Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Gẹ́gẹ́ bí Galatia 6:8 ṣe sọ, “ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹlu níní ẹran-ara rẹ̀ lọ́kàn yoo ká ìdíbàjẹ́ lati inú ẹran-ara rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹlu níní ẹ̀mí lọ́kàn yoo ká ìyè àìnípẹ̀kun lati inú ẹ̀mí.” “Ẹ̀mí” wo ni a ní lọ́kàn, báwo sì ni a ṣe lè tipa báyìí ká ìyè?
Èdè ọ̀rọ̀ Heberu àti Griki náà tí a túmọ̀ sí “ẹ̀mí” ní onírúurú ìtumọ̀, irú bíi (1) ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun, (2) ipá ìwàláàyè tí ó wà nínú àwọn ẹ̀dá ènìyàn àti ẹranko, (3) ipá tí ń sún agbára èrò-orí ẹnì kan ṣiṣẹ́, àti (4) ẹ̀dá ẹ̀mí, tàbí áńgẹ́lì. Àkọ́kọ́ lára àwọn wọ̀nyí—ipa agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun—ni ìtumọ̀ tí a rí nínú Galatia 6:8.
Gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni, kíyèsí Galatia 3:2, níbi tí a ti kọ́kọ́ rí ìlò “ẹ̀mí” nínú ìwé Àwọn Ará Galatia. Paulu bi àwọn Kristian pé: “Ẹ̀yin ha gba ẹ̀mí nitori awọn iṣẹ́ òfin tabi nitori gbígbọ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́?” Lẹ́yìn náà, ní Galatia 3:5, ó so “ẹ̀mí” yẹn pọ̀ mọ́ ṣíṣe àwọn iṣẹ́ agbára. Nítorí náà “ẹ̀mí” tí ó tọ́ka sí ni ẹ̀mí mímọ́, ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun tí kò ṣeé fojúrí.
Lẹ́yìn èyí, ní Galatia 5:16, Paulu fi ìyàtọ̀ hàn láàárín ẹ̀mí àti ẹran-ara. A kà pé: “Emi wí pé, Ẹ máa rìn nipa ẹ̀mí ẹ̀yin kì yoo sì ṣe ìfẹ́-ọkàn ti ẹran-ara rárá.” Nípa “ìfẹ́-ọkàn ti ẹran-ara” òun tí ó ní lọ́kàn ni ẹran-ara ẹ̀ṣẹ̀ ti ẹ̀dá ènìyàn. Nípa báyìí, ní Galatia 5:19-23, ó to “iṣẹ́ ti ẹran-ara” lẹ́sẹẹsẹ ní ìyàtọ̀ sí “àmújáde-èso ti ẹ̀mí.”
Nípa bẹ́ẹ̀, ní Galatia 6:8, ẹni náà “tí ń fúnrúgbìn pẹlu níní ẹran-ara rẹ̀ lọ́kàn” gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹnì kan tí ó yọ̀ọ̀da kí ìfẹ́-ọkàn ẹlẹ́ṣẹ̀ ti ẹ̀dá ènìyàn darí òun, tí ó fara fún “iṣẹ́ ti ẹran-ara.” Ó lè ní ìrírí àbájáde oníwà ìbàjẹ́ ti irú ìwà bẹ́ẹ̀, bí òun kò bá sì yípadà, dájúdájú òun kì yóò jèrè ìyè nínú tàbí lábẹ́ Ìjọba Ọlọrun.—1 Korinti 6:9, 10.
Gẹ́gẹ́ bí Kristian olùfọkànsìn a níláti ní ìfẹ́-ọkàn láti ‘fúnrúgbìn pẹlu níní ẹ̀mí Ọlọrun lọ́kàn.’ Ìyẹn wémọ́ gbígbé ìgbésí-ayé ní ọ̀nà kan tí ó ń fàyègba ẹ̀mí mímọ́ láti ṣiṣẹ́ fàlàlà nínú ìgbésí-ayé wa, tí ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi àwọn àmújáde-èso rẹ̀ hàn. A níláti fi ìyẹn sọ́kàn nígbà tí a bá ń pinnu ohun tí a níláti kà tàbí àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n tí a níláti wò. A ń fúnrúgbìn pẹ̀lú ẹ̀mí lọ́kàn bí a ṣe ń fiyèsí àwọn ìpàdé ìjọ tí a sì ń gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn àwọn alàgbà tí ẹ̀mí yàn sípò sílò.—Ìṣe 20:28.
Ó dùnmọ́ni pé, Galatia 6:8 wá sí ìparí pẹ̀lú ìdánilójú náà pé bí a ṣe ń fúnrúgbìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́, àwa yóò wà ní ojú ìlà láti “ká ìyè àìnípẹ̀kun lati inú ẹ̀mí.” Bẹ́ẹ̀ni, lórí ìpìlẹ̀ ìràpadà Kristi, Ọlọrun yóò nawọ́ ìyè tí kò lópin sí wa nípasẹ̀ ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí mímọ́.—Matteu 19:29; 25:46; Johannu 3:14-16; Romu 2:6, 7; Efesu 1:7.