ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 7/1 ojú ìwé 20-25
  • Àwọn Olùgbé Papọ̀ Ní “Ilẹ̀” Tí A Múpadàbọ̀sípò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Olùgbé Papọ̀ Ní “Ilẹ̀” Tí A Múpadàbọ̀sípò
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ilẹ̀” Tẹ̀mí
  • Àwọn Àjèjì Jẹ́ Ògbóṣáṣá ní “Ilẹ̀” Náà
  • “Bíi Séríkí”
  • Àwọn Àlùfáà àti Àwọn Àgbẹ̀
  • “Ilẹ̀” náà Wà Títí
  • “Israeli Ọlọrun” àti “Ogunlọ́gọ̀ Ńlá”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìṣàbójútó Lọ́nà Ìṣètò Ìṣàkóso Ọlọ́run Ní Sànmánì Kristẹni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ǹjẹ́ o Ti Rí “Ẹ̀mí Òtítọ́ Náà” Gbà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ọlọ́run Kà Wọ́n Sẹ́ni Tó Yẹ Láti Ṣamọ̀nà Lọ Sáwọn Ìsun Omi Ìyè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 7/1 ojú ìwé 20-25

Àwọn Olùgbé Papọ̀ Ní “Ilẹ̀” Tí A Múpadàbọ̀sípò

“A óò máa pè yín ní Àlùfáà Oluwa: wọn óò máa pè yín ní Ìránṣẹ́ Ọlọrun wa.”—ISAIAH 61:6.

1, 2. (a) Kí ni àyè àwọn aláwọ̀ṣe ní Israeli? (b) Irú ẹ̀mí wo ni àwọn mẹ́ḿbà “ogunlọ́gọ̀ ńlá” náà fi hàn ní àkókò òde-òní?

NÍ ÀWỌN àkókò ìgbàanì, nígbà ti Israeli bá jẹ́ olùṣòtítọ́ wọ́n máa ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí sí ògo Jehofa lójú aráyé. (Isaiah 41:8, 9; 43:10) Ọ̀pọ̀ lára àwọn àjèjì dáhùnpadà wọ́n sì wá láti jọ́sìn Jehofa ní ìkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn àyànfẹ́ Rẹ̀. Níti gàsíkíá, ohun tí Rutu sọ fún Naomi ni àwọn náà sọ fún Israeli pé: “Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò máa ṣe ènìyàn mi, Ọlọrun rẹ ni yóò sì máa ṣe Ọlọrun mi.” (Rutu 1:16) Wọ́n juwọ́sílẹ̀ fún àwọn ohun tí a là sílẹ̀ nínú májẹ̀mú Òfin, kí àwọn ọkùnrin kọlà. (Eksodu 12:43-48) Àwọn kan lára àwọn obìnrin náà fẹ́ àwọn ọmọ Israeli. Rahabu ará Jeriko àti Rutu ará Moabu di ìyá-ńlá fún Jesu Kristi. (Matteu 1:5) Àwọn aláwọ̀ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ apákan ìjọ Israeli.—Deuteronomi 23:7, 8.

2 Ní ìjọra pẹ̀lú àwọn aláwọ̀ṣe ní Israeli, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” lónìí ti sọ fún àwọn àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró pé: “A óò bá ọ lọ, nítorí àwa ti gbọ́ pé, Ọlọrun wà pẹ̀lú rẹ.” (Ìṣípayá 7:9; Sekariah 8:23) Wọ́n mọ̀ pé àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró wọ̀nyí ni “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” ti Jehofa, wọn sì ń ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú wọn tímọ́tímọ́ débi pé àwọn ẹni-àmì-òróró àti “àwọn àgùtàn mìíràn” jẹ́ “agbo kan, olùṣọ́ àgùtàn kan.” (Matteu 24:45-47; Johannu 10:16) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà nígbà tí gbogbo àwọn ẹni-àmì-òróró arákùnrin wọn bá ti gba èrè wọn ní ọ̀run? Wọn kò níláti bẹ̀rù. Jálẹ̀ gbogbo “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí, Jehofa ti múrasílẹ̀ fún àkókò náà.—2 Timoteu 3:1.

“Ilẹ̀” Tẹ̀mí

3. Kí ni “awọn ọ̀run titun” tí Peteru sọtẹ́lẹ̀, ìgbà wo sì ni a fìdí wọn múlẹ̀?

3 Aposteli Peteru sọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣètò ìṣàkóso àtọ̀runwá nínú èyí tí 144,000 àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró yóò jẹ́ apákan. Ó wí pé: “Awọn ọ̀run titun ati ilẹ̀-ayé titun kan wà tí awa ń dúró dè ní ìbámu pẹlu ìlérí rẹ̀, ninu awọn wọnyi ni òdodo yoo sì máa gbé.” (2 Peteru 3:13) “Awọn ọ̀run titun” wọ̀nyí ni a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní 1914, nígbà tí Kristi gun orí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba ní Ìjọba ọ̀run. Ṣùgbọ́n kí ni níti “ilẹ̀-ayé titun”?

4. (a) Ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò retí wo ni ó ṣẹlẹ̀ ní 1919? (b) Kí ni ‘orílẹ̀-èdè tí a bí lẹ́ẹ̀kan náà,’ kí sì ni ‘ilẹ̀ tí ó hu nǹkan jáde pẹ̀lú ìrọbí’?

4 Ní 1919, Jehofa mú àwọn àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró jáde kúrò nínú oko-òǹdè Babiloni Ńlá. (Ìṣípayá 18:4) Fún àwọn aṣáájú Kristẹndom, ìṣẹ̀lẹ̀ amúnijígìrì yìí ni a kò retí rárá. Nípa rẹ̀, Bibeli sọ pé: “Ta ni ó tí ì gbọ́ irú èyí rí? Ta ni ó tí ì rí irú èyí rí? Ilẹ̀ yóò ha hu nǹkan jáde pẹ̀lú ìrọbí ní ọjọ́ kan bí? Tàbí a ha lè bí orílẹ̀-èdè kan lẹ́ẹ̀kan náà bí?” (Isaiah 66:8, NW) Nígbà tí ijọ ẹni-àmì-òróró yọ jáde lójijì níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí a dánídè, ó jẹ́ orílẹ̀-èdè tí a “bí lẹ́ẹ̀kan náà” nítòótọ́. Ṣùgbọ́n, kí ni, “ilẹ̀” náà? Ní ọ̀nà kan, nípa ti ẹ̀mí ó jẹ́ ọgbọọgba pẹ̀lú ilẹ̀ Israeli ìgbàanì. Ó jẹ́ ilẹ̀-àkóso ìgbòkègbodò tí a yọ̀ọ̀da fún “orílẹ̀-èdè” titun tí a bí náà, ibi tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Paradise ti inú ìwé Isaiah ti ní ìmúṣẹ tẹ̀mí, ti òde-òní. (Isaiah 32:16-20; 35:1-7; fiwé Heberu 12:12-14.) Ibi yòówù ti Kristian kan wà níti ara, ó wà ní “ilẹ̀” náà.

5. Apá pàtàkì wo ni ó bẹ̀rẹ̀ ní 1919? Ṣàlàyé.

5 Kí ni èyí ní ín ṣe pẹ̀lú “ilẹ̀-ayé titun” tí Peteru sọtẹ́lẹ̀? Tóò, “orílẹ̀-èdè” titun náà, tí a bí ní 1919 nínú “ilẹ̀” tí a múpadàbọ̀sípò, ni ó níláti dàgbà di ètò-àjọ kárí-ayé tí ó ní àwọn ẹni-àmì-òróró olùyin Jehofa àti àwọn tí kì í ṣe ẹni-àmì-òróró nínú. Ètò-àjọ yìí yóò la Armageddoni já sínú ayé titun Ọlọrun. Ní ọ̀nà yìí orílẹ̀-èdè náà ni a lè wò gẹ́gẹ́ bí apá pàtàkì ẹgbẹ́ ẹ̀dá ènìyàn olódodo, ilẹ̀-ayé titun, tí yóò wà lẹ́yìn ìparun ayé Satani.a Ní àárín àwọn ọdún 1930, àwọn ẹni-àmì-òróró, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwùjọ kan, ni a ti kójọpọ̀ sínú ilẹ̀ náà tí a múpadàbọ̀sípò. Láti ìgbà náà wá, ìtẹnumọ́ ti wà lórí kíkó ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àgùtàn mìíràn jọ, tí iye wọn lónìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà márùn-ún. (Ìṣípayá 14:15, 16) Àwọn olùgbé “ilẹ̀” náà ha ti pọ̀ jù bí? Bẹ́ẹ̀kọ́, ààlà rẹ̀ ní a lè mú gbòòrò púpọ̀ tó bí ó bá ti yẹ. (Isaiah 26:15) Níti tòótọ́, ó múnilóríyá láti rí àwọn olùgbé rẹ̀ tí ń pọ̀ síi bí àwọn àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró ti ń fi “èso”—oúnjẹ tẹ̀mí afúnnilókun, tí ń fúnni ní ìlera kún—“ilẹ̀” náà. (Isaiah 27:6) Ṣùgbọ́n kí ni ipò àwọn àgùtàn mìíràn wọ̀nyí nínú “ilẹ̀” ti a múpadàbọ̀sípò tí àwọn ènìyàn Ọlọrun?

Àwọn Àjèjì Jẹ́ Ògbóṣáṣá ní “Ilẹ̀” Náà

6. Báwo ni àwọn àjèjì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí di ògbóṣáṣá nínú “ilẹ̀” àwọn ènìyàn Ọlọrun?

6 Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn aláwọ̀ṣe ní ilẹ̀ Israeli ṣe juwọ́sílẹ̀ fún Òfin Mose, ogunlọ́gọ̀ ńlá lónìí ní “ilẹ̀” tí a múpadàbọ̀sípò náà ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jehofa. Bí àwọn arákùnrin wọn ẹni-àmì-òróró ṣe kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n yàgò pátápátá kúrò nínú ìjọsìn èké wọ́n sì pa ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀ mọ́. (Ìṣe 15:19, 20; Galatia 5:19, 20; Kolosse 3:5) Wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jehofa pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, èrò-inú, ọkàn, àti okun wọn, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn gẹ́gẹ́ bí ara wọn. (Matteu 22:37; Jakọbu 2:8) Ní Israeli ìgbàanì àwọn aláwọ̀ṣe ṣèrànlọ́wọ́ nínú kíkọ́ tẹmpili Solomoni wọ́n sì kọ́wọ́ti dídá ìjọsìn tòótọ́ padà. (1 Kronika 22:2; 2 Kronika 15:8-14; 30:25) Lónìí, ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ń lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n ń ṣèrànlọ́wọ́ láti gbé àwọn ìjọ àti àyíká ró, kí a má tilẹ̀ mẹ́nuba àwọn ìdáwọ́lé ilé kíkọ́ nípa ti ara, bí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ, àti àwọn ilé lílo ẹ̀ka.

7. Kí ni ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìgbèkùn Jerusalemu nígbà tí àwọn ọmọ Lefi kò tó láti bójútó iṣẹ́-ìsìn tẹ́ḿpìlì?

7 Ní 537 B.C.E., nígbà tí Israeli padà dé láti oko-òǹdè Babiloni, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣíṣètò iṣẹ́-ìsìn ní tẹ́ḿpìlì tí a túnkọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n padà kò pọ̀ púpọ̀. Nípa báyìí, àwọn Netinimu—àwọn àjèjì olùgbé tí wọ́n kọlà tí wọ́n ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọ Lefi tẹ́lẹ̀—ni a fún ní àǹfààní tí ó pọ̀ síi nínú iṣẹ́-ìsìn tẹ́ḿpìlì. Bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò dọ́gba pẹ̀lú àwọn ẹni-àmì-òróró àlùfáà Aaroni.b—Esra 7:24; 8:15-20; Nehemiah 3:22-26.

8, 9. Báwo ni àwọn àgùtàn mìíràn ṣe gba ẹrù-iṣẹ́ tí ń pọ̀ síi nínú ṣíṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?

8 Àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró lónìí ti tẹ̀lé àpẹẹrẹ yìí. Bí “ìgbà ìkẹyìn” ti tẹ̀síwájú, àwọn tí ó ṣẹ́kù lára àwọn ẹni-àmì-òróró ti túbọ̀ ń dínkù sí i ní “ilẹ̀” àwọn ènìyàn Ọlọrun. (Danieli 12:9; Ìṣípayá 12:17) Nítorí ìdí èyí, nísinsìnyí ogunlọ́gọ̀ ńlá ni ó ń ṣàṣeparí èyí tí ó pọ̀ jù nínú “iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀” náà. (Ìṣípayá 7:15) Ní títẹ̀lé ìdarí àwọn arákùnrin wọn ẹni-àmì-òróró, wọ́n ń “rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọrun nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” Wọn kò “gbàgbé rere ṣíṣe ati ṣíṣe àjọpín awọn nǹkan pẹlu awọn ẹlòmíràn,” ní mímọ̀ pé “irúfẹ́ awọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọrun dùn sí jọjọ.”—Heberu 13:15, 16.

9 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ń fi ọgọ́ọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún pọ̀ sí i lọ́dọọdún, àìní tí ń pọ̀ síi wà fún àbójútó. Nígbà kan rí èyí ni a ń bójútó kìkì láti ọwọ́ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró. Nísinsìnyí, àbójútó èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọ, àti àwọn àyíká, àgbègbè, àti àwọn ẹ̀ka ilé-iṣẹ́, ni ó ti di ọ̀ranyàn láti fi fún àwọn àgùtàn mìíràn. Ní 1992 díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí ni a fún ní àǹfààní láti máa pésẹ̀ sí ìpàdé àwọn ìgbìmọ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí àwọn olùrànlọ́wọ́ tí ń kópa nínú ìjíròrò ṣùgbọ́n tí kì í lọ́wọ́ nínú ìpinnu ṣíṣe. Síbẹ̀, àwọn àgùtàn mìíràn ṣì jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn ẹni-àmì-òróró Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn wọ́n sì kà á sí àǹfààní láti ṣètìlẹyìn fún wọn gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú ti Jehofa.—Matteu 25:34-40.

“Bíi Séríkí”

10, 11. Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn Filistini kan, báwo ni àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá àwọn ènìyàn Ọlọrun tẹ́lẹ̀rí ṣe yí ọkàn-àyà wọn padà? Pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni?

10 Ọ̀nà tí àwọn olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú gbà lo àwọn àgùtàn mìíràn nínú ipò ẹrù-iṣẹ́ ni a sọtẹ́lẹ̀ nínú Sekariah 9:6, 7. (NW) A kà níbẹ̀ pé: “Dájúdájú èmi yóò ké ìgbéraga àwọn Filistini kúrò. Èmi yóò sì mú àwọn ohun tí ẹ̀jẹ̀ ti kó àbàwọ́n bá kúrò ní ẹnu rẹ̀ àti àwọn ohun ìríra rẹ̀ kúró láàárín eyín rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ dájúdájú ni yóò sì ṣẹ́kù fún Ọlọrun wa; yóò sì dàbíi séríkí kan ní Juda, àti Ekroni bí àwọn Jebusi.”c Àwọn Filistini jẹ́ ọ̀tá àwọn ènìyàn Jehofa tí a ti fi bú, bí ayé Satani ti wà lónìí. (1 Johannu 5:19) Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn ará Filistini run nígbẹ̀yìn gbẹ́yín gẹ́gẹ́ bí ènìyàn kan, bẹ́ẹ̀ ni ayé yìí, pẹ̀lú àwọn ohun tí ó parapọ̀ jẹ́ ti ìsìn, òṣèlú, àti ti ìṣòwò, yóò ní ìrírí ìbínú ìparun Jehofa.—Ìṣípayá 18:21; 19:19-21.

11 Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Sekariah, àwọn Filistini kan yí ọkàn wọn padà, èyí sì ṣàpẹẹrẹ pé àwọn ènìyàn ayé kan lónìí kì yóò máa báa lọ láti jẹ́ ọ̀tá Jehofa. Wọn yóò pa ìbọ̀rìṣà ti ìsìn tì pẹ̀lú ààtò tí ń kóni nírìíra àti ẹbọ ìríra tí wọn yóò sì di mímọ́ tónítóní lójú Jehofa. Ní ọjọ́ wa irú àwọn “Filistini” tí a túnṣe yìí ni a rí láàárín ogunlọ́gọ̀ ńlá.

12. Ní àkókò òde-òní, báwo ni “Ekroni” ṣe di “bí àwọn Jebusi”?

12 Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ náà, Ekroni tíí ṣe ìlú-ńlá Filistini tí ó ṣe pàtàkì jùlọ yóò di “bí àwọn Jebusi.” Àwọn Jebusi náà ti fìgbà kan rí jẹ́ àwọn ọ̀tá Israeli. Jerusalemu wà lọ́wọ́ wọn títí di ìgbà tí Dafidi ṣẹ́gun rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀, dájúdájú àwọn kan lára àwọn tí ó la ogun náà já pẹ̀lú Israeli di àwọn aláwọ̀ṣe. Wọ́n ṣiṣẹ́sìn ní ilẹ̀ Israeli gẹ́gẹ́ bí ẹrú wọ́n sì tilẹ̀ ní àǹfààní láti ṣiṣẹ́ nínú kíkọ́ tẹ́ḿpìlì náà. (2 Samueli 5:4-9; 2 Kronika 8:1-18) Lónìí, “àwọn ará Ekroni” tí wọ́n yípadà sí jíjọ́sìn Jehofa náà ní àǹfààní iṣẹ́-ìsìn ní “ilẹ̀” náà lábẹ́ àbójútó olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú.

13. Kí ni séríkí ní ayé ìgbàanì?

13 Sekariah sọ pé àwọn ará Filistini yóò dàbí séríkí ní Juda. Ọ̀rọ̀ Heberu náà ʼal·luphʹ, ní èdè mìíràn “séríkí,” túmọ̀ sí “olórí ẹgbẹ̀rún” (tàbí, “olórí ẹgbẹ̀rún ọmọ ogun”). Ó jẹ́ ipò tí ó ga gan-an. Ó hàn kedere pé orílẹ̀-èdè Edomu ní séríkí 13 péré. (Genesisi 36:15-19) Ọ̀rọ̀ náà “séríkí” ni a kì í sábà lò nígbà tí a bá sọ̀rọ̀ nípa Israeli, ṣùgbọ́n gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “olórí (tàbí, balógun) ẹgbẹ̀rún” máa ń jẹyọ nígbà gbogbo. Nígbà tí Mose pe gbogbo àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè Israeli jọ, ó pe “àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní Israeli.”d Méjìlá àwọn wọ̀nyí ni ó wà, pẹ̀lú ẹ̀rí tí ó dájú Mose nìkan ni wọ́n rẹlẹ̀ sí. (Numeri 1:4-16) Ní ọ̀nà tí ó farajọ èyí, nínú ìṣètò àwọn ọmọ ogun, àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún jẹ́ igbákejì sí kìkì ọ̀gágun tàbí ọba.—2 Samueli 18:1, 2; 2 Kronika 25:5.

14. Báwo lónìí ni “Filistini” ṣe dàbí séríkí?

14 Sekariah kò sọtẹ́lẹ̀ nítòótọ́ pé ọmọ Filistini tí ó bá ronúpìwàdà yóò jẹ́ séríkí ní Israeli. Ìyẹn kò ní bójúmu, níwọ̀n bí òun kì í ti ṣe ọmọ Israeli àbínibí. Ṣùgbọ́n yóò dà bí séríkí, tí yóò ní ipò ọlá-àṣẹ tí a lè fi wé ti séríkí. Èyí sì rí bẹ́ẹ̀. Bí àṣẹ́kù àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ti ń dínkù ní iye tí ọjọ́-orí ọ̀pọ̀ àwọn tí ó là á já sì ní ààlà, gẹ́gẹ́ bí a ti lè sọ pé ó rí níti gidi, àwọn àgùtàn mìíràn tí a ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ dáradára ń ṣèrànlọ́wọ́ nígbà tí a bá nílò wọn. Wọn kò fẹ́ láti gbapò lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn ẹni-àmì-òróró. Ṣùgbọ́n àwọn olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú ń fún wọn ní ọlá-àṣẹ bí wọ́n ti nílò rẹ̀ tó ní “ilẹ̀” náà kí ètò-àjọ Ọlọrun baà lè máa tẹ̀síwájú létòlétò. Irú ọ̀nà ìtẹ̀síwájú bẹ́ẹ̀ ni a rí nínú àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn.

Àwọn Àlùfáà àti Àwọn Àgbẹ̀

15. (a) Ní ìmúṣẹ Isaiah 61:5, 6, àwọn wo ni àwọn “Àlùfáà Oluwa,” nígbà wo sì ni wọ́n ń ṣiṣẹ́sìn ní ààyè yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́? (b) Àwọn wo ni àwọn “àlejò” tí ń ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ ní Israeli, àti—nípa tẹ̀mí—kí ni iṣẹ́ yìí ní nínú?

15 Isaiah 61:5, 6 kà pé: “Àwọn àlejò yóò sì dúró, wọn óò sì bọ́ ọ̀wọ́ ẹran yín, àwọn ọmọ àlejò yóò sì ṣe atúlẹ̀ yín, àti olùrẹ́ ọwọ́ àjàrà yín. Ṣùgbọ́n a óò máa pè yín ní Àlùfáà Oluwa: wọn óò máa pè yín ní Ìránṣẹ́ Ọlọrun wa: ẹ óò jẹ ọrọ̀ àwọn Kèfèrí, àti nínú ògo wọn ní ẹ óò máa ṣògo.” Lónìí, “Àlùfáà Oluwa” ni àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró. Ní òpin gbogbo rẹ̀, wọn yóò ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí “Àlùfáà Oluwa . . . Ìránṣẹ́ Ọlọrun wa,” nínú Ìjọba ọ̀run. (Ìṣípayá 4:9-11) Àwọn wo ni “àlejò” tí ń bójútó iṣẹ́ àgbẹ̀? Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àgùtàn mìíràn, tí ń gbé ní “ilẹ̀” Israeli Ọlọrun. Kí ni iṣẹ́ olùṣọ́ àgùtàn, iṣẹ́ àgbẹ̀, àti iṣẹ́ olùrẹ́ ọwọ́ àjàrà tí wọ́n gbé fún wọn? Ní ọ̀nà tí ẹ̀mí tí ó ṣe pàtàkì, ẹrù-iṣẹ́ yìí ní ín ṣe pẹ̀lú ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́, bíbójútó wọn, àti kíkórè wọn.—Isaiah 5:7; Matteu 9:37, 38; 1 Korinti 3:9; 1 Peteru 5:2.

16. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ àwọn wo ni yóò ṣe gbogbo iṣẹ́ “ilẹ̀” àwọn ènìyàn Ọlọrun?

16 Lọ́wọ́lọ́wọ́, iye kéréje lára àwọn ọmọ Israeli nípa ti ẹ̀mí ṣì wà lórí ilẹ̀-ayé tí wọ́n ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ olùṣọ́ àgùtàn, iṣẹ́ àgbẹ̀, àti iṣẹ́ olùrẹ́ ọwọ́ àjàrà nípa tẹ̀mí. Nígbà tí a bá mú gbogbo ìjọ ẹni-àmì-òróró pátápátá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, gbogbo iṣẹ́ yìí ni a óò fi sílẹ̀ fún àwọn àgùtàn mìíràn. Àní àbójútó ti ẹ̀dá ènìyàn fún “ilẹ̀” náà pàápàá yóò wà lọ́wọ́ àwọn àgùtàn mìíràn tí wọ́n bá tóótun nígbà náà, àwọn tí a pè ní ẹgbẹ́ olórí nínú ìwé Esekieli.—Esekieli, orí 45, 46.e

“Ilẹ̀” náà Wà Títí

17. Ìmúrasílẹ̀ wo ni Jehofa ti ń ṣe jálẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

17 Bẹ́ẹ̀ni, ogunlọ́gọ̀ ńlá náà kò nídìí láti bẹ̀rù! Jehofa ti ṣe ìmúrasílẹ̀ tí ó pọ̀ tó fún wọn. Ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ lórí ilẹ̀-ayè ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí ni kíkó àwọn ẹni-àmì-òróró jọ àti fífi èdídí dí wọn. (Ìṣípayá 7:3) Bí ó ti wù kí ó rí, bí a ti ń ṣe àṣeparí ìyẹn lọ́wọ́, Jehofa ti mú kí àwọn àgùtàn mìíràn wà ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn nínú ilẹ̀ tẹ̀mí tí a múpadàbọ̀sípò. Níbẹ̀ ni a ti bọ́ wọn nípa tẹ̀mí tí a sì ti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ níti ọ̀nà tí a ń gbà gbé ìgbésí-ayé Kristian. Síwájú síi, a ti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ dáradára níti iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀, títí kan iṣẹ́ àbójútó. Nítorí èyí wọ́n dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jehofa àti àwọn ẹni-àmì-òróró arákùnrin wọn.

18. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni àwọn àgùtàn mìíràn yóò là kọjá tí wọn yóò sì di ìdúróṣinṣin wọn mú ní “ilẹ̀” Israeli nípa tẹ̀mí?

18 Nígbà tí Gogu ará Magogu bá gbé ìkọlù rẹ̀ tí ó kẹ́yìn wá sórí àwọn ènìyàn Ọlọrun, àwọn àgùtàn mìíràn yóò di ìdúró wọn mú ṣinṣin pẹ̀lú àwọn àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró ní “ilẹ̀ ìletò tí kò ní odi.” Àwọn àgùtàn mìíràn yóò ṣì wà ní “ilẹ̀” náà nígbà tí wọ́n bá la ìparun àwọn orílẹ̀-èdè já wọn yóò sì bọ́ sínú ilẹ̀-ayé titun Ọlọrun. (Esekieli 38:11; 39:12, 13; Danieli 12:1; Ìṣípayá 7:9, 14) Bí wọ́n bá ń bá a lọ láti máa jẹ́ olùṣòtítọ́, wọn kì yóò ní ìdí láti kúrò ní ọgangan ibi tí ó gbádùnmọ́ni náà.—Isaiah 11:9.

19, 20. (a) Nínú ayé titun, iṣẹ́ àbójútó ńláǹlà wo ni àwọn olùgbé “ilẹ̀” náà yóò gbádùn? (b) Ohun wo ni a ń fi ìháragàgà ńláǹlà fojúsọ́nà fún?

19 Àwọn ọba ẹ̀dá ènìyàn ni wọ́n ń ṣàkóso Israeli àtijọ́ wọ́n sì ní àwọn àlùfáà ọmọ Lefi. Nínú ayé titun náà, àwọn Kristian yóò ní iṣẹ́ àbójútó tí ó pọ̀ ju èyí lọ. Lábẹ́ Jehofa Ọlọrun, wọn yóò jẹ́ ọmọ-abẹ́ Àlùfáà Àgbà títóbi lọ́lá àti Ọba, Jesu Kristi, àti àwọn 144,000 alájùmọ̀ṣiṣẹ́pọ̀ àlùfáà àti ọba—díẹ̀ lára àwọn tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin wọn lórí ilẹ̀-ayé. (Ìṣípayá 21:1) Àwọn olùgbé ilẹ̀ ti ẹ̀mí náà tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ yóò gbé lórí ilẹ̀-ayé tí a ti múpadàbọ̀sípò di paradise níti gidi, tí wọn yóò sì máa yọ̀ ṣìnkìn nínú ìwòsàn ìbùkún tí a darí rẹ̀ wá láti ọ̀run nípasẹ̀ Jerusalemu Titun.—Isaiah 32:1; Ìṣípayá 21:2; 22:1, 2.

20 Bí kẹ̀kẹ́-ogun ńlá òkè-ọ̀run ti Jehofa ti ń tẹ̀síwájú láìdúró láti ṣàṣeyọrí àwọn ète rẹ̀, gbogbo wa ń wọ̀nà pẹ̀lú ìfojúsọ́nà tí ó gbámúṣé sí ṣíṣe ipa tí a pín fún wa. (Esekieli 1:1-28) Nígbà tí a bá ṣàṣeparí gbogbo àwọn ète wọ̀nyí nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, ronú nípa ìdùnnú-ayọ̀ tí a óò fi ṣayẹyẹ ayọ̀-ìṣẹ́gun ìsọdimímọ́ Jehofa! Orin ìyìn ńlá náà tí a kọ sínú Ìṣípayá 5:13 ni gbogbo ẹ̀dá yóò kọ pé: “Ẹni naa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ati Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa ni kí ìbùkún ati ọlá ati ògo ati agbára ńlá wà fún títí láé ati láéláé”! Yálà ipò tiwa yóò jẹ́ ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀-ayé, a kò ha ń yánhànhàn láti wà níbẹ̀, kí a pa ohun wa pọ̀ nínú ègbè orin ìyìn tí ó galọ́lá náà bí?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìwé “New Heavens and a New Earth,” tí a tẹ̀jáde ní 1953 láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ojú-ìwé 322 sí 323.

b Fún ìjíròrò lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Ipese Jehofa, ‘Awọn Ẹni Ti A Fi Funni’” nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti April 15, 1992.

c Wo ìwé Paradise Restored to Mankind—By Theocracy!, tí a tẹ̀jáde ní 1972 láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ojú-ìwé 264 sí 269.

d Ọrọ̀ Heberu náà: raʼ·shehʹ ʼal·phehʹ Yis·ra·ʼelʹ, ni a túmọ̀ sí khi·liʹar·khoi Is·ra·elʹ “àwọn olórí ẹgbẹ̀rún ọmọ ogun ti Israeli” nínú Septuagint.

e Wo “The Nations Shall Know That I Am Jehovah”—How?, tí a tẹ̀jáde ní 1971 láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ojú-ìwé 401 sí 407.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ “Ilẹ̀” wo ní a múpadàbọ̀sípò ní 1919, báwo ni a sì ṣe fi àwọn olùgbé kún inú rẹ̀?

◻ Báwo ni a ṣe fún àwọn àgùtàn mìíràn ní ẹrù-iṣẹ́ tí ó pọ̀ síi nínú “ilẹ̀” Ọlọrun tí a múpadàbọ̀sípò?

◻ Ní ọ̀nà wo ní àwọn mẹ́ḿbà àgùtàn mìíràn fi dà “bí àwọn ará Jebusi”? “bí séríkí ní Juda”?

◻ Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí àwọn àgùtàn mìíràn olùṣòtítọ́ yóò fi wà ní “ilẹ̀” náà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn ará Filistini ti òde-òní yóò “dàbí àwọn séríkí ní Juda”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Àwọn ẹni-àmì-òróró àti àwọn àgùtàn mìíràn ń ṣiṣẹ́ papọ̀ nínú ilẹ̀ tẹ̀mí náà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́