ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 6/15 ojú ìwé 13-18
  • Kí Ní Ń Sún Ọ Láti Ṣiṣẹ́sin Ọlọrun?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ní Ń Sún Ọ Láti Ṣiṣẹ́sin Ọlọrun?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ohun Ìdènà fún Ìsúnniṣe Tí Ó Yẹ
  • “Ìfẹ́ Tí Kristi Ní Sọ Ọ́ Di Ọ̀ranyàn fún Wa”
  • ‘Ẹ Ṣọ́ra fún Ìwúkàrà Awọn Farisi’
  • “Olúkúlùkù Ní Ìbámu Pẹ̀lú Agbára Ìlèṣe Nǹkan Tirẹ̀”
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpèjúwe Nípa Àwọn Tálẹ́ńtì Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ṣiṣe Iṣiro Lori Ìlò Owó-Àkànlò Kristi
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • Ẹ̀kọ́ Tí Àpèjúwe Tálẹ́ńtì Kọ́ Wa
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Tó Nífẹ̀ẹ́ Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 6/15 ojú ìwé 13-18

Kí Ní Ń Sún Ọ Láti Ṣiṣẹ́sin Ọlọrun?

“Iwọ . . . gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn-àyà rẹ ati pẹlu gbogbo ọkàn rẹ ati pẹlu gbogbo èrò-inú rẹ ati pẹlu gbogbo okun rẹ.”—MARKU 12:30.

1, 2. Àwọn ohun amóríyá wo ní a ti ṣàṣeparí rẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ ìwàásù?

ÌNÍYELÓRÍ tòótọ́ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan ni a kì í pinnu kìkì nípa ìrísí rẹ̀. Ọ̀dà tí a fi kùn ún lè bùkún ìrísí òde rẹ̀, iṣẹ́ ọnà rèterète sì lè fa ẹnì kan tí ó ṣeé ṣe kí ó rà á mọ́ra; ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ gan-an ni àwọn ohun tí a kò rí lójú ẹsẹ̀—ẹ́ńjìnnì tí ń mú kí ọkọ̀ náà rìn, papọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ mìíràn tí ń darí rẹ̀.

2 Ó farajọ iṣẹ́-ìsìn Kristian sí Ọlọrun. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń pọ̀ síi nínú iṣẹ́ tí Ọlọrun fẹ́. Lọ́dọọdún, iye tí ó lé ní billion kan wákàtí ni a ń lò ní wíwàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun. Síwájú síi, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ni a ń darí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn ni ó sì ń ṣe ìrìbọmi. Bí o bá jẹ́ olùpòkìkí ìhìnrere náà, o ti nípìn-ín—àní bí ó bá tilẹ̀ jọ pé ó kéré—nínú àwọn àkójọ ìsọfúnni oníṣirò amóríyá wọ̀nyí. O sì lè ní ìdánilójú pé ‘Ọlọrun kì í ṣe aláìṣòdodo tí yoo fi gbàgbé iṣẹ́ rẹ ati ìfẹ́ tí o fihàn fún orúkọ rẹ̀.’—Heberu 6:10.

3. Ohun mìíràn wo yàtọ̀ sí iṣẹ́ ni ó níláti jẹ àwọn Kristian lógún jùlọ, èésìtiṣe?

3 Bí ó ti wù kí ó rí, ìníyelórí tòótọ́ iṣẹ́-ìsìn wa—lápapọ̀ tàbí lẹ́nìkọ̀ọ̀kan—ni a kì í díwọ̀n kìkì nípa nọ́ḿbà. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fún Samueli pé, “ènìyàn a máa wo ojú, Oluwa a máa wo ọkàn.” (1 Samueli 16:7) Bẹ́ẹ̀ni, ohun tí a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ni ó ṣe pàtàkì jùlọ lójú Ọlọrun. Òtítọ́ ni pé, iṣẹ́ ṣe kókó. Àwọn ìṣe ìfọkànsin Ọlọrun ń ṣe ẹ̀kọ́ Jehofa lọ́ṣọ̀ọ́ ó sì ń fa àwọn tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn mọ́ra. (Matteu 5:14-16; Titu 2:10; 2 Peteru 3:11) Síbẹ̀, iṣẹ́ wa kì í sọ gbogbo rẹ̀. Jesu tí a jí dìde ní ìdí fún ṣíṣàníyàn nípa ìjọ tí ń bẹ ní Efesu—láìka àkọsílẹ̀ iṣẹ́ rere wọn sí. Ó sọ fún wọn pé: “Mo mọ awọn iṣẹ́ rẹ. . . . Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ní èyí lòdì sí ọ, pé iwọ ti fi ìfẹ́ tí iwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.”—Ìṣípayá 2:1-4.

4. (a) Lọ́nà wo ni iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun ṣe lè dàbí ààtò-ìsìn aláìgbọdọ̀máṣe? (b) Èéṣe tí a fi nílò àyẹ̀wò ara-ẹni?

4 Ewu kan wà níbẹ̀. Ní àwọn sáà àkókò kan, iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun lè dàbí ààtò-ìsìn aláìgbọdọ̀máṣe. Kristian kan tí ó jẹ́ adélébọ̀ ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà yìí: “Èmi yóò jáde lọ fún iṣẹ́-ìsìn, n óò lọ sí àwọn ìpàdé, n óò kẹ́kọ̀ọ́, n óò gbàdúrà—ṣùgbọ́n mo ń ṣe gbogbo rẹ̀ bí ẹ̀rọ tí ń tẹ̀lé ipa-iṣẹ́ tí a ti wéwèé rẹ̀ tẹ́lẹ̀, n kò nímọ̀lára ohunkóhun rí.” Àmọ́ ṣáá o, ó yẹ kí a gbóríyìn fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun nígbà tí wọ́n bá tiraka láìka nínímọ̀lára pé ‘a gbé wọn ṣánlẹ̀’ tàbí ‘a mú wọn balẹ̀’ sí. (2 Korinti 4:9; 7:6) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ déédéé Kristian wa bá dúró gbagidi, ó yẹ kí a yẹ inú ẹ́ńjìnnì náà wò, kí a sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ọkọ̀ ìrìnnà tí ó dára jùlọ pàápàá nílò ìtọ́jú láti ìgbà-dé-ìgbà; bákan náà, gbogbo Kristian níláti máa ṣàyẹ̀wò ara wọn déédéé. (2 Korinti 13:5) Àwọn mìíràn lè rí àwọn iṣẹ́ wa, ṣùgbọ́n wọn kò lè wòyemọ ohun tí ń sún wa láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ wa. Nítorí náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, níláti ronú nípa ìbéèrè náà pé: ‘Kí ní ń sún mi láti ṣiṣẹ́sin Ọlọrun?’

Àwọn Ohun Ìdènà fún Ìsúnniṣe Tí Ó Yẹ

5. Àṣẹ wo ni Jesu sọ pé ó jẹ́ èkínní?

5 Nígbà tí a bi í pé èwo ni èkínní nínú gbogbo àwọn òfin tí a fún àwọn ọmọ Israeli, Jesu ṣàyọlò àṣẹ kan tí ó kórí àfiyèsí jọ, kì í ṣe sórí ìrísí òde, ṣùgbọ́n ìsúnniṣe ti inú lọ́hùn-ún pé: “Iwọ . . . gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn-àyà rẹ ati pẹlu gbogbo ọkàn rẹ ati pẹlu gbogbo èrò-inú rẹ ati pẹlu gbogbo okun rẹ.” (Marku 12:28-30) Nípa bẹ́ẹ̀ Jesu fi ohun tí ó níláti jẹ́ ipá ìsúnniṣe tí ń bẹ lẹ́yìn iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun hàn yàtọ̀—ìfẹ́.

6, 7. (a) Lọ́nà wo ni Satani gbà gbéjàko agbo ìdílé lọ́nà ìyọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́, èésìtiṣe? (2 Korinti 2:11) (b) Báwo ni bí a ṣe tọ́ ẹnì kan dàgbà ṣe lè nípa lórí ìṣarasíhùwà rẹ̀ sí ọlá-àṣẹ tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá?

6 Agbára-ìṣe wa láti mú ànímọ́ ìfẹ́ tí ó ṣe kókó yìí dàgbà ni Satani fẹ́ ké nígbèrí. Láti ṣàṣeparí èyí, ọ̀nà kan tí ó ti lò ni láti gbéjàko agbo ìdílé. Èéṣe? Nítorí pé ibí yìí ni a ti ń pilẹ̀ èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn wa àkọ́kọ́ tí ó sì lè wà pẹ́títí jùlọ nípa ìfẹ́. Satani mọ ìlànà Bibeli náà dájú ṣáká pé ohunkóhun tí a bá kọ́ nígbà ọmọdé lè wúlò nígbà tí a bá dàgbà. (Owe 22:6) Ó ń fi pẹ̀lú ìyọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́ gbìdánwò láti fèrú yí ìpìlẹ̀-èrò wa tí a ti ní nípa ìfẹ́ láti ìgbà ọmọdé po. Gẹ́gẹ́ bí “ọlọrun ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii,” Satani ń rí i pé a ń ṣiṣẹ́ fún ète òun nígbà tí a bá tọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dàgbà nínú àwọn ilé tí kò ti sí ìfẹ́ ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ ibùjókòó ìkorò, ìrunú, àti ọ̀rọ̀ èébú.—2 Korinti 4:4; Efesu 4:31, 32; 6:4, àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References; Kolosse 3:21.

7 Ìwé náà Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ ṣàlàyé pé ọwọ́ tí bàbá kan fi ń mú ipa-iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òbí “le ní iyọrisi titayọ lori iwa awọn ọmọ rẹ̀ lẹhinwa-ọla si aṣẹ, ìbáà ṣe ti eniyan tabi ti Ọlọrun.”a Ọkùnrin Kristian kan tí a tọ́ dàgbà lábẹ́ àṣẹ bóofẹ́-bóokọ̀ ti bàbá kan tí ó le koko sọ pé: “Lójú tèmi, ṣíṣègbọràn sí Jehofa rọrùn; nínífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ló wá jẹ́ ohun tí ó nira.” Àmọ́ ṣáá o, ìgbọràn ṣe kókó, nítorí pé ní ojú Ọlọrun “ìgbọràn sàn ju ẹbọ lọ.” (1 Samueli 15:22) Ṣùgbọ́n kí ní lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe rékọjá ṣíṣègbọràn lásán kí a sì mú ìfẹ́ fún Jehofa dàgbà gẹ́gẹ́ bí ipá ìsúnniṣe tí ń bẹ lẹ́yìn ìjọsìn wa?

“Ìfẹ́ Tí Kristi Ní Sọ Ọ́ Di Ọ̀ranyàn fún Wa”

8, 9. Báwo ni ẹbọ ìràpadà Jesu ṣe níláti ru ìfẹ́ wa fún Jehofa sókè?

8 Ohun ìsúnniṣe tí ó tóbi jùlọ láti lè mú ìfẹ́ àtọkànwá dàgbà fún Jehofa ni ìmọrírì fún ẹbọ ìràpadà Jesu Kristi. “Nipa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọrun hàn kedere ninu ọ̀ràn tiwa, nitori Ọlọrun rán Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.” (1 Johannu 4:9) Gbàrà tí a bá ti lóye rẹ̀ tí a sì fi ìmọrírì hàn, ìṣe ìfẹ́ yìí máa ń fa ìhùwàpadà onífẹ̀ẹ́ jáde. “Awa nífẹ̀ẹ́, nitori [Jehofa] ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.”—1 Johannu 4:19.

9 Jesu fi pẹ̀lú ìmúratán tẹ́wọ́gba iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀ láti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà ènìyàn. “Nipa èyí ni awa fi wá mọ ìfẹ́, nitori ẹni yẹn fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ fún wa.” (1 Johannu 3:16; Johannu 15:13) Ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ tí Jesu ní níláti mú ìhùwàpadà onímọrírì jáde nínú wa. Fún àpẹẹrẹ: Kí a sọ pé a ti yọ ọ́ nínú ewu bíbómilọ. Ìwọ yóò ha wulẹ̀ padà sílé, tí ìwọ yóò nú ara rẹ̀, tí ìwọ yóò sì gbàgbé nípa rẹ̀ bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́! Ìwọ yóò nímọ̀lára pé o jẹ ẹni náà tí ó yọ ọ́ nínú ewu ní gbèsè. Ó ṣetán, o jẹ ẹni náà ní gbèsè ìwàláàyè rẹ. Àwa ha jẹ Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi ní gbèsè tí ó dínkù sí ìyẹn bí? Láìsí ìràpadà, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò ti bómilọ, gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè sọ pé ó jẹ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Dípò bẹ́ẹ̀, nítorí ìṣe onífẹ̀ẹ́ ńláǹlà yìí, a ní ìfojúsọ́nà ti wíwàláàyè títíláé nínú paradise orí ilẹ̀-ayé.—Romu 5:12, 18; 1 Peteru 2:24.

10. (a) Báwo ni a ṣe lè mú ìràpadà bá ara wa mú? (b) Báwo ni ìfẹ́ tí Kristi ni ṣe mú wa lọ́ranyàn?

10 Ṣe àṣàrò lórí ìràpadà. Mú un ba ara rẹ mu, gẹ́gẹ́ bí Paulu ti ṣe: “Nítòótọ́, ìgbésí-ayé tí mo ń gbé ninu ẹran-ara nísinsìnyí ni mo ń gbé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ninu Ọmọkùnrin Ọlọrun, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi tí ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Galatia 2:20) Irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ yóò mú kí iná ìsúnniṣe àtọkànwá máa jó, nítorí Paulu kọ̀wé sí àwọn ará Korinti pé: “Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa, nitori . . . oun . . . kú fún gbogbo wọn kí awọn wọnnì tí ó wà láàyè máṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bíkòṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn tí a sì gbé dìde.” (2 Korinti 5:14, 15) Bibeli The Jerusalem Bible sọ pé ìfẹ́ Kristi “jẹ́ ìyàlẹ́nu gidi fún wa.” Nígbà tí a bá gbé ìfẹ́ Kristi yẹ̀wò, a máa ń fi ọ̀ranyàn mú wa, a máa ń rùmọ̀lára wa sókè lọ́nà tí ó jinlẹ̀, àní ó máa ń jẹ́ ìyàlẹ́nu gidi fún wa. Ó ń gbún ọkàn wa ní kẹ́ṣẹ́ ó sì ń sún wa láti gbé ìgbésẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ J. B. Phillips ṣe tún un sọ lọ́rọ̀ mìíràn, “orísun gan-an ti ìgbésẹ̀ wa ni ìfẹ́ fún Kristi.” Irú ìsúnniṣe mìíràn èyíkéyìí kò lè mú èso tí yóò wà pẹ́ títí wá nínú wa, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwọn Farisi ti fi hàn.

‘Ẹ Ṣọ́ra fún Ìwúkàrà Awọn Farisi’

11. Ṣàpèjúwe ìṣarasíhùwà àwọn Farisi sí àwọn iṣẹ́ tí ó jẹmọ́ ìsìn.

11 Àwọn Farisi sọ ìjọsìn Ọlọrun di aláìgbéṣẹ́ rárá. Dípò títẹnumọ́ ìfẹ́ fún Ọlọrun, wọ́n tẹnumọ́ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ìdiwọ̀n fún ipò tẹ̀mí. Gbígbà tí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ òfin gbà wọ́n lọ́kàn mú kí wọn fara hàn bí olódodo lóde, ṣùgbọ́n nínú lọ́hùn-ún wọ́n “kún fún egungun òkú ènìyàn ati gbogbo onírúurú ohun àìmọ́.”—Matteu 23:27.

12. Lẹ́yìn tí Jesu wo ọkùnrin kan sàn, báwo ni àwọn Farisi ṣe fi ara wọn hàn pé àwọn yigbì ní ọkàn-àyà?

12 Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan Jesu fi tìyọ́nú tìyọ́nú wo ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ gbẹ hangogo sàn. Ẹ wo bí ọkùnrin yìí yóò ti láyọ̀ tó láti ní ìrírí ìwòsàn ojú-ẹsẹ̀ ti àmódi kan tí kò sí iyèméjì pé ó ti fa ìnira ti ara-ìyára àti ti èrò ìmọ̀lára fún un! Síbẹ̀, àwọn Farisi kò bá a yọ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n wonkoko mọ ìtọpinpin ìlànà—pé Jesu ti ṣe ìrànwọ́ ní ọjọ́ Sábáàtì. Pẹ̀lú ìtọpinpin ìtumọ̀ Òfin tí ó gbà wọ́n lọ́kàn, àwọn Farisi kùnà ìtumọ̀ tòótọ́ gan-an tí Òfin náà ní pátápátá. Abájọ tí Jesu fi “ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi sí yíyigbì ọkàn-àyà wọn”! (Marku 3:1-5) Síwájú síi, ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ . . . ṣọ́ra fún ìwúkàrà awọn Farisi ati awọn Sadusi.” (Matteu 16:6) Ìgbésẹ̀ wọn àti ìṣarasíhùwà wọn ni a túfó nínú Bibeli fún àǹfààní wa.

13. Ẹkọ́ wo ni a rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ àwọn Farisi?

13 Àpẹẹrẹ àwọn Farisi ń kọ́ wa pé a níláti ní ojú-ìwòye tí ó lọ́gbọ́n nínú nípa iṣẹ́. Nítòótọ́, iṣẹ́ ṣe kókó, nítorí “ìgbàgbọ́ láìsí awọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” (Jakọbu 2:26) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé ní ìtẹ̀sí láti ṣèdájọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa ohun tí wọ́n ṣe dípò ohun tí wọ́n jẹ́. Nígbà mìíràn, a tilẹ̀ lè ṣèdájọ́ ara wa lọ́nà yìí. Iṣẹ́ ti lè gbà wá lọ́kàn, bí ẹni pé èyí nìkan ní ìlànà àfilélẹ̀ tí ipò tẹ̀mí wa rọ̀ mọ́. A lè gbàgbé ìjẹ́pàtàkì ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ète ìsúnniṣe wa. (Fiwé 2 Korinti 5:12.) A lè di agbófinrù aláìṣeé yípadà ẹni tí “ń sẹ́ kòkòrò kantíkantí ṣugbọn tí ń gbé ràkúnmí mì kàló,” tí ń ṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ òfin nígbà tí ó sì ń tẹ ète rẹ̀ lójú.—Matteu 23:24.

14. Báwo ni àwọn Farisi ṣe dàbí ife tàbí àwo ìjẹun tí ó lẹ́gbin?

14 Ohun tí kò yé àwọn Farisi ni pé bí ẹnì kan bá nífẹ̀ẹ́ Jehofa nítòótọ́, àwọn ìṣe ìfọkànsin Ọlọrun yóò wá lọ́nà ti ẹ̀dá. Ipò tẹ̀mí máa ń ṣàn láti inú wá sóde. Nípa èyí Jesu fi tagbára tagbára fi àwọn Farisi bú fún ìrònú amúniṣìnà wọn, ní sísọ pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin ati ẹ̀yin Farisi, alágàbàgebè! nitori pé ẹ̀yin fọ òde ife ati àwo ìjẹun mọ́, ṣugbọn ní inú wọ́n kún fún ìkónilẹ́rù ati àìmọníwọ̀n. Farisi afọ́jú, kọ́kọ́ fọ inú ife ati àwo ìjẹun mọ́, kí òde rẹ̀ pẹlu le di èyí tí ó mọ́.”—Matteu 23:25, 26.

15. Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ tí ń fi hàn pé Jesu wo rékọjá ìrísí.

15 Ìrísí òde ife, àwo ìjẹun, tàbí ilé kan pàápàá kò ṣí ohun gbogbo payá. Ẹwà tẹ́ḿpìlì Jerusalemu, èyí tí Jesu pè ní “hòrò awọn ọlọ́ṣà” nítorí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú rẹ̀, ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní kàyéfì. (Marku 11:17; 13:1) Ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa tẹ́ḿpìlì náà jẹ́ òtítọ́ nípa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristian aláfẹnujẹ́, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Kristẹndọm ti fi hàn. Jesu wí pé òun yóò ṣèdájọ́ àwọn kan tí wọ́n sọ pé àwọn ń ṣe “iṣẹ́ agbára” ní orúkọ òun pé wọ́n jẹ́ “oníṣẹ́ ìwà-àìlófin.” (Matteu 7:22, 23) Ní ìyàtọ̀ gédégédé, òun sọ nípa opó kan tí ó ṣètọrẹ iye owó kan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má tó nǹkankan ní tẹ́ḿpìlì pé: “Òtòṣì opó yii sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo awọn tí wọ́n ń sọ owó sínú awọn àpótí ìṣúra naa . . . lati inú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní sínú rẹ̀, gbogbo ohun-ìní ìgbésí-ayé rẹ̀.” (Marku 12:41-44) Ìdájọ́ tí kò báramu ha ni bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Nínú àwọn ọ̀ràn méjèèjì, Jesu fi ojú-ìwòye Jehofa hàn. (Johannu 8:16) Ó rí àwọn ète ìsúnniṣe tí ń bẹ lẹ́yìn àwọn iṣẹ́ náà ó sì ṣèdájọ́ bí ó ti yẹ.

“Olúkúlùkù Ní Ìbámu Pẹ̀lú Agbára Ìlèṣe Nǹkan Tirẹ̀”

16. Èéṣe tí kò fi yẹ kí a máa fi ìgbòkègbodò wa wéra nígbà gbogbo pẹ̀lú ti Kristian mìíràn?

16 Bí agbára ìsúnniṣe wa bá tọ̀nà, kò sí ìdí kankan láti máa ṣe ìfiwéra nígbà gbogbo. Fún àpẹẹrẹ, a kò ṣàṣeparí ohun rere kankan nípa fífi pẹ̀lú ìtiraka díje láti lè lo iye àkókò kan náà tí Kristian mìíràn lò nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ tàbí mú ara wa dọ́gba pẹ̀lú àṣeyọrí onítọ̀hún nínú wíwàásù. Jesu sọ pé kí o nífẹ̀ẹ́ Jehofa pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, èrò-inú, ọkàn, àti okun rẹ—kì í ṣe ti ẹlòmíràn. Agbára ìlèṣe ẹnìkọ̀ọ̀kan, ìmí-inú, àti àyíká ipò yàtọ̀ síra. Bí ipò tìrẹ bá yọ̀ǹda, ìfẹ́ yóò sún ọ láti lo àkókò púpọ̀ síi nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà—bóyá gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún pàápàá. Bí ó ti wù kí ó rí, bí o bá ń bá àìsàn kan jìjàkadì, àkókò tí o lò nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà lè dínkù sí iye tí ìwọ yóò fẹ́ láti lò. Máṣe rẹ̀wẹ̀sì. Kì í ṣe wákàtí ni a fi ń díwọ̀n ìṣòtítọ́ sí Ọlọrun. Bí o bá ní ète ìsúnniṣe tí ó mọ́ gaara, ìwọ yóò ní ìdí fún níní ìdùnnú-ayọ̀. Paulu kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ fúnra rẹ̀ jẹ́, nígbà naa ni oun yoo ní ìdí fún ayọ̀ àṣeyọrí níti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹlu ẹlòmíràn.”—Galatia 6:4.

17. Ní ọ̀rọ̀ tìrẹ, ṣàlàyé òwe àkàwé tálẹ́ńtì ní kúkúrú.

17 Gbé òwe àkàwé Jesu nípa tálẹ́ńtì yẹ̀wò, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ ní Matteu 25:14-30. Ọkùnrin kan tí ó máa tó rín ìrìn-àjò lọ sí ìdálẹ̀ fi ọlá-àṣẹ pé àwọn ẹrú rẹ̀ ó sì fi àwọn nǹkan ìní rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́. “Ó sì fi talẹnti márùn-ún fún ọ̀kan, méjì fún òmíràn, ati ẹyọkan fún òmíràn síbẹ̀, fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹlu agbára ìlèṣe nǹkan tirẹ̀.” Nígbà tí ọ̀gá náà padà dé láti yanjú ìṣirò owó pẹ̀lú àwọn ẹrú rẹ̀, kí ni ó rí? Ẹrú tí a ti fún ní tálẹ́ńtì márùn-ún jèrè márùn-ún síi. Bákan náà, ẹrú tí a ti fún ní tálẹ́ńtì méjì jèrè méjì síi. Ẹrú tí a ti fún ní tálẹ́ńtì kan bò ó mọ́ inú ilẹ̀ kò sì ṣe ohunkóhun láti sọ ọrọ̀ ọ̀gá rẹ̀ di púpọ̀. Báwo ni ọ̀gá náà ṣe gbé ipò náà yẹ̀wò?

18, 19. (a) Èéṣe tí ọ̀gá náà kò ṣe fi ẹrú tí a fún ní tálẹ́ńtì méjì wé ẹrú tí a fún ní tálẹ́ńtì márùn-ún? (b) Kí ni òwe àkàwé tálẹ́ńtì kọ́ wa nípa ìgbóríyìn àti ṣíṣe ìfiwéra? (d) Èéṣe tí a fi ṣèdájọ́ ẹrú kẹta lọ́nà tí kò báradé?

18 Lákọ̀ọ́kọ́, jẹ́ kí a gbé àwọn ẹrú tí a fún ní tálẹ́ńtì márùn-ún àti méjì yẹ̀wò níkọ̀ọ̀kan. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹrú wọ̀nyí, ni ọ̀gá náà wí fún pé: “O káre láé, ẹrú rere ati olùṣòtítọ́!” Ohun yóò ha ti sọ èyí fún ẹrú náà tí ó ní tálẹ́ńtì márùn-ún bí ó bá jẹ́ pé méjì péré ni òun jèrè? Kò dájú! Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, òun kò sọ fún ẹrú náà tí ó jèrè tálẹ́ńtì méjì pé: ‘Èéṣe tí o kò fi jèrè márùn-ún? Họ́wù, wo ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ sì wo iye tí ó jèrè fún mi!’ Rárá, ọ̀gá oníyọ̀ọ́nú náà, tí ó ṣàpẹẹrẹ Jesu, kò ṣe ìfiwéra. Ó yan tálẹ́ńtì “fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹlu agbára ìlèṣe nǹkan tirẹ̀,” kò sì retí ohunkóhun padà ju ohun tí olúkúlùkù bá lè fúnni. Àwọn ẹrú méjèèjì gba oríyìn kan náà, nítorí pé àwọn méjèèjì fi tọkàn tọkàn ṣiṣẹ́ fún ọ̀gá wọn. Gbogbo wa lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú èyí.

19 Àmọ́ ṣáá o, a kò gbóríyìn fún ẹrú kẹta. Níti tòótọ́, a jù ú sínú òkùnkùn lóde. Níwọ̀n bí òun ti gbà tálẹ́ńtì kan, a kò lè retí pé kí ó pèsè ohun púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ti ẹrú náà tí ó ní tálẹ́ńtì márùn-ún. Ṣùgbọ́n, òun kò tilẹ̀ gbìyànjú! Ìdájọ́ aláìbáradé rẹ̀ ga dé ìpẹ̀kun nítorí ìwà ‘burúkú ati ìlọ́ra’ tí ó wà ní ọkàn-àyà rẹ̀, èyí tí ó fi àìnífẹ̀ẹ́ fún ọ̀gá náà hàn.

20. Báwo ni Jehofa ṣe ń wo àwọn ààlà wa?

20 Jehofa retí pé kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa nífẹ̀ẹ́ òun pẹ̀lú gbogbo okun wa, síbẹ̀ ẹ wo bí ó ti múni lọ́kàn yọ̀ tó pé “ó mọ ẹ̀dá wa; ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá”! (Orin Dafidi 103:14) Owe 21:2 (NW) sọ pé “Jehofa ń ṣe ìfojú díwọ̀n ọkàn-àyà”—kì í ṣe àkójọ ìsọfúnni oníṣirò. Ó lóye ààlà èyíkéyìí tí a kò ní agbára lé lórí, yálà wọ́n jẹ́ ti ìṣúnná owó, ti ará, ti èrò-ìmọ̀lára, tàbí lọ́nà mìíràn. (Isaiah 63:9) Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, ó ń retí pé kí a lo èyí tí ó dára jù nínú gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ wa tí a lè ní. Jehofa jẹ́ ẹni pípé, ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ń bá àwọn olùjọsìn rẹ̀ aláìpé lò, òun kì í ṣe olójú-ìwòye pé ohunkóhun tí ó bá dínkù sí ìjẹ́pípé kò yẹ ní títẹ́wọ́gbà. Kì í ṣe aláìlọ́gbọ́n nínú, nínú àwọn ìbálò rẹ̀ tàbí aláìlóye nínú àwọn ìfojúsọ́nà rẹ̀.

20 Nínífẹ̀ẹ́ Jehofa pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, ọkàn, èrò-inú, àti okun wa “níyelórí lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo awọn ọrẹ-ẹbọ sísun ati ẹbọ.” (Marku 12:33) Bí ìfẹ́ bá sún wa, nígbà náà àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun. Peteru kọ̀wé pé bí àwọn ànímọ́ oníwà-bí-Ọlọ́run, títíkan ìfẹ́, “bá wà ninu yín tí wọ́n sì kún àkúnwọ́sílẹ̀, wọn kì yoo jẹ́ kí ẹ di yálà aláìṣiṣẹ́ tabi aláìléso níti ìmọ̀ pípéye nipa Oluwa wa Jesu Kristi.”—2 Peteru 1:8.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

Ní Ṣíṣàtúnyẹ̀wò

◻ Kí ni ó níláti jẹ́ ipá ìsúnniṣe tí ń bẹ lẹ́yìn iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun?

◻ Báwo ni ìfẹ́ Kristi ṣe sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa láti ṣiṣẹ́sin Jehofa?

◻ Ohun tí ó gba àfiyèsí àwọn Farisi jùlọ wo ni a gbọ́dọ̀ yẹra fún?

◻ Èéṣe tí kò fi lọ́gbọ́n nínú láti máa fi iṣẹ́-ìsìn wa wéra ṣáá pẹ̀lú ti Kristian mìíràn?

21. Bí ìfẹ́ bá sún wa ṣe iṣẹ́-ìsìn wa sí Ọlọrun, ìyọrísí rere wo ni yóò tẹ̀lé e?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Agbára ìlèṣe nǹkan, ìmí-inú, àti àyíká ipò àwọn ènìyàn máa ń yàtọ̀ síra

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́