ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 6/1 ojú ìwé 30-31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Jésù Kristi Ṣe Lè Ràn Wá Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • A Mọyì Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Tí Ọlọ́run Ń Fi Hàn sí Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ọlọ́run Dá Wa Sílẹ̀ Nípasẹ̀ Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ẹ Jẹ́ Kí Aráyé Gbọ́ Ìhìn Rere Nípa Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 6/1 ojú ìwé 30-31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Báwo ni àǹfààní iṣẹ́-ìsìn àlùfáà àgbà ti Kristi Jesu, tí a mẹ́nu kàn ní Heberu 4:15, 16, ṣe kan “awọn àgùtàn mìíràn” nísinsìnyí?

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ipa-iṣẹ́ Jesu gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà ní ìjẹ́pàtàkì lákọ̀ọ́kọ́ fún àwọn wọnnì tí wọn yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ ní òkè-ọ̀run, àwọn Kristian tí wọ́n ní ìrètí ti orí ilẹ̀-ayé ń jàǹfààní nísinsìnyí nínú iṣẹ́-ìsìn àlùfáà Jesu.

Láti ìgbà Adamu, àwọn ẹ̀dá ènìyàn ni a ti di ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ lé lórí. A ń jìyà lọ́wọ́ àìpé àjogúnbá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israeli ti ṣe. Wọ́n yíjú sí ìtògìn-ìn-rìn àwọn àlùfáà àgbà àti àwọn àlùfáà amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́, tí ń ṣe ìrúbọ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ti ara wọn àti fún ti àwọn ènìyàn mìíràn pẹ̀lú. Nígbà tí ó tó àkókò, a fi àmì-òróró yan Jesu gẹ́gẹ́ bí àlùfáà “ní ìbámu pẹlu irú-ọ̀nà ti Melkisedeki.” Lẹ́yìn tí a ti jí i dìde, Jesu fara hàn níwájú Jehofa láti gbé ìtóye ẹbọ ẹ̀dá ènìyàn rẹ̀ pípé kalẹ̀.—Orin Dafidi 110:1, 4, NW.

Kí ni èyí túmọ̀ sí fún wa lónìí? Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Heberu, Paulu jíròrò iṣẹ́-ìsìn Jesu gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà. Ní Heberu 5:1, a kà pé: “Olúkúlùkù àlùfáà àgbà tí a mú láàárín awọn ènìyàn ni a yànsípò nitori ènìyàn lórí awọn ohun tí ó jẹmọ́ ti Ọlọrun, kí ó lè fi awọn ẹ̀bùn ati awọn ohun ẹbọ rúbọ fún awọn ẹ̀ṣẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ni ẹsẹ̀ 5 àti 6, Paulu fi hàn pé Jesu di àlùfáà àgbà, èyí tí ó lè yọrí sí àǹfààní fún wa.

Lọ́nà wo? Paulu kọ̀wé pé: “Bí oun tilẹ̀ jẹ́ Ọmọkùnrin, ó kọ́ ìgbọràn lati inú awọn ohun tí ó jìyà rẹ̀; ati lẹ́yìn tí a ti sọ ọ́ di pípé ó di ẹni tí ó ní ẹrù-iṣẹ́ fún mímú ìgbàlà àìnípẹ̀kun wá fún gbogbo awọn wọnnì tí ń ṣègbọràn sí i.” (Heberu 5:8, 9) Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹsẹ̀ yẹn lè mú kí a ronú nípa bí a ṣe lè jàǹfààní nínú ayé titun, nígbà tí a óò mú ipò ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Ọlọrun àti Jesu kúrò tí wọn yóò sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Ìfojúsọ́nà tòótọ́ ni ìyẹn jẹ́, tí a gbékarí ìtóye ìràpadà ẹbọ Jesu àti iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó dájú pé, a lè jàǹfààní nísinsìnyí gan-an láti inú ipa-iṣẹ́ rẹ̀ tàbí iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà. Ṣàkíyèsí Heberu 4:15, 16: “Awa ní gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, kì í ṣe ẹni kan tí kò lè bánikẹ́dùn fún awọn àìlera wa, bíkòṣe ẹni kan tí a ti dánwò ní gbogbo ọ̀nà bí awa fúnra wa, ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀. Nitori naa, ẹ jẹ́ kí a súnmọ́ ìtẹ́ inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹlu òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, kí a lè rí àánú gbà kí a sì rí inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.” Nígbà wo ni yóò jẹ́ “àkókò tí ó tọ́”? Ó jẹ́ nígbà tí a nílò àánú àti inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí. Gbogbo wa, nítorí àìpé wa, níláti nímọ̀lára àìní yìí nísinsìnyí.

Heberu 4:15, 16 sọ kókó náà pé Jesu—tí ó jẹ́ àlùfáà ní òkè-ọ̀run báyìí—ti jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn rí pẹ̀lú, nítorí náà ó lè fi ọ̀rọ̀ ro ara rẹ̀ wò. Sí àwọn wo? Sí wa. Nígbà wo? Nísinsìnyí. Nígbà tí ó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn, Jesu ní ìrírí másùnmáwo àti ìkìmọ́lẹ̀ tí ó wọ́pọ̀ lọ́dọ̀ ẹ̀dá ènìyàn. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan, ebi pa Jesu òùngbẹ sì gbẹ ẹ́. Láìka pé ó jẹ́ ẹni pípé sí pẹ̀lú, àárẹ̀ mú un. Ìyẹn níláti fún wa ní ìdánilójú. Èéṣe? Nítorí pé Jesu ní ìrírí àárẹ̀ tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu, ó mọ bí a ṣe sábà máa ń nímọ̀lára. Rántí, pẹ̀lú, pé Jesu níláti wọ̀jà pẹ̀lú aáwọ̀ tí owú jíjẹ dásílẹ̀ láàárín àwọn aposteli rẹ̀. (Marku 9:33-37; Luku 22:24) Bẹ́ẹ̀ni, ó ní ìjákulẹ̀. Kò ha yẹ kí ìyẹn fún wa ní ìdánilójú pé òun lóye wa nígbà tí a bá ní ìjákulẹ̀, tí a sì rẹ̀wẹ̀sì bí? Dájúdájú.

Nígbà tí o bá rẹ̀wẹ̀sì, kí ni o lè ṣe? Paulu ha sọ pé o wulẹ̀ níláti dúró, títí di inú ayé titun, nígbà tí Àlùfáà Àgbà rẹ, Jesu, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti di pípé nínú èrò-inú àti ara bí? Rárá o. Paulu wí pé: “A lè rí àánú gbà kí a sì rí inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́,” ìyẹn sì ní àkókò lọ́ọ́lọ́ọ́ nínú. Síwájú síi, nígbà tí Jesu jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn, ó ní ìrírí ìjìyà àti ìnira, tí a sì ‘dán an wò ní gbogbo ọ̀nà bí awa fúnra wa.’ Nítorí náà nígbà tí a bá dojúkọ irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ó ṣetán láti ràn wá lọ́wọ́, lórí ìpìlẹ̀ òye rẹ̀ nípa ohun tí a ń ní ìrírí rẹ̀. Ìyẹn kò ha fà ọ́ sún mọ́ ọn bí?

Wàyí o ṣàkíyèsí ẹsẹ̀ 16. Paulu sọ pé àwa—èyí sì ní nínú àwọn ẹni-àmì-òróró àti àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ àgùtàn mìíràn lápapọ̀—lè tọ Ọlọrun lọ pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. (Johannu 10:16) Aposteli náà kò ní in lọ́kàn pé a wulẹ̀ lè sọ ohunkóhun tí a bá fẹ́ nínú àdúrà wa, àní àwọn ohun tí ó lè múnibínú, tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Jesu àti ipa-iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà, a lè tọ Ọlọrun lọ láìka pé a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ sí.

Ọ̀nà mìíràn tí a lè gbà jàǹfààní pàápàá nísinsìnyí nínú iṣẹ́-ìsìn Àlùfáà Àgbà wa, Jesu Kristi, wémọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, tàbí àṣìṣe wa. Kò sí iyèméjì pé a kò retí pé Jesu yóò lo èrè ẹbọ rẹ̀ fún wa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ètò-ìgbékalẹ̀ ti ìsinsìnyí. Àní bí ó bá tilẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ a kò tí ì lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Rántí ọ̀ràn tí a ṣàkọsílẹ̀ ní Luku 5:18-26, tí ó kan ọkùnrin alárùn ẹ̀gbà tí wọ́n sọ ibùsùn rẹ̀ kalẹ̀ gba àárín àwo ìbolé? Jesu wí fún un pé: “Ọkùnrin yii, a dárí awọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” Ìyẹn kò túmọ̀ sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan ní pàtó tí ó fa àrùn ẹ̀gbà náà. Ó gbọ́dọ̀ ti túmọ̀ sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin náà ní gbogbogbòò, títí dé ìwọ̀n àyè kan pẹ̀lú ó ti lè ní àìpé àjogúnbá tí ń fa àìsàn nínú.

Lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ tí òun yóò rú, Jesu lè gbé ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin náà lọ, gẹ́gẹ́ bí ewúrẹ́ Asaseli ṣe gbé ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israeli lọ ní Ọjọ́ Ètùtù. (Lefitiku 16:7-10) Síbẹ̀, ẹ̀dá ènìyàn ni ọkùnrin alárùn ẹ̀gbà náà ṣì jẹ́. Yóò tún padà dẹ́ṣẹ̀, bí àkókò sì ti ń lọ ó kú, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́sẹ̀ kan ṣe gbọ́dọ̀ ṣe. (Romu 5:12; 6:23) Ohun tí Jesu sọ kò túmọ̀ sí pé ọkùnrin náà gba ìyè ayérayé ní ojú-ẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n a fi ìwọ̀n ìdáríjì kan ní àkókò náà bùkún ọkùnrin náà.

Wàyí o gbé ọ̀ràn tiwa yẹ̀wò. Níwọ̀n bí a ti jẹ́ aláìpé, lójoojúmọ́ ni a ń ṣe àṣìṣe. (Jakọbu 3:2) Kí ni a lè ṣe nípa ìyẹn? Ó dára, ní òkè-ọ̀run a ni Àlùfáà Àgbà aláàánú ẹni tí a lè tipasẹ̀ rẹ̀ súnmọ́ Jehofa nínú àdúrà. Bẹ́ẹ̀ni, gẹ́gẹ́ bí Paulu ti kọ̀wé, gbogbo wa lè “súnmọ́ ìtẹ́ inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí [Ọlọrun] pẹlu òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, kí a lè rí àánú gbà kí a sì rí inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.” Nítorí náà, ó dájú pé gbogbo ẹni tí ó jẹ́ ara àgùtàn mìíràn lónìí ń jèrè àǹfààní àgbàyanu, títí kan ẹ̀rí-ọkàn mímọ́ gaara, láti inú iṣẹ́-ìsìn àlùfáà àgbà Kristi.

Gbogbo Kristian tí ó ní ìrètí ti ilẹ̀-ayé lè fojúsọ́nà fún àwọn àǹfààní títóbilọ́lá nínú ayé titun tí ń súnmọ́lé. Nígbà náà ni Àlùfáà Àgbà wa yóò lo èrè ẹbọ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí yóò sì yọrí sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá. Òun yóò tún nawọ́ àǹfààní títóbi jù nípa bíbójútó ìlera ti ara àti tẹ̀mí àwọn ènìyàn. Jesu yóò sì mú ìdálẹ́kọ̀ọ́ àwọn ènìyàn Ọlọrun tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé gbòòrò síi, níwọ̀n bí kíkọ́ni ní Òfin ti jẹ́ ẹrù-iṣẹ́ pàtàkì àwọn àlùfáà ní Israeli. (Lefitiku 10:8-11; Deuteronomi 24:8; 33:8, 10) Nígbà náà, bí a ṣe ń jàǹfààní nínú iṣẹ́-ìsìn àlùfáà Jesu nísinsìnyí, ohun púpọ̀ síi ń dúró dè wá!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́