Ìrẹ̀lẹ́kún Láti Ọ̀dọ̀ “Ọlọrun Ìtùnú Gbogbo”
“Ìbùkún ni fún Ọlọrun ati Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ati Ọlọrun ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú ninu gbogbo ìpọ́njú wa.”—2 KORINTI 1:3, 4.
1, 2. Irú ìtùnú wo ni àwọn ènìyàn tí ń kẹ́dùn nílò?
ÀWỌN ènìyàn tí ń kẹ́dùn nílò ojúlówó ìtùnú—kì í ṣe òbu-ọ̀rọ̀ àti èyí tí kò ní ìtumọ̀. Gbogbo wa ni a máa ń gbọ́ ‘tí ó bá yá ìwọ yóò gbàgbé,’ ṣùgbọ́n ní gbàrà tí ọ̀fọ̀ náà ṣẹ̀, ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ wo ni irú èrò bẹ́ẹ̀ lè tù nínú? Àwọn Kristian mọ̀ pé Ọlọrun ti ṣèlérí àjíǹde, ṣùgbọ́n ìyẹn kò dènà ìdunni wọra àti ìkìmọ́lẹ̀ ìdààmú ti àdánù òjijì. Ó sì dájú pé bí o bá pàdánù ọmọ kan, àwọn ọmọ yòókù tí wọ́n wàláàyè kò lè rọ́pò èyí tí ó ṣeyebíye náà.
2 Ní àkókò àdánù, ohun tí ó ràn wá lọ́wọ́ jùlọ ni ojúlówó ìtùnú, ìtùnú tí ó ní ìpìlẹ̀ tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ nínú àwọn ìlérí Ọlọrun. A tún nílò ẹ̀mí ìfọ̀ràn-rora-ẹni-wò. Dájúdájú èyí jẹ́ òtítọ́ fún àwọn ará Rwanda, àti ní pàtàkì fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó wà níbẹ̀ tí wọ́n pàdánù àwọn ẹni tí wọ́n fẹ́ràn nínú ìpakúpa bíburú jáì ti àwùjọ ẹ̀yà. Láti ọ̀dọ̀ ta ni gbogbo àwọn tí ń kẹ́dùn ti lè rí ìtùnú gbà?
Jehofa—Ọlọrun Ìtùnú
3. Báwo ni Jehofa ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ niti fífúnni ní ìtùnú?
3 Jehofa ti fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní ti fífún gbogbo wa ní ìtùnú. Ó rán Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo, Kristi Jesu, sí ayé láti fún wa ní ìtùnú àti ìrètí ayérayé. Jesu kọ́ni pé: “Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ ninu rẹ̀ má baà parun ṣugbọn kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Johannu 3:16) Ó tún sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kò sí ẹni kan tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹni kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nitori awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Johannu 15:13) Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn ó sọ pé: “Ọmọkùnrin ènìyàn . . . wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bíkòṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́ kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà kan ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Matteu 20:28) Paulu sì sọ pé: “Ọlọrun dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún ìtẹ́wọ́gbà wa níti pé, nígbà tí awa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Romu 5:8) Nípasẹ̀ ìwọ̀nyí àti ọ̀pọ̀ àwọn ẹsẹ mìíràn, a lóye ìfẹ́ Ọlọrun àti ti Kristi Jesu.
4. Èéṣe tí aposteli Paulu ní pàtàkì fi jẹ Jehofa ní gbèsè?
4 Aposteli Paulu ní pàtàkì mọ̀ nípa inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jehofa. A ti gbà á sílẹ̀ kúrò nínú ipò òkú nípa ti ẹ̀mí, kúrò nínú jíjẹ́ onígbòónára ẹni tí ń ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi sí jíjẹ́ Kristian tí a ń ṣe inúnibíni sí fúnra rẹ̀. (Efesu 2:1-5) Ó ṣàpèjúwe ìrírí ara rẹ̀ pé: “Emi ni mo kéré jùlọ ninu awọn aposteli, emi kò sì yẹ ní ẹni tí a ń pè ní aposteli, nitori mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọrun. Ṣugbọn nípasẹ̀ inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọrun mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́. Inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ tí ó sì wà fún mi kò jásí asán, ṣugbọn mo ṣe òpò púpọ̀ ju gbogbo wọn lọ, síbẹ̀ kì í ṣe emi bíkòṣe inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọrun tí ó wà pẹlu mi.”—1 Korinti 15:9, 10.
5. Kí ni Paulu kọ nípa ìtùnú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun?
5 Lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú nígbà náà, Paulu kọ̀wé pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọrun ati Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ati Ọlọrun ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú ninu gbogbo ìpọ́njú wa, kí awa lè tu awọn wọnnì tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú èyíkéyìí nínú nípasẹ̀ ìtùnú tí Ọlọrun fi ń tu awa tìkára wa nínú. Nitori gan-an gẹ́gẹ́ bí awọn ìjìyà fún Kristi ti pọ̀ gidigidi ninu wa, bẹ́ẹ̀ ni ìtùnú tí a ń rí gbà nípasẹ̀ Kristi pọ̀ gidigidi pẹlu. Wàyí o yálà a wà ninu ìpọ́njú, ó jẹ́ fún ìtùnú ati ìgbàlà yín; tabi yálà a ń tù wa nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín tí ń ṣiṣẹ́ lati mú kí ẹ faradà awọn ìjìyà kan naa tí awa pẹlu ń jìyà. Ati nitori naa ìrètí wa fún yín dúró láìmì, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ nítòótọ́ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti jẹ́ alájọpín awọn ìjìyà naa, ní ọ̀nà kan naa ni ẹ̀yin yoo ṣàjọpín ìtùnú pẹlu.”—2 Korinti 1:3-7.
6. Kí ni ọ̀rọ̀ Griki náà tí a pè ní “ìtùnú” dọ́gbọ́n túmọ̀ sí?
6 Ẹ wo irú àwọn ọ̀rọ̀ tí ń runisókè tí èyí jẹ́! Ọ̀rọ̀ Griki tí a túmọ̀ sí “ìtùnú” níhìn-ín yìí ní ìsopọ̀ ní tààràtà pẹ̀lú “pípeni sí ìhà ọ̀dọ̀ ẹni.” Nítorí náà, “ó jẹ́ dídúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹnì kan láti fún un ní ìṣírí nígbà tí ó bá ń dojúkọ ìdánwò tí ó le koko.” (A Linguistic Key to the Greek New Testament) Ọ̀mọ̀wé kan tí ó kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli jinlẹ̀ kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ náà . . . máa ń túmọ̀ sí ju ìbákẹ́dùn tí ó máratuni. . . . Ìtùnú Kristian ni ìtùnú tí ń mú ìgboyà wá, ìtùnú tí ń ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti wọ̀yá ìjà pẹ̀lú gbogbo ìṣòro ìgbésí-ayé pẹ̀lú àṣeyọrí.” Ó tún ní nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí a gbéka orí ìlérí àti ìrètí tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀—ìyẹn ni ti àjíǹde òkú.
Jesu àti Paulu —Àwọn Olùtùnú Oníyọ̀ọ́nú
7. Bawo ni Paulu ṣe tu àwọn Kristian arákùnrin rẹ̀ nínú?
7 Ẹ wo irú àpẹẹrẹ àgbàyanu tí Paulu jẹ́ níti fífúnni ní ìtùnú! Ó lè kọ̀wé sí àwọn ará ní Tessalonika pe: “Awa di ẹni pẹ̀lẹ́ ní àárín yín, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí abiyamọ ń ṣìkẹ́ awọn ọmọ tirẹ̀. Nitori naa, ní níní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún yín, ó dùnmọ́ wa nínú jọjọ lati fi fún yín, kì í ṣe ìhìnrere Ọlọrun nìkan, ṣugbọn ọkàn awa fúnra wa pẹlu, nitori ẹ di olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún wa. Ní ìbáramuṣọ̀kan pẹlu èyíinì ẹ̀yin mọ̀ dáadáa bí a tí ń bá a nìṣó ní gbígba ẹnìkọ̀ọ̀kan yín níyànjú, ati ní rírẹ̀ yín lẹ́kún ati ní jíjẹ́rìí yín, bí baba ti ń ṣe sí awọn ọmọ rẹ̀.” Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí onífẹ̀ẹ́, tí ó bìkítà, gbogbo wa lè ṣàjọpín ọ̀yàyà àti òye wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ní ìgbà tí wọ́n bá wà nínú àìní.—1 Tessalonika 2:7, 8, 11.
8. Èéṣe tí ẹ̀kọ́ Jesu fi jẹ́ ìtùnú fún àwọn tí ń kẹ́dùn?
8 Nínú fífi irú ìbìkítà àti inúrere bẹ́ẹ̀ hàn, Paulu wulẹ̀ ń ṣàfarawé Àwòfiṣàpẹẹrẹ rẹ̀ gíga jù, Jesu. Rántí ìkésíni oníyọ̀ọ́nú tí Jesu nawọ́ rẹ̀ sí gbogbo wa gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú Matteu 11:28-30 pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú emi yoo sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nitori onínú tútù ati ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni emi, ẹ̀yin yoo sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nitori àjàgà mi jẹ́ ti inúrere ẹrù mi sì fúyẹ́.” Bẹ́ẹ̀ni, ẹ̀kọ́ Jesu tunilára nítorí pé ó nawọ́ ìrètí àti ìlérí jáde—ìlérí àjíǹde. Èyí ni ìrètí àti ìlérí tí a ń fi lọ àwọn ènìyàn, fún àpẹẹrẹ, nígbà tí a bá fi ìwé pẹlẹbẹ náà Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú sílẹ̀ fún wọn. Ìrètí yìí lè ran gbogbo wa lọ́wọ́, àní bí a bá tilẹ̀ ti ń kẹ́dùn fún ìgbà pípẹ́.
Bí A Ṣe Lè Tu Àwọn Tí Ń Kẹ́dùn Nínú
9. Èéṣe tí a fi níláti ní sùúrù pẹ̀lú àwọn tí ń kẹ́dùn?
9 Ẹ̀dùn-ọkàn kò mọ sí àkókò kan gbàrà lẹ́yìn tí ẹnì kan tí a fẹ́ràn bá kú. Àwọn ènìyàn kan máa ń kẹ́dùn títí gbogbo ọjọ́ ayé wọn, pàápàá àwọn tí wọ́n pàdánù àwọn ọmọ. Tọkọtaya Kristian olùṣòtítọ́ kan ní Spania pàdánù ọmọkùnrin wọn ọlọ́dún 11 ní 1963 gẹ́gẹ́ bí òjìyà àrùn ọpọlọ wíwú àti ògóóró ẹ̀yìn. Títí di oní olónìí, wọ́n ṣì ń ṣẹ́mi lójú nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa Paquito. Àwọn àjọ̀dún, fọ́tò, ohun ìrántí, lè mú àwọn ìrántí bíbaninínújẹ́ padà. Nítorí ìdí èyí, a níláti ní sùúrù kí a máṣe máa ronú pé ó ti yẹ kí àwọn ẹlòmíràn ti kọ́fẹpadà nínú ìpàdánù wọn nísinsìnyí. Aláṣẹ ìṣègùn kan gbà pé: “Ìsoríkọ́ àti èrò-ìmọ̀lára tí ń yí padà lè wà fún ọdún mélòókan.” Nítorí náà, rántí pé gan-an gẹ́gẹ́ bí àpá ẹran-ara ṣe lè wà lára wa títí sáà ìwàláàyè, bákan náà ni àpá èrò-ìmọ̀lára.
10. Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti ran àwọn tí ń kẹ́dùn lọ́wọ́?
10 Kí ni àwọn ohun tí ó gbéṣẹ́ tí a lè ṣe láti lè tu àwọn tí ń kẹ́dùn nínú ìjọ Kristian nínú? Pẹ̀lú òtítọ́ inú a lè sọ fún arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan tí ó nílò ìtùnú pé, “Bí ohunkóhun bá wà tí mo lè ṣe láti ṣèrànlọ́wọ́, ṣáà jẹ́ kí n mọ̀.” Ṣùgbọ́n ìgbà mélòó ní ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ti pè wá níti gidi láti sọ pé, “Mo ti ronú ohun kan tí o lè ṣe láti ràn mí lọ́wọ́”? Ó hàn gbangba pé, a níláti lo àtinúdá tí ó yẹ bí a bá níláti tu ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú. Nítorí náà, kí ni a lè ṣe ní ọ̀nà tí ó wúlò? Àwọn àbá díẹ̀ tí ó gbéṣẹ́ nìyí.
11. Báwo ni fífetísílẹ̀ wa ṣe lè jẹ́ ìtùnú fún àwọn mìíràn?
11 Fetísílẹ̀: Ọ̀kan nínú ohun tí ó ń ṣèrànlọ́wọ́ jùlọ tí o lè ṣe ni láti ṣàjọpín ìrora ẹni náà tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nípa fífetísílẹ̀. O lè béèrè pé, “O ha fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bí?” Jẹ́ kí ẹni náà pinnu. Kristian kan rántí nígbà tí bàbá rẹ̀ kú, pé: “Ó ṣèrànwọ́ fún mi níti gidi nígbà tí àwọn mìíràn bá béèrè ohun tí ó ṣẹlẹ̀ tí wọ́n sì fetísílẹ̀ níti gidi.” Gẹ́gẹ́ bí Jakọbu ti gbani nímọ̀ràn, yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́. (Jakọbu 1:19) Fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àti pẹ̀lú ìbákẹ́dùn fetísílẹ̀ kí o sì ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn. Bibeli dábàá nínú Romu 12:15 pé: “Sunkún pẹlu awọn ènìyàn tí ń sunkún.” Rántí pé Jesu sunkún pẹ̀lú Marta àti Maria.—Johannu 11:35.
12. Irú ìdánilójú wo ni a lè fún àwọn wọnnì tí ń ṣọ̀fọ̀?
12 Pèsè ìdánilójú: Fi sọ́kàn pé ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà lè máa kọ́kọ́ ronú pé òun jẹ̀bi, kí ó máa ronú pé bóyá ohun púpọ̀ wà síi tí òun ìbá ti ṣe. Mú un dá ẹni náà lójú pé ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé gbogbo ohun tí ó ṣeé ṣe ni ó ti ṣe (tàbí ohun yòówù mìíràn tí ó bá mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì gbéniró). Jẹ́ kí ó dá a lójú pé ìmọ̀lára rẹ̀ kò ṣàjèjì. Sọ fún un nípa àwọn mìíràn tí o mọ̀ tí wọ́n fi pẹ̀lú àṣeyọrí jèrè ìkọ́fẹpadà láti inú irú òfò tí ó farajọ èyí. Ní èdè mìíràn, jẹ́ ẹni tí ń tètè nímọ̀lára kí o sì ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn. Inúrere wa lè ní àṣeyọrí gidigidi! Solomoni kọ̀wé pé: “Bí èso igi wúrà nínú agbọ̀n fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò rẹ̀.”—Owe 16:24; 25:11; 1 Tessalonika 5:11, 14.
13. Bí a bá mú ara wa wà lárọ̀ọ́wọ́tó, báwo ni ìyẹn ṣe lè ṣèrànlọ́wọ́?
13 Wà lárọ̀ọ́wọ́tó: Mú ara rẹ wà lárọ̀ọ́wọ́tó kì í ṣe kìkì fún àwọn ọjọ́ díẹ̀ àkọ́kọ́ nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àti ìbátan bá wà níbẹ̀ ṣùgbọ́n fún ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn náà bí ó bá pọndandan, nígbà tí àwọn yòókù ti padà sẹ́nu ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́. Sáà ìkẹ́dùn náà lè yàtọ̀ gidigidi sí ara wọn, ó sinmi lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ọkàn-ìfẹ́ Kristian àti ìbákẹ́dùn wa lè túmọ̀ sí ohun iyebíye nígbà àìní èyíkéyìí. Bibeli sọ pé “ọ̀rẹ́ kan sì ń bẹ tí ó fi ara mọ́ni ju arákùnrin lọ.” Nípa báyìí, ọ̀rọ̀ náà pé, “Ìgbà ìpọ́njú ni a ń mọ ọ̀rẹ́,” jẹ́ òtítọ́ hán-ún tí a gbọ́dọ̀ fi sílò.—Owe 18:24; fiwé Ìṣe 28:15.
14. Kí ni a lè sọ̀rọ̀ lé lórí láti tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú?
14 Sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ dídára ti ẹni náà tí ó kú: Èyí ni ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà mìíràn tí a lè ṣe bí a bá pèsè rẹ̀ ní àkókò tí ó tọ́. Ṣàjọpín àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ṣókí tí ó gbéniró tí ó sì gbádùn mọ́ni tí o rántí nípa ẹni náà. Máṣe fòyà láti lo orúkọ ẹni náà. Máṣe hùwà bí ẹni pé ẹni tí a fẹ́ràn tí a pàdánù náà kò tilẹ̀ wàláàyè rí tàbí pé kò jámọ́ nǹkankan. Ó tuni nínú láti mọ ohun tí ìtẹ̀jáde kan láti Harvard Medical School sọ pé: “Irú ìkọ́fẹpadà kan ni a ti ṣàṣeyọrí rẹ̀ nígbà tí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà bá lè ronú nípa ẹni tí ó kú náà láìjẹ́ pé ìbànújẹ́ bò ó mọ́lẹ̀ . . . Bí ó ti ń tẹ́wọ́gba ìjótìítọ́ titun yìí tí ó sì ń faramọ́ ọn, ẹ̀dùn-ọkàn yóò máa yípadà di àwọn ìrántí tí a fọkàn-ṣìkẹ́.” “Àwọn ìrántí tí a fọkàn-ṣìkẹ́”—ẹ wo bí ó ti tuni nínú tó láti rántí àwọn àsìkò tí ó ṣeyebíye tí a lò papọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tí a fẹ́ràn! Ẹlẹ́rìí kan tí ó pàdánù bàbá rẹ̀ ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn sọ pé: “Kíka Bibeli pẹ̀lú Bàbá kété lẹ́yìn tí ó bẹ̀rẹ̀ síi kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ jẹ́ ìrántí pàtàkì kan fún mi. Àti dídùbúlẹ̀ sí bèbè odò kí n sì máa sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ìṣòro mi. Mo máa ń rí i kìkì ní ọdún mẹ́ta-mẹ́ta tàbí mẹ́rin-mẹ́rin, nítorí náà àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyẹn ṣeyebíye.”
15. Bawo ni ẹnì kan ṣe lè lo ìdánúṣe láti ṣèrànlọ́wọ́?
15 Lo ìdánúṣe nígbà tí ó bá yẹ: Àwọn kan tí ń kẹ́dùn lè kojú rẹ̀ dáradára ju àwọn mìíràn lọ. Nítorí náà, lo àwọn ìgbésẹ̀ tí ó gbéṣẹ́ láti ṣèrànlọ́wọ́, bí àyíká ipò bá ti gbà. Kristian obìnrin kan tí ń kẹ́dùn rántí pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sọ pé, ‘Bí ohunkóhun bá wà tí mo lè ṣe, jẹ́ kí n mọ̀.’ Ṣùgbọ́n Kristian arábìnrin kan ko béèrè. Ó lọ tààràtà sínú yàrá, ó ká aṣọ bẹ́ẹ̀dì, ó sì fọ àwọn aṣọ tí ó ti dọ̀tí náà. Òmíràn gbé garawa, omi, àti àwọn ohun èlò ìfọ-nǹkan ó sì fọ kápẹ́ẹ̀tì níbi tí ọkọ mi bì sí. Àwọn wọ̀nyí ni ọ̀rẹ́ tòótọ́, n kò sì lè gbàgbé wọn.” Níbi tí ó bá ti hàn pé a nílò ìrànlọ́wọ́, lo ọgbọ́n àtinúdá—bóyá nípa síse oúnjẹ, ṣíṣèrànwọ́ láti tún ilé ṣe, tàbí ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Àmọ́ ṣáá o, a níláti ṣọ́ra kí a máṣe yọjúràn nígbà tí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà bá fẹ́ láti dá wà. Nípa báyìí, a níláti fi ọ̀rọ̀ Paulu náà sọ́kàn pé: “Ní ìbámu pẹlu èyí, gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ Ọlọrun, mímọ́ ati olùfẹ́, ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inúrere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú, ìwàtútù, ati ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.” Inúrere, sùúrù, àti ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé.—Kolosse 3:12; 1 Korinti 13:4-8.
16. Èéṣe tí lẹ́tà tàbí káàdì fi lè pèsè ìtùnú?
16 Kọ lẹ́tà tàbí kí o fi káàdì ìtùnú ránṣẹ́: Ohun tí a sábà máa ń gbójúfò ni ìníyelórí lẹ́tà ìbánidárò tàbí káàdì ìbánikẹ́dùn tí ó rẹwà. Àǹfààní wo ni ó ní? Ó ṣeé kà ní àkàtúnkà. Kì í ṣe dandan ni kí irú lẹ́tà bẹ́ẹ̀ gùn, ṣùgbọ́n ó níláti fi ìyọ́nú rẹ hàn. Ó tún níláti ṣàgbéyọ jíjẹ́ ẹni ti ẹ̀mí ṣùgbọ́n kò níláti kún fún ìwàásù. Kìkì ìhìn-iṣẹ́ pàtàkì náà pé “A wà níhìn-ín fún ọ” lè jẹ́ ìrẹ̀lẹ́kún.
17. Báwo ni àdúrà ṣe lè mú ìtùnú wá?
17 Gbàdúrà pẹ̀lú wọn: Máṣe fojúkéré ìníyelórí àdúrà rẹ pẹ̀lú wọn àti fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀. Bibeli sọ nínú Jakọbu 5:16 pé: “Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo . . . ní ipá púpọ̀.” Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn tí ń kẹ́dùn bá gbọ́ tí a ń gbàdúrà nítorí wọn, ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìmọ̀lára òdì bí ẹ̀bi kúrò. Ní àwọn àkókò àìlera wa, àti ti ìrẹ̀wẹ̀sì, Satani máa ń gbìyànjú láti jìn wá lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú àwọn “ètekéte,” tàbí “ọgbọ́n àrékérekè” rẹ̀. Ìgbà yìí ni a nílò ìtùnú àti ìtìlẹ́yìn àdúrà, gẹ́gẹ́ bí Paulu ti sọ: ‘Pẹlu gbogbo irú-oríṣi àdúrà ati ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà ninu ẹ̀mí. Ati pé fún ète yẹn ẹ máa wà lójúfò pẹlu gbogbo ìdúró láìyẹsẹ̀ ati pẹlu ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ nitori gbogbo awọn ẹni mímọ́.’—Efesu 6:11, 18, Kingdom Interlinear; fiwé Jakọbu 5:13-15.
Ohun Ti A Níláti Yẹra Fún
18, 19. Báwo ni a ṣe lè fí ọgbọ́n hàn nínú àwọn ìjíròrò wa?
18 Nígbà tí ẹnì kan bá ń kẹ́dùn, àwọn ohun kan wà bákan náà tí a kò níláti ṣe tàbí sọ. Owe 12:18 kìlọ̀ pé: “Àwọn kan ń bẹ tí ń yára sọ̀rọ̀ lásán bí ìgúnni idà; ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọgbọ́n, ìlera ni.” Nígbà mìíràn, láìfura, a ń kùnà láti fi ọgbọ́n hàn. Fún àpẹẹrẹ, a lè sọ pé, “Mo mọ bí ìmọ̀lára rẹ ṣe rí.” Ṣùgbọ́n èyí ha rí bẹ́ẹ̀ nítòótọ́ bí? O ha ti ní ìrírí irú òfò kan náà gan-an rí bí? Bákan náà, ènìyàn máa ń hùwàpadà ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀síra. Ìhùwàpadà rẹ lè má jẹ́ bákan náà pẹ̀lú ti ẹni náà tí ń kẹ́dùn. O lè fi ẹ̀mí ìmọ̀lára hàn púpọ̀ bí o bá sọ pé, “Mo fi ọ̀ràn ro ara mi wò nítorí mo ní ìrírí irú òfò kan náà nígbà tí . . . kú nígbà kan sẹ́yìn.”
19 Yóò tún fi ẹ̀mí-ìmọ̀lára hàn láti yẹra fún sísọ̀rọ̀ nípa bóyá ẹni tí ó kú náà yóò ní àjíǹde tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ń dánilẹ́jọ́ nípa ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́-ọ̀la sí alábàáṣègbéyàwó wọn aláìgbàgbọ́ tí ó kú ti dun àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin kan wọra. Àwa kì í ṣe onídàájọ́ àwọn tí yóò ní àjíǹde àti àwọn tí kì yóò ní. A lè ní ìtura pé Jehofa, ẹni tí ó rí ọkàn-àyà, yóò jẹ́ aláàánú púpọ̀ púpọ̀ ju bí èyí tí ó pọ̀ jù nínú wa yóò ti jẹ́ lọ.—Orin Dafidi 86:15; Luku 6:35-37.
Àwọn Ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ Tí Ń Tuni Nínú
20, 21. Kí ni àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ díẹ̀ tí ó lè tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú?
20 Ọ̀kan nínú àwọn orísun tí ó ga jùlọ tí ó lè ran ẹni tí ń kẹ́dùn lọ́wọ́, bí a bá lò ó ní àsìkò tí ó tọ́, ni gbígbé àwọn ìlérí Jehofa fún àwọn òkú yẹ̀wò. Àwọn èrò tí ó bá Bibeli mu wọ̀nyí yóò wúlò yálà ẹni tí ń kẹ́dùn náà ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí tẹ́lẹ̀ tàbí ó jẹ́ ẹni tí a bá pàdé nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ yìí? A mọ̀ pé Jehofa ni Ọlọrun ìtùnú gbogbo, nítorí ó sọ pé: “Èmi, àní èmi ni ẹni tí ń tù yín nínú.” Ó tún sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ìyá rẹ̀ ń tù nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi óò tù yín nínú.”—Isaiah 51:12; 66:13.
21 Onipsalmu náà kọ̀wé pé: “Èyí ni ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi: nítorí ọ̀rọ̀ rẹ ni ó sọ mí di ààyè. Oluwa, èmi rántí ìdájọ́ àtijọ́; èmi sì tu ara mi nínú. Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìṣeun-àánú rẹ kí ó máa ṣe ìtùnú mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ.” Ṣàkíyèsí pé ọ̀rọ̀ náà “ìtùnú” ni a lò léraléra nínú àwọn àyọkà wọ̀nyẹn. Bẹ́ẹ̀ni, a lè rí ìtùnú tòótọ́ fún ara wa àti fún àwọn mìíràn nípa yíyíjú sí Ọ̀rọ̀ Jehofa ní àkókò ìpọ́njú wa. Èyí, papọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìyọ́nú àwọn ará, lè ràn wá lọ́wọ́ láti lè farada àdánù wa pẹ̀lú àṣeyọrí kí a sì mú ìgbésí-ayé wa kún fún ìgbòkègbodò onídùnnú-ayọ̀ lẹ́ẹ̀kan síi nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian.—Orin Dafidi 119:50, 52, 76.
22. Ìfojúsọ́nà wo ni ó wà níwájú wa?
22 De àyè ipò kan a tún lè borí ẹ̀dùn-ọkàn wa nípa jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí ní ríran àwọn mìíràn lọ́wọ́ nínú ìrora ọkàn wọn. Bí a ti ń darí àfiyèsí wa sí àwọn mìíràn tí wọ́n nílò ìtùnú, àwa náà ń ní ayọ̀ tòótọ́ ti fífúnni nípa ti ẹ̀mí. (Ìṣe 20:35) Ẹ jẹ́ kí a ṣàjọpín ìran ọjọ́ àjíǹde nígbà tí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè gbogbo tẹ́lẹ̀ rí, láti ìrandíran, yóò máa kí àwọn ẹni tí wọ́n fẹ́ràn tí wọ́n ti pàdánù káàbọ̀ láti inú òkú sínú ayé titun kan. Ẹ wo irú ìfojúsọ́nà tí èyí jẹ́! Ẹ wo irú omijé ayọ̀ tí yóò dà jáde nígbà náà bí a ti ń rántí pé nítòótọ́ Jehofa ni Ọlọrun “ẹni tí ń tu awọn wọnnì tí a mú balẹ̀ nínú”!—2 Korinti 7:6.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Báwo ni Jehofa ṣe jẹ́ “Ọlọrun ìtùnú gbogbo”?
◻ Báwo ni Jesu àti Paulu ṣe tu àwọn tí ń kẹ́dùn nínú?
◻ Kí ni àwọn nǹkan tí a lè ṣe láti tu àwọn tí ń kẹ́dùn nínú?
◻ Kí ni a níláti yẹra fún nígbà tí a bá ń bá àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lò?
◻ Àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ wo ni o yàn láàyò láti máa lò ní àkókò àdánù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Fi ọgbọ́n lo ìdánúṣe láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ń kẹ́dùn