo ni àwọn ẹlẹ́rìí olùfojúrí ṣe hùwàpadà sí àjíǹde Lasaru?

13 Ẹ̀kọ́ Jesu fún wa ní ìtùnú àti ìrètí tí ó galọ́lá fún ọjọ́ ọ̀la. Fún àpẹẹrẹ, kí ni òun ṣe níti ọ̀ràn Lasaru? Ó lọ sí ibojì níbi ti a ti tẹ́ òkú Lasaru sí fún ọjọ́ mẹ́rin. O gbàdúrà, “nígbà tí ó sì ti wí nǹkan wọnyi, ó ké jáde ní ohùn rara pé: ‘Lasaru, jáde wá!’ Ọkùnrin tí ó ti kú naa jáde wá pẹlu ẹsẹ̀ ati ọwọ́ rẹ̀ tí a fi awọn aṣọ ìdìkú dì, ojú rẹ̀ ni a sì fi aṣọ dì yíká. Jesu wí fún wọn pé: ‘Ẹ tú u ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ.’” Ìwọ ha lè ronúwòye ìyàlẹ́nu àti ayọ̀ tí ó wà lójú Marta àti Maria bí? Ẹ wo bí yóò ti ṣe àwọn aládùúgbò ní kàyéfì tó nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu yìí! Abájọ tí ọ̀pọ̀ lára àwọn òǹwòran fi ní ìgbàgbọ́ nínú Jesu. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn onísìn alátakò rẹ̀ “gbìmọ̀pọ̀ lati pa á.”—Johannu 11:41-53.

14. Àjíǹde Lasaru jẹ́ ìtọ́wò fún kí ni?

14 Jesu ṣe iṣẹ́-ìyanu mánigbàgbé yẹn níṣojú ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí olùfojúrí. Ó jẹ́ ìtọ́wò fún àjíǹde ọjọ́ iwájú tí òun ti sọtẹ́lẹ̀ ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣáájú, nígbà tí ó sọ pé: “Kí ẹnu máṣe yà yín sí èyí, nitori pé wákàtí naa ń bọ̀ ninu èyí tí gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n wà ninu awọn ibojì ìrántí yoo gbọ́ ohùn [ọmọkùnrin Ọlọrun] wọn yoo sì jáde wá, awọn wọnnì tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, awọn wọnnì tí wọ́n sọ ohun bíburú jáì dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.”—Johannu 5:28, 29.

15. Ẹ̀rí wo ni Paulu àti Anania ní fún àjíǹde Jesu?

15 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mẹ́nu kàn án tẹ́lẹ̀, aposteli Paulu gbàgbọ́ nínú àjíǹde. Lórí ìpìlẹ̀ wo? Òun ti jẹ́ Saulu tí ó lókìkí burúkú tẹ́lẹ̀rí, tí ń ṣe inúnibíni sí àwọn Kristian. Orúkọ àti òkìkí rẹ̀ tàn kálẹ̀ láàárín àwọn onígbàgbọ́. Ó ṣetán, kì í ha íṣe òun ni ẹni náà tí ó fọwọ́ sí sísọ Stefanu Kristian ajẹ́rìíkú ní òkúta bí? (Ìṣe 8:1; 9:1, 2, 26) Síbẹ̀, lójú ọ̀nà sí Damasku, Kristi tí a ti jí dìde náà pe orí Saulu wálé, ó sì bu ìfọ́jú lù ú fún ìgbà díẹ̀. Saulu gbọ́ ohùn kan tí ó wí fún un pé: “‘Saulu, Saulu, èéṣe tí iwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?’ Ó wí pé: ‘Ta ni ọ́, Oluwa?’ Ó wí pé: ‘Emi ni Jesu, ẹni tí iwọ ń ṣe inúnibíni sí.’” Lẹ́yìn náà Kristi kan náà tí a jí dìde fún Anania, ẹni tí ń gbé ní Damasku ní ìtọ́ni, láti lọ sí ilé náà níbi tí Saulu ti ń gbàdúrà kí ó sì dá agbára ìríran rẹ̀ padà. Nípa báyìí, láti inú ìrírí ara-ẹni, Saulu àti Anania ní ẹ̀rí tí ó pọ̀ tó láti gbàgbọ́ nínú àjíǹde.—Ìṣe 9:4, 5, 10-12.

16, 17. (a) Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Paulu kò gbàgbọ́ nínú ìpìlẹ̀-èrò Griki nípa àìleèkú ọkàn ti ẹ̀dá ènìyàn tí a jogúnbá? (b) Ìrètí tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ wo ni Bibeli fúnni? (Heberu 6:17-20)

16 Ṣàkíyèsí bí Saulu, aposteli Paulu, ṣe dáhùn nígbà tí, a mú un wá sí iwájú Gómìnà Feliksi gẹ́gẹ́ bí Kristian tí a ṣe inúnibíni sí. A kà ní Ìṣe 24:15 pé: “Mo . . . ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọrun . . . pé àjíǹde awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo yoo wà.” Ó hàn gbangba pé, Paulu kò gbàgbọ́ nínú ìpìlẹ̀-èrò àwọn Griki ti àìleèkú ọkàn ti ẹ̀dá ènìyàn tí a jogúnbá, èyí tí a lérò pé ó ń kọjá sínú ìwàláàyè lẹ́yìn ikú ti àròsọ àtọwọ́dọ́wọ́ tàbí sí ayé àwọn òkú. Ó gbàgbọ́ nínú àjíǹde, ó sì kọ́ àwọn ènìyàn láti gbà á gbọ́. Èyí yóò túmọ̀ sí ẹ̀bùn ìwàláàyè àìleèkú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí ní ọ̀run pẹ̀lú Kristi fún àwọn kan àti fún àwọn tí ó pọ̀ jùlọ ìwàláàyè lẹ́ẹ̀kan síi lórí ilẹ̀-ayé pípé.—Luku 23:43; 1 Korinti 15:20-22, 53, 54; Ìṣípayá 7:4, 9, 17; 14:1, 3.

17 Nípa báyìí Bibeli fún wa ní ìlérí tí ó ṣe kedere àti ìrètí tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ pé nípasẹ̀ àjíǹde, ọ̀pọ̀ ni yóò rí àwọn tí wọ́n fẹ́ràn lẹ́ẹ̀kan síi níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé ṣùgbọ́n lábẹ́ àyíká ipò tí ó yàtọ̀ gan-an.—2 Peteru 3:13; Ìṣípayá 21:1-4.

Ìrànlọ́wọ́ Tí Ó Gbéṣẹ́ fún Àwọn Tí Ń Kẹ́dùn

18. (a) Ohun-èlò tí ó wúlò wo ni a mú jáde ní àwọn Àpéjọpọ̀ “Ìbẹ̀rù Ọlọrun”? (Wo àpótí.) (b) Àwọn ìbéèrè wo ni ó yẹ kí a dáhùn nísinsìnyí?

18 Nísinsìnyí a ní àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ń rántí a sì ní ẹ̀dùn-ọkàn wa. Kí ni a lè ṣe láti la àkókò àdánwò tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ yìí kọjá? Kí ni àwọn mìíràn lè ṣe láti ran àwọn tí ń kẹ́dùn lọ́wọ́? Síwájú síi, kí ni a lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún àwọn olóòótọ́ ọkàn tí a ń bá pàdé nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá wa tí wọ́n wà láìní ìrètí tí ó dájú tí wọ́n sì ń kẹ́dùn? Kí sì ni ìtùnú síwájú síi tí a lè rí fàyọ láti inú Bibeli nípa àwọn tí a fẹ́ràn tí wọ́n ti sùn nínú ikú? Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yóò pèsè àwọn àbá.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìsọfúnni síwájú síi lórí ọ̀fọ̀ ní àkókò Bibeli, wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 2, ojú-ìwé 446 sí 447, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

b Fún ìsọfúnni síwájú síi lórí ìrètí àjíǹde tí a rí nínú Bibeli, wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 2, ojú-ìwé 783 sí 793.

O Ha Lè Dáhùn Bí?

◻ Èéṣe tí a fi lè sọ pé ikú jẹ́ ọ̀tá?

◻ Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun nígbà tí a ń kọ Bibeli ṣe fi ẹ̀dùn-ọkàn wọn hàn?

◻ Ìrètí wo ni ó wà fún àwọn tí a fẹ́ràn tí wọ́n ti kú?

◻ Ìpìlẹ̀ wo ni Paulu ní fún gbígbàgbọ́ nínú àjíǹde?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Ìrànlọ́wọ́ Tí Ó Gbéṣẹ́ fún Àwọn Tí Ń Kẹ́dùn

Ní àwọn Àpéjọpọ̀ “Ìbẹ̀rù Ọlọrun” ti 1994 sí 1995, Watch Tower Society kéde ìmújáde ìwé pẹlẹbẹ titun tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú. Ìtẹ̀jáde tí ń fúnni ní ìṣírí yìí ni a ti ṣe láti mú ìtùnú wá fún àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè gbogbo àti èdè. Bí o ti lè ti rí i, ó pèsè àlàyé Bibeli tí ó rọrùn nípa ikú àti ipò tí àwọn òkú wà. Pàápàá ní pàtàkì, ó tẹnumọ́ ìlérí Ọlọrun ti àjíǹde sí ìyè lórí paradise ilẹ̀-ayé, tí a fọ̀ mọ́, nípasẹ̀ Kristi Jesu. Nítòótọ́ ni ó ń mú ìtùnú wá fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀. Nítorí náà, ó níláti jẹ́ ohun-èèlò kan tí ó wúlò nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian ó sì níláti ṣiṣẹ́ láti ru ọkàn-ìfẹ́ sókè, tí yóò yọrí sí púpọ̀ síi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé. Àwọn ìbéèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan ní a ti fí pẹ̀lú ọgbọ́n fí sínú àwọn àpótí ní apá ìparí ẹ̀ka-ìpín kọ̀ọ̀kan kí àtúnyẹ̀wò tí ó rọrùn lórí àwọn kókó tí a kárí baà lè ṣeé ṣe pẹ̀lú olóòótọ́ ọkàn èyíkéyìí, tí ń ṣọ̀fọ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Nígbà tí Lasaru kú, Jesu sọkún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Jesu jí Lasaru dìde láti inú ikú

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìṣọ̀fọ̀ Àkọ́kọ́, láti ọwọ́ W. Bouguereau, láti inú ojúlówó àwo onígíláàsì ti Photo-Drama of Creation, 1914

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́